The Old Testament of the Holy Bible

Genesisi 1

Ìtàn bí a ṣe dá ayé

1 Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye. 2 Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi. 3 Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà. 4 Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun. 5 Ọlọrun si pè imọlẹ ni Ọsán, ati òkunkun ni Oru. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kini. 6 Ọlọrun si wipe, Ki ofurufu ki o wà li agbedemeji omi, ki o si yà omi kuro lara omi. 7 Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃. 8 Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji. 9 Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃. 10 Ọlọrun si pè iyangbẹ ilẹ ni Ilẹ; o si pè iwọjọpọ̀ omi ni Okun: Ọlọrun si ri pe o dara. 11 Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃. 12 Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. 13 Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹta. 14 Ọlọrun si wipe, Ki awọn imọlẹ ki o wà li ofurufu ọrun, lati pàla ọsán on oru; ki nwọn ki o si ma wà fun àmi, ati fun akoko, ati fun ọjọ́, ati fun ọdún: 15 Ki nwọn ki o si jẹ́ imọlẹ li ofurufu ọrun, lati mọlẹ sori ilẹ: o si ri bẹ̃. 16 Ọlọrun si dá imọlẹ nla meji; imọlẹ ti o tobi lati ṣe akoso ọsán, ati imọlẹ ti o kere lati ṣe akoso oru: o si dá awọn irawọ pẹlu. 17 Ọlọrun si sọ wọn lọjọ̀ li ofurufu ọrun, lati ma tàn imọlẹ sori ilẹ, 18 Ati lati ṣe akoso ọsán ati akoso oru, ati lati pàla imọlẹ on òkunkun: Ọlọrun si ri pe o dara. 19 Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹrin. 20 Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun. 21 Ọlọrun si dá erinmi nlanla ati ẹdá alãye gbogbo ti nrakò, ti omi kún fun li ọ̀pọlọpọ ni irú wọn, ati ẹiyẹ abiyẹ ni irú rẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. 22 Ọlọrun si súre fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ẹ si mã rẹ̀, ki ẹ kún inu omi li okun, ki ẹiyẹ ki o si ma rẹ̀ ni ilẹ. 23 Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ karun. 24 Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o mu ẹdá alãye ni irú rẹ̀ jade wá, ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹranko ilẹ ni irú rẹ̀: o si ri bẹ̃. 25 Ọlọrun si dá ẹranko ilẹ ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. 26 Ọlọrun si wipe, Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi irí wa: ki nwọn ki o si jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ, ati lori ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ. 27 Bẹ̃li Ọlọrun dá enia li aworan rẹ̀, li aworan Ọlọrun li o dá a; ati akọ ati abo li o dá wọn. 28 Ọlọrun si súre fun wọn. Ọlọrun si wi fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ki ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀; ki ẹ si ma jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ohun alãye gbogbo ti nrakò lori ilẹ. 29 Ọlọrun si wipe, kiye si i, Mo fi eweko gbogbo ti o wà lori ilẹ gbogbo ti nso eso fun nyin, ati igi gbogbo ninu eyiti iṣe igi eleso ti nso; ẹnyin ni yio ma ṣe onjẹ fun. 30 Ati fun gbogbo ẹranko ilẹ, ati fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ohun gbogbo ti o nrakò lori ilẹ, ti iṣe alaye, ni mo fi eweko tutu gbogbo fun li onjẹ: o si ri bẹ̃. 31 Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti o dá, si kiyesi i, daradara ni. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹfa.

Genesisi 2

1 BẸ li a pari ọrun on aiye, ati gbogbo ogun wọn. 2 Ni ijọ́ keje Ọlọrun si pari iṣẹ rẹ̀ ti o ti nṣe; o si simi ni ijọ́ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti nṣe. 3 Ọlọrun si busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́; nitori pe, ninu rẹ̀ li o simi kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti bẹ̀rẹ si iṣe. 4 Itan ọrun on aiye ni wọnyi nigbati a dá wọn, li ọjọ́ ti OLUWA Ọlọrun dá aiye on ọrun.

Ọgbà Edẹni

5 Ati olukuluku igi igbẹ ki o to wà ni ilẹ, ati olukuluku eweko igbẹ ki nwọn ki o to hù: OLUWA Ọlọrun kò sa ti rọ̀jo si ilẹ, kò si sí enia kan lati ro ilẹ. 6 Ṣugbọn ikũku a ti ilẹ wá, a si ma rin oju ilẹ gbogbo. 7 OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia; o si mí ẹmí ìye si ihò imu rẹ̀; enia si di alãye ọkàn. 8 OLUWA Ọlọrun si gbìn ọgbà kan niha ìla-õrùn ni Edeni; nibẹ̀ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si. 9 Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun mu onirũru igi hù jade wá, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; ìgi ìye pẹlu lãrin ọgbà na, ati igi ìmọ rere ati buburu. 10 Odò kan si ti Edeni ṣàn wá lati rin ọgbà na; lati ibẹ̀ li o gbé yà, o si di ipa ori mẹrin. 11 Orukọ ekini ni Pisoni: on li eyiti o yi gbogbo ilẹ Hafila ká, nibiti wurà wà; 12 Wurà ilẹ na si dara: nibẹ ni bedeliumu (ojia) wà ati okuta oniki. 13 Orukọ odò keji si ni Gihoni: on na li eyiti o yi gbogbo ilẹ Kuṣi ká. 14 Ati orukọ odò kẹta ni Hiddekeli: on li eyiti nṣàn lọ si ìha ìla-õrùn Assiria. Ati odò kẹrin ni Euferate. 15 OLUWA Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi i sinu ọgbà Edeni lati ma ro o, ati lati ma ṣọ́ ọ. 16 OLUWA Ọlọrun si fi aṣẹ fun ọkunrin na pe, Ninu gbogbo igi ọgbà ni ki iwọ ki o ma jẹ: 17 Ṣugbọn ninu igi ìmọ rere ati bururu nì, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀: nitoripe li ọjọ́ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kikú ni iwọ o kú. 18 OLUWA Ọlọrun si wipe, kò dara ki ọkunrin na ki o nikan ma gbé; emi o ṣe oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. 19 Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun si ti dá ẹranko igbẹ gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun gbogbo; o si mu wọn tọ̀ Adamu wá lati wò orukọ ti yio sọ wọn; orukọkorukọ ti Adamu si sọ olukuluku ẹda alãye, on li orukọ rẹ̀. 20 Adamu si sọ ẹran-ọ̀sin gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko igbẹ gbogbo, li orukọ; ṣugbọn fun Adamu a kò ri oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. 21 OLUWA Ọlọrun si mu orun ìjika kùn Adamu, o si sùn: o si yọ ọkan ninu egungun-ìha rẹ̀, o si fi ẹran di ipò rẹ̀: 22 OLUWA Ọlọrun si fi egungun-ìha ti o mu ni ìha ọkunrin na mọ obinrin, o si mu u tọ̀ ọkunrin na wá. 23 Adamu si wipe, Eyiyi li egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi: Obinrin li a o ma pè e, nitori ti a mu u jade lati ara ọkunrin wá. 24 Nitori na li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rẹ̀ silẹ, yio si fi ara mọ́ aya rẹ̀: nwọn o si di ara kan. 25 Awọn mejeji si wà ni ìhoho, ati ọkunrin na ati obinrin rẹ̀, nwọn kò si tiju.

Genesisi 3

Ìwà Àìgbọràn

1 EJÒ sa ṣe alarekereke jù ẹranko igbẹ iyoku lọ ti OLUWA Ọlọrun ti dá. O si wi fun obinrin na pe, õtọ li Ọlọrun wipe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ gbogbo eso igi ọgbà? 2 Obinrin na si wi fun ejò na pe, Awa a ma jẹ ninu eso igi ọgbà: 3 Ṣugbọn ninu eso igi nì ti o wà lãrin ọgbà Ọlọrun ti wipe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn a, ki ẹnyin ki o má ba kú. 4 Ejò na si wi fun obinrin na pe, Ẹnyin ki yio ku ikú kikú kan. 5 Nitori Ọlọrun mọ̀ pe, li ọjọ́ ti ẹnyin ba jẹ ninu rẹ̀, nigbana li oju nyin yio là, ẹnyin o si dabi Ọlọrun, ẹ o mọ̀ rere ati buburu. 6 Nigbati obinrin na si ri pe, igi na dara ni jijẹ, ati pe, o si dara fun oju, ati igi ti a ifẹ lati mu ni gbọ́n, o mu ninu eso rẹ̀ o si jẹ, o si fi fun ọkọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, on si jẹ. 7 Oju awọn mejeji si là, nwọn si mọ̀ pe nwọn wà ni ìhoho; nwọn si gán ewe ọpọtọ pọ̀, nwọn si dá ibantẹ fun ara wọn. 8 Nwọn si gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun, o nrìn ninu ọgbà ni itura ọjọ́: Adamu ati aya rẹ̀ si fi ara wọn pamọ́ kuro niwaju OLUWA Ọlọrun lãrin igi ọgbà. 9 OLUWA Ọlọrun si kọ si Adamu, o si wi fun u pe, Nibo ni iwọ wà? 10 O si wipe, Mo gbọ́ ohùn rẹ ninu ọgbà, ẹ̀ru si bà mi, nitori ti mo wà ni ìhoho; mo si fi ara pamọ́. 11 O si wi pe, Tali o wi fun ọ pe iwọ wà ni ìhoho? iwọ ha jẹ ninu igi nì, ninu eyiti mo paṣẹ fun ọ pe iwọ kò gbọdọ jẹ? 12 Ọkunrin na si wipe, Obinrin ti iwọ fi pẹlu mi, on li o fun mi ninu eso igi na, emi si jẹ. 13 OLUWA Ọlọrun si bi obinrin na pe, Ewo ni iwọ ṣe yi? Obinrin na si wipe, Ejò li o tàn mi, mo si jẹ.

Ọlọrun Ṣèdájọ́

14 OLUWA Ọlọrun si wi fun ejò na pe, nitori ti iwọ ti ṣe eyi, a fi iwọ bú ninu gbogbo ẹran ati ninu gbogbo ẹranko igbẹ; inu rẹ ni iwọ o ma fi wọ́, erupẹ ilẹ ni iwọ o ma jẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo. 15 Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ. 16 Fun obinrin na li o wipe, Emi o sọ ipọnju ati iloyun rẹ di pupọ̀; ni ipọnju ni iwọ o ma bimọ; lọdọ ọkọ rẹ ni ifẹ rẹ yio ma fà si, on ni yio si ma ṣe olori rẹ. 17 O si wi fun Adamu pe, Nitoriti iwọ gbà ohùn aya rẹ gbọ́, ti iwọ si jẹ ninu eso igi na, ninu eyiti mo ti paṣẹ fun ọ pe, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀; a fi ilẹ bú nitori rẹ; ni ipọnju ni iwọ o ma jẹ ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; 18 Ẹgún on oṣuṣu ni yio ma hù jade fun ọ, iwọ o si ma jẹ eweko igbẹ: 19 Li õgùn oju rẹ ni iwọ o ma jẹun, titi iwọ o fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ̀ li a ti mu ọ wá, erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ. 20 Adamu si pè orukọ aya rẹ̀ ni Efa; nitori on ni iṣe iya alãye gbogbo. 21 Ati fun Adamu ati fun aya rẹ̀ li OLUWA Ọlọrun da ẹwu awọ, o si fi wọ̀ wọn.

Ọlọrun Lé Adamu ati Efa jáde ninu Ọgbà

22 OLUWA Ọlọrun si wipe, Wò o, ọkunrin na dabi ọkan ninu wa lati mọ̀ rere ati bururu: njẹ nisisiyi ki o má ba nà ọwọ́ rẹ̀ ki o si mu ninu eso igi ìye pẹlu, ki o si jẹ, ki o si yè titi lai; 23 Nitorina OLUWA Ọlọrun lé e jade kuro ninu ọgbà Edeni, lati ma ro ilẹ ninu eyiti a ti mu u jade wá. 24 Bẹ̃li o lé ọkunrin na jade; o si fi awọn kerubu ati idà ina dè ìha ìla-õrùn Edeni ti njù kakiri, lati ma ṣọ́ ọ̀na igi ìye na.

Genesisi 4

Kaini ati Abeli

1 ADAMU si mọ̀ Efa aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Kaini, o si wipe, Mo ri ọkunrin kan gbà lọwọ OLUWA. 2 O si bí Abeli arakunrin rẹ̀. Abeli a si ma ṣe oluṣọ-agutan, ṣugbọn Kaini a ma ṣe aroko. 3 O si ṣe, li opin ọjọ́ wọnni ti Kaini mu ọrẹ ninu eso ilẹ fun OLUWA wá. 4 Ati Abeli, on pẹlu mu ninu akọbi ẹran-ọ̀sin ani ninu awọn ti o sanra. OLUWA si fi ojurere wò Abeli ati ọrẹ rẹ̀; 5 Ṣugbọn Kaini ati ọrẹ rẹ̀ ni kò nãni. Kaini si binu gidigidi, oju rẹ̀ si rẹ̀wẹsi. 6 OLUWA si bi Kaini pe, Ẽṣe ti inu fi mbi ọ? ẽ si ti ṣe ti oju rẹ̀ fi rẹ̀wẹsi? 7 Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki yio ha yá ọ? bi iwọ kò ba si ṣe rere, ẹ̀ṣẹ ba li ẹnu-ọ̀na, lọdọ rẹ ni ifẹ rẹ̀ yio ma fà si, iwọ o si ma ṣe alakoso rẹ̀. 8 Kaini si ba Abeli arakunrin rẹ̀ sọ̀rọ: o si ṣe, nigbati nwọn wà li oko, Kaini dide si Abeli arakunrin rẹ̀, o si lù u pa. 9 OLUWA si wi fun Kaini pe, Nibo ni Abeli arakunrin rẹ wà? O si wipe, Emi kò mọ̀; emi iṣe olutọju arakunrin mi bi? 10 O si wipe, Kini iwọ ṣe nì? Ohùn ẹ̀jẹ arakunrin rẹ nkigbe pè mi lati inu ilẹ wá. 11 Njẹ nisisiyi a fi ọ ré lori ilẹ, ti o yanu rẹ̀ gbà ẹ̀jẹ arakunrin rẹ lọwọ rẹ. 12 Nigbati iwọ ba ro ilẹ, lati isisiyi lọ, ki yio fi agbara rẹ̀ so eso fun ọ mọ; isansa ati alarinkiri ni iwọ o ma jẹ li aiye. 13 Kaini si wi fun OLUWA pe, ìya ẹ̀ṣẹ mi pọ̀ jù eyiti emi lè rù lọ. 14 Kiye si i, iwọ lé mi jade loni kuro lori ilẹ; emi o si di ẹniti o pamọ kuro loju rẹ; emi o si ma jẹ isansa ati alarinkiri li aiye; yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ri mi yio lù mi pa. 15 OLUWA si wi fun u pe, Nitorina ẹnikẹni ti o ba pa Kaini a o gbẹsan lara rẹ̀ lẹrinmeje. OLUWA si sàmi si Kaini lara, nitori ẹniti o ba ri i ki o má ba pa a. 16 Kaini si jade lọ kuro niwaju OLUWA, o si joko ni ilẹ Nodi, ni ìha ìla-õrùn Edeni.

Àwọn Ìran Kaini

17 Kaini si mọ̀ aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Enoku: o si tẹ̀ ilu kan dó, o si sọ orukọ ilu na ni Enoku bi orukọ ọmọ rẹ̀ ọkunrin. 18 Fun Enoku li a bí Iradi: Iradi si bí Mehujaeli: Mehujaeli si bí Metuṣaeli: Metuṣaeli si bí Lameki. 19 Lameki si fẹ́ obinrin meji: orukọ ekini ni Ada, ati orukọ ekeji ni Silla. 20 Ada si bí Jabali: on ni baba irú awọn ti o ngbé agọ́, ti nwọn si li ẹran-ọ̀sin. 21 Orukọ arakunrin rẹ̀ ni Jubali: on ni baba irú gbogbo awọn ti nlò dùru ati fère. 22 Ati Silla on pẹlu bí Tubali-kaini, olukọni gbogbo ọlọnà idẹ, ati irin: arabinrin Tubali-kaini ni Naama. 23 Lameki si wi fun awọn aya rẹ̀ pe, Ada on Silla, ẹ gbọ́ ohùn mi; ẹnyin aya Lameki, ẹ fetisi ọ̀rọ mi: nitoriti mo pa ọkunrin kan si ẹ̀dun mi, ati ọdọmọkunrin kan si ipalara mi. 24 Bi a o gbẹsan Kaini lẹrinmeje, njẹ ti Lameki ni ìgba ãdọrin meje.

Seti ati Enọṣi

25 Adamu si tun mọ̀ aya rẹ̀, o si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: o wipe, nitori Ọlọrun yàn irú-ọmọ miran fun mi ni ipò Abeli ti Kaini pa. 26 Ati Seti, on pẹlu li a bí ọmọkunrin kan fun; o si pè orukọ rẹ̀ ni Enoṣi: nigbana li awọn enia bẹ̀rẹ si ikepè orukọ OLUWA.

Genesisi 5

Ìwé Àkọsílẹ̀ Ìran Adamu

1 EYI ni iwe iran Adamu: Li ọjọ́ ti Ọlọrun dá ọkunrin, li aworan Ọlọrun li o dá a. 2 Ati akọ ati abo li o dá wọn; o si súre fun wọn, o si pè orukọ wọn ni Adamu, li ọjọ́ ti a dá wọn. 3 Adamu si wà li ãdoje ọdún, o si bí ọmọkunrin kan ni jijọ ati li aworan ara rẹ̀; o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: 4 Ọjọ́ Adamu, lẹhin ti o bí Seti, jẹ ẹgbẹrin ọdún: o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 5 Gbogbo ọjọ́ ti Adamu wà si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé ọgbọ̀n: o si kú. 6 Seti si wà li ọgọrun ọdún o lé marun, o si bí Enoṣi: 7 Seti si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé meje lẹhin ti o bí Enoṣi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 8 Ati gbogbo ọjọ́ Seti jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdun o lé mejila: o si kú. 9 Enoṣi si wà li ãdọrun ọdún, o si bí Kenani: 10 Enoṣi si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé mẹ̃dogun lẹhin ti o bí Kenani, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 11 Gbogbo ọjọ́ Enoṣi si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé marun: o si kú. 12 Kenani si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Mahalaleli: 13 Kenani si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ogoji lẹhin ti o bí Mahalaleli, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 14 Gbogbo ọjọ́ Kenani si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé mẹwa: o si kú. 15 Mahalaleli si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Jaredi: 16 Mahalaleli si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ọgbọ̀n, lẹhin ti o bí Jaredi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 17 Gbogbo ọjọ́ Mahalaleli si jẹ ẹ̃dẹgbẹ̀run ọdún o dí marun: o si kú. 18 Jaredi si wà li ọgọjọ ọdún o lé meji, o si bí Enoku: 19 Jaredi si wà li ẹgbẹrin ọdún lẹhin igbati o bì Enoku, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 20 Gbogbo ọjọ́ Jaredi si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mejidilogoji: o si kú. 21 Enoku si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Metusela: 22 Enoku si ba Ọlọrun rìn li ọ̃dunrun ọdún lẹhin ti o bì Metusela, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 23 Gbogbo ọjọ́ Enoku si jẹ irinwo ọdún o dí marundilogoji: 24 Enoku si ba Ọlọrun rìn: on kò si sí; nitori ti Ọlọrun mu u lọ. 25 Metusela si wà li ọgọsan ọdún o lé meje, o si bí Lameki: 26 Metusela si wà li ẹgbẹrin ọdún o dí mejidilogun lẹhin igbati o bí Lameki, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 27 Gbogbo ọjọ́ Metusela si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mọkanlelọgbọ̀n: o si kú. 28 Lameki si wà li ọgọsan ọdún o lé meji, o si bí ọmọkunrin kan: 29 O si sọ orukọ rẹ̀ ni Noa, pe, Eleyi ni yio tù wa ni inu ni iṣẹ ati lãla ọwọ́ wa, nitori ilẹ ti OLUWA ti fibú. 30 Lameki si wà li ẹgbẹta ọdún o dí marun, lẹhin ti o bí Noa, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 31 Gbogbo ọjọ́ Lameki si jẹ ẹgbẹrin ọdún o dí mẹtalelogun: o si kú. 32 Noa si jẹ ẹni ẹ̃dẹgbẹta ọdún: Noa si bí Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.

Genesisi 6

Ìwà Burúkú Eniyan

1 O si ṣe nigbati enia bẹ̀rẹ si irẹ̀ lori ilẹ, ti a si bí ọmọbinrin fun wọn, 2 Ni awọn ọmọ Ọlọrun ri awọn ọmọbinrin enia pe, nwọn lẹwà; nwọn fẹ́ aya fun ara wọn ninu gbogbo awọn ti nwọn yàn. 3 OLUWA si wipe, Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo ba enia jà, ẹran-ara sa li on pẹlu: ọjọ́ rẹ̀ yio si jẹ ọgọfa ọdún. 4 Awọn òmirán wà li aiye li ọjọ́ wọnni; ati lẹhin eyini pẹlu, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wọle tọ̀ awọn ọmọbinrin enia lọ, ti nwọn si bí ọmọ fun wọn, awọn na li o di akọni ti o wà nigbãni, awọn ọkunrin olokikí. 5 Ọlọrun si ri pe ìwabuburu enia di pipọ̀ li aiye, ati pe gbogbo ìro ọkàn rẹ̀ kìki ibi ni lojojumọ. 6 Inu OLUWA si bajẹ nitori ti o dá enia si aiye, o si dùn u de ọkàn rẹ̀. 7 OLUWA si wipe, Emi o pa enia ti mo ti dá run kuro li ori ilẹ; ati enia, ati ẹranko, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn. 8 Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA.

Ìtàn Noa

9 Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn. 10 Noa si bí ọmọkunrin mẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti. 11 Aiye si bajẹ niwaju Ọlọrun, aiye si kún fun ìwa-agbara. 12 Ọlọrun si bojuwò aiye, si kiye si i, o bajẹ; nitori olukuluku enia ti bà ìwa rẹ̀ jẹ li aiye. 13 Ọlọrun si wi fun Noa pe, Opin gbogbo enia de iwaju mi; nitori ti aiye kún fun ìwa-agbara lati ọwọ́ wọn; si kiye si i, emi o si pa wọn run pẹlu aiye. 14 Iwọ fi igi goferi kàn ọkọ́ kan; ikele-ikele ni iwọ o ṣe ninu ọkọ́ na, iwọ o si fi ọ̀da kùn u ninu ati lode. 15 Bayi ni iwọ o si ṣe e: Ìna ọkọ̀ na yio jẹ ọ̃dunrun igbọ́nwọ, ìbú rẹ̀ ãdọta igbọ́nwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọ̀nwọ. 16 Ferese ni iwọ o si ṣe si ọkọ̀ na ni igbọ́nwọ kan ni ki iwọ ki o si pari wọn loke; lẹgbẹ ni iwọ o si dá ẹnu-ọ̀na ọkọ̀ na, si: pẹlu yara isalẹ, atẹle, ati ẹkẹta loke ni iwọ o ṣe e. 17 Ati emi, wò o, emi nmu kikun-omi bọ̀ wá si aiye, lati pa gbogbo ohun alãye run, ti o li ẹmi ãye ninu kuro labẹ ọrun; ohun gbogbo ti o wà li aiye ni yio si kú. 18 Ṣugbọn iwọ li emi o ba dá majẹmu mi; iwọ o si wọ̀ inu ọkọ̀ na, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati aya rẹ, ati awọn aya awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ. 19 Ati ninu ẹdá alãye gbogbo, ninu onirũru ẹran, meji meji ninu gbogbo ẹran ni iwọ o mu wọ̀ inu ọkọ̀ na, lati mu nwọn là pẹlu rẹ; ti akọ ti abo ni ki nwọn ki o jẹ. 20 Ninu ẹiyẹ nipa irú ti wọn, ninu ẹran-ọ̀sin nipa irú ti wọn, ninu ohun gbogbo ti nrakò ni ilẹ nipa irú tirẹ̀, meji meji ninu gbogbo wọn ni yio ma tọ̀ ọ wá lati mu wọn wà lãye. 21 Iwọ o si mu ninu ohun jijẹ gbogbo, iwọ o si kó wọn jọ si ọdọ rẹ; yio si ṣe onjẹ fun iwọ, ati fun wọn. 22 Bẹ̃ni Noa si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ọlọrun paṣẹ fun u, bẹli o ṣe.

Genesisi 7

Ìkún Omi

1 OLUWA si wi fun Noa pe, iwọ wá, ati gbogbo awọn ara ile rẹ sinu ọkọ̀, nitori iwọ ni mo ri li olododo niwaju mi ni iran yi. 2 Ninu onirũru ẹran ti o mọ́ meje meje ni ki iwọ ki o mu wọn, ati akọ ati abo rẹ̀; ati ninu ẹran ti kò mọ́ meji meji, ati akọ ati abo rẹ̀. 3 Ninu ẹiyẹ oju-ọrun pẹlu ni meje meje, ati akọ ati abo; lati dá irú si lãye lori ilẹ gbogbo. 4 Nitori ijọ́ meje si i, emi o mu òjo rọ̀ si ilẹ li ogoji ọsán ati li ogoji oru; ohun alãye gbogbo ti mo dá li emi o parun kuro lori ilẹ. 5 Noa si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun u. 6 Noa si jẹ ẹni ẹgbẹta ọdún nigbati kíkun-omi de si aiye. 7 Noa si wọle, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati aya awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, sinu ọkọ̀, nitori kíkun-omi. 8 Ninu ẹranko mimọ́, ati ninu ẹranko ti kò mọ́, ati ninu ẹiyẹ, ati ninu ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, 9 Nwọn wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀ ni meji meji, ati akọ ati abo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun Noa. 10 O si ṣe ni ijọ́ keje, bẹ̃ni kíkun-omi de si aiye. 11 Li ẹgbẹta ọdún ọjọ́ aiye Noa, li oṣù keji, ni ọjọ́ kẹtadilogun oṣù, li ọjọ́ na ni gbogbo isun ibú nla ya, ati ferese iṣàn omi ọrun si ṣí silẹ. 12 Òjo na si wà lori ilẹ li ogoji ọsán on ogoji oru. 13 Li ọjọ́ na gan ni Noa wọ̀ inu ọkọ̀, ati Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti, awọn ọmọ Noa, ati aya Noa, (ati awọn aya ọmọ rẹ̀ mẹta pẹlu wọn). 14 Awọn, ati gbogbo ẹranko ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin gbogbo ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ nla ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ abiyẹ. 15 Nwọn si wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀, meji meji ninu ẹda gbogbo, ninu eyiti ẹmi ìye wà. 16 Awọn ti o si wọle lọ, nwọn wọle ti akọ ti abo ninu ẹdá gbogbo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. OLUWA si sé e mọ́ ile. 17 Ikún-omi si wà li ogoji ọjọ́ lori ilẹ; omi si nwú si i, o si mu ọkọ̀ fó soke, o si gbera kuro lori ilẹ. 18 Omi si gbilẹ, o si nwú si i gidigidi lori ilẹ; ọkọ̀ na si fó soke loju omi. 19 Omi si gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti o wà ni gbogbo abẹ ọrun, li a bò mọlẹ. 20 Omi gbilẹ soke ni igbọ́nwọ mẹ̃dogun; a si bò gbogbo okenla mọlẹ. 21 Gbogbo ẹdá ti nrìn lori ilẹ si kú, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ti ẹranko, ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ati gbogbo enia: 22 Gbogbo ohun ti ẹmi ìye wà ni ihò imu rẹ̀, gbogbo ohun ti o wà ni iyangbẹ ilẹ si kú. 23 Ohun alãye gbogbo ti o wà lori ilẹ li a si parun, ati enia, ati ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun, nwọn si run kuro lori ilẹ. Noa nikan li o kù, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. 24 Omi si gbilẹ li aiye li ãdọjọ ọjọ́.

Genesisi 8

Ìkún Omi Gbẹ

1 ỌLỌRUN si ranti Noa, ati ohun alãye gbogbo, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀: Ọlọrun si mu afẹfẹ kọja lori ilẹ, omi na si fà. 2 A si dí gbogbo isun ibú ati awọn ferese ọrun, o si mu òjo dá lati ọrun wá. 3 Omi si npada kuro lori ilẹ, lojojumọ lẹhin ãdọjọ ọjọ́, omi si fà. 4 Ọkọ̀ si kanlẹ li oṣù keje, ni ijọ́ kẹtadilogun oṣù, lori oke Ararati. 5 Omi si nfà titi o fi di oṣù kẹwa: li oṣù kẹwa, li ọjọ́ kini oṣù li ori awọn okenla hàn, 6 O si ṣe li opin ogoji ọjọ́, ni Noa ṣí ferese ọkọ̀ ti o kàn: 7 O si rán ìwo kan jade, ti o fò jade lọ ka kiri titi omi fi gbẹ kuro lori ilẹ. 8 O si rán oriri kan jade, lati ọdọ rẹ̀ lọ, ki o wò bi omi ba nfà kuro lori ilẹ; 9 Ṣugbọn oriri kò ri ibi isimi fun atẹlẹsẹ̀ rẹ̀, o si pada tọ ọ lọ ninu ọkọ̀, nitoriti omi wà lori ilẹ gbogbo: nigbana li o si nawọ rẹ̀, o mu u, o si fà a si ọdọ rẹ̀ ninu ọkọ̀. 10 O si duro li ọjọ́ meje miran si i: o si tun rán oriri na jade lati inu ọkọ̀ lọ. 11 Oriri na si pada wọle tọ̀ ọ wá li aṣalẹ; si kiyesi i, o já ewe olifi si ẹnu rẹ̀: bẹ̃li Noa si mọ̀ pe omi ngbẹ kuro lori ilẹ. 12 O si tun duro ni ijọ́ meje miran, o si rán oriri na jade; ti kò si tun pada tọ̀ ọ wá mọ́. 13 O si ṣe li ọdún kọkanlelẹgbẹta, li oṣù kini, li ọjọ́ kini oṣù na, on li omi gbẹ kuro lori ilẹ: Noa si ṣí ideri ọkọ̀, o si wò, si kiyesi i ori ilẹ gbẹ. 14 Li oṣù keji, ni ijọ́ kẹtadilọgbọ̀n oṣù, on ni ilẹ gbẹ. 15 Ọlọrun si sọ fun Noa pe, 16 Jade kuro ninu ọkọ̀, iwọ, ati aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn aya ọmọ rẹ pẹlu rẹ. 17 Mu ohun alãye gbogbo ti o wà pẹlu rẹ jade pẹlu rẹ, ninu ẹdá gbogbo, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ; ki nwọn ki o le ma gbá yìn lori ilẹ, ki nwọn bí si i, ki nwọn si ma rẹ̀ si i lori ilẹ. 18 Noa si jade, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati awọn aya ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; 19 Gbogbo ẹranko, gbogbo ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ gbogbo, ati ohunkohun ti nrakò lori ilẹ, gẹgẹ bi irú ti wọn, nwọn jade ninu ọkọ̀.

Noa Rúbọ

20 Noa si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA; o si mu ninu ẹranko mimọ́ gbogbo, ati ninu ẹiyẹ mimọ́ gbogbo, o si rú ẹbọ-ọrẹ sisun lori pẹpẹ na. 21 OLUWA si gbọ́ õrun didùn; OLUWA si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ki yio si tun fi ilẹ ré nitori enia mọ́; nitori ìro ọkàn enia ibi ni lati ìgba ewe rẹ̀ wá; bẹ̃li emi ki yio tun kọlù ohun alãye gbogbo mọ́ bi mo ti ṣe. 22 Niwọ̀n ìgba ti aiye yio wà, ìgba irugbìn, ati ìgba ikore, ìgba otutu ati oru, ìgba ẹ̃run on òjo, ati ọsán ati oru, ki yio dẹkun.

Genesisi 9

Ọlọrun Bá Noa Dá Majẹmu

1 ỌLỌRUN si sure fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ ma bí si i, ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si kún aiye. 2 Ati ìbẹru nyin, ati ìfoya nyin, yio ma wà lara gbogbo ẹranko aiye, ati lara gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati lara gbogbo ohun ti nrakò ni ilẹ, ati lara gbogbo ẹja okun; ọwọ́ nyin li a fi wọn lé. 3 Gbogbo ohun alãye, ti nrakò, ni yio ma ṣe onjẹ fun nyin; gẹgẹ bi eweko tutu ni mo fi ohun gbogbo fun nyin. 4 Kìki ẹran pẹlu ẹmi rẹ̀, ani ẹ̀jẹ rẹ̀, on li ẹnyin kò gbọdọ jẹ. 5 Nitõtọ ẹ̀jẹ nyin ani ẹmi nyin li emi o si bère; lọwọ gbogbo ẹranko li emi o bère rẹ̀, ati lọwọ enia, lọwọ arakunrin olukuluku enia li emi o bère ẹmi enia. 6 Ẹnikẹni ti o ba ta ẹ̀jẹ enia silẹ, lati ọwọ́ enia li a o si ta ẹ̀jẹ rẹ̀ silẹ: nitoripe li aworan Ọlọrun li o dá enia. 7 Ati ẹnyin, ki ẹnyin ki o ma bí si i; ki ẹ si ma rẹ̀ si i, ki ẹ si ma gbá yìn lori ilẹ, ki ẹ si ma rẹ̀ ninu rẹ̀. 8 Ọlọrun si wi fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, pe, 9 Ati emi, kiye si i, emi ba nyin dá majẹmu mi, ati awọn irú-ọmọ nyin lẹhin nyin; 10 Ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin; ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ẹranko aiye pélu nyin; lati gbogbo awọn ti o ti inu ọkọ̀ jade, titi o fi de gbogbo ẹranko aiye. 11 Emi o si ba nyin dá majẹmu mi; a ki yio si fi kíkun-omi ké gbogbo ẹdá kuro mọ́; bẹ̃ni kíkun-omi ki yio sí mọ́, lati pa aiye run. 12 Ọlọrun si wipe, Eyiyi li àmi majẹmu mi ti mo ba nyin dá, ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin, fun atirandiran: 13 Mo fi òṣumare mi si awọsanma, on ni yio si ma ṣe àmi majẹmu mi ti mo ba aiye dá. 14 Yio si ṣe, nigbati mo ba mu awọsanma wá si ori ilẹ, a o si ma ri òṣumare na li awọsanma: 15 Emi o si ranti majẹmu mi, ti o wà lãrin emi ati ẹnyin, ati gbogbo ọkàn alãye ni gbogbo ẹdá; omi ki yio si di kíkun mọ́ lati pa gbogbo ẹdá run. 16 Òṣumare na yio si wà li awọsanma; emi o si ma wò o, ki emi le ma ranti majẹmu lailai ti o wà pẹlu Ọlọrun ati gbogbo ọkàn alãye ti o wà ninu gbogbo ẹdá ti o wà li aiye. 17 Ọlọrun si wi fun Noa pe, Eyiyi li àmi majẹmu na, ti mo ba ara mi ati ẹdá gbogbo ti o wà lori ilẹ dá.

Noa ati Àwọn Ọmọkunrin Rẹ̀

18 Awọn ọmọ Noa, ti o si jade ninu ọkọ̀ ni Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti: Hamu si ni baba Kenaani. 19 Awọn mẹta wọnyi li ọmọ Noa: lati ọdọ wọn li a gbé ti tàn ká gbogbo aiye. 20 Noa si bẹ̀rẹ si iṣe àgbẹ, o si gbìn ọgbà-àjara: 21 O si mu ninu ọti-waini na, o mu amupara; o si tú ara rẹ̀ si ìhoho ninu agọ́ rẹ̀. 22 Hamu, baba Kenaani, si ri ìhoho baba rẹ̀, o si sọ fun awọn arakunrin rẹ̀ meji lode. 23 Ati Ṣemu ati Jafeti mu gọgọwu, nwọn si fi le ejika awọn mejeji, nwọn si fi ẹhin rìn, nwọn si bò ìhoho baba wọn; oju wọn si wà lẹhin; nwọn kò si ri ìhoho baba wọn. 24 Noa si jí kuro li oju ọti-waini rẹ̀, o si mọ̀ ohun ti ọmọ rẹ̀ kekere ṣe si i. 25 O si wipe, Egbe ni fun Kenaani; iranṣẹ awọn iranṣẹ ni yio ma ṣe fun awọn arakunrin rẹ̀. 26 O si wipe, Olubukun li OLUWA Ọlọrun Ṣemu; Kenaani yio ma ṣe iranṣẹ rẹ̀. 27 Ọlọrun yio mu Jafeti gbilẹ, yio si ma gbé agọ́ Ṣemu; Kenaani yio si ma ṣe iranṣẹ wọn. 28 Noa si wà ni irinwo ọdun o din ãdọta, lẹhin ìkún-omi. 29 Gbogbo ọjọ́ Noa jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí ãdọta: o si kú.

Genesisi 10

Ìran Àwọn Ọmọ Noa

1 IRAN awọn ọmọ Noa ni wọnyi, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti: ati fun wọn li a si bí ọmọ lẹhin kíkun-omi. 2 Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi. 3 Ati awọn ọmọ Gomeri, Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togarma. 4 Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu. 5 Lati ọdọ awọn wọnyi li a ti pín erekuṣu awọn orilẹ-ède ni ilẹ wọn, olukuluku gẹgẹ bi ohùn rẹ̀; gẹgẹ bi idile wọn, li orilẹ-ède wọn. 6 Ati awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, ati Futi, ati Kenaani. 7 Ati awọn ọmọ Kuṣi; Seba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka; ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba, ati Dedani. 8 Kuṣi si bí Nimrodu: on si bẹ̀rẹ si idi alagbara li aiye. 9 On si ṣe ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA: nitori na li a ṣe nwipe, Gẹgẹ bi Nimrodu ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA. 10 Ipilẹṣẹ ijọba rẹ̀ ni Babeli, ati Ereki, ati Akkadi, ati Kalne, ni ilẹ Ṣinari. 11 Lati ilẹ na ni Aṣṣuri ti jade lọ, o si tẹ̀ Ninefe, ati ilu Rehoboti, ati Kala dó. 12 Ati Reseni lagbedemeji Ninefe on Kala: eyi na ni ilu nla. 13 Misraimu si bí Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu, 14 Ati Patrusimu, ati Kasluhimu (lati ọdọ ẹniti Filistimu ti wá), ati Kaftorimu. 15 Kenaani si bí Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti, 16 Ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi, 17 Ati awọn ara Hiffi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini, 18 Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati; lẹhin eyini ni idile awọn ara Kenaani tàn kalẹ. 19 Ati àgbegbe awọn ara Kenaani ni Sidoni, bi o ti mbọ̀wa Gerari, titi de Gasa; bi o ti nlọ si Sodomu, ati Gomorra, ati Adma, ati Seboimu, titi dé Laṣa. 20 Awọn wọnyi li ọmọ Hamu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, ati li orilẹ-ède wọn. 21 Fun Ṣemu pẹlu, baba gbogbo awọn ọmọ Eberi, ẹgbọn Jafeti ati fun on li a bimọ. 22 Awọn ọmọ Ṣemu: Elamu, ati Aṣṣuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu. 23 Ati awọn ọmọ Aramu; Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Maṣi. 24 Arfaksadi si bí Ṣela; Ṣela si bí Eberi. 25 Ati fun Eberi li a bí ọmọkunrin meji; orukọ ekini ni Pelegi; nitori nigba ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ yà; orukọ arakunrin rẹ̀ ni Joktani. 26 Joktani si bí Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera, 27 Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla, 28 Ati Obali, ati Abimaeli, ati Ṣeba, 29 Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu: gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Joktani. 30 Ibugbe wọn si ti Meṣa lọ, bi iwọ ti nlọ si Sefari, oke kan ni ìla-õrùn. 31 Awọn wọnyi li ọmọ Ṣemu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, li orilẹ-ède wọn. 32 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Noa, gẹgẹ bi iran wọn, li orilẹ-ède wọn: lati ọwọ́ awọn wọnyi wá li a ti pín orilẹ-ède aiye lẹhin kíkun-omi.

Genesisi 11

Ilé Ìṣọ́ Babeli

1 GBOGBO aiye si jẹ ède kan, ati ọ̀rọ kan. 2 O si ṣe, bi nwọn ti nrìn lati ìha ìla-õrùn lọ, ti nwọn ri pẹtẹlẹ kan ni ilẹ Ṣinari; nwọn si tẹdo sibẹ̀. 3 Nwọn si wi, ikini si ekeji pe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a mọ briki, ki a si sun wọn jina. Briki ni nwọn ni li okuta, ọ̀da-ilẹ ni nwọn si nfi ṣe ọ̀rọ. 4 Nwọn si wipe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a tẹ̀ ilu kan dó, ki a si mọ ile-iṣọ kan, ori eyiti yio si kàn ọrun; ki a si li orukọ, ki a má ba tuka kiri sori ilẹ gbogbo. 5 OLUWA si sọkalẹ wá iwò ilu ati ile-iṣọ́ na, ti awọn ọmọ enia nkọ́. 6 OLUWA si wipe, Kiye si i, ọkan li awọn enia, ède kan ni gbogbo wọn ni; eyi ni nwọn bẹ̀rẹ si iṣe: njẹ nisisiyi kò sí ohun ti a o le igbà lọwọ wọn ti nwọn ti rò lati ṣe. 7 Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a sọkalẹ lọ, ki a dà wọn li ède rú nibẹ̀, ki nwọn ki o máṣe gbedè ara wọn mọ́. 8 Bẹ̃li OLUWA tú wọn ká lati ibẹ̀ lọ si ori ilẹ gbogbo: nwọn si ṣíwọ ilu ti nwọn ntẹdó. 9 Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Babeli; nitori ibẹ̀ li OLUWA gbe dà ède araiye rú, lati ibẹ̀ lọ OLUWA si tú wọn ká kiri si ori ilẹ gbogbo.

Àwọn Ìran Ṣemu

10 Wọnyi ni iran Ṣemu: Ṣemu jẹ ẹni ọgọrun ọdún, o si bí Arfaksadi li ọdún keji lẹhin kíkun-omi. 11 Ṣemu si wà li ẹ̃dẹgbẹta ọdún, lẹhin igbati o bí Arfaksadi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 12 Arfaksadi si wà li arundilogoji ọdún, o si bí Ṣela: 13 Arfaksadi si wà ni irinwo ọdún o le mẹta, lẹhin igbati o bí Ṣela tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 14 Ṣela si wà ni ọgbọ̀n ọdún, o si bí Eberi: 15 Ṣela si wà ni irinwo ọdún o le mẹta lẹhin ti o bí Eberi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 16 Eberi si wà li ọgbọ̀n ọdún o le mẹrin, o si bí Pelegi: 17 Eberi si wà ni irinwo ọdún o le ọgbọ̀n lẹhin igbati o bí Pelegi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 18 Pelegi si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bì Reu: 19 Pelegi si wà ni igba ọdún o le mẹsan lẹhin igbati o bí Reu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 20 Reu si wà li ọgbọ̀n ọdún o le meji, o si bí Serugu: 21 Reu si wà ni igba ọdún o le meje, lẹhin igbati o bí Serugu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 22 Serugu si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bí Nahori: 23 Serugu si wà ni igba ọdún, lẹhin igba ti o bí Nahori tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 24 Nahori si jẹ ẹni ọdún mọkanlelọgbọ̀n o si bí Tera: 25 Nahori si wà li ọgọfa ọdún o dí ọkan, lẹhin igbati o bí Tera tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 26 Tera si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Abramu, Nahori, ati Harani.

Àwọn Ìran Tẹra

27 Iran Tera si li eyi: Tera bi Abramu, Nahori, ati Harani; Harani si bí Loti. 28 Harani si kú ṣaju Tera baba rẹ̀, ni ilẹ ibi rẹ̀, ni Uri ti Kaldea. 29 Ati Abramu ati Nahor si fẹ aya fun ara wọn: orukọ aya Abramu ni Sarai; ati orukọ aya Nahori ni Milka, ọmọbinrin Harani, baba Milka, ati baba Iska. 30 Ṣugbọn Sarai yàgan; kò li ọmọ. 31 Tera si mu Abramu ọmọ rẹ̀, ati Loti, ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ati Sarai aya ọmọ rẹ̀, aya Abramu ọmọ rẹ̀; nwọn si ba wọn jade kuro ni Uri ti Kaldea, lati lọ si ilẹ Kenaani; nwọn si wá titi de Harani, nwọn si joko sibẹ̀. 32 Ọjọ́ Tera si jẹ igba ọdún o le marun: Tera si kú ni Harani.

Genesisi 12

Ọlọrun Pe Abramu

1 OLUWA si ti wi fun Abramu pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ara rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ, si ilẹ kan ti emi o fi hàn ọ: 2 Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni iwọ o si jasi: 3 Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye. 4 Bẹ̃li Abramu lọ, bi OLUWA ti sọ fun u; Loti si ba a lọ: Abramu si jẹ ẹni arundilọgọrin ọdún nigbati o jade ni Harani. 5 Abramu si mu Sarai aya rẹ̀, ati Loti ọmọ arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ini wọn ti nwọn kojọ, enia gbogbo ti nwọn ni ni Harani, nwọn si jade lati lọ si ilẹ Kenaani; ni ilẹ Kenaani ni nwọn si wá si. 6 Abramu si là ilẹ na kọja lọ si ibi ti a npè ni Ṣekemu, si igbo More. Awọn ara Kenaani si wà ni ilẹ na ni ìgba na. 7 OLUWA si fi ara hàn fun Abramu, o si wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ̀ li o si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA ti o fi ara hàn a. 8 O si ṣí kuro nibẹ̀ lọ si ori oke kan ni ìha ìla-õrùn Beteli, o si pa agọ́ rẹ̀, Beteli ni ìwọ-õrùn ati Hai ni ìla-õrùn: o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si kepè orukọ OLUWA. 9 Abramu si nrìn lọ, o nlọ si ìha gusù sibẹ̀.

Abramu ní Ijipti

10 Ìyan kan si mu ni ilẹ na: Abramu si sọkalẹ lọ si Egipti lati ṣe atipo nibẹ̀; nitoriti ìyan na mu gidigidi ni ilẹ na. 11 O si ṣe, nigbati o kù si dẹ̀dẹ lati wọ̀ Egipti, o wi fun Sarai aya rẹ̀ pe, Kiyesi i nisisiyi, emi mọ̀ pe arẹwà obinrin lati wò ni iwọ: 12 Nitorina yio si ṣe, nigbati awọn ara Egipti yio ri ọ, nwọn o wipe, aya rẹ̀ li eyi: nwọn o si pa mi, ṣugbọn nwọn o dá ọ si. 13 Mo bẹ̀ ọ, wipe, arabinrin mi ni iwọ iṣe: ki o le irọ̀ mi lọrùn nitori rẹ; ọkàn mi yio si yè nitori rẹ. 14 O si ṣe nigbati Abramu de Egipti, awọn ara Egipti wò obinrin na pe arẹwà enia gidigidi ni. 15 Awọn ijoye Farao pẹlu ri i, nwọn si ròhin rẹ̀ niwaju Farao; a si mu obinrin na lọ si ile Farao. 16 O si nṣikẹ Abramu gidigidi nitori rẹ̀: on si li agutan, ati akọ-malu, ati akọ-kẹtẹkẹtẹ, ati iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, abo-kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ. 17 OLUWA si fi iyọnu nla yọ Farao ati awọn ara ile rẹ̀ li ẹnu, nitori Sarai aya Abramu. 18 Farao si pè Abramu, o wipe, ewo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? ẽṣe ti iwọ kò fi wi fun mi pe, aya rẹ ni iṣe? 19 Ẽṣe ti iwọ fi wipe, arabinrin mi ni iṣe? bẹ̃li emi iba fẹ ẹ li aya mi si: njẹ nisisiyi wò aya rẹ, mu u, ki o si ma ba tirẹ lọ. 20 Farao si paṣẹ fun awọn ọkunrin rẹ̀ nitori Abramu: nwọn si sìn i jade lọ, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni.

Genesisi 13

Abramu ati Lọti Pínyà

1 ABRAMU si goke lati Egipti wá, on, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ati Loti pẹlu rẹ̀, si ìha gusu. 2 Abramu si là gidigidi, li ẹran-ọ̀sin, ni fadaka, ati ni wurà. 3 O si nrìn ìrin rẹ̀ lati ìha gusu lọ titi o si fi de Beteli, de ibi ti agọ́ rẹ̀ ti wà ni iṣaju, lagbedemeji Beteli on Hai. 4 Si ibi pẹpẹ ti o ti tẹ́ nibẹ̀ ni iṣaju: nibẹ̀ li Abramu si nkepè orukọ OLUWA. 5 Ati Loti pẹlu, ti o ba Abramu lọ, ni agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran, ati agọ́. 6 Ilẹ na kò si le igbà wọn, ki nwọn ki o le igbé pọ̀: nitori ini wọn pọ̀, bẹ̃nì nwọn kò si le gbé pọ̀. 7 Bẹ̃ni gbolohùn asọ̀ si wà lãrin awọn darandaran Abramu, ati awọn darandaran Loti: ati awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi ngbé ilẹ na ni ìgba na. 8 Abramu si wi fun Loti pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki gbolohùn asọ̀ ki o wà lãrin temi tirẹ, ati lãrin awọn darandaran mi, ati awọn darandaran rẹ; nitori pe ará li awa iṣe. 9 Gbogbo ilẹ kọ́ eyi niwaju rẹ? emi bẹ̀ ọ, yà ara rẹ kuro lọdọ mi: bi iwọ ba pọ̀ si apa òsi, njẹ emi o pọ̀ si ọtún; tabi bi iwọ ba pọ̀ si apa ọtùn, njẹ emi o pọ̀ si òsi. 10 Loti si gboju rẹ̀ si oke, o si wò gbogbo àgbegbe Jordani, pe o li omi nibi gbogbo, ki OLUWA ki o to pa Sodomu on Gomorra run, bi ọgbà OLUWA, bi ilẹ Egipti, bi iwọ ti mbọ̀wa si Soari. 11 Nigbana ni Loti yàn gbogbo àgbegbe Jordani fun ara rẹ̀; Loti si nrìn lọ si ìha ìla-õrùn: bẹ̃ni nwọn yà ara wọn, ekini kuro lọdọ ekeji. 12 Abramu si joko ni ilẹ Kenaani, Loti si joko ni ilu àgbegbe nì, o si pagọ́ rẹ̀ titi de Sodomu. 13 Ṣugbọn awọn ọkunrin Sodomu ṣe enia buburu, ati ẹlẹṣẹ gidigidi niwaju OLUWA.

Abramu kó Lọ sí Heburoni

14 OLUWA si wi fun Abramu, lẹhin igbati Loti yà kuro lọdọ rẹ̀ tan pe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò lati ibi ti o gbé wà nì lọ, si ìha ariwa, ati si ìha gusu, si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ìwọ-õrùn: 15 Gbogbo ilẹ ti o ri nì, iwọ li emi o sa fi fun ati fun irú-ọmọ rẹ lailai. 16 Emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi erupẹ ilẹ: tobẹ̃ bi o ba ṣepe enia kan ba le kà iye erupẹ ilẹ, on li a o to le kaye irú-ọmọ rẹ pẹlu. 17 Dide, rìn ilẹ na já ni ìna rẹ̀, ati ni ibú rẹ̀; nitori iwọ li emi o fi fun. 18 Nigbana ni Abramu ṣí agọ́ rẹ̀, o si wá o si joko ni igbo Mamre, ti o wà ni Hebroni, o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA.

Genesisi 14

Abramu Gba Lọti sílẹ̀

1 O SI ṣe li ọjọ́ Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu, ati Tidali ọba awọn orilẹ-ède; 2 Ti nwọn ba Bera ọba Sodomu jagun, pẹlu Birṣa ọba Gomorra, Ṣinabu ọba Adma, ati Semeberi ọba Seboimu, pẹlu ọba Bela (eyini ni Soari). 3 Gbogbo awọn wọnyi li o dapọ̀ li afonifoji Siddimu, ti iṣe Okun Iyọ̀. 4 Nwọn sìn Kedorlaomeri li ọdún mejila, li ọdún kẹtala nwọn ṣọ̀tẹ. 5 Li ọdún kẹrinla ni Kedorlaomeri, wá ati awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn kọlu awọn Refaimu ni Aṣteroti-Karnaimu, ati awọn Susimu ni Hamu, ati awọn Emimu ni pẹtẹlẹ Kiriataimu, 6 Ati awọn ara Hori li oke Seiri wọn, titi o fi de igbo Parani, ti o wà niha ijù. 7 Nwọn si pada, nwọn si wá si Enmiṣpati, eyini ni Kadeṣi, nwọn si kọlu gbogbo oko awọn ara Amaleki, ati awọn ara Amori ti o tẹdo ni Hasesontamari pẹlu. 8 Ọba Sodomu si jade, ati ọba Gomorra, ati ọba Adma, ati ọba Seboimu, ati ọba Bela, (eyini ni Soari;) nwọn si tẹgun si ara wọn li afonifoji Siddimu; 9 Si Kedorlaomeri ọba Elamu, ati si Tidali ọba awọn orilẹ-ède, ati Amrafeli ọba Ṣinari, ati Arioku ọba Ellasari, ọba mẹrin si marun. 10 Afonifoji Siddimu si jẹ kìki kòto ọ̀da-ilẹ; awọn ọba Sodomu ati ti Gomorra sá, nwọn si ṣubu nibẹ̀; awọn ti o si kù sálọ si ori oke. 11 Nwọn si kó gbogbo ẹrù Sodomu on Gomorra ati gbogbo onjẹ wọn, nwọn si ba ti wọn lọ. 12 Nwọn si mu Loti, ọmọ arakunrin Abramu, ti ngbé Sodomu, nwọn si kó ẹrù rẹ̀, nwọn si lọ. 13 Ẹnikan ti o sá asalà de, o si rò fun Abramu Heberu nì; on sa tẹdo ni igbo Mamre ara Amori, arakunrin Eṣkoli ati arakunrin Aneri: awọn wọnyi li o mba Abramu ṣe pọ̀. 14 Nigbati Abramu gbọ́ pe a dì arakunrin on ni igbekun, o kó awọn ọmọ ọdọ rẹ̀ ti a ti kọ́, ti a bí ni ile rẹ̀ jade, ọrindinirinwo enia o din meji, o si lepa wọn de Dani. 15 O si pín ara rẹ̀, on, pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, si wọn li oru, o si kọlù wọn, o si lépa wọn de Hoba, ti o wà li apa òsi Damasku: 16 O si gbà gbogbo ẹrù na pada, o si gbà Loti arakunrin rẹ̀ pada pẹlu, ati ẹrù rẹ̀, ati awọn obinrin pẹlu, ati awọn enia.

Mẹlikisẹdẹki Súre fún Abramu

17 Ọba Sodomu si jade lọ ipade rẹ̀ li àbọ iṣẹgun Kedorlaomeri ati awọn ọba ti o pẹlu rẹ̀, li afonifoji Ṣafe, ti iṣe Afonifoji Ọba. 18 Melkisedeki ọba Salemu si mu onjẹ ati ọti waini jade wá: on a si ma ṣe alufa Ọlọrun Ọga-ogo. 19 O si súre fun u, o si wipe, Ibukun ni fun Abramu, ti Ọlọrun ọga-ogo, ẹniti o ni ọrun on aiye. 20 Olubukun si li Ọlọrun ọga-ogo ti o fi awọn ọta rẹ le ọ lọwọ. On si dá idamẹwa ohun gbogbo fun u. 21 Ọba Sodomu si wi fun Abramu pe, Dá awọn enia fun mi, ki o si mu ẹrù fun ara rẹ. 22 Abramu si wi fun ọba Sodomu pe, Mo ti gbé ọwọ́ mi soke si OLUWA, Ọlọrun ọga-ogo, ti o ni ọrun on aiye, 23 Pe, emi ki yio mu lati fọnran owu titi dé okùn bàta, ati pe, emi kì yio mu ohun kan ti iṣe tirẹ, ki iwọ ki o má ba wipe, Mo sọ Abramu di ọlọrọ̀: 24 Bikoṣe kìki eyiti awọn ọdọmọkunrin ti jẹ, ati ipín ti awọn ọkunrin ti o ba mi lọ; Aneri, Eṣkoli, ati Mamre; jẹ ki nwọn ki o mu ipín ti wọn.

Genesisi 15

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Abramu

1 LẸHIN nkan wọnyi ọ̀rọ OLUWA tọ̀ Abramu wá li ojuran, wipe, Má bẹ̀ru, Abramu; Emi li asà rẹ, ère nla rẹ gidigidi. 2 Abramu si wipe, OLUWA Ọlọrun, kini iwọ o fi fun mi, emi sa nlọ li ailọmọ, Elieseri ti Damasku yi si ni ẹniti o ni ile mi? 3 Abramu si wipe, Wo o emi ni iwọ kò fi irú-ọmọ fun: si wo o, ẹrú ti a bi ni ile mi ni yio jẹ arolé. 4 Si wo o, ọ̀rọ OLUWA tọ̀ ọ wá, wipe, Eleyi ki yio ṣe arole rẹ; bikoṣe ẹniti yio ti inu ara rẹ jade, on ni yio ṣe arole rẹ. 5 O si mu u jade wá si gbangba, o si wi pe, Gboju wò oke ọrun nisisiyi, ki o si kà irawọ bi iwọ ba le kà wọn: o si wi fun u pe, Bẹ̃ni irú-ọmọ rẹ yio ri. 6 O si gba OLUWA gbọ́; on si kà a si fun u li ododo. 7 O si wi fun u pe, Emi li OLUWA ti o mu ọ jade lati Uri ti Kaldea wá, lati fi ilẹ yi fun ọ lati jogun rẹ̀. 8 O si wipe, OLUWA Ọlọrun, nipa bawo li emi o fi mọ̀ pe emi o jogun rẹ̀? 9 O si wi fun u pe, Mu ẹgbọrọ malu ọlọdun mẹta fun mi wá, ati ewurẹ ọlọdun mẹta, ati àgbo ọlọdun mẹta, ati oriri kan, ati ọmọ ẹiyẹle kan. 10 O si mu gbogbo nkan wọnyi wá sọdọ rẹ̀, o si là wọn li agbedemeji, o si fi ẹ̀la ekini kọju si ekeji: bikoṣe awọn ẹiyẹ ni kò là. 11 Nigbati awọn ẹiyẹ si sọkalẹ wá si ori okú wọnyi, Abramu lé wọn kuro. 12 O si ṣe nigbati õrùn nwọ̀ lọ, orun ìjika kùn Abramu; si kiyesi i, ẹ̀ru bà a, òkunkun biribiri si bò o. 13 On si wi fun Abramu pe, Mọ̀ nitõtọ pe irú-ọmọ rẹ yio ṣe alejo ni ilẹ ti ki iṣe ti wọn, nwọn o si sìn wọn, nwọn o si jẹ wọn ni íya ni irinwo ọdún; 14 Ati orilẹ-ède na pẹlu ti nwọn o ma sìn, li emi o dá lẹjọ: lẹhin na ni nwọn o si jade ti awọn ti ọrọ̀ pipọ̀. 15 Iwọ o si tọ̀ awọn baba rẹ lọ li alafia; li ogbologbo ọjọ́ li a o sin ọ. 16 Ṣugbọn ni iran kẹrin, nwọn o si tun pada wá nihinyi: nitori ẹ̀ṣẹ awọn ara Amori kò ti ikún. 17 O si ṣe nigbati õrùn wọ̀, òkunkun si ṣú, kiyesi i ileru elẽfin, ati iná fitila ti nkọja lãrin ẹ̀la wọnni. 18 Li ọjọ́ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu pe, irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate: 19 Awọn enia Keni, ati awọn enia Kenissi, ati awọn enia Kadmoni, 20 Ati awọn enia Hitti, ati awọn enia Perissi, ati awọn Refaimu, 21 Ati awọn enia Amori, ati awọn enia Kenaani, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Jebusi.

Genesisi 16

Hagari ati Iṣimaeli

1 SARAI, aya Abramu, kò bímọ fun u: ṣugbọn o li ọmọ-ọdọ kan obinrin, ara Egipti, orukọ ẹniti ijẹ Hagari. 2 Sarai si wi fun Abramu pe, kiyesi i na, OLUWA dá mi duro lati bímọ: emi bẹ̀ ọ, wọle tọ̀ ọmọbinrin ọdọ mi; o le ṣepe bọya emi a ti ipasẹ rẹ̀ li ọmọ. Abramu si gbà ohùn Sarai gbọ́. 3 Sarai, aya Abramu, si mu Hagari ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ ara Egipti na, lẹhin igbati Abramu gbé ilẹ Kenaani li ọdún mẹwa, o si fi i fun Abramu ọkọ rẹ̀ lati ma ṣe aya rẹ̀. 4 On si wọle tọ̀ Hagari, o si loyun: nigbati o ri pe on loyun, oluwa rẹ̀ obinrin wa di ẹ̀gan li oju rẹ̀. 5 Sarai si wi fun Abramu pe, Ẹbi mi wà lori rẹ: emi li o fi ọmọbinrin ọdọ mi fun ọ li àiya; nigbati o si ri pe on loyun, mo di ẹ̀gan li oju rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe idajọ lãrin temi tirẹ. 6 Ṣugbọn Abramu wi fun Sarai pe, Wò o, ọmọbinrin ọdọ rẹ wà li ọwọ́ rẹ: fi i ṣe bi o ti tọ́ li oju rẹ. Nigbati Sarai nfõró rẹ̀, o sá lọ kuro lọdọ rẹ̀. 7 Angeli OLUWA si ri i li ẹba isun omi ni ijù, li ẹba isun omi li ọ̀na Ṣuri. 8 O si wipe, Hagari ọmọbinrin ọdọ Sarai, nibo ni iwọ ti mbọ̀? nibo ni iwọ si nrè? O si wipe, emi sá kuro niwaju Sarai oluwa mi. 9 Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Pada, lọ si ọdọ oluwa rẹ, ki o si tẹriba fun u. 10 Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ni bíbi emi o mu iru-ọmọ rẹ bísi i, a ki yio si le kà wọn fun ọ̀pọlọpọ. 11 Angeli OLUWA na si wi fun u pe, kiyesi i iwọ loyun, iwọ o si bí ọmọkunrin, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Iṣmaeli; nitoriti OLUWA ti gbọ́ ohùn arò rẹ. 12 Jagidijagan enia ni yio si ṣe; ọwọ́ rẹ̀ yio wà lara enia gbogbo, ọwọ́ enia gbogbo yio si wà lara rẹ̀: on o si ma gbé iwaju gbogbo awọn arakunrin rẹ̀. 13 O si pè orukọ OLUWA ti o ba a sọ̀rọ ni, Iwọ Ọlọrun ti o ri mi: nitori ti o wipe, Emi ha wá ẹniti o ri mi kiri nihin? 14 Nitori na li a ṣe npè kanga na ni Beer-lahai-roi: kiyesi i, o wà li agbedemeji Kadeṣi on Beredi. 15 Hagari si bí ọmọkunrin kan fun Abramu: Abramu si pè orukọ ọmọ ti Hagari bí ni Iṣmaeli. 16 Abramu si jẹ ẹni ẹrindilãdọrun ọdún, nigbati Hagari bí Iṣmaeli fun Abramu.

Genesisi 17

Ilà Abẹ́ Kíkọ, Àmì Majẹmu Ọlọrun

1 NIGBATI Abramu si di ẹni ọkandilọgọrun ọdún, OLUWA farahàn Abramu, o si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare; mã rìn niwaju mi, ki iwọ ki o si pé. 2 Emi o si ba ọ dá majẹmu mi, emi o si sọ ọ di pupọ̀ gidigidi. 3 Abramu si dojubolẹ; Ọlọrun si ba a sọ̀rọ pe, 4 Bi o ṣe ti emi ni, kiyesi i, majẹmu mi wà pẹlu rẹ, iwọ o si ṣe baba orilẹ-ède pupọ̀. 5 Bẹ̃li a ki yio si pe orukọ rẹ ni Abramu mọ́, bikoṣe Abrahamu li orukọ rẹ yio jẹ; nitoriti mo ti sọ ọ di baba orilẹ-ède pupọ̀. 6 Emi o si mu ọ bí si i pupọpupọ, ọ̀pọ orilẹ-ède li emi o si mu ti ọdọ rẹ wá, ati awọn ọba ni yio ti inu rẹ jade wá. 7 Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ lãrin temi tirẹ, ati lãrin irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn, ni majẹmu aiyeraiye, lati ma ṣe Ọlọrun rẹ, ati ti irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ. 8 Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ̀ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni iní titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn. 9 Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Nitorina ki iwọ ki o ma pa majẹmu mi mọ́, iwọ, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn. 10 Eyi ni majẹmu mi, ti ẹnyin o ma pamọ́ lãrin temi ti nyin, ati lãrin irú-ọmọ rẹ, lẹhin rẹ; gbogbo ọmọkunrin inu nyin li a o kọ ni ilà. 11 Ẹnyin o si kọ ara nyin ni ilà; on ni yio si ṣe àmi majẹmu lãrin temi ti nyin. 12 Ẹniti o ba si di ọmọkunrin ijọ mẹjọ ninu nyin li a o kọ ni ilà, gbogbo ọmọkunrin ni iran-iran nyin, ati ẹniti a bí ni ile, tabi ti a fi owo rà lọwọ alejo, ti ki iṣe irú-ọmọ rẹ. 13 Ẹniti a bí ni ile rẹ, ati ẹniti a fi owo rẹ rà, a kò le ṣe alaikọ ọ ni ilà: bẹ̃ni majẹmu mi yio si wà li ara nyin ni majẹmu aiyeraiye. 14 Ati ọmọkunrin alaikọlà ti a kò kọ ni ilà ara rẹ̀, ọkàn na li a o si ké kuro ninu awọn enia rẹ̀, o dà majẹmu mi. 15 Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Bi o ṣe ti Sarai, aya rẹ nì, iwọ ki yio pè orukọ rẹ̀ ni Sarai mọ́, bikoṣe Sara li orukọ rẹ̀ yio ma jẹ. 16 Emi o si busi i fun u, emi o si bùn ọ li ọmọkunrin kan pẹlu lati ọdọ rẹ̀ wá, bẹ̃li emi o si busi i fun u, on o si ṣe iya ọ̀pọ orilẹ-ède; awọn ọba enia ni yio ti ọdọ rẹ̀ wá. 17 Nigbana li Abrahamu dojubolẹ, o si rẹrin, o si wi li ọkàn rẹ̀ pe, A o ha bímọ fun ẹni ọgọrun ọdún? Sara ti iṣe ẹni ãdọrun ọdún yio ha bímọ bi? 18 Abrahamu si wi fun Ọlọrun pe, Ki Iṣmaeli ki o wà lãye niwaju rẹ! 19 Ọlọrun si wipe, Sara, aya rẹ, yio bí ọmọkunrin kan fun ọ nitõtọ; iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Isaaki: emi o fi idi majẹmu mi mulẹ pẹlu rẹ̀, ni majẹmu aiyeraiye, ati pẹlu irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀. 20 Emi si ti gbọ́ adura rẹ fun Iṣmaeli: kiyesi i, emi o si busi i fun u, emi o si mu u bisi i, emi o si sọ ọ di pupọ̀ gidigidi; ijoye mejila ni on o bí, emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla: 21 Ṣugbọn majẹmu mi li emi o ba Isaaki dá, ẹniti Sara yio bí fun ọ li akoko iwoyi amọ́dun. 22 O si fi i silẹ li ọ̀rọ iba a sọ, Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ Abrahamu. 23 Abrahamu si mu Iṣmaeli, ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin ti a bí ni ile rẹ̀, ati gbogbo awọn ti a fi owo rẹ̀ rà, gbogbo ẹniti iṣe ọkunrin ninu awọn enia ile Abrahamu; o si kọ wọn ni ilà ara li ọjọ́ na gan, bi Ọlọrun ti sọ fun u. 24 Abrahamu si jẹ ẹni ọkandilọgọrun ọdún, nigbati a kọ ọ ni ilà ara rẹ̀. 25 Ati Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkunrin jẹ ẹni ọdún mẹtala nigbati a kọ ọ ni ilà ara rẹ̀. 26 Li ọjọ́ na gan li a kọ Abrahamu ni ilà, ati Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkunrin. 27 Ati gbogbo awọn ọkunrin ile rẹ̀, ti a bi ninu ile rẹ̀, ati ti a si fi owo rà lọwọ alejò, ni a kọ ni ilà pẹlu rẹ̀.

Genesisi 18

Ọlọrun Ṣèlérí Ọmọkunrin Kan fún Abrahamu

1 OLUWA si farahàn a ni igbo Mamre: on si joko li ẹnu-ọ̀na agọ́ ni imõru ọjọ́: 2 O si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, ọkunrin mẹta duro li ẹba ọdọ rẹ̀: nigbati o si ri wọn, o sure lati ẹnu-ọ̀na agọ́ lọ ipade wọn, o si tẹriba silẹ. 3 O si wipe, OLUWA mi, njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, emi bẹ̀ ọ, máṣe kọja lọ kuro lọdọ ọmọ-ọdọ rẹ: 4 Jẹ ki a mu omi diẹ wá nisisiyi, ki ẹnyin ki o si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ki ẹnyin ki o si simi labẹ igi: 5 Emi o si mu onjẹ diẹ wá, ki ẹnyin si fi ọkàn nyin balẹ; lẹhin eyini ki ẹnyin ma kọja lọ: njẹ nitorina li ẹnyin ṣe tọ̀ ọmọ-ọdọ nyin wá. Nwọn si wipe, Ṣe bẹ̃ bi iwọ ti wi. 6 Abrahamu si yara tọ̀ Sara lọ ninu agọ́, o wipe, Yara mu òṣuwọn iyẹfun daradara mẹta, ki o pò o, ki o si dín akara. 7 Abrahamu si sure lọ sinu agbo, o si mu ẹgbọrọ-malu kan ti o rọ̀ ti o dara, o fi fun ọmọkunrin kan; on si yara lati sè e. 8 O si mu orí-amọ́, ati wàra, ati ẹgbọrọ malu ti o sè, o si gbé e kalẹ niwaju wọn: on si duro tì wọn li abẹ igi na, nwọn si jẹ ẹ. 9 Nwọn si bi i pe, nibo ni Sara aya rẹ wà? o si wipe, wò o ninu agọ́. 10 O si wipe, Emi o si tun pada tọ̀ ọ wá nitõtọ ni iwoyi amọ́dun; si kiyesi i, Sara aya rẹ yio li ọmọkunrin kan. Sara si gbọ́ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ti o wà lẹhin ọkunrin na. 11 Njẹ Abrahamu on Sara gbó, nwọn si pọ̀ li ọjọ́; o si dẹkun ati ma ri fun Sara bi ìwa obinrin. 12 Nitorina Sara rẹrin ninu ara rẹ̀ wipe, Lẹhin igbati mo di ogbologbo tan, emi o ha li ayọ̀, ti oluwa mi si di ogbologbo pẹlu? 13 OLUWA si wi fun Abrahamu pe, Nitori kini Sara ṣe nrẹrin wipe, Emi o ha bímọ nitõtọ, ẹniti o ti gbó tán? 14 Ohun kan ha ṣoro fun OLUWA? li akoko ti a dá emi o pada tọ̀ ọ wa, ni iwoyi amọ́dun, Sara yio si li ọmọkunrin kan. 15 Sara si sẹ, wipe, Emi kò rẹrin; nitoriti o bẹ̀ru. On si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn iwọ rẹrin.

Abrahamu Bẹ̀bẹ̀ fún Sodomu

16 Awọn ọkunrin na si dide kuro nibẹ̀, nwọn kọju sihà Sodomu: Abrahamu si ba wọn lọ lati sìn wọn de ọ̀na. 17 OLUWA si wipe, Emi o ha pa ohun ti emi o ṣe mọ́ fun Abrahamu: 18 Nitori pe, Abrahamu yio sa di orilẹ-ède nla ati alagbara, ati gbogbo orilẹ-ède aiye li a o bukun fun nipasẹ rẹ̀? 19 Nitoriti mo mọ̀ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ara ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọ̀na OLUWA mọ́ lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u. 20 OLUWA si wipe, Nitori ti igbe Sodomu on Gomorra pọ̀, ati nitori ti ẹ̀ṣẹ wọn pàpọju. 21 Emi o sọkalẹ lọ nisisiyi, ki nri bi nwọn tilẹ ṣe, gẹgẹ bi okikí igbe rẹ̀, ti o de ọdọ mi; bi bẹ si kọ, emi o mọ̀. 22 Awọn ọkunrin na si yi oju wọn pada kuro nibẹ̀, nwọn si lọ si Sodomu: ṣugbọn Abrahamu duro sibẹ̀ niwaju OLUWA. 23 Abrahamu si sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Iwọ o ha run olododo pẹlu enia buburu? 24 Bọya ãdọta olododo yio wà ninu ilu na: iwọ o ha run u, iwọ ki yio ha dá ibẹ̀ na si nitori ãdọta olododo ti o wà ninu rẹ̀? 25 O ha dára, ti iwọ o fi ṣe bi irú eyi, lati run olododo pẹlu enia buburu; ti awọn olododo yio fi dabi awọn enia buburu, o ha dára: Onidajọ gbogbo aiye ki yio ha ṣe eyi ti o tọ́? 26 OLUWA si wipe, Bi mo ba ri ãdọta olododo ninu ilu Sodomu, njẹ emi o dá gbogbo ibẹ̀ si nitori wọn. 27 Abrahamu si dahùn o si wipe, Wò o nisisiyi, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ, emi ẹniti iṣe erupẹ ati ẽru. 28 Bọya marun a dín ninu ãdọta olododo na: iwọ o ha run gbogbo ilu na nitori marun? On si wipe, Bi mo ba ri marunlelogoji nibẹ̀, emi ki yio run u. 29 O si tun sọ fun u ẹ̀wẹ, o ni, Bọya, a o ri ogoji nibẹ̀, On si wipe, Emi ki o run u nitori ogoji. 30 O si tun wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, emi o si ma wi: bọya a o ri ọgbọ̀n nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u bi mo ba ri ọgbọ̀n nibẹ̀. 31 O si wipe, Wò o na, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ: bọya a o ri ogun nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori ogun. 32 O si wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, ẹ̃kanṣoṣo yi li emi o si wi mọ. Bọya a o ri mẹwa nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori mẹwa. 33 OLUWA si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna bi o ti ba Abrahamu sọ̀rọ tan; Abrahamu si pada lọ si ibujoko rẹ̀.

Genesisi 19

Ìwà Ẹ̀ṣẹ̀ Sodomu

1 AWỌN Angeli meji si wá si Sodomu li aṣalẹ; Loti si joko li ẹnu-bode Sodomu: bi Loti si ti ri wọn, o dide lati pade wọn: o si dojubolẹ; 2 O si wipe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnyin oluwa mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ yà si ile ọmọ-ọdọ nyin, ki ẹ si wọ̀, ki ẹ si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ẹnyin o si dide ni kùtukutu, ki ẹ si ma ba ti nyin lọ. Nwọn si wipe, Ndao; ṣugbọn awa o joko ni igboro li oru oni. 3 O si rọ̀ wọn gidigidi; nwọn si yà tọ̀ ọ, nwọn si wọ̀ inu ile rẹ̀; o si sè àse fun wọn, o si dín àkara alaiwu fun wọn, nwọn si jẹ. 4 Ṣugbọn ki nwọn ki o to dubulẹ, awọn ọkunrin ara ilu na, awọn ọkunrin Sodomu, nwọn yi ile na ká, ati àgba ati ewe, gbogbo enia lati ori igun mẹrẹrin wá. 5 Nwọn si pè Loti, nwọn si bi i pe, Nibo li awọn ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá li alẹ yi wà? mu wọn jade fun wa wá, ki awa ki o le mọ̀ wọn. 6 Loti si jade tọ̀ wọn lọ li ẹnu-ọ̀na, o si sé ilẹkun lẹhin rẹ̀. 7 O si wipe, Arakunrin, emi bẹ̀ nyin, ẹ máṣe hùwa buburu bẹ̃. 8 Kiyesi i nisisiyi, emi li ọmọbinrin meji ti kò ti imọ̀ ọkunrin: emi bẹ̀ nyin, ẹ jẹ ki nmu wọn jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o si fi wọn ṣe bi o ti tọ́ loju nyin: ṣugbọn awọn ọkunrin wọnyi ṣa ni ki ẹ má ṣe ni nkan; nitorina ni nwọn sa ṣe wá si abẹ orule mi. 9 Nwọn si wipe, Bì sẹhin. Nwọn si tun wipe, Eyiyi wá iṣe atipo, on si fẹ iṣe onidajọ: njẹ iwọ li a o tilẹ ṣe ni buburu jù wọn lọ. Nwọn si rọlù ọkunrin na, ani Loti, nwọn si sunmọ ọ lati fọ́ ilẹkun. 10 Ṣugbọn awọn ọkunrin na nà ọwọ́ wọn, nwọn si fà Loti mọ́ ọdọ sinu ile, nwọn si tì ilẹkun. 11 Nwọn si bù ifọju lù awọn ọkunrin ti o wà li ẹnu-ọ̀na ile na, ati ewe ati àgba: bẹ̃ni nwọn dá ara wọn li agara lati ri ẹnu-ọ̀na.

Lọti Jáde kúrò ní Sodomu

12 Awọn ọkunrin na si wi fun Loti pe, Iwọ ni ẹnikan nihin pẹlu? ana rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ati ohunkohun ti iwọ ni ni ilu, mu wọn jade kuro nihinyi: 13 Nitori awa o run ibi yi, nitori ti igbe wọn ndi pupọ̀ niwaju OLUWA; OLUWA si rán wa lati run u. 14 Loti si jade, o si sọ fun awọn ana rẹ̀ ọkunrin, ti nwọn gbe awọn ọmọbinrin rẹ̀ ni iyawo, o wipe, Ẹ dide, ẹ jade kuro nihinyi; nitoriti OLUWA yio run ilu yi. Ṣugbọn o dabi ẹlẹtàn loju awọn ana rẹ̀. 15 Nigbati ọ̀yẹ si nla, nigbana li awọn angeli na le Loti ni ire wipe, Dide, mu aya rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ mejeji ti o wà nihin; ki iwọ ki o má ba run ninu ìya ẹ̀ṣẹ ilu yi. 16 Nigbati o si nlọra, awọn ọkunrin na nawọ mu u li ọwọ́, ati ọwọ́ aya rẹ̀, ati ọwọ́ ọmọbinrin rẹ̀ mejeji; OLUWA sa ṣãnu fun u: nwọn si mu u jade, nwọn si fi i sẹhin odi ilu na. 17 O si ṣe nigbati nwọn mu wọn jade sẹhin odi tan, li o wipe, Sá asalà fun ẹmi rẹ; máṣe wò ẹhin rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe duro ni gbogbo pẹtẹlẹ; sá asalà lọ si ori oke, ki iwọ ki o má ba ṣegbe. 18 Loti si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi: 19 Kiyesi i na, ọmọ-ọdọ rẹ ti ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, iwọ si ti gbe ãnu rẹ ga, ti iwọ ti fi hàn mi ni gbigbà ẹmi mi là; ṣugbọn emi ki yio le salọ si ori oke, ki ibi ki o má ba bá mi nibẹ̀, ki emi ki o má ba kú. 20 Kiyesi i na, ilu yi sunmọ tosi lati sá si, kekere si ni: jọ̃, jẹ ki nsalà si ibẹ, (kekere ha kọ?) ọkàn mi yio si yè. 21 O si wi fun u pe, Wò o, mo gbà fun ọ niti ohun kan yi pẹlu pe, emi ki yio run ilu yi, nitori eyiti iwọ ti sọ. 22 Yara, salà sibẹ̀; nitori emi kò le ṣe ohun kan titi iwọ o fi de ibẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Soari.

Ìparun Sodomu ati Gomora

23 Orùn là sori ilẹ nigbati Loti wọ̀ ilu Soari. 24 Nigbana li OLUWA rọ̀jo sulfuri (okuta ina) ati iná lati ọdọ OLUWA lati ọrun wá si ori Sodomu on Gomorra: 25 O si run ilu wọnni, ati gbogbo Pẹtẹlẹ, ati gbogbo awọn ara ilu wọnni, ati ohun ti o hù jade ni ilẹ. 26 Ṣugbọn aya rẹ̀ bojuwò ẹhin lẹhin rẹ̀, o si di ọwọ̀n iyọ̀. 27 Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o lọ si ibi ti o gbé duro niwaju OLUWA: 28 O si wò ìha Sodomu on Gomorra, ati ìha gbogbo ilẹ àgbegbe wọnni, o si wò o, si kiyesi i, ẽfin ilẹ na rú soke bi ẽfin ileru. 29 O si ṣe nigbati Ọlọrun run ilu àgbegbe wọnni ni Ọlọrun ranti Abrahamu, o si rán Loti jade kuro lãrin iparun na, nigbati o run ilu wọnni ninu eyiti Loti gbé ti joko.

Ìtàn Ìṣẹ̀dálẹ̀ Àwọn Ará Moabu ati Àwọn Ará Amoni

30 Loti si jade kuro ni Soari: o si ngbé ori oke, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nitoriti o bẹ̀ru ati gbé Soari: o si ngbé inu ihò, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji. 31 Eyi akọbi si wi fun atẹle pe, Baba wa gbó, kò si sí ọkunrin kan li aiye mọ́ ti yio wọle tọ̀ wa wá gẹgẹ bi iṣe gbogbo aiye. 32 Wá, jẹ ki a mu baba wa mu ọti-waini, awa o si sùn tì i, ki a le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa. 33 Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na: eyi akọbi wọle tọ̀ ọ, o si sùn tì baba rẹ̀; on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide. 34 O si ṣe, ni ijọ́ keji, ni ẹgbọn wi fun aburo pe, kiyesi i, emi sùn tì baba mi li oru aná: jẹ ki a si mu u mu ọti-waini li oru yi pẹlu: ki iwọ ki o si wọle, ki o si sùn tì i, ki awa ki o le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa. 35 Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na pẹlu: aburo si dide, o si sùn tì i, on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide. 36 Bẹ̃li awọn ọmọbinrin Loti mejeji loyun fun baba wọn. 37 Eyi akọ́bi si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Moabu: on ni baba awọn ara Moabu titi di oni. 38 Eyi atẹle, on pẹlu si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Ben-ammi: on ni baba awọn ọmọ Ammoni, titi di oni.

Genesisi 20

Abrahamu ati Abimeleki

1 ABRAHAMU si ṣí lati ibẹ̀ lọ si ilẹ ìha gusù, o si joko li agbedemeji Kadeṣi on Ṣuri; o si ṣe atipo ni Gerari. 2 Abrahamu si wi niti Sara aya rẹ̀ pe, Arabinrin mi ni: Abimeleki ọba Gerari si ranṣẹ, o si mu Sara. 3 Ṣugbọn Ọlọrun tọ̀ Abimeleki wá li ojuran li oru, o si wi fun u pe, kiyesi i, okú ni iwọ, nitori obinrin ti iwọ mu nì; nitori aya ọkunrin kan ni iṣe. 4 Ṣugbọn Abimeleki kò sunmọ ọ: o si wipe, OLUWA, iwọ o run orilẹ-ède olododo pẹlu? 5 On kọ ló ha wi fun mi pe arabinrin mi ni iṣe? on, obinrin tikalarẹ̀ si wipe, arakunrin mi ni: li otitọ inu ati alaiṣẹ̀ ọwọ́ mi, ni mo fi ṣe eyi. 6 Ọlọrun si wi fun u li ojuran pe, Bẹ̃ni, emi mọ̀ pe li otitọ inu rẹ ni iwọ ṣe eyi; nitorina li emi si ṣe dá ọ duro ki o má ba ṣẹ̀ mi: nitorina li emi kò ṣe jẹ ki iwọ ki o fọwọkàn a. 7 Njẹ nitori na mu aya ọkunrin na pada fun u; woli li on sa iṣe, on o si gbadura fun ọ, iwọ o si yè: bi iwọ kò ba si mu u pada, ki iwọ ki o mọ̀ pe, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo ẹniti o jẹ tirẹ. 8 Nitorina Abimeleki dide ni kutukutu owurọ̀, o si pè gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si wi gbogbo nkan wọnyi li eti wọn: ẹ̀ru si bà awọn enia na gidigidi. 9 Nigbana li Abimeleki pè Abrahamu, o si wi fun u pe, Kili o ṣe si wa yi? ẹ̀ṣẹ kini mo ṣẹ̀ ọ, ti iwọ fi mu ẹ̀ṣẹ nla wá si ori mi, ati si ori ijọba mi? iwọ hùwa si mi ti a ki ba hù. 10 Abimeleki si wi fun Abrahamu pe, Kini iwọ ri, ti iwọ fi ṣe nkan yi? 11 Abrahamu si wipe, Nitoriti mo rò pe, nitõtọ ẹ̀ru Ọlọrun kò sí nihinyi; nwọn o si pa mi nitori aya mi. 12 Ati pẹlupẹlu nitõtọ arabinrin mi ni iṣe, ọmọbinrin baba mi ni, ṣugbọn ki iṣe ọmọbinrin iya mi; o si di aya mi. 13 O si ṣe nigbati Ọlọrun mu mi rìn kiri lati ile baba mi wá, on ni mo wi fun u pe, eyi ni ore rẹ ti iwọ o ma ṣe fun mi; nibikibi ti awa o gbé de, ma wi nipa ti emi pe, arakunrin mi li on. 14 Abimeleki si mu agutan, ati akọmalu, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, o si fi wọn fun Abrahamu, o si mu Sara, aya rẹ̀, pada fun u. 15 Abimeleki si wipe, Kiyesi i, ilẹ mi niyi niwaju rẹ: joko nibiti o wù ọ. 16 O si wi fun Sara pe, Kiyesi i, mo fi ẹgbẹrun ìwọn fadaka fun arakunrin rẹ: kiyesi i, on ni ibojú fun ọ fun gbogbo awọn ti o wà lọdọ rẹ, ati niwaju gbogbo awọn ẹlomiran li a da ọ lare. 17 Abrahamu si gbadura si Ọlọrun: Ọlọrun si mu Abimeleki li ara dá, ati aya rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin-ọdọ rẹ̀; nwọn si bimọ. 18 Nitori OLUWA ti sé inu awọn ara ile Abimeleki pinpin, nitori ti Sara, aya Abrahamu.

Genesisi 21

A Bí Isaaki

1 OLUWA si bẹ̀ Sara wò bi o ti wi, OLUWA si ṣe fun Sara bi o ti sọ. 2 Sara si loyun, o si bí ọmọkunrin kan fun Abrahamu li ogbologbo rẹ̀, li akokò igbati Ọlọrun dá fun u. 3 Abrahamu si pè orukọ ọmọ rẹ̀ ti a bí fun u, ni Isaaki, ẹniti Sara bí fun u. 4 Abrahamu si kọ Isaaki ọmọ rẹ̀ ni ilà, nigbati o di ọmọ ijọ́ mẹjọ, gẹgẹ bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. 5 Abrahamu si jẹ ẹni ọgọrun ọdún, nigbati a bí Isaaki ọmọ rẹ̀ fun u. 6 Sara si wipe, Ọlọrun pa mi lẹrin; gbogbo ẹniti o gbọ́ yio si rẹrin pẹlu mi. 7 O si wipe, Tani iba wi fun Abrahamu pe, Sara yio fi ọmú fun ọmọ mu? mo sá bí ọmọ kan fun u li ogbologbo rẹ̀. 8 Ọmọ na si dàgba, a si já a li ẹnu ọmú: Abrahamu si sè àse nla li ọjọ́ na ti a já Isaaki li ẹnu ọmú.

Wọ́n Lé Hagari ati Iṣimaeli Jáde nílé

9 Sara si ri ọmọ Hagari, ara Egipti, ti o bí fun Abrahamu, o nfi i rẹrin. 10 Nitorina li o ṣe wi fun Abrahamu pe, Lé ẹrubirin yi jade ti on ti ọmọ rẹ̀: nitoriti ọmọ ẹrubirin yi ki yio ṣe arole pẹlu Isaaki, ọmọ mi. 11 Ọrọ yi si buru gidigidi li oju Abrahamu nitori ọmọ rẹ̀. 12 Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Máṣe jẹ ki o buru li oju rẹ nitori ọmọdekunrin na, ati nitori ẹrubirin rẹ; ni gbogbo eyiti Sara sọ fun ọ, fetisi ohùn rẹ̀; nitori ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ. 13 Ati ọmọ ẹrubirin na pẹlu li emi o sọ di orilẹ-ède, nitori irú-ọmọ rẹ ni iṣe. 14 Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o mu àkara ati ìgo omi kan, o fi fun Hagari, o gbé e lé e li ejika, ati ọmọ na, o si lé e jade: on si lọ, o nrìn kakiri ni ijù Beer-ṣeba. 15 Omi na si tán ninu ìgo, o si sọ̀ ọmọ na si abẹ ìgboro kan. 16 O si lọ, o joko kọju si i, li ọ̀na jijìn rére, o tó bi itafasi kan: nitori ti o wipe, Ki emi má ri ikú ọmọ na. O si joko kọju si i, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o nsọkun. 17 Ọlọrun si gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na: angeli Ọlọrun si pè Hagari lati ọrun wá, o bi i pe, Kili o ṣe ọ, Hagari? máṣe bẹ̀ru; nitori ti Ọlọrun ti gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na nibiti o gbé wà. 18 Dide, gbé ọmọdekunrin na, ki o si dì i mu; nitori ti emi o sọ ọ di orilẹ-ède nla. 19 Ọlọrun si ṣí i li oju, o si ri kanga omi kan; o lọ, o si pọnmi kún ìgo na, o si fi fun ọmọdekunrin na mu. 20 Ọlọrun si wà pẹlu ọmọdekunrin na; o si dàgba, o si joko ni ijù, o di tafatafa. 21 O si joko ni ijù Parani: iya rẹ̀ si fẹ́ obinrin fun u lati ilẹ Egipti wá.

Majẹmu láàrin Abrahamu ati Abimeleki

22 O si ṣe li akokò na, ni Abimeleki ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, wi fun Abrahamu pe, Ọlọrun pẹlu rẹ ni gbogbo ohun ti iwọ nṣe. 23 Njẹ nisisiyi fi Ọlọrun bura fun mi nihinyi pe iwọ ki yio ṣe ẹ̀tan si mi, tabi si ọmọ mi, tabi si ọmọ-ọmọ mi: ṣugbọn gẹgẹ bi iṣeun ti mo ṣe si ọ, bẹ̃ni iwọ o si ṣe si mi, ati si ilẹ ti iwọ ti ṣe atipo ninu rẹ̀. 24 Abrahamu si wipe, emi o bura. 25 Abrahamu si ba Abimeleki wi nitori kanga omi kan, ti awọn ọmọ-ọdọ Abimeleki fi agbara gbà. 26 Abimeleki si wipe, emi kò mọ̀ ẹniti o ṣe nkan yi: bẹ̃ni iwọ kò sọ fun mi, bẹ̃li emi kò gbọ́, bikoṣe loni. 27 Abrahamu si mu agutan, ati akọmalu, o fi wọn fun Abimeleki; awọn mejeji si dá majẹmu. 28 Abrahamu si yà abo ọdọ-agutan meje ninu agbo si ọ̀tọ fun ara wọn. 29 Abimeleki si bi Abrahamu pe, kili a le mọ̀ abo ọdọ-agutan meje ti iwọ yà si ọ̀tọ fun ara wọn yi si? 30 O si wipe, nitori abo ọdọ-agutan meje yi ni iwọ o gbà lọwọ mi, ki nwọn ki o le ṣe ẹrí mi pe, emi li o wà kanga yi. 31 Nitorina li o ṣe pè ibẹ̀ na ni Beer-ṣeba; nitori nibẹ̀ li awọn mejeji gbé bura. 32 Bẹ̃ni nwọn si dá majẹmu ni Beer-ṣeba: nigbana li Abimeleki dide, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilẹ awọn ara Filistia. 33 Abrahamu si lọ́ igi tamariski kan ni Beer-ṣeba, nibẹ̀ li o si pè orukọ OLUWA, Ọlọrun Aiyeraiye. 34 Abrahamu si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọjọ́ pupọ̀.

Genesisi 22

Ọlọrun Pàṣẹ fún Abrahamu pé Kí Ó fi Isaaki Rúbọ

1 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi ni Ọlọrun dan Abrahamu wò, o si wi fun u pe, Abrahamu: on si dahùn pe, Emi niyi. 2 O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ. 3 Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãrì, o si mu meji ninu awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati Isaaki, ọmọ rẹ̀, o si là igi fun ẹbọ sisun na, o si dide, o si lọ si ibi ti Ọlọrun sọ fun u. 4 Ni ijọ́ kẹta Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o ri ibẹ̀ na li okere. 5 Abrahamu si wi fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, pe, Ẹnyin joko nihin pẹlu kẹtẹkẹtẹ; ati emi ati ọmọ yi yio lọ si ọhùn ni, a o si gbadura, a o si tun pada tọ̀ nyin wá. 6 Abrahamu si mu igi ẹbọ sisun na, o si dì i rù Isaaki, ọmọ rẹ̀; o si mu iná li ọwọ́ rẹ̀, ati ọbẹ; awọn mejeji si jùmọ nlọ. 7 Isaaki si sọ fun Abrahamu baba rẹ̀, o si wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi, ọmọ mi. On si wipe, Wò iná on igi; ṣugbọn nibo li ọdọ-agutan ẹbọ sisun na gbé wà? 8 Abrahamu si wipe, Ọmọ mi, Ọlọrun tikalarẹ̀ ni yio pèse ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun: bẹ̃li awọn mejeji jùmọ nlọ. 9 Nwọn si de ibi ti Ọlọrun ti wi fun u; Abrahamu si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si to igi rere, o si dì Isaaki ọmọ rẹ̀, o si dá a bulẹ li ori pẹpẹ lori igi na. 10 Abrahamu si nawọ rẹ̀, o si mu ọbẹ na lati dúmbu ọmọ rẹ̀. 11 Angeli OLUWA nì si kọ si i lati ọrun wá, o wipe, Abrahamu, Abrahamu: o si dahùn pe, Emi niyi. 12 O si wipe, Máṣe fọwọkàn ọmọde nì, bẹ̃ni iwọ kó gbọdọ ṣe e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ̀ pe iwọ bẹ̀ru Ọlọrun, nigbati iwọ kò ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo. 13 Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, lẹhin rẹ̀, àgbo kan ti o fi iwo rẹ̀ há ni pantiri: Abrahamu si lọ o mu àgbo na, o si fi i rubọ sisun ni ipò ọmọ rẹ̀. 14 Abrahamu si pè orukọ ibẹ̀ na ni Jehofajire: bi a ti nwi titi di oni yi, Li oke OLUWA li a o gbé ri i. 15 Angeli OLUWA nì si kọ si Abrahamu lati ọrun wá lẹrinkeji, 16 O si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, li OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo: 17 Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn; 18 Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ́. 19 Abrahamu si pada tọ̀ awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, nwọn si dide, nwọn si jùmọ lọ si Beer-ṣeba; Abrahamu si joko ni Beer-ṣeba. 20 O si ṣe, lẹhin nkan wọnyi, li a sọ fun Abrahamu pe, kiyesi i, Milka, on pẹlu si ti bimọ fun Nahori, arakunrin rẹ;

Àwọn Ìran Nahori

21 Husi akọ́bi rẹ̀, ati Busi arakunrin rẹ̀, ati Kemueli baba Aramu. 22 Ati Kesedi, ati Haso, ati Pildaṣi, ati Jidlafu, ati Betueli. 23 Betueli si bí Rebeka: awọn mẹjọ yi ni Milka bí fun Nahori, arakunrin Abrahamu. 24 Ati àle rẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ Rehuma, on pẹlu si bí Teba, ati Gahamu, ati Tahaṣi, ati Maaka.

Genesisi 23

1 SARA si di ẹni ẹtadilãdoje ọdún: iye ọdún aiye Sara li eyi. 2 Sara si kú ni Kirjat-arba; eyi na ni Hebroni ni ilẹ Kenaani: Abrahamu si wá lati ṣọ̀fọ Sara ati lati sọkun rẹ̀. 3 Abrahamu si dide kuro niwaju okú rẹ̀, o si sọ fun awọn ọmọ Heti, wipe, 4 Alejò ati atipo li emi iṣe lọdọ nyin: ẹ fun mi ni ilẹ-isinku lãrin nyin, ki emi ki o le sin okú mi kuro ni iwaju mi. 5 Awọn ọmọ Heti si dá Abrahamu lohùn, nwọn si wi fun u pe, 6 Oluwa mi, gbọ́ ti wa: alagbara ọmọ-alade ni iwọ lãrin wa: ninu ãyò bojì wa ni ki o sin okú rẹ; kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio fi ibojì rẹ̀ dù ọ, ki iwọ ki o má sin okú rẹ. 7 Abrahamu si dide duro, o si tẹriba fun awọn enia ilẹ na, fun awọn ọmọ Heti. 8 O si ba wọn sọ̀rọ wipe, Bi o ba ṣe pe ti inu nyin ni ki emi ki o sin okú mi kuro ni iwaju mi, ẹ gbọ́ ti emi, ki ẹ si bẹ̀ Efroni, ọmọ Sohari, fun mi, 9 Ki o le fun mi ni ihò Makpela, ti o ni, ti o wà li opinlẹ oko rẹ̀; li oju-owo ni ki o fifun mi, fun ilẹ-isinku lãrin nyin. 10 Efroni si joko lãrin awọn ọmọ Heti: Efroni, ọmọ Heti, si dá Abrahamu lohùn li eti gbogbo awọn ọmọ Heti, ani li eti gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀ wipe, 11 Bẹ̃kọ, Oluwa mi, gbọ́ ti emi, mo fi oko na fun ọ, ati ihò ti o wà nibẹ̀, mo fi fun ọ: li oju awọn ọmọ awọn enia mi ni mo fi i fun ọ: sin okú rẹ. 12 Abrahamu si tẹriba niwaju awọn enia ilẹ na. 13 O si wi fun Efroni, li eti awọn enia ilẹ na pe, Njẹ bi iwọ o ba fi i fun mi, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ti emi: emi o san owo oko na fun ọ; gbà a lọwọ mi, emi o si sin okú mi nibẹ̀. 14 Efroni si da Abrahamu li ohùn, o wi fun u pe, 15 Oluwa mi, gbọ́ ti emi: irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka ni ilẹ jẹ; kili eyini lãrin temi tirẹ? sa sin okú rẹ. 16 Abrahamu si gbọ́ ti Efroni; Abrahamu si wọ̀n iye fadaka na fun Efroni, ti o sọ li eti awọn ọmọ Heti, irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka, ti o kọja lọdọ awọn oniṣòwo. 17 Oko Efroni ti o wà ni Makpela, ti o wà niwaju Mamre, oko na, ati ihò ti o wà ninu rẹ̀, ati gbogbo igi ti o wà ni oko na, ti o wà ni gbogbo ẹba rẹ̀ yika, li a ṣe daju, 18 Fun Abrahamu ni ilẹ-ini, li oju awọn ọmọ Heti, li oju gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀. 19 Lẹhin eyi li Abrahamu sin Sara, aya rẹ̀, ninu ihò oko Makpela, niwaju Mamre: eyi nã ni Hebroni ni ilẹ Kenaani. 20 Ati oko na, ati ihò ti o wà nibẹ̀, li a ṣe daju fun Abrahamu, ni ilẹ isinku, lati ọwọ́ awọn ọmọ Heti wá.

Genesisi 24

Wọ́n Gbeyawo fún Isaaki

1 ABRAHAMU si gbó, o si pọ̀ li ọjọ́: OLUWA si ti busi i fun Abrahamu li ohun gbogbo. 2 Abrahamu si wi fun iranṣẹ rẹ̀, agba ile rẹ̀ ti o ṣe olori ohun gbogbo ti o ni pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ọwọ rẹ si abẹ itan mi; 3 Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé: 4 Ṣugbọn iwọ o lọ si ilẹ mi, ati si ọdọ awọn ará mi, ki iwọ ki o si fẹ́ aya fun Isaaki, ọmọ mi. 5 Iranṣẹ na si wi fun u pe, Bọya obinrin na ki yio fẹ́ ba mi wá si ilẹ yi: mo ha le mu ọmọ rẹ pada lọ si ilẹ ti iwọ gbé ti wá? 6 Abrahamu si wi fun u pe, Kiyesara ki iwọ ki o má tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀. 7 OLUWA Ọlọrun ọrun, ti o mu mi lati ile baba mi wá, ati lati ilẹ ti a bi mi, ẹniti o sọ fun mi, ti o si bura fun mi, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun; on ni yio rán angeli rẹ̀ ṣaju rẹ, iwọ o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ fun ọmọ mi wá. 8 Bi obinrin na kò ba si fẹ́ tẹle ọ, njẹ nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ni ibura mi yi: ọkan ni, ki iwọ máṣe tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀. 9 Iranṣẹ na si fi ọwọ́ rẹ̀ si abẹ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, o si bura fun u nitori ọ̀ran yi. 10 Iranṣẹ na si mu ibakasiẹ mẹwa, ninu ibakasiẹ oluwa rẹ̀, o si lọ; nitori pe li ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹrù oluwa rẹ̀ wà: o si dide, o si lọ si Mesopotamia, si ilu Nahori. 11 O si mu awọn ibakasiẹ rẹ̀ kunlẹ lẹhin ode ilu na li ẹba kanga omi kan nigba aṣalẹ, li akokò igbati awọn obinrin ima jade lọ pọnmi. 12 O si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, ṣe ọ̀na mi ni rere loni, ki o si ṣe ore fun Abrahamu oluwa mi. 13 Kiyesi i, emi duro li ẹba kanga omi yi; awọn ọmọbinrin ara ilu na njade wá lati pọnmi: 14 Ki o si jẹ ki o ṣe pe, omidan ti emi o wi fun pe, Emi bẹ̀ ọ, sọ ladugbo rẹ kalẹ, ki emi ki o mu; ti on o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu: on na ni ki o jẹ ẹniti iwọ yàn fun Isaaki iranṣẹ rẹ; nipa eyi li emi o si mọ̀ pe, iwọ ti ṣe ore fun oluwa mi. 15 O si ṣe, ki on to pari ọ̀rọ isọ, kiyesi i, Rebeka jade de, ẹniti a bí fun Betueli, ọmọ Milka, aya Nahori, arakunrin Abrahamu, ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀. 16 Omidan na li ẹwà gidigidi lati wò, wundia ni, bẹ̃li ẹnikẹni kò ti imọ̀ ọ: o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o si pọn ladugbo rẹ̀ kún, o si goke. 17 Iranṣẹ na si sure lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nmu omi diẹ ninu ladugbo rẹ. 18 O si dahùn pe, Mu, oluwa mi: o si yara, o sọ̀ ladugbo rẹ̀ ka ọwọ́, o si fun u mu. 19 Nigbati o si fun u mu tan, o si wipe, Emi o pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu, titi nwọn o fi mu tan. 20 O si yara, o si tú ladugbo rẹ̀ sinu ibumu, o si tun pada sure lọ si kanga lati pọn omi, o si pọn fun gbogbo awọn ibakasiẹ rẹ̀. 21 ọkunrin na si tẹjumọ ọ, o dakẹ, lati mọ̀ bi OLUWA mu ìrin on dara, bi bẹ̃kọ. 22 O si ṣe, bi awọn ibakasiẹ ti mu omi tan, ni ọkunrin na mu oruka wurà àbọ ìwọn ṣekeli, ati jufù meji fun ọwọ́ rẹ̀, ti ìwọn ṣekeli wurà mẹwa; 23 O si bi i pe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi: àye wà ni ile baba rẹ fun wa lati wọ̀ si? 24 On si wi fun u pe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Milka, ti o bí fun Nahori, li emi iṣe. 25 O si wi fun u pe, Awa ni koriko ati sakasáka tó pẹlu, ati àye lati wọ̀ si. 26 Ọkunrin na si tẹriba, o si sìn OLUWA. 27 O si wipe, Olubukún li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, ti kò jẹ ki ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ ki o yẹ̀ kuro lọdọ, oluwa mi, niti emi, OLUWA fi ẹsẹ̀ mi le ọ̀na ile awọn arakunrin baba mi. 28 Omidan na si sure, o si rò nkan wọnyi fun awọn ara ile iya rẹ̀. 29 Rebeka si li arakunrin kan, orukọ rẹ̀ si ni Labani: Labani si sure jade tọ̀ ọkunrin na lọ si ibi kanga. 30 O si ṣe, bi o ti ri oruka, ati jufù li ọwọ́ arabinrin rẹ̀, ti o si gbọ́ ọ̀rọ Rebeka arabinrin rẹ̀ pe, Bayi li ọkunrin na ba mi sọ; bẹ̃li o si tọ̀ ọkunrin na wá; si kiyesi i, o duro tì awọn ibakasiẹ rẹ̀ leti kanga na. 31 O si wipe, Wọle, iwọ ẹni-ibukún OLUWA; ẽṣe ti iwọ fi duro lode? mo sá ti pèse àye silẹ ati àye fun awọn ibakasiẹ. 32 Ọkunrin na si wọle na wá; o si tú awọn ibakasiẹ, o si fun awọn ibakasiẹ, ni koriko ati sakasáka, ati omi fun u lati wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ati ẹsẹ̀ awọn ọkunrin ti o pẹlu rẹ̀. 33 A si gbé onjẹ kalẹ fun u lati jẹ: ṣugbọn on si wipe, Emi ki yio jẹun titi emi o fi jiṣẹ mi tán. On si wipe, Ma wi. 34 O si wipe, Ọmọ-ọdọ Abrahamu li emi iṣe. 35 OLUWA si ti bukún fun oluwa mi gidigidi; o si di pupọ̀: o si fun u li agutan, ati mãlu, ati fadaka, ati wurà, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ. 36 Sara, aya oluwa mi, si bí ọmọ kan fun oluwa mi nigbati on (Sara) gbó tán: on li o si fi ohun gbogbo ti o ni fun. 37 Oluwa mi si mu mi bura, wipe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ obinrin fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani ni ilẹ ẹniti emi ngbé: 38 Bikoṣe ki iwọ ki o lọ si ile baba mi, ati si ọdọ awọn ibatan mi, ki o si fẹ́ aya fun ọmọ mi. 39 Emi si wi fun oluwa mi pe, Bọya obinrin na ki yio tẹle mi. 40 O si wi fun mi pe, OLUWA, niwaju ẹniti emi nrìn, yio rán angeli rẹ̀ pelu rẹ, yio si mu ọ̀na rẹ dara; iwọ o si fẹ́ aya fun ọmọ mi lati ọdọ awọn ibatan mi, ati lati inu ile baba mi: 41 Nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ninu ibura mi yi, nigbati iwọ ba de ọdọ awọn ibatan mi; bi nwọn kò ba si fi ẹnikan fun ọ, ọrùn rẹ yio si mọ́ kuro ninu ibura mi. 42 Emi si de si ibi kanga loni, mo si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, bi iwọ ba mu ọ̀na àjo mi ti mo nlọ nisisiyi dara: 43 Kiyesi i, mo duro li ẹba kanga omi; ki o si ṣẹ, pe nigbati wundia na ba jade wá ipọn omi, ti mo ba si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi li omi diẹ ki emi mu lati inu ladugbo rẹ; 44 Ti o si wi fun mi pe, Iwọ mu, emi o si pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu: ki on na ki o ṣe obinrin ti OLUWA ti yàn fun ọmọ oluwa mi. 45 Ki emi ki o si tó wi tán li ọkàn mi, kiyesi i, Rebeka jade de ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀; o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o pọn omi: emi si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi mu omi. 46 O si yara, o si sọ ladugbo rẹ̀ kalẹ kuro li ejika rẹ̀, o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu; bẹ̃li emi mu, o si fi fun awọn ibakasiẹ mu pẹlu. 47 Emi si bi i, mo si wipe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? o si wipe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Nahori, ti Milka bí fun u: emi si fi oruka si i ni imu, ati jufù si ọwọ́ rẹ̀. 48 Emi si tẹriba, mo si wolẹ fun OLUWA, mo si fi ibukún fun OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, ti o mu mi tọ̀ ọ̀na titọ lati mu ọmọbinrin arakunrin oluwa mi fun ọmọ rẹ̀ wá. 49 Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin o ba bá oluwa mi lò inu rere ati otitọ, ẹ wi fun mi: bi bẹ̃ si kọ; ẹ wi fun mi: ki emi ki o le pọ̀ si apa ọtún, tabi si òsi. 50 Nigbana ni Labani ati Betueli dahùn nwọn si wipe, Lọdọ OLUWA li ohun na ti jade wá: awa kò le sọ rere tabi buburu fun ọ. 51 Wò o, Rebeka niyi niwaju rẹ, mu u, ki o si ma lọ, ki on ki o si ma ṣe aya ọmọ oluwa rẹ, bi OLUWA ti wi. 52 O si ṣe, nigbati iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ọ̀rọ wọn, o wolẹ fun OLUWA. 53 Iranṣẹ na si yọ ohun èlo fadaka, ati èlo wurà jade, ati aṣọ, o si fi wọn fun Rebeka: o si fi ohun iyebiye pẹlu fun arakunrin rẹ̀ ati fun iya rẹ̀. 54 Nwọn si jẹ, nwọn si mu, on ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn si wọ̀ nibẹ̀ li oru ijọ́ na; nwọn si dide li owurọ̀, o si wipe, Ẹ rán mi lọ si ọdọ oluwa mi. 55 Arakunrin ati iya rẹ̀ si wipe, Jẹ ki omidan na ki o ba wa joko ni ijọ́ melokan, bi ijọ́ mẹwa, lẹhin eyini ni ki o ma wa lọ. 56 On si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe da mi duro, OLUWA sa ti ṣe ọ̀na mi ni rere; ẹ rán mi, ki emi ki o le tọ̀ oluwa mi lọ. 57 Nwọn si wipe, Awa o pè omidan na, a o si bère li ẹnu rẹ̀. 58 Nwọn si pè Rebeka, nwọn bi i pe, Iwọ o bá ọkunrin yi lọ? o si wipe, Emi o lọ. 59 Nwọn si rán Rebeka, arabinrin wọn, ati olutọ rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, ati awọn ọkunrin rẹ̀ lọ. 60 Nwọn si súre fun Rebeka, nwọn si wi fun u pe, Iwọ li arabinrin wa, ki iwọ, ki o si ṣe iya ẹgbẹgbẹrun lọnà ẹgbãrun, ki irú-ọmọ rẹ ki o si ni ẹnubode awọn ti o korira wọn. 61 Rebeka si dide, ati awọn omidan rẹ̀, nwọn si gùn awọn ibakasiẹ, nwọn si tẹle ọkunrin na: iranṣẹ na si mu Rebeka, o si ba tirẹ̀ lọ. 62 Isaaki si nti ọ̀na kanga Lahai-roi mbọ̀wá; nitori ilu ìha gusù li on ngbé. 63 Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ: o si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri i, si kiyesi i, awọn ibakasiẹ mbọ̀wá. 64 Rebeka si gbé oju rẹ̀ soke, nigbati o ri Isaaki, o sọkalẹ lori ibakasiẹ. 65 Nitori ti o ti bi iranṣẹ na pe, ọkunrin ewo li o nrìn bọ̀ li oko lati wá pade wa nì? Iranṣẹ na si ti wi fun u pe, oluwa mi ni: nitori na li o ṣe mu iboju o fi bò ara rẹ̀. 66 Iranṣẹ na si rò ohun gbogbo ti on ṣe fun Isaaki. 67 Isaaki si mu u wá si inu agọ́ Sara, iya rẹ̀, o si mu Rebeka, o di aya rẹ̀; o si fẹ́ ẹ; a si tu Isaaki ninu lẹhin ikú iya rẹ̀.

Genesisi 25

Àwọn Ọmọ Mìíràn Tí Abrahamu Bí

1 ABRAHAMU si tun fẹ́ aya kan, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Ketura. 2 O si bí Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaku, ati Ṣua fun u. 3 Jokṣani si bí Ṣeba, ati Dedani. Awọn ọmọ Dedani si ni Aṣurimu, ati Letuṣimu, ati Leumimu. 4 Ati awọn ọmọ Midiani; Efa, ati Eferi, ati Hanoku, ati Abida, ati Eldaa. Gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Ketura. 5 Abrahamu si fi gbogbo ohun ti o ni fun Isaaki. 6 Ṣugbọn awọn ọmọ àle ti Abrahamu ni, Abrahamu bùn wọn li ẹ̀bun, o si rán wọn lọ kuro lọdọ Isaaki, ọmọ rẹ̀, nigbati o wà lãye, si ìha ìla-õrùn, si ilẹ ìla-õrùn.

Ikú ati Ìsìnkú Abrahamu

7 Iwọnyi si li ọjọ́ ọdún aiye Abrahamu ti o wà, arun dí lọgọsan ọdún. 8 Abrahamu si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú li ogbologbo, arugbo, o kún fun ọjọ́; a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀. 9 Awọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣmaeli si sin i ni ihò Makpela, li oko Efroni, ọmọ Sohari enia Hitti, ti o wà niwaju Mamre; 10 Oko ti Abrahamu rà lọwọ awọn ọmọ Heti: nibẹ̀ li a gbé sin Abrahamu, ati Sara, aya rẹ̀. 11 O si ṣe lẹhin ikú Abrahamu li Ọlọrun bukún fun Isaaki, ọmọ rẹ̀; Isaaki si joko leti kanga Lahai-roi.

Àwọn Ìran Iṣimaeli

12 Iwọnyi si ni iran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, ti Hagari, ara Egipti, ọmọbinrin ọdọ Sara bí fun Abrahamu: 13 Iwọnyi si li orukọ awọn ọmọkunrin Iṣmaeli, nipa orukọ wọn, ni iran idile wọn: akọ́bi Iṣmaeli, Nebajotu; ati Kedari, ati Adbeeli, ati Mibsamu, 14 Ati Miṣma, ati Duma, ati Masa; 15 Hadari, ati Tema, Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema: 16 Awọn wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli, iwọnyi si li orukọ wọn, li ori-ori ilu wọn, li ori-ori ile odi wọn; ijoye mejila li orilẹ-ède wọn. 17 Iwọnyi si li ọdún aiye Iṣmaeli, ẹtadilogoje ọdún: o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú; a si kó o jọ pọ̀ pẹlu awọn enia rẹ. 18 Nwọn si tẹ̀dó lati Hafila lọ titi o fi de Ṣuri, ti o wà niwaju Egipti, bi iwọ ti nlọ sìha Assiria: o si kú niwaju awọn arakonrin rẹ̀ gbogbo.

Ìbí Esau ati Jakọbu

19 Iwọnyi si ni iran Isaaki, ọmọ Abrahamu: Abrahamu bí Isaaki: 20 Isaaki si jẹ ẹni ogoji ọdún, nigbati o mu Rebeka, ọmọbinrin Betueli, ara Siria ti Padan-aramu, arabinrin Labani ara Siria, li aya. 21 Isaaki si bẹ̀ OLUWA fun aya rẹ̀, nitoriti o yàgan: OLUWA si gbà ẹ̀bẹ rẹ̀, Rebeka, aya rẹ̀, si loyun. 22 Awọn ọmọ si njàgudu ninu rẹ̀: o si wipe, bi o ba ṣe pe bẹ̃ni yio ri, ẽṣe ti mo fi ri bayi? O si lọ bère lọdọ OLUWA. 23 OLUWA si wi fun u pe, orilẹ-ède meji ni mbẹ ninu rẹ, irú enia meji ni yio yà lati inu rẹ: awọn enia kan yio le jù ekeji lọ; ẹgbọ́n ni yio si ma sìn aburo. 24 Nigbati ọjọ́ rẹ̀ ti yio bí si pé, si kiyesi i, ibeji li o wà ninu rẹ̀. 25 Akọ́bi si jade wá, o pupa, ara rẹ̀ gbogbo ri bí aṣọ onirun; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Esau. 26 Ati lẹhin eyini li arakunrin rẹ̀ jade wá, ọwọ́ rẹ̀ si dì gigĩsẹ Esau mu; a si sọ orukọ rẹ̀ ni Jakobu: Isaaki si jẹ ẹni ọgọta ọdún nigbati Rebeka bí wọn.

Esau Ta Ipò Àgbà Rẹ̀

27 Awọn ọmọdekunrin na si dàgba: Esau si ṣe ọlọgbọ́n ọdẹ, ara oko; Jakobu si ṣe ọbọrọ́ enia, a ma gbé inu agọ́. 28 Isaaki si fẹ́ Esau, nitori ti o njẹ ninu ẹran-ọdẹ rẹ̀: ṣugbọn Rebeka fẹ́ Jakobu. 29 Jakobu si pa ìpẹtẹ: Esau si ti inu igbẹ́ dé, o si rẹ̀ ẹ: 30 Esau si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ìpẹtẹ rẹ pupa nì bọ́ mi; nitori ti o rẹ̀ mi: nitori na li a ṣe npè orukọ rẹ̀ ni Edomu. 31 Jakobu si wipe, Tà ogún-ibí rẹ fun mi loni. 32 Esau si wipe, Sa wò o na, emi ni nkú lọ yi: ore kini ogún-ibí yi yio si ṣe fun mi? 33 Jakobu si wipe, Bura fun mi loni; o si bura fun u: o si tà ogún-ibí rẹ̀ fun Jakobu. 34 Nigbana ni Jakobu fi àkara ati ìpẹtẹ lentile fun Esau; o si jẹ, o si mu, o si dide, o si ba tirẹ̀ lọ: bayi ni Esau gàn ogún-ibí rẹ̀.

Genesisi 26

Isaaki Gbé ní Gerari

1 ÌYAN kan si mu ni ilẹ na, lẹhin ìyan ti o tetekọ mu li ọjọ́ Abrahamu. Isaaki si tọ̀ Abimeleki, ọba awọn ara Filistia lọ, si Gerari. 2 OLUWA si farahàn a, o si wipe, Máṣe sọkalẹ lọ si Egipti; joko ni ilẹ ti emi o wi fun ọ. 3 Mã ṣe atipo ni ilẹ yi, emi o si pẹlu rẹ, emi o si bukún u fun ọ; nitori iwọ ati irú-ọmọ rẹ, li emi o fi gbogbo ilẹ wọnyi fun, emi o si mu ara ti mo bú fun Abrahamu, baba rẹ, ṣẹ. 4 Emi o si mu irú-ọmọ rẹ bisi i bi irawọ oju-ọrun, emi o si fi gbogbo ilẹ wọnyi fun irú-ọmọ rẹ; ati nipasẹ irú-ọmọ rẹ li a o bukún gbogbo orilẹ-ède aiye; 5 Nitoriti Abrahamu gbà ohùn mi gbọ́, o si pa ìlọ mi, aṣẹ mi, ìlana mi, ati ofin mi mọ́. 6 Isaaki si joko ni Gerari. 7 Awọn ọkunrin ibẹ̀ na bi i lẽre niti aya rẹ̀: o si wipe, Arabinrin mi ni: nitoriti o bẹ̀ru ati wipe, Aya mi ni; o ni, ki awọn ọkunrin ibẹ̀ na ki o má ba pa mi nitori Rebeka; nitoriti on li ẹwà lati wò. 8 O si ṣe nigbati o joko nibẹ̀ pẹ titi, ni Abimeleki, ọba awọn ara Filistia, wò ode li ojuferese, o si ri, si kiyesi i, Isaaki mba Rebeka aya rẹ̀ wẹ́. 9 Abimeleki si pè Isaaki, o si wipe, Kiyesi i, nitõtọ aya rẹ ni iṣe: iwọ ha ti ṣe wipe, Arabinrin mi ni? Isaaki si wi fun u pe, Nitoriti mo wipe, ki emi ki o má ba kú nitori rẹ̀. 10 Abimeleki si wipe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? Bí ọkan ninu awọn enia bá lọ bá aya rẹ ṣe iṣekuṣe nkọ? iwọ iba si mu ẹ̀ṣẹ wá si ori wa. 11 Abimeleki si kìlọ fun gbogbo awọn enia rẹ̀ wipe, Ẹnikẹni ti o ba tọ́ ọkunrin yi tabi aya rẹ̀, kikú ni yio kú. 12 Nigbana ni Isaaki funrugbìn ni ilẹ na, o si ri ọrọrún mu li ọdún na; OLUWA si busi i fun u: 13 Ọkunrin na si di pupọ̀, o si nlọ si iwaju, o si npọ̀ si i titi o fi di enia nla gidigidi. 14 Nitori ti o ni agbo-agutan, ati ini agbo-ẹran nla ati ọ̀pọlọpọ ọmọ-ọdọ: awọn ara Filistia si ṣe ilara rẹ̀. 15 Nitori gbogbo kanga ti awọn ọmọ-ọdọ baba rẹ̀ ti wà li ọjọ́ Abrahamu, baba rẹ̀, awọn ara Filistia dí wọn, nwọn si fi erupẹ dí wọn. 16 Abimeleki si wi fun Isaaki pe, Lọ kuro lọdọ wa; nitori ti iwọ lagbara pupọ̀ ju wa lọ. 17 Isaaki si ṣí kuro nibẹ̀, o si pa agọ́ rẹ̀ ni afonifoji Gerari, o si joko nibẹ̀. 18 Isaaki si tun wà kanga omi, ti nwọn ti wà li ọjọ́ Abrahamu, baba rẹ̀; nitori ti awọn ara Filistia ti dí wọn lẹhin ikú Abrahamu: o si pè orukọ wọn gẹgẹ bi orukọ ti baba rẹ̀ sọ wọn. 19 Awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wàlẹ li afonifoji nì, nwọn si kàn kanga isun omi nibẹ̀. 20 Awọn darandaran Gerari si mba awọn darandaran Isaaki jà, wipe, Ti wa li omi na: o si sọ orukọ kanga na ni Eseki; nitori ti nwọn bá a jà. 21 Nwọn si tun wà kanga miran, nwọn si tun jà nitori eyi na pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Sitna. 22 O si ṣí kuro nibẹ̀, o si wà kanga miran: nwọn kò si jà nitori rẹ̀: o si pè orukọ rẹ̀ ni Rehoboti; o si wipe, Njẹ nigbayi li OLUWA tó fi àye fun wa, awa o si ma bisi i ni ilẹ yi. 23 O si goke lati ibẹ̀ lọ si Beer-ṣeba. 24 OLUWA si farahàn a li oru ọjọ́ na, o si wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ: máṣe bẹ̀ru, nitori ti emi wà pẹlu rẹ, emi o si busi i fun ọ, emi o si mu irú-ọmọ rẹ rẹ̀, nitori Abrahamu ọmọ-ọdọ mi. 25 O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si kepè orukọ OLUWA, o si pa agọ́ rẹ̀ nibẹ̀: awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wà kanga kan nibẹ̀.

Abimeleki ati Isaaki Dá Majẹmu

26 Nigbana li Abimeleki tọ̀ ọ lati Gerari lọ, ati Ahusati, ọkan ninu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀. 27 Isaaki si bi wọn pe, Nitori kili ẹnyin ṣe tọ̀ mi wá, ẹnyin sa korira mi, ẹnyin si ti lé mi kuro lọdọ nyin? 28 Nwọn si wipe, Awa ri i nitõtọ pe, OLUWA wà pẹlu rẹ: awa si wipe, Njẹ nisisiyi jẹ ki ibura ki o wà lãrin wa, ani lãrin tawa tirẹ, ki awa ki o si ba iwọ dá majẹmu; 29 Pe iwọ ki yio ṣe wa ni ibi, bi awa kò si ti fọwọkàn ọ, ati bi awa kò si ti ṣe ọ ni nkan bikoṣe rere, ti awa si rán ọ jade li alafia: nisisiyi ẹni-ibukún OLUWA ni iwọ. 30 O si sè àse fun wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu. 31 Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn si bura fun ara wọn: Isaaki si rán wọn pada lọ, nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀ li alafia. 32 O si ṣe li ọjọ́ kanna li awọn ọmọ-ọdọ Isaaki wá, nwọn si rò fun u niti kanga ti nwọn wà, nwọn si wi fun u pe, Awa kàn omi. 33 O sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣeba: nitorina li orukọ ilu na ṣe njẹ Beer-ṣeba titi di oni.

Àwọn Obinrin Àjèjì Tí Esau Fẹ́

34 Esau si di ẹni ogoji ọdún nigbati o mu Juditi li aya, ọmọbinrin Beeri, ara Hitti, ati Baṣemati, ọmọbinrin Eloni, ara Hitti: 35 Ohun ti o ṣe ibinujẹ fun Isaaki ati fun Rebeka.

