Yoruba 1st John


/1 Eyiti o ti wa li atetekose, ti awa ti gbo, ti awa ti fi oju wa ri, ti awa 
si ti tejumo, ti owo wa si ti dimu, niti Oro iye.
Iye na si ti farahan, awa si ti ri i, awa si njeri, awa si nso ti iye 
ainipekun na fun nyin, ti o ti mbe lodo Baba, ti o si farahan fun wa.
Eyiti awa ti ri, ti awa si ti gbo li awa nso fun nyin, ki enyin pelu ki o le 
ni idapo pelu wa: nitoto idapo wa si mbe pelu Baba, ati pelu Omo re Jesu 
Kristi.
Awa si kowe nkan wonyi si nyin, ki ayo nyin ki o le di kikun.
Eyi si ni ise ti awa ti gbo lenu re ti awa si nje fun nyin, pe imole li 
Olorun, okunkun ko si si lodo re rara.
Bi awa ba wipe awa ni idapo pelu re, ti awa si nrin ninu okunkun, awa nseke, 
awa ko si se otito.
Sugbon bi awa ba nrin ninu imole, bi on ti mbe ninu imole, awa ni idapo pelu 
ara wa, eje Jesu Kristi Omo re ni nwe wa nu kuro ninu ese gbogbo.
Bi awa ba wipe awa ko li ese, awa tan ara wa je, otito ko si si ninu wa.
Bi awa ba jewo ese wa, oloto ati olododo li on lati dari ese wa ji wa, ati 
lati we wa nu kuro ninu aisododo gbogbo.
Bi awa ba wipe awa ko dese, awa mu u li eke, oro re ko si si ninu wa.

/2 Enyin omo mi, iwe nkan wonyi ni mo ko si nyin, ki e ma ba dese; Bi enikeni 
ba si dese, awa ni alagbawi lodo Baba, Jesu Kristi olododo.