Yoruba Help from Above

/1 Nje ki Ajo-Irekoja ki o to de, nigbati Jesu mo pe wakati re de tan, ti on o ti aiye yi kuro lo sodo Baba, fife ti o fe awon tire ti o wa li aiye, o fe won titi de opin. Ati lati odo Jesu Kristi, eleri oloto, akobi ninu awon oku, ati alase awon oba aiye; Eniti o fe wa, ti o si we wa ninu eje re kuro ninu ese wa. Oluwa ti fi ara han fun mi lati okere, pe, Nitoto emi fi ifeni aiyeraiye fe o, nitorina ni emi ti se pa oreofe mo fun o. Eniti ko ba ni ife ko mo Olorun; nitoripe ife ni Olorun. Nipa eyi li a gbe fi ife Olorun han ninu wa, nitoriti Olorun ran Omo bibi re nikansoso si aiye, ki awa ki o le ye nipase re. Nitori Olorun fe araiye tobe ge, ti o fi Omo bibi re kansoso funni, ki enikeni ti o ba gba a gbo ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun. Sugbon Olorun fi ife On papa si wa han ni eyi pe, nigbati awa je elese, Kristi ku fun wa.

: /2 Li atetekose li Oro wa, Oro si wa, pelu Olorun, Olorun si li Oro na. Oro na si di ara, on si mba wa gbe, (awa si nwo ogo re, ogo bi ti omo bibi kansoso lati odo Baba wa,) o kun fun ore-ofe ati otito. Jesu wi fun u pe, Bi akoko ti mo ba nyin gbe ti pe to yi, iwo ko si ti imo mi sibe Filippi? eniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba; iwo ha ti se wipe, Fi Baba han wa? Iwo ko ha gbagbo pe, Emi wa ninu Baba, ati pe Baba wa ninu mi? oro ti emi nso fun nyin, emi ko da a so; sugbon Baba ti ngbe inu mi, on ni nse ise re. Gbogbo eyi si se, ki eyi ti a ti so lati odo Oluwa wa li enu woli ki o le se, pe, Kiyesi i, wundia kan yio loyun, yio si bi omokunrin kan, Nwon o ma pe oruko re ni Emmanueli, Itumo eyi ti ise, Olorun wa pelu wa. Laisiyemeji, titobi ni ohun ijinle iwa-bi-Olorun, eniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Emi, ti awon angeli ri, tia wasu re larin awon orile-ede, ti a gbagbo ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.

/3 Si wo o, nwon kigbe soke wipe, Kini se tawa tire, Jesu, iwo Omo Olorun? iwo wa lati da wa loro ki o to to akoko? Enikeni ti o ba jewo pe Jesu Omo Olorun ni, Olorun ngbe inu re, ati on ninu Olorun. Nitoripe ninu re ni gbogbo ekun Iwa-Olorun ngbe li araiyara. Nitori a bi omo kan fun wa, a fi omokunrin kan fun wa: ijoba yio si wa li ejika re: a o si ma pe oruko re ni Iyanu, Oludamoran, Olorun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Omo-Alade Alafia. Bi o ti nwi lowo, wo o, awosanma didan siji bo won: si wo o, ohun kan lati inu awosanma wa, ti o wipe, Eyiyi li ayanfe Omo mi, eniti inu mi dun si gidigidi; e ma gbo tire. Angeli na si dahun o si wi fun u pe, Emi Mimo yio to o wa, ati agbara Oga-ogo yio siji bo o: nitorina ohun mimo ti a o ti inu re bi, Omo Olorun li a o ma pe e.

/4 Enyin npe mi li Olukoni ati Oluwa: enyin wi rere; beni mo je. Jesu wi fun won pe, Emi li onje iye: enikeni ti o ba to mi wa, ebi ki yio pa a; eniti o ba si gba mi gbo, orungbe ki yio gbe e mo lai. Jesu si wi fun won pe, loto, loto ni mo wi fun nyin, Ki Abrahamu to wa, emi niyi. Obirin na wi fun u pe, mo mo pe Messia mbo wa, ti a npe ni Kristi: nigbati on ba de, yio so ohun gbogbo fun wa. Jesu wi fun u pe, Emi eniti mba o soro yi li on. Nitorina Jesu tun wi fun won pe, Loto, loto ni mo wi fun nyin, Emi ni ilekun awon agutan. Jesu wi fun u pe, Emi ni ajinde, ati iye: eniti o ba gba mi gbo, bi o tile ku, yio ye. Niwon igba ti mo wa li aiye, emi ni imole aiye. O si wi fun won pe, Enyin ti isale wa; emi ti oke wa: enyin je ti aiye yi; emi ki ise ti aiye yi.

/5 Bi o si ti dake oro iso, o wi fun Simone pe, Ti si ibu, ki o si ju awon nyin si isale fun akopo. Simoni si dahun o si wi fun u pe, Olukoni, gbogbo oru ana li awa fi sise, awa ko si mu nkan: sugbon nitori oro re emi o ju awon na si isale. Nigbati nwon si ti se eyi, nwon ko opolopo eja: awon won si ya. O si pase ki ijo enia joko lori koriko, o si mu isu akara marun ati eja meji na; nigbati o gbe oju soke orun, o sure, o si bu u, o fi akara na fun awon omo-ehin re, awon omo-ehin re si fifun ijo enia. Gbogbo nwon si je, nwon si yo; nwon si ko ajeku ti o ku jo, agbon mejila kun. Awon ti o si je e to iwon egbedogbon okunrin, li aika awon obirin ati awon omode. Si kiyesi i, awon okunrin afoju meji joko leti ona; nigbati nwon gbo pe Jesu nrekoja, nwon kigbe soke, wipe, Oluwa, iwo Omo Dafidi, sanu fun wa. Beni Jesu sanu fun won, o si fi owo to won li oju: ogan oju won si la, nwon si to o lehin.

/6

free web site hit counter