Genesisi 27

Isaaki Súre fún Jakọbu

1 O si ṣe, ti Isaaki gbó, ti oju rẹ̀ si nṣe bàibai, tobẹ̃ ti kò le riran, o pè Esau, ọmọ rẹ̀ akọ́bi, o si wi fun u pe, Ọmọ mi: on si dá a li ohùn pe, Emi niyi. 2 O si wipe, Wò o na, emi di arugbo, emi kò si mọ̀ ọjọ́ ikú mi; 3 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ohun ọdẹ rẹ, apó rẹ, ati ọrun rẹ, ki o si jade lọ si igbẹ́ ki o si pa ẹran-igbẹ́ fun mi wá: 4 Ki o si sè ẹran adidùn fun mi, bi irú eyiti mo fẹ́, ki o si gbé e tọ̀ mi wá, ki emi ki o jẹ: ki ọkàn mi ki o súre fun ọ ki emi to kú. 5 Rebeka si gbọ́ nigbati Isaaki nwi fun Esau, ọmọ rẹ̀. Esau si lọ si igbẹ́ lọ iṣọdẹ, lati pa ẹran-igbẹ́ wá. 6 Rebeka si wi fun Jakobu ọmọ rẹ̀ pe, Wò o, mo gbọ́ baba rẹ wi fun Esau arakunrin rẹ pe, 7 Mu ẹran-igbẹ́ fun mi wá, ki o si sè ẹran adidùn fun mi, ki emi ki o jẹ, ki emi ki o sure fun ọ niwaju OLUWA ṣaju ikú mi. 8 Njẹ nisisiyi, ọmọ mi, gbọ́ ohùn mi, gẹgẹ bi emi o ti paṣẹ fun ọ. 9 Lọ nisisiyi sinu agbo-ẹran, ki o si mu ọmọ ewurẹ meji daradara fun mi lati ibẹ̀ wá: emi o si sè wọn li ẹran adidùn fun baba rẹ, bi irú eyiti o fẹ́: 10 Iwọ o si gbé e tọ̀ baba rẹ lọ, ki o le jẹ, ki o le súre fun ọ, ki on to kú. 11 Jakobu si wi fun Rebeka iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, enia onirun ni Esau arakunrin mi, alara ọbọrọ́ si li emi: 12 Bọya baba mi yio fọwọbà mi, emi o si dabi ẹlẹ̀tan fun u; emi o si mu egún wá si ori mi ki yio ṣe ibukún. 13 Iya rẹ̀ si wi fun u pe, lori mi ni ki egún rẹ wà, ọmọ mi: sá gbọ́ ohùn mi, ki o si lọ mu wọn fun mi wá. 14 O si lọ, o mu wọn, o si fà wọn tọ̀ iya rẹ̀ wá: iya rẹ̀ si sè ẹran adidùn; bi irú eyiti baba rẹ̀ fẹ́. 15 Rebeka si mu ãyo aṣọ Esau, ọmọ rẹ̀ ẹgbọ́n, ti o wà lọdọ rẹ̀ ni ile, o si fi wọn wọ̀ Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo: 16 O si fi awọ awọn ọmọ ewurẹ wọnni bò o li ọwọ́, ati si ọbọrọ́ ọrùn rẹ̀: 17 O si fi ẹran adidùn na, ati àkara ti o ti pèse, le Jakobu, ọmọ rẹ̀, lọwọ. 18 O si tọ̀ baba rẹ̀ wá, o wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi; iwọ tani nì ọmọ mi? 19 Jakobu si wi fun baba rẹ̀ pe, Emi Esau akọ́bi rẹ ni; emi ti ṣe gẹgẹ bi o ti sọ fun mi, dide joko, emi bẹ̀ ọ, ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ mi, ki ọkàn rẹ le súre fun mi. 20 Isaaki si wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Ẽti ri ti iwọ fi tete ri i bẹ̃, ọmọ mi? on si wipe, Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u tọ̀ mi wá ni. 21 Isaaki si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, sunmọ mi, ki emi ki o fọwọbà ọ, ọmọ mi, bi iwọ iṣe Esau, ọmọ mi nitotọ, bi bẹ̃kọ. 22 Jakobu si sunmọ Isaaki baba rẹ̀, o si fọwọbà a, o si wipe, Ohùn Jakobu li ohùn, ṣugbọn ọwọ́ li ọwọ́ Esau. 23 On kò si mọ̀ ọ, nitoriti ọwọ́ rẹ̀ ṣe onirun, bi ọwọ́ Esau, arakunrin rẹ̀: bẹ̃li o sure fun u. 24 O si wipe, Iwọ ni Esau ọmọ mi nitotọ? o si wipe, emi ni. 25 O si wipe, Gbé e sunmọ ọdọ mi, emi o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ mi, ki ọkàn mi ki o le sure fun ọ. O si gbé e sunmọ ọdọ rẹ̀, o si jẹ: o si gbé ọti-waini fun u, on si mu. 26 Isaaki baba rẹ̀ si wi fun u pe, Sunmọ ihín nisisiyi ọmọ mi, ki o si fi ẹnu kò mi li ẹnu. 27 O si sunmọ ọ, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: o si gbọ́ õrùn aṣọ rẹ̀, o si sure fun u, o si wipe, Wò o, õrùn ọmọ mi o dabi õrùn oko eyiti OLUWA ti busi. 28 Ọlọrun yio si fun ọ ninu ìri ọrun, ati ninu ọrá ilẹ, ati ọ̀pọlọpọ ọkà ati ọti-waini: 29 Ki enia ki o mã sìn ọ, ki orilẹ-ède ki o mã tẹriba fun ọ: mã ṣe oluwa awọn arakunrin rẹ, ki awọn ọmọ iya rẹ ki o tẹriba fun ọ: ifibú li awọn ẹniti o fi ọ bú, ibukún si ni fun awọn ẹniti o sure fun ọ. 30 O si ṣe, bi Isaaki ti pari ire isú fun Jakobu, ti Jakobu si fẹrẹ má jade tan kuro niwaju Isaaki baba rẹ̀, ni Esau, arakunrin rẹ̀ wọle de lati igbẹ́ ọdẹ rẹ̀ wá. 31 On pẹlu si ti sè ẹran adidùn, o si mu u tọ̀ baba rẹ̀ wá, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Ki baba mi ki o dide ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ rẹ̀, ki ọkàn rẹ le sure fun mi. 32 Isaaki baba rẹ̀ si bi i pe, Iwọ tani nì? on si wipe, Emi Esau, ọmọ rẹ akọbi ni. 33 Isaaki si warìri gidigidi rekọja, o si wipe, Tani nla? tali ẹniti o ti pa ẹran-igbẹ́, ti o si gbé e tọ̀ mi wá, emi si ti jẹ ninu gbogbo rẹ̀, ki iwọ ki o to de, emi si ti sure fun u? nitõtọ a o si bukún fun u. 34 Nigbati Esau gbọ́ ọ̀rọ baba rẹ̀, o fi igbe nlanla ta, o si sun ẹkun kikorò gidigidi, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Sure fun mi, ani fun emi pẹlu, baba mi. 35 O si wipe, Arakunrin rẹ fi erú wá, o si ti gbà ibukún rẹ lọ. 36 O si wipe, A kò ha pè orukọ rẹ̀ ni Jakobu ndan? nitori o jì mi li ẹsẹ̀ ni ìgba meji yi: o gbà ogún-ibi lọwọ mi; si kiyesi i, nisisiyi o si gbà ire mi lọ. O si wipe, Iwọ kò ha pa ire kan mọ́ fun mi? 37 Isaaki si dahùn o si wi fun Esau pe, Wõ, emi ti fi on ṣe oluwa rẹ, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li emi ti fi ṣe iranṣẹ rẹ̀; ati ọkà ati ọti-waini ni mo fi gbè e: ewo li emi o ha ṣe fun ọ nisisiyi, ọmọ mi? 38 Esau si wi fun baba rẹ̀ pe, Ire kanṣoṣo li o ni iwọ baba mi? sure fun mi, ani fun mi pẹlu, baba mi? Esau si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun. 39 Isaaki baba rẹ̀ si dahùn o si wi fun u pe, Wõ, ibujoko rẹ yio jẹ ọrá ilẹ, ati ibi ìri ọrun lati oke wá; 40 Nipa idà rẹ ni iwọ o ma gbé, iwọ o si ma sìn arakunrin rẹ; yio si ṣe nigbati iwọ ba di alagbara tan, iwọ o já àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ. 41 Esau si korira Jakobu nitori ire ti baba rẹ̀ su fun u: Esau si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọjọ́ ọ̀fọ baba mi sunmọ-etile; nigbana li emi o pa Jakobu, arakunrin mi. 42 A si sọ ọ̀rọ Esau akọ́bi rẹ̀ wọnyi fun Rebeka: on si ranṣẹ o si pè Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo, o si wi fun u pe, Kiyesi i, Esau, arakunrin rẹ, ntù ara rẹ ninu niti rẹ lati pa ọ. 43 Njẹ nisisiyi ọmọ mi, gbọ́ ohùn mi; si dide, sá tọ̀ Labani arakunrin mi lọ si Harani; 44 Ki o si bá a joko ni ijọ́ melo kan, titi ibinu arakunrin rẹ yio fi tuka; 45 Titi inu arakunrin rẹ yio fi tutu si ọ, ti yio si fi gbagbe ohun ti o fi ṣe e: nigbana li emi o ranṣẹ mu ọ lati ibẹ̀ wá: ẽṣe ti emi o fi fẹ́ ẹnyin mejeji kù ni ijọ́ kanṣoṣo?

Isaaki Rán Jakọbu Lọ sọ́dọ̀ Labani

46 Rebeka si wi fun Isaaki pe, Agara aiye mi ma dá mi nitori awọn ọmọbinrin Heti, bi Jakobu ba fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Heti, bi irú awọn wọnyi yi iṣe ninu awọn ọmọbinrin ilẹ yi, aiye mi o ha ti ri?

Genesisi 28

1 ISAAKI si pè Jakobu, o si sùre fun u, o si kìlọ fun u, o si wi fun u pe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani. 2 Dide, lọ si Padan-aramu, si ile Betueli, baba iya rẹ; ki iwọ ki o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ wá ninu awọn ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ. 3 Ki Ọlọrun Olodumare ki o gbè ọ, ki o si mu ọ bisi i, ki o si mu ọ rẹ̀ si i, ki iwọ ki o le di ọ̀pọlọpọ enia. 4 Ki o si fi ibukún Abrahamu fun ọ, fun iwọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ; ki iwọ ki o le ni ilẹ na ninu eyiti iwọ nṣe atipo, ti Ọlọrun fi fun Abrahamu. 5 Isaaki si rán Jakobu lọ: o si lọ si Padan-aramu si ọdọ Labani, ọmọ Betueli, ara Siria, arakunrin Rebeka, iya Jakobu on Esau.

Esau Fẹ́ Aya Mìíràn

6 Nigbati Esau ri pe Isaaki sure fun Jakobu ti o si rán a lọ si Padan-aramu, lati fẹ́ aya lati ibẹ̀; ati pe bi o ti sure fun u, o si kìlọ fun u wipe, iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; 7 Ati pe Jakobu gbọ́ ti baba ati ti iya rẹ̀, ti o si lọ si Padan-aramu: 8 Nigbati Esau ri pe awọn ọmọbinrin Kenaani kò wù Isaaki baba rẹ̀; 9 Nigbana ni Esau tọ̀ Iṣmaeli lọ, o si fẹ́ Mahalati ọmọbinrin Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, arabinrin Nebajotu, kún awọn obinrin ti o ni.

Àlá Jakọbu ní Bẹtẹli

10 Jakobu si jade kuro lati Beer-ṣeba lọ, o si lọ si ìha Harani. 11 O si de ibi kan, o duro nibẹ̀ li oru na, nitori õrùn wọ̀; o si mu ninu okuta ibẹ̀ na, o fi ṣe irọri rẹ̀, o si sùn nibẹ̀ na. 12 O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀. 13 Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ. 14 Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye. 15 Si kiyesi i, emi wà pẹlu rẹ, emi o sì pa ọ mọ́ ni ibi gbogbo ti iwọ nlọ, emi o si tun mu ọ bọ̀wá si ilẹ yi; nitori emi ki yio kọ̀ ọ silẹ, titi emi o fi ṣe eyiti mo wi fun ọ tan. 16 Jakobu si jí li oju-orun rẹ̀, o si wipe, OLUWA mbẹ nihinyi nitõtọ; emi kò si mọ̀. 17 Ẹrù si bà a, o si wipe, Ihinyi ti li ẹ̀ru tó! eyi ki iṣe ibi omiran, bikoṣe ile Ọlọrun, eyi si li ẹnubode ọrun. 18 Jakobu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si mu okuta ti o fi ṣe irọri rẹ̀, o si fi lelẹ fun ọwọ̀n, o si ta oróro si ori rẹ̀. 19 O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Beteli: ṣugbọn Lusi li orukọ ilu na ri. 20 Jakobu si jẹ́ ẹjẹ́ wipe, Bi Ọlọrun ba pẹlu mi, ti o si pa mi mọ́ li ọ̀na yi ti emi ntọ̀, ti o si fun mi li ohun jijẹ, ati aṣọ bibora, 21 Ti mo si pada wá si ile baba mi li alafia; njẹ OLUWA ni yio ma ṣe Ọlọrun mi. 22 Okuta yi, ti mo fi lelẹ ṣe ọwọ̀n ni yio si ṣe ile Ọlọrun: ati ninu ohun gbogbo ti iwọ o fi fun mi, emi o si fi idamẹwa rẹ̀ fun ọ.

Genesisi 29

Jakọbu Dé sí Ilé Labani

1 JAKOBU si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n, o si wá si ilẹ awọn ara ìla-õrùn. 2 O si wò, si kiyesi i, kanga kan ninu oko, si kiyesi i, agbo-agutan mẹta dubulẹ tì i; nitori pe, lati inu kanga na wá ni nwọn ti nfi omi fun awọn agbo-agutan: okuta nla si wà li ẹnu kanga na. 3 Nibẹ̀ ni gbogbo awọn agbo-ẹran kojọ pọ̀ si: nwọn si fun awọn agutan li omi, nwọn si tun yí okuta dí ẹnu kanga si ipò rẹ̀. 4 Jakobu si bi wọn pe, Ẹnyin arakunrin mi, nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, lati Harani li a ti wá. 5 O si bi wọn pe, ẹnyin mọ̀ Labani, ọmọ Nahori? Nwọn si wipe, Awa mọ̀ ọ. 6 O si bi wọn pe, Alafia ki o wà bi? nwọn si wipe Alafia ni; si kiyesi i, Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀ mbọ̀wá pẹlu ọwọ́-ẹran. 7 O si wipe, Kiyesi i, ọjọ́ mbẹ sibẹ̀, bẹ̃ni kò tó akokò ti awọn ẹran yio wọjọ pọ̀: ẹ fun awọn agutan li omi, ki ẹ si lọ ibọ́ wọn. 8 Nwọn si wipe, Awa kò le ṣe e, titi gbogbo awọn agbo-ẹran yio fi wọjọ pọ̀, ti nwọn o si fi yí okuta kuro li ẹnu kanga; nigbana li a le fun awọn agutan li omi. 9 Nigbati o si mba wọn sọ̀rọ lọwọ, Rakeli de pẹlu awọn agutan baba rẹ̀: on li o sa nṣọ́ wọn. 10 O si ṣe, nigbati Jakobu ri Rakeli, ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ̀, ati agutan Labani, arakunrin iya rẹ̀, ni Jakobu si sunmọ ibẹ̀, o si yí okuta kuro li ẹnu kanga, o si fi omi fun gbogbo agbo-ẹran Labani, arakunrin iya rẹ̀. 11 Jakobu si fi ẹnu kò Rakeli li ẹnu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun. 12 Jakobu si wi fun Rakeli pe arakunrin baba rẹ̀ li on, ati pe, ọmọ Rebeka li on: ọmọbinrin na si sure o si sọ fun baba rẹ̀. 13 O si ṣe ti Labani gburó Jakobu, ọmọ arabinrin rẹ̀, o sure lọ ipade rẹ̀, o si gbá a mú, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si mu u wá si ile rẹ̀. On si ròhin gbogbo nkan wọnni fun Labani. 14 Labani si wi fun u pe, egungun on ẹran-ara mi ni iwọ iṣe nitõtọ. O si bá a joko ni ìwọn oṣù kan.

Jakọbu Sin Labani nítorí Rakẹli ati Lea

15 Labani si wi fun Jakobu pe, Iwọ o ha ma sìn mi li asan bi, nitoriti iwọ iṣe arakunrin mi? elo li owo iṣẹ rẹ, wi fun mi? 16 Labani si ni ọmọbinrin meji: orukọ ẹgbọ́n a ma jẹ Lea, orukọ aburo a si ma jẹ Rakeli. 17 Oju Lea kò li ẹwà, ṣugbọn Rakeli ṣe arẹwà, o si wù ni. 18 Jakobu si fẹ́ Rakeli; o si wipe, Emi o sìn ọ li ọdún meje nitori Rakeli, ọmọbinrin rẹ abikẹhin. 19 Labani si wipe, O san lati fi i fun ọ, jù ki nfi i fun ẹlomiran lọ: ba mi joko. 20 Jakobu si sìn i li ọdún meje fun Rakeli; nwọn sì dabi ijọ́ melokan li oju rẹ̀ nitori ifẹ́ ti o fẹ́ ẹ. 21 Jakobu si wi fun Labani pe, Fi aya mi fun mi, nitoriti ọjọ́ mi pé, ki emi ki o le wọle tọ̀ ọ. 22 Labani si pè gbogbo awọn enia ibẹ̀ jọ, o si se àse. 23 O si ṣe li alẹ, o mú Lea ọmọbinrin rẹ̀, o sìn i tọ̀ ọ wá; on si wọle tọ̀ ọ lọ. 24 Labani si fi Silpa, ọmọ-ọdọ rẹ̀, fun Lea, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀. 25 O si ṣe, li owurọ, wò o, o jẹ́ Lea: o si wi fun Labani pe, Ẽwo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? nitori Rakeli ki mo ṣe sìn ọ, njẹ ẽhatiṣe ti o fi ṣe erú si mi? 26 Labani si wi fun u pe, A kò gbọdọ ṣe bẹ̃ ni ilẹ wa, lati sìn aburo ṣaju ẹgbọ́n. 27 Ṣe ọ̀sẹ ti eleyi pé, awa o si fi eyi fun ọ pẹlu, nitori ìsin ti iwọ o sìn mi li ọdún meje miran si i. 28 Jakobu si ṣe bẹ̃, o si ṣe ọ̀sẹ rẹ̀ pé: o si fi Rakeli ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya pẹlu. 29 Labani si fi Bilha, ọmọbinrin ọdọ rẹ̀, fun Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀. 30 O si wọle tọ̀ Rakeli pẹlu, o si fẹ́ Rakeli jù Lea lọ, o si sìn i li ọdún meje miran si i.

Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Bí fún Jakọbu

31 Nigbati OLUWA si ri i pe a korira Lea, o ṣi i ni inu: ṣugbọn Rakeli yàgan. 32 Lea si loyun, o si bí ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Reubeni: nitori ti o wipe, OLUWA wò ìya mi nitõtọ: njẹ nitorina, ọkọ mi yio fẹ́ mi. 33 O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Nitori ti OLUWA ti gbọ́ pe a korira mi, nitorina li o ṣe fun mi li ọmọ yi pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Simeoni. 34 O si tun loyun, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Njẹ nigbayi li ọkọ mi yio faramọ́ mi, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹta fun u: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Lefi. 35 O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan: o si wipe, Nigbayi li emi o yìn OLUWA: nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Judah; o si dẹkun bíbi.

Genesisi 30

1 NIGBATI Rakeli ri pe on kò bimọ fun Jakobu, Rakeli ṣe ilara arabinrin rẹ̀; o si wi fun Jakobu pe, Fun mi li ọmọ, bikoṣe bẹ̃ emi o kú. 2 Jakobu si binu si Rakeli: o si wipe, Emi ha wà ni ipò Ọlọrun, ẹniti o dù ọ li ọmọ bíbi? 3 On si wipe, Wò Bilha iranṣẹbinrin mi, wọle tọ̀ ọ; on ni yio si bí lori ẽkun mi, ki a le gbé mi ró pẹlu nipasẹ rẹ̀. 4 O si fi Bilha, iranṣẹbinrin rẹ̀, fun u li aya: Jakobu si wọle tọ̀ ọ. 5 Bilha si yún, o si bí ọmọkunrin kan fun Jakobu. 6 Rakeli si wipe, Ọlọrun ti ṣe idajọ mi, o si ti gbọ́ ohùn mi, o si fi ọmọkunrin kan fun mi pẹlu: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Dani. 7 Bilha, iranṣẹbinrin Rakeli, si tun yún, o si bi ọmọkunrin keji fun Jakobu. 8 Rakeli si wipe, Ijakadi nla ni mo fi bá arabinrin mi ja, emi si dá a: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Naftali. 9 Nigbati Lea ri pe on dẹkun ọmọ bíbi, o si mú Silpa, iranṣẹbinrin rẹ̀, o si fi i fun Jakobu li aya. 10 Silpa, iranṣẹbinrin Lea, si bí ọmọkunrin kan fun Jakobu. 11 Lea si wipe, Ire de: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gadi. 12 Silpa iranṣẹbinrin Lea si bí ọmọkunrin keji fun Jakobu. 13 Lea si wipe, Alabukún fun li emi, nitori ti awọn ọmọbinrin yio ma pè mi li alabukún fun: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Aṣeri. 14 Li akokò ìgba ikore alikama, Reubeni si lọ, o si ri eso mandraki ni igbẹ́, o si mú wọn fun Lea iya rẹ̀ wá ile. Nigbana ni Rakeli wi fun Lea pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi ninu mandraki ọmọ rẹ. 15 O si wi fun u pe, Iṣe nkan kekere ti iwọ gbà ọkọ lọwọ mi? iwọ si nfẹ́ gbà mandraki ọmọ mi pẹlu? Rakeli si wipe, Nitori na ni yio ṣe sùn tì ọ li alẹ yi nitori mandraki ọmọ rẹ. 16 Jakobu si ti inu oko dé li aṣalẹ, Lea si jade lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Iwọ kò le ṣe aima wọle tọ̀ mi wá, nitori ti emi ti fi mandraki ọmọ mi bẹ̀ ọ li ọ̀wẹ. On si sùn tì i li oru na. 17 Ọlọrun si gbọ́ ti Lea, o si yún, o si bí ọmọkunrin karun fun Jakobu. 18 Lea si wipe, Ọlọrun san ọ̀ya mi fun mi, nitori ti mo fi iranṣẹbinrin mi fun ọkọ mi; o si pè orukọ rẹ̀ ni Issakari. 19 Lea si tun yún, o si bí ọmọkunrin kẹfa fun Jakobu. 20 Lea si wipe, Ọlọrun ti fun mi li ẹ̀bun rere; nigbayi li ọkọ mi yio tó ma bá mi gbé, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹfa fun u: o si pè orukọ rẹ̀ ni Sebuluni. 21 Nikẹhin rẹ̀ li o si bí ọmọbinrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Dina. 22 Ọlọrun si ranti Rakeli, Ọlọrun si gbọ́ tirẹ̀, o si ṣí i ni inu. 23 O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Ọlọrun mú ẹ̀gan mi kuro: 24 O si pè orukọ rẹ̀ ni Josefu; o si wipe, Ki OLUWA ki o fi ọmọkunrin kan kún u fun mi pẹlu.

Jakọbu Dúnàá Dúrà pẹlu Labani

25 O si ṣe, nigbati Rakeli bí Josefu tán, Jakobu si wi fun Labani pe, Rán mi jade lọ, ki emi ki o le ma lọ si ibiti mo ti wá, ati si ilẹ mi. 26 Fun mi li awọn obinrin mi, ati awọn ọmọ mi, nitori awọn ẹniti mo ti nsìn ọ, ki o si jẹ ki nma lọ: iwọ sá mọ̀ ìsin ti mo sìn ọ. 27 Labani si wipe, Duro, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, joko: nitori ti mo ri i pe, OLUWA ti bukún fun mi nitori rẹ. 28 O si wi fun u pe, Sọ iye owo iṣẹ rẹ, emi o si fi fun ọ. 29 O si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ bi emi ti sìn ọ, ati bi ẹran-ọ̀sin rẹ ti wà lọdọ mi. 30 Diẹ ni iwọ sá ti ní ki nto dé ọdọ rẹ, OLUWA si busi i li ọ̀pọlọpọ fun ọ lati ìgba ti mo ti dé: njẹ nisisiyi nigbawo li emi o pèse fun ile mi? 31 O si bi i pe, Kili emi o fi fun ọ? Jakobu si wi pe, Iwọ máṣe fun mi li ohun kan: bi iwọ o ba le ṣe eyi fun mi, emi o ma bọ́, emi o si ma ṣọ́ agbo-ẹran rẹ. 32 Emi o là gbogbo agbo-ẹran rẹ já loni, emi o mú gbogbo ẹran abilà ati alamì kuro nibẹ̀, ati gbogbo ẹran pupa rúsurusu kuro ninu awọn agutan, ati gbogbo ẹran alamì ati abilà ninu awọn ewurẹ: eyi ni yio si ma ṣe ọ̀ya mi. 33 Ododo mi yio si jẹ mi li ẹrí li ẹhin-ọla nigbati iwọ o wá wò ọ̀ya mi: gbogbo eyiti kò ba ṣe abilà ati alami ninu awọn ewurẹ, ti kò si ṣe pupa rúsurusu ninu awọn agutan, on na ni ki a kà si mi li ọrùn bi olè. 34 Labani si wipe, Wò o, jẹ ki o ri bi ọ̀rọ rẹ. 35 Li ọjọ́ na li o si yà awọn obukọ oni-tototó ati alamì, ati gbogbo awọn ewurẹ ti o ṣe abilà ati alamì, ati gbogbo awọn ti o ní funfun diẹ lara, ati gbogbo oni-pupa rúsurusu ninu awọn agutan, o si fi wọn lé awọn ọmọ rẹ̀ lọwọ. 36 O si fi ìrin ọjọ́ mẹta si agbedemeji on tikalarẹ̀ ati Jakobu: Jakobu si mbọ́ agbo-ẹran Labani iyokù. 37 Jakobu si mú ọpá igi-poplari tutù, ati igi haseli, ati kesnuti; o si bó wọn li abófin, o si mu ki funfun ti o wà lara awọn ọpá na hàn. 38 O si fi ọpá ti o bó lelẹ niwaju awọn agbo-ẹran li oju àgbará, ni ibi ọkọ̀ imumi, nigbati awọn agbo-ẹran wá mu omi, ki nwọn ki o le yún nigbati nwọn ba wá mumi. 39 Awọn agbo-ẹran si yún niwaju ọpá wọnni, nwọn si bí ẹran oni-tototó, ati abilà, ati alamì. 40 Jakobu si yà awọn ọdọ-agutan, o si kọju awọn agbo-ẹran si oni-tototó, ati gbogbo onìpupa rúsurusu ninu agbo-ẹran Labani: o si fi awọn agbo-ẹran si ọ̀tọ fun ara rẹ̀, kò si fi wọn sinu ẹran Labani. 41 O si ṣe, nigbati ẹran ti o lera jù ba yún, Jakobu a si fi ọpá na lelẹ niwaju awọn ẹran na li oju àgbará, ki nwọn o le ma yún lãrin ọpá wọnni. 42 Ṣugbọn nigbati awọn ẹran ba ṣe alailera, on ki ifi si i; bẹ̃li ailera ṣe ti Labani, awọn ti o lera jẹ́ ti Jakobu. 43 ọkunrin na si pọ̀ gidigidi, o si li ẹran-ọ̀sin pupọ̀, ati iranṣẹbinrin, ati iranṣẹkunrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ.

Genesisi 31

Jakọbu Sá kúrò lọ́dọ̀ Labani

1 O SI gbọ́ ọ̀rọ awọn ọmọ Labani ti nwọn wipe, Jakobu kó nkan gbogbo ti iṣe ti baba wa; ati ninu ohun ti iṣe ti baba wa li o ti ní gbogbo ọrọ̀ yi. 2 Jakobu si wò oju Labani, si kiyesi i, kò ri si i bi ìgba atijọ. 3 OLUWA si wi fun Jakobu pe, Pada lọ si ilẹ awọn baba rẹ, ati si ọdọ awọn ara rẹ; emi o si pẹlu rẹ. 4 Jakobu si ranṣẹ o si pè Rakeli on Lea si pápa si ibi agbo-ẹran rẹ̀, 5 O si wi fun wọn pe, Emi wò oju baba nyin pe, kò ri si mi bi ìgba atijọ; ṣugbọn Ọlọrun baba mi ti wà pẹlu mi. 6 Ẹnyin si mọ̀ pe gbogbo agbara mi li emi fi sìn baba nyin. 7 Baba nyin si ti tàn mi jẹ, o si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa: ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ ki o pa mi lara. 8 Bi o ba si wi bayi pe, Awọn abilà ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí abilà: bi o ba si wi bayi, Awọn oni-tototó ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí oni-tototó. 9 Bẹ̃li Ọlọrun si gbà ẹran baba nyin, o si fi wọn fun mi. 10 O si ṣe li akokò ti awọn ẹran yún, mo si gbé oju mi soke, mo si ri li oju-alá, si kiyesi i, awọn obukọ ti o ngùn awọn ẹran jẹ́ oni-tototó, abilà, ati alamì. 11 Angeli Ọlọrun si sọ fun mi li oju-alá pe, Jakobu: emi si wipe, Emi niyi. 12 O si wipe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò, gbogbo awọn obukọ ti ngùn awọn ẹran li o ṣe tototó, abilà, ati alamì: nitori ti emi ti ri ohun gbogbo ti Labani nṣe si ọ. 13 Emi li Ọlọrun Beteli, nibiti iwọ gbé ta oróro si ọwọ̀n, nibiti iwọ gbè jẹ́ ẹjẹ́ fun mi: dide nisisiyi, jade kuro ni ilẹ yi, ki o si pada lọ si ilẹ ti a bi ọ. 14 Rakeli ati Lea si dahùn nwọn si wi fun u pe, Ipín, tabi ogún kan ha tun kù fun wa mọ́ ni ile baba wa? 15 Alejò ki on nkà wa si? nitori ti o ti tà wa; o si ti mù owo wa jẹ gúdu-gudu. 16 Nitori ọrọ̀ gbogbo ti Ọlọrun ti gbà lọwọ baba wa, eyinì ni ti wa, ati ti awọn ọmọ wa: njẹ nisisiyi ohunkohun ti Ọlọrun ba sọ fun ọ, on ni ki o ṣe. 17 Nigbana ni Jakobu dide, o si gbé awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn aya rẹ̀ gùn ibakasiẹ. 18 O si kó gbogbo ẹran rẹ̀ lọ, ati gbogbo ẹrù ti o ní, ẹran ti o ní fun ara rẹ̀, ti o ní ni Padan-aramu, lati ma tọ̀ Isaaki baba rẹ̀ lọ ni ilẹ Kenaani. 19 Labani si lọ irẹrun agutan rẹ̀: Rakeli si ti jí awọn ere baba rẹ̀ lọ. 20 Jakobu si tàn Labani ara Siria jẹ, niti pe kò wi fun u ti o fi salọ. 21 Bẹ̃li o kó ohun gbogbo ti o ní salọ: o si dide, o si kọja odò, o si kọju rẹ̀ si oke Gileadi.

Labani Lépa Jakọbu

22 A si wi fun Labani ni ijọ́ kẹta pe, Jakobu salọ. 23 O si mú awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si lepa rẹ̀ ni ìrin ijọ́ meje: o si bá a li oke Gileadi. 24 Ọlọrun si tọ̀ Labani, ara Siria wá li oru li oju-alá, o si wi fun u pe, Kiyesi ara rẹ, ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu. 25 Nigbana ni Labani bá Jakobu. Jakobu ti pa agọ́ rẹ̀ li oke na: ati Labani pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ dó li oke Gileadi. 26 Labani si wi fun Jakobu pe, Kini iwọ ṣe nì, ti iwọ tàn mi jẹ ti iwọ si kó awọn ọmọbinrin mi lọ bi ìgbẹsin ti a fi idà mú? 27 Ẽṣe ti iwọ fi salọ li aṣíri, ti iwọ si tàn mi jẹ; ti iwọ kò si wi fun mi ki emi ki o le fi ayọ̀ ati orin, ati ìlu, ati dùru, sìn ọ; 28 Ti iwọ kò si jẹ ki emi fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin mi li ẹnu? iwọ ṣiwere li eyiti iwọ ṣe yi. 29 O wà ni ipa mi lati ṣe nyin ni ibi: ṣugbọn Ọlọrun baba nyin ti sọ fun mi li oru aná pe, Kiyesi ara rẹ ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu. 30 Ati nisisiyi, iwọ kò le ṣe ailọ, nitori ti ọkàn rẹ fà gidigidi si ile baba rẹ, ṣugbọn ẽhaṣe ti iwọ fi jí awọn oriṣa mi lọ? 31 Jakobu si dahùn o si wi fun Labani pe, Nitori ti mo bẹ̀ru ni: nitori ti mo wipe, iwọ le fi agbara gbà awọn ọmọbinrin rẹ lọwọ mi. 32 Lọwọ ẹnikẹni ti iwọ ba ri awọn oriṣa rẹ ki o máṣe wà lãye: li oju awọn arakunrin wa wọnyi, wá ohun ti iṣe tirẹ lọdọ mi, ki o si mú u si ọdọ rẹ. Jakobu kò sa mọ̀ pe Rakeli ti jí wọn. 33 Labani si wọ̀ inu agọ́ Jakobu lọ, ati inu agọ́ Lea, ati inu agọ́ awọn iranṣẹbinrin mejeji; ṣugbọn kò ri wọn. Nigbana li o jade kuro ninu agọ́ Lea, o si wọ̀ inu agọ́ Rakeli lọ. 34 Rakeli si gbé awọn ere na, o si fi wọn sinu gãri ibakasiẹ, o si joko le wọn. Labani si wá gbogbo agọ́ ṣugbọn kò ri wọn. 35 O si wi fun baba rẹ̀ pe, Oluwa mi, máṣe jẹ ki o bi ọ ninu nitori ti emi kò le dide niwaju rẹ; nitori ti iṣe obinrin mbẹ lara mi. O si wá agọ́ kiri, ṣugbọn kò ri awọn ere na. 36 Inu si bi Jakobu, o si bá Labani sọ̀: Jakobu si dahùn o wi fun Labani pe, Kini irekọja mi? kili ẹ̀ṣẹ mi ti iwọ fi lepa mi wìriwiri bẹ̃? 37 Njẹ bi iwọ ti tú ẹrù mi gbogbo, kili iwọ ri ninu gbogbo nkan ile rẹ? gbé e kalẹ nihinyi niwaju awọn arakunrin rẹ, ki nwọn ki o le ṣe idajọ rẹ̀ fun awa mejeji. 38 Ogún ọdún yi ni mo ti wà lọdọ rẹ; agutan rẹ ati ewurẹ rẹ kò sọnù, agbo ọwọ́-ẹran rẹ li emi kò si pajẹ. 39 Eyiti ẹranko fàya emi kò mú u fun ọ wá; emi li o gbà òfo rẹ̀; li ọwọ́ mi ni iwọ bère rẹ̀, a ba jí i li ọsán, a ba jí i li oru. 40 Bayi ni mo wà; ongbẹ ngbẹ mi li ọsán, otutù si nmu mi li oru: orun mi si dá kuro li oju mi. 41 Bayi li o ri fun mi li ogún ọdún ni ile rẹ; mo sìn ọ li ọdún mẹrinla nitori awọn ọmọbinrin rẹ mejeji, ati li ọdún mẹfa nitori ohun-ọ̀sin rẹ: iwọ si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa. 42 Bikoṣe bi Ọlọrun baba mi, Ọlọrun Abrahamu, ati ẹ̀ru Isaaki ti wà pẹlu mi, nitõtọ ofo ni iwọ iba rán mi jade lọ. Ọlọrun ri ipọnju mi, ati lãla ọwọ́ mi, o si ba ọ wi li oru aná.

Labani ati Jakọbu Dá Majẹmu

43 Labani si dahùn o si wi fun Jakobu pe, Awọn ọmọbinrin wọnyi, awọn ọmọbinrin mi ni, ati awọn ọmọ wọnyi, awọn ọmọ mi ni, ati awọn ọwọ́-ẹran wọnyi ọwọ́-ẹran mi ni, ati ohun gbogbo ti o ri ti emi ni: kili emi iba si ṣe si awọn ọmọbinrin mi wọnyi loni, tabi si awọn ọmọ wọn ti nwọn bí? 44 Njẹ nisisiyi, wá, jẹ ki a bá ara wa dá majẹmu, temi tirẹ; ki o si ṣe ẹrí lãrin temi tirẹ. 45 Jakobu si mú okuta kan, o si gbé e ró ṣe ọwọ̀n. 46 Jakobu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ ma kó okuta jọ; nwọn si kó okuta jọ, nwọn si ṣe òkiti: nwọn si jẹun nibẹ̀ lori òkiti na. 47 Labani si sọ orukọ rẹ̀ ni Jegari-Sahaduta: ṣugbọn Jakobu sọ ọ ni Galeedi. 48 Labani si wipe, Òkiti yi li ẹri lãrin temi tirẹ loni. Nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Galeedi: 49 Ati Mispa; nitori ti o wipe, Ki OLUWA ki o ma ṣọ́ temi tirẹ nigbati a o yà kuro lọdọ ara wa. 50 Bi iwọ ba pọ́n awọn ọmọbinrin mi li oju, tabi bi iwọ ba fẹ́ aya miran pẹlu awọn ọmọbinrin mi, kò sí ẹnikan pẹlu wa; wò o, Ọlọrun li ẹlẹri lãrin temi tirẹ. 51 Labani si wi fun Jakobu pe, Wò òkiti yi, si wò ọwọ̀n yi, ti mo gbé ró lãrin temi tirẹ. 52 Òkiti yi li ẹri, ọwọ̀n yi li ẹri, pe emi ki yio rekọja òkiti yi sọdọ rẹ; ati pe iwọ ki yio si rekọja òkiti yi ati ọwọ̀n yi sọdọ mi fun ibi. 53 Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Nahori, Ọlọrun baba wọn, ni ki o ṣe idajọ lãrin wa. Jakobu si fi ẹ̀ru Isaaki baba rẹ̀ bura. 54 Nigbana ni Jakobu rubọ lori oke na, o si pè awọn arakunrin rẹ̀ wá ijẹun: nwọn si jẹun, nwọn si fi gbogbo oru ijọ́ na sùn lori oke na. 55 Ni kutukutu owurọ̀ Labani si dide, o si fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ li ẹnu, o si sure fun wọn: Labani si dide, o si pada lọ si ipò rẹ̀.

Genesisi 32

Jakọbu Múra láti Pàdé Esau

1 JAKOBU si nlọ li ọ̀na rẹ̀, awọn angeli Ọlọrun si pade rẹ̀. 2 Nigbati Jakobu si ri wọn, o ni, Ogun Ọlọrun li eyi: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Mahanaimu. 3 Jakobu si ranṣẹ siwaju rẹ̀ si Esau, arakunrin rẹ̀, si ilẹ Seiri, pápa oko Edomu. 4 O si rán wọn wipe, Bayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau, oluwa mi; Bayi ni Jakobu iranṣẹ rẹ wi, Mo ti ṣe atipo lọdọ Labani, mo si ti ngbé ibẹ̀ titi o fi di isisiyi: 5 Mo si ní malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agbo-ẹran, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin: mo si ranṣẹ wá wi fun oluwa mi, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ. 6 Awọn onṣẹ si pada tọ̀ Jakobu wá, wipe, Awa dé ọdọ Esau, arakunrin rẹ, o si mbọ̀wá kò ọ, irinwo ọkunrin li o si wà pẹlu rẹ̀. 7 Nigbana li ẹ̀ru bà Jakobu gidigidi, ãjo si mú u, o si pín awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, ati awọn ọwọ́-ẹran, awọn ọwọ́-malu, ati awọn ibakasiẹ, si ipa meji; 8 O si wipe, bi Esau ba kàn ẹgbẹ kan, ti o si kọlù u, njẹ ẹgbẹ keji ti o kù yio là. 9 Jakobu si wipe, Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, OLUWA ti o wi fun mi pe, pada lọ si ilẹ rẹ, ati sọdọ awọn ara rẹ, emi o si ṣe ọ ni rere: 10 Emi kò yẹ si kikini ninu gbogbo ãnu, ati ninu gbogbo otitọ, ti iwọ fihàn fun ọmọ-ọdọ rẹ, nitori pe, kìki ọpá mi ni mo fi kọja Jordani yi; nisisiyi emi si di ẹgbẹ meji. 11 Emi bẹ̀ ọ, gbà mi lọwọ arakunrin mi, lọwọ Esau: nitori ti mo bẹ̀ru rẹ̀, ki o má ba wá lati kọlù mi, ti iya ti ọmọ. 12 Iwọ si wipe, Nitõtọ emi o ṣe ọ ni rere, emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi iyanrin okun, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ. 13 O si sùn nibẹ̀ li alẹ ijọ́ na; o si mú ninu ohun ti o tẹ̀ ẹ li ọwọ li ọrẹ fun Esau, arakunrin rẹ̀; 14 Igba ewurẹ, on ogún obukọ, igba agutan, on ogún àgbo, 15 Ọgbọ̀n ibakasiẹ ti o ní wàra, pẹlu awọn ọmọ wọn, ogojì abo-malu on akọ-malu mẹwa, ogún abo-kẹtẹkẹtẹ, on ọmọ-kẹtẹkẹtẹ mẹwa. 16 O si fi wọn lé ọwọ́ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ni ọ̀wọ́ kọkan; o si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin ṣaju mi, ki ẹ si fi àlàfo si agbedemeji ọwọ́-ọwọ. 17 O si fi aṣẹ fun eyiti o tète ṣaju wipe, Nigbati Esau, arakunrin mi, ba pade rẹ, ti o si bi ọ wipe, Ti tani iwọ? nibo ni iwọ si nrè? ati ti tani wọnyi niwaju rẹ? 18 Nigbana ni ki iwọ ki o wipe, Ti Jakobu iranṣẹ rẹ ni; ọrẹ ti o rán si Esau oluwa mi ni: si kiyesi i, on tikalarẹ̀ si mbẹ lẹhin wa. 19 Bẹ̃li o si fi aṣẹ fun ekeji, ati fun ẹkẹta, ati fun gbogbo awọn ti o tẹle ọwọ́ wọnni wipe, Bayibayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau nigbati ẹnyin ba ri i. 20 Ki ẹnyin ki o wi pẹlu pe, Kiyesi i, Jakobu iranṣẹ rẹ mbọ̀ lẹhin wa. Nitori ti o wipe, Emi o fi ọrẹ ti o ṣaju mi tù u loju, lẹhin eyini emi o ri oju rẹ̀, bọya yio tẹwọgbà mi. 21 Bẹ̃li ọrẹ na si kọja lọ niwaju rẹ̀: on tikalarẹ̀ si sùn li oru na ninu awọn ẹgbẹ.

Jakọbu jìjàkadì ní Penieli

22 O si dide li oru na, o si mú awọn aya rẹ̀ mejeji, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ mejeji, ati awọn ọmọ rẹ̀ mọkọkanla, o si kọja iwọdò Jabboku. 23 O si mú wọn, o si rán wọn si oke odò na, o si rán ohun ti o ní kọja si oke odò. 24 O si kù Jakobu nikan; ọkunrin kan si mbá a jijakadi titi o fi di afẹmọ́jumọ. 25 Nigbati o si ri pe on kò le dá a, o fọwọkàn a ni ihò egungun itan rẹ̀; ihò egungun itan Jakobu si yẹ̀ li orike, bi o ti mbá a jijakadi. 26 O si wipe, Jẹ ki emi ki o lọ nitori ti ojúmọ mọ́ tán. On si wipe, Emi ki yio jẹ ki iwọ ki o lọ, bikoṣepe iwọ ba sure fun mi. 27 O si bi i pe, Orukọ rẹ? On si dahùn pe, Jakobu. 28 O si wipe, A ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli: nitoripe, iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori. 29 Jakobu si bi i o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, sọ orukọ rẹ fun mi. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi? o si sure fun u nibẹ̀. 30 Jakobu si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Penieli: o ni, Nitori ti mo ri Ọlọrun li ojukoju, a si dá ẹmi mi si. 31 Bi o si ti nkọja Penieli, õrùn là bá a, o si nmukun ni itan rẹ̀. 32 Nitori na li awọn ọmọ Israeli ki iṣe ijẹ iṣan ti ifà, ti o wà ni kòto itan, titi o fi di oni-oloni: nitori ti o fọwọkàn kòto egungun itan Jakobu ni iṣan ti ifà.

Genesisi 33

Jakọbu Pàdé Esau

1 JAKOBU si gbé oju rẹ̀ soke, o si wò, si kiyesi i, Esau dé, ati irinwo ọkunrin pẹlu rẹ̀. On si pín awọn ọmọ fun Lea, ati fun Rakeli, ati fun awọn iranṣẹbinrin mejeji. 2 O si tì awọn iranṣẹbinrin ati awọn ọmọ wọn ṣaju, ati Lea ati awọn ọmọ rẹ̀ tẹle wọn, ati Rakeli ati Josefu kẹhin. 3 On si kọja lọ siwaju wọn, o si wolẹ li ẹrinmeje titi o fi dé ọdọ arakunrin rẹ̀. 4 Esau si sure lati pade rẹ̀, o si gbá a mú, o si rọmọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: nwọn si sọkun. 5 O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri awọn obinrin ati awọn ọmọ; o si bi i pe, Tani wọnyi pẹlu rẹ? On si wipe, Awọn ọmọ ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ fun iranṣẹ rẹ ni. 6 Nigbana li awọn iranṣẹbinrin sunmọ ọdọ rẹ̀, awọn ati awọn ọmọ wọn, nwọn si tẹriba. 7 Ati Lea pẹlu ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba: nikẹhin ni Josefu ati Rakeli si sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba. 8 O si wipe, Kini iwọ fi ọwọ́ ti mo pade ni pè? On si wipe, Lati fi ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi ni. 9 Esau si wipe, Emi ní tó, arakunrin mi; pa eyiti o ní mọ́ fun ara rẹ. 10 Jakobu si wipe, Bẹ̃kọ, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi, njẹ gbà ọrẹ mi lọwọ mi: nitori ti emi sa ri oju rẹ bi ẹnipe emi ri oju Ọlọrun, ti inu rẹ si dùn si mi; 11 Emi bẹ̀ ọ, gbà ẹ̀bun mi ti a mú fun ọ wá; nitori ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ ba mi ṣe, ati pe, nitori ti mo ní tó. O si rọ̀ ọ, on si gbà a. 12 O si wipe, Jẹ ki a bọ́ si ọ̀na ìrin wa, ki a si ma lọ, emi o si ṣaju rẹ. 13 Ṣugbọn on wi fun u pe, oluwa mi mọ̀ pe awọn ọmọ kò lera, ati awọn agbo-ẹran, ati ọwọ́-malu ati awọn ọmọ wọn wà pẹlu mi: bi enia ba si dà wọn li àdaju li ọjọ́ kan, gbogbo agbo ni yio kú. 14 Emi bẹ̀ ọ, ki oluwa mi ki o ma kọja nṣó niwaju iranṣẹ rẹ̀: emi o si ma fà wá pẹlẹ, gẹgẹ bi awọn ẹran ti o saju mi, ati bi ara awọn ọmọ ti le gbà, titi emi o fi dé ọdọ oluwa mi ni Seiri. 15 Esau si wipe, Njẹ ki emi ki o fi enia diẹ silẹ pẹlu rẹ ninu awọn enia ti o pẹlu mi. On si wipe, Nibo li eyini jasi, ki emi ki o sa ri õre-ọfẹ li oju oluwa mi. 16 Esau si pada li ọjọ́ na li ọ̀na rẹ̀ lọ si Seiri. 17 Jakobu si rìn lọ si Sukkotu, o si kọ́ ile fun ara rẹ̀, o si pa agọ́ fun awọn ẹran rẹ̀: nitorina li a ṣe sọ orukọ ibẹ̀ na ni Sukkotu. 18 Jakobu si wá li alafia, si ilu Ṣekemu ti o wà ni ilẹ Kenaani, nigbati o ti Padan-aramu dé: o si pa agọ́ rẹ̀ niwaju ilu na. 19 O si rà oko biri kan, nibiti o gbé ti pa agọ́ rẹ̀ lọwọ awọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu, li ọgọrun owo fadaka. 20 O si tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ̀, o si sọ orukọ rẹ̀ ni El-Elohe-Israeli.

Genesisi 34

Wọ́n fi Ipá bá Dina Lòpọ̀

1 DINA ọmọbinrin Lea, ti o bí fun Jakobu si jade lọ lati wò awọn ọmọbinrin ilu na. 2 Nigbati Ṣekemu, ọmọ Hamori, ara Hiffi, ọmọ alade ilu na ri i, o mú u, o si wọle tọ̀ ọ, o si bà a jẹ́. 3 Ọkàn rẹ̀ si fà mọ́ Dina, ọmọbinrin Jakobu, o si fẹ́ omidan na, o si sọ̀rọ rere fun omidan na. 4 Ṣekemu si sọ fun Hamori baba rẹ̀ pe, Fẹ́ omidan yi fun mi li aya. 5 Jakobu si gbọ́ pe o ti bà Dina ọmọbinrin on jẹ́; njẹ awọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu awọn ẹran ni pápa: Jakobu si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ titi nwọn fi dé. 6 Hamori, baba Ṣekemu, si jade tọ̀ Jakobu lọ lati bá a sọ̀rọ. 7 Awọn ọmọ Jakobu si ti oko dé nigbati nwọn gbọ́: inu awọn ọkunrin na si bàjẹ́, inu si ru wọn gidigidi, nitori ti o ṣe ohun buburu ni Israeli, niti o bá ọmọbinrin Jakobu dàpọ: ohun ti a ki ba ti ṣe. 8 Hamori si bá wọn sọ̀rọ pe, Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, nfẹ́ ọmọbinrin nyin; emi bẹ̀ nyin, ẹ fi i fun u li aya. 9 Ki ẹnyin ki o si bá wa gbeyawo, ki ẹnyin ki o si fi awọn ọmọbinrin nyin fun wa, ki ẹnyin ki o si ma mú awọn ọmọbinrin wa. 10 Ẹnyin o si ma bá wa gbé: ilẹ yio si wà niwaju nyin, ẹnyin o joko ki ẹ si ma ṣòwo ninu rẹ̀, ki ẹ si ma ní iní ninu rẹ̀. 11 Ṣekemu si wi fun baba omidan na ati fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju nyin, ohun ti ẹnyin o si kà fun mi li emi o fi fun nyin. 12 Ẹ bère ana lọwọ mi ati ẹ̀bun bi o ti wù ki o pọ̀ to, emi o si fi fun nyin gẹgẹ bi ẹnyin o ti kà fun mi: ṣugbọn ẹ fun mi li omidan na li aya. 13 Awọn ọmọ Jakobu si fi ẹ̀tan da Ṣekemu ati Hamori baba rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, nitori ti o bà Dina arabinrin wọn jẹ́: 14 Nwọn si wi fun wọn pe, Awa kò le ṣe nkan yi lati fi arabinrin wa fun ẹni alaikọlà, nitori ohun àbuku ni fun wa; 15 Kiki ninu eyi li awa le jẹ fun nyin: bi ẹnyin o ba wà bi awa, pe ki a kọ olukuluku ọkunrin nyin li ilà. 16 Nigbana li awa o fi awọn ọmọbinrin wa fun nyin, awa o si mú awọn ọmọbinrin nyin sọdọ wa; awa o si ma bá nyin gbé, awa o si di enia kanna. 17 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti wa lati kọlà; njẹ awa o mú ọmọbinrin wa, awa o si ba ti wa lọ. 18 Ọ̀rọ wọn si dún mọ́ Hamori, ati Ṣekemu, ọmọ Hamori. 19 Ọdọmọkunrin na kò si pẹ́ titi lati ṣe nkan na, nitoriti o fẹ́ ọmọbinrin Jakobu; o si li ọlá jù gbogbo ara ile baba rẹ̀ lọ. 20 Ati Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wá si ẹnubode ilu wọn, nwọn si bá awọn ara ilu wọn sọ̀rọ wipe, 21 Awọn ọkunrin wọnyi mbá wa gbé li alafia; nitorina ẹ jẹ ki nwọn ki o ma gbé ilẹ yi, ki nwọn ki o si ma ṣòwo nibẹ̀; kiyesi i, ilẹ sa gbàye tó niwaju wọn; ẹnyin jẹ ki a ma fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, ki awa ki o si ma fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn. 22 Kìki ninu eyi li awọn ọkunrin na o ṣe jẹ fun wa, lati ma bá wa gbé, lati di enia kan, bi gbogbo ọkunrin inu wa ba kọlà, gẹgẹ bi nwọn ti kọlà. 23 Tiwa kọ ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ati gbogbo ohunọ̀sin wọn yio ha ṣe? ki a sa jẹ fun wọn nwọn o si ma ba wa joko, 24 Gbogbo awọn ti njade li ẹnubode ilu wọn si fetisi ti Hamori ati ti Ṣekemu ọmọ rẹ̀; a si kọ gbogbo awọn ọkunrin ni ilà, gbogbo ẹniti o nti ẹnubode wọn jade. 25 O si ṣe ni ọjọ́ kẹta, ti ọgbẹ wọn kan, ni awọn ọmọkunrin Jakobu meji si dide, Simeoni ati Lefi, awọn arakunrin Dina, olukuluku nwọn mú idà rẹ̀, nwọn si fi igboyà wọ̀ ilu na, nwọn si pa gbogbo awọn ọkunrin. 26 Nwọn si fi oju idà pa Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀, nwọn si mú Dina jade kuro ni ile Ṣekemu, nwọn si jade lọ. 27 Awọn ọmọ Jakobu si wọle awọn ti a pa, nwọn si kó ilu na lọ, nitori ti nwọn bà arabinrin wọn jẹ́. 28 Nwọn kó agutan wọn, ati akọmalu wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ohun ti o wà ni ilu na, ati eyiti o wà li oko. 29 Ati ọrọ̀ wọn gbogbo, ati gbogbo ọmọ wọn wẹ́rẹ, ati aya wọn ni nwọn dì ni igbekun, nwọn si kó ohun gbogbo ti o wà ninu ile lọ. 30 Jakobu si wi fun Simeoni on Lefi pe, Ẹnyin mu wahalà bá mi niti ẹnyin mu mi di õrun ninu awọn onilẹ, ninu awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi: bi emi kò si ti pọ̀ ni iye, nwọn o kó ara wọn jọ si mi, nwọn o si pa mi: a o si pa mi run, emi ati ile mi. 31 Nwọn si wipe, Ki on ki o ha ṣe si arabinrin wa bi ẹnipe si panṣaga?

Genesisi 35

Ọlọrun Súre fún Jakọbu ní Bẹtẹli

1 ỌLỌRUN si wi fun Jakobu pe, Dide goke lọ si Beteli ki o si joko nibẹ̀, ki o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, fun Ọlọrun, ti o farahàn ọ, nigbati iwọ sá kuro niwaju Esau, arakunrin rẹ. 2 Nigbana ni Jakobu wi fun awọn ara ile rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ti o wà li ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mú àjeji oriṣa ti o wà lọwọ nyin kuro, ki ẹnyin ki o si sọ ara nyin di mimọ́, ki ẹnyin ki o si pa aṣọ nyin dà: 3 Ẹ si jẹ ki a dide, ki a si goke lọ si Beteli; nibẹ̀ li emi o si gbé tẹ́ pẹpẹ kan fun Ọlọrun ti o da mi li ohùn li ọjọ́ ipọnju mi, ẹniti o si wà pẹlu mi li àjo ti mo rè. 4 Nwọn si fi gbogbo àjeji oriṣa ti o wà lọwọ wọn fun Jakobu, ati gbogbo oruka eti ti o wà li eti wọn: Jakobu si pa wọn mọ́ li abẹ igi oaku ti o wà leti Ṣekemu. 5 Nwọn si rìn lọ: ẹ̀ru Ọlọrun si mbẹ lara ilu ti o yi wọn ká, nwọn kò si lepa awọn ọmọ Jakobu. 6 Bẹ̃ni Jakobu si wá si Lusi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, eyinì ni Beteli, on ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀. 7 O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni El-bet-el: nitori pe nibẹ̀ li Ọlọrun tọ̀ ọ wá, nigbati o sá kuro niwaju arakunrin rẹ̀. 8 Ṣugbọn Debora olutọ́ Rebeka kú, a si sin i nisalẹ Beteli labẹ igi oaku kan: orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Alloni-bakutu. 9 Ọlọrun si tún farahàn Jakobu, nigbati o ti Padan-aramu bọ̀, o si sure fun u. 10 Ọlọrun si wi fun u pe, Jakobu li orukọ rẹ: a ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ́: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Israeli. 11 Ọlọrun si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare: ma bisi i, si ma rẹ̀; orilẹ-ède, ati ẹgbẹ-ẹgbẹ orilẹ-ède ni yio ti ọdọ rẹ wá, awọn ọba yio si ti inu rẹ jade wá; 12 Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun. 13 Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ rẹ̀ ni ibi ti o gbé mbá a sọ̀rọ. 14 Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ ni ibi ti o gbé bá a sọ̀rọ, ani ọwọ̀n okuta: o si ta ọrẹ ohun mimu si ori rẹ̀, o si ta oróro si ori rẹ̀. 15 Jakobu si sọ orukọ ibi ti Ọlọrun gbé bá a sọ̀rọ ni Beteli.

Ikú Rakẹli

16 Nwọn si rìn lati Beteli lọ; o si kù diẹ ki nwọn ki o dé Efrati: ibi si tẹ̀ Rakeli: o si ṣoro jọjọ fun u. 17 O si ṣe nigbati o wà ninu irọbí, ni iyãgba wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: iwọ o si li ọmọkunrin yi pẹlu. 18 O si ṣe, bi ọkàn rẹ̀ ti nlọ̀ (o sa kú) o sọ orukọ rẹ̀ ni Ben-oni: ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ ni Benjamini. 19 Rakeli si kú, a si sin i li ọ̀na Efrati, ti iṣe Betlehemu. 20 Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ li oju-õri rẹ̀, eyinì ni Ọwọ̀n oju-õri Rakeli titi di oni-oloni. 21 Israeli si nrìn lọ, o si pa agọ́ rẹ̀ niwaju ile iṣọ Ederi.

Àwọn Ọmọ Jakọbu

22 O si ṣe nigbati Israeli joko ni ilẹ na, Reubeni si wọle tọ̀ Bilha, àle baba rẹ̀ lọ; Israeli si gbọ́. Njẹ awọn ọmọ Jakobu jẹ́ mejila. 23 Awọn ọmọ Lea; Reubẹni, akọ́bi Jakobu, ati Simeoni, ati Lefi, ati Judah, ati Issakari, ati Sebuluni. 24 Awọn ọmọ Rakeli; Josefu, ati Benjamini: 25 Ati awọn ọmọ Bilha, iranṣẹbinrin Rakeli; Dani, ati Naftali: 26 Ati awọn ọmọ Silpa, iranṣẹbinrin Lea; Gadi ati Aṣeri. Awọn wọnyi li ọmọ Jakobu, ti a bí fun u ni Padanaramu.

Ikú Isaaki

27 Jakobu si dé ọdọ Isaaki baba rẹ̀, ni Mamre, si Kiriat-arba, ti iṣe Hebroni, nibiti Abrahamu ati Isaaki gbé ṣe atipo pẹlu. 28 Ọjọ́ Isaaki si jẹ́ ọgọsan ọdún. 29 Isaaki si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú, a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀, o gbó, o si kún fun ọjọ́, awọn ọmọ rẹ̀, Esau ati Jakobu si sin i.

Genesisi 36

Àwọn Ìran Esau

1 WỌNYI si ni iran Esau, ẹniti iṣe Edomu. 2 Esau fẹ́ awọn aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ada, ọmọbinrin Eloni, enia Hitti, ati Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, ara Hiffi; 3 Ati Baṣemati, ọmọbinrin Iṣmaeli, arabinrin Nebajotu. 4 Ada si bí Elifasi fun Esau; Baṣemati si bí Reueli; 5 Aholibama si bí Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora: awọn wọnyi li ọmọkunrin Esau, ti a bí fun u ni ilẹ Kenaani. 6 Esau si mú awọn aya rẹ̀, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn enia ile rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati gbogbo ohun-ọ̀sin, ati ohun iní gbogbo ti o ní ni ilẹ Kenaani; o si lọ si ilẹ kan kuro niwaju Jakobu arakunrin rẹ̀. 7 Nitori ti ọrọ̀ wọn pọ̀ jù ki nwọn ki o gbé pọ̀ lọ; ilẹ ti nwọn si ṣe atipo si kò le gbà wọn, nitori ohun-ọ̀sin wọn. 8 Bẹ̃ni Esau tẹ̀dó li oke Seiri: Esau ni Edomu. 9 Wọnyi si ni iran Esau, baba awọn ara Edomu, li oke Seiri: 10 Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Esau; Elifasi, ọmọ Ada, aya Esau, Rueli, ọmọ Baṣemati, aya Esau. 11 Ati awọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari, Sefo, ati Gatamu, ati Kenasi. 12 Timna li o si ṣe àle Elifasi, ọmọ Esau; on si bí Amaleki fun Elifasi; wọnyi si li awọn ọmọ Ada, aya Esau. 13 Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli; Nahati, ati Sera, Ṣamma, ati Misa: awọn wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau. 14 Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, aya Esau: on si bí Jeuṣi fun Esau, ati Jaalamu, ati Kora. 15 Awọn wọnyi ni olori ninu awọn ọmọ Esau: awọn ọmọ Elifasi, akọ́bi Esau; Temani olori, Omari olori, Sefo olori, Kenasi olori, 16 Kora olori, Gatamu olori, Amaleki olori: wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Elifasi wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Ada. 17 Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli ọmọ Esau; Nahati olori, Sera olori, Ṣamma olori, Misa olori; wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Reueli wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau. 18 Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, aya Esau; Jeuṣi olori, Jaalamu olori, Kora olori: wọnyi li awọn ti o ti ọdọ Aholibama wá, aya Esau, ọmọbinrin Ana. 19 Wọnyi li awọn ọmọ Esau, eyini ni Edomu, wọnyi si li awọn olori wọn.

Àwọn Ìran Seiri

20 Wọnyi li awọn ọmọ Seiri, enia Hori, ti o tẹ̀dó ni ilẹ na; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, 21 Ati Diṣoni, ati Eseri, ati Diṣani: wọnyi li awọn olori enia Hori, awọn ọmọ Seiri ni ilẹ Edomu. 22 Ati awọn ọmọ Lotani ni Hori ati Hemamu: arabinrin Lotani si ni Timna. 23 Ati awọn ọmọ Ṣobali ni wọnyi; Alfani, ati Mahanati, ati Ebali, Sefo, ati Onamu. 24 Wọnyi si li awọn ọmọ Sibeoni; ati Aja on Ana: eyi ni Ana ti o ri awọn isun omi gbigbona ni ijù, bi o ti mbọ́ awọn kẹtẹkẹtẹ Sibeoni baba rẹ̀. 25 Wọnyi si li awọn ọmọ Ana; Disoni ati Aholibama, ọmọbinrin Ana. 26 Wọnyi si li awọn ọmọ Diṣoni; Hemdani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani. 27 Awọn ọmọ Eseri ni wọnyi; Bilhani, ati Saafani, ati Akani. 28 Awọn ọmọ Diṣani ni wọnyi; Usi ati Arani. 29 Wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Hori wá; Lotani olori, Ṣobali olori, Sibeoni olori, Ana olori, 30 Diṣoni olori, Eseri olori, Diṣani olori; wọnyi li awọn olori awọn enia Hori, ninu awọn olori wọn ni ilẹ Seiri.

Àwọn Ọba Edomu

31 Wọnyi si li awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan ki o to jọba lori awọn ọmọ Israeli. 32 Bela ti iṣe ọmọ Beori si jọba ni Edomu: orukọ ilu rẹ̀ a si ma jẹ́ Dinhaba. 33 Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀. 34 Jobabu si kú, Huṣamu ti ilẹ Temani si jọba ni ipò rẹ̀. 35 Huṣamu si kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ẹniti o kọlù Midiani ni igbẹ́ Moabu si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Afiti. 36 Hadadi si kú, Samla ti Masreka si jọba ni ipò rẹ̀. 37 Samla si kú, Ṣaulu ti Rehobotu leti odò nì si jọba ni ipò rẹ̀. 38 Ṣaulu si kú, Baal-hanani ọmọ Akbori si jọba ni ipò rẹ̀. 39 Baal-hanani ọmọ Akbori si kú, Hadari si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Pau; Mehetabeli si li orukọ aya rẹ̀, ọmọbinrin Metredi, ọmọbinrin Mesahabu. 40 Wọnyi si li orukọ awọn olori ti o ti ọdọ Esau wá, gẹgẹ bi idile wọn, nipa ipò wọn, nipa orukọ wọn; Timna olori, Alfa olori, Jeteti olori; 41 Aholibama olori, Ela olori, Pinoni olori; 42 Kenasi olori, Temani olori, Mibsari olori; 43 Magdieli olori, Iramu olori: wọnyi li awọn olori Edomu, nipa itẹ̀dó wọn ni ilẹ iní wọn: eyi ni Esau, baba awọn ara Edomu.

Genesisi 37

Josẹfu ati Àwọn Arakunrin Rẹ̀

1 JAKOBU si joko ni ilẹ ti baba rẹ̀ ti ṣe atipo, ani ilẹ Kenaani. 2 Wọnyi ni iran Jakobu. Nigbati Josefu di ẹni ọdún mẹtadilogun, o nṣọ́ agbo-ẹran pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; ọmọde na si wà pẹlu awọn ọmọ Bilha, ati pẹlu awọn ọmọ Silpa, awọn aya baba rẹ̀; Josefu si mú ihin buburu wọn wá irò fun baba wọn. 3 Israeli si fẹ́ Josefu jù gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ lọ, nitori ti iṣe ọmọ ogbó rẹ̀; o si dá ẹ̀wu alarabara aṣọ fun u. 4 Nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ri pe baba wọn fẹ́ ẹ jù gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn korira rẹ̀, nwọn kò si le sọ̀rọ si i li alafia. 5 Josefu si lá alá kan, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀; nwọn si tun korira rẹ̀ si i. 6 O si wi fun wọn pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ gbọ́ alá yi ti mo lá. 7 Sa wò o, awa nyí ití li oko, si wò o, ití mi dide, o si duro ṣanṣan; si wò o, ití ti nyin dide duro yiká, nwọn si ntẹriba fun ití mi. 8 Awọn arakunrin rẹ̀ si wi fun u pe, Iwọ o ha jọba lori wa bi? tabi iwọ o ṣe olori wa nitõtọ? nwọn si tun korira rẹ̀ si i nitori alá rẹ̀ ati nitori ọ̀rọ rẹ̀. 9 O si tun lá alá miran, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀, o wipe, Sa wò o, mo tun lá alá kan si i; si wò o, õrùn, ati oṣupa, ati irawọ mọkanla nforibalẹ fun mi. 10 O si rọ́ ọ fun baba rẹ̀, ati fun awọn arakunrin rẹ̀: baba rẹ̀ si bá a wi, o si wi fun u pe, Alá kili eyi ti iwọ lá yi? emi ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ yio ha wá nitõtọ, lati foribalẹ fun ọ bi? 11 Awọn arakunrin rẹ̀ si ṣe ilara rẹ̀; ṣugbọn baba rẹ̀ pa ọ̀rọ na mọ́.

Wọ́n Ta Josẹfu Lẹ́rú sí Ijipti

12 Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ lati bọ́ agbo-ẹran baba wọn ni Ṣekemu. 13 Israeli si wi fun Josefu pe, Ni Ṣekemu ki awọn arakunrin rẹ gbé mbọ́ ẹran? wá, emi o si rán ọ si wọn. On si wi fun u pe, Emi niyi. 14 O si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, lọ wò alafia awọn arakunrin rẹ, ati alafia awọn agbo-ẹran; ki o si mú ihin pada fun mi wá. Bẹ̃li o si rán a lati afonifoji Hebroni lọ, on si dé Ṣekemu. 15 Ọkunrin kan si ri i, si wò o, o nrìn kakiri ni pápa: ọkunrin na si bi i pe, Kini iwọ nwá? 16 On si wipe, Emi nwá awọn arakunrin mi: mo bẹ̀ ọ, sọ ibi ti nwọn gbé mbọ́ agbo-ẹran wọn fun mi. 17 Ọkunrin na si wipe, Nwọn ti lọ kuro nihin; nitori mo gbọ́, nwọn nwipe, ẹ jẹ ki a lọ si Dotani. Josefu si lepa awọn arakunrin rẹ̀, o si ri wọn ni Dotani. 18 Nigbati nwọn si ri i lokere; ki o tilẹ to sunmọ eti ọdọ wọn, nwọn di rikiṣi si i lati pa a. 19 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Wò o, alála nì mbọ̀wá. 20 Nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si wọ́ ọ sọ sinu ọkan ninu ihò wọnyi, awa o si wipe ẹranko buburu li o pa a jẹ: awa o si ma wò bi alá rẹ̀ yio ti ri. 21 Reubeni si gbọ́, o si gbà a li ọwọ́ won; o si wipe, Ẹ máṣe jẹ ki a gbà ẹmi rẹ̀. 22 Reubeni si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe ta ẹ̀jẹ, ṣugbọn ẹ sọ ọ sinu ihò yi ti mbẹ li aginjù, ki ẹ má si fọwọkàn a; nitori ki o ba le gbà a lọwọ wọn lati mú u pada tọ̀ baba rẹ̀ lọ. 23 O si ṣe nigbati Josefu dé ọdọ awọn arakunrin rẹ̀, nwọn bọ́ ẹ̀wu Josefu, ẹ̀wu alarabara aṣọ ti o wà lara rẹ̀; 24 Nwọn si mú u, nwọn si gbe e sọ sinu ihò kan: ihò na si gbẹ, kò li omi. 25 Nwọn si joko lati jẹun: nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn si wò, si kiyesi i, ọwọ́-èro ara Iṣmaeli nti Gileadi bọ̀; ti awọn ti ibakasiẹ ti o rù turari ati ikunra ati ojia, nwọn nmú wọn lọ si Egipti. 26 Judah si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ere ki li o jẹ́ bi awa ba pa arakunrin wa, ti a si bò ẹ̀jẹ rẹ̀? 27 Ẹ wá ẹ jẹ ki a tà a fun awọn ara Iṣmaeli ki a má si fọwọ wa kàn a; nitori arakunrin wa ati ara wa ni iṣe. Awọn arakunrin rẹ̀ si gbà tirẹ̀. 28 Nigbana li awọn oniṣòwo ara Midiani nkọja lọ; nwọn si fà a, nwọn si yọ Josefu jade ninu ihò, nwọn si tà Josefu li ogún owo fadaka: nwọn si mú Josefu lọ si Egipti. 29 Reubeni si pada lọ si ihò; si wò o, Josefu kò sí ninu ihò na; o si fà aṣọ rẹ̀ ya. 30 O si pada tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wipe, Ọmọde na kò sí; ati emi, nibo li emi o gbé wọ̀? 31 Nwọn si mú ẹ̀wu Josefu, nwọn si pa ọmọ ewurẹ kan, nwọn si rì ẹ̀wu na sinu ẹ̀jẹ na. 32 Nwọn si fi ẹ̀wu alarabara aṣọ na ranṣẹ, nwọn si mú u tọ̀ baba wọn wá; nwọn si wipe, Eyi li awa ri: mọ̀ nisisiyi bi ẹ̀wu ọmọ rẹ ni, bi on kọ́. 33 On si mọ̀ ọ, o si wipe, Ẹ̀wu ọmọ mi ni; ẹranko buburu ti pa a jẹ; li aiṣe aniani, a ti fà Josefu ya pẹrẹpẹrẹ. 34 Jakobu si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si ṣọ̀fọ ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ pupọ̀. 35 Ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ obinrin dide lati ṣìpẹ fun u; ṣugbọn o kọ̀ lati gbipẹ̀; o si wipe, Ninu ọ̀fọ li emi o sa sọkalẹ tọ̀ ọmọ mi lọ si isà-okú. Bayi ni baba rẹ̀ sọkun rẹ̀. 36 Awọn ara Midiani si tà a si Egipti fun Potifari, ijoye Farao kan, ati olori ẹṣọ́.

Genesisi 38

Juda ati Tamari

1 O SI ṣe li akokò na, ni Judah sọkalẹ lọ kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, o si yà sọdọ ara Adullamu kan, orukọ ẹniti ijẹ́ Hira. 2 Judah si ri ọmọbinrin ara Kenaani kan nibẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Ṣua; o si mú u, o si wọle tọ̀ ọ. 3 O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Eri. 4 O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Onani. 5 O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣela: o wà ni Kesibu, nigbati o bí i. 6 Judah si fẹ́ aya fun Eri akọ́bi rẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Tamari. 7 Eri akọ́bi Judah si ṣe enia buburu li oju OLUWA; OLUWA si pa a. 8 Judah si wi fun Onani pe, Wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ lọ, ki o si ṣú u li opó, ki o si bimọ si ipò arakunrin rẹ. 9 Onani si mọ̀ pe, irú-ọmọ ki yio ṣe tirẹ̀; o si ṣe bi o ti wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ̀ lọ, o si dà a silẹ, ki o má ba fi irú-ọmọ fun arakunrin rẹ̀. 10 Ohun ti o si ṣe buru loju OLUWA, nitori na li OLUWA pa a pẹlu. 11 Nigbana ni Judah wi fun Tamari aya ọmọ rẹ̀ pe, Joko li opó ni ile baba rẹ, titi Ṣela ọmọ mi o fi dàgba: nitori o wipe, Ki on má ba kú pẹlu, bi awọn arakunrin rẹ̀. Tamari si lọ, o si joko ni ile baba rẹ̀. 12 Nigbati ọjọ́ si npẹ́, ọmọbinrin Ṣua, aya Juda kú; Judah si gbipẹ̀, o si tọ̀ awọn olurẹrun agutan rẹ̀, lọ si Timnati, on ati Hira ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu. 13 A si wi fun Tamari pe, Kiyesi i, baba ọkọ rẹ lọ si Timnati lati rẹrun agutan rẹ̀. 14 O si bọ́ aṣọ opó rẹ̀ kuro li ara rẹ̀, o si fi iboju bò ara rẹ̀, o si roṣọ, o si joko li ẹnubode Enaimu, ti o wà li ọ̀na Timnati; nitoriti o ri pe Ṣela dàgba, a kò si fi on fun u li aya. 15 Nigbati Judah ri i, o fi i pè panṣaga; nitori o boju rẹ̀. 16 O si yà tọ̀ ọ li ẹba ọ̀na, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, wá na, jẹ ki emi ki o wọle tọ̀ ọ; (on kò sa mọ̀ pe aya ọmọ on ni iṣe.) On si wipe Kini iwọ o fi fun mi, ki iwọ ki o le wọle tọ̀ mi? 17 O si wipe, emi o rán ọmọ ewurẹ kan si ọ lati inu agbo wá. On si wipe, iwọ ki o fi ògo fun mi titi iwọ o fi rán a wá? 18 O si bi i pe, Ògo kili emi o fi fun ọ? on si wipe, Èdidi rẹ, ati okùn rẹ, ati ọpá rẹ ti o wà li ọwọ́ rẹ; o si fi wọn fun u, o si wọle tọ̀ ọ lọ, on si ti ipa ọdọ rẹ̀ yún. 19 On si dide, o ba tirẹ̀ lọ, o si bọ́ iboju rẹ̀ lelẹ kuro lara rẹ̀, o si mú aṣọ opó rẹ̀ ró. 20 Judah si rán ọmọ ewurẹ na lati ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu na lọ, lati gbà ògo nì wá lọwọ obinrin na: ṣugbọn on kò ri i. 21 Nigbana li o bère lọwọ awọn ọkunrin ibẹ̀ na pe, Nibo ni panṣaga nì ngbé, ti o wà ni Enaimu li ẹba ọ̀na? Nwọn si wipe, Panṣaga kan kò sí nihin. 22 O si pada tọ̀ Judah lọ, o si wipe, Emi kò ri i; ati pẹlu awọn ọkunrin ara ibẹ̀ na wipe, Kò sí panṣaga kan nibẹ̀. 23 Judah si wipe, Jẹ ki o ma mú u fun ara rẹ̀, ki oju ki o má tì wa: kiyesi i, emi rán ọmọ ewurẹ yi, iwọ kò si ri i. 24 O si ṣe niwọ̀n oṣù mẹta lẹhin rẹ̀, ni a wi fun Judah pe, Tamari aya ọmọ rẹ ṣe àgbere; si kiyesi i pẹlu, o fi àgbere loyun. Judah si wipe, Mú u jade wá, ki a si dána sun u. 25 Nigbati a si mú u jade, o ranṣẹ si baba ọkọ rẹ̀ pe, ọkunrin ti o ní nkan wọnyi li emi yún fun: o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mọ̀ wọn, ti tani nkan wọnyi, èdidi, ati okùn, ati ọpá. 26 Judah si jẹwọ, o si wipe, O ṣe olododo jù mi lọ; nitori ti emi kò fi i fun Ṣela ọmọ mi. On kò si mọ̀ ọ mọ́ lai. 27 O si ṣe li akokò ti o nrọbí, si kiyesi i, ìbejì wà ni inu rẹ̀. 28 O si ṣe nigbati o nrọbí, ti ọkan yọ ọwọ́ jade: iyãgba si mú okùn ododó o so mọ́ ọ li ọwọ́, o wipe, Eyi li o kọ jade. 29 O si ṣe, bi o ti fà ọwọ́ rẹ̀ pada, si kiyesi i, aburo rẹ̀ jade: o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yà? yiyà yi wà li ara rẹ, nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Peresi: 30 Nikẹhin li arakunrin rẹ̀ jade, ti o li okùn ododó li ọwọ́ rẹ̀: a si sọ orukọ rẹ̀ ni Sera.

Genesisi 39

Josẹfu ati Aya Pọtifari

1 A SI mú Josefu sọkalẹ wá si Egipti; Potifari, ijoye Farao kan, olori ẹṣọ́, ara Egipti, si rà a lọwọ awọn ara Iṣmaeli ti o mú u sọkalẹ wá sibẹ̀. 2 OLUWA si wà pẹlu Josefu, o si ṣe alasiki enia; o si wà ni ile oluwa rẹ̀ ara Egipti na. 3 Oluwa rẹ̀ si ri pe OLUWA pẹlu rẹ̀, ati pe, OLUWA mu ohun gbogbo ti o ṣe dara li ọwọ́ rẹ̀. 4 Josefu si ri ojurere li oju rẹ̀, on si nsìn i: o si fi i jẹ́ olori ile rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní on li o fi lé e lọwọ. 5 O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko. 6 O si fi ohun gbogbo ti o ní si ọwọ́ Josefu; kò si mọ̀ ohun ti on ní bikoṣe onjẹ ti o njẹ. Josefu si ṣe ẹni daradara ati arẹwà enia. 7 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni aya oluwa rẹ̀ gbé oju lé Josefu; o si wipe, Bá mi ṣe. 8 Ṣugbọn on kọ̀, o si wi fun aya oluwa rẹ̀ pe, kiyesi i, oluwa mi kò mọ̀ ohun ti o wà lọdọ mi ni ile, o si ti fi ohun gbogbo ti o ní lé mi lọwọ: 9 Kò sí ẹniti o pọ̀ jù mi lọ ninu ile yi; bẹ̃ni kò si pa ohun kan mọ́ kuro lọwọ mi bikoṣe iwọ, nitori pe aya rẹ̀ ni iwọ iṣe: njẹ emi o ha ti ṣe hù ìwabuburu nla yi, ki emi si dẹ̀ṣẹ si Ọlọrun? 10 O si ṣe, bi o ti nsọ fun Josefu lojojumọ́, ti on kò si gbọ́ tirẹ̀ lati dubulẹ tì i, tabi lati bá a ṣe. 11 O si ṣe niwọ̀n akokò yi, ti Josefu wọle lọ lati ṣe iṣẹ rẹ̀; ti kò si sí ẹnikan ninu awọn ọkunrin ile ninu ile nibẹ̀. 12 On si di Josefu li aṣọ mú, o wipe, bá mi ṣe: on si jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, o si sá, o bọ sode. 13 O si ṣe, nigbati o ri i pe Josefu jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, ti o si sá jade, 14 Nigbana li o kepè awọn ọkunrin ile rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ wò o, o mú Heberu kan wọle tọ̀ wa wá lati fi wa ṣe ẹlẹyà; o wọle tọ̀ mi wá lati bá mi ṣe, mo si kigbe li ohùn rara: 15 O si ṣe, nigbati o gbọ́ pe mo gbé ohùn mi soke ti mo si kigbe, o jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá, o bọ sode. 16 O si fi aṣọ Josefu lelẹ li ẹba ọdọ rẹ̀, titi oluwa rẹ̀ fi bọ̀wá ile. 17 O si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi pe, Ẹrú Heberu ti iwọ mu tọ̀ wa, o wọle tọ̀ mi lati fi mi ṣe ẹlẹyà: 18 O si ṣe, bi mo ti gbé ohùn mi soke ti mo si ké, o si jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá jade. 19 O si ṣe, nigbati oluwa rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ aya rẹ̀, ti o sọ fun u wipe, Bayibayi li ẹrú rẹ ṣe si mi; o binu gidigidi. 20 Oluwa Josefu si mú u, o si fi i sinu túbu, nibiti a gbé ndè awọn ara túbu ọba; o si wà nibẹ̀ ninu túbu. 21 Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josefu, o si ṣãnu fun u, o si fun u li ojurere li oju onitúbu. 22 Onitúbu si fi gbogbo awọn ara túbu ti o wà ninu túbu lé Josefu lọwọ; ohunkohun ti nwọn ba si ṣe nibẹ̀, on li oluṣe rẹ̀. 23 Onitúbu kò si bojuwò ohun kan ti o wà li ọwọ́ rẹ̀; nitori ti OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati ohun ti o ṣe OLUWA mú u dara.

Genesisi 40

Josẹfu Túmọ̀ Àlá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Meji

1 O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi, li agbọti ọba Egipti ati alasè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Egipti oluwa wọn. 2 Farao si binu si meji ninu awọn ijoye rẹ̀, si olori awọn agbọti, ati si olori awọn alasè. 3 O si fi wọn sinu túbu ninu ile olori ẹṣọ́, sinu túbu ti a gbé dè Josefu si. 4 Olori ẹṣọ́ na si fi Josefu jẹ́ olori wọn; o si nṣe itọju wọn: nwọn si pẹ diẹ ninu túbu na. 5 Awọn mejeji si lá alá kan, olukuluku lá alá tirẹ̀ li oru kanna, olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀, agbọti ati alasè ọba Egipti, ti a dè sinu túba na. 6 Josefu si wọle tọ̀ wọn lọ li owurọ̀, o si wò wọn, si kiyesi i, nwọn fajuro. 7 O si bi awọn ijoye Farao ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ile túbu oluwa rẹ̀ pe, Ẽṣe ti oju nyin fi buru bẹ̃ loni? 8 Nwọn si wi fun u pe, Awa lá alá, kò si sí onitumọ̀ rẹ̀. Josefu si wi fun wọn pe, Ti Ọlọrun ki itumọ̀ iṣe ndan? emi bẹ̀ nyin, ẹ rọ́ wọn fun mi. 9 Olori agbọti si rọ́ alá tirẹ̀ fun Josefu, o si wi fun u pe, Li oju alá mi, kiyesi i, àjara kan wà niwaju mi, 10 Ati lara àjara na li ẹka mẹta wà; o si rudi, itana rẹ̀ si tú jade; ati ṣiri rẹ̀ si so eso-ájara ti o pọ́n. 11 Ago Farao si wà li ọwọ́ mi: emi si mú eso-àjara na, mo si fún wọn sinu ago Farao, mo si fi ago na lé Farao lọwọ. 12 Josefu si wi fun u pe, Itumọ̀ rẹ̀ li eyi: ẹka mẹta nì, ijọ́ mẹta ni: 13 Ni ijọ́ mẹta oni, ni Farao yio gbe ori rẹ soke yio si mú ọ pada si ipò rẹ: iwọ o si fi ago lé Farao li ọwọ́ gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju nigbati iwọ ti iṣe agbọti rẹ̀. 14 Ṣugbọn ki o ranti mi nigbati o ba dara fun ọ, ki o si fi iṣeun rẹ hàn fun mi, emi bẹ̀ ọ, ki o si da orukọ mi fun Farao, ki o si mú mi jade ninu ile yi. 15 Nitõtọ jíji li a jí mi tà lati ilẹ awọn Heberu wá: ati nihinyi pẹlu, emi kò ṣe nkan ti nwọn fi fi mi sinu ihò-túbu yi. 16 Nigbati olori alasè ri pe itumọ̀ alá na dara, o si wi fun Josefu pe, Emi wà li oju-alá mi pẹlu, si kiyesi i, emi rù agbọ̀n àkara funfun mẹta li ori mi: 17 Ati ninu agbọ̀n ti o wà loke li onirũru onjẹ sisè wà fun Farao; awọn ẹiyẹ si njẹ ẹ ninu agbọ̀n na ti o wà li ori mi. 18 Josefu si dahún o si wipe, itumọ̀ rẹ̀ li eyi: agbọ̀n mẹta nì, ijọ́ mẹta ni. 19 Ni ijọ́ mẹta oni ni Farao yio gbé ori rẹ kuro lara rẹ, yio si so ọ rọ̀ lori igi kan; awọn ẹiyẹ yio si ma jẹ ẹran ara rẹ kuro lara rẹ. 20 O si ṣe ni ijọ́ kẹta, ti iṣe ọjọ́ ibí Farao, ti o sè àse fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ gbogbo: o si gbé ori olori agbọti soke ati ti olori awọn alasè lãrin awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. 21 O si tun mú olori agbọti pada si ipò rẹ̀; on si fi ago lé Farao li ọwọ́: 22 Ṣugbọn olori alasè li o sorọ̀: bi Josefu ti tumọ̀ alá na fun wọn. 23 Ṣugbọn olori agbọti kò ranti Josefu, o gbagbe rẹ̀.

Genesisi 41

Josẹfu Túmọ̀ Àlá Ọba

1 O SI ṣe li opin ọdún meji ṣanṣan, ni Farao lá alá: si kiyesi i, o duro li ẹba odo. 2 Si kiyesi i abo-malu meje, ti o dara ni wiwò, ti o sanra, jade lati inu odò na wá: nwọn si njẹ ninu ẽsu-odò. 3 Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o buru ni wiwò, ti o si rù, jade lẹhin wọn lati inu odò na wá; nwọn si duro tì awọn abo-malu nì ni bèbe odò na. 4 Awọn abo-malu ti o buru ni wiwò ti o si rù si mú awọn abo-malu meje ti o dara ni wiwò ti o si sanra wọnni jẹ. Bẹ̃ni Farao jí. 5 O si sùn, o si lá alá lẹrinkeji: si kiyesi i, ṣiri ọkà meje yọ lara igi ọkà kan, ti o kún ti o si dara. 6 Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje ti o fori, ti afẹfẹ íla-õrùn rẹ̀ dànu si rú jade lẹhin wọn. 7 Ṣiri meje ti o fori si mú ṣiri meje daradara ti o kún nì jẹ. Farao si jí, si kiyesi i, alá ni. 8 O si ṣe li owurọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò lelẹ; o si ranṣẹ o si pè gbogbo awọn amoye Egipti, ati gbogbo awọn ọ̀mọran ibẹ̀ wá: Farao si rọ́ alá rẹ̀ fun wọn: ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o le tumọ wọn fun Farao. 9 Nigbana li olori agbọti wi fun Farao pe, Emi ranti ẹ̀ṣẹ mi loni: 10 Farao binu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si fi mi sinu túbu ni ile-túbu olori ẹṣọ́, emi ati olori alasè: 11 Awa si lá alá li oru kanna, emi ati on; awa lá alá olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀. 12 Ọdọmọkunrin kan ara Heberu, ọmọ-ọdọ olori ẹṣọ́, si wà nibẹ̀ pẹlu wa; awa si rọ́ wọn fun u, o si tumọ̀ alá wa fun wa, o tumọ̀ fun olukuluku gẹgẹ bi alá tirẹ̀. 13 O si ṣe bi o ti tumọ̀ fun wa, bẹ̃li o si ri; emi li o mú pada si ipò iṣẹ mi, on li o si sorọ̀. 14 Nigbana ni Farao ranṣẹ o si pè Josefu, nwọn si yara mú u jade kuro ninu ihò-túbu; o si fari rẹ̀, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si tọ̀ Farao wá. 15 Farao sí wi fun Josefu pe, Emi lá alá, kò si si ẹnikan ti o le tumọ̀ rẹ̀: emi si gburó rẹ pe, bi iwọ ba gbọ́ alá, iwọ le tumọ̀ rẹ̀. 16 Josefu si da Farao li ohùn pe, Ki iṣe emi: Ọlọrun ni yio fi idahùn alafia fun Farao. 17 Farao si wi fun Josefu pe, Li oju-alá mi, kiyesi i, emi duro lori bèbe odò. 18 Si kiyesi i, abo-malu meje ti o sanra, ti o si dara lati wò, jade lati inu odò na wa; nwọn si njẹ ni ẽsu-odò: 19 Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o joro, ti o burujù ni wiwò, ti o si rù, jade soke lẹhin wọn, nwọn buru tobẹ̃ ti emi kò ri irú wọn rí ni ilẹ Egipti. 20 Awọn abo-malu ti o rù, ti nwọn si buru ni wiwò, nwọn mú awọn abo-malu meje sisanra iṣaju wọnni jẹ: 21 Nigbati nwọn si jẹ wọn tán, a kò le mọ̀ pe, nwọn ti jẹ wọn: nwọn si buru ni wiwò sibẹ̀ gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Bẹ̃ni mo jí. 22 Mo si ri li oju-alá mi, si kiyesi i, ṣiri ọkà meje jade lara igi ọkà kan, o kún o si dara: 23 Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje rirẹ̀, ti o si fori, ati ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu, o rú jade lẹhin wọn: 24 Awọn ṣiri ti o fori si mú awọn ṣiri rere meje nì jẹ; mo si rọ́ ọ fun awọn amoye; ṣugbọn kò sí ẹniti o le sọ ọ fun mi. 25 Josefu si wi fun Farao pe, Ọkan li alá Farao: Ọlọrun ti fi ohun ti on mbọ̀wá iṣe hàn fun Farao. 26 Awọn abo-malu daradara meje nì, ọdún meje ni: ati ṣiri daradara meje nì, ọdún meje ni: ọkan li alá na. 27 Ati awọn abo-malu meje nì ti o rù ti o si buru ni wiwò ti nwọn jade soke lẹhin wọn, ọdún meje ni; ati ṣiri ọkà meje ti o fori nì, ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu nì, ọdún meje ìyan ni yio jasi. 28 Eyi li ohun ti mo ti wi fun Farao pe, ohun ti Ọlọrun mbọ̀wá iṣe, o ti fihàn fun Farao. 29 Kiyesi i, ọdún meje ọ̀pọ mbọ̀ já gbogbo ilẹ Egipti: 30 Lẹhin wọn ọdún meje ìyan si mbọ̀; gbogbo ọ̀pọ nì li a o si gbagbe ni ilẹ Egipti; ìyan na yio si run ilẹ; 31 A ki yio si mọ̀ ọ̀pọ na mọ́ ni ilẹ nitori ìyan na ti yio tẹle e, nitori yio mú gidigidi. 32 Nitorina li alá na ṣe dìlu ni meji fun Farao; nitoripe lati ọdọ Ọlọrun li a ti fi idi ọ̀ran na mulẹ, Ọlọrun yio si mú u ṣẹ kánkan. 33 Njẹ nisisiyi, ki Farao ki o wò amoye ati ọlọgbọ́n ọkunrin kan, ki o si fi i ṣe olori ilẹ Egipti. 34 Ki Farao ki o ṣe eyi, ki o si yàn awọn alabojuto si ilẹ yi, ki nwọn ki o si gbà idamarun ni ilẹ Egipti li ọdún meje ọ̀pọ nì. 35 Ki nwọn ki o si kó gbogbo onjẹ ọdún meje rere nì ti o dé, ki nwọn ki o si tò ọkà jọ si ọwọ́ Farao, ki nwọn ki o si pa onjẹ mọ́ ni ilu wọnni. 36 Onjẹ na ni yio si ṣe isigbẹ fun ilẹ dè ọdún meje ìyan na, ti mbọ̀wá si ilẹ Egipti; ki ilẹ ki o má ba run nitori ìyan na.

Wọ́n fi Josẹfu Jẹ Alákòóso Ilẹ̀ Ijipti

37 Ohun na si dara li oju Farao, ati li oju gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. 38 Farao si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A ha le ri ẹnikan bi irú eyi, ọkunrin ti Ẹmi Ọlọrun mbẹ ninu rẹ̀? 39 Farao si wi fun Josefu pe, Niwọnbi Ọlọrun ti fi gbogbo nkan yi hàn ọ, kò sí ẹniti o ṣe amoye ati ọlọgbọ́n bi iwọ: 40 Iwọ ni yio ṣe olori ile mi, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ li a o si ma ṣe akoso awọn enia mi: itẹ́ li emi o fi tobi jù ọ lọ: 41 Farao si wi fun Josefu pe, Wò o, emi fi ọ jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti. 42 Farao si bọ́ oruka ọwọ́ rẹ̀ kuro, o si fi bọ̀ Josefu li ọwọ́, o si wọ̀ ọ li aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si fi ẹ̀wọn wurà si i li ọrùn; 43 O si mu u gùn kẹkẹ́ keji ti o ní; nwọn si nké niwaju rẹ̀ pe, Kabiyesi: o si fi i jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti. 44 Farao si wi fun Josefu pe, Emi ni Farao, lẹhin rẹ ẹnikẹni kò gbọdọ gbé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ soke ni gbogbo ilẹ Egipti. 45 Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti. 46 Josefu si jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nigbati o duro niwaju Farao ọba Egipti. Josefu si jade kuro niwaju Farao, o si là gbogbo ilẹ Egipti já. 47 Li ọdún meje ọ̀pọ nì, ilẹ si so eso ni ikunwọ-ikunwọ. 48 O si kó gbogbo onjẹ ọdún meje nì jọ, ti o wà ni ilẹ Egipti, o si fi onjẹ na ṣura ni ilu wọnni: onjẹ oko ilu ti o yi i ká, on li o kójọ sinu rẹ̀. 49 Josefu si kó ọkà jọ bi iyanrin okun lọ̀pọlọpọ; titi o fi dẹkun ati mã ṣirò; nitori ti kò ní iye. 50 A si bí ọmọkunrin meji fun Josefu, ki ọdún ìyan na ki o to dé, ti Asenati bí fun u, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. 51 Josefu si sọ orukọ akọ́bi ni Manasse: wipe, Nitori ti Ọlọrun mu mi gbagbe gbogbo iṣẹ́ mi, ati gbogbo ile baba mi. 52 Orukọ ekeji li o si sọ ni Efraimu: nitori Ọlọrun ti mu mi bisi i ni ilẹ ipọnju mi. 53 Ọdún meje ọ̀pọ na ti o wà ni ilẹ Egipti si pari. 54 Ọdún meje ìyan si bẹ̀rẹ si dé, gẹgẹ bi Josefu ti wi: ìyan na si mú ni ilẹ gbogbo; ṣugbọn ni gbogbo ilẹ Egipti li onjẹ gbé wà. 55 Nigbati ìyan mú ni gbogbo ilẹ Egipti, awọn enia kigbe onjẹ tọ̀ Farao: Farao si wi fun gbogbo awọn ara Egipti pe, Ẹ ma tọ̀ Josefu lọ; ohunkohun ti o ba wi fun nyin ki ẹ ṣe. 56 Ìyan na si wà lori ilẹ gbogbo: Josefu si ṣí gbogbo ile iṣura silẹ, o si ntà fun awọn ara Egipti; ìyan na si nmú si i ni ilẹ Egipti. 57 Ilẹ gbogbo li o si wá si Egipti lati rà onjẹ lọdọ Josefu; nitori ti ìyan na mú gidigidi ni ilẹ gbogbo.

Genesisi 42

Àwọn Arakunrin Josẹfu Lọ Ra Ọkà ní Ijipti

1 NIGBATI Jakobu si ri pe ọkà wà ni Egipti, Jakobu wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eṣe ti ẹnyin fi nwò ara nyin li oju? 2 O si wipe, Wò o, mo gbọ́ pe ọkà mbẹ ni Egipti: ẹ sọkalẹ lọ sibẹ̀, ki ẹ si rà fun wa lati ibẹ̀ wá; ki awa ki o le yè, ki a máṣe kú. 3 Awọn arakunrin Josefu mẹwẹwa si sọkalẹ lọ lati rà ọkà ni Egipti. 4 Ṣugbọn Jakobu kò rán Benjamini arakunrin Josefu pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; nitori ti o wipe, Ki ibi ki o má ba bá a. 5 Awọn ọmọ Israeli si wá irà ọkà ninu awọn ti o wá: nitori ìyan na mú ni ilẹ Kenaani. 6 Josefu li o si ṣe balẹ ilẹ na, on li o ntà fun gbogbo awọn enia ilẹ na; awọn arakunrin Josefu si wá, nwọn si tẹ̀ ori wọn ba fun u, nwọn dojubolẹ. 7 Josefu si ri awọn arakunrin rẹ̀, o si mọ̀ wọn, ṣugbọn o fi ara rẹ̀ ṣe àjeji fun wọn, o si sọ̀rọ akọ si wọn: o si wi fun wọn pe, Nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, Lati ilẹ Kenaani lati rà onjẹ. 8 Josefu si mọ̀ awọn arakunrin rẹ̀, ṣugbọn awọn kò mọ̀ ọ. 9 Josefu si ranti alá wọnni ti o ti lá si wọn, o si wi fun wọn pe, Amí li ẹnyin; lati ri ìhoho ilẹ yi li ẹnyin ṣe wá. 10 Nwọn si wi fun u pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, ṣugbọn lati rà onjẹ li awọn iranṣẹ rẹ ṣe wá. 11 Ọmọ ẹnikan na ni gbogbo wa iṣe; olõtọ enia li awa, awa iranṣẹ rẹ ki iṣe amí. 12 O si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn lati ri ìhoho ilẹ li ẹ ṣe wá. 13 Nwọn si wipe, Arakunrin mejila li awa iranṣẹ rẹ, ọmọ ẹnikan na ni ilẹ Kenaani: si wò o, eyi abikẹhin si wà lọdọ baba wa loni-oloni, ọkan kò si sí. 14 Josefu si wi fun wọn pe, On na li eyiti mo wi fun nyin pe, Amí li ẹnyin: 15 Eyi bayi li a o fi ridi nyin, nipa ẹmi Farao bi ẹnyin o ti lọ nihin, bikoṣepe arakunrin abikẹhin nyin wá ihinyi. 16 Ẹ rán ẹnikan ninu nyin, ki o si mú arakunrin nyin wá, a o si pa nyin mọ́ ninu túbu, ki a le ridi ọ̀rọ nyin, bi otitọ wà ninu nyin: bikoṣe bẹ̃, ẹmi Farao bi amí ki ẹnyin iṣe. 17 O si kó gbogbo wọn pọ̀ sinu túbu ni ijọ́ mẹta. 18 Josefu si wi fun wọn ni ijọ́ kẹta pe, Ẹ ṣe eyi ki ẹ si yè; nitori emi bẹ̀ru Ọlọrun. 19 Bi ẹnyin ba ṣe olõtọ enia, ki a mú ọkan ninu awọn arakunrin nyin dè ni ile túbu nyin: ẹ lọ, ẹ mú ọkà lọ nitori ìyan ile nyin. 20 Ṣugbọn ẹ mú arakunrin nyin abikẹhin fun mi wá; bẹ̃li a o si mọ̀ ọ̀rọ nyin li otitọ, ẹ ki yio si kú. Nwọn si ṣe bẹ̃. 21 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Awa jẹbi nitõtọ nipa ti arakunrin wa, niti pe, a ri àrokan ọkàn rẹ̀, nigbati o bẹ̀ wa, awa kò si fẹ́ igbọ́; nitorina ni iyọnu yi ṣe bá wa. 22 Reubeni si da wọn li ohùn pe, Emi kò wi fun nyin pe, Ẹ máṣe ṣẹ̀ si ọmọde na; ẹ kò si fẹ̀ igbọ́? si wò o, nisisiyi, a mbère ẹ̀jẹ rẹ̀. 23 Nwọn kò si mọ̀ pe Josefu gbède wọn; nitori gbedegbẹyọ li o fi mba wọn sọ̀rọ. 24 O si yipada kuro lọdọ wọn, o si sọkun; o si tun pada tọ̀ wọn wá, o si bá wọn sọ̀rọ, o si mú Ṣimeoni ninu wọn, o si dè e li oju wọn.

Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada sí Kenaani

25 Nigbana ni Josefu paṣẹ ki nwọn fi ọkà kún inu àpo wọn, ki nwọn si mú owo olukuluku pada sinu àpo rẹ̀, ki nwọn ki o si fun wọn li onjẹ ọ̀na; bayi li o si ṣe fun wọn. 26 Nwọn si dì ọkà lé kẹtẹkẹtẹ wọn, nwọn si lọ kuro nibẹ̀. 27 Bi ọkan ninu wọn si ti tú àpo rẹ̀ ni ile-èro lati fun kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ li onjẹ, o kofiri owo rẹ̀; si wò o, o wà li ẹnu àpo rẹ̀. 28 O si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Nwọn mú owo mi pada; si wò o, o tilẹ wà li àpo mi: àiya si fò wọn, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Kili eyiti Ọlọrun ṣe si wa yi? 29 Nwọn si dé ọdọ Jakobu baba wọn ni ilẹ Kenaani, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti o bá wọn fun u wipe, 30 Ọkunrin na ti iṣe oluwa ilẹ na, sọ̀rọ lile si wa, o si fi wa pè amí ilẹ na. 31 A si wi fun u pe, Olõtọ, enia li awa; awa ki iṣe amí: 32 Arakunrin mejila li awa, ọmọ baba wa; ọkan kò sí, abikẹhin si wà lọdọ baba wa ni ilẹ Kenaani loni-oloni. 33 Ọkunrin na, oluwa ilẹ na, si wi fun wa pe, Nipa eyi li emi o fi mọ̀ pe olõtọ enia li ẹnyin; ẹ fi ọkan ninu awọn arakunrin nyin silẹ lọdọ mi, ki ẹ si mú onjẹ nitori ìyan ile nyin, ki ẹ si ma lọ. 34 Ẹ si mú arakunrin nyin abikẹhin nì tọ̀ mi wá: nigbana li emi o mọ̀ pe ẹnyin ki iṣe amí, bikoṣe olõtọ enia: emi o si fi arakunrin nyin lé nyin lọwọ, ẹnyin o si ma ṣòwo ni ilẹ yi. 35 O si ṣe, bi nwọn ti ndà àpo wọn, wò o, ìdi owo olukuluku wà ninu àpo rẹ̀: nigbati awọn ati baba wọn si ri ìdi owo wọnni, ẹ̀ru bà wọn. 36 Jakobu baba wọn si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin gbà li ọmọ: Josefu kò sí; Simeoni kò si sí; ẹ si nfẹ́ mú Benjamini lọ: lara mi ni gbogbo nkan wọnyi pọ̀ si. 37 Reubeni si wi fun baba rẹ̀ pe, Pa ọmọ mi mejeji bi emi kò ba mú u fun ọ wá: fi i lé mi lọwọ, emi o si mú u pada fun ọ wá. 38 On si wipe, Ọmọ mi ki yio bá nyin sọkalẹ lọ; nitori arakunrin rẹ̀ ti kú, on nikan li o si kù: bi ibi ba bá a li ọ̀na ti ẹnyin nlọ, nigbana li ẹnyin o fi ibinujẹ mú ewú mi lọ si isà-okú.

Genesisi 43

Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada Lọ sí Ijipti pẹlu Bẹnjamini

1 ÌYAN na si mú ni ilẹ na gidigidi. 2 O si ṣe, nigbati nwọn jẹ ọkà ti nwọn ti múbọ̀ Egipti wá tán, baba wọn wi fun wọn pe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá. 3 Judah si wi fun u pe, ọkunrin na tẹnumọ́ ọ gidigidi fun wa pe, Ẹnyin kò gbọdọ ri oju mi, bikoṣepe arakunrin nyin ba pẹlu nyin. 4 Bi iwọ o ba rán arakunrin wa pẹlu wa, awa o sọkalẹ lọ lati rà onjẹ fun ọ: 5 Ṣugbọn bi iwọ ki yio ba rán a, awa ki yio sọkalẹ lọ: nitoriti ọkunrin na wi fun wa pe, Ẹnyin ki yio ri oju mi, bikoṣe arakunrin nyin ba pẹlu nyin. 6 Israeli si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi hùwa buburu bẹ̃ si mi, ti ẹnyin fi wi fun ọkunrin na pe, ẹnyin ní arakunrin kan pẹlu? 7 Nwọn si wipe, ọkunrin na bère timọtimọ niti awa tikara wa, ati niti ibatan wa, wipe, Baba nyin wà sibẹ̀? ẹnyin li arakunrin miran? awa si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi: awa o ti ṣe le mọ̀ daju pe yio wipe, Mú arakunrin nyin sọkalẹ wá? 8 Judah si wi fun Israeli baba rẹ̀ pe, Rán ọdọmọde na ba mi lọ, awa o si dide, a o lọ; ki awa ki o le yè, ki a má si ṣe kú, ati awa ati iwọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wa. 9 Emi ni yio ṣe onigbọwọ rẹ̀: li ọwọ́ mi ni iwọ o bère rẹ̀; bi emi kò ba mú u pada fun ọ wá, ki nsi mu u duro niwaju rẹ, njẹ emi ni yio rù ẹbi na lailai. 10 Bikoṣepe bi awa ti nṣe ilọra, awa iba sa ti pada bọ̀ lẹrinkeji nisisiyi. 11 Israeli baba wọn si wi fun wọn pe, Njẹ bi bẹ̃ ba ni, eyi ni ki ẹ ṣe, ẹ mú ninu ãyo eso ilẹ yi, sinu ohun-èlo nyin, ki ẹ si mú ọrẹ lọ fun ọkunrin na, ikunra diẹ, ati oyin diẹ, ati turari, ojia, eso pupa, ati eso almondi: 12 Ki ẹ si mú owo miran li ọwọ́ nyin; ati owo ti a mú pada wá li ẹnu àpo nyin, ẹ si tun mú u li ọwọ́ lọ; bọya o le ṣe èṣi: 13 Ẹ mú arakunrin nyin pẹlu, ẹ si dide, ẹ tun pada tọ̀ ọkunrin na lọ: 14 Ki Ọlọrun Olodumare ki o si fun nyin li ãnu niwaju ọkunrin na, ki o le rán arakunrin nyin ọhún wá, ati Benjamini. Bi a ba gbà mi li ọmọ, a gbà mi li ọmọ. 15 Awọn ọkunrin na si mú ọrẹ na, nwọn si mú iṣẹ́po owo meji li ọwọ́ wọn, ati Benjamini; nwọn si dide, nwọn si sọkalẹ lọ si Egipti, nwọn si duro niwaju Josefu. 16 Nigbati Josefu si ri Benjamini pẹlu wọn, o wi fun olori ile rẹ̀ pe, Mú awọn ọkunrin wọnyi rè ile, ki o si pa ẹran, ki o si pèse: nitori ti awọn ọkunrin wọnyi yio ba mi jẹun li ọjọkanri. 17 Ọkunrin na si ṣe bi Josefu ti wi; ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na lọ si ile Josefu. 18 Awọn ọkunrin na si mbẹ̀ru, nitori ti a mú wọn wá si ile Josefu; nwọn si wipe, Nitori owo ti a mú pada sinu àpo wa li akọ́wa li a ṣe mú wa wọle; ki o le fẹ wa lẹfẹ, ki o si le kọlù wa, ki o si le kó wa ṣe ẹrú ati awọn kẹtẹkẹtẹ wa. 19 Nwọn si sunmọ iriju ile Josefu, nwọn si bá a sọ̀rọ li ẹnu-ọ̀na ile na, 20 Nwọn si wipe, Alagba, nitõtọ li awa sọkalẹ wá ni iṣaju lati rà onjẹ: 21 O si ṣe, nigbati awa dé ile-èro, ti awa tú àpo wa, si kiyesi i, owo olukuluku wà li ẹnu àpo rẹ̀, owo wa ni pípe ṣánṣan: awa si tun mú u li ọwọ́ pada wá. 22 Owo miran li awa si mú li ọwọ́ wa sọkalẹ wá lati rà onjẹ: awa kò mọ̀ ẹniti o fi owo wa sinu àpo wa. 23 O si wi fun wọn pe, Alafia ni fun nyin, ẹ má bẹ̀ru: Ọlọrun nyin ati Ọlọrun baba nyin, li o fun nyin ni iṣura ninu àpo nyin: owo nyin dé ọwọ́ mi. O si mú Simeoni jade tọ̀ wọn wá. 24 Ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na wá si ile Josefu, o si fun wọn li omi, nwọn si wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; o si fun awọn kẹtẹkẹtẹ wọn li ohun jijẹ. 25 Nwọn si ti mú ọrẹ na silẹ dè atibọ̀ Josefu lọsán: nitori ti nwọn gbọ́ pe nwọn o jẹun nibẹ̀. 26 Nigbati Josefu si wọlé, nwọn si mú ọrẹ ti o wà li ọwọ́ wọn fun u wá sinu ile, nwọn si tẹriba fun u ni ilẹ. 27 On si bère alafia wọn, o si wipe, Alafia ki baba nyin wà, arugbo na ti ẹnyin wi? o wà lãye sibẹ̀? 28 Nwọn si dahun pe, Ara baba wa, iranṣẹ rẹ le, o wà sibẹ̀. Nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si bù ọlá fun u. 29 O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri Benjamini, aburo rẹ̀, ọmọ iya rẹ̀, o si wipe, Abikẹhin nyin na ti ẹnyin wi fun mi li eyi? o si wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe ojurere si ọ, ọmọ mi. 30 Josefu si yara; nitori ti inu yọ́ ọ si aburo rẹ̀: o wá ibi ti yio gbé sọkun; o si bọ́ si iyẹwu, o si sọkun nibẹ̀. 31 O si bọju rẹ̀, o si jade; o si mú oju dá, o si wipe, Ẹ gbé onjẹ kalẹ. 32 Nwọn si gbé tirẹ̀ kalẹ fun u lọ̀tọ, ati fun wọn lọ̀tọ, ati fun awọn ara Egipti ti o mbá a jẹun lọ̀tọ; nitori ti awọn ara Egipti kò gbọdọ bá awọn enia Heberu jẹun; nitori irira ni fun awọn ara Egipti. 33 Nwọn si joko niwaju rẹ̀, akọ́bi gẹgẹ bi ipò ibí rẹ̀, ati abikẹhin gẹgẹ bi ipò ewe rẹ̀: ẹnu si yà awọn ọkunrin na si ara wọn. 34 O si bù onjẹ fun wọn lati iwaju rẹ̀ lọ: ṣugbọn onjẹ Benjamini jù ti ẹnikẹni wọn lẹrinmarun. Nwọn si mu, nwọn si bá a ṣe ariya.

Genesisi 44

Ife Tí Ó Sọnù

1 O SI fi aṣẹ fun iriju ile rẹ̀, wipe, Fi onjẹ kún inu àpo awọn ọkunrin wọnyi, ìwọn ti nwọn ba le rù, ki o si fi owo olukuluku si ẹnu àpo rẹ̀. 2 Ki o si fi ago mi, ago fadaka nì, si ẹnu àpo abikẹhin, ati owo ọkà rẹ̀. O si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ ti Josefu ti sọ. 3 Bi ojúmọ si ti mọ́, a si rán awọn ọkunrin na lọ, awọn ati awọn kẹtẹkẹtẹ wọn. 4 Nigbati nwọn si jade kuro ni ilu na, ti nwọn kò si jìna, Josefu wi fun iriju rẹ̀ pe, Dide, lepa awọn ọkunrin na; nigbati iwọ ba si bá wọn, wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi fi buburu san rere? 5 Ninu eyi ki oluwa mi ima mu, eyiti o si fi nmọ̀ran? ẹnyin ṣe buburu li eyiti ẹnyin ṣe yi. 6 O si lé wọn bá, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn. 7 Nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti oluwa mi fi sọ irú ọ̀rọ wọnyi? Ki a má ri pe awọn ọmọ-ọdọ rẹ ṣe bi irú nkan wọnyi. 8 Kiyesi i, owo ti awa ri li ẹnu àpo wa, awa si tun mú pada fun ọ lati ilẹ Kenaani wá: bawo li awa o ṣe jí fadaka tabi wurà ninu ile oluwa rẹ? 9 Lọdọ ẹnikẹni ninu awọn iranṣẹ rẹ ti a ba ri i, ki o kú, ati awa pẹlu ki a di ẹrú oluwa mi. 10 O si wipe, Njẹ ki o si ri bẹ̃ gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin: ẹniti a ba ri i li ọwọ́ rẹ̀ on ni yio di ẹrú mi, ẹnyin o si ṣe alailẹṣẹ. 11 Nigbana ni olukuluku nwọn yara sọ̀ àpo rẹ̀ kalẹ, olukuluku nwọn si tú àpo rẹ̀. 12 O si nwá a kiri, o bẹ̀rẹ lati ẹgbọ́n wá, o si pin lọdọ abikẹhin: a si ri ago na ninu àpo Benjamini. 13 Nigbana ni nwọn fà aṣọ wọn ya olukuluku si dì ẹrù lé kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilu. 14 Ati Judah ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si ile Josefu; on sa wà nibẹ̀: nwọn si wolẹ niwaju rẹ̀. 15 Josefu si wi fun wọn pe, Iwa kili eyiti ẹnyin hù yi? ẹnyin kò mọ̀ pe irú enia bi emi a ma mọ̀ran nitõtọ? 16 Judah si wipe, Kili a o wi fun oluwa mi? kili a o fọ̀? tabi awa o ti ṣe wẹ̀ ara wa mọ́? Ọlọrun ti hú ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jade: wò o, awa di ẹrú oluwa mi, ati awa, ati ẹniti a ri ago na li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu. 17 On si wipe, Ki a má ri pe emi o ṣe bẹ̃: ṣugbọn ọkunrin na li ọwọ́ ẹniti a ri ago na, on ni yio ṣe ẹrú mi; bi o ṣe ti ẹnyin, ẹ goke tọ̀ baba nyin lọ li alafia.

Juda Bẹ̀bẹ̀ fún Ìdásílẹ̀ Bẹnjamini

18 Nigbana ni Judah sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o sọ gbolohùn ọ̀rọ kan li eti oluwa mi, ki o máṣe binu si iranṣẹ rẹ; bi Farao tikalarẹ̀ ni iwọ sá ri. 19 Oluwa mi bère lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, wipe, Ẹnyin ní baba, tabi arakunrin bi? 20 Awa si wi fun oluwa mi pe, Awa ní baba, arugbo, ati ọmọ kan li ogbologbo rẹ̀, abikẹhin; arakunrin rẹ̀ si kú, on nikanṣoṣo li o si kù li ọmọ iya rẹ̀, baba rẹ̀ si fẹ́ ẹ. 21 Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Mú u sọkalẹ tọ̀ mi wá, ki emi ki o le fi oju mi kàn a. 22 Awa si wi fun oluwa mi pe, Ọdọmọde na kò le fi baba rẹ̀ silẹ: nitoripe bi o ba fi i silẹ, baba rẹ̀ yio kú. 23 Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Ayaṣebi arakunrin nyin abikẹhin ba bá nyin sọkalẹ wá, ẹnyin ki yio ri oju mi mọ́. 24 O si ṣe nigbati awa goke tọ̀ baba mi iranṣẹ rẹ lọ, awa sọ̀rọ oluwa mi fun u. 25 Baba wa si wipe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá. 26 Awa si wipe, Awa kò le sọkalẹ lọ: bi arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa, njẹ awa o sọkalẹ lọ; nitori ti awa ki o le ri oju ọkunrin na, bikoṣepe arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa. 27 Baba mi iranṣẹ rẹ si wi fun wa pe Ẹnyin mọ̀ pe aya mi bí ọmọ meji fun mi: 28 Ọkan si ti ọdọ mi jade lọ, mo si wipe, Nitõtọ a fà a ya pẹrẹpẹrẹ; emi kò si ri i lati igbana wá: 29 Bi ẹnyin ba si mú eyi lọ lọwọ mi pẹlu, ti ibi kan si ṣe e, ibinujẹ li ẹnyin o fi mú ewú mi lọ si isà-okú. 30 Njẹ nisisiyi, nigbati mo ba dé ọdọ baba mi, iranṣẹ rẹ, ti ọmọde na kò si wà pẹlu wa; bẹ̃ni ẹmi rẹ̀ dìmọ́ ẹmi ọmọde na; 31 Yio si ṣe, bi o ba ri pe ọmọde na kò pẹlu wa, yio kú: awọn iranṣẹ rẹ yio si fi ibinujẹ mú ewú baba wa iranṣẹ rẹ lọ si isà-okú. 32 Nitori iranṣẹ rẹ li o ṣe onigbọwọ ọmọde na fun baba mi wipe, Bi emi kò ba mú u tọ̀ ọ wá, emi ni o gbà ẹbi na lọdọ baba mi lailai. 33 Njẹ nisisiyi emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o joko ni ipò ọmọde na li ẹrú fun oluwa mi; ki o si jẹ ki ọmọde na ki o bá awọn arakunrin rẹ̀ goke lọ. 34 Nitori bi bawo li emi o fi goke tọ̀ baba mi lọ ki ọmọde na ki o ma wà pẹlu mi? ki emi má ba ri ibi ti mbọ̀wá bá baba mi.

Genesisi 45

Josẹfu Farahan Àwọn Arakunrin Rẹ̀

1 NIGBANA ni Josefu kò le mu oju dá mọ́ niwaju gbogbo awọn ti o duro tì i; o si kigbe pe, Ẹ mu ki gbogbo enia ki o jade kuro lọdọ mi. Ẹnikẹni kò si duro tì i, nigbati Josefu sọ ara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀. 2 O si sọkun kikan: ati awọn ara Egipti ati awọn ara ile Farao gbọ́. 3 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi ni Josefu; baba mi wà sibẹ̀? awọn arakunrin rẹ̀ kò si le da a lohùn; nitori ti ẹ̀ru bà wọn niwaju rẹ̀. 4 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi bẹ̀ nyin ẹ sunmọ ọdọ mi. Nwọn si sunmọ ọ. O si wi pe, Emi ni Josefu, arakunrin nyin, ti ẹnyin tà si Egipti. 5 Njẹ nisisiyi, ẹ máṣe binujẹ, ki ẹ má si ṣe binu si ara nyin, ti ẹnyin tà mi si ihin: nitori pe, Ọlọrun li o rán mi siwaju nyin lati gbà ẹmi là. 6 Lati ọdún meji yi ni ìyan ti nmú ni ilẹ: o si tun kù ọdún marun si i, ninu eyiti a ki yio ni itulẹ tabi ikorè. 7 Ọlọrun si rán mi siwaju nyin lati da irú-ọmọ si fun nyin lori ilẹ, ati lati fi ìgbala nla gbà ẹmi nyin là. 8 Njẹ nisisiyi, ki iṣe ẹnyin li o rán mi si ihin, bikoṣe Ọlọrun: o si ti fi mi ṣe baba fun Farao, ati oluwa gbogbo ile rẹ̀, ati alakoso gbogbo ilẹ Egipti. 9 Ẹ yara ki ẹ si goke tọ̀ baba mi lọ, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi ni Josefu ọmọ rẹ wipe, Ọlọrun fi mi jẹ́ oluwa gbogbo Egipti: sọkalẹ tọ̀ mi wá, má si ṣe duro. 10 Iwọ o si joko ni ilẹ Goṣeni, iwọ o si wà leti ọdọ mi, iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ, ati ọwọ-ẹran rẹ, ati ọwọ́-malu rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní. 11 Nibẹ̀ li emi o si ma bọ́ ọ; nitori ọdún ìyan kù marun si i; ki iwọ, ati awọn ara ile rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní, ki o má ba ri ipọnju. 12 Si kiyesi i, oju nyin, ati oju Benjamini arakunrin mi ri pe, ẹnu mi li o nsọ̀rọ fun nyin. 13 Ki ẹnyin ki o si ròhin gbogbo ogo mi ni Egipti fun baba mi, ati ti ohun gbogbo ti ẹnyin ri; ki ẹnyin ki o si yara, ki ẹ si mú baba mi sọkalẹ wá ihin. 14 O si rọ̀mọ́ Benjamini arakunrin rẹ̀ li ọrùn, o si sọkun; Benjamini si sọkun li ọrùn rẹ̀. 15 O si fi ẹnu kò gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li ẹnu, o si sọkun si wọn lara: lẹhin eyini li awọn arakunrin rẹ̀ bá a sọ̀rọ. 16 A si gbọ́ ìhin na ni ile Farao pe, awọn arakunrin Josefu dé: o si dùn mọ́ Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀. 17 Farao si wi fun Josefu pe, Wi fun awọn arakunrin rẹ, Eyi ni ki ẹ ṣe; ẹ dì ẹrù lé ẹranko nyin, ki ẹ si lọ si ilẹ Kenaani; 18 Ẹ si mú baba nyin, ati awọn ara ile nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá; emi o si fun nyin li ohun rere ilẹ Egipti, ẹnyin o si ma jẹ ọrá ilẹ yi. 19 Njẹ a fun ọ li aṣẹ, eyi ni ki ẹ ṣe; ẹ mú kẹkẹ́-ẹrù lati ilẹ Egipti fun awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati fun awọn aya nyin, ki ẹ si mú baba nyin, ki ẹ si wá. 20 Ẹ má si ṣe aniyàn ohun-èlo; nitori ohun rere gbogbo ilẹ Egipti ti nyin ni. 21 Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃: Josefu si fi kẹkẹ́-ẹrù fun wọn, gẹgẹ bi aṣẹ Farao, o si fi onjẹ ọ̀na fun wọn. 22 O fi ìparọ-aṣọ fun gbogbo wọn fun olukuluku wọn; ṣugbọn Benjamini li o fi ọdunrun owo fadaka fun, ati ìparọ-aṣọ marun. 23 Bayi li o si ranṣẹ si baba rẹ̀; kẹtẹkẹtẹ mẹwa ti o rù ohun rere Egipti, ati abo-kẹtẹkẹtẹ mẹwa ti o rù ọkà ati àkara ati onjẹ fun baba rẹ̀ li ọ̀na. 24 Bẹ̃li o rán awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si lọ: o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe jà li ọ̀na. 25 Nwọn si goke lati ilẹ Egipti lọ, nwọn si dé ọdọ Jakobu baba wọn ni ilẹ Kenaani. 26 Nwọn si wi fun u pe, Josefu mbẹ lãye sibẹ̀, on si ni bãlẹ gbogbo ilẹ Egipti. O si rẹ̀ Jakobu dé inu nitori ti kò gbà wọn gbọ́. 27 Nwọn si sọ ọ̀rọ Josefu gbogbo fun u, ti o wi fun wọn: nigbati o si ri kẹkẹ́-ẹrù ti Josefu rán wá lati fi mú u lọ, ọkàn Jakobu baba wọn sọji: 28 Israeli si wipe, O tó; Josefu ọmọ mi mbẹ lãye sibẹ̀; emi o lọ ki nsi ri i ki emi ki o to kú.

Genesisi 46

Jakọbu ati Ìdílé Rẹ̀ Lọ sí Ijipti

1 ISRAELI si mú ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n ti on ti ohun gbogbo ti o ní, o si dé Beer-ṣeba, o si rú ẹbọ si Ọlọrun Isaaki baba rẹ̀. 2 Ọlọrun si bá Israeli sọ̀rọ li ojuran li oru, o si wipe, Jakobu, Jakobu. O si wipe, Emi niyi. 3 O si wipe, Emi li Ọlọrun, Ọlọrun baba rẹ: má bẹ̀ru lati sọkalẹ lọ si ilẹ Egipti; nitori ibẹ̀ li emi o gbé sọ iwọ di orilẹ-ède nla. 4 Emi o si bá ọ sọkalẹ lọ si Egipti; emi o si mú ọ goke wá nitõtọ: Josefu ni yio si fi ọwọ́ rẹ̀ pa ọ li oju dé. 5 Jakobu si dide lati Beer-ṣeba lọ: awọn ọmọ Israeli si mú Jakobu baba wọn lọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wọn, ati awọn aya wọn, ninu kẹkẹ́-ẹrù ti Farao rán lati mú u lọ. 6 Nwọn si mú ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ti nwọn ní ni ilẹ Kenaani, nwọn si wá si Egipti, Jakobu, ati gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: 7 Awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin awọn ọmọ rẹ̀, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ li o mú pẹlu rẹ̀ wá si ilẹ Egipti. 8 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti, Jakobu ati awọn ọmọ rẹ̀: Reubeni, akọ́bi Jakobu. 9 Ati awọn ọmọ Reubeni; Hanoku, ati Pallu, ati Hesroni, ati Karmi. 10 Ati awọn ọmọ Simeoni; Jemueli, ati Jamini, ati Ohadi, ati Jakini, ati Sohari, ati Ṣaulu, ọmọ obinrin ara Kenaani kan. 11 Ati awọn ọmọ Lefi; Gerṣoni, Kohati, ati Merari. 12 Ati awọn ọmọ Judah; Eri ati Onani, ati Ṣela, ati Peresi, ati Sera: ṣugbọn Eri on Onani ti kú ni ilẹ Kenaani. Ati awọn ọmọ Peresi ni Hesroni on Hamulu. 13 Ati awọn ọmọ Issakari; Tola, ati Pufa, ati Jobu, ati Simroni. 14 Ati awọn ọmọ Sebuluni; Seredi, ati Eloni, ati Jaleeli. 15 Awọn wọnyi li awọn ọmọ Lea, ti o bí fun Jakobu ni Padan-aramu, pẹlu Dina ọmọbinrin rẹ̀: gbogbo ọkàn awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, o jẹ́ mẹtalelọgbọ̀n. 16 Ati awọn ọmọ Gadi; Sifioni, ati Haggi, Ṣuni, ati Esboni, Eri, ati Arodi, ati Areli. 17 Ati awọn ọmọ Aṣeri; Jimna, ati Iṣua, ati Isui, ati Beria, ati Sera arabinrin wọn: ati awọn ọmọ Beria; Heberi, ati Malkieli. 18 Wọnyi li awọn ọmọ Silpa, ti Labani fi fun Lea ọmọbinrin rẹ̀, wọnyi li o si bí fun Jakobu, ọkàn mẹrindilogun. 19 Awọn ọmọ Rakeli aya Jakobu; Josefu ati Benjamini. 20 Manasse ati Efraimu li a si bí fun Josefu ni ilẹ Egipti, ti Asenati ọmọbinrin Potifera alufa Oni bí fun u. 21 Ati awọn ọmọ Benjamini; Bela, ati Bekeri, ati Aṣbeli, Gera, ati Naamani, Ehi, ati Roṣi, Muppimu, ati Huppimu, ati Ardi. 22 Wọnyi li awọn ọmọ Rakeli, ti a bí fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ mẹrinla. 23 Ati awọn ọmọ Dani; Huṣimu. 24 Ati awọn ọmọ Naftali; Jahseeli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣillemu. 25 Wọnyi si li awọn ọmọ Bilha, ti Labani fi fun Rakeli ọmọbinrin rẹ̀, o si bí wọnyi fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ meje. 26 Gbogbo ọkàn ti o ba Jakobu wá si Egipti, ti o si ti inu Jakobu jade, li àika aya awọn ọmọ Jakobu, ọkàn na gbogbo jẹ́ mẹrindilãdọrin; 27 Ati awọn ọmọ Josefu ti a bí fun u ni Egipti jẹ́ ọkàn meji; gbogbo ọkàn ile Jakobu, ti o wá si ilẹ Egipti jẹ́ ãdọrin ọkàn.

Jakọbu ati Ìdílé Rẹ̀ ní Ijipti

28 O si rán Judah siwaju rẹ̀ si Josefu ki o kọju wọn si Goṣeni; nwọn si dé ilẹ Goṣeni. 29 Josefu si dì kẹkẹ́ rẹ̀, o si lọ si Goṣeni lọ ipade Israeli baba rẹ̀, o si fi ara rẹ̀ hàn a; on si rọ̀ mọ́ ọ li ọrùn, o si sọkun si i li ọrùn pẹ titi. 30 Israeli si wi fun Josefu pe, Jẹ ki emi ki o kú wayi, bi mo ti ri oju rẹ yi, nitori ti iwọ wà lãye sibẹ̀. 31 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀, ati fun awọn ara ile baba rẹ̀ pe, Emi o goke lọ, emi o si sọ fun Farao, emi o si wi fun u pe, Awọn arakunrin mi, ati awọn ara ile baba mi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, nwọn tọ̀ mi wá; 32 Oluṣọ-agutan si li awọn ọkunrin na, ẹran sisìn ni iṣẹ wọn; nwọn si dà agbo-ẹran ati ọwọ́-ẹran wọn wá, ati ohun gbogbo ti nwọn ní. 33 Yio si ṣe, nigbati Farao ba pè nyin, ti yio si bi nyin pe, Kini iṣẹ nyin? 34 Ki ẹnyin ki o wipe, Òwo awọn iranṣẹ rẹ li ẹran sisìn lati ìgba ewe wa wá titi o fi di isisiyi, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu: ki ẹnyin ki o le joko ni ilẹ Goṣeni; nitori irira li oluṣọ-agutan gbogbo si awọn ara Egipti.

Genesisi 47

1 NIGBANA ni Josefu wọle, o si sọ fun Farao, o si wipe, Baba mi, ati awọn arakunrin mi ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ati ohun gbogbo ti nwọn ní, nwọn ti ilẹ Kenaani wá; si kiyesi i, nwọn mbẹ ni ilẹ Goṣeni. 2 O si mú marun ninu awọn arakunrin rẹ̀, o si mu wọn duro niwaju Farao. 3 Farao si bi awọn arakunrin rẹ̀ pe, Kini iṣẹ nyin? Nwọn si wi fun Farao pe, Oluṣọ-agutan li awọn iranṣẹ rẹ, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu. 4 Nwọn si wi fun Farao pẹlu pe, Nitori ati ṣe atipo ni ilẹ yi li awa ṣe wá; nitori awọn iranṣẹ rẹ kò ní papa-oko tutù fun ọwọ́-ẹran wọn; nitori ti ìyan yi mú gidigidi ni ilẹ Kenaani: njẹ nitorina awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awọn iranṣẹ rẹ ki o joko ni ilẹ Goṣeni. 5 Farao si wi fun Josefu pe, Baba rẹ ati awọn arakunrin rẹ tọ̀ ọ wá: 6 Ilẹ Egipti ni yi niwaju rẹ; ninu ãyo ilẹ ni ki o mu baba ati awọn arakunrin rẹ joko; jẹ ki nwọn ki o joko ni ilẹ Goṣeni: bi iwọ ba si mọ̀ ẹnikẹni ti o li ãpọn ninu wọn, njẹ ki iwọ ki o ṣe wọn li olori lori ẹran-ọsin mi. 7 Josefu si mú Jakobu baba rẹ̀ wọle wá, o si mu u duro niwaju Farao: Jakobu si sure fun Farao. 8 Farao si bi Jakobu pe, Ọdún melo li ọjọ́ aiye rẹ? 9 Jakobu si wi fun Farao pe, Ãdoje ọdún li ọjọ́ atipo mi: diẹ ti on ti buburu li ọdún ọjọ́ aiye mi jẹ́, nwọn kò si ti idé ọdún ọjọ́ aiye awọn baba mi li ọjọ́ atipo wọn. 10 Jakobu si sure fun Farao, o si jade kuro niwaju Farao. 11 Josefu si fi baba rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ joko, o si fun wọn ni iní ni ilẹ Egipti, ni ibi ãyo ilẹ, ni ilẹ Ramesesi, bi Farao ti pa li aṣẹ. 12 Josefu si fi onjẹ bọ́ baba rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ile baba rẹ̀ gẹgẹ bi iye awọn ọmọ wọn.

Àkókò Ìyàn

13 Onjẹ kò si sí ni gbogbo ilẹ; nitori ti ìyan na mú gidigidi, tobẹ̃ ti ilẹ Egipti ati gbogbo ilẹ Kenaani gbẹ nitori ìyan na. 14 Josefu si kó gbogbo owo ti a ri ni ilẹ Egipti ati ni ilẹ Kenaani jọ, fun ọkà ti nwọn rà: Josefu si kó owo na wá si ile Farao. 15 Nigbati owo si tán ni ilẹ Egipti, ati ni ilẹ Kenaani, gbogbo awọn ara Egipti tọ̀ Josefu wá, nwọn si wipe, Fun wa li onjẹ: nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ? owo sa tán. 16 Josefu si wipe, Ẹ mú ẹran nyin wá, emi o si fun nyin li onjẹ dipò ẹran nyin, bi owo ba tán. 17 Nwọn si mú ẹran wọn tọ̀ Josefu wá: Josefu si fun wọn li onjẹ dipò ẹṣin, ati ọwọ́-ẹran, ati dipò ọwọ́-malu, ati kẹtẹkẹtẹ: o si fi onjẹ bọ́ wọn dipò gbogbo ẹran wọn li ọdún na. 18 Nigbati ọdún na si pari, nwọn si tọ̀ ọ wá li ọdún keji, nwọn si wi fun u pe, Awa ki yio pa a mọ́ lọdọ oluwa mi, bi a ti ná owo wa tán; ẹran-ọ̀sin si ti di ti oluwa mi; kò si sí nkan ti o kù li oju oluwa mi, bikoṣe ara wa, ati ilẹ wa: 19 Nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ, ati awa ati ilẹ wa? fi onjẹ rà wa ati ilẹ wa, ati awa ati ilẹ wa yio ma ṣe ẹrú Farao: ki o si fun wa ni irugbìn, ki awa ki o le yè, ki a má kú, ki ilẹ ki o má ṣe di ahoro. 20 Bẹ̃ni Josefu rà gbogbo ilẹ Egipti fun Farao; nitori olukuluku awọn ara Egipti li o tà oko rẹ̀, nitori ti ìyan na mú wọn: ilẹ si di ti Farao. 21 Bi o si ṣe ti awọn enia ni, o ṣí wọn si ilu, lati opin ilẹ kan ni Egipti dé opin ilẹ keji. 22 Kìki ilẹ awọn alufa ni kò rà; nitori ti awọn alufa ní ipín ti wọn lati ọwọ́ Farao wá, nwọn si njẹ ipín wọn ti Farao fi fun wọn; nitorina ni nwọn kò fi tà ilẹ wọn. 23 Nigbana ni Josefu wi fun awọn enia pe, Kiyesi i, emi ti rà nyin loni ati ilẹ nyin fun Farao: wò o, irugbìn niyi fun nyin, ki ẹnyin ki o si gbìn ilẹ na. 24 Yio si se, ni ikore ki ẹnyin ki o fi ida-marun fun Farao, ọ̀na mẹrin yio jẹ́ ti ara nyin fun irugbìn oko, ati fun onjẹ nyin, ati fun awọn ara ile nyin, ati onjẹ fun awọn ọmọ nyin wẹrẹ. 25 Nwọn si wipe, Iwọ ti gbà ẹmi wa là: ki awa ki o ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi, awa o si ma ṣe ẹrú Farao. 26 Josefu si ṣe e ni ilana ni ilẹ Egipti titi di oni-oloni pe, Farao ni yio ma ní idamarun; bikoṣe ilẹ awọn alufa nikan ni kò di ti Farao.

Ẹ̀bẹ̀ tí Jakọbu Bẹ̀ kẹ́yìn

27 Israeli si joko ni ilẹ Egipti, ni ilẹ Goṣeni; nwọn si ní iní nibẹ̀, nwọn bísi i, nwọn si rẹ̀ gidigidi. 28 Jakobu si wà li ọdún mẹtadilogun ni ilẹ Egipti; gbogbo ọjọ́ aiye Jakobu si jẹ́ ãdọjọ ọdún o di mẹta: 29 Akokò Israeli si sunmọ-etile ti yio kú: o si pè Josefu ọmọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bi emi ba ri ojurere li oju rẹ, jọ̃, fi ọwọ́ rẹ si abẹ itan mi, ki o si ṣe ãnu ati otitọ fun mi; emi bẹ̀ ọ, máṣe sin mi ni Egipti. 30 Ṣugbọn nigbati emi ba sùn pẹlu awọn baba mi, iwọ o gbe mi jade ni Egipti, ki o si sin mi ni iboji wọn. On si wipe, Emi o ṣe bi iwọ ti wi. 31 O si wipe, Bura fun mi. On si bura fun u. Israeli si tẹriba lori akete.

Genesisi 48

Jakọbu Súre fún Efuraimu ati Manase

1 O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi ni ẹnikan wi fun Josefu pe, Kiyesi i, ara baba rẹ kò dá: o si mú awọn ọmọ rẹ̀ mejeji, Manasse ati Efraimu pẹlu rẹ̀. 2 Ẹnikan si sọ fun Jakobu, o si wipe, Kiyesi i, Josefu ọmọ rẹ tọ̀ ọ wá: Israeli si gbiyanju, o si joko lori akete. 3 Jakobu si wi fun Josefu pe, Ọlọrun Olodumare farahàn mi ni Lusi ni ilẹ Kenaani, o si sure fun mi, 4 O si wi fun mi pe, Kiyesĩ, Emi o mu ọ bisi i, Emi o mu ọ rẹ̀, Emi o si sọ ọ di ọ̀pọlọpọ enia; Emi o si fi ilẹ yi fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iní titi aiye. 5 Njẹ nisisiyi Efraimu ati Manasse, awọn ọmọ rẹ mejeji ti a bí fun ọ ni ilẹ Egipti, ki emi ki o tó tọ̀ ọ wá ni Egipti, ti emi ni nwọn: bi Reubeni on Simeoni, bẹ̃ni nwọn o jẹ́ ti emi. 6 Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ ti iwọ bí lẹhin wọn ni yio ṣe tirẹ, a o si ma pè wọn li orukọ awọn arakunrin wọn ni ilẹ iní wọn. 7 Ati emi, nigbati mo ti Paddani wá, Rakeli kú lọwọ mi ni ilẹ Kenaani li ọ̀na, nigbati o kù diẹ ti a ba fi dé Efrati: emi si sin i nibẹ̀ li ọ̀na Efrati (eyi na ni Betlehemu). 8 Israeli si wò awọn ọmọ Josefu, o si bère pe, Tani wọnyi? 9 Josefu wi fun baba rẹ̀ pe, Awọn ọmọ mi ni, ti Ọlọrun fifun mi nihinyi. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mú wọn wá sọdọ mi, emi o si sure fun wọn. 10 Njẹ oju Israeli ṣú baìbai nitori ogbó, kò le riran. On si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀: o si fi ẹnu kò wọn li ẹnu, o si gbá wọn mọra. 11 Israeli si wi fun Josefu pe, Emi kò dába ati ri oju rẹ mọ́: si kiyesi i, Ọlọrun si fi irú-ọmọ rẹ hàn mi pẹlu. 12 Josefu si mú wọn kuro li ẽkun rẹ̀, o si tẹriba, o dà oju rẹ̀ bolẹ. 13 Josefu si mú awọn mejeji, Efraimu li ọwọ́ ọtún rẹ̀ si ọwọ́ òsi Israeli, ati Manasse lọwọ òsi rẹ̀, si ọwọ́ ọtún Israeli, o si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀. 14 Israeli si nà ọwọ́ ọtún rẹ̀, o si fi lé Efraimu ẹniti iṣe aburo li ori, ati ọwọ́ òsi rẹ̀ lé ori Manasse, o mọ̃mọ̀ mu ọwọ́ rẹ̀ lọ bẹ̃: nitori Manasse ni iṣe akọ́bi. 15 O si sure fun Josefu, o si wipe, Ọlọrun, niwaju ẹniti Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi rìn, Ọlọrun na ti o bọ́ mi lati ọjọ́ aiye mi titi di oni, 16 Angeli na ti o dá mi ni ìde kuro ninu ibi gbogbo, ki o gbè awọn ọmọde wọnyi; ki a si pè orukọ mi mọ́ wọn lara, ati orukọ Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi; ki nwọn ki o si di ọ̀pọlọpọ lãrin aiye. 17 Nigbati Josefu ri pe baba rẹ̀ fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ lé Efraimu lori, inu rẹ̀ kò dùn: o si mú baba rẹ̀ li ọwọ́, lati ṣí i kuro li ori Efraimu si ori Manasse. 18 Josefu si wi fun baba rẹ̀ pe, Bẹ̃kọ, baba mi: nitori eyi li akọ́bi; fi ọwọ́ ọtún rẹ lé e li ori. 19 Baba rẹ̀ si kọ̀, o si wipe, Emi mọ̀, ọmọ mi, emi mọ̀: on pẹlu yio di enia, yio si pọ̀ pẹlu: ṣugbọ́n nitõtọ aburo rẹ̀ yio jù u lọ, irú-ọmọ rẹ̀ yio si di ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède. 20 O si sure fun wọn li ọjọ́ na pe, Iwọ ni Israeli o ma fi sure, wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe nyin bi Efraimu on Manasse: bẹ̃li o fi Efraimu ṣaju Manasse. 21 Israeli si wi fun Josefu pe, Wò o, emi kú: ṣugbọn Ọlọrun yio wà pẹlu nyin, yio si tun mú nyin lọ si ilẹ awọn baba nyin. 22 Pẹlupẹlu, emi si fi ilẹ-biri kan fun ọ jù awọn arakunrin rẹ lọ, ti mo fi idà ti on ti ọrun mi gbà lọwọ awọn enia Amori.

Genesisi 49

Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Jakọbu

1 JAKOBU si pè awọn ọmọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ kó ara nyin jọ, ki emi ki o le wi ohun ti yio bá nyin lẹhin-ọla fun nyin. 2 Ẹ kó ara nyin jọ, ki ẹ si gbọ́, ẹnyin ọmọ Jakobu; ki ẹ si fetisi ti Israeli baba nyin. 3 Reubeni, iwọ li akọ́bi mi, agbara mi, ati ipilẹṣẹ ipá mi, titayọ ọlá, ati titayọ agbara. 4 Ẹnirirú bi omi, iwọ ki yio le tayọ; nitori ti iwọ gùn ori ẹni baba rẹ; iwọ si bà a jẹ́: o gùn ori akete mi. 5 Simeoni on Lefi, arakunrin ni nwọn; ohun-èlo ìka ni idà wọn. 6 Ọkàn mi, iwọ máṣe wọ̀ ìmọ wọn; ninu ajọ wọn, ọlá mi, máṣe bá wọn dàpọ; nitoripe, ni ibinu wọn nwọn pa ọkunrin kan, ati ni girimakayi wọn, nwọn já malu ni patì. 7 Ifibú ni ibinu wọn, nitori ti o rorò; ati ikannu wọn, nitori ti o ní ìka: emi o pin wọn ni Jakobu, emi o si tú wọn ká ni Israeli. 8 Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ́ rẹ yio wà li ọrùn awọn ọtá rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ. 9 Ọmọ kiniun ni Judah; ọmọ mi, ni ibi-ọdẹ ni iwọ ti goke: o bẹ̀rẹ, o ba bi kiniun, ati bi ogbó kiniun; tani yio lé e dide? 10 Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀. 11 Yio ma so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ ara àjara, ati ọmọ kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ mọ́ ara ãyo àjara; o ti fọ̀ ẹ̀wu rẹ̀ ninu ọtí-waini, ati aṣọ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ eso àjara: 12 Oju rẹ̀ yio pọ́n fun ọtí-waini, ehín rẹ̀ yio si funfun fun wàra. 13 Sebuloni ni yio ma gbé ebute okun: on ni yio si ma wà fun ebute ọkọ̀; ipinlẹ rẹ̀ yio si dé Sidoni. 14 Issakari ni kẹtẹkẹtẹ ti o lera, ti o dubulẹ lãrin awọn agbo-agutan. 15 O si ri pe isimi dara, ati ilẹ na pe o wuni; o si tẹ̀ ejiká rẹ̀ lati rẹrù, on si di ẹni nsìnrú. 16 Dani yio ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, bi ọkan ninu awọn ẹ̀ya Israeli. 17 Dani yio dabi ejò li ẹba ọ̀na, bi paramọlẹ li ọ̀na, ti ibù ẹṣin ṣán ni gigĩsẹ, tòbẹ̃ ti ẹniti o gùn u yio fi ṣubu sẹhin. 18 Emi ti duro dè ìgbala rẹ, OLUWA! 19 Gadi ọwọ́-ogun ni yio kọlù u: ṣugbọn on lé wọn. 20 Lati inu Aṣeri wá onjẹ rẹ̀ yio lọrá, on o si ma mú adidùn ọba wá. 21 Naftali li abo-agbọnrin ti o le sare: o funni li ọ̀rọ rere. 22 Josefu li ẹka eleso pupọ̀, ẹka eleso pupọ̀ li ẹba kanga; ẹtun ẹniti o yọ si ori ogiri. 23 Awọn tafàtafa bà a ninu jẹ́ pọ̀ju, nwọn si tafà si i, nwọn si korira rẹ̀: 24 Ṣugbọn ọrun rẹ̀ joko li agbara, a si mú apa ọwọ́ rẹ̀ larale, lati ọwọ́ Alagbara Jakobu wá, (lati ibẹ̀ li oluṣọ-agutan, okuta Israeli,) 25 Ani lati ọwọ́ Ọlọrun baba rẹ wá, ẹniti yio ràn ọ lọwọ; ati lati ọwọ́ Olodumare wá, ẹniti yio fi ibukún lati oke ọrun busi i fun ọ, ibukún ọgbun ti o wà ni isalẹ, ibukún ọmú, ati ti inu. 26 Ibukún baba rẹ ti jù ibukún awọn baba nla mi lọ, titi dé opin oke aiyeraiye wọnni: nwọn o si ma gbé ori Josefu, ati li atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀. 27 Benjamini ni yio ma fàniya bi ikõkò: ni kutukutu ni yio ma jẹ ẹran-ọdẹ rẹ̀, ati li aṣalẹ ni yio ma pín ikogun rẹ̀. 28 Gbogbo wọnyi li awọn ẹ̀ya Israeli mejejila: eyi ni baba wọn si sọ fun wọn, o si sure fun wọn; olukuluku bi ibukún tirẹ̀, li o sure fun wọn.

Ikú Jakọbu ati Ìsìnkú Rẹ̀

29 O si kìlọ fun wọn, o si sọ fun wọn pe, A o kó mi jọ pọ̀ pẹlu awọn enia mi: ẹ sin mi pẹlu awọn baba mi ni ihò ti o mbẹ li oko Efroni ara Hitti. 30 Ninu ihò ti o mbẹ ninu oko Makpela ti mbẹ niwaju Mamre, ni ilẹ Kenaani, ti Abrahamu rà pẹlu oko lọwọ Efroni, ara Hitti fun ilẹ-isinku. 31 Nibẹ̀ ni nwọn sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀; nibẹ̀ ni nwọn sin Isaaki ati Rebeka aya rẹ̀; nibẹ̀ ni mo si sin Lea: 32 Lọwọ awọn ọmọ Heti li a ti rà oko na ti on ti ihò ti o wà nibẹ̀. 33 Nigbati Jakobu si ti pari aṣẹ ipa fun awọn ọmọ rẹ̀, o kó ẹsẹ̀ rẹ̀ jọ sori akete, o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀.

Genesisi 50

1 JOSEFU si ṣubu lé baba rẹ̀ li oju, o si sọkun si i lara, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. 2 Josefu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn oniṣegun, ki nwọn ki o kùn baba on li ọṣẹ: awọn oniṣegun si kùn Israeli li ọṣẹ. 3 Nwọn si kún ogoji ọjọ́ fun u; nitoripe bẹ̃li a ikún ọjọ́ awọn ti a kùn li ọṣẹ: awọn ara Egipti si ṣọ̀fọ rẹ̀ li ãdọrin ọjọ́. 4 Nigbati ọjọ́ ọ̀fọ rẹ̀ kọja, Josefu sọ fun awọn ara ile Farao pe, Njẹ bi emi ba ri ore-ọfẹ li oju nyin emi bẹ̀ nyin, ẹ wi li eti Farao pe, 5 Baba mi mu mi bura wipe, Kiyesi i, emi kú: ni isà mi ti mo ti wà fun ara mi ni ilẹ Kenaani, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o sin mi. Njẹ nitorina emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o goke lọ, ki emi ki o si lọ isin baba mi, emi o si tun pada wá. 6 Farao si wipe, Goke lọ, ki o si sin okú baba rẹ, gẹgẹ bi o ti mu ọ bura. 7 Josefu si goke lọ lati sin baba rẹ̀: ati gbogbo awọn iranṣẹ Farao, ati awọn àlagba ile rẹ̀, ati gbogbo awọn àlagba ilẹ Egipti si bá a goke lọ. 8 Ati gbogbo awọn ara ile Josefu, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ara ile baba rẹ̀: kìki awọn ọmọ wẹ́wẹ wọn, ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ni nwọn fi silẹ ni ilẹ Goṣeni. 9 Ati kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin si bá a goke lọ: ẹgbẹ nlanla si ni ẹgbẹ na. 10 Nwọn si dé ibi ilẹ ipakà Atadi, ti o wà li oke Jordani, nibẹ̀ ni nwọn si gbé fi ohùn rére ẹkún nlanla ṣọ̀fọ rẹ̀: o si ṣọ̀fọ fun baba rẹ̀ li ọjọ́ meje. 11 Nigbati awọn ara ilẹ na, awọn ara Kenaani, si ri ọ̀fọ na ni ibi ilẹ ipakà Atadi, nwọn wipe, Ọ̀fọ nla li eyi fun awọn ara Egipti: nitorina ni nwọn ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Abel-misraimu, ti o wà loke odò Jordani. 12 Awọn ọmọ rẹ̀ si ṣe bi o ti fi aṣẹ fun wọn: 13 Nitori ti awọn ọmọ rẹ̀ mú u lọ si ilẹ Kenaani, nwọn si sin i ninu ihò oko Makpela, ti Abrahamu rà pẹlu oko fun iní ilẹ isinku, lọwọ Efroni ara Hitti, niwaju Mamre. 14 Josefu si pada wá si Egipti, on ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o bá a goke lọ lati sin baba rẹ̀, lẹhin ti o ti sin baba rẹ̀ tán.

Josẹfu tún Dá Àwọn Arakunrin Rẹ̀ Lọ́kànle

15 Nigbati awọn arakunrin Josefu ri pe baba wọn kú tán, nwọn wipe, Bọya Josefu yio korira wa, yio si gbẹsan gbogbo ibi ti a ti ṣe si i lara wa. 16 Nwọn si rán onṣẹ tọ̀ Josefu lọ wipe, Baba rẹ ti paṣẹ ki o tó kú pe, 17 Bayi ni ki ẹnyin wi fun Josefu pe, Njẹ emi bẹ̀ ọ, dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ awọn arakunrin rẹ jì wọn, nitori ibi ti nwọn ṣe si ọ. Njẹ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, dari irekọja awọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọn. Josefu si sọkun nigbati nwọn sọ fun u. 18 Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ pẹlu, nwọn wolẹ niwaju rẹ̀: nwọn si wipe, Wò o, iranṣẹ rẹ li awa iṣe. 19 Josefu si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: emi ha wà ni ipò Ọlọrun? 20 Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ibi li ẹnyin rò si mi; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọ si rere, lati mu u ṣẹ, bi o ti ri loni lati gbà ọ̀pọlọpọ enia là. 21 Njẹ nisisiyi, ẹ má bẹ̀ru: emi o bọ́ nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin. O si tù wọn ninu, o si sọ̀rọ rere fun wọn.

Ikú Josẹfu

22 Josefu si joko ni Egipti, on ati ile baba rẹ̀: Josefu si wà li ãdọfa ọdún. 23 Josefu si ri awọn ọmọloju Efraimu ti iran kẹta; awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse li a si gbé kà ori ẽkun Josefu pẹlu. 24 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi kú: Ọlọrun yio si bẹ̀ nyin wò nitõtọ, yio si mú nyin jade kuro ni ilẹ yi, si ilẹ ti o ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu. 25 Josefu si mu awọn ọmọ Israeli bura, wipe, Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò nitõtọ, ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lati ihin lọ. 26 Bẹ̃ni Josefu kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún: nwọn si kùn u li ọṣẹ, a si tẹ́ ẹ sinu posi ni Egipti.

Eksodu 1

Àwọn ará Ijipti fipá kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́

1 NJẸ orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti pẹlu Jakobu ni wọnyi; olukuluku pẹlu ile rẹ̀. 2 Reubeni, Simeoni, Lefi, ati Judah; 3 Issakari, Sebuluni, ati Benjamini; 4 Dani ati Naftali, Gadi ati Aṣeri. 5 Ati gbogbo ọkàn ti o ti inu Jakobu jade, o jẹ́ ãdọrin ọkàn: Josefu sa ti wà ni Egipti. 6 Josefu si kú, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo iran na. 7 Awọn ọmọ Israeli si bisi i, nwọn si pọ̀si i gidigidi, nwọn si rẹ̀, nwọn si di alagbara nla jọjọ; ilẹ na si kún fun wọn. 8 Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egipti, ti kò mọ́ Josefu. 9 O si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, kiye si i, enia awọn ọmọ Israeli npọ̀, nwọn si nlagbara jù wa lọ: 10 Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a fi ọgbọ́n ba wọn ṣe; ki nwọn ki o máṣe bisi i, yio si ṣe nigbati ogun kan ba ṣẹ̀, nwọn o dàpọ mọ́ awọn ọtá wa pẹlu, nwọn o ma bá wa jà, nwọn o si jade kuro ni ilẹ yi. 11 Nitorina ni nwọn ṣe yàn akoniṣiṣẹ le wọn, lati fi iṣẹ wọn pọ́n wọn loju. Nwọn si kọ́ ilu iṣura fun Farao, Pitomu ati Ramesesi. 12 Bi nwọn si ti npọ́n wọn loju si i, bẹ̃ni nwọn mbisi i, ti nwọn si npọ̀. Inu wọn si bàjẹ́ nitori awọn ọmọ Israeli. 13 Awọn ara Egipti si mu awọn ọmọ Israeli sìn li asìnpa: 14 Nwọn si fi ìsin lile, li erupẹ ati ni briki ṣiṣe, ati ni oniruru ìsin li oko mu aiye wọn korò: gbogbo ìsin wọn ti nwọn mu wọn sìn, asìnpa ni. 15 Ọba Egipti si wi fun awọn iyãgbà Heberu; orukọ ọkan ninu ẹniti ijẹ Ṣifra, ati orukọ ekeji ni Pua: 16 O si wipe, Nigbati ẹnyin ba nṣe iṣẹ iyãgbà fun awọn obinrin Heberu, ti ẹnyin ba ri wọn ni ikunlẹ; bi o ba ṣe ọmọkunrin ni, njẹ ki ẹnyin ki o pa a; ṣugbọn bi o ba ṣe ọmọbinrin ni, njẹ on o yè. 17 Ṣugbọn awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, nwọn kò si ṣe bi ọba Egipti ti fi aṣẹ fun wọn, nwọn si da awọn ọmọkunrin si. 18 Ọba Egipti si pè awọn iyãgbà na, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe irú nkan yi ti ẹnyin si da awọn ọmọkunrin si? 19 Awọn iyãgbà si wi fun Farao pe, nitoriti awọn obinrin Heberu kò ri bi awọn obinrin Egipti; nitoriti ara yá wọn, nwọn a si ti bí ki awọn iyãgbà to wọle tọ̀ wọn lọ. 20 Nitorina Ọlọrun ṣe rere fun awọn iyãgbà na: awọn enia na si mbisi i, nwọn si di alagbara koko. 21 O si ṣe, nitoriti awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, on si kọle fun wọn. 22 Farao si paṣẹ fun gbogbo awọn enia rẹ̀, wipe, Gbogbo ọmọkunrin ti a bí on ni ki ẹnyin gbé jù sinu odò, gbogbo awọn ọmọbinrin ni ki ẹnyin ki o dasi.

Eksodu 2

Ìbí Mose

1 ỌKUNRIN kan ara ile Lefi si lọ, o si fẹ́ ọmọbinrin Lefi kan. 2 Obinrin na si yún, o si bi ọmọkunrin kan: nigbati o si ri i pe, o ṣe ọmọ didara, o pa a mọ́ li oṣù mẹta. 3 Nigbati kò si le pa a mọ́ mọ́, o ṣe apoti ẽsu fun u, o si fi ọ̀da ilẹ ati oje igi ṣán a; o si tẹ́ ọmọ na sinu rẹ̀; o si gbé e sinu koriko odò li ẹba odò na. 4 Arabinrin rẹ̀ si duro li òkere, lati mọ̀ ohun ti yio ṣe ọmọ na. 5 Ọmọbinrin Farao si sọkalẹ wá lati wẹ̀ li odò; awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ si nrìn lọ li ẹba odò na; nigbati o si ri apoti na lãrin koriko odò, o rán ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ kan lati lọ gbé e wá. 6 Nigbati o si ṣi i, o ri ọmọ na; si kiyesi i ọmọde na nsọkun. Inu rẹ̀ si yọ́ si i, o si wipe, Ọkan ninu awọn ọmọ Heberu li eyi. 7 Nigbana li arabinrin rẹ̀ wi fun ọmọbinrin Farao pe, Emi ka lọ ipè alagbatọ kan fun ọ wá ninu awọn obinrin Heberu, ki o tọ́ ọmọ na fun ọ? 8 Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Lọ. Ọmọbinrin na si lọ, o si pè iya ọmọ na wá. 9 Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Gbé ọmọ yi lọ ki o si tọ́ ọ fun mi, emi o si san owo iṣẹ rẹ fun ọ. Obinrin na si gbé ọmọ na lọ, o si tọ́ ọ. 10 Ọmọ na si dàgba, o si mú u tọ̀ ọmọbinrin Farao wá, on si di ọmọ rẹ̀. O si sọ orukọ rẹ̀ ni Mose, o si wipe, Nitoriti mo fà a jade ninu omi.

Mose Sá Lọ sí Midiani

11 O si ṣe li ọjọ́ wọnni, ti Mose dàgba, o jade tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wò iṣẹ wọn: o si ri ara Egipti kan o nlù Heberu kan, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀. 12 O si wò ihin, o wò ọhún, nigbati o si ri pe, kò si ẹnikan, o lù ara Egipti na pa, o si bò o ninu yanrin. 13 Nigbati o si jade lọ ni ijọ́ keji, kiyesi i, ọkunrin meji ara Heberu mbá ara wọn jà: o si wi fun ẹniti o firan si ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nlù ẹgbẹ rẹ? 14 On si wipe, Tali o fi ọ jẹ́ olori ati onidajọ lori wa? iwọ fẹ́ pa mi bi o ti pa ara Egipti? Mose si bẹ̀ru, o si wipe, Lõtọ ọ̀ran yi di mimọ̀. 15 Nigbati Farao si gbọ́ ọ̀ran yi, o nwá ọ̀na lati pa Mose. Ṣugbọn Mose sá kuro niwaju Farao, o si ngbé ilẹ Midiani: o si joko li ẹba kanga kan. 16 Njẹ alufa Midiani li ọmọbinrin meje, nwọn si wá, nwọn pọn omi, nwọn si kún ọkọ̀ imumi lati fi omi fun agbo-ẹran baba wọn. 17 Awọn oluṣọ-agutan si wá, nwọn si lé wọn kuro: nigbana ni Mose dide duro, o ràn wọn lọwọ, o si fi omi fun agbo-ẹran wọn. 18 Nigbati nwọn si padà dé lati ọdọ Reueli baba wọn, o ni Ẽtiri ti ẹnyin fi tète dé bẹ̃ loni? 19 Nwọn si wipe, Ara Egipti kan li o gbà wa lọwọ awọn oluṣọ-agutan, o si pọn omi to fun wa pẹlu, o si fi fun agbo-ẹran. 20 O si wi fun awọn ọmọbinrin rẹ̀ pe Nibo li o gbé wà? ẽṣe ti ẹnyin fi ọkunrin na silẹ? ẹ pè e ki o le wá ijẹun. 21 O si dùn mọ́ Mose lati ma bá ọkunrin na gbé: on si fi Sippora ọmọbinrin rẹ̀ fun Mose. 22 On si bi ọmọkunrin kan fun u, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gerṣomu: nitoriti o wipe, Emi ti nṣe atipo ni ilẹ ajeji. 23 O si ṣe lẹhin ọjọ́ pupọ̀, ti ọba Egipti kú: awọn ọmọ Israeli si ngbin nitori ìsin na, nwọn si ke, igbe wọn si goke tọ̀ Ọlọrun lọ nitori ìsin wọn. 24 Ọlọrun si gbọ́ irora wọn, Ọlọrun si ranti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, pẹlu Isaaki, ati pẹlu Jakobu. 25 Ọlọrun si bojuwò awọn ọmọ Israeli, Ọlọrun si mọ̀ ọ fun wọn.

Eksodu 3

Ọlọrun Pe Mose

1 MOSE si nṣọ́ agbo-ẹran Jetro baba aya rẹ̀, alufa Midiani: o si dà agbo-ẹran na lọ si apa ẹhin ijù, o si dé Horebu, oke Ọlọrun. 2 Angeli OLUWA si farahàn a ninu ọwọ́ iná lati inu ãrin igbẹ̀: on si wò, si kiyesi i, iná njó igbẹ́, igbẹ́ na kò si run. 3 Mose si wipe, Njẹ emi o yipada si apakan, emi o si wò iran nla yi, ẽṣe ti igbẹ́ yi kò run. 4 Nigbati OLUWA ri pe, o yipada si apakan lati wò o, Ọlọrun kọ si i lati inu ãrin igbẹ́ na wá, o si wipe, Mose, Mose. On si dahun pe, Emi niyi. 5 O si wipe, Máṣe sunmọ ihin: bọ́ salubata rẹ kuro li ẹsẹ̀ rẹ, nitori ibiti iwọ gbé duro si nì, ilẹ mimọ́ ni. 6 O si wipe, Emi li Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu. Mose si pa oju rẹ̀ mọ́; nitoriti o bẹ̀ru lati bojuwò Ọlọrun. 7 OLUWA si wipe, Nitõtọ emi ti ri ipọnju awọn enia mi ti o wà ni Egipti, mo si gbọ́ igbe wọn nitori awọn akoniṣiṣẹ wọn; nitoriti mo mọ̀ ibanujẹ wọn; 8 Emi si sọkalẹ wa lati gbà wọn lọwọ awọn ara Egipti, ati lati mú wọn goke ti ilẹ na wá si ilẹ rere ati nla, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin; si ibi ti awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi. 9 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, igbe awọn ọmọ Israeli dé ọdọ mi; emi si ti ri pẹlu, wahala ti awọn ọba Egipti nwahala wọn. 10 Nitorina wá nisisiyi, emi o si rán ọ si Farao, ki iwọ ki o le mú awọn enia mi, awọn ọmọ Israeli, lati Egipti jade wá. 11 Mose si wi fun Ọlọrun pe, Tali emi, ti emi o fi tọ̀ Farao lọ, ati ti emi o fi le mú awọn ọmọ Israeli jade lati Egipti wá? 12 O si wipe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ; eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ pe, emi li o rán ọ: nigbati iwọ ba mú awọn enia na lati Egipti jade wá, ẹnyin o sìn Ọlọrun lori oke yi. 13 Mose si wi fun Ọlọrun pe, Kiyesi i, nigbati mo ba dé ọdọ awọn ọmọ Israeli, ti emi o si wi fun wọn pe, Ọlọrun awọn baba nyin li o rán mi si nyin; ti nwọn o si bi mi pe, Orukọ rẹ̀? kili emi o wi fun wọn? 14 Ọlọrun si wi fun Mose pe, EMI NI ẸNITI O WA: o si wipe, Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, EMI NI li o rán mi si nyin. 15 Ọlọrun si wi fun Mose pẹlu pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o rán mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati irandiran. 16 Lọ, ki o si kó awọn àgba Israeli jọ, ki o si wi fun wọn pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, ti Isaaki, ati ti Jakobu, li o farahàn mi wipe, Lõtọ ni mo ti bẹ̀ nyin wò, mo si ti ri ohun ti a nṣe si nyin ni Egipti: 17 Emi si ti wipe, Emi o mú nyin goke jade ninu ipọnju Egipti si ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin. 18 Nwọn o si fetisi ohùn rẹ: iwọ o si wá, iwọ ati awọn àgba Israeli, sọdọ ọba Egipti, ẹnyin o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu pade wa: jẹ ki a lọ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki awa ki o le rubọ si OLUWA Ọlọrun wa. 19 Emi si mọ̀ pe ọba Egipti ki yio jẹ ki ẹnyin ki o lọ, ki tilẹ iṣe nipa ọwọ́ agbara. 20 Emi o si nà ọwọ́ mi, emi o si fi iṣẹ-iyanu mi gbogbo kọlù Egipti ti emi o ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin eyinì li on o to jọwọ nyin lọwọ lọ. 21 Emi o si fi ojurere fun awọn enia yi li oju awọn ara Egipti: yio si ṣe, nigbati ẹnyin o lọ, ẹnyin ki yio lọ li ofo: 22 Olukuluku obinrin ni yio si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ, lọwọ aladugbo rẹ̀, ati lọwọ ẹniti o nṣe atipo ninu ile rẹ̀: ẹnyin o si fi wọn si ara awọn ọmọkunrin nyin, ati si ara awọn ọmọbinrin nyin: ẹnyin o si kó ẹrù awọn ara Egipti.

Eksodu 4

Ọlọrun Fún Mose ní Agbára Ìyanu

1 MOSE si dahùn o si wipe, Ṣugbọn kiyesi i, nwọn ki yio gbà mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn ki yio fetisi ohùn mi: nitoriti nwọn o wipe, OLUWA kò farahàn ọ. 2 OLUWA si wi fun u pe, Kini wà li ọwọ́ rẹ nì? On si wipe, Ọpá ni. 3 O si wi fun u pe, Sọ ọ si ilẹ. On si sọ ọ si ilẹ, o si di ejò; Mose si sá kuro niwaju rẹ̀. 4 OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ ki o si mú u ni ìru: (On si nà ọwọ́ rẹ̀, o si mú u, o si di ọpá si i li ọwọ́:) 5 Ki nwọn ki o le gbàgbọ́ pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o farahàn ọ. 6 OLUWA si tun wi fun u pe, Fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. O si fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀: nigbati o si fà a yọ jade, si kiyesi i, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, o fún bi ẹ̀gbọn owu. 7 O si wipe, Tun fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. (O si tun fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀; o si fà a yọ jade li àiya rẹ̀; si kiyesi i, o si pada bọ̀ bi ẹran ara rẹ̀.) 8 Yio si ṣe, bi nwọn kò ba gbà ọ gbọ́, ti nwọn kò si fetisi ohùn iṣẹ-àmi iṣaju, njẹ nwọn o gbà ohùn iṣẹ-àmi ikẹhin gbọ́. 9 Yio si ṣe, bi nwọn kò ba si gbà àmi mejeji yi gbọ́ pẹlu, ti nwọn kò si fetisi ohùn rẹ, njẹ ki iwọ ki o bù ninu omi odò nì, ki o si dà a si iyangbẹ ilẹ: omi na ti iwọ bù ninu odò yio di ẹ̀jẹ ni iyangbẹ ilẹ. 10 Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo. 11 OLUWA si wi fun u pe, Tali o dá ẹnu enia? tabi tali o dá odi, tabi aditi, tabi ariran, tabi afọju? Emi OLUWA ha kọ́? 12 Njẹ lọ nisisiyi, emi o si pẹlu ẹnu rẹ, emi o si kọ́ ọ li eyiti iwọ o wi. 13 On si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, rán ẹniti iwọ o rán. 14 Inu OLUWA si ru si Mose, o si wipe, Aaroni arakunrin rẹ ọmọ Lefi kò ha wà? Emi mọ̀ pe o le sọ̀rọ jọjọ. Ati pẹlu, kiyesi i, o si mbọ̀wá ipade rẹ: nigbati o ba si ri ọ, on o yọ̀ ninu ọkàn rẹ̀. 15 Iwọ o si sọ̀rọ fun u, iwọ o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu: emi o si pẹlu ẹnu rẹ, ati pẹlu ẹnu rẹ̀, emi o si kọ́ nyin li eyiti ẹnyin o ṣe. 16 On ni yio si ma ṣe ogbifọ rẹ fun awọn enia: yio si ṣe, on o ma jẹ́ ẹnu fun ọ, iwọ o si ma jẹ́ bi Olọrun fun u. 17 Iwọ o si mú ọpá yi li ọwọ́ rẹ, eyiti iwọ o ma fi ṣe iṣẹ-àmi.

Mose Pada Lọ sí Ijipti

18 Mose si lọ, o si pada tọ̀ Jetro ana rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nlọ ki emi si pada tọ̀ awọn arakunrin mi ti o wà ni Egipti, ki emi ki o si wò bi nwọn wà li ãye sibẹ̀. Jetro si wi fun Mose pe, Mã lọ li alafia. 19 OLUWA si wi fun Mose ni Midiani pe, Lọ, pada si Egipti: nitori gbogbo enia ti nwá ẹmi rẹ ti kú tán. 20 Mose si mú aya rẹ̀ ati awọn ọmọ-ọkunrin rẹ̀, o si gbé wọn gùn kẹtẹkẹtẹ kan, o si pada si ilẹ Egipti: Mose si mú ọpá Ọlọrun na li ọwọ́ rẹ̀. 21 OLUWA si wi fun Mose pe, Nigbati iwọ ba dé Egipti, kiyesi i ki iwọ ki o ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu, ti mo filé ọ lọwọ, niwaju Farao, ṣugbọn emi o mu àiya rẹ̀ le, ti ki yio fi jẹ ki awọn enia na ki o lọ. 22 Iwọ o si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA wi, Ọmọ mi ni Israeli, akọ́bi mi: 23 Emi si ti wi fun ọ pe, Jẹ ki ọmọ mi ki o lọ, ki o le ma sìn mi; iwọ si ti kọ̀ lati jẹ ki o lọ: kiyesi i, emi o pa ọmọ rẹ, ani akọ́bi rẹ. 24 O si ṣe li ọ̀na ninu ile-èro, li OLUWA pade rẹ̀, o si nwá ọ̀na lati pa a. 25 Nigbana ni Sippora mú okuta mimú, o si kọ ọmọ rẹ̀ ni ilà abẹ, o si sọ ọ si ẹsẹ̀ Mose, o si wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ fun mi nitõtọ. 26 Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. Nigbana ni Sippora wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ nitori ikọlà na. 27 OLUWA si wi fun Aaroni pe, Lọ si ijù lọ ipade Mose. On si lọ, o si pade rẹ̀ li oke Ọlọrun, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. 28 Mose si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o rán a fun Aaroni, ati gbogbo aṣẹ iṣẹ-àmi ti o fi fun u. 29 Mose ati Aaroni si lọ, nwọn si kó gbogbo àgba awọn ọmọ Israeli jọ: 30 Aaroni si sọ gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA ti sọ fun Mose, o si ṣe iṣẹ-àmi na li oju awọn enia na. 31 Awọn enia na si gbàgbọ́: nigbati nwọn si gbọ́ pe, OLUWA ti bẹ̀ awọn ọmọ Israeli wò, ati pe o si ti ri ipọnju wọn, nigbana ni nwọn tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn.

Eksodu 5

Mose ati Aaroni níwájú Ọba Ijipti

1 LẸHIN eyinì ni Mose ati Aaroni wọle, nwọn si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣe ajọ fun mi ni ijù. 2 Farao si wipe, Tali OLUWA, ti emi o fi gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ lati jẹ ki Israeli ki o lọ? Emi kò mọ̀ OLUWA na, bẹ̃li emi ki yio jẹ ki Israeli ki o lọ. 3 Nwọn si wipe, Ọlọrun awọn Heberu li o pade wa: awa bẹ̀ ọ, jẹ ki a lọ ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa; ki o má ba fi ajakalẹ-àrun tabi idà kọlù wa. 4 Ọba Egipti si wi fun wọn pe, Mose ati Aaroni, nitori kili ẹnyin ṣe dá awọn enia duro ninu iṣẹ wọn? ẹ lọ si iṣẹ nyin. 5 Farao si wipe, Kiyesi i awọn enia ilẹ yi pọ̀ju nisisiyi, ẹnyin si mu wọn simi kuro ninu iṣẹ wọn. 6 Farao si paṣẹ li ọjọ́ na fun awọn akoniṣiṣẹ awọn enia, ati fun awọn olori wọn wipe, 7 Ẹnyin kò gbọdọ fun awọn enia na ni koriko mọ́ lati ma ṣe briki, bi ìgba atẹhinwá: jẹ ki nwọn ki o ma lọ ṣà koriko fun ara wọn. 8 Ati iye briki ti nwọn ti ima ṣe ni ìgba atẹhinwá, on ni ki ẹnyin bù fun wọn; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ nkan kù kuro nibẹ̀: nitoriti nwọn nṣe imẹlẹ; nitorina ni nwọn ṣe nke wipe, Jẹ ki a lọ rubọ si Ọlorun wa. 9 Ẹ jẹ ki iṣẹ ki o wuwo fun awọn ọkunrin na, ki nwọn ki o le ma ṣe lãlã ninu rẹ̀; ẹ má si ṣe jẹ ki nwọn ki o fiyesi ọ̀rọ eke. 10 Awọn akoniṣiṣẹ enia na si jade, ati awọn olori wọn, nwọn si sọ fun awọn enia na, pe, Bayi ni Farao wipe, Emi ki yio fun nyin ni koriko mọ́. 11 Ẹ lọ, ẹ wá koriko nibiti ẹnyin gbé le ri i: ṣugbọn a ki yio ṣẹ nkan kù ninu iṣẹ nyin. 12 Bẹ̃li awọn enia na si tuka kiri ká gbogbo ilẹ Egipti lati ma ṣà idi koriko ni ipò koriko. 13 Awọn akoniṣiṣẹ lé wọn ni ire wipe, Ẹ ṣe iṣẹ nyin pé, iṣẹ ojojumọ́ nyin, bi igbati koriko mbẹ. 14 Ati awọn olori awọn ọmọ Israeli, ti awọn akoniṣiṣẹ Farao yàn lé wọn, li a nlù, ti a si mbilère pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò ṣe iṣẹ nyin pé ni briki ṣiṣe li ana ati li oni, bi ìgba atẹhinwá? 15 Nigbana li awọn olori awọn ọmọ Israeli wá, nwọn si ke tọ̀ Farao wipe, Ẽṣe ti iwọ fi nṣe awọn iranṣẹ rẹ bayi? 16 A kò fi koriko fun awọn iranṣẹ rẹ, nwọn si nwi fun wa pe, Ẹ ṣe briki: si kiyesi i, a nlù awọn iranṣẹ rẹ; ṣugbọn lọwọ awọn enia rẹ li ẹbi wà. 17 Ṣugbọn on wipe, Ẹnyin ọlẹ, ẹnyin ọlẹ: nitorina li ẹ ṣe wipe, Jẹ ki a lọ ṣẹbọ si OLUWA. 18 Njẹ ẹ lọ nisisiyi, ẹ ṣiṣẹ; a ki yio sá fi koriko fun nyin, sibẹ̀ iye briki nyin yio pé. 19 Awọn olori awọn ọmọ Israeli si ri pe, ọ̀ran wọn kò li oju, lẹhin igbati a wipe, Ẹ ki o dinkù ninu iye briki nyin ojojumọ́. 20 Nwọn si bá Mose on Aaroni, ẹniti o duro lati pade wọn bi nwọn ti nti ọdọ Farao jade wá: 21 Nwọn si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o wò nyin, ki o si ṣe idajọ; nitoriti ẹnyin mu wa di okú-õrùn li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀, lati fi idá lé wọn lọwọ lati pa wa.

Mose Ráhùn sí OLUWA

22 Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wi fun u pe, OLUWA, ẽtiṣe ti o fi ṣe buburu si awọn enia yi bẹ̃? ẽtiṣe ti o fi rán mi? 23 Nitori igbati mo ti tọ̀ Farao wá lati sọ̀rọ li orukọ rẹ, buburu li o ti nṣe si awọn enia yi; bẹ̃ni ni gbigbà iwọ kò si gbà awọn enia rẹ.

Eksodu 6

Ọlọrun Pe Mose

1 NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Nigbayi ni iwọ o ri ohun ti emi o ṣe si Farao: nitori ọwọ́ agbara li on o ṣe jọwọ wọn lọwọ lọ, ati pẹlu ọwọ́ agbara li on o fi tì wọn jade kuro ni ilẹ rẹ̀. 2 Ọlọrun si sọ fun Mose, o si wi fun u pe, Emi ni JEHOFA: 3 Emi si farahàn Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, li orukọ Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn orukọ mi JEHOFA, ni nwọn kò fi mọ̀ mi. 4 Emi si ti bá wọn da majẹmu mi pẹlu, lati fun wọn ni ilẹ Kenaani, ilẹ atipo wọn, nibiti nwọn gbé ṣe atipo. 5 Emi si ti gbọ́ irora awọn ọmọ Israeli pẹlu, ti awọn ara Egipti nmu sìn; emi si ti ranti majẹmu mi. 6 Nitorina wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi li OLUWA, emi o si mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti, emi o si yọ nyin kuro li oko-ẹrú wọn, emi o si fi apa ninà ati idajọ nla da nyin ni ìde: 7 Emi o si gbà nyin ṣe enia fun ara mi, emi o si jẹ́ Ọlọrun fun nyin: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti. 8 Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o si fi i fun nyin ni iní: Emi li OLUWA. 9 Mose si sọ bẹ̃ fun awọn ọmọ Israeli: ṣugbọn nwọn kò gbà ti Mose gbọ́ fun ibinujẹ ọkàn, ati fun ìsin lile. 10 OLUWA si sọ fun Mose pe, 11 Wọle, sọ fun Farao ọba Egipti pe, ki o jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ kuro ni ilẹ rẹ̀. 12 Mose si sọ niwaju OLUWA wipe, Kiyesi i, awọn ọmọ Israeli kò gbọ́ ti emi, Farao yio ha ti ṣe gbọ́ ti emi, emi ẹniti iṣe alaikọlà ète? 13 OLUWA si bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ, o si fi aṣẹ fun wọn si awọn ọmọ Israeli, ati si Farao, ọba Egipti, lati mú awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ Egipti.

Àkọsílẹ̀ Ìran Mose ati Ti Aaroni

14 Wọnyi li olori ile baba wọn: awọn ọmọ Reubeni akọ́bi Israeli; Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi: wọnyi ni idile Reubeni. 15 Ati awọn ọmọ Simeoni; Jemueli, ati Jamini, ati Ohadi, ati Jakini, ati Sohari, ati Ṣaulu ọmọ obinrin ara Kénaani; wọnyi ni idile Simeoni. 16 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Lefi ni iran wọn; Gerṣoni, ati Kohati, ati Merari: ọdún aiye Lefi si jẹ́ mẹtadilogoje. 17 Awọn ọmọ Gerṣoni; Libni, ati Ṣimei, ni idile wọn. 18 Ati awọn ọmọ Kohati; Amramu ati Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli ọdún aiye Kohati si jẹ́ ãdoje o le mẹta. 19 Ati awọn ọmọ Merari; Mahali, ati Muṣi. Wọnyi ni idile Lefi ni iran wọn. 20 Amramu si fẹ́ Jokebedi arabinrin baba rẹ̀ li aya, on li o si bi Aaroni ati Mose fun u: ọdún aiye Amramu si jẹ́ mẹtadilogoje. 21 Ati awọn ọmọ Ishari; Kora, ati Nefegi, ati Sikri. 22 Ati awọn ọmọ Ussieli; Miṣaeli, ati Elsafani, ati Sitri. 23 Aaroni si fẹ́ Eliṣeba, ọmọbinrin Aminadabu, arabinrin Naṣoni, li aya; on si bí Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari fun u. 24 Ati awọn ọmọ Kora; Assiri, ati Elkana, ati Abiasafu; wọnyi ni idile awọn ọmọ Kora. 25 Eleasari ọmọ Aaroni si fẹ́ ọkan ninu awọn ọmọbinrin Putieli li aya; on si bi Finehasi fun u: wọnyi li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi ni idile wọn. 26 Wọnyi ni Aaroni on Mose na, ẹniti OLUWA sọ fun pe, Ẹ mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn. 27 Awọn wọnyi li o bá Farao ọba Egipti sọ̀rọ lati mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni Egipti: wọnyi ni Mose ati Aaroni na.

Àṣẹ Tí OLUWA Pa fún Mose ati Aaroni

28 O si ṣe li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ ni ilẹ Egipti, 29 Ni OLUWA sọ fun Mose wipe, Emi li OLUWA: sọ gbogbo eyiti mo wi fun ọ fun Farao ọba Egipti. 30 Mose si wi niwaju OLUWA pe, Kiyesi i, alaikọlà ète li emi, Farao yio ha ti ṣe fetisi ti emi?

Eksodu 7

1 OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi fi ọ ṣe ọlọrun fun Farao: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma ṣe wolĩ rẹ. 2 Iwọ o sọ gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma sọ fun Farao pe, ki o rán awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ rẹ̀. 3 Emi o si mu Farao li àiya le, emi o si sọ iṣẹ-àmi mi ati iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti. 4 Ṣugbọn Farao ki yio gbọ́ ti nyin, emi o si fi ọwọ́ mi lé Egipti, emi o si fi idajọ nla mú awọn ogun mi, ani awọn ọmọ Israeli enia mi, jade kuro ni ilẹ Egipti. 5 Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba nà ọwọ́ mi lé Egipti, ti mo si mú awọn ọmọ Israeli jade kuro lãrin wọn. 6 Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃; bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn; bẹ̃ni nwọn ṣe. 7 Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún, Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún o le mẹta, nigbati nwọn sọ̀rọ fun Farao.

Ọ̀pá Aaroni

8 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 9 Nigbati Farao yio ba wi fun nyin pe, Ẹ fi iṣẹ-iyanu kan hàn: nigbana ni ki iwọ ki o wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si fi i lelẹ niwaju Farao, yio si di ejò. 10 Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: Aaroni si fi ọpá rẹ̀ lelẹ niwaju Farao ati niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀, o si di ejò. 11 Nigbana ni Farao pẹlu pè awọn ọlọgbọ́n ati awọn oṣó: awọn pẹlu, ani awọn alalupayida Egipti, si fi idán wọn ṣe bẹ̃ gẹgẹ. 12 Nitoriti olukuluku nwọn fi ọpá rẹ̀ lelẹ, nwọn si di ejò: ṣugbọn ọpá Aaroni gbe ọpá wọn mì. 13 Aiya Farao si le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

Ìṣẹ̀lẹ̀ Burúkú ṣẹ̀ ní Ijipti

14 OLUWA si wi fun Mose pe, Aiya Farao di lile, o kọ̀ lati jẹ ki awọn enia na ki o lọ. 15 Tọ̀ Farao lọ li owurọ̀; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki iwọ ki o si duro lati pade rẹ̀ leti odò; ati ọpá nì ti o di ejò ni ki iwọ ki o mú li ọwọ́ rẹ. 16 Iwọ o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu, li o rán mi si ọ wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi ni ijù: si kiyesi i, titi di isisiyi iwọ kò gbọ́. 17 Bayi li OLUWA wi, Ninu eyi ni iwọ o fi mọ̀ pe emi li OLUWA: kiyesi i, emi o fi ọpá ti o wà li ọwọ́ mi lù omi ti o wà li odò, nwọn o si di ẹ̀jẹ. 18 Ẹja ti o wà ninu odò na yio si kú, odò na yio si ma rùn; awọn ara Egipti yio si korira ati ma mu ninu omi odò na. 19 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju omi Egipti wọnni, si odò wọn, si omi ṣiṣàn wọn, ati ikudu wọn, ati si gbogbo ikojọpọ omi wọn, ki nwọn le di ẹ̀jẹ; ẹ̀jẹ yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, ati ninu ohun-èlo igi, ati ninu ohun-èlo okuta. 20 Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃ bi OLUWA ti fi aṣẹ fun wọn; o si gbé ọpá na soke o si lù omi ti o wà li odò li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀; a si sọ gbogbo omi ti o wà li odò na di ẹ̀jẹ. 21 Ẹja ti o wà li odò si kú; odò na si nrùn, awọn ara Egipti kò si le mu ninu omi odò na; ẹ̀jẹ si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, 22 Awọn alalupayida Egipti si fi idán wọn ṣe bẹ̃: àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi. 23 Farao si pada o lọ si ile rẹ̀, kò si fi ọkàn rẹ̀ si eyi pẹlu. 24 Gbogbo awọn ara Egipti si wàlẹ yi odò na ká fun omi mimu; nitoriti nwọn kò le mu ninu omi na. 25 Ọjọ́ meje si pé, lẹhin igbati OLUWA lù odò na.

Eksodu 8

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Tọ̀ Farao lọ, ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi. 2 Bi iwọ ba si kọ̀ lati jẹ ki nwọn ki o lọ, kiyesi i, emi o fi ọpọlọ kọlù gbogbo ẹkùn rẹ: 3 Odò yio si bi ọpọlọ jade li ọ̀pọlọpọ, nwọn o si goke, nwọn o si wá sinu ile rẹ, ati sinu ibùsun rẹ, ati sori akete rẹ, ati sinu ile awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu ãro rẹ, ati sinu ọpọ́n ìpo-iyẹfun rẹ: 4 Awọn ọpọlọ na yio si gùn ọ lara, ati lara awọn enia rẹ, ati lara gbogbo awọn iranṣẹ rẹ. 5 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Nà ọwọ́ rẹ pẹlu ọpá rẹ sori odò wọnni, sori omi ṣiṣàn, ati sori ikojọpọ̀ omi, ki o si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti. 6 Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ sori omi Egipti; awọn ọpọlọ si goke wá, nwọn si bò ilẹ Egipti. 7 Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃, nwọn si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti. 8 Nigbana ni Farao pè Mose ati Aaroni, o si wipe, Ẹ bẹ̀ OLUWA, ki o le mú awọn ọpọlọ kuro lọdọ mi, ati kuro lọdọ awọn enia mi; emi o si jẹ ki awọn enia na ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣẹbọ si OLUWA. 9 Mose si wi fun Farao pe, Paṣẹ fun mi: nigbawo li emi o bẹ̀bẹ fun ọ, ati fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun awọn enia rẹ, lati run awọn ọpọlọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ki nwọn ki o kù ni kìki odò nikan? 10 On si wipe, Li ọla. O si wipe, Ki o ri bi ọ̀rọ rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe, kò sí ẹniti o dabi OLUWA Ọlọrun wa. 11 Awọn ọpọlọ yio si lọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ; ni kìki odò ni nwọn o kù si. 12 Mose ati Aaroni si jade kuro lọdọ Farao: Mose si kigbe si OLUWA nitori ọpọlọ ti o ti múwa si ara Farao. 13 OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; awọn ọpọlọ na si kú kuro ninu ile, ninu agbalá, ati kuro ninu oko. 14 Nwọn si kó wọn jọ li òkiti-òkiti: ilẹ na si nrùn. 15 Ṣugbọn nigbati Farao ri pe isimi wà, o mu àiya rẹ̀ le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi. 16 OLUWA si wi fun Mose pe, Sọ fun Aaroni pe, Nà ọpá rẹ, ki o si lù ekuru ilẹ, ki o le di iná já gbogbo ilẹ Egipti. 17 Nwọn si ṣe bẹ̃; Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ pẹlu ọpá rẹ̀, o si lù erupẹ ilẹ, iná si wà lara enia, ati lara ẹran; gbogbo ekuru ilẹ li o di iná já gbogbo ilẹ Egipti. 18 Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃ lati mú iná jade wá, ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: bẹ̃ni iná si wà lara enia, ati lara ẹran. 19 Nigbana ni awọn alalupayida wi fun Farao pe, Ika Ọlọrun li eyi: ṣugbọn àiya Farao le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi. 20 OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi. 21 Bi iwọ kò ba si jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, kiyesi i, emi o rán ọwọ́ eṣinṣin si ọ, ati sara iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu awọn ile rẹ: gbogbo ile awọn ara Egipti ni yio si kún fun ọwọ́ eṣinṣin, ati ilẹ ti nwọn gbé wà pẹlu. 22 Li ọjọ́ na li emi o yà ilẹ Goṣeni sọ̀tọ, ninu eyiti awọn enia mi tẹ̀dó si, ti eṣinṣin ki yio sí nibẹ̀; nitori ki iwọ ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA lãrin ilẹ aiye. 23 Emi o si pàla si agbedemeji awọn enia mi ati awọn enia rẹ: li ọla ni iṣẹ-amì yi yio si wà. 24 OLUWA si ṣe bẹ̃; ọwọ́ eṣinṣin ọ̀pọlọpọ si dé sinu ile Farao, ati sinu ile awọn iranṣẹ rẹ̀: ati ni gbogbo ilẹ Egipti, ilẹ na bàjẹ́ nitori ọwọ́ eṣinṣin wọnni. 25 Farao si ranṣẹ pè Mose ati Aaroni o si wipe; Ẹ ma lọ ṣẹbọ si Ọlọrun nyin ni ilẹ yi. 26 Mose si wipe, Kò tọ́ lati ṣe bẹ̃; nitori awa o fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ si OLUWA Ọlọrun wa: wò o, awa le fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ li oju wọn, nwọn ki yio ha sọ wa li okuta? 27 Awa o lọ ni ìrin ijọ́ mẹta sinu ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa, bi on o ti paṣẹ fun wa. 28 Farao si wipe, Emi o jẹ ki ẹnyin lọ, ki ẹ le rubọ si OLUWA Ọlọrun nyin ni ijù; kìki ki ẹnyin ki o máṣe lọ jìna jù: ẹ bẹ̀bẹ fun mi. 29 Mose si wipe, Kiyesi i, emi njade lọ kuro lọdọ rẹ, emi o si bẹ̀ OLUWA ki ọwọ́ eṣinṣin wọnyi ki o le ṣi kuro lọdọ Farao, kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀, li ọla: kìki ki Farao ki o máṣe ẹ̀tan mọ́ li aijẹ ki awọn enia na ki o lọ rubọ si OLUWA. 30 Mose si jade kuro lọdọ Farao, o si bẹ̀ OLUWA. 31 OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; o si ṣi ọwọ́ eṣinṣin na kuro lọdọ Farao, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀; ọkan kò kù. 32 Farao si mu àiya rẹ̀ le nigbayi pẹlu, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ.

Eksodu 9

1 NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn le sìn mi. 2 Nitoripe, bi iwọ ba kọ̀ lati jẹ ki nwọn lọ, ti iwọ si da wọn duro sibẹ̀, 3 Kiyesi i, ọwọ́ OLUWA mbẹ lara ẹran-ọ̀sin rẹ ti mbẹ li oko, lara ẹṣin, lara kẹtẹkẹtẹ, lara ibakasiẹ, lara ọwọ́-malu, ati lara agbo-agutan wọnni: ajakalẹ-àrun buburu mbọ̀. 4 OLUWA yio si pàla si agbedemeji ẹran-ọ̀sin Israeli ati ẹran-ọ̀sin Egipti: kò si ohun kan ti yio kú ninu gbogbo eyiti iṣe ti awọn ọmọ Israeli. 5 OLUWA si dá akokò kan wipe, Li ọla li OLUWA yio ṣe nkan yi ni ilẹ yi. 6 OLUWA si ṣe nkan na ni ijọ́ keji, gbogbo ẹran-ọ̀sin Egipti si kú: ṣugbọn ninu ẹran-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli ọkanṣoṣọ kò si kú. 7 Farao si ranṣẹ, si kiyesi i, ọkanṣoṣo kò kú ninu ẹran-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli. Àiya Farao si le, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ. 8 OLUWA si wi fun Mose ati fun Aaroni pe, Bù ikunwọ ẽru ninu ileru, ki Mose ki o kù u si oju-ọrun li oju Farao. 9 Yio si di ekuru lẹbulẹbu ni gbogbo ilẹ Egipti, yio si di õwo ti yio ma tú pẹlu ileròro lara enia, ati lara ẹran, ká gbogbo ilẹ Egipti. 10 Nwọn si bù ẽru ninu ileru, nwọn duro niwaju Farao; Mose si kù u si oke ọrun; o si di õwo ti o ntú jade pẹlu ileròro lara enia ati lara ẹran. 11 Awọn alalupayida kò si le duro niwaju Mose nitori õwo wọnni; nitoriti õwo na wà lara awọn alalupayida, ati lara gbogbo awọn ara Egipti. 12 OLUWA si mu àiya Farao le, kò si gbọ́ ti wọn; bi OLUWA ti sọ fun Mose. 13 OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao, ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ ki nwọn le sìn mi. 14 Nitori ìgba yi li emi o rán gbogbo iyọnu mi si àiya rẹ, ati sara awọn iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe kò si ẹlomiran bi emi ni gbogbo aiye. 15 Nitori nisisiyi, emi iba nà ọwọ́ mi, ki emi ki o le fi ajakalẹ-àrun lù ọ, ati awọn enia rẹ; a ba si ti ke ọ kuro lori ilẹ. 16 Ṣugbọn nitori eyi pãpa li emi ṣe mu ọ duro, lati fi agbara mi hàn lara rẹ; ati ki a le ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye. 17 Titi di isisiyi iwọ ngbé ara rẹ ga si awọn enia mi pe, iwọ ki yio jẹ ki nwọn ki o lọ? 18 Kiyesi i, li ọla li akokò yi, li emi o mu ọ̀pọ yinyin rọ̀ si ilẹ, irú eyiti kò ti si ni Egipti lati ipilẹṣẹ rẹ̀ titi o fi di isisiyi. 19 Njẹ nisisiyi ranṣẹ, ki o si kó ẹran rẹ bọ̀, ati ohun gbogbo ti o ni ninu oko; nitori olukuluku enia ati ẹran ti a ba ri li oko, ti a kò si múbọ̀ wá ile, yinyin yio bọ lù wọn, nwọn o si kú. 20 Ẹniti o bẹ̀ru ọ̀rọ OLUWA ninu awọn iranṣẹ Farao, mu ki awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ sá padà wá ile: 21 Ẹniti kò si kà ọ̀rọ OLUWA si, jọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ si oko. 22 OLUWA si sọ fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si oke ọrun, ki yinyin ki o le bọ́ si gbogbo ilẹ Egipti, sara enia, ati sara ẹranko, ati sara eweko igbẹ́ gbogbo, já gbogbo ilẹ Egipti. 23 Mose si nà ọpá rẹ̀ si ọrun: OLUWA si rán ãra ati yinyin, iná na si njó lori ilẹ; OLUWA si rọ̀ yinyin sori ilẹ Egipti. 24 Yinyin si bọ́, iná si dàpọ mọ́ yinyin na, o papọ̀ju, irú rẹ̀ kò si ri ni gbogbo ilẹ Egipti lati ìgba ti o ti di orilẹ-ède. 25 Yinyin na si lù ohun gbogbo ti o wà ninu oko bolẹ, ati enia ati ẹranko, já gbogbo ilẹ Egipti; yinyin na si lù gbogbo eweko bolẹ, o si fà gbogbo igi igbẹ́ ya. 26 Ni kìki ilẹ Goṣeni, nibiti awọn ọmọ Israeli gbé wà, ni yinyin kò si. 27 Farao si ranṣẹ, o si pè Mose ati Aaroni, o si wi fun wọn pe, Emi ṣẹ̀ nigbayi: OLUWA li olododo, ẹni buburu si li emi ati awọn enia mi. 28 Ẹ bẹ̀ OLUWA (o sa to) ki ãra nla ati yinyin wọnyi ki o máṣe si mọ́; emi o si jẹ ki ẹ ma lọ; ẹ ki yio si duro mọ́. 29 Mose si wi fun u pe, Bi mo ba ti jade ni ilu, emi o tẹ́ ọwọ́ mi si OLUWA; ãra yio si dá, bẹ̃ni yinyin ki yio si mọ́; ki iwọ ki o le mọ̀ pe ti OLUWA li aiye. 30 Ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni ati ti awọn iranṣẹ rẹ, emi mọ̀ pe sibẹ, ẹnyin kò ti ibẹ̀ru OLUWA Ọlọrun. 31 A si lù ọgbọ́ ati ọkà barle bolẹ; nitori ọkà barle wà ni ipẹ́, ọgbọ́ si rudi. 32 Ṣugbọn alikama ati ọkà (rie) li a kò lù bolẹ: nitoriti nwọn kò ti idàgba. 33 Mose si jade kuro lọdọ Farao sẹhin ilu, o si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ si OLUWA; ãra ati yinyin si dá, bẹ̃li òjo kò si rọ̀ si ilẹ̀ mọ́. 34 Nigbati Farao ri pe, òjo ati yinyin ati ãra dá, o ṣẹ̀ si i, o si sé àiya rẹ̀ le, on ati awọn iranṣẹ rẹ̀. 35 Àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ; bi OLUWA ti wi lati ọwọ́ Mose.

Eksodu 10

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ: nitoriti mo mu àiya rẹ̀ le, ati àiya awọn iranṣẹ rẹ̀, ki emi ki o le fi iṣẹ-àmi mi wọnyi hàn niwaju rẹ̀: 2 Ati ki iwọ ki o le wi li eti ọmọ rẹ, ati ti ọmọ ọmọ rẹ, ohun ti mo ṣe ni Egipti, ati iṣẹ-àmi mi ti mo ṣe ninu wọn; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA. 3 Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si wi fun u pe, Bayi li OLUWA Ọlọrun Heberu wi, Iwọ o ti kọ̀ pẹ tó lati rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju mi? jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi. 4 Ṣugbọn bi iwọ ba si kọ̀ lati jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, kiyesi i, li ọla li emi o mú eṣú wá si ẹkùn rẹ: 5 Nwọn o si bò oju ilẹ ti ẹnikan ki yio fi le ri ilẹ: nwọn o si jẹ ajẹkù eyiti o bọ́, ti o kù fun nyin lọwọ yinyin, yio si jẹ igi nyin gbogbo ti o nruwe ninu oko. 6 Nwọn o si kún ile rẹ, ati ile awọn iranṣẹ rẹ gbogbo, ati ile awọn ara Egipti gbogbo; ti awọn baba rẹ, ati awọn baba baba rẹ kò ri ri, lati ìgba ọjọ́ ti nwọn ti wà lori ilẹ titi o fi di oni-oloni. O si yipada, o jade kuro lọdọ Farao. 7 Awọn iranṣẹ Farao si wi fun u pe, ọkunrin yi yio ti ṣe ikẹkùn si wa pẹ to? jẹ ki awọn ọkunrin na ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn OLUWA Ọlọrun wọn: iwọ kò ti imọ̀ pe Egipti run tán? 8 A si tun mú Mose ati Aaroni wá sọdọ Farao: o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ sìn OLUWA Ọlọrun nyin; ṣugbọn awọn tani yio ha lọ? 9 Mose si wipe, Awa o lọ ati ewe ati àgba, ati awọn ọmọkunrin wa ati awọn ọmọbinrin wa, pẹlu awọn agbo, ati ọwọ́-ẹran wa li awa o lọ; nitori ajọ OLUWA ni fun wa: 10 O si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o pẹlu nyin bẹ̃, bi emi o ti jẹ ki ẹ lọ yi, ati awọn ewe nyin: ẹ wò o; nitori ibi mbẹ niwaju nyin. 11 Bẹ̃kọ: ẹnyin ọkunrin ẹ lọ, ki ẹ si sìn OLUWA; eyinì li ẹnyin sá nfẹ́. Nwọn si lé wọn jade kuro niwaju Farao. 12 OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ sori ilẹ Egipti nitori eṣú, ki nwọn ki o le wá sori ilẹ Egipti, ki nwọn ki o si le jẹ gbogbo eweko ilẹ yi, gbogbo eyiti yinyin ti kù silẹ. 13 Mose si nà ọpá rẹ̀ si ori ilẹ Egipti, OLUWA si mu afẹfẹ ìla-õrùn kan fẹ́ si ori ilẹ na, ni gbogbo ọsán na, ati gbogbo oru na; nigbati o di owurọ̀, afẹfẹ ila-õrùn mú awọn eṣú na wá. 14 Awọn eṣú na si goke sori ilẹ Egipti gbogbo, nwọn si bà si ẹkùn Egipti gbogbo; nwọn papọ̀ju, kò si irú eṣú bẹ̃ ṣaju wọn, bẹ̃ni lẹhin wọn irú wọn ki yio si si. 15 Nitoriti nwọn bò oju ilẹ gbogbo, tobẹ̃ ti ilẹ fi ṣú; nwọn si jẹ gbogbo eweko ilẹ na, ati gbogbo eso igi ti yinyin kù silẹ: kò si kù ohun tutù kan lara igi, tabi lara eweko igbẹ́, já gbogbo ilẹ Egipti. 16 Nigbana ni Farao ranṣẹ pè Mose ati Aaroni kánkan; o si wipe, Emi ti ṣẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ati si nyin. 17 Njẹ nitorina emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ẹ̀ṣẹ mi jì lẹ̃kanṣoṣo yi, ki ẹ si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun nyin, ki o le mú ikú yi kuro lọdọ mi. 18 On si jade kuro niwaju Farao, o si bẹ̀ OLUWA. 19 OLUWA si yi afẹfẹ ìwọ-õrùn lile-lile ti o si fẹ́ awọn eṣú na kuro, o si gbá wọn lọ sinu Okun Pupa; kò si kù eṣú kanṣoṣo ni gbogbo ẹkùn Egipti. 20 Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ. 21 OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si ọrun, ki òkunkun ki o ṣú yiká ilẹ Egipti, ani òkunkun ti a le fọwọbà. 22 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si ọrun; òkunkun biribiri si ṣú ni gbogbo ilẹ Egipti ni ijọ́ mẹta: 23 Nwọn kò ri ara wọn, bẹ̃li ẹnikan kò si dide ni ipò tirẹ̀ ni ijọ́ mẹta: ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Israeli li o ni imọle ni ibugbé wọn. 24 Farao si pè Mose, o si wipe, Ẹ ma lọ, ẹ sìn OLUWA; kìki agbo ati ọwọ́-ẹran nyin ni ki o kù lẹhin; ki awọn ewe nyin ki o bá nyin lọ pẹlu. 25 Mose si wipe, Iwọ kò le ṣaima fun wa li ohun ẹbọ pẹlu ati ẹbọ sisun, ti awa o fi rubọ si OLUWA Ọlọrun wa. 26 Ẹran-ọ̀sin wa yio si bá wa lọ pẹlu; a ki yio fi ibósẹ-ẹran kan silẹ lẹhin; nitori ninu rẹ̀ li awa o mú sìn OLUWA Ọlọrun wa; awa kò si mọ̀ ohun na ti a o fi sìn OLUWA, titi awa o fi dé ibẹ̀. 27 Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, kò si fẹ́ jẹ ki nwọn lọ. 28 Farao si wi fun u pe, Kuro lọdọ mi, ma ṣọ́ ara rẹ, máṣe tun ri oju mi mọ́; nitori ni ijọ́ na ti iwọ ba ri oju mi iwọ o kú. 29 Mose si wipe, Iwọ fọ̀ rere; emi ki yio tun ri oju rẹ mọ́.

Eksodu 11

Mose Kéde Ikú Àwọn Àkọ́bí

1 OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o tun mú iyọnu kan wá sara Farao, ati sara Egipti; lẹhin eyinì ni on o jọwọ nyin lọwọ lọ lati ihin: nigbati on o jẹ ki ẹ lọ, àtitán ni yio tì nyin jade nihin. 2 Wi nisisiyi li eti awọn enia wọnyi, ki olukuluku ọkunrin ki o bère lọdọ aladugbo rẹ̀ ati olukuluku obinrin lọdọ aladugbo rẹ̀, ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà. 3 OLUWA si fi ojurere fun awọn enia na li oju awọn ara Egipti. Pẹlupẹlu Mose ọkunrin nì o pọ̀ gidigidi ni ilẹ Egipti, li oju awọn iranṣẹ Farao, ati li oju awọn enia na. 4 Mose si wipe, Bayi li OLUWA wi, Lãrin ọganjọ li emi o jade lọ sãrin Egipti: 5 Gbogbo awọn akọ́bi ti o wà ni ilẹ Egipti ni yio si kú, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀, titi yio si fi dé akọ́bi iranṣẹbinrin ti o wà lẹhin ọlọ; ati gbogbo akọ́bi ẹran. 6 Ẹkún nla yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, eyiti irú rẹ̀ kò si ri, ti ki yio si si irú rẹ̀ mọ́. 7 Ṣugbọn si ọkan ninu awọn ọmọ Israeli li ajá ki yio yọ ahọn rẹ̀, si enia tabi si ẹran: ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi OLUWA ti fi ìyatọ sãrin awọn ara Egipti ati Israeli. 8 Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ wọnyi ni yio si sọkalẹ tọ̀ mi wá, ti nwọn o si fori wọn balẹ fun mi pe, Iwọ jade lọ ati gbogbo awọn enia ẹhin rẹ: lẹhin ìgba na li emi o to jade. O si jade kuro niwaju Farao ni ibinu nla. 9 OLUWA si wi fun Mose pe, Farao ki yio gbọ́ tirẹ; ki a le sọ iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti. 10 Mose ati Aaroni si ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu wọnyi niwaju Farao: OLUWA si mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si fẹ́ jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o jade lọ kuro ni ilẹ rẹ̀.

Eksodu 12

Àjọ Ìrékọjá

1 OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni ni ilẹ Egipti pe, 2 Oṣù yi ni yio ṣe akọ́kà oṣù fun nyin: on ni yio ṣe ekini oṣù ọdún fun nyin. 3 Ẹ sọ fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli pe, Ni ijọ́ kẹwa oṣù yi ni ki olukuluku wọn ki o mú ọdọ-agutan sọdọ, gẹgẹ bi ile baba wọn, ọdọ-agutan kan fun ile kan: 4 Bi awọn ara ile na ba si kere jù ìwọn ọdọ-agutan na lọ, ki on ati aladugbo rẹ̀ ti o sunmọ-eti ile rẹ̀, ki o mú gẹgẹ bi iye awọn ọkàn na, olukuluku ni ìwọn ijẹ rẹ̀ ni ki ẹ ṣiro ọdọ-agutan na. 5 Ailabùku ni ki ọdọ-agutan nyin ki o jẹ́, akọ ọlọdún kan: ẹnyin o mú u ninu agutan, tabi ninu ewurẹ: 6 Ẹnyin o si fi i pamọ́ titi o fi di ijọ́ kẹrinla oṣù na: gbogbo agbajọ ijọ Israeli ni yio pa a li aṣalẹ. 7 Nwọn o si mú ninu ẹ̀jẹ na, nwọn o si fi tọ́ ara opó ìha mejeji, ati sara atẹrigba ile wọnni, ninu eyiti nwọn o jẹ ẹ. 8 Nwọn o si jẹ ẹran na ti a fi iná sun li oru na, ati àkara alaiwu; ewebẹ kikorò ni nwọn o fi jẹ ẹ. 9 Ẹ máṣe jẹ ninu rẹ̀ ni tutù, tabi ti a fi omi bọ̀, bikoṣepe sisun ninu iná; ati ori rẹ̀, ati itan rẹ̀, ati akopọ̀ inu rẹ̀ pẹlu. 10 Ẹ kò si gbọdọ jẹ ki nkan ki o kù silẹ ninu rẹ̀ dé ojumọ́; eyiti o ba si kù di ijọ́ keji on ni ki ẹnyin ki o daná sun. 11 Bayi li ẹnyin o si jẹ ẹ; ti ẹnyin ti àmure didì li ẹgbẹ nyin, bàta nyin li ẹsẹ̀ nyin, ati ọpá nyin li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si yara jẹ ẹ: irekọja OLUWA ni. 12 Nitoriti emi o là ilẹ Egipti já li oru na, emi o si kọlù gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, ti enia ati ti ẹran; ati lara gbogbo oriṣa Egipti li emi o ṣe idajọ: emi li OLUWA. 13 Ẹ̀jẹ na ni yio si ṣe àmi fun nyin lara ile ti ẹnyin gbé wà: nigbati emi ba ri ẹ̀jẹ na, emi o ré nyin kọja, iyọnu na ki yio wá sori nyin lati run nyin nigbati mo ba kọlù ilẹ Egipti. 14 Ọjọ́ oni ni yio si ma ṣe ọjọ́ iranti fun nyin, ẹnyin o si ma ṣe e li ajọ fun OLUWA ni iran-iran nyin, ẹ o si ma ṣe e li ajọ nipa ìlana lailai.

Àjọ̀dún Àìwúkàrà

15 Ijọ́ meje li ẹ o fi ma jẹ àkara alaiwu; li ọjọ́ kini gan li ẹ o palẹ iwukàra mọ́ kuro ni ile nyin; nitori ẹniti o ba jẹ àkara wiwu lati ọjọ́ kini lọ titi o fi di ọjọ́ keje, ọkàn na li a o ke kuro ninu Israeli. 16 Ati li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà, ati li ọjọ́ keje apejọ mimọ́ yio wà fun nyin; a ki yio ṣe iṣẹkiṣẹ ninu wọn, bikoṣe eyiti olukuluku yio jẹ, kìki eyinì li a le ṣe ninu nyin. 17 Ẹ o si kiyesi ajọ aiwukàra; nitori li ọjọ́ na gan ni mo mú ogun nyin jade kuro ni ilẹ Egipti; nitorina ni ki ẹ ma kiyesi ọjọ́ na ni iran-iran nyin nipa ìlana lailai. 18 Li oṣù kini li ọjọ kẹrinla oṣù na li aṣalẹ li ẹ o jẹ àkara alaiwu, titi yio fi di ọjọ́ kọkanlelogun oṣù na li aṣalẹ. 19 Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na. 20 Ẹ kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti a wu; ninu ibugbé nyin gbogbo li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.

Àjọ Ìrékọjá Kinni

21 Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na. 22 Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀. 23 Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin. 24 Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai. 25 O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi. 26 Yio si ṣe nigbati awọn ọmọ nyin ba bi nyin pe, Eredi ìsin yi? 27 Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn. 28 Awọn ọmọ Israeli si lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.

Ikú Àwọn Àkọ́bí

29 O si ṣe lãrin ọganjọ́ li OLUWA pa gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀ titi o fi dé akọ́bi ẹrú ti o wà ni túbu; ati gbogbo akọ́bi ẹran-ọ̀sin. 30 Farao si dide li oru, on ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ara Egipti; igbe nla si ta ni Egipti; nitoriti kò si ile kan ti enia kan kò kú. 31 O si pè Mose on Aaroni li oru, o si wipe, Ẹ dide, ki ẹ jade lọ kuro lãrin awọn enia mi, ati ẹnyin ati awọn ọmọ Israeli; ki ẹ si lọ sìn OLUWA, bi ẹ ti wi. 32 Ẹ si mú agbo nyin ati ọwọ́-ẹran nyin, bi ẹ ti wi, ki ẹ si ma lọ; ki ẹ si sure fun mi pẹlu. 33 Awọn ara Egipti si nrọ̀ awọn enia na, ki nwọn ki o le rán wọn jade lọ kuro ni ilẹ na kánkan; nitoriti nwọn wipe, Gbogbo wa di okú. 34 Awọn enia na si mú iyẹfun pipò wọn ki nwọn ki o to fi iwukàra si i, a si dì ọpọ́n ìpo-iyẹfun wọn sinu aṣọ wọn lé ejika wọn. 35 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; nwọn si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ lọwọ awọn ara Egipti. 36 OLUWA si fun awọn enia na li ojurere li oju awọn ara Egipti, bẹ̃ni nwọn si fun wọn li ohun ti nwọn bère. Nwọn si kó ẹrù awọn ara Egipti. 37 Awọn ọmọ Israeli si rìn lati Ramesesi lọ si Sukkotu, nwọn to ìwọn ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀ ọkunrin, li àika ọmọde. 38 Ati ọ̀pọ enia ti o dàpọ mọ́ wọn bá wọn goke lọ pẹlu; ati agbo, ati ọwọ́-ẹran, ani ọ̀pọlọpọ ẹran. 39 Nwọn si yan àkara iyẹfun pipò alaiwu ti nwọn mú jade ti Egipti wá, nwọn kò sa fi iwukàra si i; nitoriti a tì wọn jade kuro ni Egipti, nwọn kò si le duro, bẹ̃ni nwọn kò pèse ohun jijẹ kan fun ara wọn. 40 Njẹ ìgba atipo awọn ọmọ Israeli ti nwọn ṣe ni ilẹ Egipti, o jẹ́ irinwo ọdún o le ọgbọ̀n. 41 O si ṣe li opin irinwo ọdún o le ọgbọ̀n, ani li ọjọ́ na gan, li o si ṣe ti gbogbo ogun OLUWA jade kuro ni ilẹ Egipti. 42 Oru ti a ikiyesi ni gidigidi si OLUWA ni mimú wọn jade kuro ni ilẹ Egipti: eyi li oru ti a ikiyesi si OLUWA, li ati irandiran gbogbo awọn ọmọ Israeli. 43 OLUWA si wi fun Mose ati Aaroni pe, Eyi ni ìlana irekọja: alejokalejò ki yio jẹ ninu rẹ̀: 44 Ṣugbọn iranṣẹ ẹnikẹni ti a fi owo rà, nigbati iwọ ba kọ ọ nilà, nigbana ni ki o jẹ ninu rẹ̀. 45 Alejò ati alagbaṣe ki yio jẹ ninu rẹ̀. 46 Ni ile kan li a o jẹ ẹ; iwọ kò gbọdọ mú ninu ẹran rẹ̀ jade sode kuro ninu ile na; bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọ́ ọkan ninu egungun rẹ̀. 47 Gbogbo ijọ Israeli ni yio ṣe e. 48 Nigbati alejò kan ba nṣe atipo lọdọ rẹ, ti o si nṣe ajọ irekọja si OLUWA, ki a kọ gbogbo ọkunrin rẹ̀ nilà, nigbana ni ki ẹ jẹ ki o sunmọtosi, ki o si ṣe e; on o si dabi ẹniti a bi ni ilẹ na: nitoriti kò si ẹni alaikọlà ti yio jẹ ninu rẹ̀. 49 Ofin kan ni fun ibilẹ ati fun alejò ti o ṣe atipo ninu nyin. 50 Bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ṣe; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe. 51 O si ṣe li ọjọ́ na gan, OLUWA mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn.

Eksodu 13

1 OLUWA si wi fun Mose pe, 2 Yà gbogbo awọn akọ́bi sọ̀tọ fun mi, gbogbo eyiti iṣe akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia, ati ti ẹran: ti emi ni iṣe. 3 Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ ranti ọjọ́ oni, ninu eyiti ẹnyin jade kuro ni Egipti, kuro li oko-ẹrú; nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú nyin jade kuro nihin: a ki yio si jẹ àkara wiwu. 4 Li ọjọ́ oni li ẹnyin jade li oṣù Abibu. 5 Yio si ṣe nigbati OLUWA yio mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn enia Hitti, ati ti awọn ara Amori, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, on ni iwọ o ma sìn ìsin yi li oṣù yi. 6 Ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, li ọjọ́ keje li ajọ yio wà fun OLUWA. 7 Ọjọ́ meje li a o fi jẹ àkara alaiwu; ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ, bẹ̃ni ki a má si ṣe ri iwukàra lọdọ rẹ ni gbogbo ẹkùn rẹ. 8 Iwọ o si sọ fun ọmọ rẹ li ọjọ́ na pe, A nṣe eyi nitori eyiti OLUWA ṣe fun mi nigbati mo jade kuro ni Egipti. 9 Yio si ma ṣe àmi fun ọ li ọwọ́ rẹ, ati fun àmi iranti li agbedemeji oju rẹ, ki ofin OLUWA ki o le wà li ẹnu rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú ọ jade kuro ni Egipti. 10 Nitorina ni ki iwọ ki o ma kiyesi ìlana yi li akokò rẹ̀ li ọdọdún. 11 Yio si ṣe nigbati OLUWA ba mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, bi o ti bura fun ọ, ati fun awọn baba rẹ, ti yio si fi fun ọ. 12 Ni iwọ o si yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun OLUWA, ati gbogbo akọ́bi ẹran ti iwọ ni; ti OLUWA li awọn akọ. 13 Ati gbogbo akọ́bi kẹtẹkẹtẹ ni ki iwọ ki o fi ọdọ-agutan rapada; bi iwọ kò ba rà a pada, njẹ ki iwọ ki o sẹ ẹ li ọrùn: ati gbogbo akọ́bi enia ninu awọn ọmọ ọkunrin rẹ ni iwọ o rapada. 14 Yio si ṣe nigbati ọmọ rẹ yio bère lọwọ rẹ lẹhin-ọla pe, Kili eyi? ki iwọ ki o wi fun u pe, Ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni ilẹ Egipti, kuro li oko-ẹrú: 15 O si ṣe, nigbati Farao kọ̀ lati jẹ ki a lọ, on li OLUWA pa gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ati akọ́bi enia, ati akọ́bi ẹran; nitorina ni mo ṣe fi gbogbo akọ́bi ti iṣe akọ rubọ si OLUWA; ṣugbọn gbogbo awọn akọ́bi ọmọ ọkunrin mi ni mo rapada. 16 Yio si ma ṣe àmi li ọwọ́ rẹ, ati ọjá-igbaju lagbedemeji oju rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni Egipti. 17 O si ṣe, nigbati Farao jẹ ki awọn enia na ki o lọ tán, Ọlọrun kò si mú wọn tọ̀ ọ̀na ilẹ awọn ara Filistia, eyi li o sa yá; nitoriti Ọlọrun wipe, Ki awọn enia má ba yi ọkàn pada nigbati nwọn ba ri ogun, ki nwọn si pada lọ si Egipti. 18 Ṣugbọn Ọlọrun mu wọn yi lọ li ọ̀na ijù Okun Pupa: awọn ọmọ Israeli jade lọ kuro ni ilẹ Egipti ni ihamọra. 19 Mose si gbé egungun Josefu lọ pẹlu rẹ̀; nitori ibura lile li o mu awọn ọmọ Israeli bu pe, Lõtọ li Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò; ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lọ pẹlu nyin kuro nihin. 20 Nwọn si mu ọ̀na-àjo wọn pọ̀n lati Sukkoti lọ, nwọn si dó si Etamu leti ijù. 21 OLUWA si nlọ niwaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma li ọsán, lati ma ṣe amọna fun wọn; ati li oru li ọwọ̀n iná lati ma fi imọlẹ fun wọn; lati ma rìn li ọsán ati li oru. 22 Ọwọ̀n awọsanma na kò kuro li ọsán, tabi ọwọ̀n iná li oru, niwaju awọn enia na.

Eksodu 14

1 OLUWA si wi fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o dari, ki nwọn ki o si dó si iwaju Pi-hahirotu, li agbedemeji Migdolu on okun, niwaju Baal-sefoni: lọkankan rẹ̀ li ẹba okun ni ki ẹnyin ki o dó si. 3 Nitoriti Farao yio wi niti awọn ọmọ Israeli pe, Nwọn há ni ilẹ na, ijù na sé wọn mọ́. 4 Emi o si mu àiya Farao le, ti yio fi lepa wọn; a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori ogun rẹ̀ gbogbo; ki awọn ara Egipti ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA. Nwọn si ṣe bẹ̃. 5 A si wi fun ọba Egipti pe, awọn enia na sá: àiya Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀ si yi si awọn enia na, nwọn si wipe, Ẽṣe ti awa fi ṣe eyi, ti awa fi jẹ ki Israeli ki o lọ kuro ninu ìsin wa? 6 O si dì kẹkẹ́ rẹ̀, o si mú awọn enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀. 7 O si mú ẹgbẹta ãyo kẹkẹ́, ati gbogbo kẹkẹ́ Egipti, ati olori si olukuluku wọn. 8 OLUWA si mu àiya Farao ọba Egipti le, o si lepa awọn ọmọ Israeli: ọwọ́ giga li awọn ọmọ Israeli si fi jade lọ. 9 Ṣugbọn awọn ara Egipti lepa wọn, gbogbo ẹṣin ati kẹkẹ́ Farao, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, ati awọn ogun rẹ̀, o si lé wọn bá, nwọn duro li ẹba okun ni ìha Pi-hahirotu niwaju Baal-sefoni. 10 Nigbati Farao si nsunmọtosi, awọn ọmọ Israeli gbé oju soke, si kiyesi i, awọn ara Egipti mbọ̀ lẹhin wọn; ẹ̀ru si bà wọn gidigidi: awọn ọmọ Israeli si kigbe pè OLUWA. 11 Nwọn si wi fun Mose pe, Nitoriti isà kò sí ni Egipti, ki iwọ ṣe mú wa wá lati kú ni ijù? ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃, lati mú wa jade ti Egipti wá? 12 Ọrọ yi ki awa ti sọ fun ọ ni Egipti pe, Jọwọ wa jẹ ki awa ki o ma sìn awọn ara Egipti? O sá san fun wa lati ma sin awọn ara Egipti, jù ki awa kú li aginjù lọ. 13 Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri ìgbala OLUWA, ti yio fihàn nyin li oni: nitori awọn ara Egipti ti ẹnyin ri li oni yi, ẹnyin ki yio si tun ri wọn mọ́ lailai. 14 Nitoriti OLUWA yio jà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pa ẹnu nyin mọ́. 15 OLUWA si wi fun Mose pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkepè mi? sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o tẹ̀ siwaju: 16 Ṣugbọn iwọ gbé ọpá rẹ soke, ki iwọ ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju okun ki o si yà a meji: awọn ọmọ Israeli yio si là ãrin okun na kọja ni iyangbẹ ilẹ. 17 Ati emi kiyesi i, emi o mu àiya awọn ara Egipti le, nwọn o si tẹle wọn: a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori gbogbo ogun rẹ̀, ati lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀. 18 Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba gbà ogo lori Farao, lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀. 19 Angeli Ọlọrun na ti o ṣaju ogun Israeli, o si ṣi lọ ṣẹhin wọn; ọwọ̀n awọsanma si ṣi kuro niwaju wọn, o si duro lẹhin wọn: 20 O si wá si agbedemeji ogun awọn ara Egipti ati ogun Israeli; o si ṣe awọsanma ati òkunkun fun awọn ti ọhún, ṣugbọn o ṣe imọlẹ li oru fun awọn ti ihin: bẹ̃li ekini kò sunmọ ekeji ni gbogbo oru na. 21 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun; OLUWA si fi afẹfẹ lile ìla-õrùn mu okun bì sẹhin ni gbogbo oru na, o si mu okun gbẹ: omi na si pinya. 22 Awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ãrin okun ni ilẹ gbigbẹ: omi si ṣe odi si wọn li ọwọ ọtún, ati ọwọ́ òsi. 23 Awọn ara Egipti si lepa wọn, nwọn si wọ̀ ọ tọ̀ wọn lọ lãrin okun, ati gbogbo ẹṣin Farao, ati kẹkẹ́ rẹ̀, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. 24 O si ṣe, nigba iṣọ owurọ̀, OLUWA bojuwò ogun ara Egipti lãrin ọwọ̀n iná, ati ti awọsanma, o si pá ogun awọn ara Egipti làiya. 25 O si yẹ̀ kẹkẹ́ wọn, nwọn si nwọ́ turu, awọn ara Egipti si wipe, Ẹ jẹ ki a sá kuro niwaju Israeli; nitoriti OLUWA mbá awọn ara Egipti jà fun wọn. 26 OLUWA si wi fun Mose pe; Nà ọwọ́ rẹ si oju okun, ki omi ki o tun pada wá sori awọn ara Egipti, sori kẹkẹ́ wọn, ati sori ẹlẹṣin wọn. 27 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun, okun si pada bọ̀ si ipò rẹ̀ nigbati ilẹ mọ́; awọn ara Egipti si sá lù u. OLUWA si bì awọn ara Egipti ṣubu lãrin okun. 28 Omi si pada, o si bò kẹkẹ́, ati awọn ẹlẹṣin, ati gbogbo ogun Farao ti o wọ̀ inu okun tọ̀ wọn lẹhin lọ; ọkanṣoṣo kò kù ninu wọn. 29 Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli rìn ni iyangbẹ ilẹ lãrin okun; omi si jẹ́ odi fun wọn li ọwọ́ ọtún, ati li ọwọ́ òsi wọn. 30 Bayi li OLUWA gbà Israeli là li ọjọ́ na lọwọ awọn ara Egipti; Israeli si ri okú awọn ara Egipti leti okun. 31 Israeli si ri iṣẹ nla ti OLUWA ṣe lara awọn ara Egipti: awọn enia na si bẹ̀ru OLUWA, nwọn si gbà OLUWA ati Mose iranṣẹ rẹ̀ gbọ́.

Eksodu 15

1 NIGBANA ni Mose ati awọn ọmọ Israeli kọ orin yi si OLUWA nwọn si wipe, Emi o kọrin si OLUWA, nitoriti o pọ̀ li ogo: ati ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun. 2 OLUWA li agbara ati orin mi, on li o si di ìgbala mi: eyi li Ọlọrun mi, emi o si fi ìyin fun u; Ọlọrun baba mi, emi o gbé e leke. 3 Ologun li OLUWA; OLUWA li orukọ rẹ̀. 4 Kẹkẹ́ Farao ati ogun rẹ̀ li o mu wọ̀ inu okun: awọn ãyo olori ogun rẹ̀ li o si rì ninu Okun Pupa. 5 Ibú bò wọn mọlẹ: nwọn rì si isalẹ bi okuta. 6 OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ li ogo ninu agbara: OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ fọ́ ọtá tútu. 7 Ati ni ọ̀pọlọpọ ọlá rẹ ni iwọ bì awọn ti o dide si ọ ṣubu; iwọ rán ibinu rẹ, ti o run wọn bi akemọlẹ idi koriko. 8 Ati nipa ẽmi imu rẹ, li omi si fi wọjọ pọ̀, ìṣan omi dide duro gangan bi ogiri; ibú si dìlu lãrin okun. 9 Ọtá wipe, Emi o lepa, emi o bá wọn, emi o pín ikogun: a o tẹ́ ifẹkufẹ mi lọrùn lara wọn; emi o fà dà mi yọ, ọwọ́ mi ni yio pa wọn run. 10 Iwọ si mu afẹfẹ rẹ fẹ́, okun bò wọn mọlẹ: nwọn rì bi ojé ninu omi nla. 11 Tali o dabi iwọ, OLUWA, ninu awọn alagbara? tali o dabi iwọ, ologo ni mimọ́, ẹlẹru ni iyìn, ti nṣe ohun iyanu? 12 Iwọ nà ọwọ́ ọtún rẹ, ilẹ gbe wọn mì. 13 Ninu ãnu rẹ ni iwọ fi ṣe amọ̀na awọn enia na ti iwọ ti rapada: iwọ si nfi agbara rẹ tọ́ wọn lọ si ibujoko mimọ́ rẹ. 14 Awọn enia gbọ́, nwọn warìri; ikãnu si mú awọn olugbe Palestina. 15 Nigbana li ẹnu yà awọn balẹ Edomu; iwarìri si mú awọn alagbara Moabu: gbogbo awọn olugbe Kenaani yọ́ dànu. 16 Ibẹru-bojo mú wọn; nipa titobi apa rẹ nwọn duro jẹ bi okuta; titi awọn enia rẹ fi rekọja, OLUWA, titi awọn enia rẹ ti iwọ ti rà fi rekọja. 17 Iwọ o mú wọn wọle, iwọ o si gbìn wọn sinu oke ilẹ-iní rẹ, OLUWA, ni ibi ti iwọ ti ṣe fun ara rẹ, lati mã gbé, OLUWA; ni ibi mimọ́ na, ti ọwọ́ rẹ ti gbekalẹ. 18 OLUWA yio jọba lai ati lailai. 19 Nitori ẹṣin Farao wọ̀ inu okun lọ, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, OLUWA si tun mú omi okun pada si wọn lori; ṣugbọn awọn ọmọ Israeli rìn ni ilẹ gbigbẹ lãrin okun. 20 Ati Miriamu wolĩ obinrin, arabinrin Aaroni, o mú ìlu li ọwọ́ rẹ̀: gbogbo awọn obinrin si jade tẹle e ti awọn ti ìlu ati ijó. 21 Miriamu si da wọn li ohùn pe, Ẹ kọrin si OLUWA nitoriti o pọ̀ li ogo; ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun. 22 Bẹ̃ni Mose mú Israeli jade lati Okun Pupa wá, nwọn si jade lọ si ijù Ṣuri; nwọn si lọ ni ìrin ijọ́ mẹta ni ijù na, nwọn kò si ri omi. 23 Nigbati nwọn dé Mara, nwọn ko le mu ninu omi Mara, nitoriti o korò; nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Mara. 24 Awọn enia na si nkùn si Mose wipe, Kili awa o mu? 25 O si kepè OLUWA; OLUWA si fi igi kan hàn a, nigbati o si sọ ọ sinu omi na, omi si di didùn. Nibẹ̀ li o si gbé ṣe ofin ati ìlana fun wọn, nibẹ̀ li o si gbé dán wọn wò; 26 O si wipe, Bi iwọ o ba tẹtisilẹ gidigidi si ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o ba si ṣe eyiti o tọ́ li oju rẹ̀, ti iwọ o ba si fetisi ofin rẹ̀, ti iwọ o ba si pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́, emi ki yio si fi ọkan ninu àrun wọnni ti mo múwa sara awọn ara Egipti si ọ lara: nitori emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá. 27 Nwọn si dé Elimu, nibiti kanga omi mejila gbé wà, ati ãdọrin ọpẹ: nwọn si dó si ìha omi wọnni nibẹ̀.

Eksodu 16

1 NWỌN si ṣí lati Elimu, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si dé ijù Sini, ti o wà li agbedemeji Elimu on Sinai, ni ijọ́ kẹdogun oṣù keji, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni ilẹ Egipti. 2 Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni ni ijù na: 3 Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi. 4 Nigbana li OLUWA sọ fun Mose pe, Kiyesi i, emi o rọ̀jo onjẹ fun nyin lati ọrun wá; awọn enia yio si ma jade lọ ikó ìwọn ti õjọ li ojojumọ́, ki emi ki o le dan wọn wò, bi nwọn o fẹ́ lati ma rìn nipa ofin mi, bi bẹ̃kọ. 5 Yio si ṣe, li ọjọ́ kẹfa, nwọn o si pèse eyiti nwọn múwa; yio si to ìwọn meji eyiti nwọn ima kó li ojojumọ́. 6 Mose ati Aaroni si wi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli pe, Li aṣalẹ, li ẹnyin o si mọ̀ pe, OLUWA li o mú nyin jade lati Egipti wá: 7 Ati li owurọ̀ li ẹnyin o si ri ogo OLUWA; nitoriti o gbọ́ kikùn nyin si OLUWA: ta si li awa, ti ẹnyin nkùn si wa? 8 Mose si wi pe, Bayi ni yio ri nigbati OLUWA yio fun nyin li ẹran jẹ li aṣalẹ, ati onjẹ ajẹyo li owurọ̀; nitoriti OLUWA gbọ́ kikùn nyin ti ẹnyin kùn si i: ta si li awa? kikùn nyin ki iṣe si wa, bikoṣe si OLUWA. 9 Mose si sọ fun Aaroni pe, Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ iwaju OLUWA, nitoriti o ti gbọ́ kikùn nyin. 10 O si ṣe, nigbati Aaroni nsọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si bojuwò ìha ijù, si kiyesi i, ogo OLUWA hàn li awọsanma na. 11 OLUWA si sọ fun Mose pe, 12 Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli: sọ fun wọn pe, Li aṣalẹ ẹnyin o jẹ ẹran, ati li owurọ̀ a o si fi onjẹ kún nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 13 O si ṣe li aṣalẹ ni aparò fò dé, nwọn si bò ibudó mọlẹ; ati li owurọ̀ ìri si sẹ̀ yi gbogbo ibudó na ká. 14 Nigbati ìri ti o sẹ̀ bolẹ si fà soke, si kiyesi i, lori ilẹ ijù na, ohun ribiribi, o kere bi ìri didì li ori ilẹ. 15 Nigbati awọn ọmọ Israeli si ri i, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili eyi? nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun na. Mose si wi fun wọn pe, Eyi li onjẹ ti OLUWA fi fun nyin lati jẹ. 16 Eyi li ohun ti OLUWA ti palaṣẹ, ki olukuluku ki o ma kó bi ìwọn ijẹ rẹ̀; òṣuwọn omeri kan fun ẹni kọkan, gẹgẹ bi iye awọn enia nyin, ki olukuluku nyin mú fun awọn ti o wà ninu agọ́ rẹ̀. 17 Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃, nwọn si kó, ẹlomiran pupọ̀jù, ẹlomiran li aito. 18 Nigbati nwọn si fi òṣuwọn omeri wọ̀n ọ, ẹniti o kó pupọ̀ kò ni nkan lé, ẹniti o si kó kere jù, kò ṣe alaito nwọn si kó olukuluku bi ijẹ tirẹ̀. 19 Mose si wi fun wọn pe, Ki ẹnikan ki o má kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀. 20 Ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ti Mose; bẹ̃li ẹlomiran si kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, o si di idin, o si rùn; Mose si binu si wọn. 21 Nwọn si nkó o li orowurọ̀, olukuluku bi ijẹ tirẹ̀; nigbati õrùn si mu, o yọ́. 22 O si ṣe ni ijọ́ kẹfa, nwọn kó ìwọn onjẹ ẹrinmeji, omeri meji fun ẹni kọkan: gbogbo awọn olori ijọ na si wá nwọn sọ fun Mose. 23 O si wi fun wọn pe, Eyi na li OLUWA ti wi pe, Ọla li ọjọ́ isimi, isimi mimọ́ fun OLUWA; ẹ yan eyiti ẹnyin ni iyan, ki ẹ si bọ̀ eyiti ẹnyin ni ibọ̀; eyiti o si kù, ẹ fi i silẹ lati pa a mọ́ dé owurọ̀. 24 Nwọn si fi i silẹ titi di owurọ̀, bi Mose ti paṣẹ fun wọn; kò si rùn, bẹ̃ni kò sí idin ninu rẹ̀. 25 Mose si wi pe, Ẹ jẹ eyinì li oni; nitori oni li ọjọ́ isimi fun OLUWA: li oni ẹnyin ki yio ri i ninu igbẹ́. 26 Li ọjọ́ mẹfa li ẹ o ma kó o; ṣugbọn li ọjọ́ keje li ọjọ́ isimi, ninu rẹ̀ ni ki yio si nkan. 27 O si ṣe li ọjọ́ keje awọn kan ninu awọn enia jade lọ ikó, nwọn kò si ri nkan. 28 OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹ o ti kọ̀ lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́ pẹ to? 29 Wò o, OLUWA sa ti fi ọjọ́ isimi fun nyin, nitorina li o ṣe fi onjẹ ijọ́ meji fun nyin li ọjọ́ kẹfa; ki olukuluku ki o joko ni ipò rẹ̀, ki ẹnikẹni ki o máṣe jade kuro ni ipò rẹ̀ li ọjọ́ keje. 30 Bẹ̃li awọn enia na simi li ọjọ́ keje. 31 Awọn ara ile Israeli si pè orukọ rẹ̀ ni Manna; o si dabi irugbìn korianderi, funfun; adùn rẹ̀ si dabi àkara fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe. 32 Mose si wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, Ẹ kún òṣuwọn omeri kan ninu rẹ̀ lati pamọ́ fun irandiran nyin; ki nwọn ki o le ma ri onjẹ ti mo fi bọ́ nyin ni ijù, nigbati mo mú nyin jade kuro ni ilẹ Egipti 33 Mose si wi fun Aaroni pe, Mú ìkoko kan, ki o si fi òṣuwọn omeri kan ti o kún fun manna sinu rẹ̀, ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA, lati pa a mọ́ fun irandiran nyin. 34 Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li Aaroni gbé e kalẹ niwaju ibi Ẹrí lati pa a mọ́. 35 Awọn ọmọ Israeli si jẹ manna li ogoji ọdún, titi nwọn fi dé ilẹ ti a tẹ̀dó; nwọn jẹ manna titi nwọn fi dé àgbegbe ilẹ Kenaani. 36 Njẹ òṣuwọn omeri kan ni idamẹwa efa.

Eksodu 17

1 GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si rìn lati ijù Sini lọ, ni ìrin wọn, gẹgẹ bi ofin OLUWA, nwọn si dó ni Refidimu: omi kò si si fun awọn enia na lati mu. 2 Nitorina li awọn enia na ṣe mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Fun wa li omi ki a mu. Mose si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbà mi sọ̀? ẽṣe ti ẹnyin fi ndán OLUWA wò? 3 Ongbẹ omi si ngbẹ awọn enia na nibẹ̀; awọn enia na si nkùn si Mose, nwọn si wipe, Ẽtiri ti iwọ fi mú wa goke lati Egipti wá, lati fi ongbẹ pa wa ati awọn ọmọ wa, ati ẹran wa? 4 Mose si kepè OLUWA, wipe, Kili emi o ṣe fun awọn enia yi? nwọn fẹrẹ̀ sọ mi li okuta. 5 OLUWA si wi fun Mose pe, Kọja lọ siwaju awọn enia na, ki o si mú ninu awọn àgbagba Israeli pẹlu rẹ, ki o si mú ọpá rẹ, ti o fi lù odò nì li ọwọ́ rẹ, ki o si ma lọ. 6 Kiyesi i, emi o duro niwaju rẹ nibẹ̀ lori okuta ni Horebu; iwọ o si lù okuta na, omi yio si jade ninu rẹ̀, ki awọn enia ki o le mu. Mose si ṣe bẹ̃ li oju awọn àgbagba Israeli. 7 O si sọ orukọ ibẹ̀ ni Massa, ati Meriba, nitori asọ̀ awọn ọmọ Israeli, ati nitoriti nwọn dan OLUWA wò pe, OLUWA ha mbẹ lãrin wa, tabi kò si? 8 Nigbana li Amaleki wá, o si bá Israeli jà ni Refidimu. 9 Mose si wi fun Joṣua pe, Yàn enia fun wa, ki o si jade lọ ibá Amaleki jà: li ọla li emi o duro lori oke ti emi ti ọpá Ọlọrun li ọwọ́ mi. 10 Joṣua si ṣe bi Mose ti wi fun u, o si bá Amaleki jà: ati Mose, Aaroni, on Huri lọ sori oke na. 11 O si ṣe, nigbati Mose ba gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, Israeli a bori: nigbati o ba si rẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ silẹ, Amaleki a bori. 12 Ṣugbọn ọwọ́ kún Mose; nwọn si mú okuta kan, nwọn si fi si abẹ rẹ̀, o si joko lé e; Aaroni ati Huri si mu u li ọwọ́ ró, ọkan li apa kini, ekeji li apa keji; ọwọ́ rẹ̀ si duro gan titi o fi di ìwọ-õrùn. 13 Joṣua si fi oju idà ṣẹgun Amaleki ati awọn enia rẹ̀ tútu 14 OLUWA si wi fun Mose pe, Kọ eyi sinu iwe fun iranti, ki o si kà a li eti Joṣua; nitoriti emi o pa iranti Amaleki run patapata kuro labẹ ọrun. 15 Mose si tẹ́ pẹpẹ kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni JEHOFA-nissi: 16 O si wipe, OLUWA ti bura: OLUWA yio bá Amaleki jà lati irandiran.

Eksodu 18

1 NIGBATI Jetro, alufa Midiani, ana Mose, gbọ́ ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun Mose, ati fun Israeli awọn enia rẹ̀, ati pe, OLUWA mú Israeli lati Egipti jade wá; 2 Nigbana ni Jetro, ana Mose, mú Sippora aya Mose wá, lẹhin ti o ti rán a pada. 3 Ati awọn ọmọ rẹ̀ mejeji: ti orukọ ọkan njẹ Gerṣomu; nitoriti o wipe, Emi ṣe alejò ni ilẹ ajeji. 4 Ati orukọ ekeji ni Elieseri; nitoriti o wipe, Ọlọrun baba mi li alatilẹhin mi, o si gbà mi lọwọ idà Farao: 5 Ati Jetro, ana Mose, o tọ̀ Mose wá ti on ti awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀ si ijù, nibiti o gbé dó si lẹba oke Ọlọrun. 6 O si wi fun Mose pe, Emi Jetro ana rẹ li o tọ̀ ọ wá, pẹlu aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ̀. 7 Mose si jade lọ ipade ana rẹ̀, o si tẹriba, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, nwọn si bére alafia ara wọn; nwọn si wọ̀ inu agọ́. 8 Mose si sọ ohun gbogbo ti OLUWA ti ṣe si Farao, ati si awọn ara Egipti nitori Israeli fun ana rẹ̀, ati gbogbo ipọnju ti o bá wọn li ọ̀na, ati bi OLUWA ti gbà wọn. 9 Jetro si yọ̀ nitori gbogbo ore ti OLUWA ti ṣe fun Israeli, ẹniti o ti gbàla lọwọ awọn ara Egipti. 10 Jetro si wipe, Olubukún li OLUWA, ẹniti o gbà nyin là lọwọ awọn ara Egipti, ati lọwọ Farao, ẹniti o gbà awọn enia là lọwọ awọn ara Egipti. 11 Mo mọ̀ nisisiyi pe OLUWA tobi jù gbogbo oriṣa lọ: nitõtọ, ninu ọ̀ran ti nwọn ti ṣeféfe si wọn. 12 Jetro, ana Mose, si mù ẹbọ sisun, ati ẹbọ wá fun Ọlọrun: Aaroni si wá, ati gbogbo awọn àgba Israeli, lati bá ana Mose jẹun niwaju Ọlọrun. 13 O si ṣe ni ijọ́ keji ni Mose joko lati ma ṣe idajọ awọn enia: awọn enia si duro tì Mose lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ. 14 Nigbati ana Mose si ri gbogbo eyiti on nṣe fun awọn enia, o ni, Kili eyiti iwọ nṣe fun awọn enia yi? ẽṣe ti iwọ nikan fi dá joko, ti gbogbo enia si duro tì ọ, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ? 15 Mose si wi fun ana rẹ̀ pe, Nitoriti awọn enia ntọ̀ mi wá lati bère lọwọ Ọlọrun ni: 16 Nigbati nwọn ba li ẹjọ́, nwọn a tọ̀ mi wá; emi a si ṣe idajọ larin ẹnikini ati ẹnikeji, emi a si ma mú wọn mọ̀ ìlana Ọlọrun, ati ofin rẹ̀. 17 Ana Mose si wi fun u pe, Eyiti iwọ nṣe nì kò dara. 18 Dajudaju iwọ o dá ara rẹ lagara, ati iwọ, ati awọn enia yi ti o pẹlu rẹ: nitoriti nkan yi wuwo jù fun ọ; iwọ nikan ki yio le ṣe e tikalãrẹ. 19 Fetisilẹ nisisiyi si ohùn mi; emi o fun ọ ni ìmọ, Ọlọrun yio si pẹlu rẹ: iwọ wà niwaju Ọlọrun fun awọn enia yi, ki iwọ ki o ma mú ọ̀ran wọn wá si ọdọ Ọlọrun. 20 Ki o si ma kọ́ wọn ni ìlana ati ofin wọnni, ki o si ma fi ọ̀na ti nwọn o ma rìn hàn fun wọn ati iṣẹ ti nwọn o ma ṣe. 21 Pẹlupẹlu iwọ o si ṣà ninu gbogbo awọn enia yi awọn ọkunrin ti o to, ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awọn ọkunrin olõtọ, ti o korira ojukokoro; irú awọn wọnni ni ki o fi jẹ́ olori wọn, lati ṣe olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwamẹwa. 22 Ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia nigbakugba: yio si ṣe, gbogbo ẹjọ́ nla ni ki nwọn ki o ma mú tọ̀ ọ wá, ṣugbọn gbogbo ẹjọ́ kekeké ni ki nwọn ki o ma dá: yio si rọrùn fun iwọ tikalarẹ, nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù na. 23 Bi iwọ ba jẹ ṣe nkan yi, bi Ọlọrun ba si fi aṣẹ fun ọ bẹ̃, njẹ iwọ o le duro pẹ, ati gbogbo awọn enia yi pẹlu ni yio si dé ipò wọn li alafia. 24 Mose si gbà ohùn ana rẹ̀ gbọ́, o si ṣe ohun gbogbo ti o wi. 25 Mose si yàn awọn enia ti o to ninu gbogbo Israeli, o si fi wọn ṣe olori awọn enia, olori ẹgbẹgbẹrun, olori ọrọrún, olori arãdọta, olori mẹwamẹwa. 26 Nwọn si nṣe idajọ awọn enia nigbakugba: ọ̀ran ti o ṣoro, nwọn a mútọ̀ Mose wá, ṣugbọn awọn tikalawọn ṣe idajọ gbogbo ọ̀ran kekeké. 27 Mose si jẹ ki ana rẹ̀ ki o lọ; on si ba tirẹ̀ lọ si ilẹ rẹ̀.

Eksodu 19

1 LI oṣù kẹta, ti awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti tán, li ọjọ́ na gan ni nwọn dé ijù Sinai. 2 Nwọn sá ti ṣi kuro ni Refidimu, nwọn si wá si ijù Sinai, nwọn si dó si ijù na; nibẹ̀ ni Israeli si dó si niwaju oke na. 3 Mose si goke tọ̀ Ọlọrun lọ, OLUWA si kọ si i lati oke na wá wipe, Bayi ni ki iwọ ki o sọ fun ile Jakobu, ki o si wi fun awọn ọmọ Israeli pe; 4 Ẹnyin ti ri ohun ti mo ti ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa-ìyẹ́ idì, ti mo si mú nyin tọ̀ ara mi wá. 5 Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ́ gbà ohùn mi gbọ́ nitõtọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ́, nigbana li ẹnyin o jẹ́ iṣura fun mi jù gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi. 6 Ẹnyin o si ma jẹ́ ijọba alufa fun mi, ati orilẹ-ède mimọ́. Wọnyi li ọ̀rọ ti iwọ o sọ fun awọn ọmọ Israeli. 7 Mose si wá o si ranṣẹ pè awọn àgba awọn enia, o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi lelẹ niwaju wọn ti OLUWA palaṣẹ fun u. 8 Gbogbo awọn enia na si jùmọ dahùn, nwọn si wipe, Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe. Mose si mú ọ̀rọ awọn enia pada tọ̀ OLUWA lọ. 9 OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi tọ̀ ọ wá ninu awọsanma ṣíṣu, ki awọn enia ki o le ma gbọ́ nigbati mo ba mbá ọ sọ̀rọ, ki nwọn ki o si ma gbà ọ gbọ́ pẹlu lailai. Mose si sọ ọ̀rọ awọn enia na fun OLUWA. 10 OLUWA si wi fun Mose pe, Tọ̀ awọn enia yi lọ, ki o si yà wọn simimọ́ li oni ati li ọla, ki nwọn ki o si fọ̀ asọ wọn. 11 Ki nwọn ki o si mura dè ijọ́ kẹta: nitori ni ijọ́ kẹta OLUWA yio sọkalẹ sori oke Sinai li oju awọn enia gbogbo. 12 Ki iwọ ki o si sagbàra fun awọn enia yiká, pe, Ẹ ma kiyesi ara nyin, ki ẹ máṣe gùn ori oke lọ, ki ẹ má si ṣe fọwọbà eti rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn oke na, pipa ni nitõtọ: 13 Ọwọkọwọ́ kò gbọdọ kàn a, bikoṣepe ki a sọ ọ li okuta, tabi ki a gún u pa nitõtọ; iba ṣe ẹranko iba ṣe enia, ki yio là a: nigbati ipè ba dún, ki nwọn ki o gùn oke wá. 14 Mose si sọkalẹ lati ori oke na wá sọdọ awọn enia, o si yà awọn enia si mimọ́, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn. 15 O si wi fun awọn enia pe, Ẹ mura dè ijọ́ kẹta: ki ẹ máṣe sunmọ aya nyin. 16 O si ṣe, li owurọ̀ ijọ́ kẹta, ni ãrá ati mànamána wà, ati awọsanma ṣíṣu dùdu lori òke na, ati ohùn ipè na si ndún kikankikan; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti o wà ni ibudó warìri. 17 Mose si mú awọn enia jade lati ibudó wá lati bá Ọlọrun pade; nwọn si duro ni ìha isalẹ oke na. 18 Oke Sinai si jẹ́ kìki ẽfi, nitoriti OLUWA sọkalẹ sori rẹ̀ ninu iná: ẽfi na si goke bi ẽfi ileru, gbogbo oke na si mì tìtì. 19 O si ṣe ti ohùn ipè si dún, ti o si mulẹ kijikiji, Mose sọ̀rọ, Ọlọrun si fi ãrá da a li ohùn. 20 OLUWA si sọkalẹ wá si oke Sinai, lori oke na: OLUWA si pè Mose lori oke na; Mose si goke lọ. 21 OLUWA si wi fun Mose pe, Sọkalẹ, kìlọ fun awọn enia, ki nwọn ki o má ba yà sọdọ OLUWA lati bẹ̀ ẹ wò, ki ọ̀pọ ki o má ba ṣegbe ninu wọn. 22 Si jẹ ki awọn alufa pẹlu, ti o sunmọ OLUWA, ki o yà ara wọn si mimọ́, ki OLUWA ki o má ba kọlù wọn. 23 Mose si wi fun OLUWA pe, Awọn enia ki yio le wá sori oke Sinai: nitoriti iwọ ti kìlọ fun wa pe, Sọ agbàra yi oke na ká, ki o si yà a si mimọ́. 24 OLUWA si wi fun u pe, Lọ, sọkalẹ; ki iwọ ki o si goke wá, iwọ ati Aaroni pẹlu rẹ: ṣugbọn ki awọn alufa ati awọn enia ki o máṣe yà lati goke tọ̀ OLUWA wá, ki o má ba kọlù wọn. 25 Bẹ̃ni Mose sọkalẹ tọ̀ awọn enia lọ, o si sọ̀rọ fun wọn.

Eksodu 20

1 ỌLỌRUN si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi pe, 2 Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ jade lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá. 3 Iwọ kò gbọdọ lí Ọlọrun miran pẹlu mi. 4 Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni isalẹ̀ ilẹ. 5 Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi; 6 Emi a si ma fi ãnu hàn ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si npa ofin mi mọ́. 7 Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ lasan; nitoriti OLUWA ki yio mu awọn ti o pè orukọ rẹ̀ lasan bi alailẹ̀ṣẹ li ọrùn. 8 Ranti ọjọ́ isimi, lati yà a simimọ́. 9 Ọjọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo: 10 Ṣugbọn ọjọ́ keje li ijọ́ isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ohunọ̀sin rẹ, ati alejò rẹ̀ ti mbẹ ninu ibode rẹ: 11 Nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o si simi ni ijọ́ keje: nitorina li OLUWA ṣe busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́. 12 Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 13 Iwọ kò gbọdọ pania. 14 Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga. 15 Iwọ kò gbọdọ jale. 16 Iwọ kò gbọdọ jẹri eke si ẹnikeji rẹ. 17 Iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ, tabi si ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, tabi ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ. 18 Gbogbo awọn enia na si ri ãrá na, ati mànamána na, ati ohùn ipè na, nwọn ri oke na nṣe ẽfi: nigbati awọn enia si ri i, nwọn ṣí, nwọn duro li òkere rére. 19 Nwọn si wi fun Mose pe, Iwọ ma bá wa sọ̀rọ̀, awa o si gbọ́: ṣugbọn máṣe jẹ ki Ọlọrun ki o bá wa sọ̀rọ, ki awa ki o má ba kú. 20 Mose si wi fun awọn enia pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitoriti Ọlọrun wá lati dan nyin wò, ati ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o le ma wà li oju nyin, ki ẹnyin ki o máṣe ṣẹ̀. 21 Awọn enia si duro li òkere rére, Mose si sunmọ ibi òkunkun ṣiṣu na nibiti Ọlọrun gbé wà. 22 OLUWA si wi fun Mose pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin ri bi emi ti bá nyin sọ̀rọ lati ọrun wá. 23 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun miran pẹlu mi; Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun fadaka, tabi ọlọrun wurà, fun ara nyin. 24 Pẹpẹ erupẹ ni ki iwọ mọ fun mi, lori rẹ̀ ni ki iwọ ki o ma ru ẹbọ sisun rẹ, ati ẹbọ alafia rẹ, agutan rẹ, ati akọmalu rẹ: ni ibi gbogbo ti mo ba gbé fi iranti orukọ mi si, emi o ma tọ̀ ọ wá, emi o si ma bukún fun ọ. 25 Bi iwọ o ba si mọ pẹpẹ okuta fun mi, iwọ kò gbọdọ fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: nitori bi iwọ ba gbé ohun-ọnà rẹ lé ori rẹ̀, iwọ sọ ọ di aimọ́. 26 Iwọ kò si gbọdọ ba àkasọ gùn ori pẹpẹ mi, ki ìhoho rẹ ki o máṣe hàn lori rẹ̀.

Eksodu 21

1 NJẸ wọnyi ni idajọ ti iwọ o gbekalẹ niwaju wọn. 2 Bi iwọ ba rà ọkunrin Heberu li ẹrú, ọdún mẹfa ni on o sìn: li ọdún keje yio si jade bi omnira lọfẹ. 3 Bi o ba nikan wọle wá, on o si nikan jade lọ: bi o ba ti gbé iyawo, njẹ ki aya rẹ̀ ki o bá a jade lọ. 4 Bi o ba ṣepe oluwa rẹ̀ li o fun u li aya, ti on si bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin fun u; aya ati awọn ọmọ ni yio jẹ́ ti oluwa rẹ̀, on tikara rẹ̀ yio si nikan jade lọ. 5 Bi ẹru na ba si wi ni gbangba pe, Emi fẹ́ oluwa mi, aya mi, ati awọn ọmọ mi; emi ki yio jade lọ idi omnira: 6 Nigbana ni ki oluwa rẹ̀ ki o mú u lọ sọdọ awọn onidajọ; yio si mú u lọ si ẹnu-ọ̀na, tabi si opó ẹnu-ọ̀na; oluwa rẹ̀ yio si fi olù lú u li eti; on a si ma sìn i titi aiye. 7 Bi ẹnikan ba si tà ọmọ rẹ̀ obinrin li ẹrú, on ki yio jade lọ bi awọn ẹrú ọkunrin ti ijade lọ. 8 Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ. 9 Bi o ba si fẹ́ ẹ fun ọmọkunrin rẹ̀, ki o ma ṣe si i bi a ti iṣe si ọmọbinrin ẹni. 10 Bi o ba si fẹ́ obinrin miran; onjẹ rẹ̀, aṣọ rẹ̀, ati iṣe ọkọlaya rẹ̀, ki o máṣe yẹ̀. 11 Bi on ki yio ba si ṣe ohun mẹtẹta yi fun u, njẹ ki on ki o jade kuro lọfẹ li aisan owo. 12 Ẹniti o ba lù enia, tobẹ̃ ti o si ku, pipa li a o pa a. 13 Bi o ba ṣepe enia kò ba dèna, ṣugbọn ti o ṣepe Ọlọrun li o fi lé e lọwọ, njẹ emi o yàn ibi fun ọ, nibiti on o gbé salọ si. 14 Ṣugbọn bi enia ba ṣìka si aladugbo rẹ̀, lati fi ẹ̀tan pa a; ki iwọ ki o tilẹ mú u lati ibi pẹpẹ mi lọ, ki o le kú. 15 Ẹniti o ba si lù baba, tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a. 16 Ẹniti o ba si ji enia, ti o si tà a, tabi ti a ri i li ọwọ́ rẹ̀, pipa li a o pa a. 17 Ẹniti o ba si bú baba tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a. 18 Bi awọn ọkunrin ba si jùmọ̀ njà, ti ekini fi okuta lù ekeji, tabi ti o jìn i li ẹsẹ̀, ti on kò si kú ṣugbọn ti o da a bulẹ: 19 Bi o ba si tun dide, ti o ntẹ̀ ọpá rìn kiri ni ita, nigbana li ẹniti o lù u yio to bọ́; kìki gbèse akokò ti o sọnù ni yio san, on o si ṣe ati mu u lara da ṣaṣa. 20 Bi ẹnikan ba si fi ọpá lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin, ti o si kú si i li ọwọ́, a o gbẹsan rẹ̀ nitõtọ. 21 Ṣugbọn bi o ba duro di ijọ́ kan, tabi meji, a ki yio gbẹsan rẹ̀: nitoripe owo rẹ̀ ni iṣe. 22 Bi awọn ọkunrin ba njà, ti nwọn si pa obinrin aboyún lara, tobẹ̃ ti oyún rẹ̀ ṣẹ́, ṣugbọn ti ibi miran kò si pẹlu: a o mu ki o san nitõtọ, gẹgẹ bi ọkọ obinrin na yio ti dá lé e; on o si san a niwaju onidajọ. 23 Bi ibi kan ba si pẹlu, njẹ ki iwọ ki o fi ẹmi dipò ẹmi. 24 Fi oju dipò oju, ehín dipò ehín, ọwọ́ dipò ọwọ́, ẹsẹ̀ dipò ẹsẹ̀. 25 Fi ijóna dipò ijóna, ọgbẹ́, dipò ọgbẹ́, ìna dipò ìna. 26 Bi o ba ṣepe ẹnikan ba lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi ẹrú rẹ̀ obinrin li oju ti o si fọ́; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori oju rẹ̀. 27 Bi o ba si ká ehín ẹrú rẹ̀ ọkunrin, tabi ehín ẹrú rẹ̀ obinrin; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori ehín rẹ̀. 28 Bi akọmalu ba kàn ọkunrin tabi obinrin ti o si kú: sísọ ni ki a sọ akọmalu na li okuta pa bi o ti wù ki o ṣe, ki a má si ṣe jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn ọrùn oni-akọmalu na yio mọ́. 29 Ṣugbọn bi o ba ṣepe akọmalu na a ti ma fi iwo rẹ̀ kàn nigba atijọ, ti a si ti kìlọ fun oluwa rẹ̀, ti kò si sé e mọ, ṣugbọn ti o pa ọkunrin tabi obinrin, akọmalu na li a o sọ li okuta pa, oluwa rẹ̀ li a o si lù pa pẹlu. 30 Bi o ba si ṣepe a bù iye owo kan fun u, njẹ iyekiye ti a bù fun u ni yio fi ṣe irapada ẹmi rẹ̀. 31 Iba kàn ọmọkunrin, tabi iba kàn ọmọbinrin, gẹgẹ bi irú idajọ yi li a o ṣe si i. 32 Bi akọmalu na ba kan ẹrukunrin tabi ẹrubirin; on o si san ọgbọ̀n ṣekeli fadakà fun oluwa rẹ̀, a o si sọ akọmalu na li okuta pa. 33 Bi ẹnikan ba ṣi ihò silẹ, tabi bi ọkunrin kan ba si wà ihò silẹ, ti kò si bò o, ti akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ba bọ́ sinu rẹ̀; 34 Oni-ihò na yio si san; yio si fi owo fun oluwa wọn; okú ẹran a si jẹ́ tirẹ̀. 35 Bi akọmalu ẹnikan ba si pa akọmalu ẹnikeji lara ti o si kú; ki nwọn ki o tà ãye akọmalu, ki nwọn ki o si pín owo rẹ̀; oku ni ki nwọn ki o si pín pẹlu. 36 Tabi bi a ba si mọ̀ pe akọmalu na a ti ma kàn nigba atijọ ti oluwa rẹ̀ kò sé e mọ́; on o fi akọmalu san akọmalu nitõtọ; okú a si jẹ́ tirẹ̀.

Eksodu 22

1 BI ọkunrin kan ba ji akọmalu, tabi agutan kan, ti o si pa a, tabi ti o tà a; yio san akọmalu marun dipò akọmalu kan, ati agutan mẹrin dipò agutan kan. 2 Bi a ba ri olè ti nrunlẹ wọle, ti a si lù u ti o kú, a ki yio ta ẹ̀jẹ silẹ fun u. 3 Bi õrùn ba là bá a, a o ta ẹ̀jẹ silẹ fun u; sisan li on iba san; bi kò ni nkan, njẹ a o tà a nitori olè rẹ̀. 4 Bi a ba ri ohun ti o ji na li ọwọ́ rẹ̀ nitõtọ li ãye, iba ṣe akọmalu, tabi kẹtẹkẹtẹ, tabi agutan; on o san a pada ni meji. 5 Bi ọkunrin kan ba mu ki a jẹ oko tabi agbalá-àjara kan, ti o si tú ẹran rẹ̀ silẹ, ti o si jẹ li oko ẹlomiran; ninu ãyo oko ti ara rẹ̀, ati ninu ãyo agbalá-àjara tirẹ̀, ni yio fi san ẹsan. 6 Bi iná ba ṣẹ̀, ti o si mu ẹwọn, ti abà ọkà, tabi ọkà aiṣá, tabi oko li o joná; ẹniti o ràn iná na yio san ẹsan nitõtọ. 7 Bi ẹnikan ba fi owo tabi ohunèlo fun ẹnikeji rẹ̀ pamọ́; ti a ji i ni ile ọkunrin na; bi a ba mu olè na, ki o san a ni meji. 8 Bi a kò ba mú olè na, njẹ ki a mú bale na wá siwaju awọn onidajọ, bi on kò ba fọwọkàn ẹrù ẹnikeji rẹ̀. 9 Nitori irú ẹ̀ṣẹ gbogbo, iba ṣe ti akọmalu, ti kẹtẹkẹtẹ, ti agutan, ti aṣọ, tabi ti irũru ohun ti o nù, ti ẹlomiran pè ni ti on, ẹjọ́ awọn mejeji yio wá siwaju awọn onidajọ; ẹniti awọn onidajọ ba dẹbi fun, on o san a ni iṣẹmeji fun ẹnikeji rẹ̀. 10 Bi enia ba fi kẹtẹkẹtẹ, tabi akọmalu, tabi agutan, tabi ẹrankẹran lé ẹnikeji rẹ̀ lọwọ lati ma sìn; ti o ba si kú, tabi ti o farapa, tabi ti a lé e sọnù, ti ẹnikan kò ri i; 11 Ibura OLUWA yio wà lãrin awọn mejeji, pe, on kò fọwọkàn ẹrù ẹnikeji on; ki on ki o si gbà, on ki yio si san ẹsan. 12 Bi o ba ṣepe a ji i lọwọ rẹ̀, on o san ẹsan fun oluwa rẹ̀. 13 Bi o ba ṣepe a si fà a ya, njẹ ki o mú u wa ṣe ẹrí, on ki yio si san ẹsan eyiti a fàya. 14 Bi enia ba si yá ohun kan lọwọ ẹnikeji rẹ̀, ti o si farapa, tabi ti o kú, ti olohun kò si nibẹ̀, on o san ẹsan nitõtọ. 15 Ṣugbọn bi olohun ba wà nibẹ̀, on ki yio san ẹsan: bi o ba ṣe ohun ti a fi owo gbà lò ni, o dé fun owo igbàlo rẹ̀. 16 Bi ọkunrin kan ba si tàn wundia kan ti a kò ti ifẹ́, ti o si mọ̀ ọ, fifẹ́ ni yio si fẹ́ ẹ li aya rẹ̀. 17 Bi baba rẹ̀ ba kọ̀ jalẹ lati fi i fun u, on o san ojì gẹgẹ bi ifẹ́ wundia. 18 Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ajẹ́ ki o wà lãye. 19 Ẹnikẹni ti o ba bá ẹranko dàpọ pipa li a o pa a. 20 Ẹnikẹni ti o ba rubọ si oriṣakoriṣa, bikoṣe si JEHOFA nikanṣoṣo, a o pa a run tútu. 21 Iwọ kò gbọdọ ṣìka si alejò, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ni i lara: nitoripe alejò li ẹnyin ti jẹ́ ni ilẹ Egipti. 22 Ẹnyin kò gbọdọ jẹ opó ni ìya, tabi ọmọ alainibaba. 23 Bi iwọ ba jẹ wọn ni ìyakiya, ti nwọn si kigbe pè mi, emi o gbọ́ igbe wọn nitõtọ. 24 Ibinu mi yio si gboná, emi o si fi idà pa nyin; awọn aya nyin yio si di opó, awọn ọmọ nyin a si di alainibaba. 25 Bi iwọ ba yá ẹnikẹni ninu awọn enia mi li owo ti o ṣe talaka lọdọ rẹ, iwọ ki yio jẹ́ bi agbẹ̀da fun u; bẹ̃ni iwọ ki yio gbẹ̀da lọwọ rẹ̀. 26 Bi o ba ṣepe iwọ gbà aṣọ ẹnikeji rẹ ṣe ògo, ki iwọ ki o si fi i fun u, ki õrùn to wọ̀: 27 Nitori kìki eyi ni ibora rẹ̀, aṣọ rẹ̀ ti yio fi bora ni: kini on o fi bora sùn? yio si ṣe bi o ba kigbe pè mi, emi o gbọ́; nitori alãnu li emi. 28 Iwọ kò gbọdọ gàn awọn onidajọ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bú ijoye kan ninu awọn enia rẹ. 29 Iwọ kò gbọdọ jafara lati mú irè oko rẹ wá, ati ọti rẹ. Akọ́bi awọn ọmọ rẹ ọkunrin ni iwọ o fi fun mi. 30 Bẹ̃ gẹgẹ ni ki iwọ ki o fi akọmalu ati agutan rẹ ṣe: ijọ́ meje ni ki o ba iya rẹ̀ gbọ́; ni ijọ́ kẹjọ ni ki iwọ ki o fi i fun mi. 31 Ẹnyin o si jẹ́ enia mimọ́ fun mi; nitorina ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹran ti a ti ọwọ ẹranko igbẹ́ fàya; ajá ni ki ẹnyin ki o wọ́ ọ fun.

Eksodu 23

1 IWỌ kò gbọdọ gbà ìhin eke: máṣe li ọwọ́ si i pẹlu enia buburu lati ṣe ẹlẹri aiṣododo. 2 Iwọ kò gbọdọ tọ̀ ọ̀pọlọpọ enia lẹhin lati ṣe ibi, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ̀ li ọ̀ran ki o tẹ̀ si ọ̀pọ enia lati yi ẹjọ́ po. 3 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbè talaka li ẹjọ́ rẹ̀. 4 Bi iwọ ba bá akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ọtá rẹ ti o ṣina, ki iwọ ki o mú u pada fun u wá nitõtọ. 5 Bi iwọ ba ri kẹtẹkẹtẹ ẹniti o korira rẹ, ti o dubulẹ labẹ ẹrù rẹ̀, ti iwọ iba yẹra lati bá a tú u, iwọ o bá a tú u nitõtọ. 6 Iwọ kò gbọdọ yi ẹjọ́ talaka rẹ po li ọ̀ran rẹ̀. 7 Takéte li ọ̀ran eke; ati alaiṣẹ ati olododo ni iwọ kò gbọdọ pa: nitoriti emi ki yio dá enia buburu lare. 8 Iwọ kò gbọdọ gbà ọrẹ: nitori ọrẹ ni ifọ́ awọn ti o riran loju, a si yi ọ̀ran awọn olododo po. 9 Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ pọ́n alejò kan loju: ẹnyin sa ti mọ̀ inu alejò, nitoriti ẹnyin ti jẹ́ alejò ni ilẹ Egipti. 10 Ọdún mẹfa ni iwọ o si gbìn ilẹ rẹ, on ni iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ. 11 Ṣugbọn li ọdún keje iwọ o jẹ ki o simi, ki o si gbé jẹ; ki awọn talaka enia rẹ ki o ma jẹ ninu rẹ̀: eyiti nwọn si fisilẹ ni ki ẹran igbẹ ki o ma jẹ. Irú bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe si agbalá-àjara, ati agbalá-olifi rẹ. 12 Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣe iṣẹ rẹ, ni ijọ́ keje ki iwọ ki o si simi: ki akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ ki o le simi, ki a le tù ọmọ iranṣẹbinrin rẹ, ati alejò, lara. 13 Ati li ohun gbogbo ti mo wi fun nyin, ẹ ma ṣọra: ki ẹ má si ṣe iranti orukọ oriṣakoriṣa ki a má ṣe gbọ́ ọ li ẹnu nyin. 14 Ni ìgba mẹta ni iwọ o ṣe ajọ fun mi li ọdún. 15 Iwọ o kiyesi ajọ aiwukàra: ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, bi mo ti pa a laṣẹ fun ọ, li akokò oṣù Abibu (nitori ninu rẹ̀ ni iwọ jade kuro ni Egipti); a kò gbọdọ ri ẹnikan niwaju mi li ọwọ́ ofo: 16 Ati ajọ ikore, akọ́so iṣẹ rẹ, ti iwọ gbìn li oko rẹ: ati ajọ ikore oko, li opin ọdún, nigbati iwọ ba ṣe ikore iṣẹ oko rẹ tán. 17 Ni ìgba mẹta li ọdún ni gbogbo awọn ọkunrin rẹ yio farahàn niwaju Oluwa JEHOFA. 18 Iwọ kò gbọdọ ta ọrẹ ẹ̀jẹ ẹbọ mi ti on ti àkara wiwu; bẹ̃li ọrá ẹbọ ajọ mi kò gbọdọ kù titi di ojumọ́. 19 Akọ́ka eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o múwa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀. 20 Kiyesi i, emi rán angeli kan siwaju rẹ lati pa ọ mọ́ li ọ̀na, ati lati mú ọ dé ibi ti mo ti pèse silẹ. 21 Kiyesi ara lọdọ rẹ̀, ki o si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, máṣe bi i ninu; nitoriti ki yio dari irekọja nyin jì nyin, nitoriti orukọ mi mbẹ lara rẹ̀. 22 Ṣugbọn bi iwọ o ba gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ nitõtọ, ti iwọ si ṣe gbogbo eyiti mo wi; njẹ emi o jasi ọtá awọn ẹniti nṣe ọtá nyin, emi o si foró awọn ti nforó nyin. 23 Nitoriti angeli mi yio ṣaju rẹ, yio si mú ọ dé ọdọ awọn enia Amori, ati awọn Hitti, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: emi a si ke wọn kuro. 24 Iwọ kò gbọdọ tẹriba fun oriṣa wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn, ki o má si ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: bikoṣepe ki iwọ ki o fọ́ wọn tútu, ki iwọ ki o si wó ere wọn palẹ. 25 Ẹnyin o si ma sìn OLUWA Ọlọrun nyin, on o si busi onjẹ rẹ, ati omi rẹ; emi o si mú àrun kuro lãrin rẹ. 26 Obinrin kan ki yio ṣẹ́nu, bẹ̃ni ki yio yàgan ni ilẹ rẹ: iye ọjọ́ rẹ li emi ó fi kún. 27 Emi o rán ẹ̀ru mi siwaju rẹ, emi o si dà gbogbo awọn enia rú ọdọ ẹniti iwọ o dé, emi o si mu gbogbo awọn ọtá rẹ yi ẹ̀hin wọn dà si ọ. 28 Emi o si rán agbọ́n siwaju rẹ, ti yio lé awọn enia Hifi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn enia Hitti kuro niwaju rẹ. 29 Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju rẹ li ọdún kan; ki ilẹ na ki o má ba di ijù, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba rẹ̀ si ọ. 30 Diẹdiẹ li emi o ma lé wọn jade kuro niwaju rẹ, titi iwọ o fi di pupọ̀, ti iwọ o si tẹ̀ ilẹ na dó. 31 Emi o si fi opinlẹ rẹ lelẹ, lati Okun Pupa wá titi yio fi dé okun awọn ara Filistia, ati lati aṣalẹ̀ nì wá dé odò nì; nitoriti emi o fi awọn olugbe ilẹ na lé nyin lọwọ; iwọ o si lé wọn jade kuro niwaju rẹ. 32 Iwọ kò gbọdọ bá wọn ṣe adehùn, ati awọn oriṣa wọn pẹlu. 33 Nwọn kò gbọdọ joko ni ilẹ rẹ, ki nwọn ki o má ba mu ọ ṣẹ̀ si mi: nitori bi iwọ ba sìn oriṣa wọn, yio ṣe idẹkùn fun ọ nitõtọ.

Eksodu 24

1 O SI wi fun Mose pe, Goke tọ̀ OLUWA wá, iwọ, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli; ki ẹnyin ki o si ma sìn li òkere rére. 2 Mose nikanṣoṣo ni yio si sunmọ OLUWA; ṣugbọn awọn wọnyi kò gbọdọ sunmọ tosi; bẹ̃li awọn enia kò gbọdọ bá a gòke lọ. 3 Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA, ati gbogbo idajọ fun awọn enia: gbogbo enia si fi ohùn kan dahùn wipe, Gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA wi li awa o ṣe. 4 Mose si kọwe gbogbo ọ̀rọ OLUWA, o si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si tẹ́ pẹpẹ kan nisalẹ òke na, o mọ ọwọ̀n mejila, gẹgẹ bi ẹ̀ya Israeli mejila. 5 O si rán awọn ọdọmọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si fi akọmalu ru ẹbọ alafia si OLUWA. 6 Mose si mú àbọ ẹ̀jẹ na o si fi i sinu awokòto; ati àbọ ẹ̀jẹ na o fi wọ́n ara pẹpẹ na. 7 O si mú iwé majẹmu nì, o si kà a li eti awọn enia: nwọn si wipe, Gbogbo eyiti OLUWA wi li awa o ṣe, awa o si gbọràn. 8 Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si wọ́n ọ sara awọn enia, o si wipe, Kiyesi ẹ̀jẹ majẹmu, ti OLUWA bá nyin dá nipasẹ ọ̀rọ gbogbo wọnyi. 9 Nigbana ni Mose, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli gòke lọ: 10 Nwọn si ri Ọlọrun Israeli; bi iṣẹ okuta Safire wà li abẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dabi irisi ọrun ni imọ́toto rẹ̀. 11 Kò si nà ọwọ́ rẹ̀ lé awọn ọlọlá ọmọ Israeli: nwọn si ri Ọlọrun, nwọn si jẹ, nwọn si mu. 12 OLUWA si wi fun Mose pe, Gòke tọ̀ mi wá sori òke, ki o si duro nibẹ̀; emi o si fi walã okuta fun ọ, ati aṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ, ki iwọ ki o le ma kọ́ wọn. 13 Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun. 14 O si wi fun awọn àgba na pe, Ẹ duro dè wa nihinyi, titi awa o fi tun pada tọ̀ nyin wá: si kiyesi i, Aaroni ati Huri mbẹ pẹlu nyin: bi ẹnikan ba li ọ̀ran kan, ki o tọ̀ wọn wá. 15 Mose si gòke lọ sori òke na, awọsanma si bò òke na mọlẹ. 16 Ogo OLUWA si sọkalẹ sori òke Sinai, awọsanma na si bò o mọlẹ ni ijọ́ mẹfa: ni ijọ́ keje o ké si Mose lati ãrin awọsanma wá. 17 Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israeli. 18 Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.

Eksodu 25

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú ọrẹ fun mi wá: lọwọ olukuluku enia ti o ba fifunni tinutinu ni ki ẹnyin ki o gbà ọrẹ mi. 3 Eyi si li ọrẹ ti ẹnyin o gbà lọwọ wọn; wurà, ati fadakà, ati idẹ; 4 Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ, ati irun ewurẹ; 5 Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu. 6 Oróro fun fitila, olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn; 7 Okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya. 8 Ki nwọn ki o si ṣe ibi mimọ́ kan fun mi; ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn. 9 Gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo fihàn ọ, nipa apẹrẹ agọ́, ati apẹrẹ gbogbo ohunèlo inu rẹ̀, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe e. 10 Nwọn o si ṣe apoti igi ṣittimu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀. 11 Iwọ o si fi kìki wurà bò o, ninu ati lode ni iwọ o fi bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà sori rẹ̀ yiká. 12 Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi wọn si igun mẹrin rẹ̀; oruka meji yio si wà li apa kini rẹ̀, oruka meji yio si wà li apa keji rẹ̀. 13 Iwọ o si ṣe ọpá ṣittimu, ki iwọ ki o si fi wurà bò wọn. 14 Iwọ o si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, ki a le ma fi wọn gbé apoti na. 15 Ọpá wọnni yio si ma wà ninu oruka apoti na: a ki yio si yọ wọn kuro ninu rẹ̀. 16 Iwọ o si fi ẹrí ti emi o fi fun ọ sinu apoti nì. 17 Iwọ o si fi kìki wurà ṣe itẹ-anu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀. 18 Iwọ o si ṣe kerubu wurà meji; ni iṣẹ lilù ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ni ìku itẹ́-ãnu na mejeji. 19 Si ṣe kerubu kini ni ìku kan, ati kerubu keji ni ìku keji: lati itẹ́-ãnu ni ki ẹnyin ki o ṣe awọn kerubu na ni ìku rẹ̀ mejeji. 20 Awọn kerubu na yio si nà iyẹ́-apa wọn si oke, ki nwọn ki o fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, ki nwọn ki o si kọjusi ara wọn; itẹ́-ãnu na ni ki awọn kerubu na ki o kọjusi. 21 Iwọ o si fi itẹ́-ãnu na sori apoti na; ati ninu apoti na ni iwọ o fi ẹri ti emi o fi fun ọ si. 22 Nibẹ̀ li emi o ma pade rẹ, emi o si ma bá ọ sọ̀rọ lati oke itẹ́-ãnu wá, lati ãrin awọn kerubu mejeji wá, ti o wà lori apoti ẹrí na, niti ohun gbogbo ti emi o palaṣẹ fun ọ si awọn ọmọ Israeli. 23 Iwọ o si ṣe tabili igi ṣittimu kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀. 24 Iwọ o si fi kìki wurà bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà si i yiká. 25 Iwọ o si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, iwọ o si ṣe igbáti wurà si eti rẹ̀ yiká. 26 Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà li ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹrẹrin. 27 Li abẹ igbáti na li oruka wọnni yio wà, fun ibi ọpá lati ma fi rù tabili na. 28 Iwọ o si ṣe ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi wurà bò wọn, ki a le ma fi wọn rù tabili na. 29 Iwọ o si ṣe awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, ati awo rẹ̀, lati ma fi dà: kìki wurà ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn. 30 Iwọ o si ma gbé àkara ifihàn kalẹ lori tabili na niwaju mi nigbagbogbo. 31 Iwọ o si fi kìki wurà ṣe ọpá-fitila kan: iṣẹlilù li a o fi ṣe ọpá-fitila na, ipilẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀; ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn o jẹ́: 32 Ẹka mẹfa ni yio yọ ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha keji: 33 Ago mẹta ni ki a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi ati itanna li ẹka kan; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka ekeji, pẹlu irudi ati itanna: bẹ̃li ẹka mẹfẹ̃fa ti o yọ lara ọpá-fitila na. 34 Ati ninu ọpá-fitila na li ago mẹrin yio wà ti a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi wọn ati itanna wọn. 35 Irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, gẹgẹ bi ẹka rẹ̀ mẹfẹfa ti o ti ara ọpá-fitila na yọ jade. 36 Irudi wọn ati ẹka wọn ki o ri bakanna: ki gbogbo rẹ̀ ki o jẹ́ lilù kìki wurà kan. 37 Iwọ o si ṣe fitila rẹ̀ na, meje: ki nwọn ki o si fi fitila wọnni sori rẹ̀, ki nwọn ki o le ma ṣe imọlẹ si iwaju rẹ̀. 38 Ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, kìki wurà ni ki o jẹ́. 39 Talenti kan kìki wurà ni ki o fi ṣe e, pẹlu gbogbo ohunèlo wọnyi. 40 Si kiyesi i, ki iwọ ki o ṣe wọn gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, ti a fihàn ọ lori oke.

Eksodu 26

1 IWỌ o fi aṣọ-tita mẹwa ṣe agọ́ na; aṣọ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ti on ti awọn kerubu iṣẹ ọlọnà ni ki iwọ ki o ṣe wọn. 2 Ina aṣọ-tita kan ki o jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ibò aṣọ-tita kan igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na ni ki o jẹ́ ìwọn kanna. 3 Aṣọ-tita marun ni ki a solù mọ́ ara wọn; ati aṣọ-tita marun keji ni ki a solù mọ́ ara wọn. 4 Iwọ o si ṣe ojóbo aṣọ-alaró si eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù, ati bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe li eti ikangun aṣọ-tita keji, ni ibi isolù keji. 5 Ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ-tita kan, ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o si ṣe si eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji; ki ojóbo ki o le kọ́ ara wọn. 6 Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, iwọ o si fi ikọ́ na fà awọn aṣọ-tita so: on o si jẹ́ agọ́ kan. 7 Iwọ o si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ, lati ṣe ibori sori agọ́ na: aṣọ-tita mọkanla ni iwọ o ṣe e. 8 Ìna aṣọ-tita kan yio jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ati ibò aṣọ-tita kan yio jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla na yio si jẹ́ ìwọn kanna. 9 Iwọ o si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, iwọ o si ṣẹ aṣọ-tita kẹfa po ni meji niwaju agọ́ na. 10 Iwọ o si ṣe ãdọta ojóbo li eti aṣọ-tita na, ti o yọ si ode jù ninu isolù, ati ãdọta ojóbo li eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù. 11 Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ, ki o si fi ikọ́ wọnni sinu ojóbo, ki o si fi so agọ́ na pọ̀, yio si jẹ́ ọkan. 12 Ati iyokù ti o kù ninu aṣọ-tita agọ́ na, àbọ aṣọ-tita ti o kù, yio rọ̀ sori ẹhin agọ na. 13 Ati igbọnwọ kan li apa kan, ati igbọnwọ kan li apa keji, eyiti o kù ni ìna aṣọ-tita agọ́ na, yio si rọ̀ si ìha agọ́ na ni ìha ihin ati ni ìha ọhún, lati bò o. 14 Iwọ o si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori rẹ̀. 15 Iwọ o si ṣe apáko igi ṣittimu fun agọ́ na li ogurodo. 16 Igbọnwọ mẹwa ni gigùn apáko na, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibò apáko kan. 17 Ìtẹbọ meji ni ki o wà li apáko kan, ti o tò li ẹsẹ-ẹsẹ̀ si ara wọn: bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo apáko agọ́ na. 18 Iwọ o si ṣe apáko agọ́ na, ogún apáko ni ìha gusù si ìha gusù. 19 Iwọ o si ṣe ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ meji na, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ meji na; 20 Ati ìha keji agọ́ na ni ìha ariwa, ogún apáko ni yio wà nibẹ̀: 21 Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà wọn; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko na kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji. 22 Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn apáko mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe. 23 Ati apáko meji ni iwọ o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha ẹhin rẹ̀. 24 A o si so wọn pọ̀ nisalẹ, a o si so wọn pọ̀ li oke ori rẹ̀ si oruka kan: bẹ̃ni yio si ṣe ti awọn mejeji; nwọn o si ṣe ti igun mejeji. 25 Nwọn o si jẹ́ apáko mẹjọ, ati ihò-ìtẹbọ fadakà wọn, ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji. 26 Iwọ o si ṣe ọpá idabu igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na, 27 Ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha keji agọ́ na, ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha agọ́ na, fun ìha mejeji ni ìha ìwọ-õrùn. 28 Ati ọpá ãrin li agbedemeji apáko wọnni yio ti ìku dé ìku. 29 Iwọ o si fi wurà bò apáko wọnni, iwọ o si fi wurà ṣe oruka wọn li àye fun ọpá idabu wọnni: iwọ o si fi wurà bò ọpá idabu wọnni. 30 Iwọ o si gbé agọ́ na ró, gẹgẹ bi apẹrẹ rẹ̀, ti a fihàn ọ lori oke. 31 Iwọ o si ṣe aṣọ-ikele alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti iṣẹ ọlọnà: ti on ti awọn kerubu nì ki a ṣe e: 32 Iwọ o si fi rọ̀ sara opó igi ṣittimu mẹrin, ti a fi wurà bò, wurà ni ikọ́ wọn lori ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrẹrin na. 33 Iwọ o si ta aṣọ-ikele na si abẹ ikọ́ wọnni, ki iwọ ki o le mú apoti ẹrí nì wá si inu aṣọ-ikele nì: aṣọ-ikele nì ni yio si pinya lãrin ibi mimọ́ ati ibi mimọ́ julọ fun nyin. 34 Iwọ o si fi itẹ́-ãnu sori apoti ẹrí nì, ni ibi mimọ́ julọ. 35 Iwọ o si gbé tabili na kà ẹhin ode aṣọ-ikele nì, ati ọpá-fitila nì kọjusi tabili na ni ìha agọ́ na ni ìha gusù: iwọ o si gbé tabili na kà ìha ariwa. 36 Iwọ o si ṣe aṣọ-tita kan fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na, ti aṣọ-alaró, ti elesè-aluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe. 37 Iwọ o si ṣe opó igi ṣittimu marun fun aṣọ-tita na, ki o si fi wurà bò wọn; ati ikọ́ wọn wurà: iwọ o si dà ihò-ìtẹbọ idẹ marun fun wọn.

Eksodu 27

1 IWỌ o si tẹ́ pẹpẹ igi ṣittimu kan, ìna rẹ̀ igbọnwọ marun, ati ìbú rẹ̀ igbọnwọ marun; ìwọn kan ni ìha mẹrẹrin: igbọnwọ mẹta si ni giga rẹ̀. 2 Iwọ o si ṣe iwo rẹ̀ si ori igun mẹrẹrin rẹ̀: iwo rẹ̀ yio si wà lara rẹ̀: iwọ o si fi idẹ bò o. 3 Iwọ o si ṣe tasà rẹ̀ lati ma gbà ẽru rẹ̀, ati ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀ ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo-iná rẹ̀ wọnni: gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ni iwọ o fi idẹ ṣe. 4 Iwọ o si ṣe oju-àro idẹ fun u ni iṣẹ-àwọn; lara àwọn na ni ki iwọ ki o ṣe oruka mẹrin ni igun mẹrẹrin rẹ̀. 5 Iwọ o si fi si abẹ ayiká pẹpẹ na nisalẹ, ki àwọn na ki o le dé idaji pẹpẹ na. 6 Iwọ o si ṣe ọpá fun pẹpẹ na, ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi idẹ bò wọn. 7 A o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ oruka wọnni, ọpá wọnni yio si wà ni ìha mejeji pẹpẹ na, lati ma fi rù u. 8 Onihò ninu ni iwọ o fi apáko ṣe e: bi a ti fihàn ọ lori oke, bẹ̃ni ki nwọn ki o ṣe e. 9 Iwọ o si ṣe agbalá agọ́ na: ni ìha gusù lọwọ ọtún li aṣọ-tita agbalá ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti ọgọrun igbọnwọ ìna, yio wà ni ìha kan: 10 Ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ wọn, ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà. 11 Ati bẹ̃ gẹgẹ niti ìha ariwa ni gigùn aṣọ-tita wọnni yio jẹ́ ọgọrun igbọnwọ ni ìna wọn, ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ rẹ̀ ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà. 12 Ati niti ibú agbalá na, ni ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ yio wà: opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa. 13 Ati ibú agbalá na ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn yio jẹ́ ãdọta igbọnwọ. 14 Aṣọ-tita apakan ẹnu-ọ̀na na yio jẹ́ igbọnwọ mẹdogun: opó wọn mẹta, ihò-ìtẹbọ wọn mẹta. 15 Ati ni ìha keji ni aṣọ-tita igbọnwọ mẹdogun yio wà: opó wọn mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹta. 16 Ati fun ẹnu-ọ̀na agbalá na aṣọ-tita ogún igbọnwọ yio wà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe: opó wọn mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹrin. 17 Gbogbo opó ti o yi sarè na ká li a o si fi ọpá fadakà sopọ̀; ikọ́ wọn yio jẹ́ fadakà, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ. 18 Ìna agbalá na ki o jẹ́ ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ arãdọtọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ igbọnwọ marun, ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ. 19 Gbogbo ohun-èlo agọ́ na, ni gbogbo ìsin rẹ̀, ati gbogbo ekàn rẹ̀, ati gbogbo ekàn agbalá na ki o jẹ́ idẹ. 20 Iwọ o si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú oróro olifi daradara ti a gún fun ọ wá, fun imọlẹ, lati mu ki fitila ki o ma tàn nigbagbogbo. 21 Li agọ́ ajọ lẹhin ode aṣọ-ikele ti o wà niwaju ẹ̀rí na, Aaroni ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ ni yio tọju rẹ̀ lati alẹ titi di owurọ̀ niwaju OLUWA: yio si di ìlana lailai ni irandiran wọn lọdọ awọn ọmọ Israeli.

Eksodu 28

1 IWỌ si mú Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀ si ọdọ rẹ, kuro ninu awọn ọmọ Israeli, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi, ani Aaroni, Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari, awọn ọmọ Aaroni. 2 Iwọ o si dá aṣọ mimọ́ fun Aaroni arakunrin rẹ fun ogo ati fun ọṣọ́. 3 Iwọ o si sọ fun gbogbo awọn ti o ṣe amoye, awọn ẹniti mo fi ẹmi ọgbọ́n kún, ki nwọn ki o le dá aṣọ Aaroni lati yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 4 Wọnyi si li aṣọ ti nwọn o dá; igbàiya kan, ati ẹ̀wu-efodi, ati aṣọ igunwà, ati ẹ̀wu-awọtẹlẹ ọlọnà, fila, ati ọjá-amure: nwọn o si dá aṣọ mimọ́ wọnyi fun Aaroni arakunrin rẹ, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 5 Nwọn o si mú wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ. 6 Nwọn o si ṣe ẹ̀wu-efodi ti wurà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ti ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ iṣẹ ọlọnà, 7 Yio ní aṣọ ejika meji ti o solù li eti rẹ̀ mejeji; bẹ̃ni ki a so o pọ̀. 8 Ati onirũru-ọnà ọjá rẹ̀, ti o wà lori rẹ̀ yio ri bakanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ. 9 Iwọ o si mú okuta oniki meji, iwọ o si fin orukọ awọn ọmọ Israeli sara wọn: 10 Orukọ awọn mẹfa sara okuta kan, ati orukọ mẹfa iyokù sara okuta keji, gẹgẹ bi ìbí wọn. 11 Iṣẹ-ọnà afin-okuta, bi ifin èdidi-àmi, ni iwọ o fin okuta mejeji gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli: iwọ o si dè wọn si oju-ìde wurà. 12 Iwọ o si fi okuta mejeji si ejika ẹ̀wu-efodu na, li okuta iranti fun awọn ọmọ Israeli; Aaroni yio si ma rù orukọ wọn niwaju OLUWA li ejika rẹ̀ mejeji fun iranti. 13 Iwọ o si ṣe oju-ìde wurà: 14 Ati okùn ẹ̀wọn meji ti kìki wurà; iṣẹ ọnà-lilọ ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ki iwọ ki o si so okùn ẹ̀wọn iṣẹ ọnà-lilọ ni si oju-ìde na. 15 Iwọ o si fi iṣẹ ọgbọ́n na ṣe igbàiya idajọ na; nipa iṣẹ-ọnà ẹ̀wu-efodi ni iwọ o ṣe e; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododò, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ni iwọ o fi ṣe e. 16 Iha mẹrin ọgbọgba ni ki iwọ ki o ṣe e ni iṣẹpo meji; ika kan ni ìna rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀. 17 Iwọ o si tò ìto okuta sinu rẹ̀, ẹsẹ̀ okuta mẹrin: ẹsẹ̀ kini, sardiu, topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini: 18 Ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi; 19 Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu; 20 Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, ati oniki, ati jasperi: a o si tò wọn si oju wurà ni didè wọn. 21 Okuta wọnni yio si wà gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn; bi ifin edidi-àmi; olukuluku gẹgẹ bi orukọ rẹ̀ ni nwọn o wà fun ẹ̀ya Israeli mejejila. 22 Iwọ o si ṣe okùn ẹ̀wọn kìka wurà iṣẹ ọnà-lilọ si igbàiya na. 23 Iwọ o si ṣe oruka wurà meji sara igbàiya na, iwọ o si fi oruka meji na si eti mejeji igbàiya na. 24 Iwọ o si fi okùn ẹ̀wọn wurà mejeji sinu oruka meji wọnni li eti igbàiya na. 25 Ati eti ẹ̀wọn meji ni ki iwọ ki o so mọ́ oju-ìde mejeji, ki o si fi si ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀. 26 Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si eti mejeji igbàiya na li eti rẹ̀, ti o wà ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inú. 27 Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi mejeji nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ti o kọjusi isolù rẹ̀, loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na. 28 Nwọn o si fi oruka rẹ̀ so igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi na ti on ti ọjá àwọn alaró, ki o le wà loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ki a má si ṣe tú igbàiya na kuro lara ẹ̀wu-efodi na. 29 Aaroni yio si ma rù orukọ awọn ọmọ Israeli ninu igbàiya idajọ li àiya rẹ̀, nigbati o ba nwọ̀ ibi mimọ́ nì lọ, fun iranti nigbagbogbo niwaju OLUWA. 30 Iwọ o si fi Urimu on Tummimu sinu igbàiya idajọ; nwọn o si wà li àiya Aaroni, nigbati o ba nwọle lọ niwaju OLUWA; Aaroni yio si ma rù idajọ awọn ọmọ Israeli li àiya rẹ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA. 31 Iwọ o si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni kìki aṣọ-alaró. 32 Oju ọrùn yio si wà lãrin rẹ̀ fun ori; ọjá iṣẹti yio si wà yi oju rẹ̀ ká, iṣẹ-oniṣọnà gẹgẹ bi ẹ̀wu ogun, ki o má ba fàya. 33 Ati ni iṣẹti rẹ̀ nisalẹ ni iwọ o ṣe pomegranate aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, yi iṣẹti rẹ̀ ká; ati ṣaworo wurà lãrin wọn yiká; 34 Ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, li eti iṣẹti aṣọ igunwa na yiká. 35 On o si wà lara Aaroni lati ma fi ṣiṣẹ: a o si ma gbọ́ iró rẹ̀ nigbati o ba wọ̀ ibi mimọ́ lọ niwaju OLUWA, ati nigbati o ba si njade bọ̀, ki o má ba kú. 36 Iwọ o si ṣe awo ni kìki wurà, iwọ o si fin sara rẹ̀, gẹgẹ bi fifin èdidi-àmi pe, MIMỌ́ SI OLUWA. 37 Iwọ o si fi i sara ọjá-àwọn alaró, ki o le ma wà lara fila nì, niwaju fila na ni ki o wà. 38 On o si ma wà niwaju ori Aaroni, ki Aaroni le ma rù ẹ̀ṣẹ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yio si yàsimimọ́, ninu gbogbo ẹ̀bun mimọ́ wọn: on o si ma wà niwaju ori rẹ̀ nigbagbogbo, ki OLUWA ki o le ni inudidùn si wọn. 39 Iwọ o si fi ọ̀gbọ didara wun ẹ̀wu-awọtẹlẹ, iwọ o si fi ọ̀gbọ didara ṣe fila, iwọ o si fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe ọjá-amure. 40 Iwọ o si dá ẹ̀wu-awọtẹlẹ fun awọn ọmọ Aaroni, iwọ o si dá ọjá-amure fun wọn, iwọ o si dá fila fun wọn, fun ogo ati fun ọṣọ́. 41 Iwọ o si fi wọn wọ̀ Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; iwọ o si ta oróro si wọn li ori, iwọ o si yà wọn simimọ́, iwọ o si sọ wọn di mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 42 Iwọ o si dá ṣòkoto ọ̀gbọ fun wọn lati ma fi bò ìhoho wọn, ki o ti ibadi dé itan: 43 Nwọn o si wà lara Aaroni, ati lara awọn ọmọ rẹ̀, nigbati nwọn ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ, lati ṣiṣẹ ni ibi mimọ́; ki nwọn ki o má ba dẹ̀ṣẹ, nwọn a si kú: ìlana lailai ni fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.

Eksodu 29

1 EYI si li ohun ti iwọ o ṣe si wọn lati yà wọn simimọ́, lati ma ṣe alufa fun mi: mú ẹgbọ̀rọ akọmalu kan, ati àgbo meji ti kò li abùku. 2 Ati àkara alaiwu, ati adidùn àkara alaiwu ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si lori; iyẹfun alikama ni ki o fi ṣe wọn. 3 Iwọ o si fi wọn sinu agbọ̀n kan, iwọ o si mú wọn wá ninu agbọ̀n na, pẹlu akọmalu na ati àgbo mejeji. 4 Iwọ o si mú Aaroni pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn. 5 Iwọ o si mú aṣọ wọnni, iwọ o si fi ẹ̀wu-awọtẹlẹ nì wọ̀ Aaroni, ati aṣọ igunwa efodi, ati efodi, ati igbàiya, ki o si fi onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi dì i. 6 Iwọ o si fi fila nì dé e li ori, iwọ o si fi adé mimọ́ nì sara fila na. 7 Nigbana ni iwọ o si mú oróro itasori, iwọ o si dà a si i li ori, iwọ o si fi oróro yà a simimọ́. 8 Iwọ o si mú awọn ọmọ rẹ̀ wá tosi, iwọ o si wọ̀ wọn li ẹ̀wu. 9 Iwọ o si dì wọn li ọjá-amure, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si fi fila dé wọn: iṣẹ-alufa yio si ma jẹ́ ti wọn ni ìlana titi aiye: iwọ o si yà Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ simimọ́. 10 Iwọ o si mú akọmalu na wá siwaju agọ́ ajọ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé akọmalu na li ori. 11 Iwọ o si pa akọmalu na niwaju OLUWA, loju ọ̀na agọ́ ajọ. 12 Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, iwọ o si fi ika rẹ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na; iwọ o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si ìha isalẹ pẹpẹ na. 13 Iwọ o si mú gbogbo ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bori ẹ̀dọ, ati ti iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, iwọ o si sun u lori pẹpẹ na. 14 Ṣugbọn ẹran akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati igbẹ rẹ̀, on ni ki iwọ ki o fi iná sun lẹhin ode ibudó: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 15 Iwọ o si mú àgbo kan; ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori. 16 Iwọ o si pa àgbo na, iwọ o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀, iwọ o si fi i wọ́n pẹpẹ na yiká. 17 Iwọ o si kun àgbo na, iwọ o si fọ̀ ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀, iwọ o si fi wọn lé ara wọn, ati lé ori rẹ̀. 18 Iwọ o si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ na: ẹbọ sisun ni si OLUWA: õrùn didùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 19 Iwọ o si mú àgbo keji; Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori. 20 Nigbana ni ki iwọ ki o pa àgbo na, ki o si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si eti ọtún awọn ọmọ rẹ̀, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn, ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n pẹpẹ na yiká. 21 Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ ti o wà lori pẹpẹ, ati ninu oróro itasori, iwọ o si wọ́n ọ sara Aaroni, ati sara aṣọ rẹ̀, ati sara awọn ọmọ rẹ̀, ati sara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: ki a le sọ ọ di mimọ́, ati aṣọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀. 22 Iwọ o si mú ọrá, ati ìru ti o lọrá ti àgbo na, ati ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ̀, ati iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, ati itan ọtún; nitori àgbo ìyasimimọ́ ni: 23 Ati ìṣu àkara kan, ati àkara kan ti a fi oróro din, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan kuro ninu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA: 24 Iwọ o si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni lọwọ, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀; iwọ o si ma fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. 25 Iwọ o si gbà wọn li ọwọ́ wọn, iwọ o si sun wọn lori pẹpẹ na li ẹbọ sisun, fun õrùn didùn niwaju OLUWA: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. 26 Iwọ o si mú igẹ̀ àgbo ìyasimimọ́ Aaroni, iwọ o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; ìpín tirẹ li eyinì. 27 Iwọ o si yà igẹ̀ ẹbọ fifì na simimọ́, ati itan ẹbọ agbesọsoke, ti a fì, ti a si gbesọsoke ninu àgbo ìyasimimọ́ na, ani ninu eyiti iṣe ti Aaroni, ati ninu eyiti iṣe ti awọn ọmọ rẹ̀: 28 Eyi ni yio si ma ṣe ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ìlana lailai lọwọ awọn ọmọ Israeli: nitori ẹbọ agbesọsoke ni: ẹbọ agbesọsoke ni yio si ṣe lati ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, ninu ẹbọ alafia wọn, ani ẹbọ agbesọsoke wọn si OLUWA. 29 Ati aṣọ mimọ́ ti Aaroni ni yio ṣe ti awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, lati ma fi oróro yàn wọn ninu wọn, ati lati ma yà wọn simimọ́ ninu wọn. 30 Ẹnikan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti o ba jẹ́ alufa ni ipò rẹ̀ ni yio mú wọn wọ̀ ni ijọ́ meje, nigbati o ba wá sinu agọ́ ajọ, lati ṣe ìsin ni ibi mimọ́ nì. 31 Iwọ o si mú àgbo ìyasimimọ́ nì, iwọ o si bọ̀ ẹran rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan. 32 Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si jẹ ẹran àgbo na, ati àkara na ti o wà ninu agbọ̀n nì, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 33 Nwọn o si jẹ nkan wọnni ti a fi ṣètutu na, lati yà wọn simimọ́, ati lati sọ wọn di mimọ́: ṣugbọn alejò ni kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, nitoripe mimọ́ ni. 34 Bi ohun kan ninu ẹran ìyasimimọ́ na, tabi ninu àkara na, ba kú titi di ojumọ́, nigbana ni ki iwọ ki o fi iná sun iyokù: a ki yio jẹ ẹ, nitoripe mimọ́ ni. 35 Bayi ni iwọ o si ṣe fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti mo paṣẹ fun ọ: ijọ́ meje ni iwọ o fi yà wọn simimọ́. 36 Iwọ o si ma pa akọmalu kọkan li ojojumọ́ ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu: iwọ o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, nigbati iwọ ba ṣètutu si i tán, iwọ o si ta oróro si i lati yà a simimọ́. 37 Ni ijọ́ meje ni iwọ o fi ṣètutu si pẹpẹ na, iwọ o si yà a simimọ́: on o si ṣe pẹpẹ mimọ́ julọ; ohunkohun ti o ba fọwọkàn pẹpẹ na, mimọ́ ni yio jẹ́. 38 Njẹ eyi ni iwọ o ma fi rubọ lori pẹpẹ na; ọdọ-agutan meji ọlọdún kan li ojojumọ́ lailai. 39 Ọdọ-agutan kan ni iwọ o fi rubọ li owurọ̀; ati ọdọ-agutan keji ni iwọ o fi rubọ li aṣalẹ: 40 Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin hini oróro ti a gún pòlu; ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ mimu, fun ọdọ-agutan ekini. 41 Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o pa rubọ li aṣalẹ, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi ẹbọ jijẹ owurọ̀, ati gẹgẹ bi ẹbọ mimu rẹ̀, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. 42 Ẹbọ sisun titilai ni yio ṣe lati irandiran nyin li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ niwaju OLUWA: nibiti emi o ma bá nyin pade lati ma bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀. 43 Nibẹ̀ li emi o ma pade awọn ọmọ Israeli; a o si fi ogo mi yà agọ́ na simimọ́. 44 Emi o si yà agọ́ ajọ na simimọ́, ati pẹpẹ nì: emi o si yà Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ simimọ́, lati ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 45 Emi o si ma gbé ãrin awọn ọmọ Israeli, emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn. 46 Nwọn o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun wọn, ti o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá, ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn: emi li OLUWA Ọlọrun wọn.

Eksodu 30

1 IWỌ o si ṣe pẹpẹ kan lati ma jó turari lori rẹ̀: igi ṣittimu ni ki iwọ ki o fi ṣe e. 2 Igbọnwọ kan ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀; ìha mẹrin ọgbọgba ni ki o jẹ́: igbọnwọ meji si ni giga rẹ̀: iwo rẹ̀ yio si wà lara rẹ̀. 3 Iwọ o si fi kìki wurà bò o, oke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀; iwọ o si ṣe igbáti wurà yi i ká. 4 Ati oruka wurà meji ni ki iwọ ki o ṣe nisalẹ igbáti rẹ̀, ni ìha igun rẹ̀ meji, li ẹgbẹ rẹ̀ mejeji ni ki iwọ ki o ṣe e si; nwọn o si jasi ipò fun ọpá wọnni, lati ma fi gbé e. 5 Iwọ o si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, iwọ o si fi wurà bò wọn. 6 Iwọ o si gbé e kà iwaju aṣọ-ikele nì ti o wà lẹba apoti ẹrí, niwaju itẹ́-ãnu ti o wà lori apoti ẹrí nì, nibiti emi o ma bá ọ pade. 7 Aaroni yio si ma jó turari didùn lori rẹ̀; li orowurọ̀, nigbati o ba tun fitila wọnni ṣe, on o si ma jó o lori rẹ̀. 8 Nigbati Aaroni ba si tàn fitila wọnni li aṣalẹ, yio si ma jó turari lori rẹ̀, turari titilai niwaju OLUWA lati irandiran nyin. 9 Ẹnyin kò gbọdọ mú ajeji turari wá sori rẹ̀, tabi ẹbọ sisun, tabi ẹbọ onjẹ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ dà ẹbọ ohun mimu sori rẹ̀. 10 Aaroni yio si ma fi ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ ètutu ṣètutu lori iwo rẹ̀ lẹ̃kan li ọdún: yio ṣètutu lori rẹ̀ lẹ̃kan li ọdun lati irandiran nyin: mimọ́ julọ ni si OLUWA. 11 OLUWA si sọ fun Mose pe, 12 Nigbati iwọ ba kà iye awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi ẹgbẹ wọn, nigbana li olukuluku ọkunrin yio mú irapada ọkàn rẹ̀ fun OLUWA wá, nigbati iwọ ba kà iye wọn; ki ajakalẹ-àrun ki o máṣe si ninu wọn, nigbati iwọ ba nkà iye wọn. 13 Eyi ni nwọn o múwa, olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, àbọ ṣekeli, ani ṣekeli ibi mimọ́: (ogún gera ni ṣekeli kan:) àbọ ṣekeli li ọrẹ fun OLUWA. 14 Olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, ni yio fi ọrẹ fun OLUWA. 15 Olowo ki o san jù bẹ̃ lọ, bẹ̃li awọn talaka kò si gbọdọ di li àbọ ṣekeli, nigbati nwọn ba mú ọrẹ wá fun OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin. 16 Iwọ o si gbà owo ètutu na lọwọ awọn ọmọ Israeli, iwọ o si fi i lelẹ fun ìsin agọ́ ajọ; ki o le ma ṣe iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin. 17 OLUWA si sọ fun Mose pe, 18 Iwọ o si ṣe agbada idẹ kan, ati ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fun wiwẹ̀: iwọ o si gbẹ́ e kà agbedemeji agọ́ ajọ, ati pẹpẹ nì, iwọ o si pọn omi sinu rẹ̀. 19 Nitori Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn nibẹ̀: 20 Nigbati nwọn ba nwọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, nwọn o fi omi wẹ̀ ki nwọn ki o má ba kú: tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ nì lati ṣe ìsin, lati ru ẹbọ sisun ti a fi iná ṣe si OLUWA: 21 Nwọn o si wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn, ki nwọn ki o má ba kú: yio si di ìlana fun wọn lailai, fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lati irandiran wọn. 22 OLUWA si sọ fun Mose pe, 23 Iwọ mú ãyo olõrùn si ọdọ rẹ, pẹlu ojia sísan ẹdẹgbẹta ṣekeli, ati kinnamoni didùn idameji bẹ̃, ani ãdọtalerugba ṣekeli, ati kalamu didùn ãdọtalerugba ṣekeli, 24 Ati kassia ẹdẹgbẹta ṣekeli, ṣekeli ibi mimọ́, ati hini oróro olifi kan: 25 Iwọ o si ṣe e li oróro mimọ́ ikunra, ti a fi ọgbọ́n alapòlu pò: yio si jẹ́ oróro mimọ́ itasori. 26 Iwọ o si ta ninu rẹ̀ sara agọ́ ajọ, ati apoti ẹrí nì, 27 Ati tabili ati ohunèlo rẹ̀ gbogbo, ati ọpáfitila ati ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari, 28 Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀. 29 Iwọ o si yà wọn simimọ́, ki nwọn ki o le ṣe mimọ́ julọ: ohunkohun ti o ba fọwọkàn wọn yio di mimọ́. 30 Iwọ o si ta òróró sí Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si yà wọn si mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe alufa fun mi. 31 Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Eyi ni yio ma ṣe oróro mimọ́ itasori fun mi lati irandiran nyin. 32 A ko gbọdọ dà a si ara enia, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe irú rẹ̀, ni ìwọn pipò rẹ̀: mimọ́ ni, yio si ma ṣe mimọ́ fun nyin. 33 Ẹnikẹni ti o ba pò bi irú rẹ̀, tabi ẹnikẹni ti o ba fi sara alejò ninu rẹ̀, on li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 34 OLUWA si wi fun Mose pe, Mú olõrùn didùn sọdọ rẹ, stakte, ati onika, ati galbanumu; olõrùn didùn wọnyi, pẹlu turari daradara: òṣuwọn kan na li olukuluku; 35 Iwọ o si ṣe e ni turari, apòlu nipa ọgbọ́n-ọnà alapòlu, ti a fi iyọ̀ si, ti o dara ti o si mọ́. 36 Iwọ o si gún diẹ ninu rẹ̀ kunna, iwọ o si fi i siwaju ẹrí ninu rẹ̀ ninu agọ́ ajọ, nibiti emi o gbé ma bá ọ pade: yio ṣe mimọ́ julọ fun nyin. 37 Ati ti turari ti iwọ o ṣe, ẹnyin kò gbọdọ ṣe e fun ara nyin ni ìwọn pipò rẹ̀: yio si ṣe mimọ́ fun ọ si OLUWA. 38 Ẹnikẹni ti o ba ṣe irú rẹ̀, lati ma gbõrùn rẹ̀, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

Eksodu 31

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Wò ó, emi ti pè Besaleli li orukọ, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah: 3 Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà. 4 Lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, 5 Ati li okuta gbigbẹ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà. 6 Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ: 7 Agọ́ ajọ na, ati apoti ẹrí nì, ati itẹ́-ãnu ti o wà lori rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo Agọ́ na. 8 Ati tabili na ati ohun-èlo rẹ̀, ati ọpá-fitila mimọ́ pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari; 9 Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada nì ti on ti ẹsẹ̀ rẹ̀; 10 Ati aṣọ ìsin, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa; 11 Ati oróro itasori, ati turari olõrùn didùn fun ibi mimọ́ nì: gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ ni nwọn o ṣe. 12 OLUWA si sọ fun Mose pe, 13 Ki iwọ ki o sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ isimi mi li ẹnyin o pamọ́ nitõtọ: nitori àmi ni lãrin emi ati lãrin nyin lati irandiran nyin; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA ti o yà nyin simimọ́. 14 Nitorina ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́ isimi mọ́; nitoripe mimọ́ ni fun nyin: ẹniti o ba bà a jẹ́ on li a o pa nitõtọ: nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ kan ninu rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 15 Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ; ṣugbọn ni ọjọ́ keje ni ọjọ́ isimi, mimọ́ ni si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ li ọjọ́ isimi, on li a o si pa nitõtọ. 16 Nitorina li awọn ọmọ Israeli yio ṣe ma pa ọjọ́ isimi mọ́, lati ma kiyesi ọjọ́ isimi lati irandiran wọn, fun majẹmu titilai. 17 Àmi ni iṣe lãrin emi ati lãrin awọn ọmọ Israeli titilai: nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, ni ijọ́ keje o si simi, o si ṣe ìtura. 18 O si fi walã ẹrí meji, walã okuta, ti a fi ika Ọlọrun kọ, fun Mose, nigbati o pari ọ̀rọ bibá a sọ tán lori oke Sinai.

Eksodu 32

1 NIGBATI awọn enia ri pe, Mose pẹ lati sọkalẹ ti ori òke wá, awọn enia kó ara wọn jọ sọdọ Aaroni, nwọn si wi fun u pe, Dide, dá oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa lọ; bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. 2 Aaroni si wi fun wọn pe, Ẹ kán oruka wurà ti o wà li eti awọn aya nyin, ati ti awọn ọmọkunrin nyin, ati ti awọn ọmọbinrin nyin, ki ẹ si mú wọn tọ̀ mi wá. 3 Gbogbo awọn enia si kán oruka wurà ti o wà li eti wọn, nwọn si mú wọn tọ̀ Aaroni wá. 4 O si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si fi ohun-ọnà fifin ṣe e, nigbati o si dà a li aworan ẹgbọrọmalu tán: nwọn si wipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ Egipti wá. 5 Nigbati Aaroni si ri i, o tẹ́ pẹpẹ kan niwaju rẹ̀; Aaroni si kede, o si wipe, Ọla li ajọ fun OLUWA. 6 Nwọn si dide ni kùtukutu ijọ́ keji nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si mú ẹbọ alafia wá; awọn enia si joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. 7 OLUWA si sọ fun Mose pe, Lọ, sọkalẹ lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, nwọn ti ṣẹ̀. 8 Nwọn ti yipada kánkan kuro ni ipa-ọ̀na ti mo làsilẹ fun wọn: nwọn ti dá ere ẹgbọrọmalu fun ara wọn, nwọn si ti mbọ ọ, nwọn si ti rubọ si i, nwọn nwipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ̀ Egipti wá. 9 OLUWA si wi fun Mose pe, Emi ti ri awọn enia yi, si kiyesi i, ọlọrùn lile enia ni: 10 Njẹ nisisiyi jọwọ mi jẹ, ki ibinu mi ki o gbona si wọn, ki emi ki o le pa wọn run: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla. 11 Mose si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, OLUWA, ẽtiṣe ti ibinu rẹ fi gbona si awọn enia rẹ, ti iwọ fi ipá nla ati ọwọ́ agbara rẹ mú lati ilẹ Egipti jade wá? 12 Nitori kini awọn ara Egipti yio ṣe sọ wipe, Nitori ibi li o ṣe mú wọn jade, lati pa wọn lori oke, ati lati run wọn kuro lori ilẹ? Yipada kuro ninu ibinu rẹ ti o muna, ki o si yi ọkàn pada niti ibi yi si awọn enia rẹ. 13 Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Israeli awọn iranṣẹ rẹ, ẹniti iwọ fi ara rẹ bura fun, ti iwọ si wi fun wọn pe, Emi o mu irú-ọmọ nyin bisi i bi irawọ ọrun, ati gbogbo ilẹ na ti mo ti sọ nì, irú-ọmọ nyin li emi o fi fun, nwọn o si jogún rẹ̀ lailai. 14 OLUWA si yi ọkàn pada niti ibi na ti o ti sọ pe on o ṣe si awọn enia rẹ̀. 15 Mose si yipada, o si sọkalẹ lati ori òke na wá, walã ẹrí meji nì si wà li ọwọ́ rẹ̀; walã ti a kọwe si ni ìha mejeji; lara ekini ati ekeji li a kọwe si. 16 Iṣẹ́ Ọlọrun si ni walã wọnni, ikọwe na ni ikọwe Ọlọrun, a fin i sara walã na. 17 Nigbati Joṣua si gbọ́ ariwo awọn enia na, bi nwọn ti nhó, o wi fun Mose pe, Ariwo ogun mbẹ ni ibudó. 18 Mose si wi pe, Ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nhó nitori iṣẹgun, bẹ̃ni ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nkigbe pe a ṣẹgun wọn: ohùn awọn ti nkọrin ni mo gbọ́ yi. 19 O si ṣe, bi o ti sunmọ ibudó, o si ri ẹgbọrọmalu na, ati agbo ijó: ibinu Mose si ru gidigidi, o si sọ walã wọnni silẹ kuro li ọwọ́ rẹ̀, o si fọ́ wọn nisalẹ òke na. 20 O si mú ẹgbọrọ-malu na ti nwọn ṣe, o si sun u ni iná, o si lọ̀ ọ di ẹ̀tu, o si kù u soju omi, o si mu awọn ọmọ Israeli mu u. 21 Mose si wi fun Aaroni pe, Kili awọn enia wọnyi fi ṣe ọ, ti iwọ fi mú ẹ̀ṣẹ̀ nla wá sori wọn? 22 Aaroni si wipe, Máṣe jẹ ki ibinu oluwa mi ki o gbona: iwọ mọ̀ awọn enia yi pe, nwọn buru. 23 Awọn li o sa wi fun mi pe, Ṣe oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa: bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. 24 Emi si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba ni wurà, ki nwọn ki o kán a kuro; bẹ̃ni nwọn fi fun mi: nigbana li emi fi i sinu iná, ẹgbọrọmalu yi si ti jade wá. 25 Nigbati Mose ri i pe awọn enia na kò ṣe ikoso; nitoriti Aaroni sọ wọn di alailakoso lãrin awọn ti o dide si wọn. 26 Nigbana ni Mose duro li ẹnubode ibudó, o si wipe, Ẹnikẹni ti o wà ni ìha ti OLUWA, ki o tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn ọmọ Lefi si kó ara wọn jọ sọdọ rẹ̀. 27 O si wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli, wipe, Ki olukuluku ọkunrin ki o kọ idà rẹ̀ si ẹgbẹ́ rẹ̀, ki ẹ si ma wọle, ki ẹ si ma jade lati ẹnubode dé ẹnubode já gbogbo ibudó, olukuluku ki o si pa arakunrin rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa ẹgbẹ rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa aladugbo rẹ̀. 28 Awọn ọmọ Lefi si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose: awọn ti o ṣubu ninu awọn enia li ọjọ́ na to ìwọn ẹgbẹdogun enia. 29 Mose sa ti wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ li oni fun OLUWA, ani olukuluku ọkunrin lara ọmọ rẹ̀, ati lara arakunrin rẹ̀; ki o le fi ibukún si nyin lori li oni. 30 O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Mose wi fun awọn enia pe, Ẹnyin dá ẹ̀ṣẹ nla: njẹ nisisiyi, emi o gòke tọ̀ OLUWA, bọya emi o ṣètutu fun ẹ̀ṣẹ nyin. 31 Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wipe, Yẽ, awọn enia wọnyi ti dá ẹ̀ṣẹ nla, nwọn si dá oriṣa wurà fun ara wọn. 32 Nisisiyi, bi iwọ o ba dari ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn; bi bẹ̃ si kọ, emi bẹ̀ ọ, pa mi rẹ́ kuro ninu iwé rẹ ti iwọ ti kọ. 33 OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹnikẹni ti o ṣẹ̀ mi, on li emi o parẹ́ kuro ninu iwé mi. 34 Njẹ nisisiyi lọ, ma mú awọn enia na lọ si ibiti mo ti sọ fun ọ: kiyesi i, angeli mi yio ṣaju rẹ: ṣugbọn li ọjọ́ ti emi o ṣe ìbẹwo, emi o bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò lara wọn. 35 OLUWA si yọ awọn enia na lẹnu, nitoriti nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu, ti Aaroni ṣe.

Eksodu 33

1 OLUWA si wi fun Mose pe, Dide, gòke lati ihin lọ, iwọ ati awọn enia na ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, si ilẹ ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi i fun: 2 Emi o si rán angeli kan si iwaju rẹ; emi o si lé awọn ara Kenaani, awọn ara Amori, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi jade: 3 Si ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; emi ki yio sa gòke lọ lãrin rẹ; nitori ọlọrùn lile ni iwọ: ki emi ki o má ba run ọ li ọ̀na. 4 Nigbati awọn enia na si gbọ́ ihin buburu yi, nwọn kãnu: enia kan kò si wọ̀ ohun ọṣọ́ rẹ̀. 5 OLUWA si ti wi fun Mose pe, Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, ọlọ́rùn lile ni nyin: bi emi ba gòke wá sãrin rẹ ni iṣẹju kan, emi o si run ọ: njẹ nisisiyi bọ́ ohun ọṣọ́ rẹ kuro lara rẹ, ki emi ki o le mọ̀ ohun ti emi o fi ọ ṣe. 6 Awọn ọmọ Israeli si bọ́ ohun ọṣọ́ wọn kuro lara wọn leti oke Horebu. 7 Mose si mú agọ́ na, o si pa a lẹhin ibudó, li òkere rére si ibudó; o pè e ni Agọ́ ajọ. O si ṣe, olukuluku ẹniti mbère OLUWA o jade lọ si agọ́ ajọ, ti o wà lẹhin ibudó. 8 O si ṣe, nigbati Mose jade lọ si ibi agọ́ na, gbogbo awọn enia a si dide duro, olukuluku a si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀, a ma wò ẹhin Mose, titi yio fi dé ibi agọ́ na. 9 O si ṣe, bi Mose ti dé ibi agọ́ na, ọwọ̀n awọsanma sọkalẹ, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: OLUWA si bá Mose sọ̀rọ. 10 Gbogbo enia si ri ọwọ̀n awọsanma na o duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: gbogbo enia si dide duro, nwọn si wolẹ sìn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀. 11 OLUWA si bá Mose sọ̀rọ li ojukoju, bi enia ti ibá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ. O si tun pada lọ si ibudó: ṣugbọn Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, ọdọmọkunrin kan, kò lọ kuro ninu agọ́ na. 12 Mose si wi fun OLUWA pe, Wò o, iwọ wi fun mi pe, Mú awọn enia wọnyi gòke lọ: sibẹ̀ iwọ kò jẹ ki emi ki o mọ̀ ẹniti iwọ o rán pẹlu mi. Ṣugbọn iwọ wipe, Emi mọ̀ ọ li orukọ, iwọ si ri ore-ọfẹ li oju mi pẹlu. 13 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, fi ọ̀na rẹ hàn mi nisisiyi, ki emi ki o le mọ̀ ọ, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ: ki o si rò pe orilẹ-ède yi enia rẹ ni. 14 On si wipe, Oju mi yio ma bá ọ lọ, emi o si fun ọ ni isimi. 15 On si wi fun u pe, Bi oju rẹ kò ba bá wa lọ, máṣe mú wa gòke lati ihin lọ. 16 Nipa ewo li a o fi mọ̀ nihinyi pe, emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ani emi ati awọn enia rẹ? ki iha iṣe ni ti pe iwọ mbá wa lọ ni, bẹ̃ni a o si yà wa sọ̀tọ, emi ati awọn enia rẹ, kuro lara gbogbo enia ti o wà lori ilẹ? 17 OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o ṣe ohun yi ti iwọ sọ pẹlu: nitoriti iwọ ri ore-ọfẹ li oju mi, emi si mọ̀ ọ li orukọ. 18 O si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ogo rẹ̀ hàn mi. 19 On si wi fun u pe, Emi o mu gbogbo ore mi kọja niwaju rẹ, emi o si pè orukọ OLUWA niwaju rẹ; emi o si ṣe ore-ọfẹ fun ẹniti emi nfẹ ṣe ore-ọfẹ fun, emi o si ṣe ãnu fun ẹniti emi o ṣe ãnu fun. 20 On si wipe, Iwọ kò le ri oju mi: nitoriti kò sí enia kan ti iri mi, ti si yè. 21 OLUWA si wipe, Wò, ibi kan wà lẹba ọdọ mi, iwọ o si duro lori apata: 22 Yio si ṣe, nigbati ogo mi ba nrekọja, emi o fi ọ sinu palapala apata, emi o si fi ọwọ́ mi bò ọ titi emi o fi rekọja: 23 Nigbati emi o mú ọwọ́ mi kuro, iwọ o si ri akẹhinsi mi: ṣugbọn oju mi li a ki iri.

Eksodu 34

1 OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju: emi o si kọ ọ̀rọ walã ti iṣaju, ti iwọ ti fọ́, sara walã wọnyi. 2 Si mura li owurọ̀, ki iwọ ki o si gún òke Sinai wá li owurọ̀, ki o si wá duro niwaju mi nibẹ̀ lori òke na. 3 Ẹnikẹni ki yio si bá ọ gòke wá, ki a má si ṣe ri ẹnikẹni pẹlu li òke na gbogbo; bẹ̃ni ki a máṣe jẹ ki agbo-agutan tabi ọwọ́-ẹran ki o jẹ niwaju òke na. 4 On si gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju; Mose si dide ni kutukutu owurọ̀, o si gún òke Sinai, bi OLUWA ti paṣẹ fun u, o si mú walã okuta mejeji li ọwọ́ rẹ̀. 5 OLUWA si sọkalẹ ninu awọsanma, o si bá a duro nibẹ̀, o si pè orukọ OLUWA. 6 OLUWA si rekọja niwaju rẹ̀, o si nkepè, OLUWA, OLUWA, Olọrun alãnu ati olore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹniti o pọ̀ li ore ati otitọ; 7 Ẹniti o npa ãnu mọ́ fun ẹgbẹgbẹrun, ti o ndari aiṣedede, ati irekọja, ati ẹ̀ṣẹ jì, ati nitõtọ ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijiyà; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn omọ, ati lara awọn ọmọ ọmọ, lati irandiran ẹkẹta ati ẹkẹrin. 8 Mose si yara, o si foribalẹ, o si sìn. 9 On si wipe, Njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi Oluwa, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki Oluwa ki o ma bá wa lọ; nitori enia ọlọrùn lile ni; ki o si dari aiṣẹdede wa ati ẹ̀ṣẹ wa jì, ki o si fi wa ṣe iní rẹ. 10 On si wipe, Kiyesi i, emi dá majẹmu kan: emi o ṣe ohun iyanu, niwaju gbogbo awọn enia rẹ irú eyiti a kò ti iṣe lori ilẹ gbogbo rí, ati ninu gbogbo orilẹ-ède: ati gbogbo enia ninu awọn ti iwọ wà, nwọn o ri iṣẹ OLUWA, nitori ohun ẹ̀ru li emi o fi ọ ṣe. 11 Iwọ kiyesi eyiti emi palaṣẹ fun ọ li oni yi: kiyesi i, emi lé awọn Amori jade niwaju rẹ, ati awọn ara Kenaani, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi. 12 Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nibikibi ti iwọ nlọ, ki o má ba di idẹwò fun ọ lãrin rẹ: 13 Bikoṣepe ki ẹnyin ki o wó pẹpẹ wọn, ki ẹnyin ki o fọ́ ọwọ̀n wọn, ki ẹnyin si wó ere oriṣa wọn lulẹ. 14 Nitoriti ẹnyin kò gbọdọ bọ oriṣa: nitori OLUWA, orukọ ẹniti ijẹ Ojowu, Ọlọrun ojowú li on: 15 Ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nigbati nwọn ba nṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ti nwọn si nrubọ si oriṣa wọn, ti nwọn si pè ọ ti iwọ si lọ jẹ ninu ẹbọ wọn; 16 Ki iwọ ki o má si ṣe fẹ́ ninu awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmokọnrin rẹ, ki awọn ọmọbinrin wọn ki o má ba ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ki nwọn ki o má ba mu ki awọn ọmọkunrin rẹ ki o ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn. 17 Iwọ kò gbọdọ dà ere oriṣakoriṣa kan fun ara rẹ. 18 Ajọ aiwukàra ni ki iwọ ki o ma pamọ́. Ijọ́ meje ni iwọ o jẹ àkara alaiwu, bi mo ti paṣẹ fun ọ, ni ìgba oṣù Abibu: nitoripe li oṣù Abibu ni iwọ jade kuro ni Egipti. 19 Gbogbo akọ́bi ni ti emi; ati akọ ninu gbogbo ohunọ̀sin rẹ; akọ́bi ti malu, ati ti agutan. 20 Ṣugbọn akọ́bi kẹtẹkẹtẹ ni ki iwọ ki o fi ọdọ-agutan rapada: bi iwọ kò ba si rà a pada, njẹ ki iwọ ki o ṣẹ́ ẹ li ọrùn. Gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọkunrin rẹ ni ki iwọ ki o rapada. Kò si sí ẹnikan ti yio farahàn niwaju mi lọwọ ofo. 21 Ijọ́ mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ni ijọ́ keje ni ki iwọ ki o simi: ni ìgba ifunrugbìn, ati ni ìgba ikore ni ki iwọ ki o simi. 22 Iwọ o si ma kiyesi ajọ ọ̀sẹ, akọ́so eso alikama, ati ajọ ikore li opin ọdún. 23 Li ẹrinmẹta li ọdún kan ni gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ yio farahàn niwaju Oluwa, ỌLỌRUN, Ọlọrun Israeli. 24 Nitoriti emi o lé awọn orilẹ-ède nì jade niwaju rẹ, emi o si fẹ̀ ipinlẹ rẹ: bẹ̃li ẹnikẹni ki yio fẹ́ ilẹ̀-iní rẹ, nigbati iwọ o gòke lọ lati pejọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ẹrinmẹta li ọdún kan. 25 Iwọ kò gbọdọ ta ẹ̀jẹ ẹbọ mi silẹ nibiti iwukàra wà, bẹ̃li ẹbọ ajọ irekọja kò gbọdọ kù titi di owurọ̀. 26 Akọ́so eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o mú wa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀. 27 OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ kọwe ọ̀rọ wọnyi: nitori nipa ìmọ ọ̀rọ wọnyi li emi bá iwọ ati Israeli dá majẹmu. 28 On si wà nibẹ̀, lọdọ OLUWA li ogoji ọsán ati ogoji oru: on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi. On si kọwe ọ̀rọ majẹmu na, ofin mẹwa nì, sara walã wọnni. 29 O si ṣe, nigbati Mose sọkalẹ lati ori òke Sinai wá ti on ti walã ẹrí mejeji nì li ọwọ́ Mose, nigbati o sọkalẹ ti ori òke na wá, ti Mose kò mọ̀ pe awọ oju on ndán nitoriti o bá a sọ̀rọ. 30 Nigbati Aaroni ati gbogbo awọn ọmọ Israeli ri Mose, kiyesi i, awọ oju rẹ̀ ndán; nwọn si bẹ̀ru lati sunmọ ọdọ rẹ̀. 31 Mose si kọ si wọn; ati Aaroni ati gbogbo awọn ijoye inu ajọ si pada tọ̀ ọ́ wá: Mose si bá wọn sọ̀rọ. 32 Lẹhin eyinì ni gbogbo awọn ọmọ Israeli si sunmọ ọ: o si paṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA bá a sọ lori òke Sinai fun wọn. 33 Nigbati Mose si bá wọn sọ̀rọ tán, o fi iboju bò oju rẹ̀. 34 Ṣugbọn nigbati Mose ba lọ si iwaju OLUWA lati bá a sọ̀rọ, a mú iboju na kuro titi o fi jade: a si jade, a si bá awọn ọmọ Israeli sọ̀rọ aṣẹ ti a pa fun u. 35 Awọn ọmọ Israeli si ri oju Mose pe, awọ, oju rẹ̀ ndán: Mose si tun fi iboju bò oju rẹ̀, titi o fi wọle lọ bá a sọ̀rọ.

Eksodu 35

1 MOSE si pè apejọ gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Wọnyi li ọ̀rọ ti OLUWA palaṣẹ pe, ki ẹnyin ki o ṣe wọn. 2 Ijọ́ mẹfa ni ki a fi ṣe iṣẹ, ṣugbọn ijọ́ keje ni yio ṣe ọjọ́ mimọ́ fun nyin, ọjọ́ isimi ọ̀wọ si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹ ninu rẹ̀ li a o lupa nitõtọ. 3 Ẹnyin kò gbọdọ da iná ni ile nyin gbogbo li ọjọ́ isimi. 4 Mose si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, wipe, 5 Ẹnyin mú ọrẹ wá lati inu ara nyin fun OLUWA: ẹnikẹni ti ọkàn rẹ̀ fẹ́, ki o mú u wá, li ọrẹ fun OLUWA; wurà, ati fadakà, ati idẹ; 6 Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara, ati irun ewurẹ; 7 Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu; 8 Ati oróro fun fitila, ati olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn; 9 Ati okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya. 10 Gbogbo ọlọgbọ́n inú ninu nyin yio si wá, yio si wá ṣiṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ; 11 Ibugbé na, ti on ti agọ́ rẹ̀, ati ibori rẹ̀, kọkọrọ rẹ̀, ati apáko rẹ̀, ọpá rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀; 12 Apoti nì, ati ọpá rẹ̀, itẹ́-ãnu nì, ati aṣọ-ikele na; 13 Tabili na, ati ọpá rẹ̀, ati ohun-èlo rẹ̀ gbogbo, ati àkara ifihàn nì; 14 Ati ọpà-fitila na fun titanna, ati ohun-elo rẹ̀, ati fitila rẹ̀, pẹlu oróro fun titanna. 15 Ati pẹpẹ turari, ati ọpá rẹ̀, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-sisorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na, ani atiwọle ẹnu agọ́ na; 16 Ati pẹpẹ ẹbọsisun, ti on ti àwọn oju-àro idẹ rẹ̀, ati ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, agbada na ti on ti ẹsẹ rẹ̀; 17 Aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agbalá na; 18 Ekàn agọ́ na, ati ekàn agbalá na, ati okùn wọn; 19 Aṣọ ìsin wọnni, lati sìn ni ibi mimọ́, aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa. 20 Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si lọ kuro ni iwaju Mose. 21 Nwọn si wá, olukuluku ẹniti ọkàn rẹ́ ru ninu rẹ̀, ati olukuluku ẹniti ọkàn rẹ̀ mu u fẹ́, nwọn si mú ọrẹ OLUWA wá fun iṣẹ agọ́ ajọ na, ati fun ìsin rẹ̀ gbogbo, ati fun aṣọ mimọ́ wọnni. 22 Nwọn si wá, ati ọkunrin ati obinrin, iye awọn ti ọkàn wọn fẹ́, nwọn si mú jufù wá, ati oruka-eti, ati oruka-àmi, ati ilẹkẹ wurà, ati onirũru ohun ọṣọ́ wurà; ati olukuluku enia ti o nta ọrẹ, o ta ọrẹ wurà fun OLUWA. 23 Ati olukuluku enia lọdọ ẹniti a ri aṣọ-alaró, ati elesè àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ daradara, ati irun ewurẹ, ati awọ àgbo pupa, ati awọ seali, mú wọn wá. 24 Olukuluku ẹniti o ta ọrẹ fadakà ati idẹ, o mú ọrẹ OLUWA wá: ati olukuluku enia lati ọdọ ẹniti a ri igi ṣittimu fun iṣẹkiṣẹ ìsin na, mú u wá. 25 Ati gbogbo awọn obinrin ti iṣe ọlọgbọ́n inu, nwọn fi ọwọ́ wọn ranwu, nwọn si mú eyiti nwọn ran wá, ti alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ daradara. 26 Ati gbogbo awọn obinrin inu ẹniti o ru soke li ọgbọ́n nwọn ran irun ewurẹ. 27 Ati awọn ijoye mú okuta oniki wá, ati okuta ti a o tò, fun ẹ̀wu-efodi nì, ati fun igbàiya nì; 28 Ati olõrùn, ati oróro; fun fitila, ati fun oróro itasori, ati fun turari didùn. 29 Awọn ọmọ Israeli ta ọrẹ atinuwa fun OLUWA; olukuluku ọkunrin ati obinrin, ẹniti ọkàn wọn mu wọn fẹ́ lati mú u wá fun onirũru iṣẹ, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe lati ọwọ́ Mose wá, 30 Mose si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Wò o, OLUWA ti pè Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, li orukọ. 31 O si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, li oyé, ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà; 32 Ati lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, 33 Ati li okuta gbigbẹ́ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà. 34 O si fi sinu ọkàn rẹ̀ lati ma kọni, ati on, ati Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani. 35 O si fi ọgbọ́n inu kún wọn, lati ṣe onirũru iṣẹ, ti alagbẹdẹ, ati ti ọnà, ati ti agunnà, li aṣọ-alaró, ati li elesè-àluko, li ododó, ati li ọ̀gbọ daradara, ati ti ahunṣọ, ati ti awọn ẹniti nṣe iṣẹkiṣẹ ati ti awọn ẹniti nhumọ̀ iṣẹ-ọnà.

Eksodu 36

1 BESALELI ati Oholiabu yio si ṣiṣẹ, ati olukuluku ọlọgbọ́n inu, ninu ẹniti OLUWA fi ọgbọn ati oyé si, lati mọ̀ bi a ti ṣiṣẹ onirũru iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA ti palaṣẹ. 2 Mose si pè Besaleli ati Oholiabu, ati gbogbo ọkunrin ọlọgbọ́n inu, ninu ọkàn ẹniti OLUWA fi ọgbọ́n si, ani gbogbo ẹniti inu wọn ru soke lati wá si ibi iṣẹ na lati ṣe e: 3 Nwọn si gbà gbogbo ọrẹ na lọwọ Mose, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, lati fi ṣe e. Sibẹ̀ nwọn si nmú ọrẹ ọfẹ fun u wá li orowurọ̀. 4 Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọgbọ́n, ti o ṣe gbogbo isẹ ibi mimọ́ na, lọ olukuluku kuro ni ibi iṣẹ rẹ̀ ti nwọn ṣe; 5 Nwọn si sọ fun Mose pe, Awọn enia múwa pupọ̀ju fun iṣẹ ìsin na, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe. 6 Mose si paṣẹ, nwọn si ṣe ki nwọn ki o kede yi gbogbo ibudó na ká, wipe, Máṣe jẹ ki ọkunrin tabi obinrin ki o tun ṣe iṣẹkiṣẹ fun ọrẹ ibi mimọ́ na mọ́. Bẹ̃li a da awọn enia lẹkun ati ma múwa. 7 Nitoriti ohun-èlo ti nwọn ni o to fun gbogbo iṣẹ na, lati fi ṣe e, o si pọ̀ju. 8 Ati olukuluku ọkunrin ọlọgbọ́n ninu awọn ti o ṣe iṣẹ agọ́ na, nwọn ṣiṣẹ aṣọ-tita mẹwa; ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, pẹlu awọn kerubu, iṣẹ-ọnà li on fi ṣe wọn. 9 Ina aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ati ibò aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na jẹ́ ìwọn kanna. 10 O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn: ati aṣọ-tita marun keji li o si solù mọ́ ara wọn. 11 O si pa ojóbo aṣọ-alaró li eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù; bẹ̃ gẹgẹ li o ṣe si ìha eti ikangun aṣọ-tita keji nibi isolù keji. 12 Ãdọta ojóbo li o pa lara aṣọ-tita kan, ati ãdọta ojóbo li o si pa li eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji: ojóbo na so aṣọ-tita kini mọ́ keji. 13 O si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, o si fi ikọ́ wọnni fi aṣọ-tita kan kọ́ ekeji: bẹ̃li o si di odidi agọ́. 14 O si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ fun agọ́ na lori ibugbé na: aṣọ-tita mọkanla li o ṣe wọn. 15 Ìna aṣọ-tita kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ibò aṣọ-tita kan si jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla jẹ́ ìwọn kanna. 16 O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn. 17 O si pa ãdọta ojóbo si ìha eti ikangun aṣọ-tita na ni ibi isolù, ati ãdọta ojóbo li o si pa si eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù. 18 O si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ lati so agọ́ na lù pọ̀, ki o le ṣe ọkan. 19 O si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori eyi. 20 O si ṣe apáko igi ṣittimu fun agọ́ na li ogurodo. 21 Gigùn apáko kan jẹ́ igbọnwọ mẹwa, ati ibú apáko kan jẹ́ igbọnwọ kan on àbọ. 22 Apáko kan ni ìtẹbọ meji, nwọn jìna si ara wọn li ọgbọgba; bẹ̃li o ṣe sara gbogbo apáko agọ́ na. 23 O si fi apáko ṣe agọ́ na; ogún apáko ni fun ìha ọtún, si ìha gusù: 24 Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà li o ṣe nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ rẹ̀ meji, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ rẹ̀ meji. 25 Ati fun ìha keji agọ́ na, ti o wà ni ìha ariwa, o ṣe ogún apáko, 26 Ati ogoji ihò-ìtẹbọ wọn ti fadakà; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji. 27 Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn o ṣe apáko mẹfa. 28 Apáko meji li o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha mejeji. 29 A si so wọn lù nisalẹ, a si so wọn lù pọ̀ li ori rẹ̀, si oruka kan: bẹ̃li o ṣe si awọn meji ni igun mejeji. 30 Apáko mẹjọ li o wà, ihò-ìtẹbọ wọn si jẹ́ ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun ti fadakà; ìtẹbọ mejimeji li o wà nisalẹ apáko kọkan. 31 O si ṣe ọpá igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na, 32 Ati ọpá marun fun apáko ìha keji agọ́ na, ati ọpá marun fun apáko agọ́ na fun ìha ìwọ-õrùn. 33 O si ṣe ọpá ãrin o yọ jade lara apáko wọnni, lati opin ekini dé ekeji. 34 O si fi wurà bò apáko wọnni, o si fi wurà ṣe oruka wọn, lati ṣe ipò fun ọpá wọnni, o si fi wurà bò ọpá wọnni. 35 O si fi aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ṣe aṣọ-ikele: iṣẹ ọlọnà li o fi ṣe e ti on ti awọn kerubu. 36 O si ṣe opó igi ṣittimu mẹrin si i, o si fi wurà bò wọn: kọkọrọ wọn ti wurà ni, o si dà ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrin fun wọn. 37 O si ṣe aṣọ-isorọ̀ kan fun ẹnu-ọ̀na Agọ́ na, aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti iṣẹ abẹ́rẹ; 38 Ati opó rẹ̀ mararun ti on ti kọkọrọ wọn: o si fi wurà bò ọnà ori wọn, ati ọjá wọn: ṣugbọn idẹ ni ihò-ìtẹbọ wọn mararun.

Eksodu 37

1 BESALELI si fi igi ṣittimu ṣe apoti na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀: 2 O si fi kìki wurà bò o ninu ati lode, o si ṣe igbáti wurà si i yiká. 3 O si dà oruka wurà mẹrin fun u, lati fi si igun mẹrẹrin rẹ̀; oruka meji si ìha kini rẹ̀, ati meji si ìha keji rẹ̀. 4 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá, o si fi wurà bò wọn. 5 O si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, lati ma rù apoti na 6 O si fi kìki wurà ṣe itẹ́-ãnu na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀. 7 O si ṣe kerubu wurà meji; iṣẹ lilù li o ṣe wọn, ni ìku mejeji itẹ́-ãnu na; 8 Kerubu kan ni ìku kini, ati kerubu keji ni ìku keji: lati ara itẹ́-ãnu li o ti ṣe awọn kerubu na ni ìku mejeji rẹ̀. 9 Awọn kerubu na si nà iyẹ́-apa wọn soke, nwọn si fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, nwọn si dojukọ ara wọn; itẹ́-ãnu na ni awọn kerubu kọjusi. 10 O si fi igi ṣittimu ṣe tabili kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀: 11 O si fi kìki wurà bò o, o si ṣe igbáti wurà si i yiká. 12 O si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, o si ṣe igbáti wurà kan fun eti rẹ̀ yiká. 13 O si dà oruka wurà mẹrin fun u, o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà ni ibi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rẹ̀. 14 Labẹ igbáti na ni oruka wọnni wà, àye fun ọpá lati fi rù tabili na. 15 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn, lati ma rù tabili na. 16 O si ṣe ohunèlo wọnni ti o wà lori tabili na, awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, lati ma fi dà ohun mimu, kìki wurà ni. 17 O si fi kìki wurà, ṣe ọpá-fitila: iṣẹ lilù li o ṣe ọpá-fitila na; ọpá rẹ̀, ati ẹka rẹ̀, ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn: 18 Ẹka mẹfa li o jade ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan rẹ̀, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na, ni ìha keji rẹ̀. 19 Ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka kan, irudi kan ati itanna; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka keji, irudi kan ati itanna: bẹ̃ni li ẹka mẹfẹfa ti o jade lara ọpá-fitila na. 20 Ati ninu ọpá-fitila na li a ṣe ago mẹrin bi itanna almondi, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀: 21 Ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, gẹgẹ bi ẹka mẹfẹfa ti o jade lara rẹ̀. 22 Irudi wọn ati ẹka wọn jẹ bakanna: gbogbo rẹ̀ jẹ́ iṣẹ lilù kìki wurà kan. 23 O si ṣe fitila rẹ̀, meje, ati alumagaji rẹ̀, ati awo rẹ̀, kìki wurà ni. 24 Talenti kan kìki wurà li o fi ṣe e, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀. 25 O si fi igi ṣittimu ṣe pẹpẹ turari: gigùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, ibú rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ kan, ìha mẹrin ọgbọgba; giga rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ meji; iwo rẹ̀ wà lara rẹ̀. 26 O si fi kìki wurà bò o, ati òke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀: o si ṣe igbáti wurà si i yiká. 27 O si ṣe oruka wurà meji si i nisalẹ̀ igbáti rẹ̀ na, ni ìha igun rẹ̀ meji, ìha mejeji rẹ̀, lati ṣe àye fun ọpá wọnni lati ma fi rù u. 28 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn. 29 O si ṣe oróro mimọ́ itasori nì, ati õrùn didùn kìki turari, gẹgẹ bi iṣẹ alapòlu.

Eksodu 38

1 O SI fi igi ṣittimu ṣe pẹpẹ ẹbọsisun: igbọnwọ marun ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ marun ni ibú rẹ̀; onìha mẹrin ọgbọgba ni; igbọnwọ mẹta si ni giga rẹ̀. 2 O si ṣe iwo rẹ̀ si i ni igun rẹ̀ mẹrẹrin; iwo rẹ̀ wà lara rẹ̀: o si fi idẹ bò o. 3 O si ṣe gbogbo ohunèlo pẹpẹ na, ìkoko rẹ̀, ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo iná wọnni: gbogbo ohunèlo rẹ̀ li o fi idẹ ṣe. 4 O si ṣe àro idẹ fun pẹpẹ na ni iṣẹ àwọn nisalẹ ayiká rẹ̀, dé agbedemeji rẹ̀. 5 O si dà oruka mẹrin fun ìku mẹrẹrin àro idẹ na, li àye fun ọpá wọnni. 6 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi idẹ bò wọn. 7 O si fi ọpá wọnni sinu oruka ni ìha pẹpẹ na, lati ma fi rù u; o fi apáko ṣe pẹpẹ na li onihò ninu. 8 O si fi idẹ ṣe agbada na, o si fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀, ti awojiji ẹgbẹ awọn obinrin ti npejọ lati sìn li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 9 O si ṣe agbalá na: ni ìha gusù li ọwọ́ ọtún aṣọ-tita agbalá na jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ọgọrun igbọnwọ: 10 Opó wọn jẹ́ ogún, ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà. 11 Ati fun ìha ariwa ọgọrun igbọnwọ, opó wọn jẹ́ ogún, ati ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà. 12 Ati fun ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ, opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà. 13 Ati fun ìha ìla-õrùn, si ìha ìla-õrùn ãdọta igbọnwọ. 14 Aṣọ-tita apakan jẹ́ igbọnwọ mẹdogun; opó wọn jẹ́ mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn jẹ́ mẹta. 15 Ati fun apa keji: li apa ihin ati li apa ọhún ẹnu-ọ̀na agbalá na, li aṣọ-tita onigbọnwọ mẹdogun wà; opó wọn jẹ́ mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn jẹ́ mẹta. 16 Gbogbo aṣọ-tita agbalá na yiká jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ. 17 Ati ihò-ìtẹbọ fun opó wọnni jẹ́ idẹ; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà; ati ibori ori wọn jẹ́ fadakà; ati gbogbo opó agbalá na li a fi fadakà gbà li ọjá. 18 Ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na jẹ́ iṣẹ abẹ́rẹ, aṣọ-alaró, ati elesè-aluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ: ogún igbọnwọ si ni gigùn rẹ̀, ati giga ni ibò rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun, o bá aṣọ-tita agbalá wọnni ṣedede. 19 Opó wọn si jẹ́ mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ, mẹrin; kọkọrọ wọn jẹ́ fadakà, ati ibori ori wọn ati ọjá wọn jẹ́ fadakà. 20 Ati gbogbo ekàn agọ́ na, ati ti agbalá rẹ̀ yiká jẹ́ idẹ. 21 Eyi ni iye agọ́ na, agọ́ ẹrí nì, bi a ti kà wọn, gẹgẹ bi ofin Mose, fun ìrin awọn ọmọ Lefi, lati ọwọ́ Itamari wá, ọmọ Aaroni alufa. 22 Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, si ṣe ohun gbogbo ti OLUWA paṣẹ fun Mose. 23 Ati Oholiabu pẹlu rẹ̀, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, alagbẹdẹ, ati ọlọgbọ́n ọlọnà, alaró ati ahunṣọ alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara. 24 Gbogbo wurà ti a lò si iṣẹ na, ni onirũru iṣẹ ibi mimọ́ nì, ani wurà ọrẹ nì, o jẹ́ talenti mọkandilọgbọ̀n, ati ẹgbẹrin ṣekeli o din ãdọrin, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́. 25 Ati fadakà awọn ẹniti a kà ninu ijọ-enia jẹ́ ọgọrun talenti, ati ṣekeli ojidilẹgbẹsan o le mẹdogun, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́: 26 Abọ ṣekeli kan li ori ọkunrin kọkan, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́, lori ori olukuluku ti o kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ le ẹgbẹtadilogun o le ãdọjọ enia. 27 Ati ninu ọgọrun talenti fadakà na li a ti dà ihò-ìtẹbọ wọnni ti ibi mimọ́, ati ihò-ìtẹbọ ti aṣọ-ikele na, ọgọrun ihò-ìtẹbọ ninu ọgọrun talenti na, talenti ka fun ihò-ìtẹbọ kan. 28 Ati ninu ojidilẹgbẹsan ṣekeli o le mẹdogun, o mú ṣe kọkọrọ fun ọwọ̀n wọnni, o si fi i bò ori wọn, o si fi i ṣe ọjá wọn. 29 Ati idẹ ọrẹ na jẹ́ ãdọrin talenti, ati egbejila ṣekeli. 30 On li o si fi ṣe ihò-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ati pẹpẹ idẹ na, ati àro idẹ sara rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na, 31 Ati ihò-ìtẹbọ agbalá, na yikà, ati ìho-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agbalá, ati gbogbo ekàn agọ́ na, ati gbogbo ekàn agbalà na yikà.

Eksodu 39

1 NWỌN si fi ninu aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, dá aṣọ ìsin, lati ma fi sìn ni ibi mimọ́, nwọn si dá aṣọ mimọ́ ti iṣe fun Aaroni; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 2 O si ṣe ẹ̀wu-efodi na ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ. 3 Nwọn si lù wurà nì di ewé fẹlẹfẹlẹ, nwọn si là a li okùn wẹ́wẹ, ati lati fi ṣe iṣẹ ọlọnà sinu aṣọ-alaró, ati sinu elesè-àluko, ati sinu ododó, ati sinu ọ̀gbọ didara nì. 4 Nwọn ṣe aṣọ ejika si i, lati so o lù: li eti mejeji li a so o lù. 5 Ati onirũru-ọnà ọjá ti o wà lara rẹ̀, lati fi dì i o jẹ́ ọkanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, aṣọ-alaró, elesè-àluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 6 Nwọn si ṣiṣẹ́ okuta oniki ti a tò sinu oju-ìde wurà, ti a fin bi ifin èdidi-àmi ti a fin orukọ awọn ọmọ Israeli si. 7 O si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi na, li okuta, iranti fun awọn ọmọ Israeli: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 8 O si fi iṣẹ ọlọnà ṣiṣẹ igbàiya na, bi iṣẹ ẹ̀wu-efodi nì; ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododo, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ. 9 Oniha mẹrin ọgbọgba ni; nwọn ṣe igbàiya na ni iṣẹpo meji: ika kan ni gigùn rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀, o jẹ́ iṣẹpo meji. 10 Nwọn si tò ẹsẹ̀ okuta mẹrin si i: ẹsẹ̀ ekini ni sardiu, ati topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini. 11 Ati ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi. 12 Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu. 13 Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, oniki, ati jasperi: a si tò wọn si oju-ìde wurà ni titò wọn. 14 Okuta wọnni si jasi gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn, bi ifin èdidi-àmi, olukuluku ti on ti orukọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ya mejejila. 15 Nwọn si ṣe ẹ̀wọn iṣẹ-ọnà-lilọ kìki wurà si igbàiya na. 16 Nwọn si ṣe oju-ìde wurà meji, ati oruka wurà meji; nwọn si fi oruka mejeji si eti igbàiya na mejeji. 17 Nwọn si fi ẹ̀wọn wurà iṣẹ-ọnà-lilọ mejeji bọ̀ inu oruka wọnni, ni eti igbàiya na. 18 Ati eti mejeji ti ẹ̀wọn iṣẹ-lilọ mejeji nì ni nwọn fi mọ́ inu oju-ìde mejeji, nwọn si fi wọn sara okùn ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀. 19 Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si eti mejeji igbàiya na, si eti rẹ̀ ti o wà, ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inu. 20 Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si ìha mejeji ẹ̀wu-efodi na nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ki o kọjusi isolù rẹ̀, loke ọjá ẹ̀wu-efodi na. 21 Nwọn si fi oruka rẹ̀ dè igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi pẹlu ọjá-àwọn aṣọ-aláró, ki o le ma wà lori onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ati ki igbàiya ni ki o máṣe tú kuro lara ẹ̀wu-efodi na; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 22 O si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni iṣẹ wiwun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ-aláró. 23 Oju-ọrùn si wà li agbedemeji aṣọ-igunwa na, o dabi oju-ẹ̀wu ogun, pẹlu ọjá yi oju na ká, ki o máṣe ya. 24 Nwọn si ṣe pomegranate aṣọ: alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ si iṣẹti aṣọ-igunwa na. 25 Nwọn si ṣe ṣaworo kìki wurà, nwọn si fi ṣaworo na si alafo pomegranate wọnni si eti iṣẹti aṣọ igunwa na, yiká li alafo pomegranate wọnni; 26 Ṣaworo kan ati pomegranate kan, ṣaworo kan ati pomegranate kan, yi iṣẹti aṣọ-igunwa na ká lati ma fi ṣiṣẹ alufa; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 27 Nwọn si ṣe ẹ̀wu ọ̀gbọ daradara ti iṣẹ híhun fun Aaroni, ati fun awọn ọmo rẹ̀, 28 Ati fila ọṣọ́ ọ̀gbọ daradara, ati fila ọ̀gbọ didara, ati ṣòkoto ọ̀gbọ olokún wiwẹ, 29 Ati ọjá ọ̀gbọ olokùn wiwẹ́, ati ti aṣọ-alaró, ti elesè-àluko, ati ti ododo, oniṣẹ abẹ́rẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 30 Nwọn si ṣe awo adé mimọ́ na ni kìki wurà, nwọn si kọwe si i, ikọwe bi fifin èdidi-àmi, MIMỌ SI OLUWA. 31 Nwọn si dì ọjá àwọn alaró mọ́ ọ, lati fi dì i loke sara fila na; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 32 Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ agọ́ ti agọ́ ajọ na pari: awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA palaṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe. 33 Nwọn si mú agọ́ na tọ̀ Mose wá, agọ́ na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ikọ́ rẹ̀, apáko rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ati ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ wọnni; 34 Ati ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati ibori awọ seali, ati ikele aṣọ-tita. 35 Apoti ẹrí nì, ati ọpá rẹ̀ wọnni, ati itẹ́-ãnu nì; 36 Tabili na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati àkara ifihàn; 37 Ọpá-fitila mimọ́, pẹlu fitila rẹ̀ wọnni, fitila ti a tò li ẹsẹ̀-ẹsẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati oróro titanna; 38 Ati pẹpẹ wurà, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na; 39 Pẹpẹ idẹ, ati oju-àro-àwọn idẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, agbada na ati ẹsẹ̀ rẹ̀; 40 Aṣọ-tita agbalá na, ọwọ̀n rẹ̀ ati ihò-ìtẹbọ̀ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na, okùn rẹ̀, ati ekàn rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo ìsin agọ́ na, ani agọ́ ajọ; 41 Aṣọ ìsin lati ma fi sìn ninu ibi mimọ́, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa. 42 Gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA fi aṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe gbogbo iṣẹ na. 43 Mose si bojuwò gbogbo iṣẹ na, si kiyesi i, nwọn si ṣe e bi OLUWA ti palaṣẹ, bẹ̃ gẹgẹ ni nwọn ṣe e; Mose si sure fun wọn.

Eksodu 40

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Li ọjọ́ kini oṣù kini ni ki iwọ ki o gbé ibugbé agọ́ na ró. 3 Iwọ o si fi apoti ẹrí nì sinu rẹ̀, iwọ o si ta aṣọ-ikele ni bò apoti na. 4 Iwọ o si gbé tabili wọle, ki o si tò ohun wọnni ti o ni itò si ori rẹ̀; iwọ o si mú ọpá-fitila wọle, iwọ o si tò fitila rẹ̀ wọnni lori rẹ̀. 5 Iwọ o si fi pẹpẹ wurà ti turari nì si iwaju apoti ẹrí, iwọ o si fi aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na sara agọ́ na. 6 Iwọ o si fi pẹpẹ ẹbọsisun nì si iwaju ẹnu-ọ̀na ibugbé agọ́ ajọ. 7 Iwọ o si gbé agbada nì kà agbede-meji agọ́ ajọ ati pẹpẹ, iwọ o si pọn omi sinu rẹ̀. 8 Iwọ o si fà agbalá na yiká, iwọ o si ta aṣọ-isorọ̀ si ẹnu-ọ̀na agbalá na. 9 Iwọ o si mù oróro itasori nì, iwọ o si ta a sara agọ́ na, ati sara ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀: yio si jẹ́ mimọ́. 10 Iwọ o si ta oróro sara pẹpẹ ẹbọsisun, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, iwọ o si yà pẹpẹ na simimọ́: yio si ma jẹ́ pẹpẹ ti o mọ́ julọ. 11 Iwọ o si ta oróro sara agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́. 12 Iwọ o si mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn. 13 Iwọ o si fi aṣọ mimọ́ wọnni wọ̀ Aaroni; iwọ o si ta oróro si i li ori, iwọ o si yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 14 Iwọ o si mú awọn ọmọ rẹ̀ wá, iwọ o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn: 15 Iwọ o si ta oróro si wọn li ori, bi iwọ ti ta si baba wọn li ori, ki nwọn ko le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi: nitoriti itasori wọn yio jẹ́ iṣẹ-alufa lailai nitõtọ, lati irandiran wọn. 16 Bẹ̃ni Mose ṣe: gẹgẹ bi eyiti OLUWA palaṣẹ fun u, bẹ̃li o ṣe. 17 O si ṣe li oṣù kini li ọdún keji ni ijọ́ kini oṣù na, ni a gbé agọ́ na ró. 18 Mose si gbé agọ́ na ró, o si de ihò-ìtẹbọ rẹ̀, o si tò apáko rẹ̀, o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ, o si gbé ọwọ̀n rẹ̀ ró. 19 O si nà aṣọ agọ́ na sori agọ́, o si fi ibori agọ́ na bò o li ori; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 20 O si mú, o si fi ẹrí nì sinu apoti na, o si fi ọpá wọnni sara apoti na, o si fi itẹ́-ãnu nì si oke lori apoti na: 21 O si gbé apoti na wá sinu agọ́, o si ta aṣọ-ikele, o si ta a bò apoti ẹrí; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 22 O si fi tabili nì sinu agọ́ ajọ, ni ìha ariwa agọ́ na, lẹhin ode aṣọ-ikele nì. 23 O si tò àkara na lẹ̀sẹsẹ daradara lori rẹ̀ niwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 24 O si fi ọpá-fitila nì sinu agọ́ ajọ, ki o kọjusi tabili nì ni ìha gusù agọ na. 25 O si tàn fitila wọnni siwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 26 O si fi pẹpẹ wurà nì sinu agọ́ ajọ niwaju aṣọ-ikele nì: 27 O si fi turari didùn joná lori rẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 28 O si ta aṣọ-isorọ̀ nì si ẹnu-ọ̀na agọ́ na. 29 O si fi pẹpẹ ẹbọsisun si ẹnu-ọ̀na ibugbé agọ́ ajọ, o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori rẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 30 O si gbé agbada nì kà agbede-meji agọ́ ajọ ati pẹpẹ, o si pọn omi si i, lati ma fi wẹ̀. 31 Ati Mose ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wẹ̀ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn ninu rẹ̀. 32 Nigbati nwọn ba lọ sinu agọ́ ajọ, ati nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ na, nwọn a wẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 33 O si fà agbalá na yi agọ́ ati pẹpẹ na ká, o si ta aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na. Bẹ̃ni Mose pari iṣẹ na. 34 Nigbana li awọsanma bò agọ́ ajọ, ogo OLUWA si kún inu agọ́ na. 35 Mose kò si le wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, nitoriti awọsanma wà lori rẹ̀, ogo OLUWA si kun inu agọ́ na. 36 Nigbati a si fà awọsanma na soke, kuro lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a ma dide rìn lọ ni ìrin wọn gbogbo: 37 Ṣugbọn bi a kò fà awọsanma na soke, njẹ nwọn kò ni idide rìn titi ọjọ-kọjọ́ ti o ba fà soke. 38 Nitoriti awọsanma OLUWA wà lori agọ́ na li ọsán, iná si wà ninu awọsanma na li oru, li oju gbogbo ile Israeli, ni gbogbo ìrin wọn.

Lefitiku 1

Àwọn Ẹbọ Tí A Sun Lódidi

1 OLUWA si pè Mose, o si sọ fun u lati inu agọ́ ajọ wa, pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikan ninu nyin ba mú ọrẹ-ẹbọ wá fun OLUWA, ki ẹnyin ki o mú ọrẹ-ẹbọ nyin wá ninu ohunọ̀sin, ani ti inu ọwọ́-ẹran, ati ti agbo-ẹran. 3 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ẹbọ sisun ti inu ọwọ́-ẹran, ki on ki o mú akọ wá alailabùku: ki o mú u wá tinutinu rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ siwaju OLUWA. 4 Ki o si fi ọwọ rẹ̀ lé ori ẹbọ sisun na; yio si di itẹwọgbà fun u lati ṣètutu fun u. 5 Ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA: awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, yio si mú ẹ̀jẹ na wá, nwọn o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 6 Ki o si bó ẹbọ sisun na; ki o si kun u. 7 Awọn ọmọ Aaroni alufa ni yio si fi iná sori pẹpẹ na, nwọn o si tò igi lori iná na: 8 Awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si tò ninu rẹ̀, ani ori ati ọrá wọn sori igi ti mbẹ lori iná, ti mbẹ lori pẹpẹ: 9 Ṣugbọn ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀ ni ki o ṣàn ninu omi: ki alufa ki o si sun gbogbo rẹ̀ lori pẹpẹ na lati ṣe ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 10 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ti agbo-ẹran, eyinì ni ti agutan, tabi ti ewurẹ, fun ẹbọ sisun; akọ ni ki o múwa alailabùku. 11 Ki o si pa a niwaju OLUWA li ẹba pẹpẹ ni ìha ariwa: ati awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si bù ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká. 12 Ki o si kun u, ori rẹ̀ ati ọrá rẹ̀: alufa na yio si tò wọn sori igi ti mbẹ lori iná ti mbẹ lori pẹpẹ: 13 Ṣugbọn ki o ṣìn ifun ati itan rẹ̀ ninu omi: ki alufa na ki o si mú gbogbo rẹ̀ wá, ki o si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 14 Bi o ba si ṣepe ti ẹiyẹ ni ẹbọ sisun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA, njẹ ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá ninu àdaba, tabi ninu ọmọ ẹiyẹle. 15 Ki alufa na ki o si mú u wá si pẹpẹ na, ki o si mi i li ọrùn, ki o si sun u lori pẹpẹ na; ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ki o si ro si ẹba pẹpẹ na. 16 Ki o si fà ajẹsi rẹ̀ já pẹlu ẽri rẹ̀, ki o si kó o lọ si ẹba pẹpẹ na ni ìha ìlà-õrùn, lori ibi ẽru nì: 17 Ki o si là a ti on ti iyẹ́-apa rẹ̀, ṣugbọn ki yio pín i ni meji jalẹ: ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ na, lori igi na ti mbẹ lori iná: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

Lefitiku 2

Ẹbọ Ohun Jíjẹ

1 NIGBATI ẹnikan ba si nta ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ fun OLUWA, ki ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ki o jẹ ti iyẹfun daradara; ki o si dà oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀. 2 Ki o si mú u tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni wá: ki alufa si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun na, ati ninu oróro na, pẹlu gbogbo turari rẹ̀; ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀ lori pẹpẹ, lati ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA: 3 Iyokù ti ẹbọ ohunjijẹ na, a si jẹ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ lati inu ẹbọ OLUWA ni ti a fi iná ṣe. 4 Bi iwọ ba si mú ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ wá, ti a yan ninu àro, ki o jẹ́ àkara alaiwu iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, tabi àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si. 5 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ohunjijẹ, ti a ṣe ninu awopẹtẹ, ki o jẹ́ ti iyẹfun didara alaiwu, ti a fi òróró pò. 6 Ki iwọ ki o si dá a kelekele, ki o si dà oróro sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni. 7 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ ba ṣe ẹbọ ohunjijẹ, ti a yan ninu apẹ, iyẹfun didara ni ki a fi ṣe e pẹlu oróro. 8 Ki iwọ ki o si mú ẹbọ ohunjijẹ na wá, ti a fi nkan wọnyi ṣe fun OLUWA: on o si mú u tọ̀ alufa na wá, ki on ki o si mú u wá sori pẹpẹ nì. 9 Alufa yio si mú ẹbọ-iranti ninu ohunjijẹ na, yio si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 10 Eyiti o si kù ninu ẹbọ ohunjijẹ, ki o jẹ́ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ ni, ọrẹ-ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe. 11 A kò gbọdọ fi iwukàra ṣe gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti ẹnyin o mú tọ̀ OLUWA wá: nitori ẹnyin kò gbọdọ sun iwukàra, tabi: oyinkoyin, ninu ọrẹ-ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe. 12 Bi ọrẹ-ẹbọ akọ́so, ẹnyin le mú wọn wá fun OLUWA: ṣugbọn a ki yio sun wọn lori pẹpẹ fun õrùn didùn. 13 Ati gbogbo ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ dùn; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ ki iyọ̀ majẹmu Ọlọrun rẹ ki o má sí ninu ẹbọ ohunjijẹ rẹ: gbogbo ọrẹ-ẹbọ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ si. 14 Bi iwọ ba si mú ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ wá fun OLUWA, ki iwọ ki o si mú ṣiri ọkà daradara ti a yan lori iná wá fun ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ, ọkà gigún, ti ṣiri tutù. 15 Ki iwọ ki o si fi oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni. 16 Ki alufa ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀, apakan ninu ọkà gigún rẹ̀, ati apakan ninu oróro rẹ̀, pẹlu gbogbo turari rẹ̀: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.

Lefitiku 3

Ẹbọ Alaafia

1 BI ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ẹbọ alafia, bi o ba mú u lati inu ọwọ́-ẹran wá, on iba ṣe akọ tabi abo, ki o mú u wá siwaju OLUWA li ailabùku. 2 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ki awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká. 3 Ki o si mú ninu ẹbọ alafia nì wá, ọrẹ-ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun na. 4 Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ́ lara wọn, ti mbẹ li ẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro. 5 Ki awọn ọmọ Aaroni ki o si sun u lori pẹpẹ nì lori ẹbọ sisun, ti mbẹ lori igi ti o wà lori iná: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA. 6 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ fun ọrẹ-ẹbọ alafia si OLUWA ba ṣe ti agbo-ẹran; akọ tabi abo, ki o mú u wá li ailabùku. 7 Bi o ba mu ọdọ-agutan wá fun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA: 8 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká. 9 Ki o si múwa ninu ẹbọ alafia nì, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá rẹ̀, ati gbogbo ìru rẹ̀ ti o lọrá, on ni ki o mú kuro sunmọ egungun ẹhin; ati ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun, 10 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro. 11 Ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni. 12 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ewurẹ, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA: 13 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká. 14 Ki o si mú ninu ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun, 15 Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro. 16 Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe fun õrùn didùn ni: ti OLUWA ni gbogbo ọrá. 17 Ìlana titilai ni fun irandiran nyin, ni gbogbo ibugbé nyin, pe ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ọrá tabi ẹ̀jẹ.

Lefitiku 4

Ẹbọ fún Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Eniyan Bá Ṣèèṣì Dá

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkàn kan ba fi aimọ̀ sẹ̀ si ọkan ninu ofin OLUWA, li ohun ti kò yẹ ni ṣiṣe, ti o si ṣẹ̀ si ọkan ninu wọn: 3 Bi alufa ti a fi oróro yàn ba ṣẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ awọn enia; nigbana ni ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan alailabùku fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti ṣẹ̀. 4 Ki o si mú akọmalu na wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ niwaju OLUWA; ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori akọmalu na, ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA. 5 Ki alufa na ti a fi oróro yàn, ki o bù ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ki o si mú u wá si agọ́ ajọ: 6 Ki alufa na ki o tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ na wọ́n nkan nigba meje niwaju OLUWA, niwaju aṣọ-ikele ibi mimọ́. 7 Ki alufa ki o si fi diẹ ninu ẹ̀jẹ na sara iwo pẹpẹ turari didùn niwaju OLUWA, eyiti mbẹ ninu agọ́ ajọ; ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ akọmalu nì si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun, ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 8 Ki o si mú gbogbo ọrá akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ kuro lara rẹ̀; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun na, 9 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro, 10 Bi a ti mú u kuro lara akọmalu ẹbọ-ọrẹ ẹbọ alafia: ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ ẹbọsisun. 11 Ati awọ akọmalu na, ati gbogbo ẹran rẹ̀, pẹlu ori rẹ̀, ati pẹlu itan rẹ̀, ati ifun rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀, 12 Ani gbogbo akọmalu na ni ki o mú jade lọ sẹhin ibudó si ibi mimọ́ kan, ni ibi ti a ndà ẽru si, ki o si fi iná sun u lori igi: ni ibi ti a ndà ẽru si ni ki a sun u. 13 Bi gbogbo ijọ enia Israeli ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, ti ohun na si pamọ́ li oju ijọ, ti nwọn si ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA, ti a ki ba ṣe, ti nwọn si jẹbi; 14 Nigbati ẹ̀ṣẹ ti nwọn ba ti ṣẹ̀ si i, ba di mimọ̀, nigbana ni ki ijọ enia ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá nitori ẹ̀ṣẹ na, ki nwọn ki o si mú u wá siwaju agọ́ ajọ. 15 Ki awọn àgbagba ijọ enia ki o fi ọwọ́ wọn lé ori akọmalu na niwaju OLUWA: ki a si pa akọmalu na niwaju OLUWA. 16 Ki alufa ti a fi oróro yàn ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na wá si agọ́ ajọ: 17 Ki alufa na ki o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, ki o si wọ́n ọ nigba meje niwaju OLUWA, niwaju aṣọ-ikele. 18 Ki o si fi diẹ ninu ẹ̀jẹ na sara iwo pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ti mbẹ ninu agọ́ ajọ, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun, ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 19 Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ lara rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ. 20 Ki o si fi akọmalu na ṣe; bi o ti fi akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ṣe, bẹ̃ni ki o si fi eyi ṣe: ki alufa na ki o si ṣètutu fun wọn, a o si dari rẹ̀ jì wọn. 21 Ki o si gbé akọmalu na jade lọ sẹhin ibudó, ki o si sun u bi o ti sun akọmalu iṣaju: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni fun ijọ enia. 22 Nigbati ijoye kan ba ṣẹ̀, ti o si fi aimọ̀ rú ọkan ninu ofin OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ti a ki ba rú, ti o si jẹbi; 23 Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ninu eyiti o ti ṣẹ̀, ba di mímọ̀ fun u; ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, akọ alailabùku: 24 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ewurẹ na, ki o si pa a ni ibiti nwọn gbé npa ẹbọ sisun niwaju OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 25 Ki alufa na ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà ẹ̀jẹ si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun. 26 Ki o si sun gbogbo ọrá rẹ̀ li ori pẹpẹ, bi ti ọrá ẹbọ alafia: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i. 27 Bi ọkan ninu awọn enia ilẹ na ba fi aimọ̀ sẹ̀, nigbati o ba ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA ti a ki ba ṣe, ti o si jẹbi; 28 Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀, ba di mimọ̀ fun u, nigbana ni ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, abo alailabùku, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀. 29 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ni ibi ẹbọsisun. 30 Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ rẹ̀ si isalẹ pẹpẹ. 31 Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ kuro, bi a ti imú ọrá kuro ninu ẹbọ ọrẹ-ẹbọ alafia; ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn si OLUWA; ki alufa na ki o si ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i. 32 Bi o ba si mú ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki o si mú u wá, abo alailabùku. 33 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si pa a fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni ibi ti nwọn gbé npa ẹbọ sisun. 34 Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ rẹ̀ si isalẹ pẹpẹ: 35 Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ kuro, bi a ti imú ọrá ọdọ-agutan kuro ninu ẹbọ ọrẹ-ẹbọ alafia; ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ, gẹgẹ bi ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ki alufa ki o si ṣètutu fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.

Lefitiku 5

Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Ó Nílò Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀ṣẹ̀

1 BI ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o si gbọ́ ohùn ibura, ti o si ṣe ẹlẹri, bi on ba ri tabi bi on ba mọ̀, ti kò ba wi, njẹ ki o rù aiṣedede rẹ̀. 2 Tabi bi ẹnikan ba farakàn ohun alaimọ́ kan, iba ṣe okú ẹranko alaimọ́, tabi okú ẹranọ̀sin alaimọ́, tabi okú ohun ti nrakò alaimọ́, ti o ba si pamọ́ fun u, on pẹlu yio si ṣe alaimọ́, yio si jẹbi: 3 Tabi bi o ba farakàn ohun aimọ́ ti enia, ohunkohun aimọ́ ti o wù ki o ṣe ti a fi sọ enia di elẽri, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi: 4 Tabi bi ẹnikan ba bura, ti o nfi ète rẹ̀ sọ ati ṣe ibi, tabi ati ṣe rere, ohunkohun ti o wù ki o ṣe ti enia ba fi ibura sọ, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi: 5 Yio si ṣe, nigbati o ba jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi, ki o jẹwọ pe on ti ṣẹ̀ li ohun na. 6 Ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, abo lati inu agbo-ẹran wá, ọdọ-agutan tabi ọmọ ewurẹ kan, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 7 Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá fun ẹbọ ẹbi fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀; ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun. 8 Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, ẹniti yio tète rubọ eyiti iṣe ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti yio si mi i li ọrùn, ṣugbọn ki yio pín i meji: 9 Ki o si fi ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì wọ́n ìha pẹpẹ; ati ẹ̀jẹ iyokù ni ki a ro si isalẹ pẹpẹ na: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 10 Ki o si ru ekeji li ẹbọ sisun, gẹgẹ bi ìlana na: ki alufa ki o si ṣètutu fun u, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i. 11 Ṣugbọn bi on kò ba le mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá, njẹ ki ẹniti o ṣẹ̀ na ki o mú idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun daradara wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki o máṣe fi oróro si i, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sori rẹ̀: nitoripe ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 12 Nigbana ni ki o mú u tọ̀ alufa wá, ki alufa ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ani ẹbọ-iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ na, gẹgẹ bi ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 13 Ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀ li ọkan ninu wọnyi, a o si dari rẹ̀ jì i: iyokù si jẹ́ ti alufa, bi ẹbọ ohunjijẹ.

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀bi

14 OLUWA si sọ fun Mose pe, 15 Bi ẹnikan ba ṣìṣe, ti o ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀ ninu ohun mimọ́ OLUWA; nigbana ni ki o múwa fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran wá, ni idiyele rẹ nipa ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 16 Ki o si ṣe atunṣe nitori ibi ti o ti ṣe ninu ohun mimọ́, ki o si fi idamarun pẹlu rẹ̀, ki o si fi i fun alufa: alufa yio si fi àgbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i. 17 Bi ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o ba si ṣe ọkan ninu nkan wọnyi, eyiti ofin OLUWA kọ̀ lati ṣe; bi kò tilẹ mọ̀, ṣugbọn o jẹbi, yio si rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 18 Ki o si mú àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran tọ̀ alufa wá ni idiyele rẹ, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori aimọ̀ rẹ̀ ninu eyiti o ṣìṣe ti kò si mọ̀, a o si dari rẹ̀ jì i. 19 Ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni: nitõtọ li o dẹ̀ṣẹ si OLUWA.

Lefitiku 6

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Bi ẹnikan ba ṣẹ̀, ti o dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ti o si sẹ́ fun ẹnikeji rẹ̀, li ohun ti o fi fun u pamọ́, tabi li ohun ti a fi dógo, tabi ohun ti a fi agbara gbà, tabi ti o rẹ ẹnikeji rẹ̀ jẹ; 3 Tabi ti o ri ohun ti o nù he, ti o si ṣeké nitori rẹ̀, ti o si bura eké; li ọkan ninu gbogbo ohun ti enia ṣe, ti o ṣẹ̀ ninu rẹ̀: 4 Yio si ṣe, bi o ba ti ṣẹ̀, ti o si jẹbi, ki o si mú ohun ti o fi agbara gbà pada, tabi ohun ti o fi irẹjẹ ní, tabi ohun ti a fi fun u pamọ́, tabi ohun ti o nù ti o rihe. 5 Tabi gbogbo eyi na nipa eyiti o bura eké; ki o tilẹ mú u pada li oju-owo rẹ̀, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si fi i fun olohun, li ọjọ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 6 Ki o si mú ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wá fun OLUWA, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran tọ̀ alufa wá, ni idiyele rẹ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: 7 Alufa yio si ṣètutu fun u niwaju OLUWA, a o si dari rẹ̀ jì; nitori ohunkohun ninu gbogbo ohun eyiti o ti ṣe ti o si jẹbi ninu rẹ̀.

Ẹbọ Sísun Lódidi

8 OLUWA si sọ fun Mose pe, 9 Paṣẹ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ sisun: Ẹbọ sisun ni, nitori sisun rẹ̀ lori pẹpẹ ni gbogbo oru titi di owurọ̀, iná pẹpẹ na yio si ma jò ninu rẹ̀. 10 Ki alufa ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ rẹ̀ wọ̀, ati ṣòkoto ọ̀gbọ rẹ̀ nì ki o fi si ara rẹ̀, ki o si kó ẽru ti iná jọ, ti on ti ẹbọ sisun lori pẹpẹ, ki o si fi i si ìha pẹpẹ. 11 Ki o si bọ́ ẹ̀wu rẹ̀ silẹ, ki o si mú ẹ̀wu miran wọ̀, ki o si gbé ẽru wọnni jade lọ sẹhin ibudó si ibi kan ti o mọ́. 12 Ki iná ori pẹpẹ nì ki o si ma jó lori rẹ̀; ki a máṣe pa a; ki alufa ki o si ma kòná igi lori rẹ̀ li orowurọ̀, ki o si tò ẹbọ sisun sori rẹ̀; ki o si ma sun ọrá ẹbọ alafia lori rẹ̀. 13 Ki iná ki o ma jó titi lori pẹpẹ na; kò gbọdọ kú lai.

Ẹbọ Ohun Jíjẹ

14 Eyi si li ofin ẹbọ ohunjijẹ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o ru u niwaju OLUWA, niwaju pẹpẹ. 15 Ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun didara ẹbọ ohunjijẹ na, ati ti oróro rẹ̀, ati gbogbo turari ti mbẹ lori ẹbọ ohunjijẹ, ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn, ani fun iranti rẹ̀, si OLUWA. 16 Iyokù rẹ̀ ni Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio jẹ: àkara alaiwu ni, ki a jẹ ẹ ni ibi mimọ́; ni agbalá agọ́ ajọ ni ki nwọn ki o jẹ ẹ. 17 Ki a máṣe fi iwukàra yan a. Mo ti fi i fun wọn ni ipín ti wọn ninu ẹbọ mi ti a fi iná ṣe; mimọ́ julọ ni, bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ ẹbi. 18 Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn ọmọ Aaroni ni ki o jẹ ninu rẹ̀, yio jasi aṣẹ titilai ni iraniran nyin, nipa ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: ẹnikẹni ti o ba kàn wọn yio di mimọ́. 19 OLUWA si sọ fun Mose pe, 20 Eyi li ọrẹ-ẹbọ Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn o ru si OLUWA, li ọjọ́ ti a fi oróro yàn a; idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ titilai, àbọ rẹ̀ li owurọ̀, ati àbọ rẹ̀ li alẹ. 21 Ninu awopẹtẹ ni ki a fi oróro ṣe e; nigbati a ba si bọ̀ ọ, ki iwọ ki o si mú u wọ̀ ile: ati ìṣu yiyan ẹbọ ohunjijẹ na ni ki iwọ ki o fi rubọ õrùn didùn si OLUWA. 22 Ati alufa ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti a fi oróro yàn ni ipò rẹ̀ ni ki o ru u: aṣẹ titilai ni fun OLUWA, sisun ni ki a sun u patapata. 23 Nitori gbogbo ẹbọ ohunjijẹ alufa, sisun ni ki a sun u patapata: a kò gbọdọ jẹ ẹ.

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀ṣẹ̀

24 OLUWA si sọ fun Mose pe, 25 Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ni ibi ti a gbé pa ẹbọ sisun, ni ki a si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ niwaju OLUWA: mimọ́ julọ ni. 26 Alufa ti o ru u fun ẹ̀ṣẹ ni ki o jẹ ẹ: ni ibi mimọ́ kan ni ki a jẹ ẹ, ninu agbalá agọ́ ajọ. 27 Ohunkohun ti o ba kàn ẹran rẹ̀ yio di mimọ́: nigbati ẹ̀jẹ rẹ̀ ba si ta sara aṣọ kan, ki iwọ ki o si fọ̀ eyiti o ta si na ni ibi mimọ́ kan. 28 Ṣugbọn ohunèlo àmọ, ninu eyiti a gbé bọ̀ ọ on ni ki a fọ́; bi a ba si bọ̀ ọ ninu ìkoko idẹ, ki a si fọ̀ ọ, ki a si ṣìn i ninu omi. 29 Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: mimọ́ julọ ni. 30 Kò si sí ẹbọ ẹ̀ṣẹ kan, ẹ̀jẹ eyiti a múwa sinu agọ́ ajọ, lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ti a gbọdọ jẹ: sisun ni ki a sun u ninu iná.

Lefitiku 7

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀bi

1 EYI si li ofin ẹbọ ẹbi: mimọ́ julọ ni. 2 Ni ibi ti nwọn gbé pa ẹbọ sisun ni ki nwọn ki o pa ẹbọ ẹbi: ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ yiká. 3 Ki o si fi gbogbo ọrá inu rẹ̀ rubọ; ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati ọrá ti o bò ifun lori, 4 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro: 5 Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹbi ni. 6 Gbogbo ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: ni ibi mimọ́ kan ki a jẹ ẹ: mimọ́ julọ ni. 7 Bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ si li ẹbọ ẹbi: ofin kan ni fun wọn: alufa ti nfi i ṣètutu ni ki on ní i. 8 Ati alufa ti nru ẹbọ sisun ẹnikẹni, ani alufa na ni yio ní awọ ẹran ẹbọ sisun, ti o ru fun ara rẹ̀. 9 Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a yan ninu àro, ati gbogbo eyiti a yan ninu apẹ, ati ninu awopẹtẹ, ni ki o jẹ́ ti alufa ti o ru u. 10 Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a fi oróro pò, ati gbigbẹ, ni ki gbogbo awọn ọmọ Aaroni ki o ní, ẹnikan bi ẹnikeji rẹ̀.

Ẹbọ Alaafia

11 Eyi si ni ofin ẹbọ alafia, ti on o ru si OLUWA. 12 Bi o ba mú u wá fun idupẹ́, njẹ ki o mú adidùn àkara alaiwu wá ti a fi oróro pò, pẹlu ẹbọ ọpẹ́ rẹ̀, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati adidùn àkara iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, ti a din. 13 Pẹlu adidùn àkara wiwu ki o mú ọrẹ-ẹbọ pẹlu ẹbọ alafia rẹ̀ wa fun idupẹ́. 14 Ati ninu rẹ̀ ni ki o mú ọkan kuro ninu gbogbo ọrẹ-ẹbọ na fun ẹbọ agbesọsoke si OLUWA; ki o si jẹ́ ti alufa ti o nwọ́n ẹ̀jẹ ẹbọ alafia. 15 Ati ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ fun idupẹ́, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti a fi rubọ; ki o máṣe kù ninu rẹ̀ silẹ titi di owurọ̀. 16 Ṣugbọn bi ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ ba ṣe ti ẹjẹ́, tabi ọrẹ-ẹbọ atinuwá, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti o ru ẹbọ rẹ̀: ati ni ijọ́ keji ni ki a jẹ iyokù rẹ̀ pẹlu: 17 Ṣugbọn iyokù ninu ẹran ẹbọ na ni ijọ́ kẹta ni ki a fi iná sun. 18 Bi a ba si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, ki yio dà, bẹ̃li a ki yio kà a si fun ẹniti o ru u: irira ni yio jasi, ọkàn ti o ba si jẹ ẹ yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 19 Ẹran ti o ba si kàn ohun aimọ́ kan, a kò gbọdọ jẹ ẹ; sisun ni ki a fi iná sun u. Ṣugbọn ẹran na ni, gbogbo ẹniti o mọ́ ni ki o jẹ ninu rẹ̀. 20 Ṣugbọn ọkàn na ti o ba jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ti on ti ohun aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 21 Pẹlupẹlu ọkàn na ti o ba fọwọkàn ohun aimọ́ kan, bi aimọ́ enia, tabi ẹranko alaimọ́, tabi ohun irira elẽri, ti o si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 22 OLUWA si sọ fun Mose pe, 23 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ọrákọra akọmalu, tabi ti agutan, tabi ti ewurẹ. 24 Ati ọrá ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, ati ọrá eyiti ẹranko fàya, on ni ki a ma lò ni ilò miran: ṣugbọn ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ. 25 Nitoripe ẹnikẹni ti o ba jẹ ọrá ẹran, ninu eyiti enia mú rubọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ani ọkàn ti o ba jẹ ẹ on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 26 Pẹlupẹlu ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, iba ṣe ti ẹiyẹ tabi ti ẹran, ninu ibugbé nyin gbogbo. 27 Ọkànkọkàn ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 28 OLUWA si sọ fun Mose pe, 29 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹniti o ba ru ẹbọ alafia rẹ̀ si OLUWA, ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ tọ̀ OLUWA wá ninu ẹbọ alafia rẹ̀: 30 Ọwọ́ on tikara rẹ̀ ni ki o fi mú ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe wá; ọrá pẹlu igẹ̀ rẹ̀, on ni ki o múwa, ki a le fì igẹ̀ na li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. 31 Ki alufa na ki o sun ọrá na lori pẹpẹ: ṣugbọn ki igẹ̀ na ki o jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀. 32 Itan ọtún ni ki ẹnyin ki o fi fun alufa, fun ẹbọ agbesọsoke ninu ẹbọ alafia nyin. 33 Ninu awọn ọmọ Aaroni ẹniti o rubọ ẹ̀jẹ ẹbọ alafia, ati ọrá, ni ki o ní itan ọtun fun ipín tirẹ̀. 34 Nitoripe igẹ̀ fifì ati itan agbeṣọsoke, ni mo gbà lọwọ awọn ọmọ Israeli ninu ẹbọ alafia wọn, mo si fi wọn fun Aaroni alufa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa ìlana titilai, lati inu awọn ọmọ Israeli. 35 Eyi ni ipín Aaroni, ati ìpín awọn ọmọ rẹ̀, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, li ọjọ́ na ti o mú wọn wá lati ṣe alufa OLUWA; 36 Ti OLUWA palaṣẹ lati fi fun wọn lati inu awọn ọmọ Israeli, li ọjọ́ ti o fi oróro yàn wọn. Ìlana lailai ni iraniran wọn. 37 Eyi li ofin ẹbọ sisun, ti ẹbọ ohunjijẹ, ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ti ẹbọ ẹbi, ati ti ìyasimimọ́, ati ti ẹbọ alafia; 38 Ti OLUWA palaṣẹ fun Mose li òke Sinai, li ọjọ́ ti o paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá fun OLUWA ni ijù Sinai.

Lefitiku 8

Ìyàsímímọ́ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati ẹ̀wu wọnni, ati oróro itasori, ati akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo meji, ati agbọ̀n àkara alaiwu kan; 3 Ki iwọ ki o si pè gbogbo ijọ enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 4 Mose si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u; a si pe awọn enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 5 Mose si wi fun ijọ enia pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ lati ṣe. 6 Mose si mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wá, o si fi omi wẹ̀ wọn. 7 O si wọ̀ ọ li ẹ̀wu, o si fi amure dì i, o si fi aṣọ igunwa wọ̀ ọ, o si wọ̀ ọ li ẹ̀wu-efodi, o si fi onirũru-ọ̀na ọjá ẹ̀wu-efodi dì i, o si fi gbà a li ọjá. 8 O si dì igbàiya mọ́ ọ; o si fi Urimu ati Tummimu sinu igbàiya na. 9 O si fi fila dé e li ori; ati lara fila na pẹlu, ani niwaju rẹ̀, li o fi awo wurà na si, adé mimọ́ nì; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 10 Mose si mú oróro itasori, o si ta a sara agọ́, ati sara ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, o si yà wọn simimọ́. 11 O si mú ninu rẹ̀ fi wọ́n ori pẹpẹ nigba meje, o si ta a sara pẹpẹ na, ati si gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, lati yà wọn simimọ́. 12 O si dà ninu oróro itasori si ori Aaroni, o si ta a si i lara, lati yà a simimọ́. 13 Mose si mú awọn ọmọ Aaroni wá, o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn, o si fi amure di wọn, o si fi fila dé wọn li ori; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 14 O si mú akọmalu wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ fọwọ́ wọn lé ori akọmalu na fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 15 O si pa a; Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si fi iká rẹ̀ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na yiká, o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ, o si yà a simimọ́, lati ṣètutu fun u. 16 O si mú gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, Mose si sun u lori pẹpẹ. 17 Ṣugbọn akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀, on li o fi iná sun lẹhin ibudó; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 18 O si mú àgbo ẹbọ sisun wá: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na. 19 O si pa a: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká. 20 O si kun àgbo na; Mose si sun ori rẹ̀, ati ara rẹ̀, ati ọrá na. 21 O si ṣìn ifun rẹ̀ ati itan rẹ̀ ninu omi; Mose si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ: ẹbọ sisun fun õrùn didùn ni: ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 22 O si mú àgbo keji wá, àgbo ìyasimimọ́: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na. 23 O si pa a; Mose si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀. 24 O si mú awọn ọmọ Aaroni wá, Mose si tọ́ ninu ẹ̀jẹ na si eti ọtún wọn, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká. 25 O si mú ọrá na, ati ìru ti o lọrá, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, ati itan ọtún: 26 Ati lati inu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA, o mú adidùn àkara alaiwu kan, ati adidùn àkara oloróro kan, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan, o si fi wọn sori ọrá nì, ati si itan ọtún na: 27 O si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni li ọwọ́, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀, o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. 28 Mose si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si sun wọn lori pẹpẹ li ẹbọ sisun: ìyasimimọ́ ni nwọn fun õrùn didùn: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. 29 Mose si mú igẹ̀ ẹran na, o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: nitori ipín ti Mose ni ninu àgbo ìyasimimọ́; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 30 Mose si mú ninu oróro itasori nì, ati ninu ẹ̀jẹ ti mbẹ lori pẹpẹ, o si fi i wọ́n ara Aaroni, ati ara aṣọ rẹ̀ wọnni, ati ara awọn ọmọ rẹ̀, ati ara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; o si yà Aaroni simimọ́, ati aṣọ rẹ̀ wọnni, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀. 31 Mose si wi fun Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ bọ̀ ẹran na li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin si jẹ ẹ pẹlu àkara nì ti mbẹ ninu agbọ̀n ìyasimimọ́, bi mo ti fi aṣẹ lelẹ wipe, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ni ki o jẹ ẹ. 32 Eyiti o ba si kù ninu ẹran na ati ninu àkara na ni ki ẹnyin ki o fi iná sun. 33 Ki ẹnyin ki o máṣe jade si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ni ijọ́ meje, titi ọjọ́ ìyasimimọ́ nyin yio fi pé; nitori ijọ́ meje ni a o fi yà nyin simimọ́. 34 Bi o ti ṣe li oni yi, bẹ̃li OLUWA fi aṣẹ lelẹ lati ṣe, lati ṣètutu fun nyin. 35 Nitorina ni ki ẹnyin ki o joko nibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, li ọsán ati li oru ni ijọ́ meje, ki ẹnyin ki o si ma pa aṣẹ OLUWA mọ́, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi. 36 Bẹ̃li Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo ti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ lati ọwọ́ Mose wá.

Lefitiku 9

Aaroni Rúbọ sí OLUWA

1 O si ṣe ni ijọ́ kẹjọ, ni Mose pè Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn àgba Israeli; 2 O si wi fun Aaroni pe, Mú ọmọ akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan alailabùku fun ẹbọ sisun, ki o fi wọn rubọ niwaju OLUWA. 3 Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ mú obukọ kan wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ati ọmọ malu kan, ati ọdọ-agutan kan, mejeji ọlọdún kan, alailabùku, fun ẹbọ sisun; 4 Ati akọmalu kan ati àgbo kan fun ẹbọ alafia, lati fi ru ẹbọ niwaju OLUWA; ati ẹbọ ohunjijẹ ti a fi oróro pò: nitoripe li oni li OLUWA yio farahàn nyin. 5 Nwọn si mú ohun ti Mose filelẹ li aṣẹ́ wá siwaju agọ́ ajọ: gbogbo ijọ si sunmọtosi nwọn si duro niwaju OLUWA. 6 Mose si wipe, Eyi li ohun ti OLUWA filelẹ li aṣẹ, ki ẹnyin ki o ṣe: ogo OLUWA yio si farahàn nyin. 7 Mose si sọ fun Aaroni pe, Sunmọ pẹpẹ, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati ẹbọ sisun rẹ, ki o si ṣètutu fun ara rẹ, ati fun awọn enia: ki o si ru ọrẹ-ẹbọ awọn enia, ki o si ṣètutu fun wọn; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ. 8 Aaroni si sunmọ pẹpẹ, o si pa ọmọ malu ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikalarẹ̀. 9 Awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá: o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, o si tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ: 10 Ṣugbọn ọrá, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, o sun u lori pẹpẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 11 Ati ẹran ati awọ li o fi iná sun lẹhin ibudó. 12 O si pa ẹbọ sisun: awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. 13 Nwọn si mú ẹbọ sisun tọ̀ ọ wá, ti on ti ipín rẹ̀, ati ori: o si sun wọn lori pẹpẹ. 14 O si ṣìn ifun ati itan rẹ̀, o si sun wọn li ẹbọ sisun lori pẹpẹ. 15 O si mú ọrẹ-ẹbọ awọn enia wá, o si mú obukọ, ti iṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, o si pa a, o si fi i rubọ ẹ̀ṣẹ, bi ti iṣaju. 16 O si mú ẹbọ sisun wá, o si ru u gẹgẹ bi ìlana na. 17 O si mú ẹbọ ohunjijẹ wá, o si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, o si sun u lori pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀. 18 O si pa akọmalu ati àgbo fun ẹbọ alafia, ti iṣe ti awọn enia; awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. 19 Ati ọrá inu akọmalu na ati ti inu àgbo na, ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati eyiti o bò ifun, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ: 20 Nwọn si fi ọrá na lé ori igẹ̀ wọnni, o si sun ọrà na lori pẹpẹ. 21 Ati igẹ̀ na ati itan ọtún ni Aaroni fì li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; bi Mose ti fi aṣẹ lelẹ. 22 Aaroni si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke si awọn enia, o si sure fun wọn; o si sọkalẹ kuro ni ibi irubọ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia. 23 Mose ati Aaroni si wọ̀ inu agọ́ ajọ, nwọn si jade, nwọn si sure fun awọn enia: ogo OLUWA si farahàn fun gbogbo enia. 24 Iná kan si ti ọdọ OLUWA jade wá, o si jó ẹbọ sisun ati ọrá ori pẹpẹ na; nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn hó kùhu, nwọn si dojubolẹ.

Lefitiku 10

Ẹ̀ṣẹ̀ Nadabu ati Abihu

1 ATI Nadabu ati Abihu, awọn ọmọ Aaroni, olukuluku nwọn mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari sori wọn, nwọn si mú ajeji iná wá siwaju OLUWA, ti on kò fi aṣẹ fun wọn. 2 Iná si ti ọdọ OLUWA jade, o si run wọn, nwọn si kú niwaju OLUWA. 3 Nigbana ni Mose wi fun Aaroni pe, Eyiyi li OLUWA wipe, A o yà mi simimọ́ ninu awọn ti nsunmọ mi, ati niwaju awọn enia gbogbo li a o yìn mi li ogo. Aaroni si dakẹ. 4 Mose si pé Miṣaeli ati Elsafani, awọn ọmọ Usieli arakunrin Aaroni, o si wi fun wọn pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ gbé awọn arakunrin nyin kuro niwaju ibi mimọ́ jade sẹhin ibudó. 5 Bẹ̃ni nwọn sunmọ ibẹ̀, nwọn si gbé ti awọn ti ẹ̀wu wọn jade sẹhin ibudó; bi Mose ti wi. 6 Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ máṣe ṣi ibori nyin, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fà aṣọ nyin ya; ki ẹnyin ki o má ba kú, ati ki ibinu ki o má ba wá sori gbogbo ijọ: ṣugbọn ki awọn arakunrin nyin, gbogbo ile Israeli ki o sọkun ijóna ti OLUWA ṣe yi. 7 Ki ẹnyin ki o má si ṣe jade kuro lati ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe oróro itasori OLUWA mbẹ lara nyin. Nwọn si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose.

Òfin fún Àwọn Àlùfáàa

8 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, 9 Máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, iwọ, tabi awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nigbati ẹnyin ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: ìlana ni titilai ni iraniran nyin: 10 Ki ẹnyin ki o le ma fi ìyatọ sãrin mimọ́ ati aimọ́, ati sãrin ẽri ati ailẽri; 11 Ati ki ẹnyin ki o le ma kọ́ awọn ọmọ Israeli ni gbogbo ìlana ti OLUWA ti sọ fun wọn lati ọwọ́ Mose wá. 12 Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ ti o kù pe, Ẹ mú ẹbọ ohunjijẹ ti o kù ninu ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe, ki ẹ si jẹ ẹ lainí iwukàra lẹba pẹpẹ: nitoripe mimọ́ julọ ni: 13 Ki ẹnyin ki o si jẹ ẹ ni ibi mimọ́, nitoripe ipín tirẹ, ati ipín awọn ọmọ rẹ ni, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: nitoripe, bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi. 14 Ati igẹ̀ fifì, ati itan agbesọsoke ni ki ẹnyin ki o jẹ ni ibi mimọ́ kan; iwọ, ati awọn ọmọkunrin rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ pẹlu rẹ: nitoripe ipín tirẹ ni, ati ipín awọn ọmọ rẹ, ti a fi fun nyin ninu ẹbọ alafia awọn ọmọ Israeli. 15 Itan agbesọsoke ati igẹ̀ fifì ni ki nwọn ki o ma múwa pẹlu ẹbọ ti a fi iná ṣe ti ọrá, lati fì i fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA: yio si ma jẹ́ tirẹ, ati ti awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nipa ìlana titilai; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ. 16 Mose si fi pẹlẹpẹlẹ wá ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, si kiyesi i, a ti sun u: o si binu si Eleasari ati Itamari, awọn ọmọ Aaroni ti o kù, wipe, 17 Nitori kini ẹnyin kò ṣe jẹ ẹbọ èṣẹ na ni ibi mimọ́, nitoripe mimọ́ julọ ni, a si ti fi fun nyin lati rù ẹ̀ṣẹ ijọ enia, lati ṣètutu fun wọn niwaju OLUWA? 18 Kiyesi i, a kò mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu ibi mimọ́: ẹnyin iba ti jẹ ẹ nitõtọ ni ibi mimọ́, bi mo ti paṣẹ. 19 Aaroni si wi fun Mose pe, Kiyesi i, li oni ni nwọn ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn ati ẹbọ sisun wọn niwaju OLUWA; irú nkan wọnyi li o si ṣubulù mi: emi iba si ti jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ li oni, o ha le dara li oju OLUWA? 20 Nigbati Mose gbọ́ eyi inu rẹ̀ si tutù.

Lefitiku 11

Àwọn Ẹranko Tí Ó Tọ̀nà láti Jẹ

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni, o wi fun wọn pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ ninu gbogbo ẹran ti mbẹ lori ilẹ aiye. 3 Ohunkohun ti o ba yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là li ẹsẹ̀, ti o si njẹ apọjẹ, ninu ẹran, on ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 4 Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹ máṣe jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi awọn ti o si yà bàta-ẹsẹ̀: bi ibakasiẹ, nitoriti o njẹ apọjẹ ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin. 5 Ati gara, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin. 6 Ati ehoro, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin. 7 Ati ẹlẹdẹ̀, bi o ti yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là ẹsẹ̀, ṣugbọn on kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin. 8 Ninu ẹran wọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ, okú wọn li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn; alaimọ́ ni nwọn jasi fun nyin. 9 Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti mbẹ ninu omi: ohunkohun ti o ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, ninu okun, ati ninu odò, awọn ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 10 Ati gbogbo eyiti kò ní lẹbẹ ati ipẹ́ li okun, ati li odò, ninu gbogbo ohun ti nrá ninu omi, ati ninu ohun alãye kan ti mbẹ ninu omi, irira ni nwọn o jasi fun nyin, 11 Ani irira ni nwọn o ma jẹ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, okú wọn ni ẹ o sì kàsi irira. 12 Ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun. 13 Wọnyi li ẹnyin o si ma kàsi irira ninu ẹiyẹ; awọn li a kò gbọdọ jẹ, irira ni nwọn iṣe: idì, ati aṣá-idì, ati idì-ẹja. 14 Ati igún, ati aṣá li onirũru rẹ̀; 15 Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀; 16 Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀, 17 Ati òyo ati ìgo, ati owiwi; 18 Ati ogbugbu, ati ofù, ati àkala; 19 Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán. 20 Gbogbo ohun ti nrakò, ti nfò ti o si nfi mẹrẹrin rìn ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin. 21 Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti nfò, ti nrakò, ti nfi gbogbo mẹrẹrin rìn, ti o ní tete lori ẹsẹ̀ wọn, lati ma fi ta lori ilẹ; 22 Ani ninu wọnyi ni ki ẹnyin ma jẹ; eṣú ni irú rẹ̀, ati eṣú onihoho nipa irú rẹ̀, ati ọbọnbọn nipa irú rẹ̀, ati ẹlẹnga nipa irú rẹ̀. 23 Ṣugbọn gbogbo ohun iyokù ti nfò ti nrakò, ti o ní ẹsẹ̀ mẹrin, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin. 24 Nitori wọnyi li ẹnyin o si jẹ́ alaimọ́: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: 25 Ẹnikẹni ti o ba si rù ohun kan ninu okú wọn ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 26 Ẹranko gbogbo ti o yà bàta-ẹsẹ̀, ti kò si là ẹsẹ̀, tabi ti kò si jẹ apọjẹ, ki o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: gbogbo ẹniti o ba farakàn wọn ki o jẹ́ alaimọ́. 27 Ati ohunkohun ti o ba si nrìn lori ẽkanna rẹ̀, ninu gbogbo onirũru ẹranko, ti nfi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rìn, alaimọ́ ni nwọn fun nyin: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 28 Ẹniti o ba si rù okú wọn ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: alaimọ́ ni nwọn fun nyin. 29 Wọnyi ni yio si jasi alaimọ́ fun nyin ninu ohun ti nrakò lori ilẹ; ase, ati eku, ati awun nipa irú rẹ̀. 30 Ati ọmọ̃le, ati ahanhan, ati alãmu, ati agiliti, ati agẹmọ. 31 Wọnyi li alaimọ́ fun nyin ninu gbogbo ohun ti nrakò: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 32 Ati lara ohunkohun ti okú wọn ba ṣubulù, ki o jasi alaimọ́; ibaṣe ohun èlo-igi, tabi aṣọ, tabi awọ, tabi àpo, ohunèlo ti o wù ki o ṣe, ninu eyiti a nṣe iṣẹ kan, a kò gbọdọ má fi bọ̀ inu omi, on o si jasi alaimọ́ titi di aṣalẹ; bẹ̃li a o si sọ ọ di mimọ́. 33 Ati gbogbo ohunèlo amọ̀, ninu eyiti ọkan ninu okú nwọn ba bọ́ si, ohunkohun ti o wù ki o wà ninu rẹ̀ yio di alaimọ́, ki ẹnyin ki o si fọ́ ọ. 34 Ninu onjẹ gbogbo ti a o ba jẹ, ti irú omi nì ba dà si, yio di alaimọ́: ati ohun mimu gbogbo ti a o ba mu ninu irú ohunèlo na yio di alaimọ́. 35 Ati ohunkohun lara eyiti ninu okú wọn ba ṣubulù, yio di alaimọ́; iba ṣe àro, tabí idana, wiwó ni ki a wó wọn lulẹ: alaimọ́ ni nwọn, nwọn o si jẹ́ alaimọ́ fun nyin. 36 Ṣugbọn orisun tabi kanga kan, ninu eyiti omi pupọ̀ gbé wà, yio jẹ́ mimọ́: ṣugbọn eyiti o ba kàn okú wọn yio jẹ́ alaimọ́. 37 Bi ninu okú wọn ba bọ́ sara irugbìn kan ti iṣe gbigbìn, yio jẹ́ mimọ́. 38 Ṣugbọn bi a ba dà omi sara irugbìn na, ti ninu okú wọn ba si bọ́ sinu rẹ̀, yio si jẹ́ alaimọ́ fun nyin. 39 Ati bi ẹran kan, ninu eyiti ẹnyin ba ma jẹ, ba kú; ẹniti o ba farakàn okú rẹ̀ yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 40 Ẹniti o ba si jẹ ninu okú rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ẹniti o ba si rù okú rẹ̀ ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 41 Ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ yio jasi irira; a ki yio jẹ ẹ. 42 Ohunkohun ti nfi inu wọ́, ati ohunkohun ti nfi mẹrẹrin rìn, ati ohunkohun ti o ba ní ẹsẹ̀ pupọ̀, ani ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, awọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; nitoripe irira ni nwọn. 43 Ẹnyin kò gbọdọ fi ohun kan ti nrakò, sọ ara nyin di irira, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi wọn sọ ara nyin di alaimọ́ ti ẹnyin o fi ti ipa wọn di elẽri. 44 Nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin: nitorina ni ki ẹnyin ki o yà ara nyin si mimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́; nitoripe mimọ́ li Emi: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi ohunkohun ti nrakò sọ ara nyin di elẽri. 45 Nitoripe Emi li OLUWA ti o mú nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: nitorina ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́, nitoripe mimọ́ li Emi. 46 Eyiyi li ofin ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ẹda gbogbo alãye ti nrá ninu omi, ati ti ẹda gbogbo ti nrakò lori ilẹ: 47 Lati fi iyatọ sãrin aimọ́ ati mimọ́, ati sãrin ohun alãye ti a ba ma jẹ, ati ohun alãye ti a ki ba jẹ.

Lefitiku 12

Ìwẹ̀nùmọ́ Àwọn Obinrin Lẹ́yìn Ìbímọ

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi obinrin kan ba lóyun, ti o si bi ọmọkunrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; gẹgẹ bi ọjọ́ ìyasọtọ fun ailera rẹ̀ ni ki o jẹ́ alaimọ́. 3 Ni ijọ́ kẹjọ ni ki a si kọ ọmọkunrin na nilà. 4 Ki obinrin na ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọjọ́ mẹtalelọgbọ̀n; ki o máṣe fọwọkàn ohun mimọ́ kan, bẹ̃ni ki o máṣe lọ sinu ibi mimọ́, titi ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ yio fi pé. 5 Ṣugbọn bi o ba bi ọmọbinrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ li ọsẹ̀ meji, bi ti inu ìyasọtọ rẹ̀: ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọgọta ọjọ́ o le mẹfa. 6 Nigbati ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ ba pé, fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, ki o mú ọdọ-agutan ọlọdún kan wá fun ẹbọ sisun, ati ẹiyẹle, tabi àdaba, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ ajọ: 7 Ẹniti yio ru u niwaju OLUWA, ti yio si ṣètutu fun u; on o si di mimọ́ kuro ninu isun ẹ̀jẹ rẹ̀. Eyi li ofin fun ẹniti o bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin. 8 Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá; ọkan fun ẹbọ sisun, ati ekeji fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: alufa yio si ṣètutu fun u, on o si di mimọ́.

Lefitiku 13

Àwọn Òfin tí ó Jẹmọ́ Àrùn Ara

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 2 Nigbati enia kan ba ní iwú, apá, tabi àmi didán kan li awọ ara rẹ̀, ti o si mbẹ li awọ ara rẹ̀ bi àrun ẹ̀tẹ; nigbana ni ki a mú u tọ̀ Aaroni alufa wá, tabi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀, alufa: 3 Alufa yio si wò àrun ti mbẹ li awọ ara rẹ̀: bi irun ti mbẹ li oju àrun na ba si di funfun, ati ti àrun na li oju rẹ̀ ba jìn jù awọ ara rẹ̀ lọ, àrun ẹ̀tẹ ni: ki alufa ki o si wò o, ki o si pè e li alaimọ́. 4 Bi àmi didán na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ati li oju rẹ̀ ti kò si jìn jù awọ lọ, ti irun rẹ̀ kò di funfun, nigbana ni ki alufa ki o sé alarun na mọ́ ni ijọ́ meje: 5 Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba duro li oju rẹ̀, ti àrun na kò ba si ràn li ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje si i: 6 Ki alufa ki o si tun wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba ṣe bi ẹni wodú, ti àrun na kò si ràn si i li awọ ara, ki alufa ki o pè e ni mimọ́: kìki apá ni: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o jẹ́ mimọ́. 7 Ṣugbọn bi apá na ba ràn pupọ̀ si i li awọ ara, lẹhin igbati alufa ti ri i tán fun mimọ́ rẹ̀, alufa yio si tun wò o. 8 Alufa yio wò o, kiyesi i, apá na ràn li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ẹ̀tẹ ni. 9 Nigbati àrun ẹ̀tẹ ba mbẹ li ara enia, nigbana ni ki a mú u tọ̀ alufa wá; 10 Ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi iwú na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ti o si sọ irun rẹ̀ di funfun, ti õju si mbẹ ninu iwú na, 11 Ẹ̀tẹ lailai ni li awọ ara rẹ̀, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ki o máṣe sé e mọ́; nitoripe alaimọ́ ni. 12 Bi ẹ̀tẹ ba si sọ jade kakiri li awọ ara, ti ẹ̀tẹ na ba si bò gbogbo ara ẹniti o ní àrun na, lati ori rẹ̀ titi dé ẹsẹ̀ rẹ̀, nibikibi ti alufa ba wò; 13 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi ẹ̀tẹ na ba bò gbogbo ara rẹ̀, ki o pè àlarun na ni mimọ́; gbogbo rẹ̀ di funfun: mimọ́ li on. 14 Ṣugbọn ni ijọ́ ti õju na ba hàn ninu rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́. 15 Ki alufa ki o wò õju na, ki o si pè e li alaimọ́: nitoripe aimọ́ li õju: ẹ̀tẹ ni. 16 Tabi bi õju na ba yipada, ti o si di funfun, ki o si tọ̀ alufa wá, 17 Alufa yio si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba di funfun, nigbana ni ki alufa ki o pè àlarun na ni mimọ́: mimọ́ li on. 18 Ara pẹlu, ninu eyi, ani li awọ ara ti õwo ti sọ, ti o si jiná, 19 Ati ni apá õwo na bi iwú funfun ba mbẹ nibẹ̀, tabi àmi didán, funfun ti o si ṣe bi ẹni pọ́n ki a si fi i hàn alufa; 20 Alufa yio wò o, si kiyesi i, li oju rẹ̀ bi o ba jìn jù awọ ara lọ, ti irun rẹ̀ si di funfun, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu õwo na. 21 Ṣugbọn bi alufa na ba wò o, si kiyesi i, ti irun funfun kò si sí ninu rẹ̀, bi kò ba si jìn jù awọ ara lọ, ti o si dabi ẹni wodú, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje: 22 Bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ni. 23 Ṣugbọn bi àmi didán na ba duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn, õwo tita ni; ki alufa ki o si pè e ni mimọ́. 24 Tabi bi ara kan ba mbẹ, ninu awọ ara eyiti ijóni bi iná ba wà, ti ojú jijóna na ba ní àmi funfun didán, ti o ṣe bi ẹni pọn rusurusu tabi funfun; 25 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi irun ninu àmi didán na ba di funfun, ti o ba si jìn jù awọ ara lọ li oju; ẹ̀tẹ li o ti inu ijóni nì sọ jade; nitorina ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ ni. 26 Ṣugbọn bi alufa ba wò o, si kiyesi i, ti kò sí irun funfun li apá didán na, ti kò si jìn jù awọ ara iyokù lọ, ṣugbọn ti o ṣe bi ẹni ṣújú; nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje: 27 Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́; àrun ẹ̀tẹ ni. 28 Bi àmi didán na ba si duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn si i li awọ ara, ṣugbọn ti o dabi ẹni sújú: iwú ijóni ni, ki alufa ki o si pè e ni mimọ́: nitoripe ijóni tita ni. 29 Bi ọkunrin tabi obinrin kan ba ní àrun li ori rẹ̀ tabi li àgbọn, 30 Nigbana ni ki alufa ki o wò àrun na: si kiyesi i, bi o ba jìn jù awọ ara lọ li oju, bi irun tinrin pupa ba mbẹ ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li aimọ́: ipẹ́ gbigbẹ ni, ani ẹ̀tẹ li ori tabi li àgbọn ni. 31 Bi alufa ba si wò àrun pipa na, si kiyesi i, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju, ti kò si sí irun dudu ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé àlarun pipa na mọ́ ni ijọ́ meje: 32 Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò àrun na: si kiyesi i, bi pipa na kò ba ràn, ti kò si sí irun pupa ninu rẹ̀, ti pipa na kò si jìn jù awọ ara lọ li oju, 33 Ki o fári, ṣugbọn ki o máṣe fá ibi pipa na; ki alufa ki o si sé ẹni pipa nì mọ́ ni ijọ́ meje si i: 34 Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò pipa na; si kiyesi i bi pipa na kò ba ràn si awọ ara, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju; nigbana ni ki alufa ki o pè e ni mimọ́: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ mimọ́. 35 Ṣugbọn bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara rẹ̀ lẹhin ìpenimimọ́ rẹ̀; 36 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara, ki alufa ki o máṣe wá irun pupa mọ́; alaimọ́ ni. 37 Ṣugbọn li oju rẹ̀ bi pipa na ba duro, ti irun dudu si hù ninu rẹ̀; pipa na jiná, mimọ́ li on: ki alufa ki o pè e ni mimọ́. 38 Bi ọkunrin kan tabi obinrin kan ba ní àmi didán li awọ ara wọn, ani àmi funfun didán; 39 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi àmi didán li awọ ara wọn ba ṣe bi ẹni ṣe funfun ṣe dudu; ifinra li o sọ jade li ara; mimọ́ li on. 40 Ati ọkunrin ti irun rẹ̀ ba re kuro li ori rẹ̀, apari ni; ṣugbọn mimọ́ li on. 41 Ẹniti irun rẹ̀ ba re silẹ ni ìha iwaju rẹ̀, o pari ni iwaju; ṣugbọn mimọ́ li on. 42 Bi õju funfun-pupa rusurusu ba mbẹ li ori pipa na, tabi iwaju ori pipa na; ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu pipa ori na, tabi ni pipá iwaju na. 43 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi iwú õju na ba funfun-pupa rusurusu ni pipa ori rẹ̀, tabi pipa iwaju rẹ̀, bi ẹ̀tẹ ti ihàn li awọ ara; 44 Ẹlẹtẹ ni, alaimọ́ ni: ki alufa ki o pè e li aimọ́ patapata; àrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀. 45 Ati adẹ́tẹ na, li ara ẹniti àrun na gbé wà, ki o fà aṣọ rẹ̀ ya, ki o si fi ori rẹ̀ silẹ ni ìhoho, ki o si fi ìbo bò ète rẹ̀ òke, ki o si ma kepe, Alaimọ́, alaimọ́. 46 Ni gbogbo ọjọ́ ti àrun na mbẹ li ara rẹ̀ ni ki o jẹ́ elẽri; alaimọ́ ni: on nikan ni ki o ma gbé; lẹhin ibudó ni ibujoko rẹ̀ yio gbé wà.

Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Kí Nǹkan Séèébu

47 Ati aṣọ ti àrun ẹ̀tẹ mbẹ ninu rẹ̀, iba ṣe aṣọ kubusu, tabi aṣọ ọ̀gbọ; 48 Iba ṣe ni ita, tabi ni iwun; ti ọ̀gbọ, tabi ti kubusu; iba ṣe li awọ, tabi ohun kan ti a fi awọ ṣe; 49 Bi àrun na ba ṣe bi ọbẹdo tabi bi pupa lara aṣọ na, tabi lara awọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo awọ kan; àrun ẹ̀tẹ ni, ki a si fi i hàn alufa: 50 Ki alufa ki o si wò àrun na, ki o si sé ohun ti o ní àrun na mọ́ ni ijọ́ meje: 51 Ki o si wò àrun na ni ijọ́ keje: bi àrun na ba ràn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu awọ, tabi ninu ohun ti a fi awọ ṣe; àrun oun ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; alaimọ́ ni. 52 Nitorina ki o fi aṣọ na jóna, iba ṣe ita, tabi iwun, ni kubusu tabi li ọ̀gbọ, tabi ninu ohunèlo awọ kan, ninu eyiti àrun na gbé wà: nitoripe ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; ki a fi jóna. 53 Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na kò ba tàn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe; 54 Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o fọ̀ ohun na ninu eyiti àrun na gbé wà, ki o si sé e mọ́ ni ijọ meje si i. 55 Ki alufa ki o si wò àrun na, lẹhin igbati a fọ̀ ọ tán: si kiyesi i, bi àrun na kò ba pa awọ rẹ̀ dà, ti àrun na kò si ràn si i, alaimọ́ ni; ninu iná ni ki iwọ ki o sun u; o kẹ̀ ninu, iba gbo ninu tabi lode. 56 Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na ba ṣe bi ẹni wodú lẹhin igbati o ba fọ̀ ọ tán; nigbana ni ki o fà a ya kuro ninu aṣọ na, tabi ninu awọ na, tabi ninu ita, tabi ninu iwun: 57 Bi o ba si hàn sibẹ̀ ninu aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe, àrun riràn ni: ki iwọ ki o fi iná sun ohun ti àrun na wà ninu rẹ̀. 58 Ati aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunkohun ti a fi awọ ṣe, ti iwọ ba fọ̀, bi àrun na ba wọ́n kuro ninu wọn nigbana ni ki a tun fọ̀ ọ lẹkeji, on o si jẹ́ mimọ́. 59 Eyi li ofin àrun ẹ̀tẹ, ninu aṣọ, kubusu tabi ti ọ̀gbọ, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ohunkohun èlo awọ kan, lati pè e ni mimọ́, tabi lati pè e li aimọ́.

Lefitiku 14

Ìwẹ̀nùmọ́ lẹ́yìn Àrùn Ara

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Eyi ni yio ma ṣe ofin adẹ́tẹ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀: ki a mú u tọ̀ alufa wá: 3 Ki alufa ki o si jade sẹhin ibudó; ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi àrun ẹ̀tẹ na ba jiná li ara adẹ́tẹ na: 4 Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ pe, ki a mú ãye ẹiyẹ meji mimọ́ wá, fun ẹniti a o wẹ̀numọ́, pẹlu igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu: 5 Ki alufa ki o paṣẹ pe ki a pa ọkan ninu ẹiyẹ nì ninu ohunèlo àmọ li oju omi ti nṣàn: 6 Niti ẹiyẹ alãye, ki o mú u, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu, ki o si fi wọn ati ẹiyẹ alãye nì bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa li oju omi ti nṣàn: 7 Ki o si fi wọ́n ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu ẹ̀tẹ nigba meje, ki o si pè e ni mimọ́, ki o si jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ si gbangba oko. 8 Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje. 9 Yio si ṣe ni ijọ́ keje, ni ki o fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro li ori rẹ̀, ati irungbọn rẹ̀, ati ipenpeju rẹ̀, ani gbogbo irun rẹ̀ ni ki o fá kuro: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ pẹlu ninu omi, on o si di mimọ́. 10 Ni ijọ́ kẹjọ ki o mú ọdọ-agutan meji akọ alailabùku wá, ati ọdọ-agutan kan abo ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa mẹta òṣuwọn deali iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati òṣuwọn logu oróro kan. 11 Ki alufa ti o sọ ọ di mimọ́ ki o mú ọkunrin na ti a o sọ di mimọ́, ati nkan wọnni wá, siwaju OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: 12 Ki alufa ki o mú akọ ọdọ-agutan kan, ki o si fi i ru ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: 13 Ki o si pa akọ ọdọ-agutan na ni ibiti on o gbé pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ ati ẹbọ sisun, ní ibi mimọ́ nì: nitoripe bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti jẹ́ ti alufa, bẹ̃ si ni ẹbọ irekọja: mimọ́ julọ ni: 14 Ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki alufa ki o si fi i si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀: 15 Ki alufa ki o si mú ninu oróro òṣuwọn logu na, ki o si dà a si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀: 16 Ki alufa ki o si tẹ̀ ika rẹ̀ ọtún bọ̀ inu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀, ki o si fi ika rẹ̀ ta ninu oróro na nigba meje niwaju OLUWA: 17 Ati ninu oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ ni ki alufa ki o fi si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, lori ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi: 18 Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o dà si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́: ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA. 19 Ki alufa ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu aimọ́ rẹ̀; lẹhin eyinì ni ki o pa ẹran ẹbọ sisun. 20 Ki alufa ki o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori pẹpẹ: ki alufa ki o ṣètutu fun u, on o si di mimọ́. 21 Bi o ba si ṣe talaka, ti kò le mú tobẹ̃ wá, njẹ ki o mú akọ ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹbi lati fì, lati ṣètutu fun u, ati ọkan ninu idamẹwa òṣuwọn deali iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ, ati òṣuwọn logu oróro kan; 22 Ati àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji, irú eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to; ki ọkan ki o si ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki ekeji ki o si ṣe ẹbọ sisun. 23 Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá ni ijọ́ kẹjọ fun ìwẹnumọ́ rẹ̀, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, niwaju OLUWA. 24 Ki alufa ki o si mú ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. 25 Ki o si pa ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki o si fi i si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀. 26 Ki alufa ki o si dà ninu oróro na si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀: 27 Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ ọtún ta ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀ nigba meje niwaju OLUWA: 28 Ki alufa ki o si fi ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, si ibi ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi: 29 Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o fi si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́, lati ṣètutu fun u niwaju OLUWA. 30 Ki o si fi ọkan ninu àdaba nì rubọ, tabi ọkan ninu ọmọ ẹiyẹle nì, iru eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to: 31 Ani irú eyiti apa rẹ̀ ka, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ niwaju OLUWA. 32 Eyi li ofin rẹ̀ li ara ẹniti àrun ẹ̀tẹ wà, apa ẹniti kò le ka ohun ìwẹnumọ́ rẹ̀.

Bí Ara Ògiri Bá Séèébu

33 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 34 Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, ti mo fi fun nyin ni ilẹ-iní, ti mo ba si fi àrun ẹ̀tẹ sinu ile kan ninu ilẹ-iní nyin; 35 Ti onile na si wá ti o si wi fun alufa pe, O jọ li oju mi bi ẹnipe àrun mbẹ ninu ile na: 36 Nigbana ni ki alufa ki o fun wọn li aṣẹ, ki nwọn ki o kó ohun ile na jade, ki alufa ki o to wọ̀ inu rẹ̀ lọ lati wò àrun na, ki ohun gbogbo ti mbẹ ninu ile na ki o máṣe jẹ́ alaimọ́: lẹhin eyinì ni ki alufa ki o wọ̀ ọ lati wò ile na: 37 Ki o si wò àrun na, si kiyesi i, bi àrun na ba mbẹ lara ogiri ile na pẹlu ìla gbòrogbòro, bi ẹni ṣe bi ọbẹdò tabi pupa rusurusu, ti o jìn li oju jù ogiri lọ; 38 Nigbana ni ki alufa ki o jade ninu ile na si ẹnu-ọ̀na ile na, ki o si há ilẹkun ile na ni ijọ́ meje: 39 Ki alufa ki o tun wá ni ijọ́ keje, ki o si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba ràn lara ogiri ile na; 40 Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o yọ okuta na kuro lara eyiti àrun na gbé wà, ki nwọn ki o si kó wọn lọ si ibi aimọ́ kan lẹhin ilu na: 41 Ki o si mu ki nwọn ki o ha inu ile na yiká kiri, ki nwọn ki o kó erupẹ ti a ha nì kuro lọ si ẹhin ilu na si ibi aimọ́ kan: 42 Ki nwọn ki o si mú okuta miran, ki nwọn ki o si fi i di ipò okuta wọnni, ki nwọn ki o si mú ọrọ miran ki nwọn ki o si fi rẹ́ ile na. 43 Bi àrùn na ba si tun pada wá, ti o si tun sọ jade ninu ile na, lẹhin igbati nwọn ba yọ okuta wọnni kuro, ati lẹhin igbati nwọn ba ha ile na, ati lẹhin igbati nwọn ba rẹ́ ẹ; 44 Nigbana ni ki alufa ki o wá, ki o wò o, si kiyesi i, bi àrun ba ràn si i ninu ile na, ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni mbẹ ninu ile na: aimọ́ ni. 45 Ki o si wó ile na, okuta rẹ̀, ati ìti igi rẹ̀, ati gbogbo erupẹ ile na; ki o si kó wọn jade kuro ninu ilu na lọ si ibi aimọ́ kan. 46 Ẹniti o ba si wọ̀ ile na ni gbogbo ìgba na ti a sé e mọ́, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 47 Ẹniti o ba dubulẹ ninu ile na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀: ẹniti o jẹun ninu ile na ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀. 48 Ati bi alufa ba wọ̀ ile, ti o si wò o, si kiyesi i, ti àrun inu ile na kò ba ràn si i, lẹhin igbati a rẹ́ ile na tán; nigbana ni ki alufa ki o pè ile na ni mimọ́, nitoripe àrun na ti jiná. 49 Ki o si mú ẹiyẹ meji, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu wá, lati wẹ̀ ile na mọ́: 50 Ki o si pa ọkan ninu ẹiyẹ na, ninu ohunèlo amọ loju omi ti nṣàn: 51 Ki o si mú igi opepe, ati ewe-hissopu, ati ododó, ati ẹiyẹ alãye nì, ki o si tẹ̀ wọn bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa nì, ati ninu omi ṣiṣàn nì, ki o si fi wọ́n ile na nigba meje: 52 Ki o si fi ẹ̀jẹ ẹiyẹ na wẹ̀ ile na mọ́, ati pẹlu omi ṣiṣàn nì, ati pẹlu ẹiyẹ alãye nì, ati pẹlu igi opepe nì, ati pẹlu ewe-hissopu nì, ati pẹlu ododó: 53 Ṣugbọn ki o jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ kuro ninu ilu lọ sinu gbangba oko, ki o si ṣètutu si ile na: yio si di mimọ́. 54 Eyi li ofin fun gbogbo onirũru àrun ẹ̀tẹ, ati ipẹ́; 55 Ati fun ẹ̀tẹ aṣọ, ati ti ile; 56 Ati fun wiwu, ati fun apá, ati fun àmi didán: 57 Lati kọni nigbati o ṣe alaimọ́, ati nigbati o ṣe mimọ́: eyi li ofin ẹ̀tẹ.

Lefitiku 15

Àwọn Ohun Àìmọ́ tí Ń Jáde Lára

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnikan ba ní àrun isun lara rẹ̀, nitori isun rẹ̀ alaimọ́ li on. 3 Eyi ni yio si jẹ́ aimọ́ rẹ̀ ninu isun rẹ̀: ara rẹ̀ iba ma sun isun rẹ̀, tabi bi ara rẹ̀ si dá kuro ninu isun rẹ̀, aimọ́ rẹ̀ ni iṣe. 4 Gbogbo ori akete ti ẹniti o ní isun na ba dubulẹ lé, aimọ́ ni: ati gbogbo ohun ti o joko lé yio jẹ́ alaimọ́. 5 Ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀ ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 6 Ẹniti o si joko lé ohunkohun ti ẹniti o ní isun ti joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 7 Ẹniti o si farakàn ara ẹniti o ní isun, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 8 Bi ẹniti o ní isun ba tutọ sara ẹniti o mọ́; nigbana ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 9 Ati asákasá ti o wù ki ẹniti o ní isun ki o gùn ki o jẹ́ alaimọ́. 10 Ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o wà nisalẹ rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ati ẹniti o rù ohun kan ninu nkan wọnni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 11 Ati ẹnikẹni ti ẹniti o ní isun ba farakàn, ti kò ti wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ ninu omi, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 12 Ati ohunèlo amọ̀, ti ẹniti o ní isun ba fọwọkàn, fifọ́ ni ki a fọ́ ọ: ati gbogbo ohunèlo igi ni ki a ṣàn ninu omi. 13 Nigbati ẹniti o ní isun ba si di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, fun isọdimimọ́ rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi ti nṣàn, yio si jẹ́ mimọ́. 14 Ati ni ijọ́ kẹjọ, ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si fi wọn fun alufa: 15 Ki alufa ki o si fi wọn rubọ, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun rẹ̀. 16 Ati bi ohun irú ìdapọ ọkunrin ba ti ara rẹ̀ jade, nigbana ni ki o wẹ̀ gbogbo ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 17 Ati gbogbo aṣọ, ati gbogbo awọ, lara eyiti ohun irú ìdapọ ba wà, on ni ki a fi omi fọ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 18 Ati obinrin na, ẹniti ọkunrin ba bá dàpọ ti on ti ohun irú ìdapọ, ki awọn mejeji ki o wẹ̀ ninu omi, ki nwọn ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 19 Bi obinrin kan ba si ní isun, ti isun rẹ̀ li ara rẹ̀ ba jasi ẹ̀jẹ, ki a yà a sapakan ni ijọ́ meje: ẹnikẹni ti o ba si farakàn a, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 20 Ati ohun gbogbo ti o dubulẹ lé ninu ile ìyasapakan rẹ̀ yio jẹ́ aimọ́: ohunkohun pẹlu ti o joko lé yio jẹ́ aimọ́. 21 Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 22 Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 23 Bi o ba si ṣepe lara akete rẹ̀ ni, tabi lara ohun ti o joko lé, nigbati o ba farakàn a, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 24 Bi ọkunrin kan ba si bá a dàpọ rára, ti ohun obinrin rẹ̀ ba mbẹ lara ọkunrin na, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; ati gbogbo akete ti on dubulẹ lé ki o jẹ́ aimọ́. 25 Ati bi obinrin kan ba ní isun ẹ̀jẹ li ọjọ́ pupọ̀ le ìgba ìyasapakan rẹ̀; tabi bi o ba si sun rekọja ìgba ìyasapakan rẹ̀; gbogbo ọjọ́ isun aimọ́ rẹ̀ yio si ri bi ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀: o jẹ́ alaimọ́. 26 Gbogbo akete ti o dubulẹ lé ni gbogbo ọjọ́ isun rẹ̀ ki o si jẹ́ fun u bi akete ìyasapakan rẹ̀: ati ohunkohun ti o joko lé ki o jẹ́ aimọ́, bi aimọ́ ìyasapakan rẹ̀. 27 Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn nkan wọnni ki o jẹ́ alaimọ́, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ̀ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 28 Ṣugbọn bi obinrin na ba di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, lẹhin eyinì ni ki o si jẹ́ mimọ́. 29 Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 30 Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun aimọ́ rẹ̀. 31 Bayi ni ki ẹnyin ki o yà awọn ọmọ Israeli kuro ninu aimọ́ wọn; ki nwọn ki o má ba kú ninu aimọ́ wọn, nigbati nwọn ba sọ ibugbé mi ti mbẹ lãrin wọn di aimọ́. 32 Eyi li ofin ẹniti o ní isun, ati ti ẹniti ohun irú rẹ̀ jade lara rẹ̀, ti o si ti ipa rẹ̀ di alaimọ́; 33 Ati ti ẹniti o ri ohun obinrin rẹ̀, ati ti ẹniti o ní isun, ati ti ọkunrin, ati ti obinrin, ati ti ẹniti o ba bá ẹniti iṣe alaimọ́ dàpọ.

Lefitiku 16

Ọjọ́ Ètùtù

1 OLUWA si sọ fun Mose lẹhin ikú awọn ọmọ Aaroni meji, nigbati nwọn rubọ niwaju OLUWA, ti nwọn si kú; 2 OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni arakunrin rẹ, ki o máṣe wá nigbagbogbo sinu ibi mimọ́, ninu aṣọ-ikele niwaju itẹ́-ãnu, ti o wà lori apoti nì; ki o má ba kú: nitoripe emi o farahàn ninu awọsanma lori itẹ́-ãnu. 3 Bayi ni ki Aaroni ki o ma wá sinu ibi mimọ́: pẹlu ẹgbọrọ akọmalu fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo fun ẹbọ sisun. 4 Ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ mimọ́ wọ̀, ki o si bọ̀ ṣòkoto ọ̀gbọ nì si ara rẹ̀, ki a si fi amure ọ̀gbọ kan dì i, fila ọ̀gbọ ni ki a fi ṣe e li ọṣọ́: aṣọ mimọ́ ni wọnyi; nitorina ni o ṣe wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si mú wọn wọ̀. 5 Ki o si gbà ọmọ ewurẹ meji akọ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan fun ẹbọ sisun, lọwọ ijọ awọn ọmọ Israeli. 6 Ki Aaroni ki o si fi akọmalu ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikara rẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀. 7 Ki o si mú ewurẹ meji nì, ki o si mú wọn wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 8 Ki Aaroni ki o si di ìbo ewurẹ meji na; ìbo kan fun OLUWA, ati ìbo keji fun Asaseli (ewurẹ idasilẹlọ). 9 Ki Aaroni ki o si mú ewurẹ ti ìbo OLUWA mú wá, ki o si fi ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 10 Ṣugbọn ewurẹ ti ìbo mú fun Asaseli on ni ki o múwa lãye siwaju OLUWA, lati fi i ṣètutu, ati ki o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ si ijù fun Asaseli. 11 Ki Aaroni ki o si mú akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá, ti iṣe ti on tikararẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ki o si pa akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti iṣe fun ara rẹ̀: 12 Ki o si mú awo-turari ti o kún fun ẹyin iná lati ori pẹpẹ wá lati iwaju OLUWA, ki ọwọ́ rẹ̀ ki o si kún fun turari didùn ti a gún kunná, ki o si mú u wá sinu aṣọ-ikele: 13 Ki o si fi turari na sinu iná niwaju OLUWA, ki ẽfin turari ki o le bò itẹ́-ãnu ti mbẹ lori ẹri, ki on ki o má ba kú. 14 Ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ki o si fi ika rẹ̀ wọn ọ sori itẹ́-ãnu ni ìha ìla-õrùn; ati niwaju itẹ́-ãnu ni ki o fi ìka rẹ̀ wọ́n ninu ẹ̀jẹ na nigba meje. 15 Nigbana ni ki o pa ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, eyiti iṣe ti awọn enia, ki o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu aṣọ-ikele, ki o si fi ẹ̀jẹ na ṣe bi o ti fi ẹ̀jẹ akọmalu ṣe, ki o si fi wọ́n ori itẹ̀-ãnu, ati niwaju itẹ́-ãnu: 16 Ki o si ṣètutu si ibi mimọ́ nì, nitori aimọ́ awọn ọmọ Israeli, ati nitori irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn: bẹ̃ni ki o si ṣe si agọ́ ajọ, ti mbẹ lọdọ wọn ninu aimọ́ wọn. 17 Ki o má si sí ẹnikan ninu agọ́ ajọ nigbati o ba wọle lati ṣètutu ninu ibi mimọ́, titi yio fi jade, ti o si ti ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ati fun gbogbo ijọ enia Israeli. 18 Ki o si jade si ibi pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ki o si ṣètutu si i; ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ati ninu ẹ̀jẹ ewurẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ na yiká. 19 Ki o si fi ika rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ na wọ́n ara rẹ̀ nigba meje, ki o si wẹ̀ ẹ mọ́, ki o si yà a simimọ́ kuro ninu aimọ́ awọn ọmọ Israeli.

Ewúrẹ́ tí A Di Ẹrù Ẹ̀ṣẹ̀ lé Lórí

20 Nigbati o ba si pari ati ṣètutu si ibi mimọ́, ati si agọ́ ajọ, ati pẹpẹ, ki o mú ewurẹ alãye nì wá: 21 Ki Aaroni ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ mejeji lé ori ewurẹ alãye na, ki o si jẹwọ gbogbo aiṣedede awọn ọmọ Israeli sori rẹ̀, ati gbogbo irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn; ki o si fi wọn lé ori ewurẹ na, ki o si ti ọwọ́ ẹniti o yẹ rán a lọ si ijù: 22 Ki ewurẹ na ki o si rù gbogbo aiṣedede wọn lori rẹ̀ lọ si ilẹ ti a kò tẹ̀dó: ki o si jọwọ ewurẹ na lọwọ lọ sinu ijù. 23 Ki Aaroni ki o si wá sinu agọ́ ajọ, ki o si bọ́ aṣọ ọ̀gbọ wọnni silẹ, ti o múwọ̀ nigbati o wọ̀ ibi mimọ́ lọ, ki o si fi wọn sibẹ̀: 24 Ki o si fi omi wẹ̀ ara rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan, ki o si mú aṣọ rẹ̀ wọ̀, ki o si jade wá, ki o si ru ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ sisun awọn enia, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀ ati fun awọn enia. 25 Ọrá ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì ni ki o si sun lori pẹpẹ. 26 Ati ẹniti o jọwọ ewurẹ nì lọwọ lọ fun Asaseli, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó. 27 Ati akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ewurẹ nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹ̀jẹ eyiti a múwa lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ni ki ẹnikan ki o mú jade lọ sẹhin ode ibudó; ki nwọn ki o si sun awọ wọn, ati ẹran wọn, ati igbẹ́ wọn ninu iná. 28 Ati ẹniti o sun wọn ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó.

Ìlànà fún Ìrántí Ọjọ́ Ètùtù

29 Eyi ni ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin: pe li oṣù keje, li ọjọ́ kẹwa oṣù, ni ki ẹnyin ki o pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹnyin má si ṣe iṣẹ kan rára, iba ṣe ibilẹ, tabi alejò ti nṣe atipo lãrin nyin: 30 Nitoripe li ọjọ́ na li a o ṣètutu fun nyin, lati wẹ̀ nyin mọ́; ki ẹnyin ki o le mọ́ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin niwaju OLUWA. 31 On o jẹ́ ọjọ́ isimi fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju, nipa ìlana titilai. 32 Ati alufa na, ẹniti a o ta oróro si li ori, ati ẹniti a o yàsimimọ́ si iṣẹ-alufa dipò baba rẹ̀, on ni ki o ṣètutu na, ki o si mú aṣọ ọ̀gbọ wọnni wọ̀, ani aṣọ mimọ́ wọnni: 33 Ki o si ṣètutu si ibi mimọ́, ki o si ṣètutu si agọ́ ajọ, ati si pẹpẹ; ki o si ṣètutu fun awọn alufa, ati fun gbogbo ijọ enia. 34 Ki eyi ki o si jẹ́ ìlana titilai fun nyin, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli nitori ẹ̀ṣẹ wọn gbogbo lẹ̃kan li ọdún. O si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Lefitiku 17

Ẹ̀jẹ̀ Lọ́wọ̀–Ninu Rẹ̀ Ni Ẹ̀mí wà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe; Eyi li ohun ti OLUWA ti palaṣẹ, wipe, 3 Ẹnikẹni ti iṣe enia ile Israeli, ti o ba pa akọmalu tabi ọdọ-agutan, tabi ewurẹ, ninu ibudó, tabi ti o pa a lẹhin ibudó, 4 Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u li ẹbọ wi OLUWA niwaju agọ́ OLUWA: a o kà ẹ̀jẹ si ọkunrin na lọrùn, o ta ẹ̀jẹ silẹ; ọkunrin na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: 5 Nitori idí eyi pe, ki awọn ọmọ Israeli ki o le ma mú ẹbọ wọn wá, ti nwọn ru ni oko gbangba, ani ki nwọn ki o le mú u tọ̀ OLUWA wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, sọdọ alufa, ki o si ru wọn li ẹbọ alafia si OLUWA. 6 Ki alufa ki o si bù ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si sun ọrá na fun õrùn didún si OLUWA. 7 Ki nwọn ki o má si ṣe ru ẹbọ wọn si obukọ mọ́, ti nwọn ti ntọ̀ lẹhin ṣe àgbere. Eyi ni yio ma ṣe ìlana lailai fun wọn ni iran-iran wọn. 8 Ki iwọ ki o si wi fun wọn, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ru ẹbọ sisun tabi ẹbọ kan, 9 Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u si OLUWA; ani ọkunrin na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 10 Ati ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ; ani emi o kọ oju mi si ọkàn na ti o jẹ ẹ̀jẹ, emi o si ke e kuro ninu awọn enia rẹ̀. 11 Nitoripe ẹmi ara mbẹ ninu ẹ̀jẹ: emi si ti fi i fun nyin lati ma fi ṣètutu fun ọkàn nyin lori pẹpẹ nì: nitoripe ẹ̀jẹ ni iṣe ètutu fun ọkàn. 12 Nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọkàn kan ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ, bẹ̃li alejò kan ti nṣe atipo ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ. 13 Ati ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti nṣe ọdẹ ti o si mú ẹranko tabi ẹiyẹ ti a ba jẹ; ani ki o ro ẹ̀jẹ rẹ̀ dànu, ki o si fi erupẹ bò o. 14 Nitoripe ẹmi gbogbo ara ni, ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ẹmi rẹ̀: nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ ẹrankẹran: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi ara gbogbo: ẹnikẹni ti o ba jẹ ẹ li a o ke kuro. 15 Ati gbogbo ọkàn ti o ba jẹ ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, tabi eyiti a fàya, iba ṣe ọkan ninu awọn ibilẹ, tabi alejò, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: nigbana li on o mọ́. 16 Ṣugbọn bi kò ba fọ̀ wọn, tabi ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀; njẹ on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

Lefitiku 18

Àwọn Èèwọ̀ tí Ó Jẹmọ́ Bíbá Obinrin Lòpọ̀

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 3 Ẹnyin kò gbọdọ hùwa bi ìwa ilẹ Egipti nibiti ẹnyin ti ngbé: ẹnyin kò si gbọdọ hùwa ìwa ilẹ Kenaani, nibiti emi o mú nyin lọ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ rìn nipa ìlana wọn. 4 Ki ẹnyin ki o ma ṣe ofin mi, ki ẹnyin si ma pa ìlana mi mọ́, lati ma rìn ninu wọn: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 5 Ẹnyin o si ma pa ìlana mi mọ́, ati ofin mi: eyiti bi enia ba ṣe, on o ma yè ninu wọn: Emi li OLUWA. 6 Ẹnikẹni kò gbọdọ sunmọ ẹnikan ti iṣe ibatan rẹ̀ lati tú ìhoho rẹ̀: Emi li OLUWA. 7 Ihoho baba rẹ, tabi ìhoho iya rẹ̀, ni iwọ kò gbọdọ tú: iya rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀. 8 Ihoho aya baba rẹ ni iwọ kò gbọdọ tú: ìhoho baba rẹ ni. 9 Ihoho arabinrin rẹ, ọmọ baba rẹ, tabi ọmọ iya rẹ, ti a bi ni ile, tabi ti a bi li ode, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú. 10 Ìhoho ọmọbinrin ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ti ọmọbinrin ọmọ rẹ obinrin, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú: nitoripe ìhoho ara rẹ ni nwọn. 11 Ìhoho ọmọbinrin aya baba rẹ, ti a bi lati inu baba rẹ wá, arabinrin rẹ ni, iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀. 12 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin baba rẹ: ibatan baba rẹ ni. 13 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ: nitoripe ibatan iya rẹ ni. 14 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arakunrin baba rẹ, iwọ kò gbọdọ sunmọ aya rẹ̀: arabinrin baba rẹ ni. 15 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya ọmọ rẹ: nitoripe aya ọmọ rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀. 16 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya arakunrin rẹ: ìhoho arakunrin rẹ ni. 17 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho obinrin ati ti ọmọbinrin rẹ̀; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ obinrin, lati tú ìhoho wọn; nitoripe ibatan ni nwọn: ohun buburu ni. 18 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ́ arabinrin aya rẹ li aya, lati bà a ninu jẹ́, lati tú ìhoho rẹ̀, pẹlu rẹ̀ nigbati o wà lãye. 19 Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ sunmọ obinrin kan lati tú u ni ìhoho, ni ìwọn igbati a yà a sapakan nitori aimọ́ rẹ̀. 20 Pẹlupẹlu iwọ kò gbọdọ bá aya ẹnikeji rẹ dàpọ lati bà ara rẹ jẹ́ pẹlu rẹ̀. 21 Iwọ kò si gbọdọ fi irú-ọmọ rẹ kan fun Moleki, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA. 22 Iwọ kò gbọdọ bá ọkunrin dápọ bi obinrin: irira ni. 23 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá ẹranko kan dàpọ, lati fi i bà ara rẹ jẹ́: bẹ̃ni obinrin kan kò gbọdọ duro niwaju ẹranko kan lati dubulẹ tì i: idaru-dàpọ ni. 24 Ẹ máṣe bà ara nyin jẹ́ ninu gbogbo nkan wọnyi: nitoripe ninu gbogbo nkan wọnyi li awọn orilẹ-ède, ti mo lé jade niwaju nyin dibajẹ́: 25 Ilẹ na si dibajẹ́: nitorina ni mo ṣe bẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wò lori rẹ̀, ilẹ tikararẹ̀ si bì awọn olugbé rẹ̀ jade. 26 Nitorina ni ki ẹnyin ki o ṣe ma pa ìlana ati ofin mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọkan ninu irira wọnyi; tabi ẹnikan ninu ibilẹ nyin, tabi alejò ti nṣe atipo ninu nyin: 27 Nitoripe gbogbo irira wọnyi li awọn ọkunrin ilẹ na ṣe, ti o ti wà ṣaju nyin, ilẹ na si dibajẹ́; 28 Ki ilẹ na ki o má ba bì nyin jade pẹlu, nigbati ẹnyin ba bà a jẹ́, bi o ti bì awọn orilẹ-ède jade, ti o ti wà ṣaju nyin. 29 Nitoripe ẹnikẹni ti o ba ṣe ọkan ninu irira wọnyi, ani ọkàn wọnni ti o ba ṣe wọn li a o ke kuro lãrin awọn enia wọn. 30 Nitorina ni ki ẹnyin ki o pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ọkan ninu irira wọnyi, ti nwọn ti ṣe ṣaju nyin, ki ẹnyin ki o má si bà ara nyin jẹ́ ninu rẹ̀: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

Lefitiku 19

Àwọn Òfin Tí Wọ́n Jẹmọ́ Ẹ̀tọ́ ati Jíjẹ́ Mímọ́

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi OLUWA Ọlọrun nyin jẹ́ mimọ́. 3 Ki olukuluku nyin ki o bẹ̀ru iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 4 Ẹ máṣe yipada si ere, bẹ̃ni ki ẹnyin má si ṣe ṣe oriṣa didà fun ara nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 5 Bi ẹnyin ba si ru ẹbọ alafia si OLUWA, ki ẹnyin ki o ru u ki ẹ le di ẹni itẹwọgbà. 6 Li ọjọ́ ti ẹnyin ru ẹbọ na ni ki a jẹ ẹ, ati ni ijọ́ keji: bi ohun kan ba si kù ninu rẹ̀ titi di ijọ́ kẹta, ninu iná ni ki a sun u. 7 Bi a ba si jẹ ninu rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, irira ni; ki yio dà: 8 Nitorina ẹniti o ba jẹ ẹ ni yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀, nitoriti o bà ohun mimọ́ OLUWA jẹ́: ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 9 Ati nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa igun oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pa èṣẹ́ ikore rẹ. 10 Iwọ kò si gbọdọ pèṣẹ́ ọgbà-àjara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká gbogbo àjara ọgbà-àjara rẹ; ki iwọ ki o fi wọn silẹ fun awọn talaka ati alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 11 Ẹnyin kò gbọdọ jale, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe alaiṣõtọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣeké fun ara nyin. 12 Ẹnyin kò si gbọdọ fi orukọ mi bura eké, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA. 13 Iwọ kò gbọdọ rẹ́ ẹnikeji rẹ jẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ haramu: owo ọ̀ya alagbaṣe kò gbọdọ sùn ọdọ rẹ titi di owurọ̀. 14 Iwọ kò gbọdọ bú aditi, tabi ki o fi ohun idugbolu siwaju afọju, ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA. 15 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ: iwọ kò gbọdọ gbè talaka, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe ojusaju alagbara: li ododo ni ki iwọ ki o mã ṣe idajọ ẹnikeji rẹ. 16 Iwọ kò gbọdọ lọ soke lọ sodo bi olofófo lãrin awọn enia rẹ: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ró tì ẹ̀jẹ ẹnikeji rẹ: Emi li OLUWA. 17 Iwọ kò gbọdọ korira arakunrin rẹ li ọkàn rẹ: ki iwọ ki o bá ẹnikeji rẹ wi, ki iwọ ki o máṣe jẹbi nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 18 Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bẹ̃ni ki o máṣe ṣe ikùnsinu si awọn ọmọ enia rẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o fẹ́ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ: Emi li OLUWA. 19 Ki ẹnyin ki o pa ìlana mi mọ́. Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ẹranọ̀sin rẹ ki o ba onirũru dàpọ: iwọ kò gbọdọ fọ́n daru-dàpọ irugbìn si oko rẹ: bẹ̃li aṣọ ti a fi ọ̀gbọ ati kubusu hun pọ̀ kò gbọdọ kan ara rẹ. 20 Ati ẹnikẹni ti o ba bá obinrin dàpọ, ti iṣe ẹrú, ti a fẹ́ fun ọkọ, ti a kò ti ràpada rára, ti a kò ti sọ di omnira; ọ̀ran ìna ni; ki a máṣe pa wọn, nitoriti obinrin na ki iṣe omnira. 21 Ki ọkunrin na ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ani àgbo kan fun ẹbọ ẹbi. 22 Ki alufa ki o si fi àgbo ẹbọ ẹbi ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da: a o si dari ẹ̀ṣẹ ti o da jì i. 23 Ati nigbati ẹnyin o ba si dé ilẹ na, ti ẹnyin o si gbìn onirũru igi fun onjẹ, nigbana ni ki ẹnyin kà eso rẹ̀ si alaikọlà: li ọdún mẹta ni ki o jasi bi alaikọlà fun nyin; ki a máṣe jẹ ẹ. 24 Ṣugbọn li ọdún kẹrin, gbogbo eso rẹ̀ na ni yio jẹ́ mimọ́, si ìyin OLUWA. 25 Ati li ọdún karun ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu eso rẹ̀, ki o le ma mú ibisi rẹ̀ wá fun nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 26 Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohun kan ti on ti ẹ̀jẹ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe ifaiya, tabi ṣe akiyesi ìgba. 27 Ẹnyin kò gbọdọ gẹ̀ ori nyin, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ tọ́ irungbọn rẹ. 28 Ẹnyin kò gbọdọ sín gbẹ́rẹ kan si ara nyin nitori okú, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ kọ àmi kan si ara nyin: Emi li OLUWA. 29 Máṣe bà ọmọ rẹ obinrin jẹ́, lati mu u ṣe àgbere; ki ilẹ na ki o má ba di ilẹ àgbere, ati ki ilẹ na má ba kún fun ìwabuburu. 30 Ki ẹnyin ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́, ki ẹnyin ki o si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA. 31 Máṣe yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe wá ajẹ́ kiri, lati fi wọn bà ara nyin jẹ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 32 Ki iwọ ki o si dide duro niwaju ori-ewú, ki o si bọ̀wọ fun oju arugbo, ki o si bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA. 33 Ati bi alejò kan ba nṣe atipo pẹlu rẹ ni ilẹ nyin, ẹnyin kò gbọdọ ni i lara. 34 Ki alejò ti mbá nyin gbé ki o jasi fun nyin bi ibilẹ, ki iwọ ki o si fẹ́ ẹ bi ara rẹ; nitoripe ẹnyin ti ṣe alejò ni ilẹ Egipti: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 35 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ, ni ìwọn ọpá, ni òṣuwọn iwuwo, tabi ni òṣuwọn oninu. 36 Oṣuwọn otitọ, òṣuwọn iwuwo otitọ, òṣuwọn efa otitọ, ati òṣuwọn hini otitọ, ni ki ẹnyin ki o ní: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá. 37 Nitorina ni ki ẹnyin ki o si ma kiyesi gbogbo ìlana mi, ati si gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA.

Lefitiku 20

Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ni Israeli, ti o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki; pipa ni ki a pa a: ki awọn enia ilẹ na ki o sọ ọ li okuta pa. 3 Emi o si kọju mi si ọkunrin na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀; nitoriti o fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, lati sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, ati lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ́. 4 Bi awọn enia ilẹ na ba si mú oju wọn kuro lara ọkunrin na, nigbati o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, ti nwọn kò si pa a: 5 Nigbana li emi o kọju si ọkunrin na, ati si idile rẹ̀, emi o si ke e kuro, ati gbogbo awọn ti o ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin, lati ma ṣe àgbere tọ̀ Moleki lẹhin, lãrin awọn enia wọn. 6 Ati ọkàn ti o ba yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, ati ajẹ́, lati ṣe àgbere tọ̀ wọn lẹhin, ani emi o kọju mi si ọkàn na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀. 7 Nitorina ẹnyin yà ara nyin simimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 8 Ki ẹnyin ki o si ma pa ìlana mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́. 9 Ẹnikẹni ti o ba fi baba tabi iya rẹ̀ ré, pipa li a o pa a: o fi baba on iya rẹ̀ ré; ẹ̀jẹ rẹ̀ wà lori rẹ̀. 10 Ati ọkunrin na ti o bá aya ọkunrin miran ṣe panṣaga, ani on ti o bá aya ẹnikeji rẹ̀ ṣe panṣaga, panṣaga ọkunrin ati panṣaga obinrin li a o pa nitõtọ. 11 Ati ọkunrin ti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho baba rẹ̀: pipa li a o pa awọn mejeji; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn. 12 Ọkunrin kan ti o ba bá aya ọmọ rẹ̀ dàpọ, pipa ni ki a pa awọn mejeji: nwọn ṣe rudurudu; ẹ̀jẹ wọn wà lori wọn. 13 Ati ọkunrin ti o ba bá ọkunrin dàpọ, bi ẹni ba obinrin dàpọ, awọn mejeji li o ṣe ohun irira: pipa li a o pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn. 14 Ati ọkunrin ti o ba fẹ́ obinrin ati iya rẹ̀, ìwabuburu ni: iná li a o fi sun wọn, ati on ati awọn; ki ìwabuburu ki o má ṣe sí lãrin nyin. 15 Ati ọkunrin ti o ba bá ẹranko dàpọ, pipa ni ki a pa a: ki ẹnyin ki o si pa ẹranko na. 16 Bi obinrin kan ba si sunmọ ẹranko kan, lati dubulẹ tì i, ki iwọ ki o pa obinrin na, ati ẹranko na: pipa ni ki a pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn. 17 Ati bi ọkunrin kan ba fẹ́ arabinrin rẹ̀, ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀, ti o si ri ìhoho rẹ̀, ti on si ri ìhoho rẹ̀; ohun buburu ni; a o si ke wọn kuro loju awọn enia wọn: o tú ìhoho arabinrin rẹ̀; on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 18 Ati bi ọkunrin kan ba bá obinrin dàpọ ti o ní ohun obinrin rẹ̀ lara, ti o ba si tú u ni ìhoho; o tú isun rẹ̀ ni ìhoho, obinrin na si fi isun ẹ̀jẹ rẹ̀ hàn: awọn mejeji li a o si ke kuro lãrin awọn enia wọn. 19 Iwọ kò si gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ, tabi ti arabinrin baba rẹ: nitoripe o tú ìhoho ibatan rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn. 20 Bi ọkunrin kan ba si bá aya arakunrin õbi rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho arakunrin õbi rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn; nwọn o kú li ailọmọ. 21 Bi ọkunrin kan ba si fẹ́ aya arakunrin rẹ̀, ohun-aimọ́ ni: o tú ìhoho arakunrin rẹ̀; nwọn o jẹ́ alailọmọ. 22 Nitorina li ẹnyin o ṣe ma pa gbogbo ìlana mi mọ́, ati gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: ki ilẹ na, ninu eyiti mo mú nyin wá tẹ̀dó si, ki o má ṣe bì nyin jade. 23 Ẹnyin kò si gbọdọ rìn ninu ìlana orilẹ-ède, ti emi lé jade kuro niwaju nyin: nitoriti nwọn ṣe gbogbo wọnyi, nitorina ni mo ṣe korira wọn. 24 Ṣugbọn emi ti wi fun nyin pe, Ẹnyin o ní ilẹ wọn, ati pe emi o fi i fun nyin lati ní i, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède. 25 Nitorina ki ẹnyin ki o fi ìyatọ sãrin ẹranko mimọ́ ati alaimọ́, ati sãrin ẹiyẹ alaimọ́ ati mimọ́: ki ẹnyin ki o má si ṣe fi ẹranko, tabi ẹiyẹ, tabi ohunkohun alãye kan ti nrakò lori ilẹ, ti mo ti yàsọ̀tọ fun nyin bi alaimọ́, sọ ọkàn nyin di irira. 26 Ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́ fun mi: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, mo si ti yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède, ki ẹnyin ki o le jẹ́ ti emi. 27 Ọkunrin pẹlu tabi obinrin ti o ní ìmo afọṣẹ, tabi ti iṣe ajẹ́, pipa ni ki a pa a: okuta ni ki a fi sọ wọn pa: ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.

Lefitiku 21

Àwọn Àlùfáàa Gbọdọ̀ Jẹ́ Mímọ́

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu awọn enia rẹ̀ kò gbọdọ di alaimọ́ nitori okú. 2 Bikoṣe fun ibatan rẹ̀ ti o sunmọ ọ, eyinì ni, iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin, ati arakunrin rẹ̀; 3 Ati arabinrin rẹ̀ ti iṣe wundia, ti o wà lọdọ rẹ̀, ti kò ti ilí ọkọ, nitori rẹ̀ ni ki o di alaimọ́. 4 Ṣugbọn on kò gbọdọ ṣe ara rẹ̀ li aimọ́, lati bà ara rẹ̀ jẹ́, olori kan sa ni ninu awọn enia rẹ̀. 5 Nwọn kò gbọdọ dá ori wọn fá, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ tọ́ irungbọn wọn, tabi singbẹrẹ kan si ara wọn. 6 Ki nwọn ki o si jasi mimọ́ fun Ọlọrun wọn, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ Ọlọrun wọn jẹ́: nitoripe ẹbọ OLUWA ti a fi ina ṣe, ati àkara Ọlọrun wọn, ni nwọn fi nrubọ: nitorina ni ki nwọn ki o jẹ́ mimọ́. 7 Nwọn kò gbọdọ fẹ́ aya ti iṣe àgbere, tabi ẹni ibàjẹ́; bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fẹ́ obinrin ti a ti ọdọ ọkọ rẹ̀ kọ̀silẹ: nitoripe mimọ́ li on fun Ọlọrun rẹ̀. 8 Nitorina ki ẹnyin ki o yà a simimọ́; nitoriti o nrubọ àkara Ọlọrun rẹ: yio jẹ́ mimọ́ si ọ: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, ti o yà nyin simimọ́. 9 Ati bi ọmọbinrin alufa kan, ba fi iṣẹ àgbere bà ara rẹ̀ jẹ́, o bà baba rẹ̀ jẹ́: iná li a o da sun u. 10 Ati olori alufa ninu awọn arakunrin rẹ̀, ori ẹniti a dà oróro itasori si, ti a si yàsọtọ lati ma wọ̀ aṣọ wọnni, ki o máṣe ṣi ibori rẹ̀, tabi ki o fà aṣọ rẹ̀ ya; 11 Ki o má si ṣe wọle tọ̀ okú kan lọ, bẹ̃ni ki o máṣe sọ ara rẹ̀ di alaimọ́ nitori baba rẹ̀, tabi nitori iya rẹ̀; 12 Bẹ̃ni ki o máṣe jade kuro ninu ibi mimọ́, bẹ̃ni ki o máṣe bà ibi mimọ́ Ọlọrun rẹ̀ jẹ́, nitoripe adé oróro itasori Ọlọrun rẹ̀ mbẹ lori rẹ̀: Emi li OLUWA. 13 Wundia ni ki o fẹ́ li aya fun ara rẹ̀. 14 Opó, tabi obinrin ikọsilẹ, tabi ẹni-ibàjẹ́, tabi panṣaga, wọnyi ni on kò gbọdọ fẹ́: bikoṣe wundia ni ki o fẹ́ li aya lati inu awọn enia rẹ̀. 15 Bẹ̃ni ki o máṣe bà irú-ọmọ rẹ̀ jẹ́ ninu awọn enia rẹ̀: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà a simimọ́. 16 OLUWA si sọ fun Mose pe, 17 Sọ fun Aaroni pe, Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ rẹ ni iran-iran wọn, ti o ní àbuku kan, ki o máṣe sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀. 18 Nitoripe gbogbo ọkunrin ti o ní àbuku, ki o máṣe sunmọtosi: ọkunrin afọju, tabi amukun, tabi arẹ́mu, tabi ohun kan ti o leke, 19 Tabi ọkunrin ti iṣe aṣẹ́sẹ̀, tabi aṣẹ́wọ, 20 Tabi abuké, tabi arará, tabi ẹniti o ní àbuku kan li oju rẹ̀, tabi ti o ní ekuru, tabi ipẹ́, tabi ti kóro rẹ̀ fọ́; 21 Ẹnikẹni ti o ní àbuku ninu irúọmọ Aaroni alufa kò gbọdọ sunmọtosi lati ru ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: on li àbuku; kò gbọdọ sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀. 22 On o ma jẹ àkara Ọlọrun rẹ̀, ti mimọ́ julọ ati ti mimọ́. 23 Kìki on ki yio wọ̀ inu aṣọ-ikele nì lọ, bẹ̃ni ki o máṣe sunmọ pẹpẹ, nitoriti on ní àbuku; ki on ki o máṣe bà ibi mimọ́ mi jẹ́: nitori Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́. 24 Mose si wi fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli.

Lefitiku 22

Àwọn Ohun Ìrúbọ Gbọdọ̀ Jẹ́ Mímọ́

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, ki nwọn ki o yà ara wọn sọ̀tọ kuro ninu ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ ninu ohun wọnni, ti nwọn yàsimimọ́ fun mi: Emi li OLUWA, 3 Wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu gbogbo irú-ọmọ nyin ninu awọn iran nyin, ti o ba sunmọ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yàsimimọ́ fun OLUWA, ti o ní aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro niwaju mi: Emi li OLUWA. 4 Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ Aaroni ti iṣe adẹtẹ, tabi ti o ní isun; ki o máṣe jẹ ninu ohun mimọ́, titi on o fi di mimọ́. Ati ẹnikẹni ti o farakàn ohun ti iṣe aimọ́, bi okú, tabi ọkunrin ti ohun-irú nti ara rẹ̀ jade; 5 Tabi ẹniti o ba farakàn ohun ti nrakò kan, ti yio sọ ọ di aimọ́, tabi enia kan ti yio sọ ọ di aimọ́, irú aimọ́ ti o wù ki o ní; 6 Ọkàn ti o ba farakàn ọkan ninu irú ohun bẹ̃ ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ, ki o má si ṣe jẹ ninu ohun mimọ́, bikoṣepe o ba fi omi wẹ̀ ara rẹ̀. 7 Nigbati õrùn ba si wọ̀, on o di mimọ́; lẹhin eyinì ki o si ma jẹ ninu ohun mimọ́, nitoripe onjẹ rẹ̀ ni. 8 On kò gbọdọ jẹ ẹran ti o kú fun ara rẹ̀, tabi eyiti ẹranko fàya, lati fi i bà ara rẹ̀ jẹ́: Emi li OLUWA. 9 Nitorina ki nwọn ki o ma pa ìlana mi mọ́, ki nwọn ki o máṣe rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nwọn a si kú nitorina, bi nwọn ba bà a jẹ́: Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́. 10 Alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́: alabagbé alufa, tabi alagbaṣe kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́ na. 11 Ṣugbọn bi alufa ba fi owo rẹ̀ rà ẹnikan, ki o jẹ ninu rẹ̀; ẹniti a si bi ninu ile rẹ̀, ki nwọn ki o ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀. 12 Bi ọmọbinrin alufa na ba si ní alejò kan li ọkọ, obinrin na kò le jẹ ninu ẹbọ fifì ohun mimọ́. 13 Ṣugbọn bi ọmọbinrin alufa na ba di opó, tabi ẹni-ikọsilẹ, ti kò si lí ọmọ, ti o si pada wá si ile baba rẹ̀, bi ìgba ewe rẹ̀, ki o ma jẹ ninu onjẹ baba rẹ̀: ṣugbọn alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀. 14 Bi ẹnikan ba si jẹ ninu ohun mimọ́ li aimọ̀, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun alufa pẹlu ohun mimọ́ na. 15 Nwọn kò si gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ti nwọn mú fun OLUWA wá: 16 Tabi lati jẹ ki nwọn ki o rù aiṣedede ti o mú ẹbi wá, nigbati nwọn ba njẹ ohun mimọ́ wọn: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́. 17 OLUWA si sọ fun Mose pe, 18 Sọ fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu awọn alejò ni Israeli, ti o ba fẹ́ ru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ nitori ẹjẹ́ wọn gbogbo, ati nitori ẹbọ rẹ̀ atinuwá gbogbo, ti nwọn nfẹ́ ru si OLUWA fun ẹbọ sisun; 19 Ki o le dà fun nyin, akọ alailabùkun ni ki ẹnyin ki o fi ru u, ninu malu, tabi ninu agutan, tabi ninu ewurẹ. 20 Ṣugbọn ohunkohun ti o ní abùku, li ẹnyin kò gbọdọ múwa: nitoripe ki yio dà fun nyin. 21 Ati ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ alafia si OLUWA, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá ni malu tabi agutan, ki o pé ki o ba le dà; ki o máṣe sí abùku kan ninu rẹ̀. 22 Afọju, tabi fifàya, tabi eyiti a palara, tabi elegbo, elekuru, tabi oni-ipẹ́, wọnyi li ẹnyin kò gbọdọ fi rubọ si OLUWA, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fi ninu wọn ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA lori pẹpẹ. 23 Ibaṣe akọmalu tabi ọdọ-agutan ti o ní ohun ileke kan, tabi ohun abùku kan, eyinì ni ki iwọ ma fi ru ẹbọ ifẹ́-atinuwá; ṣugbọn fun ẹjẹ́ ki yio dà. 24 Ẹnyin kò gbọdọ mú eyiti kóro rẹ̀ fọ́, tabi ti a tẹ̀, tabi ti a ya, tabi ti a là, wá rubọ si OLUWA; ki ẹnyin máṣe e ni ilẹ nyin. 25 Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ti ọwọ́ alejò rubọ àkara Ọlọrun nyin ninu gbogbo wọnyi; nitoripe ibàjẹ́ wọn mbẹ ninu wọn, abùku si mbẹ ninu wọn: nwọn ki yio dà fun nyin. 26 OLUWA si sọ fun Mose pe, 27 Nigbati a ba bi akọmalu kan, tabi agutan kan, tabi ewurẹ kan, nigbana ni ki o gbé ijọ meje lọdọ iya rẹ̀; ati lati ijọ́ kẹjọ ati titi lọ on o di itẹwọgbà fun ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 28 Ibaṣe abomalu tabi agutan, ẹnyin kò gbọdọ pa a ati ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ kanna. 29 Nigbati ẹnyin ba si ru ẹbọ ọpẹ́ si OLUWA, ẹ ru u ki o le dà. 30 Li ọjọ́ na ni ki a jẹ ẹ; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ́kù silẹ ninu rẹ̀ titi di ijọ́ keji: Emi li OLUWA. 31 Nitorina ni ki ẹnyin ki o ma pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA. 32 Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ bà orukọ mimọ́ mi jẹ́; bikoṣe ki a yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́, 33 Ti o mú nyin jade lati ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: Emi li OLUWA.

Lefitiku 23

Àwọn Àjọ̀dún Ẹ̀sìn

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, ajọ OLUWA, ti ẹnyin o pè fun apejọ mimọ́, wọnyi li ajọ mi. 3 Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ: ṣugbọn ni ijọ́ keje li ọjọ́ isimi, apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ kan ninu rẹ̀: nitoripe ọjọ́-isimi OLUWA ni ninu ibujoko nyin gbogbo. 4 Wọnyi li ajọ OLUWA, ani apejọ mimọ́, ti ẹnyin o pè li akokò wọn.

Àjọ̀dún Ìrékọjá ati Àìwúkàrà

5 Ni ijọ́ kẹrinla oṣù kini, li aṣalẹ, li ajọ irekọja OLUWA. 6 Ati li ọjọ́ kẹdogun oṣù na li ajọ àkara alaiwu si OLUWA: ijọ́ meje li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu. 7 Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara ninu rẹ̀. 8 Bikoṣe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni ijọ́ meje: ni ijọ́ keje ni apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara. 9 OLUWA si sọ fun Mose pe, 10 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, ti ẹnyin o si ma ṣe ikore rẹ̀, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ìdi-ọkà kan akọ́so ikore nyin tọ̀ alufa wá: 11 On o si fì ìdi-ọkà na niwaju OLUWA, lati ṣe itẹwọgbà fun nyin: ni ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi ni ki alufa ki o fì i. 12 Li ọjọ́ ti ẹnyin fì ìdi-ọkà ni ki ẹnyin ki o rubọ akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan alailabùku fun ẹbọ sisun si OLUWA. 13 Ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ ki o jẹ́ meji idamẹwa òṣuwọn iyẹfun daradara, ti a fi oróro pò, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA fun õrun didùn: ati ẹbọ ohun-mimu rẹ̀ ni ki o ṣe ọtí-waini idamẹrin òṣuwọn hini. 14 Ẹnyin kò si gbọdọ jẹ àkara, tabi ọkà yiyan, tabi ọkà tutù ninu ipẹ́, titi yio fi di ọjọ́ na gan ti ẹnyin mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ Ọlọrun nyin wá: ki o si jasi ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.

Àjọ̀dún Ìkórè

15 Lati ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi, ni ọjọ́ ti ẹnyin mú ìdi-ọkà ẹbọ fifì nì wá, ki ẹnyin ki o si kà ọjọ́-isimi meje pé; 16 Ani di ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi keje, ki ẹnyin ki o kà ãdọta ọjọ́; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ titun si OLUWA. 17 Ki ẹnyin ki o si mú lati inu ibugbé nyin wá, ìṣu-àkara fifì meji ti idamẹwa meji òṣuwọn: ki nwọn ki o jẹ́ ti iyẹfun daradara, ki a fi iwukàra yan wọn, akọ́so ni nwọn fun OLUWA. 18 Pẹlu àkara na ki ẹnyin ki o si fi ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabukù rubọ, ati ẹgbọrọ akọmalu kan, ati àgbo meji: ki nwọn ki o jẹ́ ẹbọ sisun si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe olõrùn didùn ni si OLUWA. 19 Nigbana ni ki ẹnyin ki o fi obukọ kan ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan ru ẹbọ alafia. 20 Ki alufa ki o si fi wọn pẹlu àkara àwọn akọ́so fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA, pẹlu ọdọ-agutan meji nì: ki nwọn ki o si jẹ́ mimọ́ si OLUWA fun alufa na. 21 Ki ẹnyin ki o si kede li ọjọ́ na gan; ki o le jẹ́ apejọ mimọ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: yio si ma ṣe ìlana fun nyin titilai ni ibujoko nyin gbogbo ni iran-iran nyin. 22 Nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa ẹba oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pèṣẹ́ ikore rẹ̀: ki iwọ ki o fi i silẹ fun awọn talaka, ati fun alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

Àjọ̀dún Ọdún Titun

23 OLUWA si sọ fun Mose pe, 24 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Li oṣù keje, li ọjọ́ kini oṣù ni ki ẹnyin ki o ní isimi; iranti ifunpe, apejọ mimọ́. 25 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: bikoṣepe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

Ọjọ́ Ètùtù

26 OLUWA si sọ fun Mose pe, 27 Ijọ́ kẹwa oṣù keje yi ni ki o ṣe ọjọ́ ètutu: ki apejọ mimọ́ wà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹ si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 28 Ẹnyin kò si gbọdọ ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi: nitoripe ọjọ́ ètutu ni, lati ṣètutu fun nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin. 29 Nitoripe ọkànkọkàn ti kò ba pọ́n ara rẹ̀ loju li ọjọ́ na yi, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 30 Ati ọkànkọkan ti o ba ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi, ọkàn na li emi o run kuro lãrin awọn enia rẹ̀. 31 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan: ki o jẹ́ ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo. 32 Ọjọ́-isimi ni fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọn ọkàn nyin loju: lo ọjọ́ kẹsan oṣù na li alẹ, lati alẹ dé alẹ, ni ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́-isimi nyin mọ́.

Àjọ Àgọ́

33 OLUWA si sọ fun Mose pe, 34 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ kẹdogun oṣù keje yi li ajọ agọ́ ni ijọ́ meje si OLUWA. 35 Li ọjọ́ kini li apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan. 36 Ijọ meje ni ki ẹnyin fi ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ni ijọ́ kẹjọ li apejọ́ mimọ́ fun nyin; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọjọ́ ajọ ni; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan. 37 Wọnyi li ajọ OLUWA, ti ẹnyin o kedé lati jẹ́ apejọ mimọ́, lati ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ, ẹbọ, ati ẹbọ ohunmimu, olukuluku wọn li ọjọ́ rẹ̀: 38 Pẹlu ọjọ́-isimi OLUWA, ati pẹlu ẹ̀bun nyin, ati pẹlu gbogbo ẹjẹ́ nyin, ati pẹlu gbogbo ẹbọ atinuwá nyin ti ẹnyin fi fun OLUWA. 39 Pẹlupẹlu li ọjọ́ kẹdogun oṣù keje na, nigbati ẹnyin ba ṣe ikore eso ilẹ tán, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ si OLUWA ni ijọ́ meje: li ọjọ́ kini ki isimi ki o wà, ati li ọjọ́ kẹjọ ki isimi ki o wà, 40 Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o si mú eso igi daradara, imọ̀-ọpẹ, ati ẹká igi ti o bò, ati ti igi wilo odò; ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin ni ijọ́ meje. 41 Ki ẹnyin ki o si ma pa a mọ́ li ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje li ọdún: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin: ki ẹnyin ki o ma ṣe e li oṣù keje. 42 Ki ẹnyin ki o ma gbé inu agọ́ ni ijọ́ meje; gbogbo ibilẹ ni Israeli ni ki o gbé inu agọ́: 43 Ki iran-iran nyin ki o le mọ̀ pe, Emi li o mu awọn ọmọ Israeli gbé inu agọ́, nigbati mo mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 44 Mose si sọ gbogbo ajọ OLUWA wọnyi fun awọn ọmọ Israeli.

Lefitiku 24

Ìtọ́jú Àwọn Fìtílà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú oróro daradara ti olifi gigún fun ọ wá, fun imọlẹ lati ma mu fitila jó nigbagbogbo. 3 Lẹhin ode aṣọ-ikele ẹrí, ninu agọ́ ajọ, ni ki Aaroni ki o tọju rẹ̀ lati aṣalẹ di owurọ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin. 4 Ki o si tọju fitila lori ọpá-fitila mimọ́ nì nigbagbogbo niwaju OLUWA.

Àkàrà Tí Wọ́n Fi Rúbọ sí Ọlọrun

5 Ki iwọ ki o si mú iyẹfun daradara, ki o si yan ìṣu-àkara mejila ninu rẹ̀: idamẹwa meji òṣuwọn ni ki o wà ninu ìṣu-àkara kan. 6 Ki iwọ ki o si tò wọn li ẹsẹ meji, mẹfa li ẹsẹ kan, lori tabili mimọ́ niwaju OLUWA. 7 Ki iwọ ki o si fi turari daradara sori ẹsẹ̀ kọkan ki o le wà lori ìṣu-àkara na fun iranti, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 8 Li ọjọjọ́ isimi ni ki ẹ ma tun u tò niwaju OLUWA titi; gbigbà ni lọwọ awọn ọmọ Israeli nipa majẹmu titi aiye. 9 Ki o si ma jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ; ki nwọn ki o si ma jẹ ẹ ni ibi mimọ́ kan: nitoripe mimọ́ julọ ni fun u ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ìlana titilai.

Àpẹẹrẹ Ìdájọ́ ati Ìjẹníyà Tí Ó Tọ́

10 Ati ọmọkunrin obinrin Israeli kan, ti baba rẹ̀ ṣe ara Egipti, o jade lọ ninu awọn ọmọ Israeli: ọmọkunrin obinrin Israeli yi ati ọkunrin Israeli kan si jà ni ibudó. 11 Eyi ọmọkunrin obinrin Israeli yi, sọ̀rọ buburu si Orukọ nì, o si fi bú: nwọn si mú u tọ̀ Mose wá. Orukọ iya rẹ̀ ama jẹ Ṣelomiti, ọmọbinrin Dibri, ti ẹ̀ya Dani. 12 Nwọn si ha a mọ́ ile-ìde, titi a o fi fi inu OLUWA hàn fun wọn. 13 OLUWA si sọ fun Mose pe, 14 Mú ẹniti o ṣe ifibu nì wá sẹhin ibudó; ki gbogbo awọn ti o si gbọ́ ọ ki o fi ọwọ́ wọn lé ori rẹ̀, ki gbogbo ijọ enia ki o le sọ ọ li okuta. 15 Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ti o ba fi Ọlọrun rẹ̀ bú yio rù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 16 Ati ẹniti o sọ̀rọ buburu si orukọ OLUWA nì, pipa ni ki a pa a: gbogbo ijọ enia ni ki o sọ ọ li okuta pa nitõtọ: ati alejò, ati ibilẹ, nigbati o ba sọ̀rọbuburu si orukọ OLUWA, pipa li a o pa a. 17 Ati ẹniti o ba gbà ẹmi enia, pipa li a o pa a: 18 Ẹniti o ba si lù ẹran kan pa, ki o san a pada: ẹmi fun ẹmi. 19 Bi ẹnikan ba si ṣe abùku kan si ara ẹnikeji rẹ̀; bi o ti ṣe, bẹ̃ni ki a ṣe si i; 20 Ẹ̀ya fun ẹ̀ya, oju fun oju, ehin fun ehin; bi on ti ṣe abùku si ara enia, bẹ̃ni ki a ṣe si i. 21 Ẹniti o ba si lù ẹran pa, ki o san a pada: ẹniti o ba si lù enia pa, a o pa a. 22 Irú ofin kan li ẹnyin o ní, gẹgẹ bi fun alejò bẹ̃ni fun ibilẹ: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 23 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, pe ki nwọn ki o mú ẹniti o ṣe ifibu nì jade lọ sẹhin ibudó, ki nwọn ki o si sọ ọ li okuta pa. Awọn ọmọ Israeli si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Lefitiku 25

Ọdún Keje

1 OLUWA si sọ fun Mose li òke Sinai pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, nigbana ni ki ilẹ na ki o pa isimi kan mọ́ fun OLUWA. 3 Ọdún mẹfa ni iwọ o fi gbìn oko rẹ, ọdún mẹfa ni iwọ o si fi rẹwọ ọgbà-ajara rẹ, ti iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ; 4 Ṣugbọn ọdún keje ki o si jasi ìgba isimi fun ilẹ na, isimi fun OLUWA: iwọ kò gbọdọ gbìn oko rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹwọ ọgbà-àjara rẹ. 5 Eyiti o ba lalẹ̀ hù ninu ikore rẹ iwọ kò gbọdọ ká, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká eso àjara rẹ ti iwọ kò rẹ́ lọwọ: nitoripe ọdún isimi ni fun ilẹ na. 6 Ọdún isimi ilẹ na yio si ma ṣe ohunjijẹ fun nyin; fun iwọ, ati fun iranṣẹ rẹ ọkunrin, ati fun iranṣẹ rẹ obinrin, ati fun alagbaṣe rẹ, ati fun alejò rẹ ti nṣe atipo lọdọ rẹ; 7 Ati fun ohunọ̀sin rẹ, ati fun ẹran ti mbẹ ni ilẹ rẹ, ni ki ibisi rẹ̀ gbogbo ki o ṣe onjẹ fun.

Ọdún Ìdásílẹ̀ ati Ìdápadà

8 Ki iwọ ki o si kà ọdún isimi meje fun ara rẹ, ọdún meje ìgba meje; ati akokò ọdún isimi meje ni yio jẹ́ ọdún mọkandilãdọta fun ọ. 9 Ki iwọ ki o si mu ki ipè ki o dún ni ijọ́ kẹwa oṣù keje, li ọjọ́ ètutu ni ki ẹnyin ki o mu ipè na dún ni gbogbo ilẹ nyin. 10 Ki ẹnyin ki o si yà arãdọta ọdún simimọ́, ki ẹnyin ki o si kede idasilẹ ni ilẹ na fun gbogbo awọn ti ngbé inu rẹ̀: yio si ma jẹ́ jubeli fun nyin; ki ẹnyin ki o si pada olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si pada sinu idile rẹ̀. 11 Ọdún jubeli ni ki arãdọta ọdún ki o jasi fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká ilalẹ-hù inu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká eso àjara rẹ̀ ti a kò rẹ-lọwọ. 12 Nitoripe jubeli ni; mimọ́ ni ki o jasi fun nyin: ibisi rẹ̀ ni ki ẹnyin o ma jẹ lati inu oko wa. 13 Li ọdún jubeli yi ni ki olukuluku nyin ki o pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀. 14 Bi iwọ ba si tà ọjà fun ẹnikeji rẹ, tabi bi iwọ ba rà lọwọ ẹnikeji rẹ, ẹnyin kò gbọdọ rẹ ara nyin jẹ: 15 Gẹgẹ bi iye ọdún lẹhin jubeli ni ki iwọ ki o rà lọwọ ẹnikeji rẹ, ati gẹgẹ bi iye ọdún ikore rẹ̀ ni ki o tà fun ọ. 16 Gẹgẹ bi ọ̀pọ ọdún ni ki iwọ ki o bù owo rẹ̀ sí i, ati gẹgẹ bi ọdún rẹ̀ ti fàsẹhin, ni ki iwọ ki o si bù owo rẹ̀ kù; nitoripe gẹgẹ bi iye ọdún ikore ni ki o tà fun ọ. 17 Nitorina ẹnyin kò gbọdọ rẹ ara nyin jẹ; bikoṣe pe ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

Ìyọnu Tí Ó Wà ninu Ọdún Keje

18 Nitorina ki ẹnyin ki o ma ṣe ìlana mi, ki ẹ si ma pa ofin mi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; ẹnyin o si ma gbé ilẹ na li ailewu. 19 Ilẹ na yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, ẹ o si ma jẹ ajẹyo, ẹ o si ma gbé inu rẹ̀ li ailewu. 20 Bi ẹnyin ba si wipe, Kili awa o ha ma jẹ li ọdún keje? sa wo o, awa kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li awa kò gbọdọ kó ire wa: 21 Nigbana li emi o fi aṣẹ ibukún mi fun nyin li ọdún kẹfa, on o si so eso jade fun nyin fun ọdún mẹta. 22 Ẹnyin o si gbìn li ọdún kẹjọ, ẹnyin o si ma jẹ ninu eso lailai titi di ọdún kẹsan, titi eso rẹ̀ yio fi dé ni ẹnyin o ma jẹ ohun isigbẹ.

Dídá Nǹkan Ìní Pada

23 Ẹnyin kò gbọdọ tà ilẹ lailai; nitoripe ti emi ni ilẹ: nitoripe alejò ati atipo ni nyin lọdọ mi. 24 Ati ni gbogbo ilẹ-iní nyin ki ẹnyin ki o si ma ṣe ìrapada fun ilẹ. 25 Bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti o ba si tà ninu ilẹ-iní rẹ̀, bi ẹnikan ninu awọn ibatan rẹ̀ ba si wá lati rà a, njẹ ki o rà eyiti arakunrin rẹ̀ ti tà pada. 26 Bi ọkunrin na kò ba ní ẹnikan ti yio rà a pada, ti on tikara rẹ̀ ti di olowo ti o ní to lati rà a pada; 27 Nigbana ni ki o kà ọdún ìta rẹ̀, ki o si mú elé owo rẹ̀ pada fun ẹniti o tà a fun, ki on ki o le pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀. 28 Ṣugbọn bi o ba ṣepe on kò le san a pada fun u, njẹ ki ohun ti o tà na ki o gbé ọwọ́ ẹniti o rà a titi di ọdún jubeli: yio si bọ́ ni jubeli, on o si pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀. 29 Bi ọkunrin kan ba si tà ile gbigbé kan ni ilu olodi, njẹ ki o rà a pada ni ìwọn ọdún kan lẹhin ti o tà a; ni ìwọn ọdún kan ni ki o rà a pada. 30 Bi a kò ba si rà a ni ìwọn ọdún kan gbako, njẹ ki ile na ki o di ti ẹniti o rà a titilai ni iran-iran rẹ̀: ki yio bọ́ ni jubeli. 31 Ṣugbọn ile ileto wọnni ti kò ni odi yi wọn ká awọn li a kà si ibi oko ilu: ìrapada li awọn wọnni, nwọn o si bọ́ ni jubeli. 32 Ṣugbọn niti ilu awọn ọmọ Lefi, ile ilu iní wọn, ni awọn ọmọ Lefi o ma ràpada nigbakugba. 33 Bi ẹnikan ba si rà lọwọ awọn ọmọ Lefi, njẹ ile ti a tà na, ni ilu iní rẹ̀, ki o bọ́ ni jubeli: nitoripe ile ilu awọn ọmọ Lefi ni ilẹ-iní wọn lãrin awọn ọmọ Israeli. 34 Ṣugbọn ilẹ ẹba ilu wọn ni nwọn kò gbọdọ tà; nitoripe ilẹ-iní wọn ni titi aiye.

Yíyá Aláìní Lówó

35 Ati bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti ọwọ́ rẹ̀ ba si rẹlẹ lọdọ rẹ; njẹ ki iwọ ki o ràn a lọwọ; ibaṣe alejò, tabi atipo; ki on ki o le wà pẹlu rẹ. 36 Iwọ máṣe gbà elé lọwọ rẹ̀, tabi ẹdá; ṣugbọn bẹ̀ru Ọlọrun rẹ; ki arakunrin rẹ ki o le wà pẹlu rẹ. 37 Iwọ kò gbọdọ fi owo rẹ fun u li ẹdá, tabi ki o wín i li onjẹ rẹ fun asanlé. 38 Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, lati fi ilẹ Kenaani fun nyin, ati lati ma ṣe Ọlọrun nyin.

Ìdásílẹ̀ Àwọn Ẹrú

39 Ati bi arakunrin rẹ ti mba ọ gbé ba di talakà, ti o si tà ara rẹ̀ fun ọ; iwọ kò gbọdọ sìn i ni ìsin-ẹrú: 40 Bikoṣe bi alagbaṣe, ati bi atipo, ni ki o ma ba ọ gbé, ki o si ma sìn ọ titi di ọdún jubeli: 41 Nigbana ni ki o lọ kuro lọdọ rẹ, ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ki o si pada lọ si idile rẹ̀, ati si ilẹ-iní awọn baba rẹ̀ ni ki o pada si. 42 Nitoripe iranṣẹ mi ni nwọn iṣe, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: a kò gbọdọ tà wọn bi ẹni tà ẹrú. 43 Iwọ kò gbọdọ fi irorò sìn i; ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ. 44 Ati awọn ẹrú rẹ ọkunrin, ati awọn ẹrú rẹ obinrin, ti iwọ o ní; ki nwọn ki o jẹ́ ati inu awọn orilẹ-ède wá ti o yi nyin ká, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o ma rà awọn ẹrú-ọkunrin ati awọn ẹrú-obinrin. 45 Pẹlupẹlu ninu awọn ọmọ alejò ti nṣe atipo pẹlu nyin, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o rà, ati ninu awọn idile wọn ti mbẹ pẹlu nyin, ti nwọn bi ni ilẹ nyin: nwọn o si jẹ iní nyin. 46 Ẹnyin o si ma fi wọn jẹ ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin, lati ní wọn ni iní; ẹnyin o si ma sìn wọn lailai: ṣugbọn ninu awọn arakunrin nyin awọn ọmọ Israeli, ẹnikan kò gbọdọ fi irorò sìn ẹnikeji rẹ̀. 47 Ati bi alejò tabi atipo kan ba di ọlọrọ̀ lọdọ rẹ, ati arakunrin rẹ kan leti ọdọ rẹ̀ ba di talakà, ti o ba si tà ara rẹ̀ fun alejò tabi atipo na leti ọdọ rẹ, tabi fun ibatan idile alejò na: 48 Lẹhin igbati o tà ara rẹ̀ tán, a si tún le rà a pada; ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀ le rà a: 49 Ibaṣe arakunrin õbi rẹ̀, tabi ọmọ arakunrin õbi rẹ̀, le rà a, tabi ibatan rẹ̀ ninu idile rẹ̀ le rà a; tabi bi o ba di ọlọrọ̀, o le rà ara rẹ̀. 50 Ki o si ba ẹniti o rà a ṣìro lati ọdún ti o ti tà ara rẹ̀ fun u titi di ọdún jubeli: ki iye owo ìta rẹ̀ ki o si ri gẹgẹ bi iye ọdún, gẹgẹ bi ìgba alagbaṣe ni ki o ri fun u. 51 Bi ọdún rẹ̀ ba kù pupọ̀ sibẹ̀, gẹgẹ bi iye wọn ni ki o si san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada ninu owo ti a fi rà a. 52 Bi o ba si ṣepe kìki ọdún diẹ li o kù titi di ọdún jubeli, njẹ ki o ba a ṣìro, gẹgẹ bi iye ọdún rẹ̀ ni ki o san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada. 53 Bi alagbaṣe ọdọdún ni ki o ma ba a gbé: ki on ki o máṣe fi irorò sìn i li oju rẹ. 54 Bi a kò ba si fi wọnyi rà a silẹ, njẹ ki o jade lọ li ọdún jubeli, ati on, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀. 55 Nitoripe iranṣẹ mi li awọn ọmọ Israeli iṣe; iranṣẹ mi ni nwọn ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

Lefitiku 26

Ibukun fún Ìgbọràn

1 ẸNYIN kò gbọdọ yá oriṣa, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ gbé ere tabi ọwọ̀n kan dide naró fun ara nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ gbé ere okuta gbigbẹ kalẹ ni ilẹ nyin, lati tẹriba fun u: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 2 Ki ẹnyin ki o pa ọjọ́-isimi mi mọ́, ki ẹ si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA. 3 Bi ẹnyin ba nrìn ninu ìlana mi, ti ẹ si npa ofin mi mọ́, ti ẹ si nṣe wọn; 4 Nigbana li emi o fun nyin li òjo li akokò rẹ̀, ilẹ yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, igi oko yio si ma so eso wọn. 5 Ipakà nyin yio si dé ìgba ikore àjara, igba ikore àjara yio si dé ìgba ifunrugbìn: ẹnyin o si ma jẹ onjẹ nyin li ajẹyo, ẹ o si ma gbé ilẹ nyin li ailewu. 6 Emi o si fi alafia si ilẹ na, ẹnyin o si dubulẹ, kò si sí ẹniti yio dẹruba nyin: emi o si mu ki ẹranko buburu ki o dasẹ kuro ni ilẹ na, bẹ̃ni idà ki yio là ilẹ nyin já. 7 Ẹnyin o si lé awọn ọtá nyin, nwọn o si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin. 8 Marun ninu nyin yio si lé ọgọrun, ọgọrun ninu nyin yio si lé ẹgbarun: awọn ọtá nyin yio si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin. 9 Nitoriti emi o fi ojurere wò nyin, emi o si mu nyin bisi i, emi o si sọ nyin di pupọ̀, emi o si gbé majẹmu mi kalẹ pẹlu nyin. 10 Ẹnyin o si ma jẹ ohun isigbẹ, ẹnyin o si ma kó ohun ẹgbẹ jade nitori ohun titun. 11 Emi o si gbé ibugbé mi kalẹ lãrin nyin: ọkàn mi ki yio si korira nyin. 12 Emi o si ma rìn lãrin nyin, emi o si ma ṣe Ọlọrun nyin, ẹnyin o si ma ṣe enia mi. 13 Emi li OLUWA Ọlọrun nyin ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ki ẹnyin ki o máṣe wà li ẹrú wọn; emi si ti dá ìde àjaga nyin, mo si mu nyin rìn lõrogangan.

Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn

14 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, ti ẹ kò si ṣe gbogbo ofin wọnyi; 15 Bi ẹnyin ba si gàn ìlana mi, tabi bi ọkàn nyin ba korira idajọ mi, tobẹ̃ ti ẹnyin ki yio fi ṣe gbogbo ofin mi, ṣugbọn ti ẹnyin dà majẹmu mi; 16 Emi pẹlu yio si ṣe eyi si nyin; emi o tilẹ rán ẹ̀ru si nyin, àrun-igbẹ ati òjojo gbigbona, ti yio ma jẹ oju run, ti yio si ma mú ibinujẹ ọkàn wá: ẹnyin o si fun irugbìn nyin lasan, nitoripe awọn ọtá nyin ni yio jẹ ẹ. 17 Emi o si kọ oju mi si nyin, a o si pa nyin niwaju awọn ọtá nyin: awọn ti o korira nyin ni yio si ma ṣe olori nyin; ẹnyin o si ma sá nigbati ẹnikan kò lé nyin. 18 Ninu gbogbo eyi, bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, nigbana li emi o jẹ nyin ni ìya ni ìgba meje si i nitori ẹ̀ṣẹ nyin. 19 Emi o si ṣẹ́ igberaga agbara nyin; emi o si sọ ọrun nyin dabi irin, ati ilẹ nyin dabi idẹ: 20 Ẹnyin o si lò agbara nyin lasan: nitoriti ilẹ nyin ki yio mú ibisi rẹ̀ wá, bẹ̃ni igi ilẹ nyin ki yio so eso wọn. 21 Bi ẹnyin ba si nrìn lodi si mi, ti ẹnyin kò si gbọ́ ti emi; emi o si mú iyọnu ìgba meje wá si i lori nyin gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ nyin. 22 Emi o si rán ẹranko wá sinu nyin pẹlu, ti yio ma gbà nyin li ọmọ, ti yio si ma run nyin li ẹran-ọ̀sin, ti yio si mu nyin dinkù; opópo nyin yio si dahoro. 23 Bi ẹnyin kò ba gbà ìkilọ mi nipa nkan wọnyi, ṣugbọn ti ẹnyin o ma rìn lodi si mi; 24 Nigbana li emi pẹlu yio ma rìn lodi si nyin, emi o si jẹ nyin ni ìya si i ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin. 25 Emi o si mú idà wá sori nyin, ti yio gbà ẹsan majẹmu mi; a o si kó nyin jọ pọ̀ ninu ilu nyin, emi o rán ajakalẹ-àrun sãrin nyin; a o si fi nyin lé ọtá lọwọ. 26 Nigbati mo ba ṣẹ́ ọpá onjẹ nyin, obinrin mẹwa yio yan àkara nyin ninu àro kan, ìwọ̀n ni nwọn o si ma fi fun nyin li àkara nyin: ẹnyin o si ma jẹ, ẹ ki yio si yó. 27 Ninu gbogbo eyi bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, ti ẹ ba si nrìn lodi si mi; 28 Nigbana li emi o ma rìn lodi si nyin pẹlu ni ikannu; emi pẹlu yio si nà nyin ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin. 29 Ẹnyin o si jẹ ẹran-ara awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati ẹran-ara awọn ọmọ nyin obinrin li ẹnyin o jẹ. 30 Emi o si run ibi giga nyin wọnni, emi o si ke ere nyin lulẹ, emi o si wọ́ okú nyin sori okú oriṣa nyin; ọkàn mi yio si korira nyin. 31 Emi o si sọ ilu nyin di ahoro, emi o si sọ ibi mimọ́ nyin di ahoro, emi ki yio gbọ́ adùn õrùn didùn nyin mọ́. 32 Emi o si sọ ilẹ na di ahoro: ẹnu yio si yà awọn ọtá nyin ti ngbé inu rẹ̀ si i. 33 Emi o si tú nyin ká sinu awọn orilẹ-ède, emi o si yọ idà tì nyin lẹhin: ilẹ nyin yio si di ahoro, ati ilu nyin yio di ahoro. 34 Nigbana ni ilẹ na yio ní isimi rẹ̀, ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀, ẹnyin o si wà ni ilẹ awọn ọtá nyin; nigbana ni ilẹ yio simi, ti yio si ní isimi rẹ̀. 35 Ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀ ni yio ma simi; nitoripe on kò simi li ọjọ́-isimi nyin, nigbati ẹnyin ngbé inu rẹ̀. 36 Ati lara awọn ti o kù lãye ninu nyin, li emi o rán ijàiya si ọkàn wọn ni ilẹ awọn ọtá wọn: iró mimì ewé yio si ma lé wọn; nwọn o si sá, bi ẹni sá fun idà; nwọn o si ma ṣubu nigbati ẹnikan kò lepa. 37 Nwọn o si ma ṣubulù ara wọn, bi ẹnipe niwaju idà, nigbati kò sí ẹniti nlepa: ẹnyin ki yio si lí agbara lati duro niwaju awọn ọtá nyin. 38 Ẹnyin o si ṣegbé ninu awọn orilẹ-ède, ilẹ awọn ọtá nyin yio si mú nyin jẹ. 39 Ati awọn ti o kù ninu nyin yio si joro ninu ẹ̀ṣẹ wọn ni ilẹ awọn ọtá nyin; ati nitori ẹ̀ṣẹ awọn baba wọn pẹlu ni nwọn o ma joro pẹlu wọn. 40 Bi nwọn ba si jẹwọ irekọja wọn, ati irekọja awọn baba wọn, pẹlu ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, ati pẹlu nitoripe nwọn ti rìn lodi si mi; 41 Emi pẹlu rìn lodi si wọn, mo si mú wọn wá si ilẹ awọn ọtá wọn: njẹ bi àiya wọn alaikọlà ba rẹ̀silẹ, ti nwọn ba si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn; 42 Nigbana li emi o ranti majẹmu mi pẹlu Jakobu; ati majẹmu mi pẹlu Isaaki, ati majẹmu mi pẹlu Abrahamu li emi o ranti; emi o si ranti ilẹ na. 43 Nwọn o si fi ilẹ na silẹ, on o si ní isimi rẹ̀, nigbati o ba di ahoro li aisí wọn; nwọn o si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn: nitoripe, ani nitoripe nwọn gàn idajọ mi, ati ọkàn wọn korira ìlana mi. 44 Ṣugbọn sibẹ̀ ninu gbogbo eyina, nigbati nwọn ba wà ni ilẹ awọn ọtá wọn, emi ki yio tà wọn nù, bẹ̃li emi ki yio korira wọn, lati run wọn patapata, ati lati dà majẹmu mi pẹlu wọn: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun wọn: 45 Ṣugbọn nitori wọn emi o ranti majẹmu awọn baba nla wọn, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá li oju awọn orilẹ-ède, ki emi ki o le ma ṣe Ọlọrun wọn: Emi li OLUWA. 46 Wọnyi ni ìlana ati idajọ, ati ofin ti OLUWA dásilẹ, lãrin on ati awọn ọmọ Israeli li òke Sinai nipa ọwọ́ Mose.

Lefitiku 27

Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Ohun tí a fi fún OLUWA

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati enia kan ba jẹ́ ẹjẹ́ pataki kan, ki awọn enia na ki o jẹ́ ti OLUWA gẹgẹ bi idiyelé rẹ. 3 Idiyelé rẹ fun ọkunrin yio si jẹ́ lati ẹni ogún ọdún lọ titi di ọgọta ọdún, idiyelé rẹ yio si jẹ́ ãdọta ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́. 4 Bi on ba si ṣe obinrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ọgbọ̀n ṣekeli. 5 Bi o ba si ṣepe lati ọmọ ọdún marun lọ, titi di ẹni ogún ọdún, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ogún ṣekeli fun ọkunrin, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa. 6 Bi o ba si ṣepe lati ọmọ oṣù kan lọ titi di ọmọ ọdún marun, njẹ ki idiyelé rẹ fun ọkunrin ki o jẹ́ ṣekeli fadakà marun, ati fun obinrin, idiyelé rẹ yio jẹ ṣekeli fadakà mẹta. 7 Bi o ba si ṣe lati ẹni ọgọta ọdún lọ tabi jù bẹ̃ lọ; bi o ba jẹ́ ọkunrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ṣekeli mẹdogun, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa. 8 Ṣugbọn bi on ba ṣe talakà jù idiyele lọ, njẹ ki o lọ siwaju alufa, ki alufa ki o diyelé e; gẹgẹ bi agbara ẹniti o jẹ́ ẹjẹ́ na ni ki alufa ki o diyelé e. 9 Bi o ba si ṣepe ẹran ni, ninu eyiti enia mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ OLUWA wá, gbogbo eyiti ẹnikẹni ba múwa ninu irú nkan wọnni fun OLUWA ki o jẹ́ mimọ́. 10 On kò gbọdọ pa a dà, bẹ̃ni kò gbọdọ pàrọ rẹ̀, rere fun buburu, tabi buburu fun rere: bi o ba ṣepe yio pàrọ rẹ̀ rára, ẹran fun ẹran, njẹ on ati ipàrọ rẹ̀ yio si jẹ́ mimọ́. 11 Bi o ba si ṣepe ẹran alaimọ́ kan ni, ninu eyiti nwọn kò mú rubọ si OLUWA, njẹ ki o mú ẹran na wá siwaju alufa: 12 Ki alufa ki o si diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi iwọ alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri. 13 Ṣugbọn bi o ba fẹ́ rà a pada rára, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ kún idiyelé rẹ. 14 Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri. 15 Ati bi ẹniti o yà a sọ̀tọ ba nfẹ́ rà ile rẹ̀ pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ̀ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀. 16 Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà. 17 Bi o ba yà oko rẹ̀ sọ̀tọ lati ọdún jubeli wá, gẹgẹ bi idiyelé rẹ bẹ̃ni ki o ri. 18 Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ. 19 Ati bi ẹniti o yà oko na sọtọ̀ ba fẹ́ rà a pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀. 20 Bi on kò ba si fẹ́ rà oko na pada, tabi bi o ba ti tà oko na fun ẹlomiran, ki a máṣe rà a pada mọ́. 21 Ṣugbọn oko na, nigbati o ba yọ li ọdún jubeli, ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, bi oko ìya-sọtọ; iní rẹ̀ yio jẹ́ ti alufa. 22 Ati bi ẹnikan ba yà oko kan sọ̀tọ fun OLUWA ti on ti rà, ti ki iṣe ninu oko ti o jogún; 23 Njẹ ki alufa ki o ṣìro iye idiyelé rẹ̀ fun u, titi di ọdún jubeli: ki on ki o si fi idiyelé rẹ li ọjọ́ na, bi ohun mimọ́ fun OLUWA. 24 Li ọdún jubeli ni ki oko na ki o pada sọdọ ẹniti o rà a, ani sọdọ rẹ̀ ti ẹniti ini ilẹ na iṣe. 25 Ki gbogbo idiyelé rẹ ki o si jẹ́ gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́: ogún gera ni ṣekeli kan. 26 Kìki akọ́bi ẹran, ti iṣe akọ́bi ti OLUWA, li ẹnikan kò gbọdọ yàsọtọ; ibaṣe akọmalu, tabi agutan: ti OLUWA ni. 27 Bi o ba ṣe ti ẹran alaimọ́ ni, njẹ ki o gbà a silẹ gẹgẹ bi idiyelé rẹ, ki o si fi idamarun rẹ̀ kún u: tabi bi kò ba si rà a pada, njẹ ki a tà a, gẹgẹ bi idiyelé rẹ. 28 Ṣugbọn kò sí ohun ìyasọtọ kan, ti enia ba yàsọtọ fun OLUWA ninu ohun gbogbo ti o ní, ati enia, ati ẹran, ati ilẹ-iní rẹ̀, ti a gbọdọ tà tabi ti a gbọdọ rà pada: ohun gbogbo ti a ba yàsọtọ mimọ́ julọ ni si OLUWA. 29 Kò sí ẹni ìyasọtọ ti a ba yàsọtọ ninu enia, ti a le gbàsilẹ; pipa ni ki a pa a. 30 Ati gbogbo idamẹwa ilẹ na ibaṣe ti irugbìn ilẹ na, tabi ti eso igi, ti OLUWA ni: mimọ́ ni fun OLUWA. 31 Bi o ba ṣepe enia ba ràpada rára ninu ohun idamẹwa rẹ̀, ki o si fi idamarun kún u. 32 Ati gbogbo idamẹwa ọwọ́ ẹran, tabi ti agbo-ẹran, ani ohunkohun ti o ba kọja labẹ ọpá, ki ẹkẹwa ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA. 33 Ki o máṣe yẹ̀ ẹ wò bi o jẹ́ rere tabi buburu, bẹ̃li on kò gbọdọ pàrọ rẹ̀: bi o ba si ṣepe o pàrọ rẹ̀ rára, njẹ ati on ati ipàrọ rẹ̀ yio jẹ́ mimọ́; a kò gbọdọ rà a pada. 34 Wọnyi li ofin, ti OLUWA palaṣẹ fun Mose fun awọn ọmọ Israeli li òke Sinai.

Numeri 1

1 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdún keji, ti nwọn jade lati ilẹ Egipti wá, wipe, 2 Ẹ kaye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, olukuluku ọkunrin, nipa ori wọn; 3 Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli, iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn. 4 Ki ọkunrin kọkan lati inu olukuluku ẹ̀ya ki o si wà pẹlu nyin; ki olukuluku jẹ́ olori ile awọn baba rẹ̀. 5 Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin na ti yio duro pẹlu nyin: ti Reubeni; Elisuri ọmọ Ṣedeuri. 6 Ti Simeoni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai. 7 Ti Juda; Naṣoni ọmọ Amminadabu. 8 Ti Issakari; Netaneli ọmọ Suari. 9 Ti Sebuluni; Eliabu ọmọ Heloni. 10 Ti awọn ọmọ Josefu: ti Efraimu; Elliṣama ọmọ Ammihudu: ti Manasse; Gamalieli ọmọ Pedasuru. 11 Ti Benjamini; Abidani ọmọ Gideoni. 12 Ti Dani; Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 13 Ti Aṣeri; Pagieli ọmọ Okanri. 14 Ti Gadi; Eliasafu ọmọ Deueli. 15 Ti Naftali; Ahira ọmọ Enani. 16 Wọnyi li awọn ti a yàn ninu ijọ, olori ẹ̀ya awọn baba wọn, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ni Israeli. 17 Ati Mose ati Aaroni mú awọn ọkunrin wọnyi ti a pè li orukọ: 18 Nwọn si pè gbogbo ijọ enia pọ̀ li ọjọ́ kini oṣù keji, nwọn si pìtan iran wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, nipa ori wọn. 19 Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li o si kaye wọn ni ijù Sinai. 20 Ati awọn ọmọ Reubeni, akọ́bi Israeli, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 21 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Reubeni, o jẹ́ ẹgba mẹtalelogun o le ẹdẹgbẹta. 22 Ti awọn ọmọ Simeoni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 23 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Simeoni, o jẹ́ ẹgba mọkandilọgbọ̀n o le ẹdegbeje. 24 Ti awọn ọmọ Gadi, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 25 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Gadi, o jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ. 26 Ti awọn ọmọ Juda, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 27 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Juda, o jẹ́ ẹgbã mẹtadilogoji o le ẹgbẹ̀ta. 28 Ti awọn ọmọ Issakari, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 29 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Issakari, o jẹ́ ẹgbã mẹtadilọgbọ̀n o le irinwo. 30 Ti awọn ọmọ Sebuluni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 31 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Sebuluni, o jẹ́ ẹgbã mejidilọgbọ̀n o le egbeje. 32 Ti awọn ọmọ Josefu, eyinì ni, ti awọn ọmọ Efraimu, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 33 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Efraimu, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. 34 Ti awọn ọmọ Manasse, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 35 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Manasse, o jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le igba. 36 Ti awọn ọmọ Benjamini, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 37 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Benjamini, o jẹ́ ẹgba mẹtadilogun o le egbeje. 38 Ti awọn ọmọ Dani, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 39 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Dani, o jẹ́ ẹgbã mọkanlelọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin. 40 Ti awọn ọmọ Aṣeri, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 41 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Aṣeri, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ. 42 Ti awọn ọmọ Naftali, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 43 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Naftali, o jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje. 44 Wọnyi li awọn ti a kà, ti Mose ati Aaroni kà, ati awọn olori Israeli, ọkunrin mejila: olukuluku wà fun ile awọn baba rẹ̀. 45 Bẹ̃ni gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli, nipa ile baba wọn, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli; 46 Ani gbogbo awọn ti a kà o jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ enia o le egbejidilogun din ãdọta. 47 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ẹ̀ya baba wọn li a kò kà mọ́ wọn. 48 Nitoripe OLUWA ti sọ fun Mose pe, 49 Kìki ẹ̀ya Lefi ni ki iwọ ki o máṣe kà, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe kà iye wọn mọ́ awọn ọmọ Israeli. 50 Ṣugbọn ki iwọ ki o yàn awọn ọmọ Lefi sori agọ́ érí, ati sori gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati sori ohun gbogbo ti iṣe tirẹ̀: awọn ni ki o ma rù agọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀; awọn ni yio si ma ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀, ki nwọn ki o si dó yi agọ́ na ká. 51 Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, ki awọn ọmọ Lefi ki o tú u palẹ: nigbati nwọn o ba si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e duro: alejó ti o ba sunmọtosi, pipa ni. 52 Ki awọn ọmọ Israeli ki o si pa agọ́ wọn, olukuluku ni ibudó rẹ̀, ati olukuluku lẹba ọpagun rẹ̀, gẹgẹ bi ogun wọn. 53 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o dó yi agọ́ erí na ká, ki ibinu ki o má ba si lara ijọ awọn ọmọ Israeli: ki awọn ọmọ Lefi ki o si ma ṣe itọju agọ́ ẹrí na. 54 Bayi ni awọn ọmọ Israeli si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.

Numeri 2

Ètò Pípa Àgọ́ Ní Ẹlẹ́yà-mẹ̀yà

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 2 Ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o pa agọ́ rẹ̀ lẹba ọpagun rẹ̀, pẹlu asia ile baba wọn: ki nwọn ki o pagọ́ kọjusi agọ́ ajọ yiká. 3 Ki awọn ti iṣe ti ọpagun ibudó Juda ki o dó ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn, gẹgẹ bi ogun wọn: Naṣoni ọmọ Amminadabu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Juda. 4 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogoji o le ẹgbẹta. 5 Ati awọn ti o pagọ́ gbè e ki o jẹ́ ẹ̀ya Issakari: Netaneli ọmọ Suari yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Issakari: 6 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilọgbọ̀n o le irinwo. 7 Ati ẹ̀ya Sebuluni: Eliabu ọmọ Heloni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Sebuluni: 8 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejidilọgbọ̀n o le egbeje. 9 Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Juda jẹ́ ẹgba mẹtalelãdọrun o le irinwo, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn yi ni yio kọ́ ṣí. 10 Ni ìha gusù ni ki ọpagun ibudó Reubeni ki o wà, gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuru ọmọ Ṣedeuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Reubeni: 11 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtalelogun o le ẹdẹgbẹta. 12 Ati awọn ti o pagọ́ tì i ki o jẹ́ ẹ̀ya Simeoni: Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Simeoni: 13 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkandilọgbòn o le ẹdegbeje. 14 Ati ẹ̀ya Gadi: Eliasafu ọmọ Deueli ni yio si jẹ́ olori ogun ti awọn ọmọ Gadi: 15 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ. 16 Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Reubeni jẹ́ ẹgba marundilọgọrin o le ãdọtalelegbeje, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikeji. 17 Nigbana ni agọ́ ajọ yio si ṣí, pẹlu ibudó, awọn ọmọ Lefi lãrin ibudó: bi nwọn ti dó bẹ̃ni nwọn o ṣí, olukuluku ni ipò rẹ̀, pẹlu ọpagun wọn. 18 Ni ìha ìwọ-õrùn ni ki ọpagun ibudó Efraimu ki o wà gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Efraimu: 19 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. 20 Ati lẹba rẹ̀ ni ki ẹ̀ya Manasse ki o wà: Gamalieli ọmọ Pedahsuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Manasse: 21 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le igba. 22 Ati ẹ̀ya Benjamini: Abidani ọmọ Gideoni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Benjamini: 23 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogun o le egbeje. 24 Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Efraimu, jẹ́ ẹgba mẹrinlelãdọta o le ọgọrun, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikẹta. 25 Ọpagun ibudó Dani ni ki o wà ni ìha ariwa gẹgẹ bi ogun wọn: Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Dani. 26 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkanlelọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin. 27 Ati awọn ti o dó tì i ni ki o jẹ́ ẹ̀ya Aṣeri: Pagieli ọmọ Okrani yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Aṣeri: 28 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ. 29 Ati ẹ̀ya Naftali: Ahira ọmọ Enani yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Naftali: 30 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje. 31 Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Dani, jẹ́ ẹgba mejidilọgọrin o le ẹgbẹjọ. Awọn ni yio ṣí kẹhin pẹlu ọpagun wọn. 32 Eyi li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ile baba wọn: gbogbo awọn ti a kà ni ibudó gẹgẹ bi ogun wọn, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ o le egbejidilogun din ãdọta. 33 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi li a kò kà mọ́ awọn ọmọ Israeli; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 34 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose: bẹ̃ni nwọn si dó pẹlu ọpagun wọn, bẹ̃ni nwọn si nṣí, olukuluku nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn.

Numeri 3

Àwọn Ọmọ Aaroni

1 WỌNYI si li awọn iran Aaroni ati Mose li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ li òke Sinai. 2 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Aaroni; Nadabu akọ́bi, ati Abihu, Eleasari, ati Itamari. 3 Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa ti a ta oróro si wọn li ori, ẹniti o yàsọtọ lati ma ṣe iranṣẹ ni ipò iṣẹ alufa. 4 Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn.

Wọ́n yan Àwọn Ọmọ Lefi láti máa ṣe Iranṣẹ fún Àwọn Àlùfáà

5 OLUWA si sọ fun Mose pe, 6 Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u. 7 Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ gbogbo ajọ niwaju agọ́ ajọ, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́. 8 Ki nwọn ki o si ma pa gbogbo ohun-èlo agọ́ ajọ mọ́, ati aṣẹ awọn ọmọ Israeli, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́. 9 Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli. 10 Ki iwọ ki o si yàn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma duro si iṣẹalufa wọn: alejò ti o ba si sunmọtosi pipa ni ki a pa a. 11 OLUWA si sọ fun Mose pe, 12 Ati emi, kiyesi i, emi ti gbà awọn ọmọ Lefi kuro lãrin awọn ọmọ Israeli ni ipò gbogbo akọ́bi ti o ṣí inu ninu awọn ọmọ Israeli; nitorina ti emi li awọn ọmọ Lefi iṣe: 13 Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA.

Kíka Àwọn Ọmọ Lefi

14 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai pe, 15 Kaye awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn: gbogbo ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ni ki iwọ ki o kà wọn. 16 Mose si kà wọn gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, bi a ti paṣẹ fun u. 17 Wọnyi si ni awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi orukọ wọn; Gerṣoni, ati Kohati, ati Merari. 18 Wọnyi si ni orukọ awọn ọmọ Gerṣoni gẹgẹ bi idile wọn; Libni ati Ṣimei. 19 Ati awọn ọmọ Kohati gẹgẹ bi idile wọn: Amramu, ati Ishari, Hebroni, ati Usieli. 20 Ati awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn; Mali, ati Muṣi. Wọnyi ni awọn idile Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn. 21 Ti Gerṣoni ni idile awọn ọmọ Libni, ati idile awọn ọmọ Ṣimei; wọnyi ni idile awọn ọmọ Gerṣoni. 22 Awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin, lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani iye awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbata o le ẹdẹgbẹjọ. 23 Awọn idile awọn ọmọ Gerṣoni ni ki o dó lẹhin agọ́ ni ìha ìwọ-õrùn. 24 Ati Eliasafu ọmọ Laeli ni ki o ṣe olori ile baba awọn ọmọ Gerṣoni. 25 Ati itọju awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ ni, Agọ́, ibori rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ti ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, 26 Ati aṣọ isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọtita ti ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́, ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn rẹ̀ fun gbogbo iṣẹ-ìsin rẹ̀. 27 Ati ti Kohati ni idile awọn ọmọ Amramu, ati idile ti awọn ọmọ Ishari, ati idile ti awọn ọmọ Hebroni, ati idile ti awọn ọmọ Usieli: wọnyi ni idile awọn ọmọ Kohati. 28 Gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrin o le ẹgbẹta, ti nṣe itọju ibi-mimọ́. 29 Awọn idile ti awọn ọmọ Kohati ni ki o pagọ́ lẹba agọ́ si ìha gusù. 30 Ati Elisafani ọmọ Usieli ni ki o ṣe olori ile baba awọn idile awọn ọmọ Kohati. 31 Apoti, ati tabeli, ati ọpá-fitila, ati pẹpẹ wọnni, ati ohun-èlo ibi-mimọ́, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ alufa, ati aṣọ-tita, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin rẹ̀, ni yio jẹ́ ohun itọju wọn. 32 Eleasari ọmọ Aaroni alufa ni yio si ṣe olori awọn olori awọn ọmọ Lefi, on ni yio si ma ṣe itọju awọn ti nṣe itọju ibi-mimọ́. 33 Ti Merari ni idile awọn ọmọ Mali, ati idile awọn ọmọ Musi: wọnyi ni idile Merari. 34 Ati awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin, lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ọgbọkanlelọgbọ̀n. 35 Ati Surieli ọmọ Abihaili ni ki o ṣe olori ile baba awọn idile Merari; ki nwọn ki o dó ni ìhà agọ́ si ìhà ariwa. 36 Iṣẹ itọju awọn ọmọ Merari yio si jẹ́ apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo ìsin rẹ̀; 37 Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn. 38 Ṣugbọn awọn ti o pagọ́ niwaju agọ́ na, si ìha ìla-õrùn, ani niwaju agọ́ ajọ si ìha ìla-õrùn ni, ki o jẹ́ Mose, ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn nṣe itọju ibi-mimọ́, fun itọju awọn ọmọ Israeli; alejò ti o ba si sunmọtosi pipa li a o pa a. 39 Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni kà nipa aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi idile wọn, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mọkanla,

Àwọn Ọmọ Lefi Rọ́pò Àwọn Àkọ́bí

40 OLUWA si sọ fun Mose pe, Kà gbogbo awọn akọ́bi ọkunrin awọn ọmọ Israeli lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ki o si gbà iye orukọ wọn. 41 Ki iwọ ki o si gbà awọn ọmọ Lefi fun mi (Emi li OLUWA) ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli; ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi, ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli. 42 Mose si kà gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, bi OLUWA ti paṣẹ fun u. 43 Ati gbogbo awọn akọ́bi ọkunrin nipa iye orukọ, lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ ninu eyiti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkanla o le ọrinlugba o din meje. 44 OLUWA si sọ fun Mose pe, 45 Gbà awọn ọmọ Lefi ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi nipò ohun-ọ̀sin wọn; awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi; Emi li OLUWA. 46 Ati fun ìrapada awọn ọrinlugba din meje ti awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ti nwọn fi jù awọn ọmọ Lefi lọ, 47 Ani ki o gbà ṣekeli marun-marun li ori ẹni kọkan, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́ ni ki o gbà wọn; (ogun gera ni ṣekeli kan): 48 Ki o si fi ninu owo na, ani owo ìrapada ti o lé ninu wọn, fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀. 49 Mose si gbà owo ìrapada lọwọ awọn ti o lé lori awọn ti a fi awọn ọmọ Lefi rasilẹ: 50 Lọwọ awọn akọ́bi awọn ọmọ Israeli li o gbà owo na; egbeje ṣekeli o din marundilogoji, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́: 51 Mose si fi owo awọn ti a rapada fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Numeri 4

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi–Ìdílé Kohati

1 OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe, 2 Kà iye awọn ọmọ Kohati kuro ninu awọn ọmọ Lefi, nipa idile wọn, ile baba wọn, 3 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ. 4 Eyi ni yio ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ, niti ohun mimọ́ julọ wọnni: 5 Nigbati ibudó ba si ṣí siwaju, Aaroni o wá, ati awọn ọmọ rẹ̀, nwọn o si bọ́ aṣọ-ikele rẹ̀ silẹ, nwọn o si fi i bò apoti ẹrí; 6 Nwọn o fi awọ seali bò o, nwọn o si nà aṣọ kìki alaró bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá nì bọ̀ ọ. 7 Ati lori tabili àkara ifihàn nì, ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, ki nwọn ki o si fi awopọkọ sori rẹ̀, ati ṣibi ati awokòto, ati ìgo ohun didà: ati àkara ìgbagbogbo nì ki o wà lori rẹ̀: 8 Ki nwọn ki o si nà aṣọ ododó bò wọn, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò o, ki nwọn ki o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. 9 Ki nwọn ki o si mú aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi bò ọpá-fitila nì, ati fitila rẹ̀, ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo oróro rẹ̀, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ rẹ̀. 10 Ki nwọn ki o si fi on ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀ sinu awọ seali, ki nwọn ki o si gbé e lé ori igi. 11 Ati lori pẹpẹ wurà ni ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, nwọn o si fi awọ seali bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. 12 Ki nwọn ki o si kó gbogbo ohunèlo ìsin, ti nwọn fi nṣe iṣẹ-ìsin ninu ibi-mimọ́, ki nwọn ki o si fi wọn sinu aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò wọn, ki nwon ki o si fi wọn kà ori igi. 13 Ki nwọn ki o si kó ẽru kuro lori pẹpẹ, ki nwọn ki o si nà aṣọ elesè-aluko kan bò o. 14 Ki nwọn ki o si fi gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ti nwọn fi ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀ sori rẹ̀, awo iná, ati kọkọrọ ẹran, ati ọkọ́-ẽru, ati awokòto, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na; ki nwọn ki o si nà awọ seali sori rẹ̀, ki nwọn ki o si tẹ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. 15 Nigbati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ba pari ati bò ibi-mimọ́ na tán, ati gbogbo ohun-èlo ibi-mimọ́ na, nigbati ibudó yio ba ṣí siwaju; lẹhin eyinì, li awọn ọmọ Kohati yio wá lati gbé e: ṣugbọn nwọn kò gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ́ kan, ki nwọn ki o má ba kú. Wọnyi li ẹrù awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ. 16 Ohun itọju Eleasari ọmọ Aaroni alufa si ni oróro fitila, ati turari didùn, ati ẹbọ ohunjijẹ ìgbagbogbo, ati oróro itasori, ati itọju agọ́ na gbogbo, ati ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ninu ibi-mimọ́ nì, ati ohun-èlo rẹ̀ na. 17 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 18 Ẹ máṣe ke ẹ̀ya idile awọn ọmọ Kohati kuro lãrin awọn ọmọ Lefi: 19 Ṣugbọn bayi ni ki ẹ ṣe fun wọn, ki nwọn ki o le yè, ki nwọn ki o má ba kú, nigbati nwọn ba sunmọ ohun mimọ́ julọ: ki Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wọnú ilé, ki nwọn si yàn wọn olukuluku si iṣẹ rẹ̀ ati si ẹrù rẹ̀; 20 Ṣugbọn nwọn kò gbọdọ wọle lọ lati wò ohun mimọ́ ni iṣẹju kan, ki nwọn ki o má ba kú.

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi – Ìdílé Geriṣoni

21 OLUWA si sọ fun Mose pe, 22 Kà iye awọn ọmọ Gerṣoni pẹlu, gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn; 23 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki o kaye wọn; gbogbo awọn ti o wọnu-ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ. 24 Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni, lati sìn ati lati rù ẹrù: 25 Awọn ni yio si ma rù aṣọ-ikele agọ́, ati agọ́ ajọ, ibori rẹ̀, ati ibori awọ seali ti mbẹ lori rẹ̀, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ; 26 Ati aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́ ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn wọn, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin wọn, ati ohun gbogbo ti a ṣe fun wọn; bẹ̃ni nwọn o ma sìn. 27 Nipa aṣẹ Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ki gbogbo iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Gerṣoni jẹ́, ni gbogbo ẹrù wọn, ati ni gbogbo iṣẹ-ìsin wọn: ki ẹnyin si yàn wọn si itọju gbogbo ẹrù wọn. 28 Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ: ki itọju wọn ki o si wà li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi – Ìdílé Merari

29 Ati awọn ọmọ Merari, ki iwọ ki o kà wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn; 30 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki iwọ ki o kà wọn, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ́. 31 Eyi si ni itọju ẹrù wọn, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin wọn ninu agọ́ ajo; awọn apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ìhò-ìtẹbọ rẹ̀, 32 Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn, pẹlu ohun-èlo wọn gbogbo, ati pẹlu ohun-ìsin wọn gbogbo: li orukọ li orukọ ni ki ẹnyin ki o kà ohun-èlo ti iṣe itọju ẹrù wọn. 33 Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn gbogbo, ninu agọ́ ajọ, labẹ Itamari ọmọ Aaroni alufa.

Iye Àwọn Ọmọ Lefi

34 Mose ati Aaroni ati awọn olori ijọ awọn enia si kà awọn ọmọ Kohati nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn, 35 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ: 36 Awọn ti a si kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrinla o din ãdọta. 37 Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Kohati, gbogbo awọn ti o le ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose. 38 Awọn ti a si kà ninu awọn ọmọ Gerṣoni, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn, 39 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ, 40 Ani awọn ti a kà ninu wọn, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, jẹ́ ẹgbẹtala o le ọgbọ̀n. 41 Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Gerṣoni, gbogbo awọn ti o ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA. 42 Awọn ti a si kà ni idile awọn ọmọ Merari, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, 43 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ, 44 Ani awọn ti a kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrindilogun. 45 Wọnyi li awọn ti a kà ninu idile awọn ọmọ Merari, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose. 46 Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni ati awọn olori Israeli kà, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn, 47 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wá lati ṣe iṣẹ-ìsin, ati iṣẹ ẹrù ninu agọ́ ajọ, 48 Ani awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbẹtalelẹgbarin o din ogun. 49 Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA li a kà wọn nipa ọwọ́ Mose, olukuluku nipa iṣẹ-ìsin rẹ̀, ati gẹgẹ bi ẹrù rẹ̀: bẹ̃li a ti ọwọ́ rẹ̀ kà wọn, bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Numeri 5

Àwọn Aláìmọ́

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o yọ gbogbo adẹ̀tẹ kuro ni ibudó, ati gbogbo ẹniti o ní isun, ati ẹnikẹni ti o di alaimọ́ nipa okú: 3 Ati ọkunrin ati obinrin ni ki ẹnyin ki o yọ kuro, lẹhin ode ibudó ni ki ẹ fi wọn si; ki nwọn ki o máṣe sọ ibudó wọn di alaimọ́, lãrin eyiti Emi ngbé. 4 Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃, nwọn si yọ wọn sẹhin ibudó: bi OLUWA ti sọ fun Mose, bẹ̃ li awọn ọmọ Israeli ṣe.

Ìjìyà fún Ẹ̀ṣẹ̀

5 OLUWA si sọ fun Mose pe, 6 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba dá ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ti enia ida, ti o ṣe irekọja si OLUWA, ti oluwarẹ̀ si jẹ̀bi; 7 Nigbana ni ki nwọn ki o jẹwọ ẹ̀ṣẹ ti nwọn ṣẹ̀: ki o si san ẹsan ẹ̀ṣẹ rẹ̀ li oju-owo, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun ẹniti on jẹbi rẹ̀. 8 Bi o ba si ṣepe ọkunrin na kò ní ibatan kan lati san ẹsan ẹ̀ṣẹ na fun, ki a san ẹsan na fun OLUWA, ani fun alufa; pẹlu àgbo ètutu, ti a o fi ṣètutu fun u. 9 Ati gbogbo ẹbọ agbesọsoke ohun mimọ́ gbogbo ti awọn ọmọ Israeli, ti nwọn mú tọ̀ alufa wá, yio jẹ́ tirẹ̀. 10 Ati ohun mimọ́ olukuluku, ki o jẹ́ tirẹ̀: ohunkohun ti ẹnikan ba fi fun alufa ki o jẹ́ tirẹ̀.

Àwọn Aya Tí Ọkọ Wọn Bá Fura sí

11 OLUWA si sọ fun Mose pe, 12 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi aya ọkunrin kan ba yapa, ti o si ṣẹ̀ ẹ, 13 Ti ọkunrin kan si bá a dàpọ, ti o si pamọ́ fun ọkọ rẹ̀, ti o si sin, ti on si di ẹni ibàjẹ́, ti kò si sí ẹlẹri kan si i, ti a kò si mú u mọ ọ, 14 Ti ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ti obinrin na si di ẹni ibàjẹ́: tabi bi ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ṣugbọn ti on kò di ẹni ibàjẹ́: 15 Nigbana ni ki ọkunrin na ki o mú aya rẹ́ tọ̀ alufa wá, ki o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun u, idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun barle; ki o máṣe dà oróro sori rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sinu rẹ̀; nitoripe ẹbọ ohunjijẹ owú ni, ẹbọ ohunjijẹ iranti ni, ti nmú irekọja wá si iranti. 16 Ki alufa na ki o si mú u sunmọtosi, ki o mu u duro niwaju OLUWA: 17 Ki alufa ki o si bù omi mimọ́ ninu ohun-èlo amọ̀ kan; ati ninu erupẹ ti mbẹ ni ilẹ agọ́ ni ki alufa ki o bù, ki o si fi i sinu omi na: 18 Ki alufa ki o si mu obinrin na duro niwaju OLUWA, ki o si ṣí ibori obinrin na, ki o si fi ẹbọ ohunjijẹ iranti na lé e li ọwọ́, ti iṣe ẹbọ ohunjijẹ owú: ati li ọwọ́ alufa ni omi kikorò ti imú egún wá yio wà. 19 Alufa na yio si mu u bura, yio si wi fun obinrin na pe, Bi ọkunrin kò ba bá ọ dàpọ, bi iwọ kò ba si yàsapakan si ìwa-aimọ́, labẹ ọkọ rẹ, ki iwọ ki o yege omi kikorò yi ti imú egún wá: 20 Ṣugbọn bi iwọ ba yapa, labẹ ọkọ rẹ, ti iwọ si di ẹni ibàjẹ́, ti ọkunrin miran si bá ọ dàpọ laiṣe ọkọ rẹ: 21 Nigbana ni ki alufa ki o mu ki obinrin na fi èpe bura, ki alufa ki o si wi fun obinrin na pe, Ki OLUWA ki o sọ ọ di ẹni egún, ati ẹni ifire ninu awọn enia rẹ, nigbati OLUWA ba mu itan rẹ rà, ti o si mu inu rẹ wú; 22 Ati omi yi ti nmú egún wá ki o wọ̀ inu rẹ lọ, lati mu inu rẹ wú, ati lati mu itan rẹ rà: ki obinrin na ki o si wipe, Amin, amin. 23 Ki alufa ki o si kọ egún yi sinu iwé, ki o si fi omi kikorò na wẹ̀ ẹ nù: 24 Ki o si jẹ ki obinrin na ki o mu omi kikorò na ti imú egún wá: omi na ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò. 25 Nigbana li alufa yio gbà ẹbọ ohunjijẹ owú na li ọwọ́ obinrin na, yio si fì ẹbọ ohunjijẹ na niwaju OLUWA, yio si ru u lori pẹpẹ: 26 Ki alufa ki o si bù ikunwọ kan ninu ẹbọ ohunjijẹ na, ani iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ, lẹhin eyinì ki o jẹ ki obinrin na mu omi na. 27 Nigbati o ba si mu omi na tán, yio si ṣe, bi o ba ṣe ẹni ibàjẹ́, ti o si ṣẹ̀ ọkọ rẹ̀, omi ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò, inu rẹ̀, a si wú, itan rẹ̀ a si rà: obinrin na a si di ẹni egún lãrin awọn enia rẹ̀. 28 Bi obinrin na kò ba si ṣe ẹni ibàjẹ́, ṣugbọn ti o mọ́; njẹ yio yege, yio si lóyun. 29 Eyi li ofin owú, nigbati obinrin kan ba yapa, labẹ ọkọ rẹ̀, ti o si di ẹni ibàjẹ́; 30 Tabi nigbati ẹmi owú ba dé si ọkọ kan, ti o ba si njowú obinrin rẹ̀; nigbana yio mu obinrin na duro niwaju OLUWA, ki alufa ki o si ṣe gbogbo ofin yi si i. 31 Nigbana li ọkunrin na yio bọ́ kuro ninu aiṣedede, obinrin na yio si rù aiṣedede ara rẹ̀.

Numeri 6

Òfin fún Àwọn Nasiri

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba yà ara wọn sapakan lati ṣe ileri ti Nasiri, lati yà ara wọn si OLUWA: 3 Ki o yà ara rẹ̀ kuro ninu ọti-waini tabi ọti lile; ki o má si ṣe mu ọti-waini kikan, tabi ọti lile ti o kan, ki o má si ṣe mu ọti eso-àjara kan, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ eso-àjara tutù tabi gbigbẹ. 4 Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ni ki o gbọdọ jẹ ohun kan ti a fi eso-àjara ṣe, lati kóro rẹ̀ titi dé ẽpo rẹ̀. 5 Ni gbogbo ọjọ́ ileri ìyasapakan rẹ̀, ki abẹ kan máṣe kàn a li ori: titi ọjọ́ wọnni yio fi pé, ninu eyiti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, ki o jẹ́ mimọ́, ki o si jẹ ki ìdi irun ori rẹ̀ ki o ma dàgba. 6 Ni gbogbo ọjọ́ ti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, on kò gbọdọ sunmọ okú. 7 On kò gbọdọ sọ ara rẹ̀ di alaimọ́ nitori baba rẹ̀, tabi nitori iya rẹ̀, nitori arakunrin rẹ̀, tabi nitori arabinrin rẹ̀, nigbati nwọn ba kú: nitoripe ìyasapakan Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀. 8 Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀, mimọ́ li on fun OLUWA. 9 Bi enia kan ba si kú lojiji lẹba ọdọ rẹ̀, ti o ba si bà ori ìyasapakan rẹ̀ jẹ́; nigbana ni ki o fá ori rẹ̀ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀, ni ijọ́ keje ni ki o fá a. 10 Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: 11 Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun, ki o si ṣètutu fun u, nitoriti o ṣẹ̀ nipa okú, ki o si yà ori rẹ̀ simimọ́ li ọjọ́ na. 12 Ki o si yà ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ simimọ́ si OLUWA, ki o si mú akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹbi: ṣugbọn ọjọ́ ti o ti ṣaju yio di asan, nitoripe ìyasapakan rẹ̀ bàjẹ́. 13 Eyi si li ofin ti Nasiri, nigbati ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ba pé: ki a si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: 14 On o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ sisun, ati abo ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan alailabùkun fun ẹbọ alafia. 15 Ati agbọ̀n àkara alaiwu kan, àkara adidùn iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn. 16 Ki alufa ki o mú wọn wá siwaju OLUWA, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ati ẹbọ sisun rẹ̀: 17 Ki o si ru àgbo na li ẹbọ alafia si OLUWA, pẹlu agbọ̀n àkara alaiwu: ki alufa pẹlu ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 18 Ki Nasiri na ki o fá ori ìyasapakan rẹ̀ li ẹnu-ọ̀na agọ́ àjọ, ki o si mú irun ori ìyasapakan rẹ̀ ki o si fi i sinu iná ti mbẹ labẹ ẹbọ alafia na. 19 Ki alufa ki o si mú apá bibọ̀ àgbo na, ati àkara adidùn kan alaiwu kuro ninu agbọ̀n na, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan alaiwu, ki o si fi wọn lé ọwọ́ Nasiri na, lẹhin ìgba ti a fá irun ori ìyasapakan rẹ̀ tán: 20 Ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: mimọ́ li eyi fun alufa na, pẹlu àiya fifì, ati itan agbesọsoke: lẹhin na Nasiri na le ma mu ọti-waini. 21 Eyi li ofin ti Nasiri ti o ṣe ileri, ati ti ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA fun ìyasapakan rẹ̀ li àika eyiti ọwọ́ on le tẹ̀: gẹgẹ bi ileri ti o ṣe, bẹ̃ni ki o ṣe nipa ofin ìyasapakan rẹ̀.

Ibukun Àlùfáà

22 OLUWA si sọ fun Mose pe, 23 Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Bayi li ẹnyin o ma sure fun awọn ọmọ Israeli; ki ẹ ma wi fun wọn pe, 24 Ki OLUWA ki o busi i fun ọ, ki o si pa ọ mọ́: 25 Ki OLUWA ki o mu oju rẹ̀ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣãnu fun ọ: 26 Ki OLUWA ki o ma bojuwò ọ, ki o si ma fun ọ ni alafia. 27 Bayi ni nwọn o fi orukọ mi sara awọn ọmọ Israeli; emi o si busi i fun wọn.

Numeri 7

Ẹbọ Àwọn Olórí

1 OSI ṣe li ọjọ́ na ti Mose gbé agọ́ na ró tán, ti o si ta oróro si i ti o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ na ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ti o si ta oróro si wọn, ti o si yà wọn simimọ́; 2 Ni awọn ijoye Israeli, awọn olori ile baba wọn, awọn olori ẹ̀ya wọnni, ti iṣe olori awọn ti a kà, mú ọrẹ wá: 3 Nwọn si mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju OLUWA, kẹkẹ́-ẹrù mẹfa ti a bò, ati akọmalu mejila; kẹkẹ́-ẹrù kan fun ijoye meji, ati akọmalu kan fun ọkọkan: nwọn si mú wọn wá siwaju agọ́ ajọ. 4 OLUWA si sọ fun Mose pe, 5 Gbà a lọwọ wọn, ki nwọn ki o le jẹ́ ati fi ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ; ki iwọ ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀. 6 Mose si gbà kẹkẹ́-ẹrù wọnni, ati akọmalu, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi. 7 Kẹkẹ́-ẹrù meji ati akọmalu mẹrin, li o fi fun awọn ọmọ Gerṣoni, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn: 8 Ati kẹkẹ́-ẹrù mẹrin ati akọmalu mẹjọ li o fi fun awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn, li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa. 9 Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù. 10 Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na. 11 OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ. 12 Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda. 13 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 14 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 15 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 16 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 17 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Naṣoni ọmọ Amminadabu. 18 Li ọjọ́ keji ni Netaneeli ọmọ Suari, olori ti Issakari mú ọrẹ wá: 19 On múwa fun ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ: 20 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 21 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 22 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 23 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Netaneeli ọmọ Suari. 24 Li ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olori awọn ọmọ Sebuluni: 25 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 26 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 27 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 28 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 29 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Eliabu ọmọ Heloni. 30 Li ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olori awọn ọmọ Reubeni; 31 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ; 32 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 33 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 34 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 35 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri. 36 Li ọjọ́ karun Ṣelumieli ọmọ Suriṣuddai, olori awọn ọmọ Simeoni: 37 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ; 38 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 39 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 40 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 41 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Ṣelumieli ọmọ Ṣuriṣaddai. 42 Li ọjọ́ kẹfa Eliasafu ọmọ Deueli, olori awọn ọmọ Gadi: 43 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ; 44 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 45 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 46 Akọ ewure kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 47 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliasafu ọmọ Deueli. 48 Li ọjọ́ keje Eliṣama ọmọ Ammihudu, olori awọn ọmọ Efraimu: 49 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 50 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 51 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 52 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 53 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliṣama ọmọ Ammihudu. 54 Li ọjọ́ kẹjọ Gamalieli ọmọ Pedasuri, olori awọn ọmọ Manasse: 55 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 56 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 57 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 58 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 59 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Gamalieli ọmọ Pedasuri. 60 Li ọjọ́ kẹsan Abidani ọmọ Gideoni, olori awọn ọmọ Benjamini: 61 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 62 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 63 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 64 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 65 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Abidani ọmọ Gideoni. 66 Li ọjọ́ kẹwá ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olori awọn ọmọ Dani: 67 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ: 68 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 69 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 70 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 71 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 72 Li ọjọ́kọkanla Pagieli ọmọ Okrani, olori awọn ọmọ Aṣeri: 73 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 74 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 75 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 76 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 77 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Pagieli ọmọ Okrani. 78 Li ọjọ́ kejila Ahira ọmọ Enani, olori awọn ọmọ Naftali: 79 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 80 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 81 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 82 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 83 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahira ọmọ Enani. 84 Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, li ọjọ́ ti a ta oróro si i, lati ọwọ́ awọn olori Israeli wá: awopọkọ fadakà mejila, awokòto fadakà mejila, ṣibi wurà mejila: 85 Awopọkọ fadakà kọkan jẹ́ ãdoje ṣekeli: awokòto kọkan jẹ́ ãdọrin: gbogbo ohun-èlo fadakà jẹ́ egbejila ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; 86 Ṣibi wurà jẹ́ mejila, nwọn kún fun turari, ṣibi kọkan jẹ́ ṣekeli mẹwa, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; gbogbo wurà agọ́ na jẹ́ ọgọfa ṣekeli. 87 Gbogbo akọmalu fun ẹbọ sisun jẹ́ ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo mejila, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan mejila, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn: ati akọ ewurẹ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, mejila. 88 Ati gbogbo akọmalu fun ẹbọ ti ẹbọ alafia jẹ́ akọmalu mẹrinlelogun, àgbo ọgọta, obukọ ọgọta, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan ọgọta. Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, lẹhin igbati a ta oróro si i. 89 Nigbati Mose si wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ lati bá a (Ọlọrun) sọ̀rọ, nigbana li o gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si i lati ori itẹ́-ãnu nì wá ti mbẹ lori apoti ẹrí, lati agbedemeji awọn kerubu meji nì wá: o si bá a sọ̀rọ.

Numeri 8

Ìgbékalẹ̀ Fìtílà

1 OLUWA si sọ fun Mose pẹ, 2 Sọ fun Aaroni, ki o si wi fun u pe, Nigbati iwọ ba tàn fitila, ki fitila mejeje na ki o ma tàn imọlẹ lori ọpá-fitila. 3 Aaroni si ṣe bẹ̃; o tàn fitila wọnni lori ọpá-fitila na, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 4 Iṣẹ ọpá-fitila na yi si jẹ̀ ti wurà lilù; titi dé isalẹ rẹ̀, titi dé itanna rẹ̀, o jẹ́ iṣẹ lulù: gẹgẹ bi apẹrẹ ti OLUWA fihàn Mose, bẹ̃li o ṣe ọpá-fitila na.

Ìwẹ̀nùmọ́ ati Ìyàsímímọ́ Àwọn Ọmọ Lefi

5 OLUWA si sọ fun Mose pe, 6 Yọ awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli, ki o si wẹ̀ wọn mọ́. 7 Bayi ni ki iwọ ki o si ṣe si wọn, lati wẹ̀ wọn mọ́; Wọn omi etutu si wọn lara, ki nwọn ki o si fá gbogbo ara wọn, ki nwọn ki o si fọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o si wẹ̀ ara wọn mọ́. 8 Ki nwọn ki o si mú ẹgbọrọ akọmalu kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ani iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati ẹgbọrọ akọmalu keji ni ki iwọ ki o mú fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 9 Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si pe gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli jọ pọ̀: 10 Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA: ki awọn ọmọ Israeli ki o si fi ọwọ́ wọn lé awọn ọmọ Lefi. 11 Ki Aaroni ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, bi ọrẹ fifì lati ọdọ awọn ọmọ Israeli wá, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ-ìsin OLUWA. 12 Ki awọn ọmọ Lefi ki o si fi ọwọ́ wọn lé ori ẹgbọrọ akọmalu wọnni: ki iwọ ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun si OLUWA, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Lefi. 13 Ki iwọ ki o si mu awọn ọmọ Lefi duro niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì fun OLUWA. 14 Bẹ̃ni ki iwọ ki o yà awọn ọmọ Lefi sọ̀tọ kuro lãrin awọn ọmọ Israeli: awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi. 15 Lẹhin eyinì li awọn ọmọ Lefi yio ma wọ̀ inu ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si wẹ̀ wọn mọ́, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì. 16 Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi. 17 Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia ati ti ẹran: li ọjọ́ ti mo kọlù gbogbo akọ̀bi ni ilẹ Egipti ni mo ti yà wọn simimọ́ fun ara mi. 18 Emi si ti gbà awọn ọmọ Lefi dipò gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli. 19 Emi si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ li ọrẹ lati inu awọn ọmọ Israeli wá, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Israeli ninu agọ́ ajọ, ati lati ma ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli: ki àrun má ba sí ninu awọn ọmọ Israeli, nigbati awọn ọmọ Israeli ba sunmọ ibi-mimọ́. 20 Bayi ni Mose, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ṣe si awọn ọmọ Lefi: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe si wọn. 21 Awọn ọmọ Lefi si wẹ̀ ara wọn mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn; Aaroni si mú wọn wá li ọrẹ fifì siwaju OLUWA: Aaroni si ṣètutu fun wọn lati wẹ̀ wọn mọ́. 22 Lẹhin eyinì ni awọn ọmọ Lefi si wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀: bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃ni nwọn ṣe si wọn. 23 OLUWA si sọ fun Mose pe, 24 Eyi ni ti awọn ọmọ Lefi: lati ẹni ọdún mẹdọgbọ̀n lọ ati jù bẹ̃ lọ ni ki nwọn ki o ma wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ. 25 Ati lati ẹni ãdọta ọdún ni ki nwọn ki o ṣiwọ iṣẹ-ìsin, ki nwọn ki o má si ṣe sìn mọ́; 26 Bikoṣepe ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ pẹlu awọn arakunrin wọn ninu agọ́ ajọ, lati ma ṣe itọju, ki nwọn ki o má si ṣe iṣẹ-ìsin mọ́. Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si awọn ọmọ Lefi niti itọju wọn.

Numeri 9

Àjọ Ìrékọjá Keji

1 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, li oṣù kini ọdún keji ti nwọn ti ilẹ Egipti jade wá, wipe, 2 Ki awọn ọmọ Israeli ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ li akokò rẹ̀. 3 Li ọjọ́ kẹrinla oṣù yi, li aṣalẹ, ni ki ẹnyin ki o ma ṣe e li akokò rẹ̀: gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀ gbogbo, ati gẹgẹ bi ìlana rẹ̀ gbogbo, ni ki ẹnyin ki o pa a mọ́. 4 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o ma pa ajọ irekọja mọ́: 5 Nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla, oṣù kini, li aṣalẹ ni ijù Sinai: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe. 6 Awọn ọkunrin kan wà ti nwọn ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́, nwọn kò si le ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ na: nwọn si wá siwaju Mose ati siwaju Aaroni li ọjọ́ na: 7 Awọn ọkunrin na si wi fun u pe, Awa ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́: nitori kili a o ṣe fàsẹhin ti awa ki o le mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ Israeli? 8 Mose si wi fun wọn pe, Ẹ duro na; ki emi ki o le gbọ́ aṣẹ ti OLUWA yio pa niti nyin. 9 OLUWA si sọ fun Mose pe, 10 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ẹnikẹni ninu nyin, tabi ninu iran nyin, ba ti ipa okú di alaimọ́, tabi bi o ba wà li ọ̀na àjo jijìn rére, sibẹ̀ on o pa ajọ irekọja mọ́ fun OLUWA. 11 Li ọjọ́ kẹrinla oṣù keji li aṣalẹ ni ki nwọn ki o pa a mọ́; ki nwọn si fi àkara alaiwu jẹ ẹ ati ewebẹ kikorò: 12 Ki nwọn ki o máṣe kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fọ́ egungun rẹ̀ kan: gẹgẹ bi gbogbo ìlana irekọja ni ki nwọn ki o ṣe e. 13 Ṣugbọn ọkunrin na ti o mọ́ ti kò si sí li ọ̀na àjo, ti o si fàsẹhin lati pa irekọja mọ́, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: nitoriti kò mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀, ọkunrin na yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 14 Bi alejò kan ba si nṣe atipo lọdọ nyin, ti o si nfẹ́ pa irekọja mọ́ fun OLUWA; gẹgẹ bi ìlana irekọja, ati gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀, ni ki o ṣe bẹ̃: ìlana kan ni ki ẹnyin ki o ní, ati fun alejò, ati fun ibilẹ.

Ọ̀wọ̀n Iná

15 Ati li ọjọ́ ti a gbé agọ́ ró awọsanma si bò agọ́ na, eyinì ni, agọ́ ẹrí: ati li alẹ o si hàn lori agọ́ na bi iná, titi o fi di owurọ̀. 16 Bẹ̃li o si ri nigbagbogbo: awọsanma bò o, ati oye iná li oru. 17 Nigbati awọsanma ba ká soke kuro lori agọ́ na, lẹhin na awọn ọmọ Israeli a si ṣí: nibiti awọsanma ba si duro, nibẹ̀ li awọn ọmọ Israeli idó si. 18 Nipa aṣẹ OLUWA awọn ọmọ Israeli a ṣí, nipa aṣẹ OLUWA nwọn a si dó: ni gbogbo ọjọ́ ti awọsanma ba simi lori agọ́ na, nwọn a dó. 19 Nigbati awọsanma ba si pẹ li ọjọ́ pupọ̀ lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a si ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, nwọn ki si iṣi. 20 Nigba miran awọsanma a wà li ọjọ́ diẹ lori agọ́ na; nigbana gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a dó, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a si ṣí. 21 Nigba miran awọsanma a duro lati alẹ titi di owurọ̀; nigbati awọsanma si ṣí soke li owurọ̀, nwọn a ṣí: iba ṣe li ọsán tabi li oru, ti awọsanma ba ká soke, nwọn a ṣí. 22 Bi ijọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan, ti awọsanma ba pẹ lori agọ́ na, ti o simi lé e, awọn ọmọ Israeli a dó, nwọn ki si iṣí: ṣugbọn nigbati o ba ká soke, nwọn a ṣí. 23 Nipa aṣẹ OLUWA nwọn a dó, ati nipa aṣẹ OLUWA nwọn a ṣí: nwọn a ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.

Numeri 10

Àwọn Fèrè Fadaka

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Iwọ ṣe ipè fadakà meji; iṣẹ́-ọnà lilù ni ki o ṣe wọn: iwọ o si ma fi wọn pè ajọ, iwọ o si ma fi wọn ṣí ibudó. 3 Nigbati nwọn ba fun wọn, ki gbogbo ijọ ki o pé sọdọ rẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 4 Bi o ba ṣepe ipè kan ni nwọn fun, nigbana ni ki awọn ijoye, olori ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ki o pejọ sọdọ rẹ. 5 Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha ìla-õrùn ki o ṣí siwaju. 6 Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri nigba keji, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha gusù ki o ṣì siwaju: ki nwọn ki o si fun ipè idagiri ṣíṣi wọn. 7 Ṣugbọn nigbati a o ba pè ijọ pọ̀, ki ẹ fun ipè, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ fun ti idagiri. 8 Awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ni ki o si fun ipè na; ki nwọn ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin ni iran-iran nyin. 9 Bi ẹnyin ba si lọ si ogun ni ilẹ nyin lọ ipade awọn ọtá ti nni nyin lara, nigbana ni ki ẹnyin ki o fi ipè fun idagiri; a o si ranti nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, a o si gbà nyin lọwọ awọn ọtá nyin. 10 Li ọjọ̀ ayọ̀ nyin pẹlu, ati li ajọ nyin, ati ni ìbẹrẹ oṣù nyin, ni ki ẹnyin ki o fun ipè sori ẹbọ sisun nyin, ati sori ẹbọ ti ẹbọ alafia nyin; ki nwọn ki o le ma ṣe iranti fun nyin niwaju Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣí Àgọ́ Wọn

11 O si ṣe li ogun ọjọ́ oṣù keji, li ọdún keji, ni awọsanma ká soke kuro lori agọ́ ẹrí. 12 Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati ijù Sinai; awọsanma na si duro ni ijù Parani. 13 Nwọn si bẹ̀rẹsi iṣí gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose. 14 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Juda si kọ́ ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Naṣoni ọmọ Amminadabu. 15 Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari si ni Netaneli ọmọ Suari. 16 Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni. 17 A si tú agọ́ na palẹ; awọn ọmọ Gerṣoni, ati awọn ọmọ Merari ti nrù agọ́ si ṣí. 18 Ọpágun ibudó Reubeni si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuri ọmọ Ṣedeuri si li olori ogun rẹ̀. 19 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai 20 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli. 21 Awọn ọmọ Kohati ti nrù ohun mimọ́ si ṣí: awọn ti iṣaju a si ma gbé agọ́ ró dè atidé wọn. 22 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Efraimu si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu si li olori ogun rẹ̀. 23 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse ni Gamalieli ọmọ Pedasuri. 24 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni. 25 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Dani, ti o kẹhin gbogbo ibudó, si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 26 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okrani. 27 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali ni Ahira ọmọ Enani. 28 Bayi ni ìrin awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ogun wọn; nwọn si ṣí. 29 Mose si wi fun Hobabu, ọmọ Ragueli ara Midiani, ana Mose pe, Awa nṣí lọ si ibi ti OLUWA ti wi pe, Emi o fi i fun nyin: wá ba wa lọ, awa o ṣe ọ li ore: nitoripe OLUWA sọ̀rọ rere nipa Israeli. 30 On si wi fun u pe, Emi ki yio lọ; ṣugbọn emi o pada lọ si ilẹ mi, ati sọdọ ará mi. 31 O si wipe, Máṣe fi wa silẹ, emi bẹ̀ ọ; iwọ sà mọ̀ pe ni ijù li awa dó si, iwọ o si ma ṣe oju fun wa. 32 Yio si ṣe, bi iwọ ba bá wa lọ, yio si ṣe, pe, orekore ti OLUWA ba ṣe fun wa, on na li awa o ṣe fun ọ.

Àwọn Eniyan náà Tẹ̀síwájú

33 Nwọn si ṣí kuro ni òke OLUWA ni ìrin ijọ́ mẹta: apoti majẹmu OLUWA si ṣiwaju wọn ni ìrin ijọ́ mẹta, lati wá ibi isimi fun wọn. 34 Awọsanma OLUWA mbẹ lori wọn li ọsán, nigbati nwọn ba ṣí kuro ninu ibudó. 35 O si ṣe, nigbati apoti ẹrí ba ṣí siwaju, Mose a si wipe, Dide, OLUWA, ki a si tú awọn ọtá rẹ ká; ki awọn ti o korira rẹ ki o si salọ kuro niwaju rẹ. 36 Nigbati o ba si simi, on a wipe, Pada, OLUWA, sọdọ ẹgbẹgbarun awọn enia Israeli.

Numeri 11

Ibi tí Wọn sọ ní Tabera

1 AWỌN enia na nṣe irahùn, nwọn nsọ ohun buburu li etí OLUWA: nigbati OLUWA si gbọ́ ọ, ibinu rẹ̀ si rú; iná OLUWA si ràn ninu wọn, o si run awọn ti o wà li opin ibudó na. 2 Awọn enia na si kigbe tọ̀ Mose lọ; nigbati Mose si gbadura si OLUWA, iná na si rẹlẹ. 3 O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Tabera: nitoriti iná OLUWA jó lãrin wọn.

Mose Yan Aadọrin Olórí

4 Awọn adalú ọ̀pọ enia ti o wà pẹlu wọn ṣe ifẹkufẹ: awọn ọmọ Israeli pẹlu si tun sọkun wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ? 5 Awa ranti ẹja, ti awa ti njẹ ni Egipti li ọfẹ; ati apálà, ati bàra, ati ewebẹ, ati alubọsa, ati eweko: 6 Ṣugbọn nisisiyi ọkàn wa gbẹ: kò sí ohun kan rára, bikọse manna yi niwaju wa. 7 Manna na si dabi irugbìn korianderi, àwọ rẹ̀ si dabi àwọ okuta-bedeliumu. 8 Awọn enia na a ma lọ kakiri, nwọn a si kó o, nwọn a si lọ̀ ọ ninu ọlọ, tabi nwọn a si gún u ninu odó, nwọn a si sè e ninu ìkoko, nwọn a si fi din àkara: itọwò rẹ̀ si ri bi itọwò àkara oróro. 9 Nigbati ìri ba si sẹ̀ si ibudó li oru, manna a bọ́ si i. 10 Nigbana ni Mose gbọ́, awọn enia nsọkun ni idile wọn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ tirẹ̀: ibinu OLUWA si rú si wọn gidigidi; o si buru loju Mose. 11 Mose si wi fun OLUWA pe, Nitori kini iwọ fi npọ́n iranṣẹ rẹ loju? nitori kili emi kò si ṣe ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ fi dì ẹrù gbogbo enia yi lé mi? 12 Iṣe emi li o lóyun gbogbo enia yi? iṣe emi li o bi wọn, ti iwọ fi wi fun mi pe, Ma gbé wọn lọ li õkanaiya rẹ, bi baba iti igbé ọmọ ọmú, si ilẹ ti iwọ ti bura fun awọn baba wọn. 13 Nibo li emi o gbé ti mú ẹran wá fi fun gbogbo enia yi? nitoriti nwọn nsọkun si mi wipe, Fun wa li ẹran, ki awa ki o jẹ. 14 Emi nikan kò le rù gbogbo awọn enia yi, nitoriti nwọn wuwo jù fun mi. 15 Ati bi bayi ni iwọ o ṣe si mi, emi bẹ̀ ọ, pa mi kánkan, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ; má si ṣe jẹ ki emi ri òṣi mi. 16 OLUWA si sọ fun Mose pe, Pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba Israeli jọ sọdọ mi, ẹniti iwọ mọ̀ pe, nwọn ṣe àgba awọn enia, ati olori wọn; ki o si mú wọn wá si agọ́ ajọ, ki nwọn ki o si duro nibẹ̀ pẹlu rẹ. 17 Emi o si sọkalẹ wá, emi o si bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀: emi o si mú ninu ẹmi ti mbẹ lara rẹ, emi o si fi i sara wọn; nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù awọn enia na, ki iwọ ki o máṣe nikan rù u. 18 Ki iwọ ki o si wi fun awọn enia na pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ dè ọla, ẹnyin o si jẹ ẹran: nitoriti ẹnyin sọkun li etí OLUWA, wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ? o sá dara fun wa ni Egipti: nitorina ni OLUWA yio ṣe fun nyin li ẹran, ẹnyin o si jẹ. 19 Ẹ ki o jẹ ni ijọ́ kan, tabi ni ijọ́ meji, tabi ni ijọ́ marun, bẹ̃ni ki iṣe ijọ́ mẹwa, tabi ogún ọjọ́; 20 Ṣugbọn li oṣù kan tọ̀tọ, titi yio fi yọ jade ni ihò-imu nyin, ti yio si fi sú nyin: nitoriti ẹnyin gàn OLUWA ti mbẹ lãrin nyin, ẹnyin si sọkun niwaju rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti awa fi jade lati Egipti wá? 21 Mose si wipe, Awọn enia na, lãrin awọn ẹniti emi wà, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀; iwọ si wipe, Emi o fun wọn li ẹran, ki nwọn ki o le ma jẹ li oṣù kan tọ̀tọ. 22 Agbo-ẹran tabi ọwọ́-ẹran ni ki a pa fun wọn, lati tó fun wọn ni? tabi gbogbo ẹja okun li a o kójọ fun wọn lati tó fun wọn? 23 OLUWA si sọ fun Mose pe, Ọwọ́ OLUWA ha kúru bi? iwọ o ri i nisisiyi bi ọ̀rọ mi yio ṣẹ si ọ, tabi bi ki yio ṣẹ. 24 Mose si jade lọ, o si sọ ọ̀rọ OLUWA fun awọn enia: o si pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba enia jọ, o si mu wọn duro yi agọ́ ká. 25 OLUWA si sọkalẹ wá ninu awọsanma, o si bá a sọ̀rọ, o si mú ninu ẹmi ti o wà lara rẹ̀, o si fi i sara awọn ãdọrin àgba na: o si ṣe, nigbati ẹmi na bà lé wọn, nwọn sì sọtẹlẹ ṣugbọn nwọn kò ṣe bẹ̃ mọ́. 26 Ṣugbọn o kù meji ninu awọn ọkunrin na ni ibudó, orukọ ekini a ma jẹ́ Eldadi, orukọ ekeji Medadi: ẹmi na si bà lé wọn; nwọn si mbẹ ninu awọn ti a kà, ṣugbọn nwọn kò jade lọ si agọ́: nwọn si nsọtẹlẹ ni ibudó. 27 Ọmọkunrin kan si súre, o si sọ fun Mose, o si wipe, Eldadi ati Medadi nsọtẹlẹ ni ibudó. 28 Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọkan ninu awọn ọmọkunrin rẹ̀ dahùn, o si wipe, Mose oluwa mi, dá wọn lẹkun. 29 Mose si wi fun u pe, Iwọ njowú nitori mi? gbogbo enia OLUWA iba le jẹ́ wolĩ, ki OLUWA ki o fi ẹmi rẹ̀ si wọn lara! 30 Mose si lọ si ibudó, on ati awọn àgba Israeli.

OLUWA Darí Àwọn Àparò Sọ́dọ̀ Wọn

31 Afẹfẹ kan si ti ọdọ OLUWA jade lọ, o si mú aparò lati okun wá, o si dà wọn si ibudó, bi ìwọn ìrin ijọ́ kan ni ìha ihin, ati bi ìwọn ìrin ijọ́ kan ni ìha ọhún yi ibudó ká, ni ìwọn igbọnwọ meji lori ilẹ. 32 Awọn enia si duro ni gbogbo ọjọ́ na, ati ni gbogbo oru na, ati ni gbogbo ọjọ́ keji, nwọn si nkó aparò: ẹniti o kó kére, kó òṣuwọn homeri mẹwa: nwọn si sá wọn silẹ fun ara wọn yi ibudó ká. 33 Nigbati ẹran na si mbẹ lãrin ehín wọn, ki nwọn ki o tó jẹ ẹ, ibinu OLUWA si rú si awọn enia na, OLUWA si fi àrun nla gidigidi kọlù awọn enia na. 34 A si pè orukọ ibẹ̀ na ni Kibrotu-hattaafa: nitoripe nibẹ̀ ni nwọn gbé sinku awọn enia ti o ṣe ifẹkufẹ. 35 Awọn enia na si dide ìrin wọn lati Kibrotu-hattaafa lọ si Haserotu; nwọn si dó si Haserotu.

Numeri 12

Ìjìyà Miriamu

1 A TI Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ òdi si Mose nitori obinrin ara Etiopia ti o gbé ni iyawo: nitoripe o gbé obinrin ara Etiopia kan ni iyawo. 2 Nwọn si wipe, Nipa Mose nikan ni OLUWA ha sọ̀rọ bi? kò ha ti ipa wa sọ̀rọ pẹlu? OLUWA si gbọ́ ọ. 3 Ṣugbọn ọkunrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ. 4 OLUWA si sọ fun Mose, ati fun Aaroni, ati fun Miriamu li ojiji pe, Ẹnyin mẹtẹta ẹ jade wá si agọ́ ajọ. Awọn mẹtẹta si jade. 5 OLUWA si sọkalẹ wá ninu ọwọ̀n awọsanma, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na, o si pè Aaroni ati Miriamu: awọn mejeji si jade wá. 6 O si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi nisisiyi: bi wolĩ OLUWA ba mbẹ ninu nyin, emi OLUWA yio farahàn fun u li ojuran, emi o si bá a sọ̀rọ li oju-alá. 7 Mose iranṣẹ mi kò ri bẹ̃, olõtọ ni ninu gbogbo ile mi. 8 On li emi mbá sọ̀rọ li ẹnu ko ẹnu, ati ni gbangba, ki si iṣe li ọ̀rọ ti o ṣe òkunkun; apẹrẹ OLUWA li on o si ri: njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bẹ̀ru lati sọ̀rọ òdi si Mose iranṣẹ mi? 9 Ibinu OLUWA si rú si wọn; o si lọ. 10 Awọsanma si lọ kuro lori Agọ́ na; si kiyesi i, Miriamu di adẹ̀tẹ, o fun bi òjo didì; Aaroni si wò Miriamu, si kiyesi i, o di adẹ̀tẹ. 11 Aaroni si wi fun Mose pe, Yẽ, oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, máṣe kà ẹ̀ṣẹ na si wa lọrùn, eyiti awa fi wère ṣe, ati eyiti awa ti dẹ̀ṣẹ. 12 Emi bẹ̀ ọ máṣe jẹ ki o dabi ẹniti o kú, ẹniti àbọ ara rẹ̀ run tán nigbati o ti inu iya rẹ̀ jade. 13 Mose si kigbe pè OLUWA, wipe, Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ, mu u lara dá nisisiyi. 14 OLUWA si wi fun Mose pe, Bi baba rẹ̀, tilẹ tu itọ si i li oju, njẹ oju ki ba tì i ni ijọ́ meje? Ki a sé e mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje, lẹhin eyinì ki a gbà a sinu rẹ̀. 15 A si sé Miriamu mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje: awọn enia kò si ṣí titi a fi gbà Miriamu pada. 16 Lẹhin eyinì li awọn enia si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si ijù Parani.

Numeri 13

Mose Rán Amí lọ sí Ilẹ̀ Kenaani

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Rán enia, ki nwọn ki o si ṣe amí ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli: ọkunrin kan ni ki ẹnyin ki o rán ninu ẹ̀ya awọn baba wọn, ki olukuluku ki o jẹ́ ijoye ninu wọn. 3 Mose si rán wọn lati ijù Parani lọ, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA: gbogbo awọn ọkunrin na jẹ́ olori awọn ọmọ Israeli. 4 Orukọ wọn si ni wọnyi: ninu ẹ̀ya Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakuru. 5 Ninu ẹ̀ya Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori. 6 Ninu ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne. 7 Ninu ẹ̀ya Issakari, Igali ọmọ Josefu. 8 Ninu ẹ̀ya Efraimu, Oṣea ọmọ Nuni. 9 Ninu ẹ̀ya Benjamini, Palti ọmọ Rafu. 10 Ninu ẹ̀ya Sebuluni, Gaddieli ọmọ Sodi. 11 Ninu ẹ̀ya Josefu, eyinì ni, ninu ẹ̀ya Manasse, Gadi ọmọ Susi. 12 Ninu ẹ̀ya Dani, Ammieli ọmọ Gemalli. 13 Ninu ẹ̀ya Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli. 14 Ninu ẹ̀ya Naftali, Nabi ọmọ Fofsi. 15 Ninu ẹ̀ya Gaddi, Geueli ọmọ Maki. 16 Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin na, ti Mose rán lati lọ ṣe amí ilẹ na. Mose si sọ Oṣea ọmọ Nuni ni Joṣua. 17 Mose si rán wọn lọ ṣe amí ilẹ Kenaani, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà ọ̀na ìha gusù yi, ki ẹ sì lọ sori òke nì. 18 Ki ẹnyin si wò ilẹ na, bi o ti ri; ati awọn enia ti ngbé inu rẹ̀, bi nwọn ṣe alagbara tabi alailagbara, bi diẹ ni nwọn, tabi pupọ̀; 19 Ati bi ilẹ na ti nwọn ngbé ti ri, bi didara ni bi buburu ni; ati bi ilu ti nwọn ngbé ti ri, bi ninu agọ́ ni, tabi ninu ilu odi; 20 Ati bi ilẹ na ti ri, bi ẹlẹtu ni tabi bi aṣalẹ̀, bi igi ba mbẹ ninu rẹ̀, tabi kò sí. Ki ẹnyin ki o si mu ọkàn le, ki ẹnyin si mú ninu eso ilẹ na wá. Njẹ ìgba na jẹ́ akokò pipọn akọ́so àjara. 21 Bẹ̃ni nwọn gòke lọ, nwọn si ṣe amí ilẹ na lati ijù Sini lọ dé Rehobu, ati lọ si Hamati. 22 Nwọn si ti ìha gusù gòke lọ, nwọn si dé Hebroni; nibiti Ahimani, Ṣeṣai, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki gbé wà. (A ti tẹ̀ Hebroni dò li ọdún meje ṣaju Soani ni Egipti.) 23 Nwọn si dé odò Eṣkolu, nwọn si rẹ́ ọwọ́ àjara kan, ti on ti ìdi eso-àjara kan lati ibẹ̀ wá, awọn enia meji si fi ọpá rù u; nwọn si mú ninu eso-pomegranate, ati ti ọpọtọ́ wá. 24 Nwọn si sọ ibẹ̀ na ni odò Eṣkolu, nitori ìdi-eso ti awọn ọmọ Israeli rẹ́ lati ibẹ̀ wá. 25 Nwọn si pada ni rirìn ilẹ na wò lẹhin ogoji ọjọ́. 26 Nwọn si lọ nwọn tọ̀ Mose wá, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ni ijù Parani, ni Kadeṣi; nwọn si mú ọ̀rọ pada tọ̀ wọn wá, ati gbogbo ijọ, nwọn si fi eso ilẹ na hàn wọn. 27 Nwọn si rò fun u, nwọn si wipe, Awa dé ilẹ na nibiti iwọ gbé rán wa lọ, nitõtọ li o nṣàn fun warà ati fun oyin; eyi si li eso rẹ̀. 28 Ṣugbọn alagbara ni awọn enia ti ngbé inu ilẹ na, ilu olodi si ni ilu wọn, nwọn tobi gidigidi: ati pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀. 29 Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani. 30 Kalebu si pa awọn enia lẹnu mọ́ niwaju Mose, o si wipe, Ẹ jẹ ki a gòke lọ lẹ̃kan, ki a si gbà a; nitoripe awa le ṣẹ́ ẹ. 31 Ṣugbọn awọn ọkunrin ti o bá a gòke lọ wipe, Awa kò le gòke tọ̀ awọn enia na lọ; nitoriti nwọn lagbara jù wa lọ. 32 Nwọn si mú ìhin buburu ti ilẹ na, ti nwọn ti ṣe amí wá fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ ti imu awọn enia rẹ̀ jẹ ni; ati gbogbo enia ti awa ri ninu rẹ̀ jẹ́ enia ti o ṣigbọnlẹ. 33 Ati nibẹ̀ li awa gbé ri awọn omirán, awọn ọmọ Anaki ti o ti inu awọn omirán wá: awa si dabi ẹlẹnga li oju ara wa, bẹ̃li awa si ri li oju wọn.

Numeri 14

Àwọn Eniyan náà Kùn

1 GBOGBO ijọ si gbé ohùn wọn soke, nwọn si ke: awọn enia na si sọkun li oru na. 2 Gbogbo awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni: gbogbo ijọ si wi fun wọn pe, Awa iba kuku ti kú ni ilẹ Egipti! tabi awa iba kú li aginjù yi! 3 Nitori kini OLUWA ṣe mú wa wá si ilẹ yi, lati ti ipa idà ṣubu? Awọn aya wa, ati awọn ọmọ wa yio di ijẹ: kò ha san fun wa ki a pada lọ si Egipti? 4 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẹ jẹ ki a yàn olori, ki a si pada lọ si Egipti. 5 Nigbana ni Mose ati Aaroni doju wọn bolẹ niwaju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli. 6 Ati Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefunne, ti o wà ninu awọn ti o ṣe amí ilẹ na, fà aṣọ wọn ya: 7 Nwọn si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ na dara gidigidi. 8 Bi OLUWA ba fẹ́ wa, njẹ yio mú wa wọ̀ inu ilẹ na yi, yio si fi i fun wa; ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 9 Ṣugbọn ẹ máṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru awọn enia ilẹ na; nitoripe onjẹ wa ni nwọn; àbo wọn ti fi wọn silẹ, OLUWA si wà pẹlu wa: ẹ máṣe bẹ̀ru wọn. 10 Gbogbo ijọ si wipe ki a sọ wọn li okuta. Ṣugbọn ogo OLUWA hàn ninu agọ́ ajọ niwaju gbogbo awọn ọmọ Israeli.

Mose Gbadura fún Àwọn Eniyan náà

11 OLUWA si wi fun Mose pe, Awọn enia yi yio ti kẹgàn mi pẹ tó? yio si ti pẹ tó ti nwọn o ṣe alaigbà mi gbọ́, ni gbogbo iṣẹ-àmi ti mo ṣe lãrin wọn? 12 Emi o fi ajakalẹ-àrun kọlù wọn, emi o si gbà ogún wọn lọwọ wọn, emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla, ati alagbara jù wọn lọ. 13 Mose si wi fun OLUWA pe, Ṣugbọn awọn ara Egipti yio gbọ́; nitoripe nipa agbara rẹ ni iwọ fi mú awọn enia yi jade lati inu wọn wá; 14 Nwọn o si wi fun awọn ara ilẹ yi: nwọn sá ti gbọ́ pe iwọ OLUWA mbẹ lãrin awọn enia yi, nitoripe a ri iwọ OLUWA li ojukoju, ati pe awọsanma rẹ duro lori wọn, ati pe iwọ li o ṣaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma nigba ọsán, ati ninu ọwọ̀n iná li oru. 15 Njẹ bi iwọ ba pa gbogbo awọn enia yi bi ẹnikan, nigbana li awọn orilẹ-ède ti o ti gbọ́ okikí rẹ yio wipe, 16 Nitoriti OLUWA kò le mú awọn enia yi dé ilẹ ti o ti fi bura fun wọn, nitorina li o ṣe pa wọn li aginjù. 17 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki agbara OLUWA ki o tobi, gẹgẹ bi iwọ ti sọ rí pe, 18 Olupamọra ati ẹniti o pọ̀ li ãnu li OLUWA, ti ndari ẹ̀ṣẹ ati irekọja jì, ati bi o ti wù ki o ri, ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijìya; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, titi dé iran kẹta ati ẹkẹrin. 19 Emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ awọn enia yi jì, gẹgẹ bi titobi ãnu rẹ, ati bi iwọ ti darijì awọn enia yi, lati Egipti titi di isisiyi. 20 OLUWA si wipe, Emi ti darijì gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ: 21 Ṣugbọn nitõtọ, bi mo ti wà, gbogbo aiye yio si kún fun ogo OLUWA; 22 Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi; 23 Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i: 24 Ṣugbọn Kalebu iranṣẹ mi, nitoriti o ní ọkàn miran ninu rẹ̀, ti o si tẹle mi mọtimọti, on li emi o múlọ sinu ilẹ na nibiti o ti rè; irú-ọmọ rẹ̀ ni yio si ní i. 25 Njẹ awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani ngbé afonifoji: li ọla ẹ pada, ki ẹ si ṣi lọ si aginjù nipa ọ̀na Okun Pupa.

OLUWA Jẹ Àwọn Eniyan náà Níyà Nítorí pé wọ́n Kùn

26 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 27 Emi o ti mu sũru pẹ to fun ijọ enia buburu yi ti nkùn si mi? Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli, ti nwọn kùn si mi. 28 Wi fun wọn pe, OLUWA wipe, Bi mo ti wà nitõtọ, bi ẹnyin ti sọ li etí mi, bẹ̃li emi o ṣe si nyin: 29 Okú nyin yio ṣubu li aginjù yi; ati gbogbo awọn ti a kà ninu nyin, gẹgẹ bi iye gbogbo nyin, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jú bẹ̃ lọ, ti ẹ kùn si mi, 30 Ẹnyin ki yio dé inu ilẹ na, ti mo ti bura lati mu nyin gbé inu rẹ̀, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni. 31 Ṣugbọn awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe yio di ijẹ, awọn li emi o muwọ̀ ọ, awọn ni yio si mọ̀ ilẹ na ti ẹnyin gàn. 32 Ṣugbọn ẹnyin, okú nyin yio ṣubu li aginjú yi. 33 Awọn ọmọ nyin yio si ma rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, nwọn o si ma rù ìwa-àgbere nyin, titi okú nyin yio fi ṣòfo tán li aginjù. 34 Gẹgẹ bi iye ọjọ́ ti ẹnyin fi rìn ilẹ na wò, ani ogoji ọjọ́, ọjọ́ kan fun ọdún kan, li ẹnyin o rù ẹ̀ṣẹ nyin, ani ogoji ọdún, ẹnyin o si mọ̀ ibà ileri mi jẹ́. 35 Emi OLUWA ti sọ, Emi o ṣe e nitõtọ si gbogbo ijọ buburu yi, ti nwọn kójọ pọ̀ si mi: li aginjù yi ni nwọn o run, nibẹ̀ ni nwọn o si kú si. 36 Ati awọn ọkunrin na ti Mose rán lọ lati rìn ilẹ na wò, ti nwọn pada, ti nwọn si mu gbogbo ijọ kùn si i, ni mimú ìhin buburu ilẹ na wá, 37 Ani awọn ọkunrin na ti o mú ìhin buburu ilẹ na wá, nwọn ti ipa àrun kú niwaju OLUWA. 38 Ṣugbọn Joṣua ọmọ Nuni, ati Kalebu ọmọ Jefunne, ninu awọn ọkunrin na ti o rìn ilẹ na lọ, wà lãye.

Ìgbà Kinni Tí Wọ́n Gbìyànjú àtigba Ilẹ̀ náà

39 Mose si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli: awọn enia na si kãnu gidigidi. 40 Nwọn si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si gùn ori òke nì lọ, wipe, Kiyesi i, awa niyi, awa o si gòke lọ si ibiti OLUWA ti ṣe ileri: nitoripe awa ti ṣẹ̀. 41 Mose si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nre aṣẹ OLUWA kọja? kì yio sa gbè nyin. 42 Ẹ máṣe gòke lọ, nitoriti OLUWA kò sí lãrin nyin, ki a má ba lù nyin bolẹ niwaju awọn ọtá nyin. 43 Nitoriti awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani mbẹ niwaju nyin, ẹnyin o si ti ipa idà ṣubu: nitoriti ẹnyin ti yipada kuro lẹhin OLUWA, nitorina OLUWA ki yio si pẹlu nyin. 44 Ṣugbọn nwọn fi igberaga gòke lọ sori òke na: ṣugbọn apoti ẹrí OLUWA, ati Mose, kò jade kuro ni ibudò. 45 Nigbana li awọn ara Amaleki sọkalẹ wá, ati awọn ara Kenaani ti ngbé ori-òke na, nwọn si kọlù wọn nwọn si ṣẹ́ wọn titi dé Horma.

Numeri 15

Àwọn Òfin nípa Ìrúbọ

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ibujoko nyin, ti mo fi fun nyin, 3 Ti ẹnyin o ba si ṣe ẹbọ iná si OLUWA, ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá, tabi ninu ajọ nyin lati ṣe õrùn didùn si OLUWA ninu agbo-ẹran, tabi ọwọ́-ẹran: 4 Nigbana ni ki ẹniti nru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ na si OLUWA ki o mú ẹbọ ohunjijẹ wá, idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro pò: 5 Ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ ohunmimu ni ki iwọ ki o pèse pẹlu ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, fun ọdọ-agutan kan. 6 Tabi fun àgbo kan, ki iwọ ki o pèse ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun pẹlu idamẹta òṣuwọn hini oróro: 7 Ati fun ẹbọ ohunmimu, ki iwọ ki o mú idamẹta òṣuwọn hini ọti-waini wá, fun õrùn didùn si OLUWA. 8 Bi iwọ ba si pèse ẹgbọrọ akọmalu kan fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ alafia si OLUWA: 9 Nigbana ni ki o mu wá pẹlu ẹgbọrọ akọmalu na, ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun ti a fi àbọ òsuwọn hini oróro pò. 10 Ki iwọ ki o si múwa fun ẹbọ ohunmimu àbọ òṣuwọn hini ọti-waini, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 11 Bayi ni ki a ṣe niti akọmalu kan, tabi niti àgbo kan, tabi niti akọ ọdọ-agutan kan, tabi niti ọmọ-ewurẹ kan. 12 Gẹgẹ bi iye ti ẹnyin o pèse, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ṣe si olukuluku gẹgẹ bi iye wọn. 13 Gbogbo ibilẹ ni ki o ma ṣe nkan wọnyi bayi, nigbati nwọn ba nru ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA. 14 Ati bi alejò kan ba nṣe atipo lọdọ nyin, tabi ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin ni iran nyin, ti o si nfẹ́ ru ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; bi ẹnyin ti ṣe, bẹ̃ni ki on ki o ṣe. 15 Ìlana kan ni ki o wà fun ẹnyin ijọ enia, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin, ìlana titilai, ni iran-iran nyin: bi ẹnyin ti ri, bẹ̃ni ki alejò ki o si ri niwaju OLUWA. 16 Ofin kan ati ìlana kan ni ki o wà fun nyin, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin. 17 OLUWA si sọ fun Mose pe, 18 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ na nibiti emi nmú nyin lọ, 19 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba njẹ ninu onjẹ ilẹ na, ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA. 20 Ki ẹnyin ki o mú àkara atetekọṣu iyẹfun nyin wá fun ẹbọ igbesọsoke: bi ẹnyin ti ṣe ti ẹbọ igbesọsoke ilẹ ipakà, bẹ̃ni ki ẹnyin gbé e sọ. 21 Ninu atetekọ́ṣu iyẹfun nyin ni ki ẹnyin ki o fi fun OLUWA li ẹbọ igbesọsoke, ni iran-iran nyin. 22 Bi ẹnyin ba si ṣìṣe, ti ẹnyin kò si kiyesi gbogbo ofin wọnyi ti OLUWA ti sọ fun Mose, 23 Ani gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun nyin lati ọwọ́ Mose wá, lati ọjọ́ na ti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati lati isisiyi lọ, ni iran-iran nyin; 24 Yio si ṣe, bi a ba fi aimọ̀ ṣe ohun kan ti ijọ kò mọ̀, ki gbogbo ijọ ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá fun ẹbọ sisun, fun õrùn didùn si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀, gẹgẹ bi ìlana na, ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 25 Ki alufa ki o si ṣètutu fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, a o si darijì wọn; nitoripe aimọ̀ ni, nwọn si ti mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn niwaju OLUWA, nitori aimọ̀ wọn: 26 A o si darijì gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ati alejò ti iṣe atipo lọdọ wọn; nitoripe gbogbo enia wà li aimọ̀. 27 Bi ọkàn kan ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, nigbana ni ki o mú abo-ewurẹ ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 28 Ki alufa ki o ṣètutu fun ọkàn na ti o ṣẹ̀, nigbati o ba ṣẹ̀ li aimọ̀ niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun u; a o si darijì i. 29 Ofin kan ni ki ẹnyin ki o ní fun ẹniti o ṣẹ̀ ni aimọ̀, ati fun ẹniti a bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn. 30 Ṣugbọn ọkàn na ti o ba fi ikugbu ṣe ohun kan, iba ṣe ibilẹ tabi alejò, o sọ̀rọbuburu si OLUWA; ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 31 Nitoriti o gàn ọ̀rọ OLUWA, o si ru ofin rẹ̀; ọkàn na li a o ke kuro patapata, ẹ̀ṣẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀. 32 Nigbati awọn ọmọ Israeli wà li aginjù, nwọn ri ọkunrin kan ti nṣẹ́ igi li ọjọ́-isimi. 33 Awọn ti o ri i ti nṣẹ́ igi mú u tọ̀ Mose ati Aaroni wá, ati gbogbo ijọ. 34 Nwọn si há a mọ́ ile-ìde, nitoriti a kò ti isọ bi a o ti ṣe e. 35 OLUWA si sọ fun Mose pe, Pipa li a o pa ọkunrin na: gbogbo ijọ ni yio sọ ọ li okuta pa lẹhin ibudó. 36 Gbogbo ijọ si mú u wá sẹhin ibudó, nwọn si sọ ọ li okuta, on si kú; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Òfin nípa Kókó Etí Aṣọ

37 OLUWA si sọ fun Mose pe, 38 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si fi aṣẹ fun wọn ki nwọn ki o ṣe wajawaja si eti aṣọ wọn ni iran-iran wọn, ati ki nwọn ki o si fi ọjábulẹ alaró si wajawaja eti aṣọ na: 39 Yio si ma ṣe bi wajawaja fun nyin, ki ẹnyin ki o le ma wò o, ki ẹ si ma ranti gbogbo ofin OLUWA, ki ẹ si ma ṣe wọn: ki ẹnyin ki o má si ṣe tẹle ìro ọkàn nyin ati oju ara nyin, ti ẹnyin ti ima ṣe àgbere tọ̀ lẹhin: 40 Ki ẹnyin ki o le ma ranti, ki ẹ si ma ṣe ofin mi gbogbo, ki ẹnyin ki o le jẹ́ mimọ́ si Ọlọrun nyin. 41 Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade lati ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.

Numeri 16

Ọ̀tẹ̀ tí Kora, Datani ati Abiramu Dì

1 NJẸ Kora, ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ati Datani on Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ati On, ọmọ Peleti, awọn ọmọ Reubeni, dìmọ: 2 Nwọn si dide niwaju Mose, pẹlu ãdọtalerugba ọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, ijoye ninu ijọ, awọn olorukọ ninu ajọ, awọn ọkunrin olokikí: 3 Nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, nwọn si wi fun wọn pe, O tó gẹ, nitoripe gbogbo ijọ li o jẹ́ mimọ́, olukuluku wọn, OLUWA si mbẹ lãrin wọn: nitori kili ẹnyin ha ṣe ngbé ara nyin ga jù ijọ OLUWA lọ? 4 Nigbati Mose gbọ́, o doju rẹ̀ bolẹ: 5 O si sọ fun Kora ati fun gbogbo ẹgbẹ rẹ̀ pe, Li ọla OLUWA yio fi ẹniti iṣe tirẹ̀ hàn, ati ẹniti o mọ́; yio si mu u sunmọ ọdọ rẹ̀: ani ẹniti on ba yàn ni yio mu sunmọ ọdọ rẹ̀. 6 Ẹ ṣe eyi; Ẹ mú awo-turari, Kora, ati gbogbo ẹgbẹ rẹ̀; 7 Ki ẹ si fi iná sinu wọn, ki ẹ si fi turari sinu wọn niwaju OLUWA li ọla: yio si ṣe, ọkunrin ti OLUWA ba yàn, on ni ẹni mimọ́: o tó gẹ, ẹnyin ọmọ Lefi. 8 Mose si wi fun Kora pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹnyin ọmọ Lefi, ẹ gbọ́: 9 Ohun kekere ha ni li oju nyin, ti Ọlọrun Israeli yà nyin kuro ninu ijọ Israeli, lati mú nyin sunmọ ọdọ ara rẹ̀ lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ OLUWA, ati lati ma duro niwaju ijọ lati ma ṣe iranṣẹ fun wọn; 10 O si mú iwọ sunmọ ọdọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ gbogbo, awọn ọmọ Lefi pẹlu rẹ; ẹnyin si nwá iṣẹ-alufa pẹlu? 11 Nitorina, iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ kójọ pọ̀ si OLUWA: ati kini Aaroni, ti ẹnyin nkùn si i? 12 Mose si ranṣẹ pè Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu: nwọn si wipe, Awa ki yio gòke wá: 13 Ohun kekere ha ni ti iwọ mú wa gòke lati ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin wá, lati pa wa li aginjù, ti iwọ fi ara rẹ jẹ́ alade lori wa patapata? 14 Pẹlupẹlu iwọ kò ti imú wa dé ilẹ kan ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bẹ̃ni iwọ kò fun wa ni iní ilẹ ati ọgba-àjara: iwọ o yọ oju awọn ọkunrin wọnyi bi? awa ki yio gòke wá. 15 Mose si binu gidigidi, o si wi fun OLUWA pe, Máṣe kà ẹbọ wọn si: emi kò gbà kẹtẹkẹtẹ kan lọwọ wọn, bẹ̃li emi kò pa ẹnikan wọn lara. 16 Mose wi fun Kora pe, Ki iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ ki o wá siwaju OLUWA, iwọ, ati awọn, ati Aaroni li ọla: 17 Ki olukuluku wọn ki o mú awo-turari rẹ̀, ki ẹ si fi turari sinu wọn, ki olukuluku nyin ki o mú awo-turari rẹ̀ wá siwaju OLUWA, ãdọtalerugba awo-turari; iwọ pẹlu ati Aaroni, olukuluku awo-turari rẹ̀. 18 Olukuluku wọn si mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari lé ori wọn, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, pẹlu Mose ati Aaroni. 19 Kora si kó gbogbo ijọ enia jọ si wọn si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ogo OLUWA si hàn si gbogbo ijọ enia na. 20 OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe, 21 Ẹ yà ara nyin kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣéju kan. 22 Nwọn si doju wọn bolẹ, nwọn wipe, Ọlọrun, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ọkunrin kan ha le ṣẹ̀, ki iwọ ki o si binu si gbogbo ijọ? 23 OLUWA si sọ fun Mose pe, 24 Sọ fun ijọ pe, Ẹ gòke wá kuro ni sakani agọ́ Kora, Datani, ati Abiramu. 25 Mose si dide, o si tọ̀ Datani ati Abiramu lọ; awọn àgba Israeli si tẹle e. 26 O si sọ fun ijọ pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ kuro ni ibi agọ́ awọn ọkunrin buburu yi, ẹ má si ṣe fọwọkàn ohun kan ti iṣe ti wọn, ki ẹ má ba run ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn. 27 Bẹ̃ni nwọn si gòke lọ kuro nibi agọ́ Kora, Datani ati Abiramu, ni ìha gbogbo: Datani ati Abiramu si jade, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ wọn, ati awọn aya wọn, ati awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn wẹ́wẹ. 28 Mose si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe OLUWA li o rán mi lati ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi; ati pe emi kò ṣe wọn lati inu ara mi wá. 29 Bi awọn ọkunrin wọnyi ba kú bi gbogbo enia ti ikú, tabi bi a ba si bẹ̀ wọn wò bi ãti ibẹ̀ gbogbo enia wò; njẹ OLUWA ki o rán mi. 30 Ṣugbọn bi OLUWA ba ṣe ohun titun, ti ilẹ ba si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, pẹlu ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, ti nwọn si sọkalẹ lọ si ipò-okú lãye; nigbana ẹnyin o mọ̀ pe awọn ọkunrin wọnyi ti gàn OLUWA. 31 O si ṣe, bi o ti pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni sisọ, ni ilẹ là pẹrẹ nisalẹ wọn: 32 Ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si gbe wọn mì, ati awọn ara ile wọn, ati gbogbo awọn enia ti iṣe ti Kora, ati gbogbo ẹrù wọn. 33 Awọn, ati ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, sọkalẹ lọ lãye si ipò-okú, ilẹ si pa ẹnu dé mọ́ wọn, nwọn si run kuro ninu ijọ. 34 Gbogbo enia Israeli ti o yi wọn ká si salọ nitori igbe wọn: nitoriti nwọn wipe, Ki ilẹ ki o má ba gbe wa mì pẹlu. 35 Iná si jade wá lati ọdọ OLUWA, o si run awọn ãdọtalerugba ọkunrin nì ti nwọn mú turari wá.

Àwọn Àwo Turari

36 OLUWA si sọ fun Mose pe, 37 Sọ fun Eleasari ọmọ Aaroni alufa, pe ki o mú awo-turari wọnni kuro ninu ijóna, ki iwọ ki o si tu iná na ká sọhún; nitoripe nwọn jẹ́ mimọ́. 38 Awo-turari ti awọn ẹlẹṣẹ wọnyi si ọkàn ara wọn, ni ki nwọn ki o fi ṣe awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: nitoriti nwọn mú wọn wá siwaju OLUWA, nitorina ni nwọn ṣe jẹ́ mimọ́: nwọn o si ma ṣe àmi fun awọn ọmọ Israeli. 39 Eleasari alufa si mú awo-turari idẹ wọnni, eyiti awọn ẹniti o jóna fi mú ẹbọ wá; a si rọ wọn li awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: 40 Lati ma ṣe ohun iranti fun awọn ọmọ Israeli, ki alejò kan, ti ki iṣe irú-ọmọ Aaroni, ki o máṣe sunmọtosi lati mú turari wá siwaju OLUWA; ki o má ba dabi Kora, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀: bi OLUWA ti wi fun u lati ọwọ́ Mose wá.

Aaroni Gba Àwọn Eniyan náà Là

41 Ṣugbọn ni ijọ́ keji gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli nkùn si Mose ati si Aaroni, wipe, Ẹnyin pa awọn enia OLUWA. 42 O si ṣe, nigbati ijọ pejọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, ti nwọn si wò ìha agọ́ ajọ: si kiyesi i, awọsanma bò o, ogo OLUWA si farahàn. 43 Mose ati Aaroni si wá siwaju agọ́ ajọ. 44 OLUWA si sọ fun Mose pe, 45 Ẹ lọ kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣẹju kan. Nwọn si doju wọn bolẹ. 46 Mose si wi fun Aaroni pe, Mú awo-turari kan, ki o si fi iná sinu rẹ̀ lati ori pẹpẹ nì wá, ki o si fi turari lé ori rẹ̀, ki o si yára lọ sọdọ ijọ, ki o si ṣètutu fun wọn: nitoriti ibinu jade lati ọdọ OLUWA lọ; iyọnu ti bẹ̀rẹ na. 47 Aaroni si mú awo-turari bi Mose ti fi aṣẹ fun u, o si sure lọ sãrin ijọ; si kiyesi i, iyọnu ti bẹ̀rẹ na lãrin awọn enia: o si fi turari sinu rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn enia na. 48 O si duro li agbedemeji okú ati alãye; iyọnu na si duro. 49 Awọn ti o kú ninu iyọnu na si jẹ́ ẹgba meje o le ẹ̃dẹgbẹrin, laìka awọn ti o kú niti ọ̀ran Kora. 50 Aaroni si pada tọ̀ Mose lọ si ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: iyọnu na si duro.

Numeri 17

Ọ̀pá Aaroni

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si gbà ọpá kọkan lọwọ wọn, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, lọwọ gbogbo awọn olori wọn gẹgẹ bi ile awọn baba wọn ọpá mejila: ki o si kọ́ orukọ olukuluku si ara ọpá rẹ̀. 3 Ki o si kọ orukọ Aaroni sara ọpá Lefi: nitoripe ọpá kan yio jẹ́ fun ori ile awọn baba wọn. 4 Ki o si fi wọn lelẹ ninu agọ́ ajọ, niwaju ẹrí, nibiti emi o gbé pade nyin. 5 Yio si ṣe, ọpá ẹniti emi o yàn yio ruwe: emi o si da kikùn awọn ọmọ Israeli duro kuro lọdọ mi, ti nwọn nkùn si nyin. 6 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn olori wọn si fun u li ọpá, ọpá kan fun olori kan, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, ani ọpá mejila: ọpá Aaroni si wà ninu ọpá wọn. 7 Mose si fi ọpá wọnni lelẹ niwaju OLUWA ninu agọ́ ẹrí. 8 O si ṣe, ni ijọ́ keji ti Mose wọ̀ inu agọ́ ẹrí lọ; si kiyesi i, ọpá Aaroni fun ile Lefi rudi, o si tú, o si tanna, o si so eso almondi. 9 Mose si kó gbogbo ọpá na lati iwaju OLUWA jade tọ̀ gbogbo awọn ọmọ Israeli wá: nwọn si wò, olukuluku si mú ọpá tirẹ̀. 10 OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú ọpá Aaroni pada wa siwaju ẹrí, lati fi pamọ́ fun àmi fun awọn ọlọ̀tẹ nì; ki iwọ ki o si gbà kikùn wọn kuro lọdọ mi patapata ki nwọn ki o má ba kú. 11 Mose si ṣe bẹ̃: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u, bẹ̃li o ṣe. 12 Awọn ọmọ Israeli si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, awa kú, awa gbé, gbogbo wa gbé. 13 Ẹnikẹni ti o ba sunmọ agọ́ OLUWA yio kú: awa o ha fi kikú run bi?

Numeri 18

Iṣẹ́ Àwọn Àlùfáàa ati Àwọn Ọmọ Lefi

1 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati ile baba rẹ pẹlu rẹ, ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ ibi-mimọ́: ati iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ iṣẹ-alufa nyin. 2 Ati awọn arakunrin rẹ pẹlu, ẹ̀ya Lefi, ẹ̀ya baba rẹ, ni ki o múwa pẹlu rẹ, ki nwọn ki o le dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ fun ọ: ṣugbọn iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma ṣe iranṣẹ niwaju agọ́ ẹrí. 3 Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ mọ́, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju gbogbo agọ́, kìki pe nwọn kò gbọdọ sunmọ ohun-èlo ibi-mimọ́ ati pẹpẹ, ki ati awọn, ati ẹnyin pẹlu ki o má ba kú. 4 Ki nwọn ki o si dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju agọ́ ajọ, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin agọ́: alejò kan kò sí gbọdọ sunmọ ọdọ nyin. 5 Ki ẹnyin ki o si ma ṣe itọju ibi-mimọ́, ati itọju pẹpẹ: ki ibinu ki o má ba sí mọ́ lori awọn ọmọ Israeli. 6 Ati emi, kiyesi i, mo ti mú awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli: ẹnyin li a fi wọn fun bi ẹ̀bun fun OLUWA, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ. 7 Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa.

Ìpín Àwọn Àlùfáà

8 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Kiyesi i, emi si ti fi itọju ẹbọ igbesọsoke mi fun ọ pẹlu, ani gbogbo ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, iwọ li emi fi wọn fun ni ipín, ati fun awọn ọmọ rẹ, bi ipín lailai. 9 Eyi ni yio ṣe tirẹ ninu ohun mimọ́ julọ, ti a mú kuro ninu iná; gbogbo ọrẹ-ẹbọ wọn, gbogbo ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹbi wọn, ti nwọn o mú fun mi wá, mimọ́ julọ ni yio jasi fun iwọ ati fun awọn ọmọ rẹ. 10 Bi ohun mimọ́ julọ ni ki iwọ ki o ma jẹ ẹ: gbogbo ọkunrin ni yio jẹ ẹ; mimọ́ ni yio jẹ́ fun ọ. 11 Eyi si ni tirẹ; ẹbọ igbesọsoke ẹ̀bun wọn, pẹlu gbogbo ẹbọ fifì awọn ọmọ Israeli: emi ti fi wọn fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: gbogbo awọn ti o mọ́ ninu ile rẹ ni ki o jẹ ẹ. 12 Gbogbo oróro daradara, ati gbogbo ọti-waini daradara, ati alikama, akọ́so ninu wọn ti nwọn o mú fun OLUWA wá, iwọ ni mo fi wọn fun. 13 Akọ́so gbogbo ohun ti o wà ni ilẹ wọn, ti nwọn o mú fun OLUWA wá, tirẹ ni yio jẹ́; gbogbo ẹniti o mọ́ ni ile rẹ ni ki o jẹ ẹ. 14 Ohun ìyasọtọ gbogbo ni Israeli ni ki o jẹ́ tirẹ. 15 Gbogbo akọ́bi ninu gbogbo ohun alãye, ti nwọn o mú wa fun OLUWA, iba ṣe ti enia tabi ti ẹranko, ki o jẹ́ tirẹ: ṣugbọn rirà ni iwọ o rà akọ́bi enia silẹ, ati akọ́bi ẹran alaimọ́ ni ki iwọ ki o rà silẹ. 16 Gbogbo awọn ti a o ràsilẹ, lati ẹni oṣù kan ni ki iwọ ki o ràsilẹ, gẹgẹ bi idiyelé rẹ, li owo ṣekeli marun, nipa ṣekeli ibi-mimọ́ (ti o jẹ́ ogun gera). 17 Ṣugbọn akọ́bi akọmalu, tabi akọbi agutan, tabi akọ́bi ewurẹ, ni iwọ kò gbọdọ ràsilẹ; mimọ́ ni nwọn: ẹ̀jẹ wọn ni ki iwọ ki o ta sori pẹpẹ, ki iwọ ki o si sun ọrá wọn li ẹbọ ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si OLUWA. 18 Ki ẹran wọn ki o si jẹ́ tirẹ, bi àiya fifì, ati bi itan ọtún, ni yio jẹ́ tirẹ. 19 Gbogbo ẹbọ igbesọsoke ohun mimọ́ wọnni, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun OLUWA, ni mo ti fi fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: majẹmu iyọ̀ ni lailai niwaju OLUWA fun ọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ. 20 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ki yio ní iní ninu ilẹ wọn, bẹ̃ni iwọ ki yio ní ipín lãrin wọn: Emi ni ipín rẹ ati iní rẹ lãrin awọn ọmọ Israeli.

Ìpín Àwọn Ọmọ Lefi

21 Si kiyesi i, emi si ti fi gbogbo idamẹwa ni Israeli fun awọn ọmọ Lefi ni iní, nitori iṣẹ-ìsin wọn ti nwọn nṣe, ani iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ. 22 Awọn ọmọ Israeli kò si gbọdọ sunmọ agọ́ ajọ, ki nwọn ki o má ba rù ẹ̀ṣẹ, ki nwọn má ba kú. 23 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ, awọn ni yio si ma rù ẹ̀ṣẹ wọn: ìlana lailai ni ni iran-iran nyin, ati lãrin awọn ọmọ Israeli, nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní. 24 Nitori idamẹwa awọn ọmọ Israeli, ti nwọn múwa li ẹbọ igbesọsoke fun OLUWA, ni mo ti fi fun awọn ọmọ Lefi lati ní: nitorina ni mo ṣe wi fun wọn pe, Nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ Israeli.

Ìdámẹ́wàá Àwọn Ọmọ Lefi

25 OLUWA si sọ fun Mose pe, 26 Si sọ fun awọn ọmọ Lefi, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbà idamẹwa ti mo ti fi fun nyin ni ilẹiní nyin lọwọ awọn ọmọ Israeli, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke ninu rẹ̀ wá fun OLUWA, idamẹwa ninu idamẹwa na. 27 A o si kà ẹbọ igbesọsoke nyin yi si nyin, bi ẹnipe ọkà lati ilẹ ipakà wá, ati bi ọti lati ibi ifunti wá. 28 Bayi li ẹnyin pẹlu yio ma mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA ninu gbogbo idamẹwa nyin, ti ẹnyin ngbà lọwọ awọn ọmọ Israeli; ki ẹnyin ki o si mú ẹbọ igbesọsoke OLUWA ninu rẹ̀ tọ̀ Aaroni alufa wá. 29 Ninu gbogbo ẹ̀bun nyin ni ki ẹnyin ki o si mú gbogbo ẹbọ igbesọsoke OLUWA wá, ninu gbogbo eyiti o dara, ani eyiti a yàsimimọ́ ninu rẹ̀. 30 Nitorina ki iwọ ki o wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke, nigbana ni ki a kà a fun awọn ọmọ Lefi bi ọkà ilẹ-ipakà, ati bi ibisi ibi-ifunti. 31 Ẹnyin o si jẹ ẹ ni ibi gbogbo, ati ẹnyin ati awọn ara ile nyin: nitoripe ère nyin ni fun iṣẹ-ìsin nyin ninu agọ́ ajọ. 32 Ẹnyin ki yio si rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ki ẹnyin ki o má ba kú.

Numeri 19

Eérú Mààlúù Pupa náà

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 2 Eyi ni ìlana ofin, ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú ẹgbọrọ abomalu pupa kan tọ̀ ọ wá, alailabawọ́n, ati alailabùku, ati lara eyiti a kò ti dì àjaga mọ́: 3 Ki ẹnyin si fi i fun Eleasari alufa, ki on ki o mú u jade lọ sẹhin ibudó, ki ẹnikan ki o si pa a niwaju rẹ̀: 4 Ki Eleasari alufa, ki o fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n iwaju agọ́ ajọ ni ìgba meje. 5 Ki ẹnikan ki o si sun ẹgbọrọ abomalu na li oju rẹ̀; awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati ẹ̀jẹ rẹ̀, pẹlu igbẹ́ rẹ̀, ni ki o sun: 6 Ki alufa na ki o mú igi opepe, ati hissopu, ati ododó, ki o si jù u sãrin ẹgbọrọ abomalu ti a nsun. 7 Nigbana ni ki alufa na ki o fọ̀ ãṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin na ki o si wá si ibudó, ki alufa na ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 8 Ki ẹniti o sun u ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀ ninu omi, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 9 Ki ọkunrin kan ti o mọ́ ki o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na, ki o si kó o jọ si ibi kan ti o mọ́ lẹhin ibudó, ki a si pa a mọ́ fun ijọ awọn ọmọ Israeli fun omi ìyasapakan: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 10 Ki ẹniti o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: yio si jẹ́ ilana titilai, fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn.

Òfin Tí ó Jẹ Mọ́ Fífi Ara Kan òkú

11 Ẹniti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ki o jẹ́ alaimọ ni ijọ́ meje. 12 Ki oluwarẹ̀ ki o fi i wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje yio di mimọ́: ṣugbọn bi kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ ni ijọ́ kẹta, njẹ ni ijọ́ keje ki yio di mimọ́. 13 Ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ti o kú, ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, o bà agọ́ OLUWA jẹ́; ọkàn na li a o si ke kuro ninu Israeli: nitoriti a kò wọ́n omi ìyasapakan si i lara, alaimọ́ li o jẹ̀; aimọ́ rẹ̀ mbẹ lara rẹ̀ sibẹ̀, 14 Eyi li ofin na, nigbati enia kan ba kú ninu agọ́ kan: gbogbo ẹniti o wọ̀ inu agọ́ na, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu agọ́ na, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje. 15 Ati ohun-èlo gbogbo ti o ṣi silẹ, ti kò ní ideri lori rẹ̀, alaimọ́ ni. 16 Ẹnikẹni ti o ba si fọwọkàn ẹnikan ti a fi idà pa ni gbangba igbẹ́, tabi okú kan, tabi egungun ẹnikan, tabi isà-okú, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje. 17 Ati fun ẹni aimọ́ kan ki nwọn ki o mú ninu ẽru sisun ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, ki a si bù omi ti nṣàn si i ninu ohun-èlo kan: 18 Ki ẹnikan ti o mọ́ ki o si mú hissopu, ki o si tẹ̀ ẹ bọ̀ inu omi na, ki o si fi i wọ́n agọ́ na, ati ohun-èlo gbogbo, ati sara awọn enia ti o wá nibẹ̀, ati sara ẹniti o fọwọkàn egungun kan, tabi ẹnikan ti a pa, tabi ẹnikan ti o kú, tabi isà-okú: 19 Ki ẹniti o mọ́ na ki o si bùwọ́n alaimọ́ na ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje: ati ni ijọ́ keje ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́; ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omì, yio si di mimọ́ li aṣalẹ. 20 Ṣugbọn ẹniti o ba jẹ́ alaimọ́, ti kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ, nitoriti o bà ibi-mimọ́ OLUWA jẹ́: a kò si ta omi ìyasapakan si i lara; alaimọ́ li on. 21 Yio si ma jẹ́ ìlana lailai fun wọn, pe ẹniti o ba bú omi ìyasapakan wọ́n ẹni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀; ati ẹniti o si fọwọkàn omi ìyasapakan na yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 22 Ati ohunkohun ti ẹni aimọ́ na ba si farakàn, yio jẹ́ alaimọ́; ọkàn ti o ba si farakàn a, yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

Numeri 20

Ohun Tí Ó Ṣẹlẹ̀ ní Kadeṣi

1 AWỌN ọmọ Israeli si wá, ani gbogbo ijọ, si aginjù Sini li oṣù kini: awọn enia na si joko ni Kadeṣi; Miriamu si kú nibẹ̀, a si sin i nibẹ̀. 2 Omi kò si sí fun ijọ: nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni. 3 Awọn enia si mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Awa iba kuku ti kú nigbati awọn arakunrin wa kú niwaju OLUWA! 4 Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú ijọ OLUWA wá si aginjù yi, ki awa ati ẹran wá ki o kú nibẹ̀? 5 Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke ti Egipti wá, lati mú wa wá si ibi buburu yi? ki iṣe ibi irugbìn, tabi ti ọpọtọ, tabi ti àjara, tabi ti pomegranate; bẹ̃ni kò sí omi lati mu. 6 Mose ati Aaroni si lọ kuro niwaju ijọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, nwọn si doju wọn bolẹ: ogo OLUWA si hàn si wọn. 7 OLUWA si sọ fun Mose pe, 8 Mú ọpá nì, ki o si pe ijọ awọn enia jọ, iwọ, ati Aaroni arakunrin rẹ, ki ẹ sọ̀rọ si apata nì li oju wọn, yio si tú omi rẹ̀ jade; iwọ o si mú omi lati inu apata na jade fun wọn wá: iwọ o si fi fun ijọ ati fun ẹran wọn mu. 9 Mose si mú ọpá na lati iwaju OLUWA lọ, bi o ti fun u li aṣẹ. 10 Mose ati Aaroni si pe ijọ awọn enia jọ niwaju apata na, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin gbọ̀ nisisiyi, ẹnyin ọlọtẹ; ki awa ki o ha mú omi lati inu apata yi fun nyin wá bi? 11 Mose si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o si fi ọpá rẹ̀ lù apata na lẹ̃meji: omi si tú jade li ọ̀pọlọpọ, ijọ awọn enia si mu, ati ẹran wọn pẹlu. 12 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nitoriti ẹnyin kò gbà mi gbọ́, lati yà mi simimọ́ loju awọn ọmọ Israeli, nitorina ẹnyin ki yio mú ijọ awọn enia yi lọ si ilẹ na ti mo fi fun wọn. 13 Wọnyi li omi Meriba; nitoriti awọn ọmọ Israeli bá OLUWA sọ̀, o si di ẹni ìya-simimọ́ ninu wọn.

Ọba Edomu kò Jẹ́ kí Àwọn Ọmọ Israẹli Kọjá

14 Mose si rán onṣẹ lati Kadeṣi si ọba Edomu, wipe, Bayi ni Israeli arakunrin rẹ wi, Iwọ sá mọ̀ gbogbo ìrin ti o bá wa: 15 Bi awọn baba wa ti sọkalẹ lọ si Egipti, ti awa si ti gbé Egipti ni ìgba pipẹ; awọn ara Egipti si ni wa lara, ati awọn baba wa: 16 Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ: 17 Jẹ ki awa ki o là ilẹ rẹ kọja lọ, awa bẹ̀ ọ: awa ki yio là inu oko rẹ, tabi inu ọgbà-àjara, bẹ̃li awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li awa o gbà, awa ki o yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ. 18 Edomu si wi fun u pe, Iwọ ki yio kọja lọdọ mi, ki emi ki o má ba jade si ọ ti emi ti idà. 19 Awọn ọmọ Israeli si wi fun u pe, Ọ̀na opópo ọba li awa o gbà: bi awa ba mu ninu omi rẹ, emi ati ẹran mi, njẹ emi o san owo rẹ̀: laiṣe ohun miran, ki nsá fi ẹsẹ̀ mi là ilẹ kọja. 20 O si wipe, Iwọ ki yio là ilẹ kọja. Edomu si mú ọ̀pọ enia jade tọ̀ ọ wá pẹlu ọwọ́ agbara. 21 Bẹ̃li Edomu kọ̀ lati fi ọ̀na fun Israeli li àgbegbe rẹ̀: Israeli si ṣẹri kuro lọdọ rẹ̀.

Ikú Aaroni

22 Awọn ọmọ Israeli, ani gbogbo ijọ si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si wá si òke Hori. 23 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni li òke Hori li àgbegbe ilẹ Edomu wipe, 24 A o kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on ki yio wọ̀ inu ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli, nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi, nibi omi Meriba. 25 Mú Aaroni ati Eleasari ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá si ori-òke Hori: 26 Ki o si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, ki o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀: a o si kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀, yio si kú nibẹ̀. 27 Mose si ṣe bi OLUWA ti fun u li aṣẹ: nwọn si gòke lọ si ori òke Hori li oju gbogbo ijọ. 28 Mose si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀; Aaroni si kú nibẹ̀ li ori òke na: Mose ati Eleasari si sọkalẹ lati ori òke na wá. 29 Nigbati gbogbo ijọ ri pe Aaroni kú, nwọn ṣọfọ Aaroni li ọgbọ̀n ọjọ́, ani gbogbo ile Israeli.

Numeri 21

Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Kenaani

1 Ẹni ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha Gusù, gbọ́ pe Israeli gbà ọ̀na amí yọ; nigbana li o bá Israeli jà, o si mú ninu wọn ni igbekun. 2 Israeli si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, wipe, Bi iwọ ba fi awọn enia yi lé mi lọwọ nitõtọ, njẹ emi o run ilu wọn patapata. 3 OLUWA si gbọ́ ohùn Israeli, o si fi awọn ara Kenaani tọrẹ, nwọn si run wọn patapata, ati ilu wọn: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Horma.

Ejò Idẹ

4 Nwọn si rìn lati òke Hori lọ li ọ̀na Okun Pupa, lati yi ilẹ Edomu ká: sũru si tán awọn enia na pupọ̀pupọ nitori ọ̀na na. 5 Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa. 6 OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú. 7 Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na. 8 OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè. 9 Mose si rọ ejò idẹ kan, o si fi i sori ọpá-gigùn na: o si ṣe, pe bi ejò kan ba bù enia kan ṣan, nigbati o ba wò ejò idẹ na, on a yè.

Láti Òkè Hori sí Àfonífojì Moabu

10 Awọn ọmọ Israeli si ṣi siwaju, nwọn si dó ni Obotu. 11 Nwọn si ṣi lati Obotu lọ, nwọn si dó si Iye-abarimu, li aginjù ti mbẹ niwaju Moabu, ni ìha ìla-õrùn. 12 Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si afonifoji Seredi. 13 Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori. 14 Nitorina ni a ṣe wi ninu iwé Ogun OLUWA pe, Ohun ti o ṣe li Okun Pupa, ati li odò Arnoni. 15 Ati ni iṣàn-odò nì ti o darí si ibujoko Ari, ti o si gbè ipinlẹ Moabu. 16 Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Beeri: eyinì ni kanga eyiti OLUWA sọ fun Mose pe, Pe awọn enia jọ, emi o si fun wọn li omi. 17 Nigbana ni Israeli kọrin yi pe: Sun jade iwọ kanga; ẹ ma kọrin si i: 18 Kanga na, ti awọn olori wà, ti awọn ọlọlá awọn enia si fi ọpá-alade na, ati ọpá wọn wà. Ati lati aginjù na, nwọn lọ si Mattana. 19 Ati Mattana nwọn lọ si Nahalieli: ati lati Nahalieli nwọn lọ si Bamotu: 20 Ati lati Bamotu li afonifoji nì, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, si óke Pisga, ti o si kọjusi aginjù.

Ìṣẹ́gun lórí Ọba Sihoni ati Ọba Ogu

21 Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, wipe, 22 Jẹ ki emi là ilẹ rẹ kọja lọ: awa ki yio yà sinu oko, tabi ọgba-àjara; awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li a o gbà, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ. 23 Sihoni kò si jẹ ki Israeli ki o là àgbegbe rẹ̀ kọja: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo awọn enia rẹ̀ jọ, nwọn si jade tọ̀ Israeli lọ li aginjù, o si wá si Jahasi, o bá Israeli jà. 24 Israeli si fi oju idà kọlù u, o si gbà ilẹ rẹ̀ lati Arnoni lọ dé Jaboku, ani dé ti awọn ọmọ Ammoni; nitoripe ipinlẹ ti awọn ọmọ Ammoni lí agbara. 25 Israeli si gbà gbogbo ilunla wọnni: Israeli si joko ninu gbogbo ilunla ti awọn ọmọ Amori, ni Heṣboni, ati ni ilu rẹ̀ gbogbo. 26 Nitoripe Heṣboni ni ilunla Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ẹniti o ti bá ọba Moabu atijọ jà, ti o si gbà gbogbo ilẹ rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, titi dé Arnoni. 27 Nitorina awọn ti nkọrin owe a ma wipe, Wá si Heṣboni, jẹ ki a tẹ̀ ilunla Sihoni dó ki a si tun fi idi rẹ̀ mulẹ: 28 Nitoriti iná kan ti Heṣboni jade lọ, ọwọ́-iná kan lati ilunla Sihoni: o si run Ari ti Moabu, ati awọn oluwa ibi giga Arnoni. 29 Egbé ni fun iwọ, Moabu! Ẹ gbé, ẹnyin enia Kemoṣi: on ti fi awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bi isansa, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin bi igbekun, fun Sihoni ọba awọn ọmọ Amori. 30 Awa tafà si wọn; Heṣboni ṣegbé titi dé Diboni, awa si ti run wọn titi dé Nofa, ti o dé Medeba. 31 Bẹ̃li awọn ọmọ Israeli joko ni ilẹ awọn ọmọ Amori. 32 Mose si rán enia lọ ṣe amí Jaseri, nwọn si gbà ilu rẹ̀, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà nibẹ̀. 33 Nwọn si yipada, nwọn si gòke lọ li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade tọ̀ wọn lọ, on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, si ogun ni Edrei. 34 OLUWA si wi fun Mose pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe mo ti fi on lé ọ lọwọ, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀; ki iwọ ki o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni. 35 Bẹ̃ni nwọn si kọlù u, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, titi kò fi kù ọkan silẹ fun u lãye: nwọn si gbà ile rẹ̀.

Numeri 22

Ọba Moabu Ranṣẹ Pe Balaamu

1 AWỌN ọmọ Israeli si ṣí, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu li apa keji Jordani ti o kọjusi Jeriko. 2 Balaki ọmọ Sippori si ri gbogbo eyiti Israeli ti ṣe si awọn ọmọ Amori. 3 Moabu si bẹ̀ru awọn enia na gidigidi, nitoriti nwọn pọ̀: aisimi si bá Moabu nitori awọn ọmọ Israeli. 4 Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na. 5 O si ránṣẹ si Balaamu ọmọ Beori si Petori, ti o wà lẹba Odò, si ilẹ awọn ọmọ enia rẹ̀, lati pè e wá, wipe, Wò o, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá: si kiyesi i, nwọn bò oju ilẹ, nwọn si joko tì mi: 6 Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú. 7 Ati awọn àgba Moabu, ati awọn àgba Midiani dide lọ ti awọn ti ọrẹ ìbere-afọṣẹ li ọwọ́ wọn; nwọn si tọ̀ Balaamu wá, nwọn si sọ ọ̀rọ Balaki fun u. 8 O si wi fun wọn pe, Ẹ wọ̀ nihin li alẹ yi, emi o si mú ọ̀rọ pada tọ̀ nyin wá, bi OLUWA yio ti sọ fun mi: awọn ijoye Moabu si wọ̀ sọdọ Balaamu. 9 Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá, o si wipe, Awọn ọkunrin wo ni wọnyi lọdọ rẹ? 10 Balaamu si wi fun Ọlọrun pe, Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, li o ranṣẹ si mi pe, 11 Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ. 12 Ọlọrun si wi fun Balaamu pe, Iwọ kò gbọdọ bá wọn lọ; iwọ kò gbọdọ fi awọn enia na bú: nitoripe ẹni ibukún ni nwọn. 13 Balaamu si dide li owurọ̀, o si wi fun awọn ijoye Balaki pe, Ẹ ma ba ti nyin lọ si ilẹ nyin: nitoriti OLUWA kọ̀ lati jẹ ki mbá nyin lọ. 14 Awọn ijoye Moabu si dide, nwọn si tọ̀ Balaki lọ, nwọn si wipe, Balaamu kọ̀ lati bá wa wá. 15 Balaki si tun rán awọn ijoye si i, ti o si lí ọlá jù wọn lọ. 16 Nwọn tọ̀ Balaamu wá, nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Balaki ọmọ Sippori wi pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki ohun kan ki o di ọ lọwọ lati tọ̀ mi wá: 17 Nitoripe, emi o sọ ọ di ẹni nla gidigidi, emi o si ṣe ohunkohun ti iwọ wi fun mi: nitorina wá, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi. 18 Balaamu si dahùn o si wi fun awọn iranṣẹ Balaki pe, Balaki iba fẹ́ fun mi ni ile rẹ̀ ti o kún fun fadaká ati wurà, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun mi, lati ṣe ohun kekere tabi nla. 19 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ nyin, ẹ wọ̀ nihin pẹlu li oru yi, ki emi ki o le mọ̀ eyiti OLUWA yio wi fun mi si i. 20 Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá li oru, o si wi fun u pe, Bi awọn ọkunrin na ba wá pè ọ, dide, bá wọn lọ; ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o ṣe. 21 Balaamu si dide li owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si bá awọn ijoye Moabu lọ.

Balaamu ati Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Rẹ̀

22 Ibinu Ọlọrun si rú nitoriti o lọ: angeli OLUWA si duro loju ọ̀na lati di i lọ̀na. Njẹ on gùn kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, awọn iranṣẹ rẹ̀ mejeji si wà pẹlu rẹ̀. 23 Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ na si yà kuro loju ọ̀na, o si wọ̀ inu igbẹ́: Balaamu si lù kẹtẹkẹtẹ na, lati darí rẹ̀ soju ọ̀na. 24 Nigbana ni angeli OLUWA duro li ọna toro ọgbà-àjara meji, ogiri mbẹ ni ìha ihin, ati ogiri ni ìha ọhún. 25 Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o fún ara rẹ̀ mọ́ ogiri, o si fún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ogiri: on si tun lù u. 26 Angeli OLUWA si tun sun siwaju, o si tun duro ni ibi tõro kan, nibiti àye kò sí lati yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi. 27 Nigbati kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o wólẹ̀ labẹ Balaamu: ibinu Balaamu si rú pupọ̀, o si fi ọpá lu kẹtẹkẹtẹ na. 28 OLUWA si là kẹtẹkẹtẹ na li ohùn, o si wi fun Balaamu pe, Kini mo fi ṣe ọ, ti iwọ fi lù mi ni ìgba mẹta yi? 29 Balaamu si wi fun kẹtẹkẹtẹ na pe, Nitoriti iwọ fi mi ṣẹsin: idà iba wà li ọwọ́ mi, nisisiyi li emi iba pa ọ. 30 Kẹtẹkẹtẹ na si wi fun Balaamu pe, Kẹtẹkẹtẹ rẹ ki emi ṣe, ti iwọ ti ngùn lati ìgba ti emi ti ṣe tirẹ titi di oni? emi a ha ma ṣe si ọ bẹ̃ rí? On si dahùn wipe, Ndao. 31 Nigbana ni OLUWA là Balaamu li oju, o si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: o si tẹ̀ ori ba, o si doju rẹ̀ bolẹ. 32 Angeli OLUWA si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi lù kẹtẹkẹtẹ rẹ ni ìgba mẹta yi? Kiyesi i, emi jade wá lati di ọ lọ̀na, nitori ọ̀na rẹ lòdi niwaju mi. 33 Kẹtẹkẹtẹ na si ri mi, o si yà fun mi ni ìgba mẹta yi: bikoṣe bi o ti yà fun mi, pipa ni emi iba pa ọ, emi a si dá on si. 34 Balaamu si wi fun angeli OLUWA pe, Emi ti ṣẹ̀; nitori emi kò mọ̀ pe iwọ duro dè mi li ọ̀na; njẹ bi kò ba ṣe didùn inu rẹ, emi o pada. 35 Angeli OLUWA si wi fun Balaamu pe, Ma bá awọn ọkunrin na lọ: ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o sọ. Bẹ̃ni Balaamu bá awọn ijoye Balaki lọ.

Balaki Lọ Pàdé Balaamu

36 Nigbati Balaki gbọ́ pe Balaamu dé, o jade lọ ipade rẹ̀ si Ilu Moabu, ti mbẹ ni àgbegbe Arnoni, ti iṣe ipẹkun ipinlẹ na. 37 Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi kò ha ranṣẹ kanjukanju si ọ lati pè ọ? ẽṣe ti iwọ kò fi tọ̀ mi wá? emi kò ha to lati sọ ọ di ẹni nla? 38 Balaamu si wi fun Balaki pe, Kiyesi i, emi tọ̀ ọ wá: emi ha lí agbara kan nisisiyi rára lati wi ohun kan? ọ̀rọ ti OLUWA fi si mi li ẹnu, on li emi o sọ. 39 Balaamu si bá Balaki lọ, nwọn si wá si Kiriati-husotu. 40 Balaki si rubọ akọmalu ati agutan, o si ranṣẹ si Balaamu, ati si awọn ijoye ti mbẹ pẹlu rẹ̀. 41 O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Balaki mú Balaamu, o si mú u wá si ibi giga Baali, ki o ba le ri apakan awọn enia na lati ibẹ̀ lọ.

Numeri 23

Àsọtẹ́lẹ̀ Àkọ́kọ́ tí Balaamu Sọ

1 BALAAMU si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọ-malu meje, ati àgbo meje fun mi nihin. 2 Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi; ati Balaki ati Balaamu fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. 3 Balaamu si wi fun Balaki pe, Duro tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ; bọya OLUWA yio wá pade mi: ohunkohun ti o si fihàn mi emi o wi fun ọ. O si lọ si ibi giga kan. 4 Ọlọrun si pade Balaamu: o si wi fun u pe, Emi ti pèse pẹpẹ meje silẹ, mo si ti fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. 5 OLUWA si fi ọ̀rọ si Balaamu li ẹnu, o si wipe, Pada tọ̀ Balaki lọ, bayi ni ki iwọ ki o si sọ. 6 O si pada tọ̀ ọ lọ, si kiyesi i, on duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, on ati gbogbo awọn ijoye Moabu. 7 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré. 8 Emi o ti ṣe fibú, ẹniti Ọlọrun kò fibú? tabi emi o si ti ṣe firé, ẹniti OLUWA kò firé? 9 Nitoripe lati ori apata wọnni ni mo ri i, ati lati òke wọnni ni mo wò o: kiyesi i, awọn enia yi yio dágbé, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède. 10 Tali o le kà erupẹ Jakobu, ati iye idamẹrin Israeli? Jẹ ki emi ki o kú ikú olododo, ki igbẹhin mi ki o si dabi tirẹ̀! 11 Balaki si wi fun Balaamu pe, Kini iwọ nṣe si mi yi? mo mú ọ wá lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i, iwọ si sure fun wọn patapata. 12 On si dahùn o si wipe, Emi ha le ṣe aiṣọra lati sọ eyiti OLUWA fi si mi li ẹnu bi?

Àsọtẹ́lẹ̀ Keji tí Balaamu Sọ

13 Balaki si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bá mi lọ si ibomiran, lati ibiti iwọ o le ri wọn; kìki apakan wọn ni iwọ o ri, iwọ ki yio si ri gbogbo wọn tán; ki o si fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ. 14 O si mú u wá si igbẹ Sofimu sori òke Pisga, o si mọ pẹpẹ meje, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. 15 On si wi fun Balaki pe, Duro nihin tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ ipade OLUWA lọhùn yi. 16 OLUWA si pade Balaamu, o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu, wipe, Tun pada tọ̀ Balaki lọ, ki o si wi bayi. 17 O si tọ̀ ọ wá, kiyesi i, o duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, ati awọn ijoye Moabu pẹlu rẹ̀. Balaki si bi i pe, Kini OLUWA sọ? 18 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Dide, Balaki, ki o si gbọ́; ki o si fetisi mi, iwọ ọmọ Sipporu: 19 Ọlọrun ki iṣe enia ti yio fi ṣeké; bẹ̃ni ki iṣe ọmọ enia ti yio fi ronupiwada: a ma wi, ki o má si ṣe bi? tabi a ma sọ̀rọ ki o má mu u ṣẹ? 20 Kiyesi i, emi gbà aṣẹ ati sure: on si ti sure, emi kò si le yì i. 21 On kò ri ẹ̀ṣẹ ninu Jakobu, bẹ̃ni kò ri ibi ninu Israeli: OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ihó-ayọ ọba si mbẹ ninu wọn. 22 Ọlọrun mú wọn lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere. 23 Nitõtọ kò sí ìfaiya si Jakobu, bẹ̃ni kò sí afọṣẹ si Israeli: nisisiyi li a o ma wi niti Jakobu ati niti Israeli, Ohun ti Ọlọrun ṣe! 24 Kiyesi i, awọn enia na yio dide bi abokiniun, yio si gbé ara rẹ̀ soke bi kiniun: on ki yio dubulẹ titi yio fi jẹ ohun ọdẹ, titi yio si fi mu ninu ẹ̀jẹ ohun pipa. 25 Balaki si wi fun Balaamu pe, Kuku má fi wọn bú, bẹ̃ni ki o máṣe sure fun wọn rára. 26 Ṣugbọn Balaamu dahún, o si wi fun Balaki pe, Emi kò ha ti wi fun ọ pe, Gbogbo eyiti OLUWA ba sọ, on ni emi o ṣe?

Àsọtẹ́lẹ̀ Kẹta Tí Balaamu Sọ

27 Balaki si wi fun Balaamu pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, emi o mú ọ lọ si ibomiran; bọya yio wù Ọlọrun ki iwọ ki o fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ. 28 Balaki si mú Balaamu wá sori òke Peoru, ti o kọjusi aginjù. 29 Balaamu si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọmalu meje ati àgbo meje fun mi nihin. 30 Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.

Numeri 24

1 NIGBATI Balaamu ri pe o wù OLUWA lati bukún Israeli, on kò lọ mọ́ bi ìgba iṣaju, lati wá ìfaiya, ṣugbọn o doju rẹ̀ kọ aginjù. 2 Balaamu si gbé oju rẹ̀ soke o si ri Israeli dó gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; ẹmi Ọlọrun si wá sara rẹ̀. 3 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ sí nwi: 4 Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o nri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ ṣí. 5 Jakobu, agọ́ rẹ wọnyi ti dara tó, ati ibugbé rẹ iwọ Israeli! 6 Bi afonifoji ni nwọn tẹ́ lọ bẹrẹ, bi ọgbà lẹba odònla, bi igi aloe ti OLUWA gbìn, ati bi igi kedari lẹba omi. 7 Omi o ṣàn jade lati inu agbè rẹ̀ wá, irú rẹ̀ yio si wà ninu omi pupọ̀, ọba rẹ̀ yio si ga jù Agagi lọ, ijọba rẹ̀ li a o si gbeleke. 8 Ọlọrun mú u lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere: on o jẹ awọn orilẹ-ède ti iṣe ọtá rẹ̀ run, yio si fọ́ egungun wọn, yio si fi ọfà rẹ̀ ta wọn li atapoyọ. 9 O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú. 10 Ibinu Balaki si rú si Balaamu, o si fi ọwọ́ lù ọwọ́ pọ̀: Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi pè ọ lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i iwọ si súre fun wọn patapata ni ìgba mẹta yi. 11 Njẹ nisisiyi sálọ si ibujoko rẹ: emi ti rò lati sọ ọ di ẹni nla; ṣugbọn kiyesi i, OLUWA fà ọ sẹhin kuro ninu ọlá. 12 Balaamu si wi fun Balaki pe, Emi kò ti sọ fun awọn onṣẹ rẹ pẹlu ti iwọ rán si mi pe, 13 Bi Balaki tilẹ fẹ́ lati fi ile rẹ̀ ti o kún fun fadakà ati wurá fun mi, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA, lati ṣe rere tabi buburu lati inu ara mi wá; ṣugbọn eyiti OLUWA wi, eyina li emi o sọ?

Àsọtẹ́lẹ̀ Ìkẹyìn tí Balaamu Sọ

14 Njẹ nisisiyi si kiyesi i, emi nlọ sọdọ awọn enia mi: wá, emi o si sọ fun ọ ohun ti awọn enia yi yio ṣe si awọn enia rẹ li ẹhin-ọla. 15 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ ṣí nwi: 16 Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o si mọ̀ imọ̀ Ọga-Ogo, ti o ri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ si ṣí: 17 Emi ri i, ṣugbọn ki iṣe nisisiyi: emi si wò o, ṣugbọn kò sunmọtosi: irawọ kan yio ti inu Jakobu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israeli dide, yio si kọlù awọn igun Moabu, yio si ṣẹ́ gbogbo awọn ọmọ irọkẹ̀kẹ. 18 Edomu yio si di iní, Seiri pẹlu yio si di iní, fun awọn ọtá rẹ̀; Israeli yio si ṣe iṣe-agbara. 19 Lati inu Jakobu li ẹniti yio ní ijọba yio ti jade wá, yio si run ẹniti o kù ninu ilunla. 20 Nigbati o si wò Amaleki, o si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Amaleki ni ekini ninu awọn orilẹ-ède; ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ ni ki o ṣegbé. 21 O si wò awọn ara Keni, o si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Agbara ni ibujoko rẹ̀, iwọ si tẹ́ itẹ́ rẹ sinu okuta. 22 Ṣugbọn a o run awọn ara Keni, titi awọn ara Aṣṣuri yio kó o lọ ni igbekùn. 23 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, A, tani yio wà, nigbati Ọlọrun yio ṣe eyi! 24 Awọn ọkọ̀ yio ti ebute Kittimu wá, nwọn o si pọn Aṣṣuri loju, nwọn o si pọn Eberi loju, on pẹlu yio si ṣegbé. 25 Balaamu si dide, o si lọ o si pada si ibujoko rẹ̀; Balaki pẹlu si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.

Numeri 25

Àwọn Ọmọ Israẹli ní Peori

1 ISRAELI si joko ni Ṣittimu, awọn enia na si bẹ̀rẹsi iṣe panṣaga pẹlu awọn ọmọbinrin Moabu: 2 Nwọn si pe awọn enia na si ẹbọ oriṣa wọn; awọn enia na si jẹ, nwọn si tẹriba fun oriṣa wọn. 3 Israeli si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Baali-peoru: ibinu OLUWA si rú si Israeli. 4 OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú gbogbo awọn olori awọn enia na, ki o si so wọn rọ̀ si õrùn niwaju OLUWA, ki imuna ibinu OLUWA ki o le yipada kuro lọdọ Israeli. 5 Mose si wi fun awọn onidajọ Israeli pe, Ki olukuluku nyin ki o pa awọn enia rẹ̀ ti o dàpọ mọ́ Baali-peoru. 6 Si kiyesi i, ọkan ninu awọn ọmọ Israeli wá o si mú obinrin Midiani kan tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ wá li oju Mose, ati li oju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ti nsọkun ni ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 7 Nigbati Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ri i, o dide lãrin ijọ, o si mú ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀; 8 O si tọ̀ ọkunrin Israeli na lọ ninu agọ́, o si fi gún awọn mejeji li agunyọ, ọkunrin Israeli na, ati obinrin na ni inu rẹ̀. Àrun si da lãrin awọn ọmọ Israeli. 9 Awọn ti o si kú ninu àrun na jẹ́ ẹgba mejila. 10 OLUWA si sọ fun Mose pe, 11 Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ti yi ibinu mi pada kuro lara awọn ọmọ Israeli, nipa itara rẹ̀ nitori mi lãrin wọn, ki emi ki o máṣe run awọn ọmọ Israeli ninu owú mi. 12 Nitorina wipe, Kiyesi i, emi fi majẹmu alafia mi fun u. 13 Yio jẹ́ tirẹ̀ ati ti irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ani majẹmu iṣẹ-alufa titi-aiye; nitoriti o ṣe itara fun Ọlọrun rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli. 14 Njẹ orukọ ọkunrin Israeli na ti a pa, ani ti a pa pẹlu obinrin Midiani na, a ma jẹ́ Simri, ọmọ Salu, olori ile kan ninu awọn ọmọ Simeoni. 15 Orukọ obinrin Midiani na ti a pa a si ma jẹ́ Kosbi, ọmọbinrin Suru; ti iṣe olori awọn enia kan, ati ti ile kan ni Midiani. 16 OLUWA si sọ fun Mose pe, 17 Yọ awọn ara Midiani lẹnu, ki o si kọlù wọn. 18 Nitoriti nwọn fi ẹ̀tan wọn yọ nyin lẹnu, eyiti nwọn tàn nyin niti ọ̀ran Peori, ati niti ọ̀ran Kosbi, ọmọ ijoye Midiani kan, arabinrin wọn, ẹniti a pa li ọjọ́ àrun nì niti ọ̀ran Peori.

Numeri 26

Ètò Ìkànìyàn Keji

1 O SI ṣe lẹhin àrun na, ni OLUWA sọ fun Mose ati fun Eleasari alufa ọmọ Aaroni pe, 2 Kà iye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, gbogbo awọn ti o le lọ si ogun ni Israeli. 3 Mose ati Eleasari alufa si sọ fun wọn ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, lẹba Jordani leti Jeriko pe, 4 Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá. 5 Reubeni, akọ́bi Israeli: awọn ọmọ Reubeni; Hanoki, lati ọdọ ẹniti idile awọn ọmọ Hanoki ti wá: ti Pallu, idile awọn ọmọ Pallu: 6 Ti Hesroni, idile awọn ọmọ Hesroni: ti Karmi, idile awọn ọmọ Karmi. 7 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Reubeni: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanlelogun o le ẹgbẹsan o din ãdọrin. 8 Ati awọn ọmọ Pallu; Eliabu. 9 Ati awọn ọmọ Eliabu; Nemueli, ati Datani, ati Abiramu. Eyi ni Datani ati Abiramu na, ti nwọn lí okiki ninu ijọ, ti nwọn bá Mose ati Aaroni jà ninu ẹgbẹ Kora, nigbati nwọn bá OLUWA jà. 10 Ti ilẹ si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì pọ̀ pẹlu Kora, nigbati ẹgbẹ na fi kú, nigbati iná fi run awọn ãdọtalerugba ọkunrin, ti nwọn si di àmi kan. 11 Ṣugbọn awọn ọmọ Kora kò kú. 12 Awọn ọmọ Simeoni bi idile wọn: ti Nemueli, idile Nemueli: ti Jamini, idile Jamini: ti Jakini, idile Jakini: 13 Ti Sera, idile Sera: ti Ṣaulu, idile Ṣaulu. 14 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Simeoni, ẹgba mọkanla o le igba. 15 Awọn ọmọ Gadi bi idile wọn: ti Sefoni, idile Sefoni: ti Haggi, idile Haggi: ti Ṣuni, idile Ṣuni: 16 Ti Osni, idile Osni: ti Eri, idile Eri: 17 Ti Arodu, idile Arodu: ti Areli, idile Areli. 18 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. 19 Awọn ọmọ Juda, ni Eri ati Onani: ati Eri ati Onani kú ni ilẹ Kenaani. 20 Ati awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn; ti Ṣela, idile Ṣela: ti Peresi, idile Peresi: ti Sera, idile Sera. 21 Awọn ọmọ Peresi; ti Hesroni, idile Hesroni: ti Hamulu, idile Hamulu. 22 Wọnyi ni idile Juda gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejidilogoji o le ẹdẹgbẹta. 23 Awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn: ti Tola, idile Tola: ti Pufa, idile Pufa: 24 Ti Jaṣubu, idile Jaṣubu: ti Ṣimroni, idile Ṣimroni. 25 Wọnyi ni idile Issakari gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le ọdunrun. 26 Awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: ti Seredi, idile Seredi: ti Eloni, idile Eloni: ti Jaleeli, idile Jaleeli. 27 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ mẹta o le ẹdẹgbẹta. 28 Awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn: Manasse ati Efraimu. 29 Awọn ọmọ Manasse: ti Makiri, idile Makiri: Makiri si bi Gileadi: ti Gileadi, idile awọn ọmọ Gileadi. 30 Wọnyi li awọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, idile Ieseri: ti Heleki, idile Heleki: 31 Ati ti Asrieli, idile Asrieli: ati ti Ṣekemu, idile Ṣekemu: 32 Ati Ṣemida, idile awọn ọmọ Ṣemida: ati ti Heferi, idile awọn ọmọ Heferi. 33 Selofehadi ọmọ Heferi kò si lí ọmọkunrin, bikọse ọmọbinrin: orukọ awọn ọmọbinrin Selofehadi a ma jẹ Mala, ati Noa, ati Hogla, Milka, ati Tirsa. 34 Wọnyi ni idile Manasse, ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin. 35 Wọnyi li awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣutela, idile awọn ọmọ Ṣutela: ti Bekeri, idile awọn ọmọ Bekeri: ti Tahani, idile awọn ọmọ Tahani. 36 Wọnyi li awọn ọmọ Ṣutela: ti Erani, idile awọn ọmọ Erani. 37 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le ẹdẹgbẹta. Wọnyi li awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn. 38 Awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ti Bela, idile awọn ọmọ Bela: ti Aṣbeli, idile awọn ọmọ Aṣbeli: ti Ahiramu, idile awọn ọmọ Ahiramu. 39 Ti Ṣefamu, idile awọn ọmọ Ṣufamu: ti Hufamu, idile awọn ọmọ Hufamu. 40 Awọn ọmọ Bela si ni Ardi ati Naamani: ti Ardi, idile awọn ọmọ Ardi: ati ti Naamani, idile awọn ọmọ Naamani. 41 Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ẹgbẹjọ. 42 Wọnyi li awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣuhamu, idile awọn ọmọ Ṣuhamu. Wọnyi ni idile Dani gẹgẹ bi idile wọn. 43 Gbogbo idile awọn ọmọ Ṣuhamu, gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le irinwo. 44 Ti awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn: ti Imna, idile awọn ọmọ Imna: ti Iṣfi, idile awọn ọmọ Iṣfi: ti Beria, idile awọn ọmọ Beria. 45 Ti awọn ọmọ Beria: ti Heberi, idile awọn ọmọ Heberi: ti Malkieli, idile awọn ọmọ Malkieli. 46 Orukọ ọmọ Aṣeri obinrin a si ma jẹ́ Sera. 47 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn; nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje. 48 Ti awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn: ti Jaseeli, idile awọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, idile awọn ọmọ Guni: 49 Ti Jeseri, idile awọn ọmọ Jeseri: ti Ṣillemu, idile awọn ọmọ Ṣillemu. 50 Wọnyi ni idile ti Naftali gẹgẹ bi idile wọn: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le egbeje. 51 Wọnyi li a kà ninu awọn ọmọ Israeli, ọgbọ̀n ọkẹ, o le ẹgbẹsan o din ãdọrin. 52 OLUWA si sọ fun Mose pe, 53 Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ. 54 Fun awọn ti o pọ̀ ni ki iwọ ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun awọn ti o kére ni ki iwọ ki o fi diẹ fun: ki a fi ilẹ-iní olukuluku fun u gẹgẹ bi iye awọn ti a kà ninu rẹ̀. 55 Ṣugbọn kèké li a o fi pín ilẹ na: gẹgẹ bi orukọ ẹ̀ya awọn baba wọn ni ki nwọn ki o ní i. 56 Gẹgẹ bi kèké ni ki a pín ilẹ-iní na lãrin awọn pupọ̀ ati diẹ. 57 Wọnyi si li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi idile wọn: ti Gerṣoni, idile awọn ọmọ Gerṣoni: ti Kohati, idile awọn ọmọ Kohati: ti Merari, idile awọn ọmọ Merari. 58 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Lefi: idile awọn ọmọ Libni, idile awọn ọmọ Hebroni, idile awọn ọmọ Mali, idile awọn ọmọ Muṣi, idile awọn ọmọ Kora. Kohati si bi Amramu. 59 Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu. 60 Ati fun Aaroni li a bi Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari. 61 Ati Nadabu ati Abihu kú, nigbati nwọn mú iná ajeji wá siwaju OLUWA. 62 Awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanla o le ẹgbẹrun, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan ati jù bẹ̃ lọ: nitoripe a kò kà wọn kún awọn ọmọ Israeli, nitoriti a kò fi ilẹ-iní fun wọn ninu awọn ọmọ Israeli. 63 Wọnyi li awọn ti a kà lati ọwọ́ Mose ati Eleasari alufa wá, awọn ẹniti o kà awọn ọmọ Israeli ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko. 64 Ṣugbọn ninu wọnyi kò sì ọkunrin kan ninu awọn ti Mose ati Aaroni alufa kà, nigbati nwọn kà awọn ọmọ Israeli li aginjù Sinai. 65 Nitoriti OLUWA ti wi fun wọn pe, Kíku ni nwọn o kú li aginjù. Kò si kù ọkunrin kan ninu wọn, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni.

Numeri 27

Àwọn Ọmọbinrin Selofehadi

1 NIGBANA ni awọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile Manasse ọmọ Josefu wá: wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀; Mala, Noa, ati Hogla, ati Milka, ati Tirsa. 2 Nwọn si duro niwaju Mose, ati niwaju Eleasari alufa, ati niwaju awọn olori ati gbogbo ijọ, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, wipe, 3 Baba wa kú li aginjù, on kò si sí ninu ẹgbẹ awọn ti o kó ara wọn jọ pọ̀ si OLUWA ninu ẹgbẹ Kora: ṣugbọn o kú ninu ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀; kò si lí ọmọkunrin. 4 Ẽhaṣe ti orukọ, baba wa yio fi parẹ kuro ninu idile rẹ̀, nitoriti kò lí ọmọkunrin? Fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin baba wa. 5 Mose si mú ọ̀ran wọn wá siwaju OLUWA. 6 OLUWA si sọ fun Mose pe, 7 Awọn ọmọbinrin Selofehadi sọ rere: nitõtọ, fun wọn ni ilẹ-iní kan lãrin awọn arakunrin baba wọn; ki iwọ ki o si ṣe ki ilẹ-iní baba wọn ki o kọja sọdọ wọn. 8 Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkunrin kan ba kú, ti kò si lí ọmọkunrin, njẹ ki ẹnyin ki o ṣe ki ilẹ-iní rẹ̀ ki o kọja sọdọ ọmọbinrin rẹ̀. 9 Bi on kò ba si lí ọmọbinrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-ini rẹ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀. 10 Bi on kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun awọn arakunrin baba rẹ̀: 11 Bi baba rẹ̀ kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun ibatan rẹ̀, ti o sunmọ ọ ni idile rẹ̀, on ni ki o jogún rẹ̀: yio si jasi ìlana idajọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Yíyan Joṣua láti Rọ́pò Mose

12 OLUWA si sọ fun Mose pe, Gùn ori òke Abarimu yi lọ, ki o si wò ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli. 13 Nigbati iwọ ba ri i tán, a o si kó iwọ jọ pẹlu awọn enia rẹ, gẹgẹ bi a ti kó Aaroni arakunrin rẹ jọ. 14 Nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi li aginjù Sini, ni ìja ijọ, lati yà mi simimọ́ ni ibi omi nì niwaju wọn. (Wọnyi li omi Meriba ni Kadeṣi li aginjù Sini.) 15 Mose si sọ fun OLUWA pe, 16 Jẹ ki OLUWA, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ki o yàn ọkunrin kan sori ijọ, 17 Ti yio ma ṣaju wọn jade lọ, ti yio si ma ṣaju wọn wọle wá, ti yio si ma sìn wọn lọ, ti yio si ma mú wọn bọ̀; ki ijọ enia OLUWA ki o máṣe dabi agutan ti kò lí oluṣọ. 18 OLUWA si sọ fun Mose pe, Iwọ mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkunrin ninu ẹniti ẹmi wà, ki o si fi ọwọ́ rẹ lé e lori; 19 Ki o si mu u duro niwaju Eleasari alufa, ati niwaju gbogbo ijọ; ki o si fi aṣẹ fun u li oju wọn. 20 Ki iwọ ki o si fi ninu ọlá rẹ si i lara, ki gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli ki o le gbà a gbọ́. 21 Ki on si duro niwaju Eleasari alufa, ẹniti yio bère fun u nipa idajọ Urimu niwaju OLUWA: nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o jade lọ, ati nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o wọle, ati on, ati gbogbo awọn ọmọ Israeli pẹlu rẹ̀, ani gbogbo ijọ. 22 Mose si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o si mú Joṣua, o si mu u duro niwaju Eleasari alufa, ati niwaju gbogbo ijọ: 23 O si fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori, o si fi aṣẹ fun u, bi OLUWA ti wi lati ọwọ́ Mose.

Numeri 28

Ẹbọ Àtìgbàdégbà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ọrẹ-ẹbọ mi, ati àkara mi fun ẹbọ mi ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si mi, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati mú fun mi wá li akokò wọn. 3 Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Eyi li ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti ẹnyin o ma múwa fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku li ojojumọ́, fun ẹbọ sisun igbagbogbo. 4 Ọdọ-agutan kan ni ki iwọ ki o fi rubọ li owurọ̀, ati ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ; 5 Ati idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro gigún pò. 6 Ẹbọ sisun igbagbogbo ni, ti a ti lanasilẹ li òke Sinai fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 7 Ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ki o jẹ́ idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: ni ibi-mimọ ni ki iwọ da ọti lile nì silẹ fun OLUWA fun ẹbọ ohunmimu. 8 Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ: bi ẹbọ ohunjijẹ ti owurọ̀, ati bi ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ni ki iwọ ki o ṣe, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

Ẹbọ Ọjọ́ Ìsinmi

9 Ati li ọjọ́-isimi akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀: 10 Eyi li ẹbọ sisun ọjọjọ́ isimi, pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 11 Ati ni ìbẹrẹ òṣu nyin ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun kan si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku; 12 Ati idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun akọmalu kan, fun ẹbọ ohunjijẹ; ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun àgbo kan, fun ẹbọ ohunjijẹ: 13 Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun ọdọ-agutan kan fun ẹbọ ohunjijẹ; fun ẹbọ sisun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 14 Ki ẹbọ ohunmimu wọn ki o jẹ́ àbọ òṣuwọn hini ti ọti-waini fun akọmalu kan, ati idamẹta òṣuwọn hini fun àgbo kan, ati idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: eyi li ẹbọ sisun oṣuṣù ni gbogbo oṣù ọdún. 15 A o si fi obukọ kan ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ si OLUWA; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

Ẹbọ Àjọ̀dún Àjọ Àìwúkàrà

16 Ati li ọjọ́ kẹrinla oṣù kini, ni irekọja OLUWA. 17 Ati li ọjọ́ kẹdogun oṣù na yi li ajọ: ni ijọ́ meje ni ki a fi jẹ àkara alaiwu. 18 Li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: 19 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ kan ti a fi iná ṣe, ẹbọ sisun si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdun kan: ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin. 20 Ẹbọ ohunjijẹ wọn iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn ni ki ẹnyin ki o múwa fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo na. 21 Ati idamẹwa òṣuwọn ni ki iwọ ki o múwa fun ọdọ-agutan kan, fun gbogbo ọdọ-agutan mejeje; 22 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, lati ṣètutu fun nyin. 23 Ki ẹnyin ki o mú wọnyi wá pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀, ti iṣe ti ẹbọ sisun igbagbogbo. 24 Bayi ni ki ẹnyin rubọ li ọjọjọ́, jalẹ ni ijọ́ mejeje, onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: ki a ru u pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 25 Ati ni ijọ́ keje ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.

Ẹbọ Àjọ̀dún Ìkórè

26 Li ọjọ́ akọ́so pẹlu, nigbati ẹnyin ba mú ẹbọ ohunjijẹ titun wá fun OLUWA, lẹhin ọsẹ̀ nyin wọnni, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: 27 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu meji, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan, ru ẹbọ sisun fun õrùn didùn si OLUWA; 28 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, 29 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje; 30 Ati obukọ kan, lati ṣètutu fun nyin. 31 Ki ẹnyin ki o ru wọn pẹlu ẹbọ sisun igba-gbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ (ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin), ati ẹbọ ohunmimu wọn.

Numeri 29

Ẹbọ Àjọ̀dún Ọdún Titun

1 ATI li oṣù keje, li ọjọ́ kini oṣù na ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: ọjọ́ ifunpe ni fun nyin. 2 Ki ẹnyin ki o si fi ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku ru ẹbọ sisun fun õrùn didùn si OLUWA: 3 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, 4 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje: 5 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, lati ṣètutu fun nyin; 6 Pẹlu ẹbọ sisun oṣù, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn, gẹgẹ bi ìlana wọn, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

Ẹbọ Ọjọ́ Ètùtù

7 Ki ẹnyin ki o si ní apejọ mimọ́ ni ijọ́ kẹwa oṣù keje na yi; ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan: 8 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun si OLUWA fun õrùn didùn; ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan; ki nwọn ki o si jẹ́ alailabùku fun nyin: 9 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji ọsuwọn fun àgbo kan, 10 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje: 11 Obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn. 12 Ati ni ijọ́ kẹdogun oṣù keje, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje: 13 Ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ sisun kan, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu mẹtala, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan; ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku: 14 Ati ẹbọ ohun-jijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, bẹ̃ni fun akọmalu mẹtẹtala, idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, bẹ̃ni fun àgbo mejeji, 15 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mẹrẹrinla: 16 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 17 Ati ni ijọ́ keji ni ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo meji, ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku rubọ: 18 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 19 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn. 20 Ati ni ijọ́ kẹta akọmalu mọkanla, àgbo meji, akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku; 21 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 22 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 23 Ati ni ijọ́ kẹrin akọmalu mẹwa, àgbo meji, ati ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku: 24 Ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 25 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 26 Ati ni ijọ́ karun akọmalu mẹsan, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku: 27 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 28 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 29 Ati ni ijọ́ kẹfa akọmalu mẹjọ, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku: 30 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 31 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 32 Ati ni ijọ́ keje akọmalu meje, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku: 33 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 34 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 35 Ni ijọ́ kẹjọ ki ẹnyin ki o ní ajọ ti o ni ironu: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan. 36 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku: 37 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 38 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 39 Ẹbọ wọnyi ni ki ẹnyin ki o ru si OLUWA li ajọ nyin, pẹlu ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ọrẹ-atinuwa nyin, fun ẹbọ sisun nyin, ati fun ẹbọ ohunjijẹ nyin, ati fun ẹbọ ohun mimu nyin, ati fun ẹbọ alafia nyin. 40 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ fun Mose.

Numeri 30

Ìlànà nípa Ẹ̀jẹ́ Jíjẹ́

1 MOSE si sọ fun awọn olori awọn ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ. 2 Bi ọkunrin kan ba jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, tabi ti o ba bura lati fi dè ara rẹ̀ ni ìde, ki on ki o máṣe bà ọ̀rọ rẹ̀ jẹ; ki on ki o ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ẹnu rẹ̀ jade. 3 Bi obinrin kan pẹlu ba si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, ti o si dè ara rẹ̀ ni ìde, ni ile baba rẹ̀ ni ìgba ewe rẹ̀; 4 Ti baba rẹ̀ si gbọ́ ẹjẹ́ rẹ̀, ati ìde rẹ̀ ti o fi dè ara rẹ̀, ti baba rẹ̀ ba si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i; njẹ ki gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ki o duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro. 5 Ṣugbọn bi baba rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; kò sí ọkan ninu ẹjẹ́ rẹ̀, tabi ninu ìde ti o fi dè ara rẹ̀, ti yio duro: OLUWA yio si darijì i, nitoriti baba rẹ̀ kọ̀ fun u. 6 Bi o ba si kúku li ọkọ, nigbati o jẹ́ ẹjẹ́, tabi ti o sọ̀rọ kan lati ẹnu rẹ̀ jade, ninu eyiti o fi dè ara rẹ̀ ni ìde; 7 Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ẹjẹ́ rẹ̀ yio duro, ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro. 8 Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ on o mu ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́ ati ohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade, eyiti o fi dè ara rẹ̀ dasan: OLUWA yio si darijì i. 9 Ṣugbọn gbogbo ẹjẹ́ opó, ati ti obinrin ti a kọ̀silẹ, ti nwọn fi dè ara wọn, yio wà lọrùn rẹ̀. 10 Bi o ba si jẹjẹ́ ni ile ọkọ rẹ̀, tabi ti o si fi ibura dè ara rẹ̀ ni ìde, 11 Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i, ti kò si kọ̀ fun u: njẹ gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ni yio duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro. 12 Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba sọ wọn dasan patapata li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ohunkohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade nipasẹ̀ ẹjẹ́ rẹ̀, tabi nipasẹ̀ ìde ọkàn rẹ̀, ki yio duro: ọkọ rẹ̀ ti sọ wọn dasan; OLUWA yio si darijì i. 13 Gbogbo ẹjẹ́ ati ibura ìde lati fi pọ́n ara loju, ọkọ rẹ̀ li o le mu u duro, o si le sọ ọ dasan. 14 Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i patapata lati ọjọ́ dé ọjọ́; njẹ o fi mu gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ duro, tabi gbogbo ìde rẹ̀ ti mbẹ lara rẹ̀; o mu wọn duro, nitoriti o pa ẹnu rẹ̀ mọ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́. 15 Ṣugbọn bi o ba sọ wọn dasan, lẹhin igbati o gbọ́; njẹ on ni yio rù ẹ̀ṣẹ obinrin na. 16 Wọnyi ni ìlana ti OLUWA palaṣẹ fun Mose, lãrin ọkunrin ati aya rẹ̀, lãrin baba ati ọmọbinrin rẹ̀, ti iṣe ewe ninu ile baba rẹ̀.

Numeri 31

Wọ́n Dojú Ogun Mímọ́ kọ Midiani

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Gbẹsan awọn ọmọ Israeli lara awọn ara Midiani: lẹhin eyinì ni a o kó ọ jọ pẹlu awọn enia rẹ. 3 Mose si sọ fun awọn enia na pe, Ki ninu nyin ki o hamọra ogun, ki nwọn ki o si tọ̀ awọn ara Midiani lọ, ki nwọn ki o si gbẹsan OLUWA lara Midiani. 4 Ninu ẹ̀ya kọkan ẹgbẹrun enia, ni gbogbo ẹ̀ya Israeli, ni ki ẹnyin ki o rán lọ si ogun na. 5 Bẹ̃ni nwọn si yàn ninu awọn ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ẹgbẹrun enia ninu ẹ̀ya kọkan, ẹgba mẹfa enia ti o hamọra ogun. 6 Mose si rán wọn lọ si ogun na, ẹgbẹrun enia ninu ẹ̀ya kọkan, awọn ati Finehasi ọmọ Eleasari alufa si ogun na, ti on ti ohunèlo ibi-mimọ́, ati ipè wọnni li ọwọ́ rẹ̀ lati fun. 7 Nwón si bá awọn ara Midiani jà, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose; nwọn si pa gbogbo awọn ọkunrin. 8 Nwọn si pa awọn ọba Midiani, pẹlu awọn iyokù ti a pa; eyinì ni Efi, ati Rekemu, ati Suru, ati Huri, ati Reba, ọba Midiani marun: Balaamu ọmọ Beoru ni nwọn si fi idà pa. 9 Awọn ọmọ Israeli si mú gbogbo awọn obinrin Midiani ni igbẹsin, ati awọn ọmọ kekere wọn, nwọn si kó gbogbo ohunọ̀sin wọn, ati gbogbo agboẹran wọn, ati gbogbo ẹrù wọn. 10 Nwọn si fi iná kun gbogbo ilu wọn ninu eyiti nwọn ngbé, ati gbogbo ibudó wọn. 11 Nwọn si kó gbogbo ikogun wọn, ati gbogbo ohun-iní, ati enia ati ẹran. 12 Nwọn si kó igbẹsin, ati ohun-iní, ati ikogun na wá sọdọ Mose, ati Eleasari alufa, ati sọdọ ijọ awọn ọmọ Israeli, si ibudó ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, ti mbẹ lẹba Jordani leti Jeriko.

Àwọn Ọmọ Ogun Pada Wálé

13 Ati Mose, ati Eleasari alufa, ati gbogbo awọn olori ijọ, jade lọ ipade wọn lẹhin ibudó. 14 Mose si binu si awọn olori ogun na, pẹlu awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati balogun ọrọrún, ti o ti ogun na bọ̀. 15 Mose si wi fun wọn pe, Ẹ da gbogbo awọn obinrin si? 16 Kiyesi i, nipaṣe ọ̀rọ Balaamu awọn wọnyi li o mu awọn ọmọ Israeli dẹ̀ṣẹ si OLUWA niti ọ̀ran Peori, ti àrun si fi wà ninu ijọ OLUWA. 17 Njẹ nitorina, ẹ pa gbogbo ọkunrin ninu awọn ọmọ wẹ́wẹ, ki ẹ si pa gbogbo awọn obinrin ti o ti mọ̀ ọkunrin nipa ibá dapọ̀. 18 Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọbinrin kekeké ti nwọn kò mọ̀ ọkunrin nipa ibá dapọ̀, ni ki ẹnyin dasi fun ara nyin. 19 Ki ẹnyin ki o si duro lẹhin ibudó ni ijọ meje: ẹnikẹni ti o ba pa enia, ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ẹniti a pa, ki ẹnyin si wẹ̀ ara nyin mọ́, ati ara awọn igbẹsin nyin ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje. 20 Ki ẹnyin si fọ̀ gbogbo aṣọ nyin mọ́, ati gbogbo ohun ti a fi awọ ṣe, ati ohun gbogbo iṣẹ irun ewurẹ, ati ohun gbogbo ti a fi igi ṣe. 21 Eleasari alufa si wi fun awọn ologun ti nwọn lọ si ogun na pe, Eyi ni ilana ofin ti OLUWA filelẹ li aṣẹ fun Mose. 22 Kìki wurà, ati fadakà, ati idẹ ati irin, ati tanganran, ati ojé, 23 Gbogbo ohun ti o le kọja ninu iná, ni ki ẹnyin ki o mu là iná já yio si di mimọ́; ṣugbọn a o fi omi ìyasapakan wẹ̀ ẹ mọ́: ati gbogbo ohun ti kò le kọja ninu iná ni ki a mu là inu omi. 24 Ki ẹnyin ki o si fọ̀ aṣọ nyin ni ijọ́ keje, ẹnyin o si di mimọ́, lẹhin eyinì li ẹnyin o si wá sinu ibudó.

Pípín Ìkógun

25 OLUWA si sọ fun Mose pe, 26 Kà iye ikogun ti a kó, ti enia ati ti ẹran, iwọ ati Eleasari alufa, ati awọn olori ile baba ijọ: 27 Ki o si pín ikogun na si ipa meji; lãrin awọn ologun, ti o jade lọ si ogun na, ati lãrin gbogbo ijọ. 28 Ki o si gbà ohun idá ti OLUWA lọwọ awọn ologun ti nwọn jade lọ si ogun na: ọkan ninu ẹdẹgbẹta, ninu awọn enia, ati ninu malu, ati ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran: 29 Gbà a ninu àbọ ti wọn, ki o si fi i fun Eleasari alufa, fun ẹbọ igbesọsoke OLUWA. 30 Ati ninu àbọ ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, ki iwọ ki o si gbà ipín kan ninu ãdọta, ninu enia, ninu malu, ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran, ninu onirũru ẹran, ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA. 31 Ati Mose ati Eleasari alufa si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 32 Ati ikogun ti o kù ninu ohun-iní ti awọn ologun kó, o jẹ́ ọkẹ mẹrinlelọgbọ̀n o din ẹgbẹdọgbọ̀n agutan, 33 Ẹgba mẹrindilogoji malu, 34 Ọkẹ mẹta o le ẹgbẹrun kẹtẹkẹtẹ, 35 Ati enia ninu awọn obinrin ti kò mọ̀ ọkunrin nipa ibá dàpọ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun. 36 Ati àbọ ti iṣe ipín ti awọn ti o jade lọ si ogun, o jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan ni iye: 37 Idá ti OLUWA ninu agutan wọnni jẹ́ ẹdẹgbẹrin o din mẹdọgbọ̀n. 38 Ati malu jẹ́ ẹgba mejidilogun; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ mejilelãdọrin. 39 Kẹtẹkẹtẹ si jẹ́ ẹgba mẹdogun o le ẹdẹgbẹta; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgọta o le ọkan. 40 Awọn enia si jẹ́ ẹgba mẹjọ; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgbọ̀n o le meji. 41 Mose si fi idá ti ẹbọ igbesọsoke OLUWA fun Eleasari alufa, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 42 Ati ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, ti Mose pín kuro ninu ti awọn ọkunrin ti o jagun na, 43 (Njẹ àbọ ti ijọ jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan, 44 Ati ẹgba mejidilogun malu. 45 Ati ẹgba mẹdogun o le ẹdẹgbẹta kẹtẹkẹtẹ. 46 Ati ẹgba mẹjọ enia;) 47 Ani ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, Mose mú ipín kan ninu ãdọta, ati ti enia ati ti ẹran, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 48 Ati awọn olori ti o wà lori ẹgbẹgbẹrun ogun na, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati awọn balogun ọrọrún, wá sọdọ Mose: 49 Nwọn si wi fun Mose pe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kà iye awọn ologun, ti mbẹ ni itọju wa, ọkunrin kan ninu wa kò si din. 50 Nitorina li awa ṣe mú ọrẹ-ebọ wá fun OLUWA, ohunkohun ti olukuluku ri, ohun ọ̀ṣọ wurà, ẹ̀wọn, ati jufù, ati oruka-àmi, ati oruka-etí, ati ìlẹkẹ, lati fi ṣètutu fun ọkàn wa niwaju OLUWA. 51 Mose ati Eleasari alufa si gbà wurà na lọwọ wọn, ani gbogbo ohun-iṣẹ ọsọ́. 52 Ati gbogbo wurà ẹbọ igbesọsoke ti nwọn múwa fun OLUWA, lati ọdọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lati ọdọ awọn balogun ọrọrún, o jẹ́ ẹgba mẹjọ o le ẹdẹgbẹrin o le ãdọta ṣekeli. 53 (Nitoripe awọn ologun ti kó ẹrù, olukuluku fun ara rẹ̀.) 54 Mose ati Eleasari alufa si gbà wurà na lọwọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lọwọ awọn balogun ọrọrún nwọn si mú u wá sinu agọ́ ajọ, ni iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA.

Numeri 32

Àwọn Ẹ̀yà Ìlà Oòrùn Jọdani

1 NJẸ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ní ọ̀pọlọpọ ohunọ̀sin: nwọn si ri ilẹ Jaseri, ati ilẹ Gileadi, si kiyesi i, ibẹ̀ na, ibi ohunọ̀sin ni; 2 Awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni si wá, nwọn si sọ fun Mose, ati fun Eleasari alufa ati fun awọn olori ijọ pe, 3 Atarotu, ati Diboni, ati Jaseri, ati Nimra, ati Heṣboni, ati Eleale, ati Ṣebamu, ati Nebo, ati Beoni. 4 Ilẹ na ti OLUWA ti kọlù niwaju ijọ Israeli, ilẹ ohunọ̀sin ni, awa iranṣẹ rẹ si ní ohunọ̀sin. 5 Nwọn si wipe, Bi awa ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, jẹ ki a fi ilẹ yi fun awọn iranṣẹ rẹ fun ilẹ-iní; ki o má si ṣe mú wa gòke Jordani lọ. 6 Mose si wi fun awọn ọmọ Gadi ati fun awọn ọmọ Reubeni pe, Awọn arakunrin nyin yio ha lọ si ogun, ki ẹnyin ki o si joko nihinyi? 7 Ẽṣe ti ẹnyin fi ntán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju ati rekọja lọ sinu ilẹ ti OLUWA fi fun wọn? 8 Bẹ̃li awọn baba nyin ṣe, nigbati mo rán wọn lati Kadeṣi-barnea lọ lati wò ilẹ na. 9 Nitoripe nigbati nwọn gòke lọ dé afonifoji Eṣkolu, ti nwọn si ri ilẹ na, nwọn tán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju, ki nwọn ki o má le lọ sinu ilẹ ti OLUWA ti fi fun wọn. 10 Ibinu Ọlọrun si rú si wọn nigbana, o si bura, wipe, 11 Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti o gòke lati Egipti wá, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ki yio ri ilẹ na ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu: nitoriti nwọn kò tẹle mi lẹhin patapata. 12 Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne ọmọ Kenissi, ati Joṣua ọmọ Nuni: nitoripe awọn li o tẹle OLUWA lẹhin patapata. 13 Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si mu wọn rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, titi gbogbo iran na, ti o ṣe buburu li oju OLUWA fi run. 14 Si kiyesi i, ẹnyin dide ni ipò baba nyin, iran ẹ̀lẹṣẹ, lati mu ibinu gbigbona OLUWA pọ̀ si i si Israeli. 15 Nitoripe bi ẹnyin ba yipada kuro lẹhin rẹ̀, on o si tun fi wọn silẹ li aginjù; ẹnyin o si run gbogbo awọn enia yi. 16 Nwọn si sunmọ ọ wipe, Awa o kọ́ ile-ẹran nihinyi fun ohunọ̀sin wa, ati ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ wa: 17 Ṣugbọn awa tikala wa yio di ihamọra wa giri, niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa o fi mú wọn dé ipò wọn: awọn ọmọ wẹ́wẹ wa yio si ma gbé inu ilu olodi nitori awọn ara ilẹ na. 18 Awa ki yio pada bọ̀ si ile wa, titi olukuluku awọn ọmọ Israeli yio fi ní ilẹ-iní rẹ̀. 19 Nitoripe awa ki yio ní ilẹ-iní pẹlu wọn ni ìha ọhún Jordani, tabi niwaju: nitoriti awa ní ilẹ-iní wa ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla õrùn. 20 Mose si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin o ba ṣe eyi; bi ẹnyin o ba di ihamọra niwaju OLUWA lọ si ogun, 21 Bi gbogbo nyin yio ba gòke Jordani ni ihamora niwaju OLUWA, titi yio fi lé awọn ọtá rẹ̀ kuro niwaju rẹ̀, 22 Ti a o si fi ṣẹ́ ilẹ na niwaju OLUWA: lẹhin na li ẹnyin o pada, ẹnyin o si jẹ́ àlailẹṣẹ niwaju OLUWA, ati niwaju Israeli; ilẹ yi yio si ma jẹ́ iní nyin niwaju OLUWA. 23 Ṣugbọn bi ẹnyin ki yio ba ṣe bẹ̃, kiyesi i, ẹnyin dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ki o si dá nyin loju pe, ẹ̀ṣẹ nyin yio fi nyin hàn. 24 Ẹ kọ́ ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ati agbo fun agutan nyin; ki ẹ si ṣe eyiti o ti ẹnu nyin jade wa. 25 Awọn ọmọ Gadi, ati awọn Reubeni si sọ fun Mose pe, Awọn iranṣẹ rẹ yio ṣe bi oluwa mi ti fi aṣẹ lelẹ. 26 Awọn ọmọ wẹ́wẹ wa, ati awọn aya wa, agbo-ẹran wa, ati gbogbo ohunọsìn wa yio wà nibẹ̀ ni ilu Gileadi: 27 Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ yio gòke odò, olukuluku ni ihamọra ogun, niwaju OLUWA lati jà, bi oluwa mi ti wi. 28 Mose si paṣẹ fun Eleasari alufa, ati fun Joṣua ọmọ Nuni, ati fun awọn olori ile baba awọn ẹ̀ya ọmọ Israeli, nipa ti wọn. 29 Mose si wi fun wọn pe, Bi awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni yio ba bá nyin gòke Jordani lọ, olukuluku ni ihamọra fun ogun, niwaju OLUWA, ti a si ṣẹ́ ilẹ na niwaju nyin; njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ Gileadi fun wọn ni iní: 30 Ṣugbọn bi nwọn kò ba fẹ́ ba nyin gòke odò ni ihamọra, njẹ ki nwọn ki o ní iní lãrin nyin ni ilẹ Kenaani. 31 Ati awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni dahùn, wipe, Bi OLUWA ti wi fun awọn iranṣẹ rẹ, bẹ̃li awa o ṣe. 32 Awa o gòke lọ ni ihamọra niwaju OLUWA si ilẹ Kenaani, ki iní wa ni ìha ihin Jordani ki o le jẹ́ ti wa. 33 Mose si fi ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ati ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani fun wọn, ani fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse ọmọ Josefu, ilẹ na, pẹlu ilu rẹ̀ li àgbegbe rẹ̀, ani ilu ilẹ na yiká. 34 Awọn ọmọ Gadi si kọ́ Didoni, ati Atarotu, ati Aroeri; 35 Ati Atrotu-ṣofani, ati Jaseri, ati Jogbeha; 36 Ati Beti-nimra, ati Beti-harani, ilu olodi, ati agbo fun agutan. 37 Awọn ọmọ Reubeni si kọ́ Heṣboni, ati Eleale, ati Kiriataimu. 38 Ati Nebo, ati Baali-meoni, (nwọn pàrọ orukọ wọn,) ati Sibma: nwọn si sọ ilu ti nwọn kọ́ li orukọ miran. 39 Awọn ọmọ Makiri ọmọ Manase si lọ si Gileadi, nwọn si gbà a, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà ninu rẹ̀. 40 Mose si fi Gileadi fun Makiri ọmọ Manase; o si joko ninu rẹ̀. 41 Jairi ọmọ Manasse, si lọ, o si gbà awọn ilu wọn, o si sọ wọn ni Haffotu-jairi. 42 Noba si lọ, o si gbà Kenati, ati awọn ileto rẹ̀, o si sọ ọ ni Noba, nipa orukọ ara rẹ̀.

Numeri 33

Ìrìn Àjò láti Ijipti sí Moabu

1 WỌNYI ni ìrin awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá pẹlu awọn ogun wọn, nipa ọwọ́ Mose ati Aaroni. 2 Mose si kọwe ijadelọ wọn gẹgẹ bi ìrin wọn, nipa aṣẹ OLUWA; wọnyi si ni ìrin wọn gẹgẹ bi ijadelọ wọn. 3 Nwọn si ṣí kuro ni Ramesesi li oṣù kini, ni ijọ́ kẹdogun oṣù kini na; ni ijọ́ keji ajọ irekọja li awọn ọmọ Israeli jade pẹlu ọwọ́ giga li oju gbogbo awọn ara Egipti. 4 Bi awọn ara Egipti ti nsinkú gbogbo awọn akọ́bi wọn ti OLUWA kọlù ninu wọn: lara awọn oriṣa wọn pẹlu li OLUWA ṣe idajọ. 5 Awọn ọmọ Israeli si ṣí kuro ni Ramesesi, nwọn si dó si Sukkotu. 6 Nwọn si ṣí kuro ni Sukkotu, nwọn si dó si Etamu, ti mbẹ leti aginjù. 7 Nwọn si ṣí kuro ni Etamu, nwọn si pada lọ si Pi-hahirotu, ti mbẹ niwaju Baali-sefoni: nwọn si dó siwaju Migdolu. 8 Nwọn si ṣí kuro niwaju Hahirotu, nwọn si là ãrin okun já lọ si aginjù: nwọn si rìn ìrin ijọ́ mẹta li aginjù Etamu, nwọn si dó si Mara. 9 Nwọn si ṣí kuro ni Mara, nwọn si wá si Elimu: ni Elimu ni orisun omi mejila, ati ãdọrin igi ọpẹ wà; nwọn si dó sibẹ̀. 10 Nwọn si ṣí kuro ni Elimu, nwọn si dó si ẹba Okun Pupa. 11 Nwọn si ṣí kuro li Okun Pupa, nwọn si dó si aginjù Sini. 12 Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sini, nwọn si dó si Dofka. 13 Nwọn si ṣí kuro ni Dofka, nwọn si dó si Aluṣi. 14 Nwọn si ṣí kuro ni Aluṣi, nwọn si dó si Refidimu, nibiti omi kò gbé sí fun awọn enia na lati mu. 15 Nwọn si ṣí kuro ni Refidimu, nwọn si dó si aginjù Sinai. 16 Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sinai, nwọn si dó si Kibrotu-hattaafa. 17 Nwọn si ṣí kuro ni Kibrotu-hattaafa, nwọn si dó si Haserotu. 18 Nwọn si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si Ritma. 19 Nwọn si ṣí kuro ni Ritma, nwọn si dó si Rimmon-peresi. 20 Nwọn si ṣí kuro ni Rimmon-peresi, nwọn si dó si Libna. 21 Nwọn si ṣí kuro ni Libna, nwọn si dó si Rissa. 22 Nwọn si ṣí kuro ni Rissa, nwọn si dó si Kehelata. 23 Nwọn si ṣí kuro ni Kehelata, nwọn si dó si òke Ṣeferi. 24 Nwọn si ṣí kuro ni òke Ṣeferi, nwọn si dó si Harada. 25 Nwọn si ṣí kuro ni Harada, nwọn si dó si Makhelotu. 26 Nwọn si ṣí kuro ni Makhelotu, nwọn si dó si Tahati. 27 Nwọn si ṣí kuro ni Tahati, nwọn si dó si Tera. 28 Nwọn si ṣí kuro ni Tera, nwọn si dó si Mitka. 29 Nwọn si ṣí kuro ni Mitka, nwọn si dó si Haṣmona. 30 Nwọn si ṣí kuro ni Haṣmona, nwọn si dó si Moserotu. 31 Nwọn si ṣí kuro ni Moserotu, nwọn si dó si Bene-jaakani. 32 Nwọn si ṣí kuro ni Bene-jaakani, nwọn si dó si Hori-haggidgadi. 33 Nwọn si ṣí kuro ni Hori-haggidgadi, nwọn si dó si Jotbata. 34 Nwọn si ṣí kuro ni Jotbata, nwọn si dó si Abrona. 35 Nwọn si ṣí kuro ni Abrona, nwọn si dó si Esion-geberi. 36 Nwọn si ṣí kuro ni Esion-geberi, nwọn si dó si aginjù Sini, (ti ṣe Kadeṣi), 37 Nwọn si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si dó si òke Hori, leti ilẹ Edomu. 38 Aaroni alufa si gùn òke Hori lọ nipa aṣẹ OLUWA, o si kú nibẹ̀, li ogoji ọdún lẹhin ti awọn ọmọ Israeli ti ilẹ Egipti jade wá, li ọjọ́ kini oṣù karun. 39 Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún o le mẹta nigbati o kú li òke Hori. 40 Ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha gusù ni ilẹ Kenaani, o gburó pe awọn ọmọ Israeli mbọ̀. 41 Nwọn si ṣí kuro ni òke Hori, nwọn si dó si Salmona. 42 Nwọn si ṣí ni Salmona, nwọn si dó si Punoni. 43 Nwọn si ṣí kuro ni Punoni, nwọn si dó si Obotu. 44 Nwọn si ṣí kuro ni Obotu, nwọn si dó si Iye-abarimu, li àgbegbe Moabu. 45 Nwọn si ṣí kuro ni Iyimu, nwọn si dó si Dibon-gadi. 46 Nwọn si ṣí kuro ni Dibon-gadi, nwọn si dó si Almon-diblataimu. 47 Nwọn si ṣí kuro ni Almon-diblataimu, nwọn si dó si òke Abarimu, niwaju Nebo. 48 Nwọn si ṣí kuro ni òke Abarimu, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko. 49 Nwọn si dó si ẹba Jordani, lati Beti-jeṣimotu titi dé Abeli-ṣittimu ni pẹtẹlẹ̀ Moabu.

Ìlànà Nípa Líla Odò Jọdani Kọjá

50 OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe, 51 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke odò Jordani si ilẹ Kenaani: 52 Nigbana ni ki ẹnyin ki o lé gbogbo awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; ki ẹnyin si run gbogbo aworán wọn, ki ẹnyin si run gbogbo ere didà wọn, ki ẹnyin si wó gbogbo ibi giga wọn palẹ: 53 Ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na, ki ẹnyin ki o si ma gbé inu rẹ̀: nitoripe mo ti fi ilẹ na fun nyin lati ní i. 54 Ki ẹnyin ki o si fi keké pín ilẹ na ni iní fun awọn idile nyin; fun ọ̀pọ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun diẹ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní diẹ fun: ki ilẹ-iní olukuluku ki o jẹ́ ibiti keké rẹ̀ ba bọ́ si; gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba nyin ni ki ẹnyin ki o ní i. 55 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni ìha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé. 56 Yio si ṣe, bi emi ti rò lati ṣe si wọn, bẹ̃ni emi o ṣe si nyin.

Numeri 34

Àwọn Ààlà Ilẹ̀ náà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, (eyi ni ilẹ ti yio bọ́ si nyin lọwọ ni iní, ani ilẹ Kenaani gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀,) 3 Njẹ ki ìha gusù nyin ki o jẹ́ ati aginjù Sini lọ titi dé ẹba Edomu, ati opinlẹ gusù nyin ki o jẹ́ lati opin Okun Iyọ̀ si ìha ìla-õrùn: 4 Ki opinlẹ nyin ki o si yí lati gusù wá si ìgoke Akrabbimu, ki o si kọja lọ si Sini: ati ijadelọ rẹ̀ ki o jẹ́ ati gusù lọ si Kadeṣi-barnea, ki o si dé Hasari-addari, ki o si kọja si Asmoni: 5 Ki opinlẹ rẹ̀ ki o si yiká lati Asmoni lọ dé odò Egipti, okun ni yio si jẹ́ opin rẹ̀. 6 Ati opinlẹ ìha ìwọ-õrùn, ani okun nla ni yio jẹ́ opin fun nyin: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ìwọ-õrùn fun nyin. 7 Eyi ni yio si jẹ́ opinlẹ ìha ariwa fun nyin: lati okun nla lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ òke Hori: 8 Lati òke Hori lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ ati wọ̀ Hamati; ijadelọ opinlẹ na yio si jẹ́ Sedadi: 9 Opinlẹ rẹ yio si dé Sifroni, ati ijadelọ rẹ̀ yio dé Hasari-enani: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ariwa nyin. 10 Ki ẹnyin ki o si sàmi si opinlẹ nyin ni ìha ìla-õrùn lati Hasari-enani lọ dé Ṣefamu: 11 Ki opinlẹ na ki o si ti Ṣefamu sọkalẹ lọ si Ribla, ni ìha ìla-õrùn Aini; ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ, ki o si dé ìha okun Kinnereti ni ìha ìla-õrùn. 12 Ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ si Jordani, ijadelọ rẹ̀ yio jẹ Okun Iyọ̀: eyi ni yio jẹ́ ilẹ nyin gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀ yiká kiri. 13 Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi ni ilẹ na ti ẹnyin o fi keké gbà ni iní, ti OLUWA paṣẹ lati fi fun ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya nì: 14 Fun ẹ̀ya awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi ile baba wọn, ati ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi ile baba wọn ti gbà; àbọ ẹ̀ya Manasse si ti gbà, ipín wọn: 15 Ẹ̀ya mejẽji ati àbọ ẹ̀ya nì ti gbà ipín wọn ni ìha ihin Jordani leti Jeriko, ni ìha gabasi, ni ìha ìla-õrùn.

Àwọn Olórí tí Yóo Pín Ilẹ̀ náà

16 OLUWA si sọ fun Mose pe, 17 Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin ti yio pín ilẹ na fun nyin: Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni. 18 Ki ẹnyin ki o si mú olori kan ninu ẹ̀ya kọkan, lati pín ilẹ na ni iní. 19 Orukọ awọn ọkunrin na si ni wọnyi: ni ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne. 20 Ati ni ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, Ṣemueli ọmọ Ammihudu. 21 Ni ẹ̀ya Benjamini, Elidadi ọmọ Kisloni. 22 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Dani, Bukki ọmọ Jogli. 23 Olori awọn ọmọ Josefu: ni ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse, Hannieli ọmọ Efodu: 24 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu, Kemueli ọmọ Ṣiftani. 25 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni, Elisafani ọmọ Parnaki. 26 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari, Paltieli ọmọ Assani. 27 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri, Ahihudu ọmọ Ṣelomi. 28 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali, Pedaheli ọmọ Ammihudu. 29 Awọn wọnyi li ẹniti OLUWA paṣẹ fun lati pín iní na fun awọn ọmọ Israeli ni ilẹ Kenaani.

Numeri 35

Àwọn Ìlú tí A Fún Àwọn Ọmọ Lefi

1 OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe, 2 Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o fi ilu fun awọn ọmọ Lefi ninu ipín ilẹ-iní wọn, lati ma gbé; ki ẹnyin ki o si fi ẹbẹba-ilu fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnni yi wọn ká. 3 Ki nwọn ki o ní ilu lati ma gbé; ati ẹbẹba-ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn, ati fun ohun-iní wọn, ati fun gbogbo ẹran wọn. 4 Ati ẹbẹba-ilu, ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, lati odi ilu lọ sẹhin rẹ̀ ki o jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ yiká. 5 Ki ẹnyin ki o si wọ̀n lati ẹhin ode ilu na lọ ni ìha ìla-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha gusù ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ariwa ẹgba igbọnwọ; ki ilu na ki o si wà lãrin. Eyi ni yio si ma ṣe ẹbẹba-ilu fun wọn. 6 Ati ninu ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, mẹfa o jẹ́ ilu àbo, ti ẹnyin o yàn fun aṣi-enia-pa, ki o le ma salọ sibẹ̀: ki ẹnyin ki o si fi ilu mejilelogoji kún wọn. 7 Gbogbo ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi ki o jẹ́ mejidilãdọta: wọnyi ni ki ẹnyin fi fun wọn pẹlu ẹbẹba wọn. 8 Ati ilu ti ẹnyin o fi fun wọn, ki o jẹ́ ninu ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli, lọwọ ẹniti o ní pupọ̀ lí ẹnyin o gbà pupọ̀; ṣugbọn lọwọ ẹniti o ní diẹ li ẹnyin o gbà diẹ: ki olukuluku ki o fi ninu ilu rẹ̀ fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilẹ-iní rẹ̀ ti o ní.

Àwọn Ìlú-Ààbò

9 OLUWA si sọ fun Mose pe, 10 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ Kenaani; 11 Nigbana ni ki ẹnyin ki o yàn ilu fun ara nyin ti yio jẹ́ ilu àbo fun nyin; ki apania ti o pa enia li aimọ̀ ki o le ma sa lọ sibẹ̀. 12 Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ. 13 Ati ninu ilu wọnyi ti ẹnyin o fi fun wọn, mẹfa yio jẹ́ ilu àbo fun nyin. 14 Ki ẹnyin ki o yàn ilu mẹta ni ìha ihin Jordani, ki ẹnyin ki o si yàn ilu mẹta ni ilẹ Kenaani, ti yio ma jẹ́ ilu àbo. 15 Ilu mẹfa wọnyi ni yio ma jẹ́ àbo fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ati fun atipo lãrin wọn: ki olukuluku ẹniti o ba pa enia li aimọ̀ ki o le ma salọ sibẹ̀. 16 Ṣugbọn bi o ba fi ohunèlo irin lù u, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na. 17 Ati bi o ba sọ okuta lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: a o pa apania na. 18 Tabi bi o ba fi ohun-èlo igi lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na. 19 Agbẹsan ẹ̀jẹ tikalarẹ̀ ni ki o pa apania na: nigbati o ba bá a, ki o pa a. 20 Ṣugbọn bi o ba ṣepe o fi irira gún u, tabi ti o ba sọ nkan lù u, lati ibuba wá, ti on si kú; 21 Tabi bi o nṣe ọtá, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ lù u, ti on si kú: ẹniti o lù u nì pipa li a o pa a; nitoripe apania li on: agbẹsan ẹ̀jẹ ni ki o pa apania na, nigbati o ba bá a. 22 Ṣugbọn bi o ba fi nkan gún u lojiji laiṣe ọtá, tabi ti o sọ ohunkohun lù u laiba dè e, 23 Tabi okuta kan li o sọ, nipa eyiti enia le fi kú, ti kò ri i, ti o si sọ ọ lù u, ti on si kú, ti ki ṣe ọtá rẹ̀, ti kò si wá ibi rẹ̀: 24 Nigbana ni ki ijọ ki o ṣe idajọ lãrin ẹniti o pa enia ati agbẹsan ẹ̀jẹ na, gẹgẹ bi idajọ wọnyi: 25 Ki ijọ ki o si gbà ẹniti o pani li ọwọ́ agbẹsan ẹ̀jẹ, ki ijọ ki o si mú u pada lọ si ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si: ki o si ma gbé ibẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa, ti a fi oróro mimọ́ yàn. 26 Ṣugbọn bi apania na ba ṣèṣi jade lọ si opinlẹ ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si; 27 Ti agbẹsan ẹ̀jẹ na si ri i lẹhin opinlẹ ilu àbo rẹ̀, ti agbẹsan ẹ̀jẹ si pa apania na; on ki yio jẹbi ẹ̀jẹ: 28 Nitoripe on iba joko ninu ilu àbo rẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa: ati lẹhin ikú olori alufa ki apania na ki o pada lọ si ilẹ iní rẹ̀. 29 Ohun wọnyi ni o si jẹ́ ìlana idajọ fun nyin ni iraniran nyin ni ibujoko nyin gbogbo. 30 Ẹnikẹni ti o ba pa enia, lati ẹnu awọn ẹlẹri wá li a o pa apania na: ṣugbọn ẹlẹri kanṣoṣo ki yio jẹri si ẹnikan lati pa a. 31 Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o máṣe gbà ohun-irasilẹ fun ẹmi apania, ti o jẹbi ikú: ṣugbọn pipa ni ki a pa a. 32 Ki ẹnyin ki o má si ṣe gbà ohun-irasilẹ fun ẹniti o salọ si ilu àbo rẹ̀, pe ki on ki o tun pada lọ ijoko ni ilẹ na, titi di ìgba ikú alufa. 33 Ẹnyin kò si gbọdọ bà ilẹ na jẹ́ ninu eyiti ẹnyin ngbé: nitoripe ẹ̀jẹ ama bà ilẹ jẹ́: a kò si le ṣètutu fun ilẹ nitori ẹ̀je ti a ta sinu rẹ̀, bikoṣe nipa ẹ̀jẹ ẹniti o ta a. 34 Iwọ kò si gbọdọ sọ ilẹ na di alaimọ́, ninu eyiti ẹnyin o joko, ninu eyiti emi ngbé: nitori Emi JEHOFA ni ngbé inu awọn ọmọ Israeli.

Numeri 36

Ogún Àwọn Obinrin Abilékọ

1 AWỌN baba àgba ti idile awọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile awọn ọmọ Josefu, sunmọtosi, nwọn si sọ niwaju Mose, ati niwaju awọn olori, awọn baba àgba awọn ọmọ Israeli: 2 Nwọn si wipe, OLUWA ti paṣẹ fun oluwa mi lati fi keké pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli ni iní: a si fi aṣẹ fun oluwa mi lati ọdọ OLUWA wá lati fi ilẹiní Selofehadi arakunrin wa fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin. 3 Bi a ba si gbé wọn niyawo fun ẹnikan ninu awọn ọmọkunrin ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli miran, nigbana ni a o gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní awọn baba wa, a o si fi kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà a kuro ninu ipín ilẹ-iní ti wa. 4 Ati nigbati ọdún jubeli awọn ọmọ Israeli ba dé, nigbana li a o fi ilẹ-iní wọn kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba wa. 5 Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, pe, Ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu fọ̀ rere. 6 Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ nipa ti awọn ọmọbinrin Selofehadi, wipe, Ki nwọn ki o ṣe aya ẹniti o wù wọn; kiki pe, ninu idile ẹ̀ya baba wọn ni ki nwọn ki o gbeyawo si. 7 Bẹ̃ni ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli ki yio yi lati ẹ̀ya de ẹ̀ya: nitori ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le faramọ́ ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba rẹ̀: 8 Ati gbogbo awọn ọmọbinrin, ti o ní ilẹ-iní ninu ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, ki o ṣe aya fun ọkan ninu idile ẹ̀ya baba rẹ̀, ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le ma jogún ilẹ-iní awọn baba rẹ̀. 9 Bẹ̃ni ki ilẹ-iní ki o máṣe yi lati ẹ̀ya kan lọ si ẹ̀ya keji; ṣugbọn ki olukuluku ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli ki o faramọ́ ilẹ-iní tirẹ̀. 10 Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe: 11 Nitoripe a gbé Mala, Tirsa, ati Hogla, ati Milka, ati Noa, awọn ọmọbinrin Selofehadi niyawo fun awọn ọmọ arakunrin baba wọn. 12 A si gbé wọn niyawo sinu idile awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu, ilẹ-ini wọn si duro ninu ẹ̀ya idile baba wọn. 13 Wọnyi ni aṣẹ ati idajọ ti OLUWA palaṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ọwọ́ Mose, ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.

Deuteronomi 1

Ìwé Karun-un Mose, tí à ń pè ní Diutaronomi

1 WỌNYI li ọ̀rọ ti Mose sọ fun gbogbo Israeli ni ìha ihin Jordani li aginjù, ni pẹtẹlẹ̀ ti o kọjusi Okun Pupa, li agbedemeji Parani, ati Tofeli, ati Labani, ati Haserotu, ati Disahabu. 2 Ijọ́ mọkanla ni lati Horebu wá li ọ̀na òke Seiri dé Kadeṣi-barnea. 3 O si ṣe nigbati o di ogoji ọdún, li oṣù kọkanla, li ọjọ́ kini oṣù na, ni Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fun u li aṣẹ fun wọn; 4 Lẹhin igbati o pa Sihoni tán ọba awọn ọmọ Amori, ti o ngbé Heṣboni, ati Ogu ọba Baṣani, ti o ngbé Aṣtarotu, ni Edrei: 5 Ni ìha ihin Jordani, ni ilẹ Moabu, on ni Mose bẹ̀rẹsi isọ asọye ofin yi, wipe, 6 OLUWA Ọlọrun wa sọ fun wa ni Horebu, wipe, Ẹ gbé ori òke yi pẹ to: 7 Ẹ yipada, ki ẹnyin si mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si lọ si òke awọn ọmọ Amori, ati si gbogbo àgbegbe rẹ̀, ni pẹtẹlẹ̀, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni ìha gusù, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati si Lebanoni, dé odò nla nì, odò Euferate. 8 Wò o, mo ti fi ilẹ na siwaju nyin: ẹ wọ̀ ọ lọ ki ẹ si gbà ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn lẹhin wọn.

Mose Yan Àwọn Adájọ́

9 Mo si sọ fun nyin ni ìgba na pe, Emi nikan kò le rù ẹrù nyin: 10 OLUWA Ọlọrun nyin ti mu nyin bisi i, si kiyesi i, li oni ẹnyin dabi irawọ oju-ọrun fun ọ̀pọ. 11 Ki OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin ki o fi kún iye nyin ni ìgba ẹgbẹrun, ki o si busi i fun nyin, bi o ti ṣe ileri fun nyin! 12 Emi o ti ṣe le nikan rù inira nyin, ati ẹrù nyin, ati ìja nyin? 13 Ẹ mú awọn ọkunrin ọlọgbọ́n wá, ati amoye, ati ẹniti a mọ̀ ninu awọn ẹ̀ya nyin, emi o si fi wọn jẹ olori nyin. 14 Ẹnyin si da mi li ohùn, ẹ si wipe, Ohun ti iwọ sọ nì, o dara lati ṣe. 15 Bẹ̃ni mo mú olori awọn ẹ̀ya nyin, awọn ọlọgbọ́n ọkunrin, ẹniti a mọ̀, mo si fi wọn jẹ olori nyin, olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwa-mẹwa, ati awọn olori gẹgẹ bi awọn ẹ̀ya nyin. 16 Mo si fi aṣẹ lelẹ fun awọn onidajọ nyin nigbana pe, Ẹ ma gbọ́ ẹjọ́ lãrin awọn arakunrin nyin, ki ẹ si ma ṣe idajọ ododo lãrin olukuluku ati arakunrin rẹ̀, ati alejò ti mbẹ lọdọ rẹ̀. 17 Ẹ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju ni idajọ; ẹ gbọ́ ti ewe gẹgẹ bi ti àgba; ẹ kò gbọdọ bẹ̀ru oju enia; nitoripe ti Ọlọrun ni idajọ: ọ̀ran ti o ba si ṣoro fun nyin, ẹ mú u tọ̀ mi wá, emi o si gbọ́ ọ. 18 Emi si fi aṣẹ ohun gbogbo ti ẹnyin o ma ṣe lelẹ fun nyin ni ìgba na.

Mose Rán Àwọn Amí láti Kadeṣi Banea Lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí

19 Nigbati awa si kuro ni Horebu, awa rìn gbogbo aginjù nla nì ti o ni ẹ̀ru já, ti ẹnyin ri li ọ̀na òke awọn ọmọ Amori, bi OLUWA Ọlọrun wa ti fun wa li aṣẹ; awa si wá si Kadeṣi-barnea. 20 Emi si wi fun nyin pe, Ẹnyin dé òke awọn ọmọ Amori na, ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa. 21 Wò o, OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi ilẹ na siwaju rẹ: gòke lọ, ki o si gbà a, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ ti wi fun ọ; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya máṣe fò ọ. 22 Gbogbo nyin si tọ̀ mi wá, ẹ si wipe, Jẹ ki awa ki o rán enia lọ siwaju wa, ki nwọn ki o si rìn ilẹ na wò fun wa, ki nwọn ki o si mú ìhin pada tọ̀ wa wá, niti ọ̀na ti a o ba gòke lọ, ati ti ilu ti a o yọ si. 23 Ọ̀rọ na si dara loju mi: mo si yàn ọkunrin mejila ninu nyin, ẹnikan ninu ẹ̀ya kan: 24 Nwọn si yipada nwọn si lọ sori òke, nwọn si wá si afonifoji Eṣkolù, nwọn si rìn ilẹ na wò. 25 Nwọn si mú ninu eso ilẹ na li ọwọ́ wọn, nwọn si mú u sọkalẹ wá fun wa, nwọn si mú ìhin pada wá fun wa, nwọn si wipe, Ilẹ ti OLUWA wa fi fun wa, ilẹ rere ni. 26 Ṣugbọn ẹnyin kò fẹ́ gòke lọ, ẹnyin si ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin: 27 Ẹnyin si kùn ninu agọ́ nyin, wipe, Nitoriti OLUWA korira wa, li o ṣe mú wa lati Egipti jade wá, lati fi wa lé ọwọ́ awọn ọmọ Amori, lati run wa. 28 Nibo li awa o gbé gòke lọ? awọn arakunrin wa ti daiyajá wa, wipe, Awọn enia na sigbọnlẹ jù wa lọ; ilu wọn tobi a si mọdi wọn kan ọrun; pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀. 29 Nigbana ni mo wi fun nyin pe, Ẹ máṣe fòya, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru wọn. 30 OLUWA Ọlọrun nyin ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin; 31 Ati li aginjù, nibiti iwọ ri bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbé ọ, bi ọkunrin ti igbé ọmọ rẹ̀, li ọ̀na nyin gbogbo ti ẹnyin rìn, titi ẹnyin fi dé ihinyi. 32 Sibẹ̀ ninu nkan yi ẹnyin kò gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́. 33 Ti nlọ li ọ̀na ṣaju nyin, lati wá ibi fun nyin, ti ẹnyin o pagọ́ nyin si, ninu iná li oru, lati fi ọ̀na ti ẹnyin o gbà hàn nyin, ati ninu awọsanma li ọsán.

OLUWA Jẹ Àwọn Ọmọ Israẹli Níyà

34 OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, o si binu, o si bura, wipe, 35 Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti iran buburu yi, ki yio ri ilẹ rere na, ti mo ti bura lati fi fun awọn baba nyin, 36 Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, on ni yio ri i; on li emi o fi ilẹ na ti o tẹ̀mọlẹ fun, ati fun awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti o tẹle OLUWA lẹhin patapata. 37 OLUWA si binu si mi pẹlu nitori nyin, wipe, Iwọ pẹlu ki yio dé ibẹ̀: 38 Joṣua ọmọ Nuni, ti ima duro niwaju rẹ, on ni yio dé ibẹ̀: gbà a ni iyanju; nitoripe on ni yio mu Israeli ní i. 39 Ati awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe nwọn o di ijẹ, ati awọn ọmọ nyin, ti nwọn kò mọ̀ rere tabi buburu loni yi, awọn ni o dé ibẹ̀, awọn li emi o si fi i fun, awọn ni yio si ní i. 40 Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ẹ pada, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa. 41 Nigbana li ẹ dahùn, ẹ si wi fun mi pe, Awa ti ṣẹ̀ si OLUWA, awa o gòke lọ, a o si jà, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa palaṣẹ fun wa. Ati olukuluku nyin dì ihamọra ogun rẹ̀, ẹnyin mura lati gùn ori òke na. 42 OLUWA si wi fun mi pe, Wi fun wọn pe, Ẹ máṣe gòke lọ, bẹ̃ni ki ẹ màṣe jà; nitoriti emi kò sí lãrin nyin; ki a má ba lé nyin niwaju awọn ọtá nyin. 43 Mo sọ fun nyin, ẹnyin kò si gbọ́; ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA, ẹnyin sì kùgbu lọ si ori òke na. 44 Awọn ọmọ Amori, ti ngbé ori òke na, si jade tọ̀ nyin wá, nwọn si lepa nyin, bi oyin ti iṣe, nwọn si run nyin ni Seiri, titi dé Horma. 45 Ẹnyin si pada ẹ sì sọkun niwaju OLUWA; ṣugbọn OLUWA kò gbọ́ ohùn nyin, bẹ̃ni kò fetisi nyin.

Àkókò Tí Àwọn Ọmọ Israẹli Fi Wà ninu Aṣálẹ̀

46 Ẹnyin si joko ni Kadeṣi li ọjọ́ pupọ̀, gẹgẹ bi ọjọ́ ti ẹnyin joko nibẹ̀.

Deuteronomi 2

1 NIGBANA li awa pada, awa si mú ọ̀na wa pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa, bi OLUWA ti sọ fun mi: awa si yi òke Seiri ká li ọjọ́ pupọ̀. 2 OLUWA si sọ fun mi pe, 3 Ẹnyin ti yi òke yi ká pẹ to: ẹ pada si ìha ariwa. 4 Ki iwọ ki o si fi aṣẹ fun awọn enia, pe, Ẹnyin o là ẹkùn awọn arakunrin nyin kọja, awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri; ẹ̀ru nyin yio bà wọn: nitorina ẹ ṣọra nyin gidigidi: 5 Ẹ máṣe bá wọn jà; nitoripe emi ki yio fun nyin ninu ilẹ wọn, ani to bi ẹsẹ̀ kan: nitoriti mo ti fi òke Seiri fun Esau ni iní. 6 Owo ni ki ẹnyin fi rà onjẹ lọwọ wọn, ti ẹnyin o jẹ; owo ni ki ẹnyin si fi rà omi lọwọ wọn pẹlu, ti ẹnyin o mu. 7 Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ ti bukún ọ ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: o ti mọ̀ ìrin rẹ li aginjù nla yi: li ogoji ọdún yi OLUWA Ọlọrun rẹ ti mbẹ pẹlu rẹ; ọdá ohun kan kò dá ọ. 8 Nigbati awa si kọja lẹba awọn arakunrin wa awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, li ọ̀na pẹtẹlẹ̀ lati Elati wá, ati lati Esion-geberi wá, awa pada, awa si kọja li ọ̀na aginjù Moabu. 9 OLUWA si wi fun mi pe, Ẹ máṣe bi awọn ara Moabu ninu, bẹ̃ni ki ẹ máṣe fi ogun jà wọn: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ rẹ̀ fun ọ ni iní; nitoriti mo ti fi Ari fun awọn ọmọ Lotu ni iní. 10 (Awọn Emimu ti ngbé inu rẹ̀ ni ìgba atijọ rí, awọn enia nla, nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki: 11 Ti a nkà kún awọn omirán, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn awọn ara Moabu a ma pè wọn ni Emimu. 12 Awọn ọmọ Hori pẹlu ti ngbé Seiri rí, ṣugbọn awọn ọmọ Esau tẹle wọn, nwọn si run wọn kuro niwaju wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn; gẹgẹ bi Israeli ti ṣe si ilẹ-iní rẹ̀, ti OLUWA fi fun wọn.) 13 Mo ní, Dide nisisiyi, ki ẹ si gòke odò Seredi. Awa si gòke odò Seredi lọ. 14 Ìgba ti awa fi ti Kadeṣi-barnea wá, titi awa fi gòke odò Seredi lọ, o jẹ́ ọgbọ̀n ọdún o le mẹjọ; titi gbogbo iran awọn ologun fi run kuro ninu ibudó, bi OLUWA ti bura fun wọn. 15 Pẹlupẹlu ọwọ́ OLUWA lodi si wọn nitõtọ, lati run wọn kuro ninu ibudó, titi nwọn fi run tán. 16 Bẹ̃li o si ṣe, ti gbogbo awọn ologun nì run, ti nwọn si kú tán ninu awọn enia na, 17 OLUWA si sọ fun mi pe, 18 Iwọ o là ilẹ Ari lọ li oni, li àgbegbe Moabu: 19 Nigbati iwọ ba sunmọtosi awọn ọmọ Ammoni, máṣe bi wọn ninu, bẹ̃ni ki o máṣe bá wọn jà: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ awọn ọmọ Ammoni fun ọ ni iní: nitoriti mo ti fi i fun awọn ọmọ Lotu ni iní. 20 (A si kà eyinì pẹlu si ilẹ awọn omirán; awọn omirán ti ngbé inu rẹ̀ rí; awọn ọmọ Ammoni a si ma pè wọn ni Samsummimu. 21 Awọn enia nla, ti nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn OLUWA run wọn niwaju wọn; nwọn si tẹle wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn; 22 Bi o ti ṣe fun awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, nigbati o run awọn ọmọ Hori kuro niwaju wọn; ti nwọn si tẹle wọn, ti nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn titi di oni-oloni: 23 Ati awọn ọmọ Affimu ti ngbé awọn ileto, titi dé Gasa, awọn ọmọ Kaftori, ti o ti ọdọ Kaftori wá, run wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn.) 24 Ẹ dide, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si gòke odò Arnoni: wò o, emi fi Sihoni ọmọ Amori, ọba Heṣboni lé ọ lọwọ, ati ilẹ rẹ̀: bẹ̀rẹsi gbà a, ki o si bá a jagun. 25 Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi fi ìfoya rẹ, ati ẹ̀ru rẹ sara awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni gbogbo abẹ ọrun, ti yio gburó rẹ, ti yio si warìri, ti yio si ṣe ipàiya nitori rẹ.

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Sihoni Ọba

26 Mo si rán onṣẹ lati aginjù Kedemotu lọ sọdọ Sihoni ọba Heṣboni pẹlu ọ̀rọ alafia, wipe, 27 Jẹ ki emi ki o là ilẹ rẹ kọja lọ: ọ̀na opópo li emi o gbà, emi ki yio yà si ọtún tabi si òsi. 28 Pẹlu owo ni ki iwọ ki o tà onjẹ fun mi, ki emi ki o jẹ; pẹlu owo ni ki iwọ ki o si fun mi li omi, ki emi ki o mu: kìki ki nsá fi ẹsẹ̀ mi kọja; 29 Bi awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri, ati awọn ara Moabu ti ngbé Ari, ti ṣe si mi; titi emi o fi gòke Jordani si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa. 30 Ṣugbọn Sihoni ọba Heṣboni kò jẹ ki a kọja lẹba on: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u li àiya le, o sọ ọkàn rẹ̀ di agídi, ki o le fi on lé ọ lọwọ, bi o ti ri li oni yi. 31 OLUWA si sọ fun mi pe, Wò o, emi ti bẹ̀rẹsi fi Sihoni ati ilẹ rẹ̀ fun ọ niwaju rẹ: bẹ̀rẹsi gbà a, ki iwọ ki o le ní ilẹ rẹ̀. 32 Nigbana ni Sihoni jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Jahasi. 33 OLUWA Ọlọrun si fi i lé wa lọwọ niwaju wa; awa si kọlù u, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀. 34 Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na, awa si run awọn ọkunrin patapata, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ, ni gbogbo ilu; awa kò jẹ ki ọkan ki o kù: 35 Kìki ohunọ̀sin li a kó ni ikogun fun ara wa, ati ikogun ilu wọnni ti awa kó. 36 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati lati ilu ni lọ ti mbẹ lẹba afonifoji nì, ani dé Gileadi, kò sí ilu kan ti o le jù fun wa: OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn fun wa: 37 Kìki ilẹ awọn ọmọ Ammoni ni iwọ kò sunmọ, tabi ibikibi lẹba odò Jaboku, tabi ilu òke wọnni, tabi ibikibi ti OLUWA Ọlọrun wa kọ̀ fun wa.

Deuteronomi 3

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Ogu Ọba

1 NIGBANA li awa pada, a si lọ soke li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Edrei. 2 OLUWA si wi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe emi ti fi on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀, le ọ lọwọ; iwọ o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni. 3 Bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun wa fi Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, lé wa lọwọ pẹlu: awa si kọlù u titi kò si kù ẹnikan silẹ fun u. 4 Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na; kò sí ilu kan ti awa kò gbà lọwọ wọn; ọgọta ilu, gbogbo ẹkùn Argobu, ilẹ ọba Ogu ni Baṣani. 5 Gbogbo ilu wọnyi li a mọ odi giga si pẹlu ibode, ati idabu-ẹ̀kun; laikà ọ̀pọlọpọ ilu alailodi. 6 Awa si run wọn patapata, bi awa ti ṣe si Sihoni ọba Heṣboni, ni rirun awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ patapata, ni ilu na gbogbo. 7 Ṣugbọn gbogbo ohunọ̀sin, ati ikogun ilu wọnni li awa kó ni ikogun fun ara wa. 8 Nigbana li awa gbà li ọwọ́ awọn ọba ọmọ Amori mejeji, ilẹ ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani, lati afonifoji Arnoni lọ dé òke Hermoni; 9 (Awọn ara Sidoni a ma pè Hermoni ni Sirioni, ati awọn ọmọ Amori a si ma pè e ni Seniri;) 10 Gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo Gileadi, ati gbogbo Baṣani, dé Saleka ati Edrei, awọn ilu ilẹ ọba Ogu ni Baṣani. 11 (Ogu ọba Baṣani nikanṣoṣo li o sá kù ninu awọn omirán iyokù; kiyesi i, akete rẹ̀ jẹ́ akete irin; kò ha wà ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni? igbọnwọ mẹsan ni gigùn rẹ̀, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ni igbọnwọ ọkunrin.)

Àwọn Ẹ̀yà Tí Wọ́n Tẹ̀dó sí Apá Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

12 Ati ilẹ na yi, ti awa gbà ni ìgbana, lati Aroeri, ti mbẹ lẹba afonifoji Arnoni, ati àbọ òke Gileadi, ati ilu inu rẹ̀, ni mo fi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi: 13 Ati iyokù Gileadi, ati gbogbo Baṣani, ilẹ ọba Ogu, ni mo fi fun àbọ ẹ̀ya Manasse; gbogbo ẹkùn Argobu, pẹlu gbogbo Baṣani. (Ti a ma pè ni ilẹ awọn omirán. 14 Jairi ọmọ Manasse mú gbogbo ilẹ Argobu, dé opinlẹ Geṣuri ati Maakati; o si sọ wọn, ani Baṣan, li orukọ ara rẹ̀, ni Haffotu-jairi titi, di oni.) 15 Mo si fi Gileadi fun Makiri. 16 Ati awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi ni mo fi fun lati Gileadi, ani dé afonifoji Arnoni, agbedemeji afonifoji, ati opinlẹ rẹ̀; ani dé odò Jaboku, ti iṣe ipinlẹ awọn ọmọ Ammoni; 17 Pẹtẹlẹ̀ ni pẹlu, ati Jordani ati opinlẹ rẹ̀, lati Kinnereti lọ titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, nisalẹ awọn orisun Pisga ni ìha ìla-õrùn. 18 Mo si fun nyin li aṣẹ ni ìgbana, wipe, OLUWA Ọlọrun nyin ti fi ilẹ yi fun nyin lati ní i: ẹnyin o si kọja si ìha keji ni ihamọra ogun niwaju awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn akọni ọkunrin. 19 Kìki awọn aya nyin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ati ohunọ̀sin nyin, (emi mọ̀ pe ẹnyin lí ohunọ̀sin pupọ̀,) ni yio duro ni ilu nyin ti mo ti fi fun nyin; 20 Titi OLUWA o fi fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti fi fun ẹnyin, ati titi awọn pẹlu yio fi ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun wọn loke Jordani: nigbana li ẹnyin o pada, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ti mo ti fi fun nyin. 21 Emi si fi aṣẹ fun Joṣua ni ìgbana, wipe, Oju rẹ ti ri gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si awọn ọba mejeji wọnyi: bẹ̃ni OLUWA yio ṣe si gbogbo ilẹ-ọba nibiti iwọ o kọja. 22 Ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru wọn: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on ni yio jà fun nyin.

Ọlọrun Kò Jẹ́ kí Mose Wọ Ilẹ̀ Kenaani

23 Emi si bẹ̀ OLUWA ni ìgba na, wipe, 24 OLUWA Ọlọrun, iwọ ti bẹ̀rẹsi fi titobi rẹ hàn fun iranṣẹ rẹ, ati ọwọ́ agbara rẹ: nitoripe Ọlọrun wo ni li ọrun ati li aiye, ti o le ṣe gẹgẹ bi iṣẹ rẹ, ati gẹgẹ bi iṣẹ-agbara rẹ? 25 Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja si ìha keji, ki emi si ri ilẹ rere na ti mbẹ loke Jordani, òke daradara nì, ati Lebanoni. 26 Ṣugbọn OLUWA binu si mi nitori nyin, kò si gbọ́ ti emi: OLUWA si wi fun mi pe, O to gẹ; má tun bá mi sọ ọ̀rọ yi mọ́. 27 Gùn ori òke Pisga lọ, ki o si gbé oju rẹ soke si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù, ati si ìha ìla-õrùn, ki o si fi oju rẹ wò o: nitoripe iwọ ki yio gòke Jordani yi. 28 Ṣugbọn fi aṣẹ fun Joṣua, ki o si gbà a niyanju, ki o si mu u li ọkàn le: nitoripe on ni yio gòke lọ niwaju awọn enia yi, on o si mu wọn ni ilẹ na ti iwọ o ri. 29 Awa si joko li afonifoji ti o kọjusi Beti-peori.

Deuteronomi 4

Mose Rọ Àwọn Ọmọ Israẹli Pé kí Wọn Máa Gbọ́ràn

1 NJẸ nisisiyi Israeli, fetisi ìlana ati idajọ, ti emi nkọ́ nyin, lati ṣe wọn; ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹ si lọ igba ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin fi fun nyin. 2 Ẹ kò gbọdọ fikún ọ̀rọ na ti mo palaṣẹ fun nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bù kuro ninu rẹ̀, ki ẹnyin ki o le pa ofin OLUWA Ọlọrun nyin mọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin. 3 Oju nyin ti ri ohun ti OLUWA ṣe nitori Baali-peori: nitoripe gbogbo awọn ọkunrin ti o tẹlé Baali-peori lẹhin, OLUWA Ọlọrun rẹ ti run wọn kuro lãrin rẹ. 4 Ṣugbọn ẹnyin ti o faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gbogbo nyin mbẹ lãye li oni. 5 Wò o, emi ti kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, bi OLUWA Ọlọrun mi ti paṣẹ fun mi, pe ki ẹnyin ki o le ma ṣe bẹ̃ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a. 6 Nitorina ẹ pa wọn mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; nitoripe eyi li ọgbọ́n nyin ati oye nyin li oju awọn orilẹ-ède, ti yio gbọ́ gbogbo ìlana wọnyi, ti yio si wipe, Ọlọgbọ́n ati amoye enia nitõtọ ni orilẹ-ède nla yi. 7 Nitori orilẹ-ède nla wo li o wà, ti o ní Ọlọrun sunmọ wọn to, bi OLUWA Ọlọrun wa ti ri ninu ohun gbogbo ti awa kepè e si? 8 Ati orilẹ-ède nla wo li o si wà, ti o ní ìlana ati idajọ ti iṣe ododo to bi gbogbo ofin yi, ti mo fi siwaju nyin li oni? 9 Kìki ki iwọ ki o ma kiyesara rẹ, ki o si ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, ki iwọ ki o má ba gbagbé ohun ti oju rẹ ti ri, ati ki nwọn ki o má ba lọ kuro li àiya rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ṣugbọn ki iwọ ki o ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ; 10 Li ọjọ́ ti iwọ duro niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu, nigbati OLUWA wi fun mi pe, Pe awọn enia yi jọ fun mi, emi o si mu wọn gbọ́ ọ̀rọ mi, ki nwọn ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru mi li ọjọ́ gbogbo ti nwọn o wà lori ilẹ, ati ki nwọn ki o le ma kọ́ awọn ọmọ wọn. 11 Ẹnyin si sunmọtosi, ẹ si duro nisalẹ òke nì; òke na si njòna dé agbedemeji ọrun, pẹlu òkunkun, ati awọsanma, ati òkunkun biribiri. 12 OLUWA si sọ̀rọ si nyin lati ãrin iná na wá: ẹnyin gbọ́ ohùn ọ̀rọ na, ṣugbọn ẹ kò ri apẹrẹ kan; kìki ohùn li ẹnyin gbọ́. 13 O si sọ majẹmu rẹ̀ fun nyin, ti o palaṣẹ fun nyin lati ṣe, ani ofin mẹwa nì; o si kọ wọn sara walã okuta meji. 14 OLUWA si paṣẹ fun mi ni ìgba na lati kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a.

Ìkìlọ̀ nípa Ìbọ̀rìṣà

15 Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesara nyin gidigidi, nitoripe ẹnyin kò ri apẹrẹ kan li ọjọ́ ti OLUWA bá nyin sọ̀rọ ni Horebu lati ãrin iná wá: 16 Ki ẹnyin ki o má ba bà ara nyin jẹ́, ki ẹ má si lọ ṣe ere gbigbẹ, apẹrẹ ohunkohun, aworán akọ tabi abo. 17 Aworán ẹrankẹran ti mbẹ lori ilẹ, aworán ẹiyẹkẹiyẹ ti nfò li oju-ọrun. 18 Aworán ohunkohun ti nrakò lori ilẹ, aworán ẹjakẹja ti mbẹ ninu omi nisalẹ ilẹ: 19 Ati ki iwọ ki o má ba gbé oju rẹ soke ọrun, nigbati iwọ ba si ri õrùn, ati oṣupa, ati irawọ, ani gbogbo ogun ọrun, ki a má ba sún ọ lọ ibọ wọn, ki o si ma sìn wọn, eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun gbogbo orilẹ-ède labẹ ọrun gbogbo. 20 Ṣugbọn OLUWA ti gbà nyin, o si mú nyin lati ileru irin, lati Egipti jade wá, lati ma jẹ́ enia iní fun u, bi ẹnyin ti ri li oni yi. 21 OLUWA si binu si mi nitori nyin, o si bura pe, emi ki yio gòke Jordani, ati pe emi ki yio wọ̀ inu ilẹ rere nì, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni ilẹ-iní. 22 Ṣugbọn emi o kú ni ilẹ yi, emi ki yio gòke odò Jordani: ṣugbọn ẹnyin o gòke ẹnyin o si gbà ilẹ rere na. 23 Ẹ ma ṣọra nyin, ki ẹnyin má ba gbagbé majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti o ti bá nyin dá, ki ẹnyin má ba lọ ṣe ere finfin fun ara nyin, tabi aworán ohunkohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti kọ̀ fun ọ. 24 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ ajonirun iná ni, Ọlọrun owú. 25 Nigbati iwọ ba bi ọmọ, ati ọmọ ọmọ, ti ẹ ba si pẹ ni ilẹ na, ti ẹ si bà ara nyin jẹ́, ti ẹ si ṣe ere finfin, tabi aworán ohunkohun, ti ẹ si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA Ọlọrun rẹ lati mu u binu: 26 Mo pè ọrun ati aiye jẹri si nyin li oni, pe lọ́gan li ẹnyin o run kuro patapata ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a; ẹnyin ki yio lò ọjọ́ nyin pẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin o si run patapata. 27 OLUWA yio si tú nyin ká ninu awọn orilẹ-ède, diẹ ni ẹnyin o si kù ni iye ninu awọn orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio darí nyin si. 28 Nibẹ̀ li ẹnyin o si ma sìn oriṣa, iṣẹ ọwọ́ enia, igi ati okuta, ti kò riran, ti kò si gbọran, ti kò jẹun, ti kò si gbõrun. 29 Ṣugbọn bi iwọ ba wá OLUWA Ọlọrun rẹ lati ibẹ̀ lọ, iwọ o ri i, bi iwọ ba fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ wá a. 30 Nigbati iwọ ba mbẹ ninu ipọnju, ti nkan gbogbo wọnyi ba si bá ọ, nikẹhin ọjọ́, bi iwọ ba yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́: 31 Nitoripe Ọlọrun alãnu ni OLUWA Ọlọrun rẹ; on ki yio kọ̀ ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio run ọ, bẹ̃ni ki yio gbagbé majẹmu awọn baba rẹ, ti o ti bura fun wọn. 32 Njẹ bère nisisiyi niti ọjọ́ igbãni, ti o ti mbẹ ṣaju rẹ, lati ọjọ́ ti Ọlọrun ti dá enia sori ilẹ, ki o si bère lati ìha ọrun kini dé ìha keji, bi irú nkan bi ohun nla yi wà rí, tabi bi a gburó irú rẹ̀ rí? 33 Awọn enia kan ha gbọ́ ohùn Ọlọrun rí ki o ma bá wọn sọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi iwọ ti gbọ́, ti o si wà lãye? 34 Tabi Ọlọrun ha dán a wò rí lati lọ mú orilẹ-ède kan fun ara rẹ̀ lati ãrin orilẹ-ède miran wá, nipa idanwò, nipa àmi, ati nipa iṣẹ-iyanu, ati nipa ogun, ati nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa, ati nipa ẹ̀ru nla, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ṣe fun nyin ni Egipti ni oju nyin? 35 Iwọ li a fihàn, ki iwọ ki o le mọ̀ pe OLUWA on li Ọlọrun; kò sí ẹlomiran lẹhin rẹ̀. 36 O mu ọ gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ọrun wá, ki o le kọ́ ọ: ati lori ilẹ aiye o fi iná nla rẹ̀ hàn ọ; iwọ si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ lati ãrin iná wá. 37 Ati nitoriti o fẹ́ awọn baba rẹ, nitorina li o ṣe yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, o si fi agbara nla rẹ̀ mú ọ lati Egipti jade wá li oju rẹ̀; 38 Lati lé awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju rẹ, ti o tobi, ti o si lagbara jù ọ lọ, lati mú ọ wọle, lati fi ilẹ wọn fun ọ ni iní, bi o ti ri li oni yi. 39 Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ li oni, ki o si rò li ọkàn rẹ pe, OLUWA on li Ọlọrun loke ọrun, ati lori ilẹ nisalẹ: kò sí ẹlomiran. 40 Nitorina ki iwọ ki o pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati ofin rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ lori ilẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lailai.

Àwọn Ìlú Ààbò Tí Ó Wà ní Apá Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

41 Nigbana ni Mose yà ilu mẹta sọ̀tọ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn. 42 Ki apania ki o le ma sá sibẹ̀, ti o ba ṣì ẹnikeji rẹ̀ pa, ti kò si korira rẹ̀ ni ìgba atijọ rí; ati pe bi o ba sá si ọkan ninu ilu wọnyi ki o le là: 43 Beseri ni ijù, ni ilẹ pẹtẹlẹ̀, ti awọn ọmọ Reubeni; ati Ramotu ni Gileadi, ti awọn ọmọ Gadi; ati Golani ni Baṣani, ti awọn ọmọ Manasse.

Àlàyé lórí Òfin Ọlọrun Tí Mose Fẹ́ fún Wọn

44 Eyi li ofin na ti Mose filelẹ niwaju awọn ọmọ Israeli: 45 Wọnyi li ẹrí, ati ìlana, ati idajọ, ti Mose filelẹ fun awọn ọmọ Israeli, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá; 46 Ni ìha ẹ̀bá Jordani, ni afonifoji ti o kọjusi Beti-peori, ni ilẹ Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni, ẹniti Mose ati awọn ọmọ Israeli kọlù, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá: 47 Nwọn si gbà ilẹ rẹ̀, ati ilẹ Ogu ọba Baṣani, awọn ọba Amori mejeji ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn; 48 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ani dé òke Sioni (ti iṣe Hermoni,) 49 Ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ nì, ni ìha ẹ̀bá Jordani ni ìha ìla-õrùn, ani dé okun pẹtẹlẹ̀ nì, nisalẹ awọn orisun Pisga.

Deuteronomi 5

Òfin Mẹ́wàá

1 MOSE si pè gbogbo Israeli, o si wi fun wọn pe, Israeli, gbọ́ ìlana ati idajọ ti emi nsọ li etí nyin li oni, ki ẹnyin ki o le kọ́ wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ́, lati ma ṣe wọn. 2 OLUWA Ọlọrun wa bá wa dá majẹmu ni Horebu. 3 OLUWA kò bá awọn baba wa dá majẹmu yi, bikoṣe awa, ani awa, ti gbogbo wa mbẹ lãye nihin li oni. 4 OLUWA bá nyin sọ̀rọ li ojukoju lori òke na, lati ãrin iná wá, 5 (Emi duro li agbedemeji OLUWA ati ẹnyin ni ìgba na, lati sọ ọ̀rọ OLUWA fun nyin: nitoripe ẹnyin bẹ̀ru nitori iná na, ẹnyin kò si gòke lọ sori òke na;) wipe, 6 Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá. 7 Iwọ kò gbọdọ ní ọlọrun miran pẹlu mi. 8 Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworán apẹrẹ kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti mbẹ ni ilẹ nisalẹ, tabi ti mbẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ: 9 Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitoripe emi OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, ati lara iran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi. 10 Emi a si ma ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si pa ofin mi mọ́. 11 Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ li asan: nitoriti OLUWA ki yio mu ẹniti o pè orukọ rẹ̀ li asan bi alailẹṣẹ lọrùn. 12 Kiyesi ọjọ́-isimi lati yà a simimọ́, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ. 13 Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo: 14 Ṣugbọn ọjọ́ keje li ọjọ́-isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ, ati ohunọ̀sin rẹ kan, ati alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ; ki ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ki o le simi gẹgẹ bi iwọ. 15 Si ranti pe iwọ ti ṣe iranṣẹ ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ibẹ̀ jade wá nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa: nitorina li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe paṣẹ fun ọ lati pa ọjọ́-isimi mọ́. 16 Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ, ati ki o le dara fun ọ, ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 17 Iwọ kò gbọdọ pania. 18 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga. 19 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jale. 20 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹri-eké si ẹnikeji rẹ. 21 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, oko rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ. 22 Ọ̀rọ wọnyi ni OLUWA sọ fun gbogbo ijọ nyin lori òke lati ãrin iná, awọsanma, ati lati inu òkunkun biribiri wá, pẹlu ohùn nla: kò si fi kún u mọ́. O si kọ wọn sara walã okuta meji, o si fi wọn fun mi.

Ẹ̀rù Ba Àwọn Ọmọ Israẹli

23 O si ṣe, nigbati ẹnyin gbọ́ ohùn nì lati ãrin òkunkun na wá, ti òke na si njó, ti ẹnyin sunmọ ọdọ mi, gbogbo olori awọn ẹ̀ya nyin, ati awọn àgba nyin: 24 Ẹnyin si wipe, Kiyesi i, OLUWA Ọlọrun wa fi ogo rẹ̀ ati titobi rẹ̀ hàn wa, awa si ti gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ãrin iná wá: awa ti ri li oni pe, OLUWA a ma ba enia sọ̀rọ̀, on a si wà lãye. 25 Njẹ nisisiyi ẽṣe ti awa o fi kú? nitoripe iná nla yi yio jó wa run: bi awa ba tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa, njẹ awa o kú. 26 Nitoripe tani mbẹ ninu gbogbo araiye ti o ti igbọ́ ohùn Ọlọrun alãye ti nsọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi awa ti gbọ́, ti o si wà lãye? 27 Iwọ sunmọtosi, ki o si gbọ́ gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa yio wi: ki iwọ ki o sọ fun wa gbogbo ohun ti OLUWA Ọlọrun wa yio sọ fun ọ: awa o si gbọ́, awa o si ṣe e. 28 OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, nigbati ẹnyin sọ fun mi; OLUWA si sọ fun mi pe, emi ti gbọ́ ohùn ọ̀rọ awọn enia yi, ti nwọn sọ fun ọ: nwọn wi rere ni gbogbo eyiti nwọn sọ. 29 Irú ọkàn bayi iba ma wà ninu wọn, ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru mi, ki nwọn ki o si le ma pa gbogbo ofin mi mọ́ nigbagbogbo, ki o le dara fun wọn, ati fun awọn ọmọ wọn titilai! 30 Lọ wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ sinu agọ́ nyin. 31 Ṣugbọn, iwọ, duro nihin lọdọ mi, emi o si sọ ofin nì gbogbo fun ọ, ati ìlana, ati idajọ, ti iwọ o ma kọ́ wọn, ki nwọn ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ na ti mo ti fi fun wọn lati ní. 32 Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesi ati ṣe bi OLUWA Ọlọrun nyin ti paṣẹ fun nyin: ki ẹnyin ki o máṣe yi si ọtún tabi si òsi. 33 Ki ẹnyin ki o si ma rìn ninu gbogbo ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun nyin palaṣẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le yè, ki o si le dara fun nyin, ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ ti ẹnyin yio ní.

Deuteronomi 6

Òfin Ńlá

1 NJẸ wọnyi li ofin, ìlana, ati idajọ, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti palaṣẹ lati ma kọ́ nyin, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ nibiti ẹnyin gbé nlọ lati gbà a: 2 Ki iwọ ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ìlana rẹ̀ ati ofin rẹ̀ mọ́, ti emi fi fun ọ, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ. 3 Nitorina gbọ́, Israeli, ki o si ma kiyesi i lati ṣe e; ki o le dara fun ọ, ati ki ẹnyin ki o le ma pọ̀si i li ọ̀pọlọpọ, bi OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ ti ṣe ileri fun ọ, ni ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 4 Gbọ́, Israeli: OLUWA Ọlọrun wa, OLUWA kan ni. 5 Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ. 6 Ati ọ̀rọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà ni àiya rẹ: 7 Ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide. 8 Ki iwọ ki o si so wọn mọ́ ọwọ́ rẹ fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọja-igbaju niwaju rẹ. 9 Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun ọ̀na-ode rẹ.

Ìkìlọ̀ nípa Ìwà Àìgbọràn

10 Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, ti o bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fun ọ ni ilu ti o tobi ti o si dara, ti iwọ kò mọ̀, 11 Ati ile ti o kún fun ohun rere gbogbo, ti iwọ kò kún, ati kanga wiwà, ti iwọ kò wà, ọgbà-àjara ati igi oróro, ti iwọ kò gbìn; nigbati iwọ ba jẹ tán ti o ba si yó; 12 Kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ba gbagbé OLUWA ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú. 13 Bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma sìn i, ki o si ma bura li orukọ rẹ̀. 14 Ẹnyin kò gbọdọ tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia, ti o yi nyin ká kiri; 15 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni ninu nyin; ki ibinu OLUWA Ọlọrun rẹ ki o má ba rú si ọ, on a si run ọ kuro lori ilẹ. 16 Ẹnyin kò gbọdọ dán OLUWA Ọlọrun nyin wò, bi ẹnyin ti dan a wò ni Massa. 17 Ki ẹnyin ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun nyin mọ́ gidigidi, ati ẹrí rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ti o filelẹ li aṣẹ fun ọ. 18 Ki iwọ ki o ma ṣe eyiti o tọ́, ti o si dara li oju OLUWA: ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wọ̀ ilẹ rere nì lọ ki o si gbà a, eyiti OLUWA bura fun awọn baba rẹ, 19 Lati tì awọn ọtá rẹ gbogbo jade kuro niwaju rẹ, bi OLUWA ti wi. 20 Nigbati ọmọ rẹ ba bi ọ lère lẹhin-ọla, wipe, Kini èredi ẹrí, ati ìlana, ati idajọ wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun filelẹ li aṣẹ fun nyin? 21 Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun ọmọ rẹ pe, Ẹrú Farao li awa ti ṣe ni Egipti; OLUWA si fi ọwọ́ agbara mú wa jade lati Egipti wá. 22 OLUWA si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ti o tobi ti o si buru hàn lara Egipti, lara Farao, ati lara gbogbo ara ile rẹ̀ li oju wa: 23 O si mú wa jade lati ibẹ̀ wá, ki o le mú wa wọ̀ inu rẹ̀, lati fun wa ni ilẹ na ti o bura fun awọn baba wa. 24 OLUWA si pa a laṣẹ fun wa, lati ma ṣe gbogbo ìlana wọnyi, lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun wa, fun ire wa nigbagbogbo, ki o le pa wa mọ́ lãye, bi o ti ri li oni yi. 25 Yio si jẹ́ ododo wa, bi awa ba nṣọ́ ati ma ṣe gbogbo ofin wọnyi niwaju OLUWA Ọlọrun wa, bi o ti paṣẹ fun wa.

Deuteronomi 7

Àwọn Eniyan OLUWA

1 NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà a, ti o ba lé orilẹ-ède pupọ̀ kuro niwaju rẹ, awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, orilẹ-ède meje, ti o pọ̀ ti o si lagbara jù ọ lọ; 2 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si kọlù wọn; ki o si run wọn patapata; iwọ kò gbọdọ bá wọn dá majẹmu, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn: 3 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá wọn dá ana; ọmọbinrin rẹ ni iwọ kò gbọdọ fi fun ọmọkunrin rẹ̀, ati ọmọbinrin rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ mú fun ọmọkunrin rẹ. 4 Nitoripe nwọn o yi ọmọkunrin rẹ pada lati ma tọ̀ mi lẹhin, ki nwọn ki o le ma sìn ọlọrun miran: ibinu OLUWA o si rú si nyin, on a si run ọ lojiji. 5 Ṣugbọn bayi li ẹnyin o fi wọn ṣe; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn, ẹ o si bì ọwọ̀n wọn lulẹ, ẹ o si ke igbo oriṣa wọn lulẹ, ẹ o si fi iná jó gbogbo ere finfin wọn. 6 Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ: OLUWA Ọlọrun rẹ ti yàn ọ lati jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ. 7 OLUWA kò fi ifẹ́ rẹ̀ si nyin lara, bẹ̃ni kò yàn nyin, nitoriti ẹnyin pọ̀ ni iye jù awọn enia kan lọ; nitoripe ẹnyin li o tilẹ kére jù ninu gbogbo enia: 8 Ṣugbọn nitoriti OLUWA fẹ́ nyin, ati nitoriti on fẹ́ pa ara ti o ti bú fun awọn baba nyin mọ́, ni OLUWA ṣe fi ọwọ́ agbara mú nyin jade, o si rà nyin pada kuro li oko-ẹrú, kuro li ọwọ́ Farao ọba Egipti. 9 Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mọ́ ati ãnu fun awọn ti o fẹ́ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹrun iran; 10 Ti o si nsan a pada fun awọn ti o korira rẹ̀ li oju wọn, lati run wọn: on ki yio jafara fun ẹniti o korira rẹ̀, on o san a fun u loju rẹ̀. 11 Nitorina ki iwọ ki o pa ofin, ati ìlana, ati idajọ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe wọn.

Ibukun Tí Ó Wà ninu Ìgbọràn

12 Yio si ṣe, nitoriti ẹnyin fetisi idajọ wọnyi, ti ẹ si npa wọn mọ́, ti ẹ si nṣe wọn, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio ma pa majẹmu ati ãnu mọ́ fun ọ, ti o ti bura fun awọn baba rẹ: 13 On o si fẹ́ ọ, yio si bukún ọ, yio si mu ọ bisi i: on o si bukún ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ, ibisi malu rẹ, ati awọn ọmọ agbo-agutan rẹ, ni ilẹ na ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ. 14 Iwọ o jẹ́ ẹni ibukún jù gbogbo enia lọ: ki yio sí akọ tabi abo ninu nyin ti yio yàgan, tabi ninu ohunọ̀sin nyin. 15 OLUWA yio si gbà àrun gbogbo kuro lọdọ rẹ, ki yio si fi ọkan ninu àrun buburu Egipti, ti iwọ mọ̀, si ọ lara, ṣugbọn on o fi wọn lé ara gbogbo awọn ti o korira rẹ. 16 Iwọ o si run gbogbo awọn enia ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi fun ọ; oju rẹ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn awọn oriṣa wọn; nitoripe idẹkùn li eyinì yio jẹ́ fun ọ. 17 Bi iwọ ba wi li ọkàn rẹ pe, Awọn orilẹ-ède wọnyi pọ̀ jù mi lọ; bawo li emi o ṣe le lé wọn jade? 18 Ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru wọn: ṣugbọn ki iwọ ki o ranti daradara ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Farao, ati si gbogbo Egipti; 19 Idanwò nla ti oju rẹ ri, ati àmi, ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi mú ọ jade: bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio ṣe si gbogbo awọn enia na ẹ̀ru ẹniti iwọ mbà. 20 Pẹlupẹlu OLUWA Ọlọrun rẹ yio rán agbọ́n sinu wọn, titi awọn ti o kù, ti nwọn si fi ara wọn pamọ́ fun ọ yio fi run. 21 Ki iwọ ki o máṣe fòya wọn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lãrin rẹ, Ọlọrun ti o tobi ti o si lẹrù. 22 OLUWA Ọlọrun rẹ yio tì awọn orilẹ-ède na jade diẹdiẹ niwaju rẹ: ki iwọ ki o máṣe run wọn tán lẹ̃kan, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba pọ̀ si ọ. 23 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi wọn lé ọ lọwọ, yio si fi iparun nla pa wọn run, titi nwọn o fi run. 24 On o si fi awọn ọba wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si pa orukọ wọn run kuro labẹ ọrun: kò sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ, titi iwọ o fi run wọn tán. 25 Ere finfin oriṣa wọn ni ki ẹnyin ki o fi iná jó: iwọ kò gbọdọ ṣe ojukokoro fadakà tabi wurà ti mbẹ lara wọn, bẹ̃ni ki o máṣe mú u fun ara rẹ, ki o má ba di idẹkùn fun ọ; nitoripe ohun irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ: 26 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ mú ohun irira wá sinu ile rẹ, ki iwọ ki o má ba di ẹni ifibú bi rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o korira rẹ̀ patapata, ki iwọ ki o si kà a si ohun irira patapata; nitoripe ohun ìyasọtọ ni.

Deuteronomi 8

Ilẹ̀ Tí Ó Dára fún Ìní

1 GBOGBO ofin ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati ṣe, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹnyin si ma pọ̀ si i, ki ẹnyin si wọnu rẹ̀ lọ lati gbà ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin. 2 Ki iwọ ki o si ranti ọ̀na gbogbo ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti mu ọ rìn li aginjù lati ogoji ọdún yi wá, lati rẹ̀ ọ silẹ, ati lati dan ọ wò, lati mọ̀ ohun ti o wà li àiya rẹ, bi iwọ o pa ofin rẹ̀ mọ́, bi bẹ̃kọ. 3 O si rẹ̀ ọ silẹ, o si fi ebi pa ọ, o si fi manna bọ́ ọ, ti iwọ kò mọ̀, bẹ̃ni awọn baba rẹ kò mọ̀; ki o le mu ọ mọ̀ pe enia kò ti ipa onjẹ nikan wà lãye, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu OLUWA jade li enia wà lãye. 4 Aṣọ rẹ kò gbó mọ́ ọ lara, bẹ̃li ẹsẹ̀ rẹ kò wú, lati ogoji ọdún yi wá. 5 Ki iwọ ki o si mọ̀ li ọkàn rẹ pe, bi enia ti ibá ọmọ rẹ̀ wi, bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ wi. 6 Ki iwọ ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma bẹ̀ru rẹ̀. 7 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ wá sinu ilẹ rere, ilẹ odò omi, ti orisun ati ti abẹ-ilẹ, ti nrú soke lati afonifoji ati òke jade wa; 8 Ilẹ alikama ati ọkà-barle, ati àjara ati igi ọpọtọ ati igi pomegranate; ilẹ oróro olifi, ati oyin; 9 Ilẹ ninu eyiti iwọ ki o fi ìṣẹ jẹ onjẹ, iwọ ki yio fẹ ohun kan kù ninu rẹ̀; ilẹ ti okuta rẹ̀ iṣe irin, ati lati inu òke eyiti iwọ o ma wà idẹ. 10 Nigbati iwọ ba si jẹun tán ti o si yo, nigbana ni iwọ o fi ibukún fun OLUWA Ọlọrun rẹ, nitori ilẹ rere na ti o fi fun ọ.

Ìkìlọ̀ nípa Gbígbàgbé OLUWA

11 Ma kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ṣe gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, li aipa ofin rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀ mọ́, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni: 12 Ki iwọ ki o má ba jẹ yó tán, ki o kọ ile daradara, ki o si ma gbé inu rẹ̀; 13 Ati ki ọwọ́-ẹran rẹ ati agbo-ẹran rẹ, ki o ma ba pọ̀si i tán, ki fadakà rẹ ati wurà rẹ pọ̀si i, ati ki ohun gbogbo ti iwọ ní pọ̀si i; 14 Nigbana ni ki ọkàn rẹ wa gbé soke, iwọ a si gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú; 15 Ẹniti o mu ọ rìn aginjù nla ti o si li ẹ̀ru, nibiti ejò amubina wà, ati akẽkẽ, ati ọdá, nibiti omi kò sí; ẹniti o mú omi jade fun ọ lati inu okuta akọ wá; 16 Ẹniti o fi manna bọ́ ọ li aginjù, ti awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; ki o le rẹ̀ ọ silẹ, ki o le dan ọ wò, lati ṣe ọ li ore nigbẹhin rẹ: 17 Iwọ a si wi li ọkàn rẹ pe, Agbara mi ati ipa ọwọ́ mi li o fun mi li ọrọ̀ yi. 18 Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe, on li o fun ọ li agbara lati lí ọrọ̀, ki on ki o le fi idi majẹmu rẹ̀ ti o bura fun awọn baba rẹ kalẹ, bi o ti ri li oni yi. 19 Yio si ṣe, bi iwọ ba gbagbe OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ si tẹle ọlọrun miran, ti o si nsìn wọn, ti o si mbọ wọn, emi tẹnumọ́ ọ fun nyin pe, rirun li ẹnyin o run. 20 Bi awọn orilẹ-ède ti OLUWA run kuro niwaju nyin, bẹ̃li ẹnyin o run; nitoripe ẹnyin ṣe àigbọran si ohùn OLUWA Ọlọrun nyin.

Deuteronomi 9

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣe Àìgbọràn

1 GBỌ́, Israeli: iwọ o gòke Jordani li oni, lati wọle lọ ìgba awọn orilẹ-ède ti o tobi ti o si lagbara jù ọ lọ, ilu ti o tobi, ti a mọdi rẹ̀ kàn ọrun, 2 Awọn enia ti o tobi ti o si sigbọnlẹ, awọn ọmọ Anaki, ti iwọ mọ̀, ti iwọ si gburó pe, Tali o le duro niwaju awọn ọmọ Anaki? 3 Iwọ o si mọ̀ li oni pe, OLUWA Ọlọrun rẹ on ni ngòke ṣaju rẹ lọ bi iná ajonirun; yio pa wọn run, on o si rẹ̀ wọn silẹ niwaju rẹ: iwọ o si lé wọn jade, iwọ o si pa wọn run kánkán, bi OLUWA ti wi fun ọ. 4 Máṣe sọ li ọkàn rẹ, lẹhin igbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba tì wọn jade kuro niwaju rẹ, wipe, Nitori ododo mi ni OLUWA ṣe mú mi wá lati gbà ilẹ yi: ṣugbọn nitori ìwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi ni OLUWA ṣe lé wọn jade kuro niwaju rẹ. 5 Ki iṣe nitori ododo rẹ, tabi nitori pipé ọkàn rẹ, ni iwọ fi nlọ lati gbà ilẹ wọn: ṣugbọn nitori ìwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn kuro niwaju rẹ, ati ki o le mu ọ̀rọ na ṣẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu. 6 Nitorina ki o yé ọ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ kò fi ilẹ rere yi fun ọ lati ní i nitori ododo rẹ; nitoripe enia ọlọrùn lile ni iwọ. 7 Ranti, máṣe gbagbé, bi iwọ ti mu OLUWA Ọlọrun rẹ binu li aginjù: lati ọjọ́ na ti iwọ ti jade kuro ni ilẹ Egipti, titi ẹnyin fi dé ihin yi, ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA. 8 Ati ni Horebu ẹnyin mu OLUWA binu, OLUWA si binu si nyin tobẹ̃ ti o fẹ́ pa nyin run. 9 Nigbati mo gòke lọ sori òke lati gbà walã okuta wọnni, ani walã majẹmu nì ti OLUWA bá nyin dá, nigbana mo gbé ogoji ọsán, ati ogoji oru lori òke na, emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃li emi kò mu omi. 10 OLUWA si fi walã okuta meji fun mi, ti a fi ika Ọlọrun kọ; ati lara wọn li a kọ ọ gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ na, ti OLUWA bá nyin sọ li òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì. 11 O si ṣe li opin ogoji ọsán ati ogoji oru, ti OLUWA fi walã okuta meji nì fun mi, ani walã majẹmu nì. 12 OLUWA si wi fun mi pe, Dide, sọkalẹ kánkán lati ihin lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú lati ilẹ Egipti jade wá, ti bà ara wọn jẹ́; nwọn yipada kánkán kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun wọn; nwọn ti yá ere didà fun ara wọn. 13 OLUWA sọ fun mi pẹlu pe, Emi ti ri enia yi, si kiyesi i, enia ọlọrùn lile ni: 14 Yàgo fun mi, ki emi ki o pa wọn run, ki emi si pa orukọ wọn rẹ́ kuro labẹ ọrun: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède ti o lagbara ti o si pọ̀ jù wọn lọ. 15 Emi si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke nì wá, òke na si njóna: walã meji ti majẹmu nì si wà li ọwọ́ mi mejeji. 16 Mo si wò, si kiyesi i, ẹnyin ti ṣẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin si ti yá ẹgbọrọ-malu didà fun ara nyin: ẹnyin ti yipada kánkán kuro li ọ̀na ti OLUWA ti palaṣẹ fun nyin. 17 Emi si mú walã meji nì, mo si sọ wọn silẹ kuro li ọwọ́ mi mejeji, mo si fọ́ wọn niwaju nyin. 18 Emi si wolẹ niwaju OLUWA bi ti iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru; emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kò mu omi; nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin ti ẹnyin ṣẹ̀, ni ṣiṣe buburu li oju OLUWA, lati mu u binu. 19 Nitoriti emi bẹ̀ru ibinu ati irunu OLUWA si nyin lati pa nyin run. OLUWA si gbọ́ ti emi nigbana pẹlu. 20 OLUWA si binu si Aaroni gidigidi ti iba fi pa a run: emi si gbadura fun Aaroni nigbana pẹlu. 21 Emi si mú ẹ̀ṣẹ nyin, ẹgbọrọ-malu ti ẹnyin ṣe, mo si fi iná sun u, mo si gún u, mo si lọ̀ ọ kúnna, titi o fi dabi ekuru: mo si kó ekuru rẹ̀ lọ idà sinu odò ti o ti òke na ṣànwalẹ. 22 Ati ni Tabera, ati ni Massa, ati ni Kibrotu-hattaafa, ẹnyin mu OLUWA binu. 23 Nigbati OLUWA rán nyin lati Kadeṣi-barnea lọ, wipe, Gòke lọ ki o si gbà ilẹ na ti mo fi fun nyin; nigbana li ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin kò si gbà a gbọ́, bẹ̃li ẹnyin kò si fetisi ohùn rẹ̀. 24 Ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA lati ọjọ́ ti mo ti mọ̀ nyin. 25 Mo si wolẹ niwaju OLUWA li ogoji ọsán ati li ogoji oru, bi mo ti wolẹ niṣaju; nitoriti OLUWA wipe, on o run nyin. 26 Mo si gbadura sọdọ OLUWA wipe, Oluwa ỌLỌRUN, máṣe run awọn enia rẹ ati iní rẹ, ti iwọ ti fi titobi rẹ̀ ràsilẹ, ti iwọ mú lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara. 27 Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu awọn iranṣẹ rẹ; máṣe wò agídi awọn enia yi, tabi ìwabuburu wọn, tabi ẹ̀ṣẹ wọn: 28 Ki awọn enia ilẹ na ninu eyiti iwọ ti mú wa jade wá ki o má ba wipe, Nitoriti OLUWA kò le mú wọn dé ilẹ na ti o ti ṣe ileri fun wọn, ati nitoriti o korira wọn, li o ṣe mú wọn jade wá lati pa wọn li aginjù. 29 Ṣugbọn sibẹ̀ enia rẹ ni nwọn iṣe, ati iní rẹ, ti iwọ mú jade nipa agbara nla rẹ, ati nipa ninà apa rẹ.

Deuteronomi 10

Mose Tún Gba Òfin

1 NIGBANA li OLUWA wi fun mi pe, Gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju, ki o si tọ̀ mi wá lori òke na, ki o si ṣe apoti igi kan. 2 Emi o si kọ ọ̀rọ ti o ti wà lara walã iṣaju ti iwọ fọ́, sara walã wọnyi, iwọ o si fi wọn sinu apoti na. 3 Emi si ṣe apoti igi ṣittimu kan, mo si gbẹ́ walã okuta meji bi ti isaju, mo si lọ sori òke na, walã mejeji si wà li ọwọ́ mi. 4 On si kọ ofin mẹwẹwa sara walã wọnni, gẹgẹ bi o ti kọ ti iṣaju, ti OLUWA sọ fun nyin lori òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì; OLUWA si fi wọn fun mi. 5 Mo si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke na wá, mo si fi walã wọnni sinu apoti ti mo ti ṣe; nwọn si wà nibẹ̀, bi OLUWA ti paṣẹ fun mi. 6 (Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati Beerotu ti iṣe ti awọn ọmọ Jaakani lọ si Mosera: nibẹ̀ li Aaroni gbé kú, nibẹ̀ li a si sin i; Eleasari ọmọ rẹ̀ si nṣe iṣẹ alufa ni ipò rẹ̀. 7 Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Gudgoda; ati lati Gudgoda lọ si Jotbati, ilẹ olodò omi. 8 Nigbana li OLUWA yà ẹ̀ya Lefi sọ̀tọ, lati ma rù apoti majẹmu OLUWA, lati ma duro niwaju OLUWA lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀, titi di oni yi. 9 Nitorina ni Lefi kò ṣe ní ipín tabi iní pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; OLUWA ni iní rẹ̀, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun ti ṣe ileri fun u.) 10 Emi si duro lori òke na, gẹgẹ bi ìgba iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru: OLUWA si gbọ́ ti emi ni igbana pẹlu, OLUWA kò si fẹ́ run ọ. 11 OLUWA si wi fun mi pe, Dide, mú ọ̀na ìrin rẹ niwaju awọn enia, ki nwọn ki o le wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki nwọn ki o le gbà ilẹ na, ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.

Ohun Tí Ọlọrun Ń Bèèrè

12 Njẹ nisisiyi, Israeli, kini OLUWA Ọlọrun rẹ mbère lọdọ rẹ, bikoṣe lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, lati ma fẹ́ ẹ, ati lati ma sìn OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, 13 Lati ma pa ofin OLUWA mọ́, ati ìlana rẹ̀, ti mo filelẹ fun ọ li aṣẹ li oni, fun ire rẹ? 14 Kiyesi i, ti OLUWA Ọlọrun rẹ li ọrun, ati ọrun dé ọrun, aiye pẹlu, ti on ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀. 15 Kìki OLUWA ni inudidùn si awọn baba rẹ lati fẹ́ wọn, on si yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, ani ẹnyin jù gbogbo enia lọ, bi o ti ri li oni yi. 16 Nitorina ẹ kọ àiya nyin nilà, ki ẹ má si ṣe ọlọrùn lile mọ́. 17 Nitori OLUWA Ọlọrun nyin, Ọlọrun awọn ọlọrun ni ati OLUWA awọn oluwa, Ọlọrun titobi, alagbara, ati ẹ̀lẹru, ti ki iṣe ojuṣaju, bẹ̃ni ki igba abẹtẹlẹ. 18 On ni ima ṣe idajọ alainibaba ati opó, o si fẹ́ alejò, lati fun u li onjẹ ati aṣọ. 19 Nitorina ki ẹnyin ki o ma fẹ́ alejò: nitoripe ẹnyin ṣe alejò ni ilẹ Egipti. 20 Ki iwọ ki o ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ; on ni ki iwọ ki o ma sìn, on ni ki iwọ ki o si faramọ́, orukọ rẹ̀ ni ki o si ma fi bura. 21 On ni iyìn rẹ, on si li Ọlọrun rẹ, ti o ṣe ohun nla ati ohun ẹ̀lẹru wọnni fun ọ, ti oju rẹ ri. 22 Awọn baba rẹ sọkalẹ lọ si Egipti ti awọn ti ãdọrin enia; ṣugbọn nisisiyi OLUWA Ọlọrun rẹ sọ ọ dabi irawọ ọrun li ọ̀pọlọpọ.

Deuteronomi 11

Títóbi OLUWA

1 NITORINA ki iwọ ki o fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma pa ikilọ̀ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ofin rẹ̀ mọ́, nigbagbogbo. 2 Ki ẹnyin ki o si mọ̀ li oni: nitoripe awọn ọmọ nyin ti emi nsọ fun ti kò mọ̀, ti kò si ri ibawi OLUWA Ọlọrun nyin, titobi rẹ̀, ọwọ́ agbara rẹ̀, ati ninà apa rẹ̀, 3 Ati iṣẹ-àmi rẹ̀, ati iṣẹ rẹ̀, ti o ṣe lãrin Egipti, si Farao ọba Egipti, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀; 4 Ati ohun ti o ṣe si ogun Egipti, si ẹṣin wọn, ati kẹkẹ́-ogun wọn; bi o ti mu ki omi Okun Pupa bò wọn mọlẹ bi nwọn ti nlepa nyin lọ, ati bi OLUWA ti run wọn titi di oni-oloni; 5 Ati bi o ti ṣe si nyin li aginjù, titi ẹnyin fi dé ihin yi; 6 Ati bi o ti ṣe si Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ọmọ Reubeni; bi ilẹ ti yà ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, ati ara ile wọn, ati agọ́ wọn, ati ohun alãye gbogbo ti o tẹle wọn, lãrin gbogbo Israeli: 7 Ṣugbọn oju nyin ti ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA ti o ṣe.

Ibukun Ilẹ̀ Ìlérí náà

8 Nitorina ki ẹnyin ki o pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, ki ẹnyin ki o le lagbara, ki ẹnyin ki o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki ẹ si gbà ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a; 9 Ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 10 Nitoripe ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, kò dabi ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin ti jade wá, nibiti iwọ gbìn irugbìn rẹ, ti iwọ si nfi ẹsẹ̀ rẹ bomirin i, bi ọgbà ewebẹ̀: 11 Ṣugbọn ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a, ilẹ òke ati afonifoji ni, ti o si nmu omi òjo ọrun: 12 Ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ nṣe itọju; oju OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lara rẹ̀ nigbagbogbo, lati ìbẹrẹ ọdún dé opin ọdún. 13 Yio si ṣe, bi ẹnyin ba fetisi ofin mi daradara, ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo, ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo, 14 Nigbana li emi o ma fun nyin li òjo ilẹ nyin li akokò rẹ̀, òjo akọ́rọ̀ ati òjo àrọkuro, ki iwọ ki o le ma kó ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ sinu ile. 15 Emi o si fi koriko sinu pápa rẹ fun ohunọ̀sin rẹ, ki iwọ ki o le jẹun ki o si yó. 16 Ẹ ma ṣọ́ ara nyin, ki a má ba tàn àiya nyin jẹ, ki ẹ má si ṣe yapa, ki ẹ si sìn ọlọrun miran, ki ẹ si ma bọ wọn; 17 Ibinu OLUWA a si rú si nyin, on a si sé ọrun, ki òjo ki o má ba sí, ati ki ilẹ ki o má ba so eso rẹ̀; ẹnyin a si run kánkán kuro ni ilẹ rere na ti OLUWA fi fun nyin. 18 Ẹ fi ọ̀rọ mi wọnyi si àiya nyin ati si ọkàn nyin, ki ẹ si so wọn mọ́ ọwọ́ nyin fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọjá-igbaju niwaju nyin. 19 Ki ẹnyin ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ nyin, ki ẹnyin ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide. 20 Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun-ọ̀na-ode rẹ: 21 Ki ọjọ́ nyin ki o le ma pọ̀si i, ati ọjọ́ awọn ọmọ nyin, ni ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin lati fi fun wọn, bi ọjọ́ ọrun lori ilẹ aiye. 22 Nitoripe bi ẹnyin ba pa gbogbo ofin yi mọ́ gidigidi, ti mo palaṣẹ fun nyin, lati ma ṣe e; lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati faramọ́ ọ; 23 Nigbana ni OLUWA yio lé gbogbo awọn orilẹ-ède wọnyi jade kuro niwaju nyin, ẹnyin o si gbà orilẹ-ède ti o tobi ti o si lagbara jù nyin lọ. 24 Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀ yio jẹ́ ti nyin: lati aginjù nì, ati Lebanoni, lati odò nla nì, odò Euferate, ani dé ikẹhin okun ni yio jẹ́ opinlẹ nyin. 25 Kò sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju nyin: OLUWA Ọlọrun nyin, yio fi ìbẹru nyin ati ìfoiya nyin sara gbogbo ilẹ ti ẹnyin o tẹ̀, bi on ti wi fun nyin. 26 Wò o, emi fi ibukún ati egún siwaju nyin li oni; 27 Ibukún, bi ẹnyin ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni: 28 Ati egún, bi ẹnyin kò ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́ ti ẹnyin ba si yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, lati ma tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ti ẹnyin kò mọ̀ rí. 29 Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, ki iwọ ki o ma sure lori òke Gerisimu, ki iwọ ki o si ma gegun lori òke Ebali. 30 Awọn kọ ha wà ni ìha keji Jordani, li ọ̀na ìwọ-õrùn, ni ilẹ awọn ara Kenaani, ti ngbé Araba ti o kọjusi Gilgali, lẹba igbó More? 31 Nitoripe ẹnyin o gòke Jordani lati wọle ati lati gbà ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin, ẹnyin o si gbà a, ẹnyin o si ma gbé inu rẹ̀. 32 Ki ẹnyin ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gbogbo ìlana ati idajọ wọnni, ti mo fi siwaju nyin li oni.

Deuteronomi 12

Ibi Ìjọ́sìn Kanṣoṣo Náà

1 WỌNYI ni ìlana ati idajọ, ti ẹnyin o ma kiyesi lati ma ṣe ni ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ fi fun ọ lati ní, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà lori ilẹ-aiye. 2 Ki ẹnyin ki o run ibi gbogbo wọnni patapata, nibiti awọn orilẹ-ède nì, ti ẹnyin o gbà, nsìn oriṣa wọn, lori òke giga, ati lori òke kekeké, ati labẹ igi tutù gbogbo: 3 Ki ẹnyin ki o si wó pẹpẹ wọn, ki ẹ si bì ọwọ̀n wọn ṣubu, ki ẹ si fi iná kun igbo oriṣa wọn; ki ẹnyin ki o si ke ere fifin wọn lulẹ, ki ẹ si run orukọ wọn kuro ni ibẹ na. 4 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin. 5 Ṣugbọn ibi ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn ninu gbogbo ẹ̀ya nyin lati fi orukọ rẹ̀ si, ani ibujoko rẹ̀ li ẹnyin o ma wálọ, ati nibẹ̀ ni ki iwọ ki o ma wá: 6 Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o ma mú ẹbọ sisun nyin wá, ati ẹbọ nyin, ati idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ifẹ́-atinuwa nyin, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran nyin ati ti agbo-ẹran nyin: 7 Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o si ma jẹ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ ninu ohun gbogbo ti ẹnyin fi ọwọ́ nyin lé, ẹnyin ati awọn ara ile nyin, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún u fun ọ. 8 Ki ẹnyin ki o máṣe ṣe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awa nṣe nihin li oni, olukuluku enia ohun ti o tọ́ li oju ara rẹ̀: 9 Nitoripe ẹnyin kò sá ti idé ibi-isimi, ati ilẹ iní, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin. 10 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gòke Jordani, ti ẹnyin si joko ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin ni iní, ti o ba si fun nyin ni isimi kuro lọwọ awọn ọtá nyin gbogbo yiká, ti ẹnyin si joko li alafia: 11 Nigbana ni ibikan yio wà ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ li ẹnyin o ma mú gbogbo ohun ti mo palaṣẹ fun nyin wá; ẹbọ sisun nyin, ati ẹbọ nyin, idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati gbogbo àṣayan ẹjẹ́ nyin ti ẹnyin jẹ́ fun OLUWA. 12 Ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin, ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode nyin, nitori on kò ní ipín tabi iní pẹlu nyin. 13 Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o máṣe ru ẹbọ sisun rẹ ni ibi gbogbo ti iwọ ba ri: 14 Bikoṣe ni ibi ti OLUWA yio yàn ninu ọkan ninu awọn ẹ̀ya rẹ, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o ma ru ẹbọ sisun rẹ, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ. 15 Ṣugbọn ki iwọ ki o ma pa, ki o si ma jẹ ẹran ninu ibode rẹ gbogbo, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ ni ki o ma jẹ ninu rẹ̀, bi esuro, ati bi agbọnrin. 16 Kìki ẹ̀jẹ li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; lori ilẹ ni ki ẹ dà a si bi omi. 17 Ki iwọ ki o máṣe jẹ idamẹwa ọkà rẹ ninu ibode rẹ, tabi ti ọti-waini rẹ, tabi ti oróro rẹ, tabi ti akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, tabi ti agbo-ẹran rẹ, tabi ti ẹjẹ́ rẹ ti iwọ jẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwa rẹ, tabi ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ rẹ: 18 Bikoṣe ki iwọ ki o jẹ wọn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ: ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ninu ohun gbogbo ti iwọ fi ọwọ́ rẹ le. 19 Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o máṣe kọ̀ ọmọ Lefi silẹ ni gbogbo ọjọ́ rẹ lori ilẹ. 20 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ti iwọ ba si wipe, Emi o jẹ ẹran, nitoriti ọkàn rẹ nfẹ́ ẹran ijẹ; ki iwọ ki o ma jẹ ẹran, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ́. 21 Bi o ba ṣepe, ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ ba yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si, ba jìna jù fun ọ, njẹ ki iwọ ki o pa ninu ọwọ́-ẹran rẹ ati ninu agbo-ẹran rẹ, ti OLUWA fi fun ọ, bi emi ti fi aṣẹ fun o, ki iwọ ki o si ma jẹ ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́ ninu ibode rẹ. 22 Ani bi ã ti ijẹ esuro, ati agbọnrin, bẹ̃ni ki iwọ ki o ma jẹ wọn: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ yio jẹ ninu wọn bakanna. 23 Kìki ki o ṣọ́ ara rẹ gidigidi ki iwọ ki o máṣe jẹ ẹ̀jẹ: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi; iwọ kò si gbọdọ jẹ ẹmi pẹlu ẹran. 24 Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; iwọ o dà a silẹ bi omi. 25 Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; ki o le ma dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA. 26 Kìki ohun mimọ́ rẹ ti iwọ ní, ati ẹjẹ́ rẹ ni ki iwọ ki o mú, ki o si lọ si ibi ti OLUWA yio yàn: 27 Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun rẹ, ẹran ati ẹ̀jẹ na, lori pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ati ẹ̀jẹ ẹbọ rẹ ni ki a dà sori pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma jẹ ẹran na. 28 Kiyesara ki o si ma gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti mo palaṣẹ fun ọ, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ lailai, nigbati iwọ ba ṣe eyiti o dara ti o si tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ. 29 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba ke awọn orilẹ-ède wọnni kuro niwaju rẹ, nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà wọn, ti iwọ si rọpò wọn, ti iwọ si joko ni ilẹ wọn; 30 Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ má ba bọ́ si idẹkùn ati tẹle wọn lẹhin, lẹhin igbati a ti run wọn kuro niwaju rẹ; ki iwọ ki o má si bère oriṣa wọn, wipe, Bawo li awọn orilẹ-ède wọnyi ti nsìn oriṣa wọn? emi o si ṣe bẹ̃ pẹlu. 31 Iwọ kò gbọdọ ṣe bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe gbogbo ohun irira si OLUWA, ti on korira ni nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; nitoripe awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin wọn pẹlu ni nwọn nsun ninu iná fun oriṣa wọn. 32 Ohunkohun ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin, ẹ ma kiyesi lati ṣe e: iwọ kò gbọdọ fikún u, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bù kuro ninu rẹ̀.

Deuteronomi 13

1 BI wolĩ kan ba hù lãrin rẹ, tabi alalá kan, ti o si fi àmi tabi iṣẹ́-iyanu kan hàn ọ, 2 Ti àmi na tabi iṣẹ-iyanu na ti o sọ fun ọ ba ṣẹ, wipe, Ẹ jẹ ki a tẹlé ọlọrun miran lẹhin, ti iwọ kò ti mọ̀ rí, ki a si ma sìn wọn; 3 Iwọ kò gbọdọ fetisi ọ̀rọ wolĩ na, tabi alalá na: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ndan nyin wò ni, lati mọ̀ bi ẹnyin ba fi gbogbo àiya nyin, ati gbogbo ọkàn nyin fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin. 4 Lẹhin OLUWA Ọlọrun nyin ni ki ẹnyin ki o ma rìn, on ni ki ẹ si ma bẹ̀ru, ki ẹ si ma pa ofin rẹ̀ mọ́, ki ẹ si ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ki ẹ si ma sìn i, ki ẹ si ma faramọ́ ọ. 5 Ati wolĩ na, tabi alalá na, ni ki ẹnyin ki o pa; nitoriti o ti sẹ ọtẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ti o ti rà nyin kuro li oko-ẹrú, lati tì ọ kuro li oju ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun rẹ filelẹ li aṣẹ fun ọ lati ma rìn ninu rẹ̀. Bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ibi kuro lãrin rẹ. 6 Bi arakunrin rẹ, ọmọ iya rẹ, tabi ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ obinrin, tabi aya õkan-àiya rẹ, tabi ọrẹ́ rẹ, ti o dabi ọkàn ara rẹ, bi o ba tàn ọ ni ìkọkọ, wipe, Jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti iwọ kò mọ̀ rí, iwọ, tabi awọn baba rẹ; 7 Ninu awọn oriṣa awọn enia ti o yi nyin kakiri, ti o sunmọ ọ, tabi ti o jìna si ọ, lati opin ilẹ dé opin ilẹ; 8 Iwọ kò gbọdọ jẹ fun u, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fetisi tirẹ̀; bẹ̃ni ki oju ki o máṣe ro ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe da a si, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe bò o: 9 Ṣugbọn pipa ni ki o pa a; ọwọ́ rẹ ni yio kọ́ wà lara rẹ̀ lati pa a, ati lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia. 10 Ki iwọ ki o si sọ ọ li okuta, ki o kú; nitoriti o nwá ọ̀na lati tì ọ kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú. 11 Gbogbo Israeli yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù ìwabuburu bi irú eyi mọ́ lãrin nyin. 12 Bi iwọ ba gbọ́ ninu ọkan ninu awọn ilu rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ma gbé inu rẹ̀ pe, 13 Awọn ọkunrin kan, awọn ọmọ Beliali, nwọn jade lọ kuro ninu nyin, nwọn si kó awọn ara ilu wọn sẹhin, wipe, Ẹ jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti ẹnyin kò mọ̀ rí. 14 Nigbana ni ki iwọ ki o bère, ki iwọ ki o si ṣe àwari, ki o si bère pẹlẹpẹlẹ; si kiyesi i, bi o ba ṣe otitọ, ti ohun na ba si da nyin loju, pe a ṣe irú nkan irira bẹ̃ ninu nyin; 15 Ki iwọ ki o fi oju idà kọlù awọn ara ilu na nitõtọ, lati run u patapata, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ohunọ̀sin inu rẹ̀, ni ki iwọ ki o fi oju idà pa. 16 Ki iwọ ki o si kó gbogbo ikogun rẹ̀ si ãrin igboro rẹ̀, ki iwọ ki o si fi iná kun ilu na, ati gbogbo ikogun rẹ̀ patapata fun OLUWA Ọlọrun rẹ: ki o si ma jasi òkiti lailai; a ki yio si tun tẹ̀ ẹ dó mọ́. 17 Ki ọkan ninu ohun ìyasọtọ na má si ṣe mọ́ ọ lọwọ; ki OLUWA ki o le yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀, ki o si ma ṣãnu fun ọ, ki o si ma ṣe iyọnu rẹ, ki o si ma mu ọ bisi i, bi o ti bura fun awọn baba rẹ; 18 Nigbati iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ofin rẹ̀ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ.

Deuteronomi 14

Àṣà Tí A kò Gbọdọ̀ Dá tí A bá ń Ṣọ̀fọ̀

1 ỌMỌ OLUWA Ọlọrun nyin li ẹnyin iṣe: ẹnyin kò gbọdọ̀ bù ara nyin li abẹ, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fá iwaju nyin nitori okú. 2 Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, OLUWA si ti yàn ọ lati ma ṣe enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo orilẹ-ède lọ ti mbẹ lori ilẹ.

Ẹran Tí Ó Mọ́ ati Èyí Tí Kò Mọ́

3 Iwọ kò gbọdọ jẹ ohun irira kan. 4 Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ: akọmalu, agutan, ati ewurẹ, 5 Agbọnrin, ati esuwo, ati gala, ati ewurẹ igbẹ́, ati pigargi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu. 6 Ati gbogbo ẹranko ti o là bàta-ẹsẹ̀, ti o si pinyà bàta-ẹsẹ̀ si meji, ti o si njẹ apọjẹ ninu ẹranko, eyinì ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 7 Ṣugbọn wọnyi ni ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi ninu awọn ti o là bàta-ẹsẹ̀; bi ibakasiẹ, ati ehoro, ati garà, nitoriti nwọn njẹ apọjẹ ṣugbọn nwọn kò là bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ ni nwọn jasi fun nyin: 8 Ati ẹlẹdẹ̀, nitoriti o là bàta-ẹsẹ̀ ṣugbọn kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ ni fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn okú wọn. 9 Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo eyiti mbẹ ninu omi: gbogbo eyiti o ní lẹbẹ ti o si ní ipẹ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 10 Ati ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ti kò si ní ipẹ́, ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ẹ; alaimọ́ ni fun nyin. 11 Gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 12 Ṣugbọn wọnyi li awọn ti ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu wọn: idì, ati aṣa-idì, ati idì-ẹja. 13 Ati glede, ati aṣá, ati gunugun li onirũru rẹ̀; 14 Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀; 15 Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀; 16 Owiwi kekere, ati owiwi nla, ati ogbugbu; 17 Ati pelikan, ati àkala, ati ìgo; 18 Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán. 19 Ati ohun gbogbo ti nrakò ti nfò, o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: a kò gbọdọ jẹ wọn. 20 Ṣugbọn gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 21 Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti o tikara rẹ̀ kú: iwọ le fi i fun alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki on ki o jẹ ẹ; tabi ki iwọ ki o tà a fun ajeji: nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.

Òfin nípa Ìdámẹ́wàá

22 Ki iwọ ki o dá idamẹwa gbogbo ibisi irugbìn rẹ, ti nti oko rẹ wá li ọdọdún. 23 Niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, ni ki iwọ ki o si ma jẹ idamẹwa ọkà rẹ, ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, ati ti agbo-ẹran rẹ; ki iwọ ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ nigbagbogbo. 24 Bi ọ̀na na ba si jìn jù fun ọ, ti iwọ ki yio fi le rù u lọ, tabi bi ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si ba jìn jù fun ọ, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba bukún ọ: 25 Njẹ ki iwọ ki o yi i si owo, ki iwọ ki o si dì owo na li ọwọ́ rẹ, ki o si lọ si ibi na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn. 26 Ki iwọ ki o si ná owo na si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, si akọmalu, tabi agutan, tabi ọti-waini, tabi ọti lile kan, tabi si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́: ki iwọ ki o si ma jẹ nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma yọ̀, iwọ, ati awọn ara ile rẹ: 27 Ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ; iwọ kò gbọdọ kọ̀ ọ silẹ; nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ. 28 Li opin ọdún mẹta ni ki iwọ ki o mú gbogbo idamẹwa ibisi rẹ wa li ọdún na, ki iwọ ki o si gbé e kalẹ ninu ibode rẹ: 29 Ati ọmọ Lefi, nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ, yio wá, nwọn o si jẹ nwọn o si yó; ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le bukún ọ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ ti iwọ nṣe.

Deuteronomi 15

Ọdún Keje

1 LẸHIN ọdún mejemeje ni ki iwọ ki o ma ṣe ijọwọlọwọ. 2 Ọ̀na ijọwọlọwọ na si li eyi: gbogbo onigbese ti o wín ẹnikeji rẹ̀ ni nkan ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ; ki o ma ṣe fi agbara bère rẹ̀ lọwọ ẹnikeji rẹ̀, tabi lọwọ arakunrin rẹ̀; nitoriti a pè e ni ijọwọlọwọ OLUWA. 3 Iwọ le fi agbara bère lọwọ alejò: ṣugbọn eyiti ṣe tirẹ ti mbẹ li ọwọ́ arakunrin rẹ, ni ki iwọ ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ. 4 Ṣugbọn ki yio sí talaka ninu nyin; (nitoripe OLUWA yio busi i fun ọ pupọ̀ ni ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati gbà a;) 5 Kìki bi iwọ ba fi ifarabalẹ fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi gbogbo ofin yi, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni lati ṣe. 6 Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ, bi o ti ṣe ileri fun ọ: iwọ o si ma wín ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn iwọ ki yio tọrọ; iwọ o si ma ṣe olori ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn nwọn ki yio ṣe olori rẹ. 7 Bi talakà kan ba mbẹ ninu nyin, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ, ninu ibode rẹ kan, ni ilẹ rẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe mu àiya rẹ le si i, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe há ọwọ́ rẹ si talakà arakunrin rẹ: 8 Sugbọn lilà ni ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun u, ki iwọ ki o si wín i li ọ̀pọlọpọ tó fun ainí rẹ̀, li ohun ti nfẹ́. 9 Ma kiyesara ki ìro buburu kan ki o máṣe sí ninu àiya rẹ, wipe, Ọdún keje, ọdún ijọwọlọwọ sunmọtosi; oju rẹ a si buru si arakunrin rẹ talakà, ti iwọ kò si fun u ni nkan; on a si kigbe pè OLUWA nitori rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ fun ọ. 10 Ki iwọ ki o fi fun u nitõtọ, ki inu rẹ ki o máṣe bàjẹ́ nigbati iwọ ba fi fun u: nitoripe nitori nkan yi ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo iṣẹ rẹ, ati ni gbogbo ohun ti iwọ ba dá ọwọ́ rẹ lé. 11 Nitoripe talakà kò le tán ni ilẹ na: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun arakunrin rẹ, fun talakà rẹ, ati fun alainí rẹ, ninu ilẹ rẹ.

Ìlò Ẹrú

12 Ati bi a ba tà arakunrin rẹ kan fun ọ, ọkunrin Heberu, tabi obinrin Heberu, ti o si sìn ọ li ọdún mẹfa; njẹ li ọdún keje ki iwọ ki o rán a lọ kuro lọdọ rẹ li ominira. 13 Nigbati iwọ ba si nrán a lọ li ominira kuro lọdọ rẹ, iwọ kò gbọdọ jẹ ki o lọ li ọwọ́ ofo: 14 Ki iwọ ki o pèse fun u li ọ̀pọlọpọ lati inu agbo-ẹran rẹ wá, ati lati ilẹ-ipakà rẹ, ati lati ibi ifunti rẹ, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún ọ ni ki iwọ ki o fi fun u. 15 Ki iwọ ki o si ranti pe, iwọ a ti ma ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ: nitorina ni mo ṣe fi aṣẹ nkan yi lelẹ fun ọ li oni. 16 Yio si ṣe, bi o ba wi fun ọ pe, Emi ki yio jade lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o fẹ́ ọ ati ile rẹ, nitoriti o dara fun u lọdọ rẹ; 17 Nigbana ni ki iwọ ki o mú olu kan, ki iwọ ki o si fi lu u li etí mọ́ ara ilẹkun, ki on ki o si ma ṣe ọmọ-ọdọ rẹ lailai. Ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ni ki iwọ ki o ṣe bẹ̃ si gẹgẹ. 18 Ki o máṣe ro ọ loju, nigbati iwọ ba rán a li ominira lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o ní iye lori to alagbaṣe meji ni sísìn ti o sìn ọ li ọdún mẹfa: OLUWA Ọlọrun rẹ yio si busi i fun ọ ninu gbogbo ohun ti iwọ nṣe.

Àkọ́bí Mààlúù ati ti Aguntan

19 Gbogbo akọ́bi akọ ti o ti inu ọwọ-ẹran rẹ ati inu agbo-eran rẹ wá, ni ki iwọ ki o yàsi-mimọ́, fun OLUWA Ọlọrun rẹ: iwọ kò gbọdọ fi akọ́bi ninu akọmalu rẹ ṣe iṣẹ kan, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹrun akọ́bi agutan rẹ, 20 Ki iwọ ki o ma jẹ ẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ọdọdún, ni ibi ti OLUWA yio yàn, iwọ, ati awọn ara ile rẹ. 21 Bi abùku kan ba si wà lara rẹ̀, bi o mukun ni, bi o fọju ni, tabi bi o ni abùku buburu kan, ki iwọ ki o máṣe fi rubọ si OLUWA Ọlọrun rẹ. 22 Ki iwọ ki o jẹ ẹ ninu ibode rẹ: alaimọ́ ati ẹni ti o mọ́ ni ki o jẹ ẹ bakanna, bi esuwo, ati bi agbọnrin. 23 Kìki iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ rẹ̀; ki iwọ ki o dà a silẹ bi omi.

Deuteronomi 16

Àjọ Ìrékọjá

1 IWỌ ma kiyesi oṣù Abibu, ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe li oṣù Abibu ni OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ilẹ Egipti jade wa li oru. 2 Nitorina ki iwọ ki o ma pa ẹran irekọja si OLUWA Ọlọrun rẹ, ninu agbo-ẹran ati ninu ọwọ́-ẹran, ni ibi ti OLUWA yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si. 3 Iwọ kò gbọdọ jẹ àkara wiwu pẹlu rẹ̀; ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu pẹlu rẹ̀, ani onjẹ ipọnju; nitoripe iwọ ti ilẹ Egipti jade wá ni kanjukanju: ki iwọ ki o le ma ranti ọjọ́ ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wa, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo. 4 Ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ li àgbegbe rẹ gbogbo ni ijọ́ meje; bẹ̃ni ki ohun kan ninu ẹran ti iwọ o fi rubọ li ọjọ́ kini li aṣalẹ, ki o máṣe kù di owurọ̀. 5 Ki iwọ ki o máṣe pa ẹran irekọja na ninu ibode rẹ kan, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ: 6 Ṣugbọn bikoṣe ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o pa ẹran irekọja na li aṣalẹ, nigba ìwọ-õrùn, li akokò ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wá. 7 Ki iwọ ki o si sun u, ki iwọ ki o si jẹ ẹ ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn: ki iwọ ki o si pada li owurọ̀, ki o si lọ sinu agọ́ rẹ. 8 Ijọ́ mẹfa ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu: ati ni ijọ́ keje ki ajọ kan ki o wà fun OLUWA Ọlọrun rẹ; ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹ́ kan.

Àjọ̀dún Ìkórè

9 Ọsẹ meje ni ki iwọ ki o kà fun ara rẹ: bẹ̀rẹsi ati kà ọ̀sẹ meje na lati ìgba ti iwọ ba tẹ̀ doje bọ̀ ọkà. 10 Ki iwọ ki o si pa ajọ ọ̀sẹ mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu ọrẹ ifẹ́-atinuwa ọwọ́ rẹ, ti iwọ o fi fun u, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti busi i fun ọ: 11 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ lãrin rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si. 12 Ki iwọ ki o si ma ranti pe, ẹrú ni iwọ ti jẹ́ ni Egipti: ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ṣe ìlana wọnyi.

Àjọ̀dún Àgọ́

13 Ki iwọ ki o si ma pa ajọ agọ́ mọ́ li ọjọ́ meje, lẹhin ìgba ti iwọ ba ṣe ipalẹmọ ilẹ-ipakà rẹ ati ibi-ifunti rẹ. 14 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ajọ rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ. 15 Ijọ́ meje ni ki iwọ ki o fi ṣe ajọ si OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti OLUWA yio yàn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo asunkún rẹ, ati ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, nitorina ki iwọ ki o ma yọ̀ nitõtọ. 16 Lẹ̃mẹta li ọdún ni ki gbogbo awọn ọkunrin rẹ ki o farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn; ni ajọ àkara alaiwu, ati ni ajọ ọ̀sẹ, ati ni ajọ agọ́: ki nwọn ki o má si ṣe ṣánwọ wá iwaju OLUWA: 17 Ki olukuluku ki o mú ọrẹ wá bi agbara rẹ̀ ti to, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ.

Ìlànà nípa Ẹjọ́ Dídá

18 Awọn onidajọ ati awọn ijoye ni ki iwọ ki o fi jẹ ninu ibode rẹ gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, gẹgẹ bi ẹ̀ya rẹ: ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia na li ododo. 19 Iwọ kò gbọdọ lọ́ idajọ; iwọ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju enia: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbà ẹ̀bun; nitoripe ẹ̀bun ni ifọ́ ọlọgbọ́n li oju, on a si yi ọ̀rọ olododo po. 20 Eyiti iṣe ododo patapata ni ki iwọ ki o ma tọ̀ lẹhin, ki iwọ ki o le yè, ki iwọ ki o si ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 21 Iwọ kò gbọdọ rì igi oriṣa kan sunmọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ o mọ fun ara rẹ. 22 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbé ọwọ̀n kan kalẹ fun ara rẹ: ti OLUWA Ọlọrun rẹ korira.

Deuteronomi 17

1 IWỌ kò gbọdọ fi akọmalu, tabi agutan, ti o lí àbuku, tabi ohun buburu kan rubọ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ. 2 Bi a ba ri lãrin nyin, ninu ibode rẹ kan ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ọkunrin tabi obinrin ti nṣe nkan buburu li oju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni rire majẹmu rẹ̀ kọja, 3 Ti o si lọ ti o nsìn ọlọrun miran, ti o si mbọ wọn, iba ṣe õrùn, tabi oṣupa, tabi ọkan ninu ogun ọrun, ti emi kò palaṣẹ; 4 Ti a ba si wi fun ọ, ti iwọ si ti gbọ́, ti iwọ si wádi rẹ̀ rere, si kiyesi i, ti o jasi otitọ, ti ohun na si daniloju pe, a ṣe irú irira yi ni Israeli; 5 Nigbana ni ki iwọ ki o mú ọkunrin tabi obinrin na, ti o ṣe ohun buburu yi jade wá, si ibode rẹ, ani ọkunrin tabi obinrin na, ki iwọ ki o si sọ wọn li okuta pa. 6 Li ẹnu ẹlẹri meji, tabi ẹlẹri mẹta, li a o pa ẹniti o yẹ si ikú; ṣugbọn li ẹnu ẹlẹri kan, a ki yio pa a. 7 Ọwọ́ awọn ẹlẹri ni yio tète wà lara rẹ̀ lati pa a, lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia. Bẹ̃ni iwọ o si mú ìwabuburu kuro lãrin nyin. 8 Bi ẹjọ́ kan ba ṣoro jù fun ọ lati dá, lãrin èjẹ on ẹ̀jẹ, lãrin ọ̀ran on ọ̀ran, ati lãrin ìluni ati ìluni, ti iṣe ọ̀ran iyàn ninu ibode rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o dide, ki o si gòke lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn; 9 Ki iwọ ki o si tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi lọ, ati onidajọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni: ki o si bère; nwọn o si fi ọ̀rọ idajọ hàn ọ: 10 Ki iwọ ki o si ṣe bi ọ̀rọ idajọ, ti awọn ará ibi ti OLUWA yio yàn na yio fi hàn ọ; ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti nwọn kọ́ ọ: 11 Gẹgẹ bi ọ̀rọ ofin ti nwọn o kọ́ ọ, ati gẹgẹ bi idajọ ti nwọn o wi fun ọ, ni ki iwọ ki o ṣe: ki iwọ ki o máṣe yà si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi, kuro li ọ̀rọ ti nwọn o fi hàn ọ. 12 Ọkunrin na ti o ba si fi igberaga ṣe e, ti kò fẹ́ gbọ́ ti alufa na, ti o duro lati ma ṣe iṣẹ alufa nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, tabi lati gbọ́ ti onidajọ na, ani ọkunrin na yio kú: iwọ o si mú ìwabuburu kuro ni Israeli. 13 Gbogbo enia yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki yio si gberaga mọ́.

Ìkìlọ̀ nípa Yíyan Ọba

14 Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ ba si gbà a, ti iwọ ba si joko ninu rẹ̀, ti iwọ o si wipe, Emi o fi ọba jẹ lori mi, gẹgẹ bi gbogbo awọn orilẹ-ède ti o yi mi ká; 15 Kìki ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn, ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ọkan ninu awọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ki iwọ ki o máṣe fi alejò ṣe olori rẹ, ti ki iṣe arakunrin rẹ. 16 Ṣugbọn on kò gbọdọ kó ẹṣin jọ fun ara rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe mu awọn enia pada lọ si Egipti, nitori ki o ba le kó ẹṣin jọ: nitori OLUWA ti wi fun nyin pe, Ẹnyin kò gbọdọ tun pada lọ li ọ̀na na mọ́. 17 Bẹ̃ni ki o máṣe kó obinrin jọ fun ara rẹ̀, ki àiya rẹ̀ ki o má ba yipada: bẹ̃ni ki o máṣe kó fadakà tabi wurá jọ fun ara rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ. 18 Yio si ṣe, nigbati o ba joko lori itẹ́ ijọba rẹ̀, ki on ki o si kọ iwé ofin yi sinu iwé kan fun ara rẹ̀, lati inu eyiti mbẹ niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi: 19 Yio si wà lọdọ rẹ̀, on o si ma kà ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo: ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ̀, lati ma pa gbogbo ọ̀rọ ofin yi mọ́ ati ilana wọnyi, lati ma ṣe wọn: 20 Ki àiya rẹ̀ ki o má ba gbega jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ, ati ki o má ba yipada kuro ninu ofin na, si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi: ki on ki o le mu ọjọ́ rẹ̀ pẹ ni ijọba rẹ̀, on, ati awọn ọmọ rẹ̀, lãrin Israeli.

Deuteronomi 18

Ìpín Àwọn Àlùfáàa

1 AWỌN alufa, awọn ọmọ Lefi, ani gbogbo ẹ̀ya Lefi, ki yio ní ipín tabi iní pẹlu Israeli: ki nwọn ki o ma jẹ ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ati iní rẹ̀ ni ki nwọn ki o ma jẹ. 2 Nitorina ni nwọn ki yio ṣe ni iní lãrin awọn arakunrin wọn: OLUWA ni iní wọn, bi o ti wi fun wọn. 3 Eyi ni yio si ma jẹ́ ipín awọn alufa lati ọdọ awọn enia wá, lati ọdọ awọn ti o ru ẹbọ, iba ṣe akọ-malu tabi agutan, ki nwọn ki o si fi apa fun alufa, ati ẹrẹkẹ mejeji ati àpo. 4 Akọ́so ọkà rẹ pẹlu, ati ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́rẹ irun agutan rẹ, ni ki iwọ ki o fi fun u. 5 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ li o yàn a ninu gbogbo awọn ẹ̀ya rẹ, lati ma duro ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai. 6 Ati bi ọmọ Lefi kan ba ti inu ibode rẹ kan wá, ni gbogbo Israeli, nibiti o gbé nṣe atipo, ti o si fi gbogbo ifẹ́ inu rẹ̀ wá si ibi ti OLUWA yio yàn; 7 Njẹ ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, bi gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Lefi, ti nduro nibẹ̀ niwaju OLUWA. 8 Ipín kanna ni ki nwọn ki o ma jẹ, làika eyiti o ní nipa tità ogún baba rẹ̀.

Ìkìlọ̀ nípa Àwọn Àṣà Ìbọ̀rìṣà

9 Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe kọ́ ati ṣe gẹgẹ bi ìwa-irira awọn orilẹ-ède wọnni. 10 Ki a máṣe ri ninu nyin ẹnikan ti nmu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là iná já, tabi ti nfọ̀ afọ̀ṣẹ, tabi alakiyesi-ìgba, tabi aṣefàiya, tabi ajẹ́, 11 Tabi atuju, tabi aba-iwin-gbìmọ, tabi oṣó, tabi abokulò. 12 Nitoripe gbogbo awọn ti nṣe nkan wọnyi irira ni si OLUWA: ati nitori irira wọnyi ni OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn jade kuro niwaju rẹ. 13 Ki iwọ ki o pé lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ.

Ìlérí láti Rán Wolii Kan sí Israẹli

14 Nitori orilẹ-ède wọnyi ti iwọ o gbà, nwọn fetisi awọn alakiyesi-ìgba, ati si awọn alafọ̀ṣẹ: ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni, OLUWA Ọlọrun rẹ kò gbà fun ọ bẹ̃. 15 OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé wolĩ kan dide fun ọ lãrin rẹ, ninu awọn arakunrin rẹ, bi emi; on ni ki ẹnyin ki o fetisi; 16 Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bère lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ́ ajọ nì, wipe, Máṣe jẹ ki emi tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun mi mọ́, bẹ̃ni ki emi ki o má tun ri iná nla yi mọ́; ki emi ki o mà ba kú. 17 OLUWA si wi fun mi pe, Nwọn wi rere li eyiti nwọn sọ. 18 Emi o gbé wolĩ kan dide fun wọn lãrin awọn arakunrin wọn, bi iwọ; emi o si fi ọ̀rọ mi si i li ẹnu, on o si sọ fun wọn gbogbo eyiti mo palaṣẹ. 19 Yio si ṣe, ẹniti kò ba fetisi ọ̀rọ mi ti on o ma sọ li orukọ mi, emi o bère lọwọ rẹ̀. 20 Ṣugbọn wolĩ na, ti o kùgbu sọ ọ̀rọ kan li orukọ mi, ti emi kò fi fun u li aṣẹ lati sọ, tabi ti o sọ̀rọ li orukọ ọlọrun miran, ani wolĩ na yio kú. 21 Bi iwọ ba si wi li ọkàn rẹ pe, Bawo li awa o ṣe mọ̀ ọ̀rọ ti OLUWA kò sọ? 22 Nigbati wolĩ kan ba sọ̀rọ li orukọ OLUWA, bi ohun na kò ba ri bẹ̃, ti kò ba si ṣẹ, eyinì li ohun ti OLUWA kò sọ: wolĩ na li o fi ikùgbu sọ̀rọ: ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru rẹ̀.

Deuteronomi 19

Àwọn ìlú Ààbò

1 NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba ke awọn orilẹ-ède wọnni kuro, ilẹ ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ si rọpò wọn, ti iwọ si joko ni ilu wọn, ati ni ile wọn; 2 Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ lãrin ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní. 3 Ki iwọ ki o là ọ̀na kan fun ara rẹ, ki iwọ ki o si pín àgbegbe ilẹ rẹ si ipa mẹta, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní, ki gbogbo apania ki o ma sá sibẹ̀. 4 Eyi si ni ọ̀ran apania, ti yio ma sá sibẹ̀, ki o le yè: ẹnikẹni ti o ba ṣeṣi pa ẹnikeji rẹ̀, ti on kò korira rẹ̀ tẹlẹrí; 5 Bi nigbati enia ba wọ̀ inu igbó lọ pélu ẹnikeji rẹ̀ lati ke igi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ gbé ãke lati fi ke igi na lulẹ, ti ãke si yọ kuro ninu erú, ti o si bà ẹnikeji rẹ̀, ti on kú; ki o salọ si ọkan ninu ilu wọnni, ki o si yè: 6 Ki agbẹsan ẹ̀jẹ ki o má ba lepa apania na, nigbati ọkàn rẹ̀ gboná, ki o si lé e bá, nitoriti ọ̀na na jìn, a si pa a; nigbati o jẹ pe kò yẹ lati kú, niwọnbi on kò ti korira rẹ̀ tẹlẹrí. 7 Nitorina emi fi aṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ. 8 Ati bi OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, ti on ti bura fun awọn baba rẹ, ti o sì fun ọ ni gbogbo ilẹ na, ti o si ṣe ileri fun awọn baba rẹ; 9 Bi iwọ ba pa gbogbo ofin yi mọ́ lati ma ṣe e, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati lati ma rìn titi li ọ̀na rẹ̀; nigbana ni ki iwọ ki o fi ilu mẹta kún u si i fun ara rẹ, pẹlu mẹta wọnyi; 10 Ki a má ba tà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ninu ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki ẹ̀jẹ ki o má ba wà li ọrùn rẹ. 11 Ṣugbọn bi ọkunrin kan ba korira ẹnikeji rẹ̀, ti o si ba dè e, ti o si dide si i, ti o si lù u li alupa, ti o si kú, ti on si salọ sinu ọkan ninu ilu wọnyi: 12 Njẹ ki awọn àgba ilu rẹ̀ ki o ránni ki nwọn ki o si mú u ti ibẹ̀ wá, ki nwọn ki o si fà a lé agbẹsan ẹ̀jẹ lọwọ ki o ba le kú. 13 Ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u, ṣugbọn ki iwọ ki o mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lori Israeli, ki o si le dara fun ọ.

Àwọn Ààlà Àtayébáyé

14 Iwọ kò gbọdọ yẹ̀ àla ẹnikeji rẹ, ti awọn ara iṣaju ti pa ni ilẹ iní rẹ ti iwọ o ní, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní.

Àlàyé nípa Ẹlẹ́rìí

15 Ki ẹlẹri kanṣoṣo ki o máṣe dide jẹri tì enia nitori aiṣedede kan, tabi nitori ẹ̀ṣẹ kan ninu ẹ̀ṣẹ ti o ba ṣẹ̀: li ẹnu ẹlẹri meji, tabi li ẹnu ẹlẹri mẹta, li ọ̀ran yio fẹsẹmulẹ. 16 Bi ẹlẹri eké ba dide si ọkunrin lati jẹri tì i li ohun ti kò tọ́: 17 Njẹ ki awọn ọkunrin mejeji na lãrin ẹniti ọ̀rọ iyàn na gbé wà, ki o duro niwaju OLUWA, niwaju awọn alufa ati awọn onidajọ, ti yio wà li ọjọ wọnni, 18 Ki awọn onidajọ na ki o si tọ̀sẹ rẹ̀ pẹlẹpẹlẹ: si kiyesi i bi ẹlẹri na ba ṣe ẹlẹri eké, ti o si jẹri-eké si arakunrin rẹ̀; 19 Njẹ ki ẹnyin ki o ṣe si i, bi on ti rò lati ṣe si arakunrin rẹ̀: bẹ̃ni iwọ o si mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin. 20 Awọn ti o kù yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù irú ìwa-buburu bẹ̃ mọ́ lãrin nyin. 21 Ki oju rẹ ki o má si ṣe ṣãnu; ẹmi fun ẹmi, oju fun oju, ehín fun ehín, ọwọ́ fun ọwọ́, ẹsẹ̀ fun ẹsẹ̀.

Deuteronomi 20

Ọ̀rọ̀ nípa Ogun

1 NIGBATI iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti iwọ si ri ẹṣin, ati kẹkẹ́-ogun, ati awọn enia ti o pọ̀ jù ọ, máṣe bẹ̀ru wọn: nitori OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá. 2 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba sunmọ ogun na, ki alufa ki o sunmọtosi, ki o si sọ̀rọ fun awọn enia. 3 Ki o si wi fun wọn pe, Gbọ́, Israeli, li oni ẹnyin sunmọ ogun si awọn ọtá nyin: ẹ máṣe jẹ ki àiya nyin ki o ṣojo, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe warìri, bẹ̃ni ẹ má si ṣe fòya nitori wọn; 4 Nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ni mbá nyin lọ, lati bá awọn ọtá nyin jà fun nyin, lati gbà nyin là. 5 Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia, pe, Ọkunrin wo li o kọ ile titun, ti kò ti ikó si i? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba kó si i. 6 Ati ọkunrin wo li o gbìn ọgbà-àjara, ti kò si ti ijẹ ninu rẹ̀? jẹ ki on pẹlu ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba jẹ ẹ. 7 Ati ọkunrin wo li o fẹ́ iyawo, ti kò ti igbé e? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba gbé e. 8 Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia na si i, ki nwọn ki o si wipe, Ọkunrin wo li o wà ti o bẹ̀ru ti o si nṣojo? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki àiya awọn arakunrin rẹ̀ ki o má ba ṣojo pẹlu bi àiya tirẹ̀. 9 Yio si ṣe, nigbati awọn olori-ogun ba pari ọ̀rọ sisọ fun awọn enia tán, ki nwọn ki o si fi awọn balogun jẹ lori awọn enia na. 10 Nigbati iwọ ba sunmọ ilu kan lati bá a jà, nigbana ni ki iwọ ki o fi alafia lọ̀ ọ. 11 Yio si ṣe, bi o ba da ọ lohùn alafia, ti o si ṣilẹkun silẹ fun ọ, njẹ yio ṣe, gbogbo awọn enia ti a ba bá ninu rẹ̀, nwọn o si ma jẹ́ ọlọsin fun ọ, nwọn o si ma sìn ọ. 12 Bi kò ba si fẹ́ bá ọ ṣe alafia, ṣugbọn bi o ba fẹ́ bá ọ jà, njẹ ki iwọ ki o dótì i: 13 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi i lé ọ lọwọ, ki iwọ ki o si fi oju idà pa gbogbo ọkunrin ti mbẹ ninu rẹ̀: 14 Ṣugbọn awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ ati ohun-ọ̀sin, ati ohun gbogbo ti mbẹ ni ilu na, ani gbogbo ikogun rẹ̀, ni ki iwọ ki o kó fun ara rẹ; ki iwọ ki o si ma jẹ ikogun awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 15 Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo ilu ti o jìna rére si ọ, ti ki iṣe ninu ilu awọn orilẹ-ède wọnyi. 16 Ṣugbọn ninu ilu awọn enia wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki iwọ ki o máṣe da ohun kan si ti o nmí: 17 Ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn run patapata; awọn ọmọ Hitti, ati awọn Amori, awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ: 18 Ki nwọn ki o má ba kọ́ nyin lati ma ṣe bi gbogbo iṣẹ-irira wọn, ti nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; ẹnyin a si ṣẹ̀ bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin. 19 Nigbati iwọ ba dótì ilu kan pẹ titi, lati bá a jà lati kó o, ki iwọ ki o máṣe run igi tutù rẹ̀ ni yiyọ ãke tì wọn; nitoripe iwọ le ma jẹ ninu wọn, iwọ kò si gbọdọ ke wọn lulẹ; nitori igi igbẹ́ ha ṣe enia bi, ti iwọ o ma dòtí i? 20 Kìki igi ti iwọ mọ̀ pe nwọn ki iṣe igi jijẹ, on ni ki iwọ ki o run, ki o si ke lulẹ; ki iwọ ki o si sọ agbàra tì ilu na ti mbá ọ jà, titi a o fi ṣẹ́ ẹ.

Deuteronomi 21

Tí Ikú Ẹnìkan Bá Rúni lójú

1 BI a ba ri ẹnikan ti a pa ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati gbà a, ti o dubulẹ ni igbẹ́, ti a kò si mọ̀ ẹniti o pa a: 2 Nigbana ni ki awọn àgba rẹ ati awọn onidajọ rẹ ki o jade wá, ki nwọn ki o si wọ̀n jijìna awọn ilu ti o yi ẹniti a pa na ká. 3 Yio si ṣe, pe ilu ti o sunmọ ẹniti a pa na, ani awọn àgba ilu na ki nwọn mú ẹgbọrọ abo-malu kan, ti a kò fi ṣiṣẹ rí, ti kò si fà ninu àjaga rí; 4 Ki awọn àgba ilu na ki o mú ẹgbọrọ abo-malu na sọkalẹ wá, si afonifoji ti o ní omi ṣiṣàn kan, ti a kò ro ti a kò si gbìn, ki nwọn ki o si ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ abomalu na nibẹ̀ li afonifoji na: 5 Awọn alufa, awọn ọmọ Lefi yio si sunmọtosi; nitoripe awọn ni OLUWA Ọlọrun rẹ yàn lati ma ṣe iṣẹ-ìsin fun u, ati lati ma sure li orukọ OLUWA; nipa ọ̀rọ wọn li a o ti ma wadi ọ̀ran iyàn ati ọ̀ran lilù: 6 Ati gbogbo awọn àgba ilu nì, ti o sunmọ ẹniti a pa na, ki nwọn ki o wẹ̀ ọwọ́ wọn sori ẹgbọrọ abo-malu na, ti a ṣẹ́ li ọrùn li afonifoji nì: 7 Ki nwọn ki o si dahùn wipe, Ọwọ́ wa kò tà ẹ̀jẹ yi silẹ, bẹ̃li oju wa kò ri i. 8 OLUWA, darijì Israeli awọn enia rẹ, ti iwọ ti ràpada, ki o má si ṣe kà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ si ọrùn Israeli awọn enia rẹ. A o si dari ẹ̀jẹ na jì wọn. 9 Bẹ̃ni iwọ o si mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lãrin nyin, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA.

Àwọn Obinrin Tí Ogun Bá Kó

10 Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ si fi wọn lé ọ lọwọ, ti iwọ si dì wọn ni igbekun; 11 Ti iwọ ba si ri ninu awọn igbẹsin na arẹwà obinrin, ti iwọ si ní ifẹ́ si i, pe ki iwọ ki o ní i li aya rẹ; 12 Nigbana ni ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ; ki on ki o si fá ori rẹ̀, ki o si rẹ́ ẽkanna rẹ̀; 13 Ki o si bọ́ aṣọ igbẹsin rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ki o si joko ninu ile rẹ, ki o sọkun baba rẹ̀, ati iya rẹ̀ li oṣù kan tọ̀tọ: lẹhin ìgba na ki iwọ ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ma ṣe ọkọ rẹ̀, on a si ma ṣe aya rẹ. 14 Bi o ba si ṣe, ti on kò ba wù ọ, njẹ ki iwọ ki o jẹ ki o ma lọ si ibi ti o fẹ́; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ tà a rára li owo, iwọ kò gbọdọ lò o bi ẹrú, nitoriti iwọ ti tẹ́ ẹ logo.

Ẹ̀tọ́ Àkọ́bí ninu Ogún Baba Rẹ̀

15 Bi ọkunrin kan ba si lí aya meji, ti o fẹ́ ọkan ti o si korira ekeji, ti nwọn si bi ọmọ fun u, ati eyiti o fẹ́ ati eyiti o korira; bi akọ́bi ọmọ na ba ṣe ti ẹniti o korira; 16 Yio si ṣe, li ọjọ́ ti o ba fi awọn ọmọ rẹ̀ jogún ohun ti o ní, ki o máṣe fi ọmọ obinrin ti o fẹ́ ṣe akọ́bi ni ipò ọmọ obinrin ti o korira, ti iṣe akọ́bi: 17 Ṣugbọn ki o jẹwọ ọmọ obinrin ti o korira li akọ́bi, ni fifi ipín meji fun u ninu ohun gbogbo ti o ní: nitoripe on ni ipilẹṣẹ agbara rẹ̀; itọsi akọ́bi ni tirẹ̀.

Bí Ọmọ Ẹni Bá Ya Aláìgbọràn

18 Bi ọkunrin kan ba lí ọmọkunrin kan ti o ṣe agídi ati alaigbọran, ti kò gbà ohùn baba rẹ̀ gbọ́, tabi ohùn iya rẹ̀, ati ti nwọn nà a, ti kò si fẹ́ gbà tiwọn gbọ́: 19 Nigbana ni ki baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ki o mú u, ki nwọn ki o si fà a jade tọ̀ awọn àgba ilu rẹ̀ wá ati si ibode ibujoko rẹ̀; 20 Ki nwọn ki o si wi fun awọn àgba ilu rẹ̀ pe, Ọmọ wa yi, alagídi ati alaigbọran ni, on kò fẹ́ gbọ́ ohùn wa; ọjẹun ati ọmuti ni. 21 Ki gbogbo awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-ibi kuro lãrin nyin; gbogbo Israeli a si gbọ́, nwọn a si bẹ̀ru.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

22 Bi ọkunrin kan ba dá ẹ̀ṣẹ kan ti o yẹ si ikú, ti a si pa a, ti iwọ si so o lori igi; 23 Ki okú rẹ̀ ki o máṣe gbé ori igi ni gbogbo oru, ṣugbọn bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o sin i li ọjọ́ na; nitoripe ẹni egún Ọlọrun li ẹniti a so; ki iwọ ki o má ba bà ilẹ rẹ jẹ́, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.

Deuteronomi 22

1 IWỌ kò gbọdọ ri akọ-malu tabi agutan arakunrin rẹ ti o nṣako, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn; bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o mú wọn pada tọ̀ arakunrin rẹ wá. 2 Bi arakunrin rẹ kò ba si sí nitosi rẹ, tabi bi iwọ kò ba mọ̀ ọ, njẹ ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ, ki o si wà lọdọ rẹ titi arakunrin rẹ yio fi wá a wá, ki iwọ ki o si fun u pada. 3 Bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o si ṣe si gbogbo ohun ninù arakunrin rẹ, ti o nù lọwọ rẹ̀, ti iwọ si ri: ki iwọ ki o máṣe mú oju rẹ kuro. 4 Iwọ kò gbọdọ ri kẹtẹkẹtẹ tabi akọ-malu arakunrin rẹ ki o ṣubu li ọ̀na, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn: iwọ o si ràn a lọwọ nitõtọ lati gbé e dide. 5 Obinrin kò gbọdọ mú ohun ti iṣe ti ọkunrin wọ̀, bẹ̃li ọkunrin kò gbọdọ mú aṣọ obinrin wọ̀: nitoripe gbogbo ẹniti o ba ṣe bẹ̃ irira ni nwọn si OLUWA Ọlọrun rẹ. 6 Bi iwọ ba bá itẹ́ ẹiyẹ kan pade lori igi kan, tabi ni ilẹ, ti o ní ọmọ tabi ẹyin, ti iya si bà lé ọmọ tabi lé ẹyin na, iwọ kò gbọdọ kó iya pẹlu ọmọ: 7 Bikoṣe ki iwọ ki o jọwọ iya lọwọ lọ, ki iwọ ki o si kó ọmọ fun ara rẹ; ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ. 8 Nigbati iwọ ba kọ ile titun kan, ki iwọ ki o ṣe igbáti si orule rẹ, ki iwọ o má ba mú ẹ̀jẹ wá sara ile rẹ, bi ẹnikan ba ti ibẹ̀ ṣubu. 9 Iwọ kò gbọdọ fi irú meji irugbìn gbìn ọgbà-àjara rẹ; ki eso irugbìn rẹ gbogbo ti iwọ ti gbìn, ati asunkún ọgbà-àjara rẹ, ki o má ba di ti Ọlọrun. 10 Iwọ kò gbọdọ fi akọ-malu ati kẹtẹkẹtẹ tulẹ pọ̀. 11 Iwọ kò gbọdọ wọ̀ aṣọ olori-ori, ti kubusu ati ti ọ̀gbọ pọ̀. 12 Ki iwọ ki o ṣe wajawaja si igun mẹrẹrin aṣọ rẹ, ti iwọ fi mbò ara rẹ.

Òfin nípa Ìbálòpọ̀ Ọkunrin ati Obinrin

13 Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo kan, ti o wọle tọ̀ ọ, ti o si korira rẹ̀, 14 Ti o si kà ọ̀ran si i lọrùn, ti o si bà orukọ rẹ̀ jẹ́, ti o si wipe, Mo gbé obinrin yi, nigbati mo si wọle tọ̀ ọ, emi kò bá a ni wundia: 15 Nigbana ni ki baba ọmọbinrin na, ati iya rẹ̀, ki o mú àmi wundia ọmọbinrin na tọ̀ awọn àgba ilu lọ li ẹnu-bode: 16 Ki baba ọmọbinrin na ki o si wi fun awọn àgba na pe, Emi fi ọmọbinrin mi fun ọkunrin yi li aya, o si korira rẹ̀; 17 Si kiyesi i, o si kà ọ̀ran si i lọrùn, wipe, Emi kò bá ọmọbinrin rẹ ni wundia; bẹ̃ni wọnyi ni àmi wundia ọmọbinrin mi. Ki nwọn ki o si nà aṣọ na niwaju awọn àgba ilu. 18 Ki awọn àgba ilu na ki o si mú ọkunrin na ki nwọn ki o si nà a; 19 Ki nwọn ki o si bù ọgọrun ṣekeli fadakà fun u, ki nwọn ki o si fi i fun baba ọmọbinrin na, nitoriti o bà orukọ wundia kan ni Israeli jẹ́: ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀; ki o máṣe kọ̀ ọ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo. 20 Ṣugbọn bi ohun na ba ṣe otitọ, ti a kò ba si ri àmi wundia ọmọbinrin na: 21 Nigbana ni ki nwọn ki o mú ọmọbinrin na wá si ẹnu-ọ̀na ile baba rẹ̀, ki awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: nitoriti o hù ìwa-buburu ni Israeli, ni ṣiṣe àgbere ninu ile baba rẹ̀: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin. 22 Bi a ba mú ọkunrin kan ti o bá obinrin kan dàpọ, ti a gbé ni iyawo fun ọkọ, njẹ ki awọn mejeji ki o kú, ati ọkunrin ti o bá obinrin na dàpo, ati obinrin na: bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ìwa-buburu kuro ni Israeli. 23 Bi ọmọbinrin wundia kan ba wà ni afẹsọna fun ọkọ, ti ọkunrin kan si ri i ni ilu, ti o si bá a dàpọ; 24 Njẹ ki ẹnyin ki o mú awọn mejeji wá si ẹnu-bode ilu na, ki ẹnyin ki o si ṣo wọn li okuta pa; eyi ọmọbinrin nitoriti kò kigbe, nigbati o wà ni ilu; ati eyi ọkunrin nitoriti o tẹ́ aya ẹnikeji rẹ̀ logo: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin. 25 Ṣugbọn bi ọkunrin na ba ri ọmọbinrin ti afẹsọna na ni igbẹ́, ti ọkunrin na si fi agbara mú u, ti o si bà a dàpọ; njẹ kìki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ni ki o kú: 26 Ṣugbọn si ọmọbinrin na ni ki iwọ ki o máṣe ohun kan; ẹ̀ṣẹ ti o yẹ si ikú kò sí lara ọmọbinrin na: nitori bi igbati ọkunrin kan dide si ẹnikeji rẹ̀, ti o si pa a, bẹ̃li ọ̀ran yi ri: 27 Nitoripe o bá a ninu igbẹ́; ọmọbinrin na ti afẹsọna kigbe, kò si sí ẹniti yio gbà a silẹ. 28 Bi ọkunrin kan ba si ri ọmọbinrin kan ti iṣe wundia, ti a kò ti fẹsọna fun ọkọ, ti o si mú u, ti o si bá a dàpọ, ti a si mú wọn; 29 Njẹ ki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ki o fi ãdọta ṣekeli fadakà fun baba ọmọbinrin na, ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀, nitoriti o ti tẹ́ ẹ logo, ki on ki o máṣe kọ̀ ọ silẹ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo. 30 Ki ọkunrin kan ki o máṣe fẹ́ aya baba rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe tú aṣọ baba rẹ̀.

Deuteronomi 23

Yíyọ Orúkọ Eniyan kúrò ninu Orúkọ Àwọn Eniyan OLUWA

1 ẸNITI a fọ ni kóro, tabi ti a ke ẹ̀ya ìkọkọ rẹ̀ kuro, ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA. 2 Ọmọ-àle ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA; ani dé iran kẹwa enia rẹ̀ kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA. 3 Ọmọ Ammoni tabi ọmọ Moabu kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA; ani dé iran kẹwa enia wọn kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA lailai: 4 Nitoriti nwọn kò fi omi pẹlu onjẹ pade nyin li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti Egipti jade wá; ati nitoriti nwọn bẹ̀wẹ Balaamu ọmọ Beori ara Petori ti Mesopotamia si ọ, lati fi ọ bú. 5 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; OLUWA Ọlọrun rẹ si yi egún na pada si ibukún fun ọ, nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ fẹ́ ọ. 6 Iwọ kò gbọdọ wá alafia wọn tabi ire wọn li ọjọ́ rẹ gbogbo lailai. 7 Iwọ kò gbọdọ korira ara Edomu kan; nitoripe arakunrin rẹ ni iṣe: iwọ kò gbọdọ korira ara Egipti kan; nitoripe iwọ ti ṣe alejò ni ilẹ rẹ̀. 8 Awọn ọmọ ti a bi fun wọn yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA ni iran kẹta wọn.

Jíjẹ́ Kí Àgọ́ Àwọn Ọmọ-ogun Wà ní Mímọ́

9 Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o pa ara rẹ mọ́ kuro ninu ohun buburu gbogbo. 10 Bi ọkunrin kan ba wà ninu nyin, ti o ṣèsi di aimọ́ li oru, njẹ ki o jade lọ sẹhin ibudó, ki o máṣe wá ãrin ibudó: 11 Yio si ṣe, nigbati alẹ ba lẹ, ki on ki o fi omi wẹ̀ ara rẹ̀: nigbati õrùn ba si wọ̀, ki o ma bọ̀wá sãrin ibudó. 12 Ki iwọ ki o ní ibi kan pẹlu lẹhin ibudó, nibiti iwọ o ma jade lọ si: 13 Ki iwọ ki o si ní ìwalẹ kan pẹlu ohun-ìja rẹ; yio si ṣe, nigbati iwọ o ba gbọnsẹ lẹhin ibudó, ki iwọ ki o fi wàlẹ, ki iwọ ki o si yipada, ki o bò ohun ti o ti ara rẹ jade: 14 Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ nrìn lãrin ibudó rẹ, lati gbà ọ, ati lati fi awọn ọtá rẹ fun ọ; nitorina ki ibudó rẹ ki o jẹ́ mimọ́: ki on ki o máṣe ri ohun aimọ́ kan lọdọ rẹ, on a si pada lẹhin rẹ.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

15 Iwọ kò gbọdọ fà ẹrú ti o sá lati ọdọ oluwa rẹ̀ tọ̀ ọ wá lé oluwa rẹ̀ lọwọ: 16 Ki on ki o bá ọ joko, ani lãrin nyin, ni ibi ti on o yàn ninu ọkan ni ibode rẹ, ti o wù u jù: ki iwọ ki o máṣe ni i lara. 17 Ki àgbere ki o máṣe sí ninu awọn ọmọbinrin Israeli, tabi oníwà-sodomu ninu awọn ọmọkunrin Israeli. 18 Iwọ kò gbọdọ mú owo ọ̀ya àgbere, tabi owo ajá, wá sinu ile OLUWA Ọlọrun rẹ fun ẹjẹ́kẹjẹ: nitoripe irira ni, ani awọn mejeji si OLUWA Ọlọrun rẹ. 19 Iwọ kò gbọdọ wín arakunrin rẹ fun elé; elé owo, elé onjẹ, elé ohun kan ti a wínni li elé: 20 Alejò ni ki iwọ ki o ma wín fun elé; ṣugbọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o máṣe win fun elé: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma bukún ọ ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé, ni ilẹ na nibiti iwọ nlọ lati gbà a. 21 Nigbati iwọ ba jẹ́jẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o máṣe fàsẹhin lati san a: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio bère rẹ̀ nitõtọ lọwọ rẹ; yio si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn. 22 Ṣugbọn bi iwọ ba fàsẹhin lati jẹ́jẹ, ki yio di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn. 23 Ohun ti o ba ti ète rẹ jade, ni ki iwọ ki o pamọ́, ki o si ṣe; gẹgẹ bi iwọ ti jẹ́jẹ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ani ọrẹ ifẹ́-atinuwa, ti iwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ileri. 24 Nigbati iwọ ba wọ̀ inu ọgbà-àjara ẹnikeji rẹ lọ, iwọ le jẹ eso-àjara tẹrùn; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ mú ọkan sinu ohunèlo rẹ. 25 Nigbati iwọ ba dé inu oko-ọkà ẹnikeji rẹ, njẹ ki iwọ ki o ma fi ọwọ́ rẹ yà ṣiri rẹ̀; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ yọ doje si ọkà ẹnikeji rẹ.

Deuteronomi 24

Kíkọ Iyawo sílẹ̀ ati Títún Igbeyawo ṣe

1 BI ọkunrin kan ba fẹ́ obinrin kan, ti o si gbé e niyawo, yio si ṣe, bi obinrin na kò ba ri ojurere li oju ọkunrin na, nitoriti o ri ohun alebù kan lara rẹ̀: njẹ ki o kọ iwé ikọsilẹ fun obinrin na, ki o fi i lé e lọwọ, ki o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀. 2 Nigbati on ba si jade kuro ninu ile rẹ̀, on le lọ, ki o ma ṣe aya ọkunrin miran. 3 Bi ọkọ rẹ̀ ikẹhin ba si korira rẹ̀, ti o si kọ iwé ikọsilẹ fun u, ti o si fi i lé e lọwọ, ti o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀; tabi bi ọkọ ikẹhin ti o fẹ́ ẹ li aya ba kú; 4 Ọkọ rẹ̀ iṣaju, ti o rán a jade kuro, ki o máṣe tun ní i li aya lẹhin ìgba ti o ti di ẹni-ibàjẹ́ tán; nitoripe irira ni niwaju OLUWA: iwọ kò si gbọdọ mu ilẹ na ṣẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

5 Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo titun, ki o máṣe lọ si ogun, bẹ̃ni ki a máṣe fun u ni iṣẹkiṣẹ kan ṣe: ki o ri àye ni ile li ọdún kan, ki o le ma mu inu aya rẹ̀ ti o ní dùn. 6 Ẹnikan kò gbọdọ gbà iya-ọ̀lọ tabi ọmọ-ọlọ ni ògo: nitoripe ẹmi enia li o gbà li ògo nì. 7 Bi a ba mú ọkunrin kan ti njí ẹnikan ninu awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Israeli, ti o nsìn i bi ẹrú, tabi ti o tà a; njẹ olè na o kú; bẹ̃ni iwọ o mú ìwabuburu kuro lãrin nyin. 8 Ma kiyesi àrun-ẹ̀tẹ, ki iwọ ki o ṣọra gidigidi ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn alufa awọn ọmọ Lefi yio ma kọ́ nyin: bi emi ti pa a laṣẹ fun wọn, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ma kiyesi lati ṣe. 9 Ranti ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Miriamu li ọ̀na, nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá. 10 Nigbati iwọ ba wín arakunrin rẹ li ohun kan, ki iwọ ki o máṣe lọ si ile rẹ̀ lati mú ògo rẹ̀ wá. 11 Ki iwọ ki o duro lode gbangba, ki ọkunrin na ti iwọ wín ni nkan, ki o mú ògo rẹ̀ jade tọ̀ ọ wá. 12 Bi ọkunrin na ba si ṣe talakà, ki iwọ ki o máṣe sùn ti iwọ ti ògo rẹ̀. 13 Bi o ti wù ki o ri iwọ kò gbọdọ má mú ògo rẹ̀ pada fun u, nigbati õrùn ba nwọ̀, ki on ki o le ri aṣọ bora sùn, ki o si sure fun ọ: ododo ni yio si jasi fun ọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ. 14 Iwọ kò gbọdọ ni alagbaṣe kan lara ti iṣe talakà ati alaini, ibaṣe ninu awọn arakunrin rẹ, tabi ninu awọn alejò rẹ ti mbẹ ni ilẹ rẹ ninu ibode rẹ: 15 Ni ọjọ́ rẹ̀, ni ki iwọ ki o sanwo ọ̀ya rẹ̀ fun u, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki õrùn ki o wọ̀ bá a; nitoripe talakà li on, o si gbẹkẹ rẹ̀ lé e: ki o má ba kepè OLUWA si ọ, a si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn. 16 A kò gbọdọ pa awọn baba nitori ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ, bẹ̃ni a kò gbọdọ pa awọn ọmọ nitori awọn baba: olukuluku enia li a o pa nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 17 Iwọ kò gbọdọ yi idajọ alejò po, tabi ti alainibaba; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe gbà aṣọ opó ni ogò: 18 Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni Egipti, OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ kuro nibẹ̀: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi. 19 Nigbati iwọ ba kore rẹ li oko rẹ, ti iwọ ba si gbagbé ití-ọkà kan silẹ ninu oko, ki iwọ ki o máṣe pada lọ mú u: ki o le ma jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma busi i fun ọ, ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo. 20 Nigbati iwọ ba ngún igi olifi rẹ, ki iwọ ki o máṣe tun pada wò ẹka rẹ̀: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó. 21 Nigbati iwọ ba nká eso ọgbà-àjara rẹ, ki iwọ ki o máṣe peṣẹ́ lẹhin rẹ: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó. 22 Ki iwọ ki o si ma ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi.

Deuteronomi 25

1 BI gbolohùn-asọ̀ kan ba wà lãrin enia, ti nwọn si wá si ibi idajọ, ti nwọn si dajọ wọn; nigbana ni ki nwọn ki o fi are fun alare, ki nwọn ki o si fi ẹbi fun ẹlẹbi; 2 Yio si ṣe, bi ẹlẹbi na ba yẹ lati nà, ki onidajọ na ki o da a dọbalẹ, ki o si mu ki a nà a ni iye kan li oju on, gẹgẹ bi ìwabuburu rẹ̀. 3 Ogoji paṣan ni ki a nà a, kò gbọdọ lé: nitoripe bi o ba lé, ti o ba si fi paṣan pupọ̀ nà a jù wọnyi lọ, njẹ arakunrin rẹ yio di gigàn li oju rẹ. 4 Máṣe di akọ-malu li ẹnu nigbati o ba npakà.

Ojúṣe Ẹni sí Arakunrin Ẹni Tí Ó Ṣaláìsí

5 Bi awọn arakunrin ba ngbé pọ̀, ti ọkan ninu wọn ba si kú, ti kò si lí ọmọkunrin, ki aya okú ki o máṣe ní alejò ara ode li ọkọ: arakunrin ọkọ rẹ ni ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ní i li aya, ki o si ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ fun u. 6 Yio si ṣe, akọ́bi ọmọ ti o bi ki o rọpò li orukọ arakunrin rẹ̀ ti o kú, ki orukọ rẹ̀ ki o má ba parẹ́ ni Israeli. 7 Bi ọkunrin na kò ba si fẹ́ lati mú aya arakunrin rẹ̀, njẹ ki aya arakunrin rẹ̀ ki o gòke lọ si ẹnubode tọ̀ awọn àgba lọ, ki o si wipe, Arakunrin ọkọ mi kọ̀ lati gbé orukọ arakunrin rẹ̀ ró ni Israeli, on kò fẹ́ ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ mi. 8 Nigbana ni awọn àgba ilu rẹ̀ yio pè e, nwọn a si sọ fun u: bi o ba si duro si i, ti o si wipe, Emi kò fẹ́ lati mú u; 9 Nigbana ni aya arakunrin rẹ̀ yio tọ̀ ọ wá niwaju awọn àgba na, on a si tú bàta rẹ̀ kuro li ẹsẹ̀ rẹ̀, a si tutọ si i li oju; a si dahùn, a si wipe, Bayi ni ki a ma ṣe si ọkunrin na ti kò fẹ́ ró ile arakunrin rẹ̀. 10 A o si ma pè orukọ rẹ̀ ni Israeli pe, Ile ẹniti a tú bàta rẹ̀.

Àwọn Òfin Mìíràn

11 Bi awọn ọkunrin ba mbá ara wọn jà, ti aya ọkan ba si sunmọtosi lati gbà ọkọ rẹ̀ lọwọ ẹniti o kọlù u, ti on si nawọ́ rẹ̀, ti o si di i mú li abẹ: 12 Nigbana ni ki iwọ ki o ke ọwọ́ rẹ̀ kuro, ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u. 13 Iwọ kò gbọdọ ní onirũru ìwọn ninu àpo rẹ, nla ati kekere. 14 Iwọ kò gbọdọ ní onirũru òṣuwọn ninu ile rẹ, nla ati kekere. 15 Iwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní; òṣuwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 16 Nitoripe gbogbo ẹniti nṣe wọnyi, ati gbogbo ẹniti nṣe aiṣododo, irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ.

Òfin láti Pa Àwọn Ará Amaleki

17 Ranti ohun ti Amaleki ṣe si ọ li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti ilẹ Egipti jade wá; 18 Bi o ti pade rẹ li ọ̀na, ti o si kọlù awọn ti o kẹhin rẹ, ani gbogbo awọn ti o ṣe alailera lẹhin rẹ, nigbati ãrẹ mú ọ tán, ti agara si dá ọ; ti on kò si bẹ̀ru Ọlọrun. 19 Nitorina yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fun ọ ni isimi lọwọ gbogbo awọn ọtá rẹ yi ọ ká kiri, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati ní i, ki iwọ ki o si pa iranti Amaleki rẹ́ kuro labẹ ọrun; iwọ kò gbọdọ gbagbé.

Deuteronomi 26

Ọrẹ Ìkórè

1 YIO si ṣe, nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ti iwọ si gbà a, ti iwọ si joko ninu rẹ̀; 2 Ki iwọ ki o mú ninu akọ́so gbogbo eso ilẹ rẹ, ti iwọ o mú ti inu ile rẹ wá, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ki iwọ ki o si fi i sinu agbọ̀n, ki iwọ ki o si lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si. 3 Ki iwọ ki o si tọ̀ alufa na lọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni, ki o si wi fun u pe, Emi jẹwọ li oni fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pe emi wá si ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba wa lati fi fun wa. 4 Ki awọn alufa ki o si gbà agbọ̀n na li ọwọ́ rẹ, ki o si gbé e kalẹ niwaju pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ. 5 Iwọ o si dahùn iwọ o si wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Ara Siria kan, ti o nṣegbé ni baba mi, on si sọkalẹ lọ si Egipti, o si ṣe atipo nibẹ̀, ti on ti enia diẹ; nibẹ̀ li o si di orilẹ-ède nla, alagbara, ati pupọ̀: 6 Awọn ara Egipti si hùwabuburu si wa, nwọn si pọn wa loju, nwọn si dì ẹrù wuwo rù wa: 7 Awa si kepè OLUWA, Ọlọrun awọn baba wa, OLUWA si gbọ́ ohùn wa, o si wò ipọnju wa, ati lãlã wa, ati inira wa: 8 OLUWA si mú wa lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara, ati apa ninà, ati pẹlu ẹrù nla, ati pẹlu iṣẹ-àmi, ati pẹlu iṣẹ-iyanu: 9 O si mú wa dé ihin yi, o si fi ilẹ yi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 10 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, emi mú akọ́so ilẹ na wa, ti iwọ, OLUWA, fi fun mi. Ki iwọ ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma foribalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ: 11 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ohun rere gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ati fun ara ile rẹ, iwọ, ati ọmọ Lefi, ati alejò ti mbẹ lãrin rẹ. 12 Nigbati iwọ ba da idamẹwa asunkun rẹ tán li ọdún kẹta, ti iṣe ọdún idamẹwa, ti iwọ si fi fun ọmọ Lefi, alejò, alainibaba, ati opó, ki nwọn ki o ma jẹ li ẹnubode rẹ, ki nwọn si yó; 13 Nigbana ni ki iwọ ki o wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Emi ti mú ohun mimọ́ kuro ninu ile mi, mo si ti fi wọn fun ọmọ Lefi, ati fun alejò, ati fun alainibaba, ati fun opó, gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ rẹ ti iwọ ti pa fun mi: emi kò re aṣẹ rẹ kọja, bẹ̃li emi kò gbagbé wọn: 14 Emi kò jẹ ninu rẹ̀ ninu ọ̀fọ mi, bẹ̃li emi kò mú kuro ninu rẹ̀ fun ohun aimọ́ kan, bẹ̃li emi kò mú ninu rẹ̀ fun okú: ṣugbọn emi ti gbà ohùn OLUWA Ọlọrun mi gbọ́, emi si ti ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ palaṣẹ fun mi. 15 Wò ilẹ lati ibujoko mimọ́ rẹ wá, lati ọrun wá, ki o si busi i fun Israeli enia rẹ, ati fun ilẹ na ti iwọ fi fun wa, bi iwọ ti bura fun awọn baba wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.

Àwọn Eniyan OLUWA

16 Li oni OLUWA Ọlọrun rẹ paṣẹ fun ọ lati ma ṣe ìlana ati idajọ wọnyi: nitorina ki iwọ ki o ma pa wọn mọ́, ki iwọ ki o si ma fi gbogbo àiya rẹ ati gbogbo ọkàn rẹ ṣe wọn. 17 Iwọ jẹwọ OLUWA li oni pe on ni Ọlọrun rẹ, ati pe iwọ o ma rìn li ọ̀na rẹ̀, iwọ o si ma pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, iwọ o si ma fetisi ohùn rẹ̀: 18 OLUWA si jẹwọ rẹ li oni pe iwọ o ma jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ati pe iwọ o ma pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́; 19 On o si mu ọ ga jù orilẹ-ède gbogbo lọ ti o dá, ni ìyin, li orukọ, ati ọlá; ki iwọ ki o le ma jẹ́ enia mimọ́ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ.

Deuteronomi 27

Ìlànà nípa Kíkọ Òfin Ọlọrun Sára Òkúta

1 MOSE pẹlu awọn àgba Israeli si paṣẹ fun awọn enia na wipe, Ẹ ma pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni. 2 Yio si ṣe li ọjọ́ ti ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o si kó okuta nla jọ, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn. 3 Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara wọn, nigbati iwọ ba rekọja; ki iwọ ki o le wọ̀ inu ilẹ na lọ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ, ti ṣe ileri fun ọ. 4 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani tán, ẹnyin o kó okuta wọnyi jọ, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, li òke Ebali, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn. 5 Nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pẹpẹ okuta kan: iwọ kò gbọdọ fi ohun-èlo irin kàn wọn. 6 Okuta aigbẹ́ ni ki iwọ ki o fi mọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA Ọlọrun rẹ: 7 Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ alafia, ki iwọ ki o si jẹun nibẹ̀; ki iwọ ki o ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ. 8 Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara okuta wọnyi, ki o hàn gbangba. 9 Mose ati awọn alufa awọn ọmọ Lefi si sọ fun gbogbo Israeli pe, Israeli, dakẹ, ki o si gbọ́; li oni ni iwọ di enia OLUWA Ọlọrun rẹ. 10 Nitorina ki iwọ ki o gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, ki o si ma ṣe aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni.

Àwọn Ègún fún Àìgbọràn

11 Mose si paṣẹ fun awọn enia na li ọjọ́ na, wipe, 12 Awọn wọnyi ni ki o duro lori òke Gerisimu, lati ma sure fun awọn enia na, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani; Simeoni, ati Lefi, ati Juda, ati Issakari, ati Josefu, ati Benjamini: 13 Awọn wọnyi ni yio si duro lori òke Ebali lati gegún; Reubeni, Gadi, ati Aṣeri, ati Sebuluni, Dani, ati Naftali. 14 Awọn ọmọ Lefi yio si dahùn, nwọn o si wi fun gbogbo awọn ọkunrin Israeli li ohùn rara pe, 15 Egún ni fun ọkunrin na ti o yá ere gbigbẹ́ tabi didà, irira si OLUWA, iṣẹ ọwọ́ oniṣọnà, ti o si gbé e kalẹ ni ìkọ̀kọ̀. Gbogbo enia yio si dahùn wipe, Amin. 16 Egún ni fun ẹniti kò fi baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀ pè. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 17 Egún ni fun ẹniti o ṣí àla ẹnikeji rẹ̀ kuro. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 18 Egún ni fun ẹniti o ṣì afọju li ọ̀na. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 19 Egún ni fun ẹniti o nyi idajọ alejò po, ati ti alainibaba, ati ti opó. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 20 Egún ni fun ẹniti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ̀: nitoriti o tú aṣọ baba rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 21 Egún ni fun ẹniti o bá ẹranko dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 22 Egún ni fun ẹniti o bá arabinrin rẹ̀ dàpọ, ti iṣe ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 23 Egún ni fun ẹniti o bá iya-aya rẹ̀ dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 24 Egún ni fun ẹniti o lù ẹnikeji rẹ̀ ni ìkọkọ. Gbogbo enia ni yio si wipe, Amin. 25 Egún ni fun ẹniti o gbà ọrẹ lati pa alaiṣẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 26 Egún ni fun ẹniti kò duro si gbogbo ọ̀rọ ofin yi lati ṣe wọn. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.

Deuteronomi 28

Ibukun fún Ìgbọràn

1 YIO si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ̀ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ: 2 Gbogbo ibukún wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ. 3 Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko. 4 Ibukún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ati irú ohunọ̀sin rẹ, ati ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ. 5 Ibukún ni fun agbọ̀n rẹ ati fun ọpọ́n-ipò-àkara rẹ. 6 Ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba jade. 7 OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọ̀na kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọ̀na meje. 8 OLUWA yio paṣẹ ibukún sori rẹ ninu aká rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé; on o si busi i fun ọ ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 9 OLUWA yio fi idi rẹ kalẹ li enia mimọ́ fun ara rẹ̀, bi o ti bura fun ọ, bi iwọ ba pa aṣẹ ỌLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, ti iwọ si rìn li ọ̀na rẹ̀. 10 Gbogbo enia aiye yio si ri pe orukọ OLUWA li a fi npè ọ; nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ. 11 OLUWA yio si sọ ọ di pupọ̀ fun rere, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu irú ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, ni ilẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ lati fun ọ. 12 OLUWA yio ṣí iṣura rere rẹ̀ silẹ fun ọ, ọrun lati rọ̀jo si ilẹ rẹ li akokò rẹ̀, ati lati busi iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: iwọ o si ma wín orilẹ-ède pupọ̀, iwọ ki yio si tọrọ. 13 OLUWA yio si fi ọ ṣe ori, ki yio si ṣe ìru; iwọ o si ma leke ṣá, iwọ ki yio si jẹ́ ẹni ẹhin; bi o ba fetisi aṣẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti mo pa fun ọ li oni, lati ma kiyesi on ati ma ṣe wọn; 14 Iwọ kò si gbọdọ yà kuro ninu gbogbo ọ̀rọ ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, si ọtún, tabi si òsi, lati tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn.

Ìjìyà fún Àìgbọràn

15 Yio si ṣe, bi iwọ kò ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ ti mo filelẹ fun ọ li oni; njẹ gbogbo egún wọnyi yio ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ. 16 Egún ni fun ọ ni ilu, egún ni fun ọ li oko. 17 Egún ni fun agbọ̀n rẹ ati ọpọ́n-ipò-àkara rẹ. 18 Egún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ. 19 Egún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, egún si ni fun ọ nigbati iwọ ba jade. 20 OLUWA yio si rán egún, idamu, ati ibawi sori rẹ, ninu gbogbo ohun ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé ni ṣiṣe, titi a o fi run ọ, ati titi iwọ o fi ṣegbé kánkán; nitori buburu iṣe rẹ, nipa eyiti iwọ fi kọ̀ mi silẹ. 21 OLUWA yio si mu ajakalẹ-àrun lẹ̀ mọ́ ọ, titi on o fi run ọ kuro lori ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a. 22 OLUWA yio si fi àrun-igbẹ kọlù ọ, ati ibà, ati igbona, ati ijoni nla, ati idà, ati ìrẹdanu, ati imuwodu; nwọn o si lepa rẹ titi iwọ o fi run. 23 Ọrun rẹ ti mbẹ lori rẹ yio jẹ́ idẹ, ilẹ ti mbẹ nisalẹ rẹ yio si jẹ́ irin. 24 OLUWA yio sọ òjo ilẹ rẹ di ẹ̀tù ati ekuru: lati ọrun ni yio ti ma sọkalẹ si ọ, titi iwọ o fi run. 25 OLUWA yio si mu ọ di ẹni ikọlù niwaju awọn ọtá rẹ: iwọ o jade tọ̀ wọn lọ li ọ̀na kan, iwọ o si sá niwaju wọn li ọ̀na meje: a o si ṣí ọ kiri gbogbo ijọba aiye. 26 Okú rẹ yio si jẹ́ onjẹ fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọ̀run, ati fun ẹranko aiye, kò si sí ẹniti yio lé wọn kuro. 27 OLUWA yio si fi õwo Egipti lù ọ, ati iyọdi, ati ekúru, ati ẹyi-ara, eyiti a ki yio le wòsan. 28 OLUWA yio fi isinwin kọlù ọ, ati ifọju, ati ipàiya: 29 Iwọ o si ma fi ọwọ́ talẹ li ọsán gangan, bi afọju ti ifi ọwọ́ talẹ ninu òkunkun, iwọ ki yio si ri rere ninu ọ̀na rẹ: ẹni inilara ṣá ati ẹni kikó li ọjọ́ gbogbo ni iwọ o jẹ́, ki o si sí ẹniti o gbà ọ. 30 Iwọ o fẹ́ iyawo, ọkunrin miran ni yio si bá a dàpọ: iwọ o kọ ile, iwọ ki yio si gbé inu rẹ̀: iwọ o gbìn ọgbà-àjara, iwọ ki yio si ká eso rẹ̀. 31 A o si pa akọmalu rẹ li oju rẹ, iwọ ki yio si jẹ ninu rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ rẹ li a o si fi agbara mú lọ kuro li oju rẹ, a ki yio si mú u pada fun ọ wá: a o fi agutan rẹ fun awọn ọtá rẹ, iwọ ki yio si lí ẹniti yio gbà ọ. 32 Awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin, li a o fi fun enia miran, oju rẹ yio ma wò, yio si su ọ lati ma wò ọ̀na wọn li ọjọ́ gbogbo: ki yio si sí agbara kan li ọwọ́ rẹ. 33 Eso ilẹ rẹ, ati gbogbo iṣẹ-lãlã rẹ, ni orilẹ-ède miran ti iwọ kò mọ̀ yio jẹ; iwọ o si jẹ́ kìki ẹni inilara ati ẹni itẹmọlẹ nigbagbogbo: 34 Bẹ̃ni iwọ o si di aṣiwere nitori iran oju rẹ, ti iwọ o ri. 35 OLUWA yio si fi õwo buburu lù ọ li ẽkún, ati li ẹsẹ̀, ti a ki o le wòsan, lati atẹlẹsẹ̀ rẹ dé atari rẹ. 36 OLUWA o mú iwọ, ati ọba rẹ ti iwọ o fi jẹ́ lori rẹ, lọ si orilẹ-ède ti iwọ, ati awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; iwọ o si ma bọ oriṣa nibẹ̀, igi ati okuta. 37 Iwọ o si di ẹni iyanu, ati ẹni owe, ati ẹni ifisọrọsọ, ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio gbé darí rẹ si. 38 Iwọ o mú irugbìn pupọ̀ lọ sinu oko, diẹ ni iwọ o si ri kójọ; nitoripe eṣú ni yio jẹ ẹ run. 39 Iwọ o gbìn ọgbà-àjara, iwọ o si ṣe itọju rẹ̀, ṣugbọn iwọ ki yio mu ninu ọti-waini rẹ̀, bẹ̃ni iwọ ki yio ká ninu eso-àjara rẹ̀, nitoripe kòkoro ni yio fi wọn jẹ. 40 Iwọ o ní igi olifi ni gbogbo àgbegbe rẹ, ṣugbọn iwọ ki yio fi oróro para; nitoripe igi olifi rẹ yio rẹ̀danu. 41 Iwọ o bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn nwọn ki yio jẹ́ tirẹ; nitoripe nwọn o lọ si oko-ẹrú. 42 Gbogbo igi rẹ ati eso ilẹ rẹ yio jẹ́ ti eṣú. 43 Alejò ti mbẹ lãrin rẹ, yio ma ga jù ọ lọ siwaju ati siwaju, iwọ o si ma di ẹni irẹsilẹ, siwaju ati siwaju. 44 On ni yio ma wín ọ, iwọ ki yio si wín i: on ni yio ma ṣe ori, iwọ o si ma ṣe ìru. 45 Gbogbo egún wọnyi yio si wá sori rẹ, yio si lepa rẹ, yio si bá ọ, titi iwọ o fi run; nitoriti iwọ kò fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́ ti o palaṣe fun ọ. 46 Nwọn o si wà lori rẹ fun àmi ati fun iyanu, ati lori irú-ọmọ rẹ lailai: 47 Nitoriti iwọ kò fi àyọ sìn OLUWA Ọlọrun rẹ, ati inudidun, nitori ọ̀pọ ohun gbogbo: 48 Nitorina ni iwọ o ṣe ma sìn awọn ọtá rẹ ti OLUWA yio rán si ọ, ninu ebi, ati ninu ongbẹ, ati ninu ìhoho, ati ninu ainí ohun gbogbo: on o si fi àjaga irin bọ̀ ọ li ọrùn, titi yio fi run ọ. 49 OLUWA yio gbé orilẹ-ède kan dide si ọ lati ọ̀na jijìn, lati opin ilẹ wa bi idì ti ifò; orilẹ-ède ti iwọ ki yio gbọ́ ède rẹ̀; 50 Orilẹ-ède ọdaju, ti ki yio ṣe ojuṣaju arugbo, ti ki yio si ṣe ojurere fun ewe: 51 On o si ma jẹ irú ohunọ̀sin rẹ, ati eso ilẹ rẹ, titi iwọ o fi run: ti ki yio kù ọkà, ọti-waini, tabi oróro, tabi ibisi malu rẹ, tabi ọmọ agutan silẹ fun ọ, titi on o fi run ọ. 52 On o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, titi odi rẹ ti o ga ti o si le yio fi wó lulẹ, eyiti iwọ gbẹkẹle, ni ilẹ rẹ gbogbo: on o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, ni gbogbo ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi fun ọ. 53 Iwọ o si jẹ ọmọ inu rẹ, ẹran ara awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ti awọn ọmọ rẹ obinrin ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ninu idótì na ati ninu ihámọ na ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́. 54 Ọkunrin ti àwọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, oju rẹ̀ yio korò si arakunrin rẹ̀, ati si aya õkanàiya rẹ̀, ati si iyokù ọmọ rẹ̀ ti on jẹ kù: 55 Tobẹ̃ ti on ki yio bùn ẹnikan ninu wọn, ninu ẹran awọn ọmọ ara rẹ̀ ti o jẹ, nitoriti kò sí ohun kan ti yio kù silẹ fun u ninu idótì na ati ninu ihámọ, ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ gbogbo. 56 Obinrin ti awọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, ti kò jẹ daṣa ati fi atẹlẹsẹ̀ rẹ̀ kan ilẹ nitori ikẹra ati ìwa-ẹlẹgẹ́, oju rẹ̀ yio korò si ọkọ õkanaiya rẹ̀, ati si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin; 57 Ati si ọmọ-ọwọ rẹ̀ ti o ti agbedemeji ẹsẹ̀ rẹ̀ jade, ati si awọn ọmọ rẹ̀ ti yio bi; nitoripe on o jẹ wọn ni ìkọkọ nitori ainí ohunkohun: ninu ìdótì ati ihámọ na, ti ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ. 58 Bi iwọ kò ba fẹ́ kiyesi ati ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi ti a kọ sinu iwé yi, lati ma bẹrù orukọ yi ti o lí ogo ti o si lí ẹ̀ru OLUWA ỌLỌRUN RẸ; 59 Njẹ OLUWA yio sọ iyọnu rẹ di iyanu, ati iyọnu irú-ọmọ rẹ, ani iyọnu nla, ati eyiti yio pẹ, ati àrun buburu, ati eyiti yio pẹ. 60 On o si mú gbogbo àrun Egipti pada wá bá ọ, ti iwọ bẹ̀ru; nwọn o si lẹ̀ mọ́ ọ. 61 Gbogbo àrun pẹlu, ati gbogbo iyọnu, ti a kò kọ sinu iwé ofin yi, awọn ni OLUWA yio múwa bá ọ, titi iwọ o fi run. 62 Diẹ li ẹnyin o si kù ni iye, ẹnyin ti ẹ ti dabi irawọ oju-ọrun ni ọ̀pọlọpọ: nitoriti iwọ kò gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́. 63 Yio si ṣe, bi OLUWA ti yọ̀ sori nyin lati ṣe nyin ni ire, ati lati sọ nyin di pupọ̀; bẹ̃ni OLUWA yio si yọ̀ si nyin lori lati run nyin, ati lati pa nyin run; a o si fà nyin tu kuro lori ilẹ na ni ibi ti iwọ nlọ lati gbà a. 64 OLUWA yio si tu ọ ká sinu enia gbogbo, lati opin ilẹ dé opin ilẹ; nibẹ̀ ni iwọ o si ma bọ oriṣa ti iwọ ati baba rẹ kò mọ̀ rí, ani igi ati okuta. 65 Ati lãrin orilẹ-ède wọnyi ni iwọ ki yio ri irọrun, bẹ̃li atẹlẹsẹ̀ rẹ ki yio ri isimi: ṣugbọn OLUWA yio fi iwarìri àiya, ati oju jijoro, ati ibinujẹ ọkàn fun ọ: 66 Ẹmi rẹ yio sọrọ̀ ni iyemeji li oju rẹ; iwọ o si ma bẹ̀ru li oru ati li ọsán, iwọ ki yio si ní idaniloju ẹmi rẹ. 67 Li owurọ̀ iwọ o wipe, Alẹ iba jẹ́ lẹ! ati li alẹ iwọ o wipe, Ilẹ iba jẹ́ mọ́! nitori ibẹ̀ru àiya rẹ ti iwọ o ma bẹ̀ru, ati nitori iran oju rẹ ti iwọ o ma ri. 68 OLUWA yio si fi ọkọ̀ tun mú ọ pada lọ si Egipti, li ọ̀na ti mo ti sọ fun ọ pe, Iwọ ki yio si tun ri i mọ́: nibẹ̀ li ẹnyin o si ma tà ara nyin fun awọn ọtá nyin li ẹrú ọkunrin ati ẹrú obinrin, ki yio si sí ẹniti yio rà nyin.

Deuteronomi 29

Àdéhùn OLUWA pẹlu Israẹli ní Ilẹ̀ Moabu

1 WỌNYI li ọ̀rọ majẹmu ti OLUWA palaṣẹ fun Mose lati bá awọn ọmọ Israeli dá ni ilẹ Moabu, lẹhin majẹmu ti o ti bá wọn dá ni Horebu. 2 Mose si pè gbogbo awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ri ohun gbogbo ti OLUWA ṣe li oju nyin ni ilẹ Egipti si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ati si ilẹ rẹ̀ gbogbo. 3 Idanwò nla ti oju rẹ ti ri, iṣẹ-àmi, ati iṣẹ-iyanu nla wọnni: 4 Ṣugbọn OLUWA kò fun nyin li àiya lati mọ̀, ati oju lati ri, ati etí lati gbọ́ titi di oni yi. 5 Emi si ti mu nyin rìn li ogoji ọdún li aginjù: aṣọ nyin kò gbó mọ́ nyin li ara, bàta nyin kò si gbó mọ́ nyin ni ẹsẹ̀. 6 Ẹnyin kò jẹ àkara, bẹ̃li ẹnyin kò mu ọti-waini, tabi ọti lile: ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 7 Nigbati ẹnyin ti dé ihinyi, Sihoni ọba Hesboni, ati Ogu ọba Baṣani, jade ogun si wa, awa si kọlù wọn: 8 Awa si gbà ilẹ wọn, a si fi i fun awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse ni iní. 9 Nitorina, ẹ pa ọ̀rọ majẹmu yi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn, ki ẹnyin ki o le ma ri ire ninu ohun gbogbo ti ẹnyin nṣe. 10 Gbogbo nyin li o duro li oni niwaju OLUWA Ọlọrun nyin; awọn olori nyin, awọn ẹ̀ya nyin, awọn àgba nyin, ati awọn ijoye nyin, ani gbogbo awọn ọkunrin Israeli, 11 Awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, awọn aya nyin, ati alejò rẹ, ti mbẹ lãrin ibudó rẹ, lati aṣẹgi rẹ dé apọnmi rẹ: 12 Ki iwọ ki o le wọ̀ inu majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ibura rẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ ṣe li oni: 13 Ki o le fi idi rẹ kalẹ li oni li enia kan fun ara rẹ̀, ati ki on ki o le ma ṣe Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ fun ọ, ati bi o ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu. 14 Ki si iṣe ẹnyin nikan ni mo bá ṣe majẹmu yi ati ibura yi; 15 Ṣugbọn ẹniti o bá wa duro nihin li oni niwaju OLUWA Ọlọrun wa, ẹniti kò sí nihin pẹlu wa li oni: 16 (Nitoripe ẹnyin mọ̀ bi awa ti gbé ilẹ Egipti; ati bi awa ti kọja lãrin orilẹ-ède ti ẹnyin là kọja; 17 Ẹnyin si ti ri ohun irira wọn, ati ere wọn, igi ati okuta, fadakà ati wurà, ti o wà lãrin wọn.) 18 Ki ẹnikẹni ki o má ba wà ninu nyin, ọkunrin, tabi obinrin, tabi idile, tabi ẹ̀ya, ti àiya rẹ̀ ṣí kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun wa li oni, lati lọ isìn oriṣa awọn orilẹ-ède wọnyi; ki gbòngbo ti nyọ orõro ati iwọ, ki o má ba wà ninu nyin; 19 Yio si ṣe, nigbati o ba gbọ́ ọ̀rọ egún yi, ti o sure fun ara rẹ̀ ninu àiya rẹ̀, wipe, Emi o ní alafia, bi emi tilẹ nrìn ninu agídi ọkàn mi, lati run tutù pẹlu gbigbẹ: 20 OLUWA ki yio darijì i, ṣugbọn nigbana ni ibinu OLUWA ati owú rẹ̀ yio gbona si ọkunrin na, ati gbogbo egún wọnyi ti a kọ sinu iwé yi ni yio bà lé e, OLUWA yio si nù orukọ rẹ̀ kuro labẹ ọrun. 21 OLUWA yio si yà a si ibi kuro ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, gẹgẹ bi gbogbo egún majẹmu, ti a kọ sinu iwé ofin yi. 22 Ati iran ti mbọ̀, awọn ọmọ nyin ti yio dide lẹhin nyin, ati alejò ti yio ti ilẹ jijìn wá, yio si wi, nigbati nwọn ba ri iyọnu ilẹ na, ati àrun na, ti OLUWA mu bá a; 23 Ati pe gbogbo ilẹ rẹ̀ di imi-õrùn, ati iyọ̀, ati ijóna, ti a kò le gbìn nkan si, tabi ti kò le seso, tabi ti koriko kò le hù ninu rẹ̀, bi ibìṣubu Sodomu, ati Gomorra, Adma, ati Seboiimu, ti OLUWA bìṣubu ninu ibinu rẹ̀, ati ninu ikannu rẹ̀: 24 Ani gbogbo orilẹ-ède yio ma wipe, Ẽṣe ti OLUWA fi ṣe bayi si ilẹ yi? Kili a le mọ̀ õru ibinu nla yi si? 25 Nwọn o si wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ majẹmu OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o ti bá wọn dá nigbati o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá. 26 Nitoriti nwọn lọ, nwọn si bọ oriṣa, nwọn si tẹriba fun wọn, oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, ti on kò si fi fun wọn. 27 Ibinu OLUWA si rú si ilẹ na, lati mú gbogbo egún ti a kọ sinu iwé yi wá sori rẹ̀: 28 OLUWA si fà wọn tu kuro ni ilẹ wọn ni ibinu, ati ni ikannu, ati ni irunu nla, o si lé wọn lọ si ilẹ miran, bi o ti ri li oni yi. 29 Ti OLUWA Ọlọrun wa ni ohun ìkọkọ: ṣugbọn ohun ti afihàn ni tiwa ati ti awọn ọmọ wa lailai, ki awa ki o le ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi.

Deuteronomi 30

Ìpadà-bọ̀-sípò ati Ibukun Israẹli

1 YIO si ṣe, nigbati gbogbo nkan wọnyi ba dé bá ọ, ibukún ati egún, ti mo filelẹ niwaju rẹ, ti iwọ o ba si ranti ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si, 2 Ti iwọ ba si yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo; 3 Nigbana ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio yi oko-ẹrú rẹ pada, yio si ṣãnu fun ọ, yio si pada, yio si kó ọ jọ kuro ninu gbogbo orilẹ-ède wọnni nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si. 4 Bi a ba si lé ẹni rẹ kan lọ si ìha opin ọrun, lati ibẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio kó ọ jọ, lati ibẹ̀ ni yio si mú ọ wá: 5 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si mú ọ wá sinu ilẹ na ti awọn baba rẹ ti ní, iwọ o si ní i; on o si ṣe ọ li ore, yio si mu ọ bisi i jù awọn baba rẹ lọ. 6 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si kọ àiya rẹ nilà, ati àiya irú-ọmọ rẹ, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, ki iwọ ki o le yè. 7 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si fi gbogbo egún wọnyi lé awọn ọtá rẹ lori, ati lori awọn ti o korira rẹ, ti nṣe inunibini si ọ. 8 Iwọ o si pada, iwọ o si gbà ohùn OLUWA gbọ́, iwọ o si ma ṣe gbogbo ofin rẹ̀ ti mo palaṣẹ fun ọ li oni. 9 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si sọ ọ di pupọ̀ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, fun rere: nitoriti OLUWA yio pada wa yọ̀ sori rẹ fun rere, bi o ti yọ̀ sori awọn baba rẹ: 10 Bi iwọ ba gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́, ti a kọ sinu iwé ofin yi; bi iwọ ba si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ. 11 Nitori aṣẹ yi ti mo pa fun ọ li oni, kò ṣoro jù fun ọ, bẹ̃ni kò jìna rere si ọ. 12 Kò sí li ọrun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio gòke lọ si ọrun fun wa, ti yio si mú u wá fun wa, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e? 13 Bẹ̃ni kò sí ni ìha keji okun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio rekọja okun lọ fun wa, ti yio si mú u fun wa wá, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e? 14 Ṣugbọn ọ̀rọ na li o wà nitosi rẹ girigiri yi, li ẹnu rẹ, ati li àiya rẹ, ki iwọ ki o le ma ṣe e. 15 Wò o, emi fi ìye ati ire, ati ikú ati ibi, siwaju rẹ li oni; 16 Li eyiti mo palaṣẹ fun ọ li oni lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀ mọ́, ki iwọ ki o le yè, ki o si ma bisi i, ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le busi i fun ọ ni ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a. 17 Ṣugbọn bi àiya rẹ ba pada, ti iwọ kò ba si gbọ́, ṣugbọn ti iwọ di ẹni fifà lọ, ti iwọ si mbọ oriṣa, ti iwọ si nsìn wọn; 18 Emi sọ fun nyin li oni, pe ṣiṣegbé li ẹnyin o ṣegbé; ẹnyin ki yio mu ọjọ́ nyin pẹ lori ilẹ, nibiti iwọ ngòke Jordani lọ lati gbà a. 19 Emi pè ọrun ati ilẹ jẹri tì nyin li oni pe, emi fi ìye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn ìye, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irú-ọmọ rẹ: 20 Ki iwọ ki o le ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ki iwọ ki o le ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ati ki iwọ ki o le ma faramọ́ ọ: nitoripe on ni ìye rẹ, ati gigùn ọjọ́ rẹ: ki iwọ ki o le ma gbé inu ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, ati fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn.

Deuteronomi 31

Joṣua Gba Ipò Mose

1 MOSE si lọ, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo Israeli. 2 O si wi fun wọn pe, Emi di ẹni ọgọfa ọdún li oni; emi kò le ma jade ki nsi ma wọle mọ́: OLUWA si ti wi fun mi pe, Iwọ ki yio gòke Jordani yi mọ́. 3 OLUWA Ọlọrun rẹ, on ni yio rekọja ṣaju rẹ, on ni yio si run orilẹ-ède wọnyi kuro niwaju rẹ, iwọ o si gbà wọn: ati Joṣua, on ni yio gòke ṣaju rẹ, bi OLUWA ti wi. 4 OLUWA yio si ṣe si wọn bi o ti ṣe si Sihoni ati si Ogu, ọba awọn Amori, ati si ilẹ wọn; awọn ẹniti o run. 5 OLUWA yio si fi wọn tọrẹ niwaju nyin, ki ẹnyin ki o le fi wọn ṣe gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ ti mo pa fun nyin. 6 Ẹ ṣe giri ki ẹ si mu àiya le, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya wọn: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ, on li o mbá ọ lọ; on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ. 7 Mose si pè Joṣua, o si wi fun u li oju gbogbo Israeli pe, Ṣe giri ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio bá awọn enia yi lọ si ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba wọn, lati fi fun wọn; iwọ o si mu wọn gbà a. 8 Ati OLUWA on li o nlọ ṣaju rẹ; on ni yio pẹlu rẹ, on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ: máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ.

Kíka Òfin ní Ọdún Keje-keje

9 Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli. 10 Mose si paṣẹ fun wọn, wipe, Li opin ọdún meje meje li akokò ọdún idasilẹ, ni ajọ agọ́. 11 Nigbati gbogbo Israeli ba wá farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti on o gbé yàn, ki iwọ ki o kà ofin yi niwaju gbogbo Israeli li etí wọn. 12 Kó awọn enia na jọ, awọn ọkunrin ati awọn obinrin ati awọn ọmọde, ati alejò rẹ ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki nwọn ki o le gbọ́, ati ki nwọn ki o le kọ ati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ati ki nwọn ki o ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi; 13 Ati ki awọn ọmọ wọn, ti kò mọ̀, ki o le gbọ́, ki nwọn si kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngóke Jordani lọ lati gbà a.

Ìlànà Ìkẹyìn Tí OLUWA fún Mose

14 OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, ọjọ́ rẹ sunmọ-etile ti iwọ o kú: pè Joṣua, ki ẹ si fara nyin hàn ninu agọ́ ajọ, ki emi ki o le fi aṣẹ lé e lọwọ. Mose ati Joṣua si lọ, nwọn si fara wọn hàn ninu agọ́ ajọ. 15 OLUWA si yọ si wọn ninu agọ́ na ninu ọwọ̀n awọsanma: ọwọ̀n awọsanma na si duro loke ẹnu-ọ̀na agọ́ na. 16 OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, iwọ o sùn pẹlu awọn baba rẹ; awọn enia yi yio si dide, nwọn o si ma ṣe àgbere tọ̀ awọn oriṣa ilẹ na lẹhin, nibiti nwọn nlọ lati gbé inu wọn, nwọn o si kọ̀ mi silẹ, nwọn o si dà majẹmu mi ti mo bá wọn dá. 17 Nigbana ni ibinu mi yio rú si wọn li ọjọ́ na, emi o si kọ̀ wọn silẹ, emi o si pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, a o si jẹ wọn run, ati ibi pupọ̀ ati iyọnu ni yio bá wọn; tobẹ̃ ti nwọn o si wi li ọjọ́ na pe, Kò ha jẹ́ pe nitoriti Ọlọrun wa kò sí lãrin wa ni ibi wọnyi ṣe bá wa? 18 Emi o fi oju mi pamọ́ patapata li ọjọ́ na, nitori gbogbo ìwabuburu ti nwọn o ti hù, nitori nwọn yipada si oriṣa. 19 Njẹ nisisiyi, kọwe orin yi fun ara nyin, ki ẹ fi kọ́ awọn ọmọ Israeli: fi i si wọn li ẹnu, ki orin yi ki o le ma jẹ́ ẹrí fun mi si awọn ọmọ Israeli. 20 Nitoripe nigbati emi ba mú wọn wá si ilẹ na, ti mo bura fun awọn baba wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; ti nwọn ba si jẹ ajẹyo tán, ti nwọn si sanra; nigbana ni nwọn o yipada si oriṣa, nwọn a si ma sìn wọn, nwọn a si kẹ́gan mi, nwọn a si dà majẹmu mi. 21 Yio si ṣe, nigbati ibi pupọ̀ ati iyọnu ba bá wọn, ki orin yi ki o jẹri tì wọn bi ẹlẹri; nitoripe a ki yio gbagbé rẹ̀ lati ẹnu awọn ọmọ wọn: nitori mo mọ̀ ìro inu wọn, ti nwọn nrò, ani nisisiyi, ki emi ki o to mú wọn wá sinu ilẹ na ti mo bura si. 22 Nitorina ni Mose ṣe kọwe orin yi li ọjọ́ na gan, o si fi kọ́ awọn ọmọ Israeli. 23 O si paṣẹ fun Joṣua ọmọ Nuni, o si wipe, Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio mú awọn ọmọ Israeli lọ sinu ilẹ na ti mo bura fun wọn: Emi o si wà pẹlu rẹ. 24 O si ṣe, nigbati Mose pari kikọ ọ̀rọ ofin yi tán sinu iwé, titi nwọn fi pari, 25 Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ti nrù apoti majẹmu OLUWA, wipe, 26 Gbà iwé ofin yi, ki o si fi i sapakan apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o ma wà nibẹ̀ fun ẹrí si ọ. 27 Nitoripe mo mọ̀ ọ̀tẹ rẹ, ati lile ọrùn rẹ: kiyesi i, nigbati emi wà lãye sibẹ̀ pẹlu nyin li oni, ọlọtẹ̀ li ẹnyin ti nṣe si OLUWA; melomelo si ni lẹhin ikú mi? 28 Pè gbogbo awọn àgba ẹ̀ya nyin jọ sọdọ mi, ati awọn ijoye nyin, ki emi ki o le sọ ọ̀rọ wọnyi li etí wọn ki emi ki o si pè ọrun ati aiye jẹri tì wọn. 29 Nitori mo mọ̀ pe lẹhin ikú mi ẹnyin o bà ara nyin jẹ́ patapata, ati pe ẹnyin o yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin; ibi yio si bá nyin li ọjọ́ ikẹhin; nitoriti ẹnyin o ma ṣe buburu li oju OLUWA, lati fi iṣẹ ọwọ́ nyin mu u binu.

Orin Mose

30 Mose si sọ ọ̀rọ orin yi li etí gbogbo ijọ Israeli, titi nwọn fi pari.

Deuteronomi 32

1 FETISILẸ, ẹnyin ọrun, emi o si sọ̀rọ; si gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi, iwọ aiye: 2 Ẹkọ́ mi yio ma kán bi ojò ohùn mi yio ma sẹ̀ bi ìri; bi òjo winiwini sara eweko titun, ati bi ọ̀wara òjo sara ewebẹ̀: 3 Nitoriti emi o kokikí orukọ OLUWA kiri: ẹ fi ọlá fun Ọlọrun wa. 4 Apata na, pipé ni iṣẹ rẹ̀; nitoripe idajọ ni gbogbo ọ̀na rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati alàiṣegbe, ododo ati otitọ li on. 5 Nwọn ti bà ara wọn jẹ́ lọdọ rẹ̀, nwọn ki iṣe ọmọ rẹ̀, àbuku wọn ni; iran arekereke ati wiwọ́ ni nwọn. 6 Bayi li ẹnyin o ha san ẹsan fun OLUWA, ẹnyin aṣiwere enia ati alaigbọn? On ha kọ́ ni baba rẹ ti o rà ọ? on li o dá ọ, on li o si fi ẹsẹ̀ rẹ mulẹ? 7 Ranti ọjọ́ igbãni, ronu ọdún iraniran: bi baba rẹ lere yio si fihàn ọ; bi awọn àgba rẹ, nwọn o si sọ fun ọ. 8 Nigbati Ọga-ogo pín iní fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israeli. 9 Nitoripe ipín ti OLUWA li awọn enia rẹ̀; Jakobu ni ipín iní rẹ̀. 10 O ri i ni ilẹ aṣalẹ̀, ati ni aginjù nibiti ẹranko nke; o yi i ká, o tọju rẹ̀, o pa a mọ́ bi ẹyin oju rẹ̀: 11 Bi idì ti irú itẹ́ rẹ̀, ti iràbaba sori ọmọ rẹ̀, ti inà iyẹ́-apa rẹ̀, ti igbé wọn, ti ima gbé wọn lọ lori iyẹ́-apa rẹ̀: 12 Bẹ̃ni OLUWA nikan ṣamọ̀na rẹ̀, kò si sí oriṣa pẹlu rẹ̀. 13 O mu u gùn ibi giga aiye, ki o le ma jẹ eso oko; o si jẹ ki o mu oyin lati inu apata wá, ati oróro lati inu okuta akọ wá; 14 Ori-amọ́ malu, ati warà agutan, pẹlu ọrá ọdọ-agutan, ati àgbo irú ti Baṣani, ati ewurẹ, ti on ti ọrá iwe alikama; iwọ si mu ẹ̀jẹ eso-àjara, ani ọti-waini. 15 Ṣugbọn Jeṣuruni sanra tán, o si tapa: iwọ sanra tán, iwọ kì tan, ọrá bò ọ tán: nigbana li o kọ̀ Ọlọrun ti o dá a, o si gàn Apata ìgbala rẹ̀. 16 Nwọn fi oriṣa mu u jowú, ohun irira ni nwọn fi mu u binu. 17 Nwọn rubọ si iwin-buburu ti ki iṣe Ọlọrun, si oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, si oriṣa ti o hù ni titun, ti awọn baba nyin kò bẹ̀ru. 18 Apata ti o bi ọ ni iwọ kò ranti, iwọ si ti gbagbé Ọlọrun ti o dá ọ. 19 OLUWA si ri i, o si korira wọn, nitori ìwa-imunibinu awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati ti awọn ọmọbinrin rẹ̀. 20 O si wipe, Emi o pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, emi o si ma wò bi igbẹhin wọn yio ti ri; nitori iran alagídi ni nwọn, awọn ọmọ ninu ẹniti kò sí igbagbọ. 21 Nwọn ti fi ohun ti ki iṣe Ọlọrun mu mi jowú; nwọn si fi ohun asan wọn mu mi binu: emi o si fi awọn ti ki iṣe enia mu wọn jowú; emi o si fi aṣiwere orilẹ-ède mu wọn binu. 22 Nitoripe iná kan ràn ninu ibinu mi, yio si jó dé ipò-okú ni isalẹ, yio si run aiye pẹlu asunkún rẹ̀, yio si tinabọ ipilẹ awọn okenla. 23 Emi o kó ohun buburu jọ lé wọn lori; emi o si lò ọfà mi tán si wọn lara: 24 Ebi yio mu wọn gbẹ, oru gbigbona li a o fi run wọn, ati iparun kikorò; emi o si rán ehín ẹranko si wọn, pẹlu oró ohun ti nrakò ninu erupẹ. 25 Idà li ode, ati ipàiya ninu iyẹwu, ni yio run ati ọmọkunrin ati wundia, ọmọ ẹnu-ọmu, ati ọkunrin arugbo elewu irun pẹlu. 26 Mo wipe, Emi o tu wọn ká patapata, emi o si mu iranti wọn dá kuro ninu awọn enia: 27 Bikoṣepe bi mo ti bẹ̀ru ibinu ọtá, ki awọn ọtá wọn ki o má ba ṣe alaimọ̀, ati ki nwọn ki o má ba wipe, Ọwọ́ wa leke ni, ki isi ṣe OLUWA li o ṣe gbogbo eyi. 28 Nitori orilẹ-ède ti kò ní ìmọ ni nwọn, bẹ̃ni kò sí òye ninu wọn. 29 Ibaṣepe nwọn gbọ́n, ki òye eyi ki o yé wọn, nwọn iba rò igbẹhin wọn! 30 Ẹnikan iba ti ṣe lé ẹgbẹrun, ti ẹni meji iba si lé ẹgbãrun sá, bikoṣepe bi Apata wọn ti tà wọn, ti OLUWA si fi wọn tọrẹ? 31 Nitoripe apata wọn kò dabi Apata wa, ani awọn ọtá wa tikalawọn ni nṣe onidajọ. 32 Nitoripe igi-àjara wọn, ti igi-àjara Sodomu ni, ati ti igbẹ́ Gomorra: eso-àjara wọn li eso-àjara orõro, ìdi wọn korò: 33 Ọti-waini wọn iwọ ti dragoni ni, ati oró mimu ti pamọlẹ̀. 34 Eyi ki a tojọ sọdọ mi ni ile iṣura, ti a si fi èdidi dì ninu iṣura mi? 35 Ti emi ni igbẹsan, ati ẹsan, li akokò ti ẹsẹ̀ wọn yio yọ́: nitoriti ọjọ́ idamu wọn sunmọtosi, ohun ti o si mbọ̀ wa bá wọn nyára wá. 36 Nitoripe OLUWA yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si kãnu awọn iranṣẹ rẹ̀; nigbati o ba ri pe agbara wọn lọ tán, ti kò si sí ẹnikan ti a sé mọ́, tabi ti o kù. 37 On o si wipe, Nibo li oriṣa wọn gbé wà, apata ti nwọn gbẹkẹle: 38 Ti o ti jẹ ọrá ẹbọ wọn, ti o ti mu ọti-waini ẹbọ ohunmimu wọn? jẹ ki nwọn dide ki nwọn si ràn nyin lọwọ, ki nwọn ṣe àbo nyin. 39 Wò o nisisiyi pe Emi, ani Emi ni, kò si sí ọlọrun pẹlu mi: mo pa, mo si sọ di ãye; mo ṣalọgbẹ, mo si mu jiná; kò si sí ẹnikan ti o le gbà silẹ li ọwọ́ mi. 40 Nitoripe mo gbé ọwọ́ mi soke ọrun, mo si wipe, Bi Emi ti wà titilai. 41 Bi mo ba si pọ́n idà didan mi, ti mo ba si fi ọwọ́ mi lé idajọ; emi o san ẹsan fun awọn ọtá mi, emi o radi i fun awọn ti o korira mi. 42 Emi o mu ọfà mi rin fun ẹ̀jẹ, idà mi o si jẹ ẹran; ninu ẹ̀jẹ ẹni pipa ati ti igbekun, lati ori awọn aṣaju ọtá. 43 Ẹ ma yọ̀, ẹnyin orilẹ-ède, pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on o gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀, yio si gbẹsan lara awọn ọtá rẹ̀, yio si ṣètutu fun ilẹ rẹ̀, ati fun awọn enia rẹ̀. 44 Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi li etí awọn enia na, on, ati Hoṣea ọmọ Nuni.

Ìlànà Ìkẹyìn tí Mose fún Wọn

45 Mose si pari sisọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo Israeli: 46 O si wi fun wọn pe, Ẹ gbé ọkàn nyin lé gbogbo ọ̀rọ ti mo sọ lãrin nyin li oni; ti ẹnyin o palaṣẹ fun awọn ọmọ nyin lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi. 47 Nitoripe ki iṣe ohun asan fun nyin; nitoripe ìye nyin ni, ati nipa eyi li ẹnyin o mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a. 48 OLUWA si sọ fun Mose li ọjọ́ na gan, wipe, 49 Gùn òke Abarimu yi lọ, si òke Nebo, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Jeriko; ki o si wò ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli ni iní. 50 Ki o si kú lori òke na, nibiti iwọ ngùn lọ, ki a si kó ọ jọ sọdọ awọn enia rẹ; bi Aaroni arakunrin rẹ ti kú li òke Horu, ti a si kó o jọ sọdọ awọn enia rẹ̀: 51 Nitoriti ẹnyin ṣẹ̀ si mi lãrin awọn ọmọ Israeli ni ibi omi Meriba-Kadeṣi, li aginjù Sini; nitoriti ẹnyin kò yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli. 52 Ṣugbọn iwọ o ri ilẹ na niwaju rẹ; ṣugbọn iwọ ki yio lọ sibẹ̀, si ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli.

Deuteronomi 33

Mose Súre fún Àwọn Ẹ̀yà Israẹli

1 EYI si ni ire, ti Mose enia Ọlọrun su fun awọn ọmọ Israeli ki o to kú. 2 O si wipe, OLUWA ti Sinai wá, o si yọ si wọn lati Seiri wá; o tàn imọlẹ jade lati òke Parani wá, o ti ọdọ ẹgbẹgbãrun awọn mimọ́ wá: lati ọwọ́ ọtún rẹ̀ li ofin kan amubĩná ti jade fun wọn wá. 3 Nitõtọ, o fẹ́ awọn enia na; gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀ wà li ọwọ́ rẹ. Nwọn si joko li ẹsẹ̀ rẹ; olukuluku ni yio gbà ninu ọ̀rọ rẹ. 4 Mose fi ofin kan lelẹ li aṣẹ fun wa, iní ti ijọ enia Jakobu. 5 O si jẹ́ ọba ni Jeṣuruni, nigbati olori awọn enia, awọn ẹ̀ya Israeli pejọ pọ̀. 6 Ki Reubeni ki o yè, ki o máṣe kú; ki enia rẹ̀ ki o máṣe mọniwọn. 7 Eyi si ni ti Judah: o si wipe, OLUWA, gbọ́ ohùn Judah, ki o si mú u tọ̀ awọn enia rẹ̀ wá: ki ọwọ́ rẹ̀ ki o to fun u; ki iwọ ki o si ṣe iranlọwọ fun u lọwọ awọn ọtá rẹ̀. 8 Ati niti Lefi o wipe, Jẹ ki Tummimu ati Urimu rẹ ki o wà pẹlu ẹni mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ danwò ni Massa, ati ẹniti iwọ bá jà li omi Meriba; 9 Ẹniti o wi niti baba rẹ̀, ati niti iya rẹ̀ pe, Emi kò ri i; bẹ̃ni kò si jẹwọ awọn arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò si mọ̀ awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti nwọn kiyesi ọ̀rọ rẹ, nwọn si pa majẹmu rẹ mọ́. 10 Nwọn o ma kọ́ Jakobu ni idajọ rẹ, ati Israeli li ofin rẹ: nwọn o ma mú turari wá siwaju rẹ, ati ọ̀tọtọ ẹbọ sisun sori pẹpẹ rẹ. 11 OLUWA, busi ohun-iní rẹ̀, ki o si tẹwọgbà iṣẹ ọwọ́ rẹ̀: lù ẹgbẹ́ awọn ti o dide si i, ati ti awọn ti o korira rẹ̀, ki nwọn ki o máṣe dide mọ́. 12 Ati niti Benjamini o wipe, Olufẹ OLUWA yio ma gbé li alafia lọdọ rẹ̀; on a ma bò o li ọjọ́ gbogbo, on a si ma gbé lãrin ejika rẹ̀. 13 Ati niti Josefu o wipe, Ibukún OLUWA ni ilẹ rẹ̀, fun ohun iyebiye ọrun, fun ìri, ati fun ibú ti o ba nisalẹ, 14 Ati fun eso iyebiye ti õrùn múwa, ati fun ohun iyebiye ti ndàgba li oṣoṣù, 15 Ati fun ohun pàtaki okenla igbãni, ati fun ohun iyebiye òke aiyeraiye, 16 Ati fun ohun iyebiye aiye ati ẹkún rẹ̀, ati fun ifẹ́ inurere ẹniti o gbé inu igbẹ́: jẹ ki ibukún ki o wá si ori Josefu, ati si atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀. 17 Akọ́bi akọmalu rẹ̀, tirẹ̀ li ọlánla; iwo rẹ̀ iwo agbanrere ni: on ni yio fi tì awọn enia, gbogbo wọn, ani opin ilẹ: awọn si ni ẹgbẹgbãrun Efraimu, awọn si ni ẹgbẹgbẹrun Manasse. 18 Ati niti Sebuluni o wipe, Sebuluni, ma yọ̀ ni ijade rẹ; ati Issakari, ninu agọ́ rẹ. 19 Nwọn o pè awọn enia na sori òke; nibẹ̀ ni nwọn o ru ẹbọ ododo: nitoripe nwọn o ma mu ninu ọ̀pọlọpọ okun, ati ninu iṣura ti a pamọ́ ninu iyanrin. 20 Ati niti Gadi o wipe, Ibukún ni fun ẹniti o mu Gadi gbilẹ: o ba bi abo-kiniun, o si fà apa ya, ani atari. 21 O si yàn apá ikini fun ara rẹ̀, nitoripe nibẹ̀ li a fi ipín olofin pamọ́ si; o si wá pẹlu awọn olori enia na, o si mú ododo OLUWA ṣẹ, ati idajọ rẹ̀ pẹlu Israeli. 22 Ati niti Dani o wipe, Ọmọ kiniun ni Dani: ti nfò lati Baṣani wá. 23 Ati niti Naftali o wipe, Iwọ Naftali, ti ojurere tẹ́lọrùn, ti o si kún fun ibukún OLUWA: gbà ìha ìwọ-õrùn ati gusù. 24 Ati niti Aṣeri o wipe, Ibukún ọmọ niti Aṣeri; ki on ki o si jẹ́ itẹwọgba fun awọn arakunrin rẹ̀, ki on ki o si ma rì ẹsẹ̀ rẹ̀ sinu oróro. 25 Bàta rẹ yio jasi irin ati idẹ; ati bi ọjọ́ rẹ, bẹ̃li agbara rẹ yio ri. 26 Kò sí ẹniti o dabi Ọlọrun, iwọ Jeṣuruni, ti ngùn ọrun fun iranlọwọ rẹ, ati ninu ọlanla rẹ̀ li oju-ọrun. 27 Ọlọrun aiyeraiye ni ibugbé rẹ, ati nisalẹ li apa aiyeraiye wà: on si tì ọtá kuro niwaju rẹ, o si wipe, Ma parun. 28 Israeli si joko li alafia, orisun Jakobu nikan, ni ilẹ ọkà ati ti ọti-waini; pẹlupẹlu ọrun rẹ̀ nsẹ̀ ìri silẹ. 29 Alafia ni fun iwọ, Israeli: tali o dabi rẹ, iwọ enia ti a ti ọwọ́ OLUWA gbàla, asà iranlọwọ rẹ, ati ẹniti iṣe idà ọlanla rẹ! awọn ọtá rẹ yio si tẹriba fun ọ; iwọ o si ma tẹ̀ ibi giga wọn mọlẹ.

Deuteronomi 34

Ikú Mose

1 MOSE si gòke lati pẹtẹlẹ̀ Moabu lọ si òke Nebo, si ori Pisga, ti o dojukọ Jeriko. OLUWA si fi gbogbo ilẹ Gileadi dé Dani hàn a; 2 Ati gbogbo Naftali, ati ilẹ Efraimu, ati ti Manasse, ati gbogbo ilẹ Juda, dé okun ìwọ-õrùn; 3 Ati gusù, ati pẹtẹlẹ̀ afonifoji Jeriko, ilu ọlọpẹ dé Soari. 4 OLUWA si wi fun u pe, Eyi ni ilẹ ti mo bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Emi o fi i fun irú-ọmọ rẹ: emi mu ọ fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ ki yio rekọja lọ sibẹ̀. 5 Bẹ̃ni Mose iranṣẹ OLUWA kú nibẹ̀ ni ilẹ Moabu, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA. 6 O si sin i ninu afonifoji ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Beti-peori; ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o mọ̀ iboji rẹ̀ titi di oni-oloni. 7 Mose si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún nigbati o kú: oju rẹ̀ kò ṣe baìbai, bẹ̃li agbara rẹ̀ kò dinku. 8 Awọn ọmọ Israeli si sọkun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu li ọgbọ̀n ọjọ́: bẹ̃li ọjọ́ ẹkún ati ọ̀fọ Mose pari. 9 Joṣua ọmọ Nuni si kún fun ẹmi ọgbọ́n; nitoripe Mose ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori: awọn ọmọ Israeli si gbà tirẹ̀ gbọ́, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 10 Wolĩ kan kò si hù mọ́ ni Israeli bi Mose, ẹniti OLUWA mọ̀ li ojukoju, 11 Ni gbogbo iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, ti OLUWA rán a lati ṣe ni ilẹ Egipti, si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀; 12 Ati ni gbogbo ọwọ́ agbara, ati ni gbogbo ẹ̀ru nla ti Mose fihàn li oju gbogbo Israeli.

Joṣua 1

Ọlọrun Pàṣẹ fún Joṣua pé Kí Ó Fi Ogun Kó Ilẹ̀ Kenaani

1 O si ṣe lẹhin ikú Mose iranṣẹ OLUWA, li OLUWA sọ fun Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, wipe, 2 Mose iranṣẹ mi kú; njẹ iwọ, dide, gòke Jordani yi, iwọ, ati gbogbo enia yi, si ilẹ ti mo fi fun wọn, ani fun awọn ọmọ Israeli. 3 Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀, ẹnyin ni mo fi fun, gẹgẹ bi mo ti sọ fun Mose. 4 Lati aginjù, ati Lebanoni yi, ani titi dé odò nla nì, odò Euferate, gbogbo ilẹ awọn Hitti, ati titi dé okun nla ni ìwọ-õrùn, eyi ni yio ṣe opin ilẹ nyin. 5 Ki yio sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃li emi ki yio kọ̀ ọ. 6 Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn. 7 Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ: má ṣe yà kuro ninu rẹ̀ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ. 8 Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ. 9 Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi? Ṣe giri ki o si mu àiya le; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ ba nlọ.

Joṣua Pàṣẹ fún Àwọn Eniyan Náà

10 Nigbana ni Joṣua paṣẹ fun awọn olori awọn enia wipe, 11 Ẹ là ãrin ibudó já, ki ẹ si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Ẹ pèse onjẹ; nitoripe ni ijọ́ mẹta oni ẹnyin o gòke Jordani yi, lati lọ gbà ilẹ ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin lati ní. 12 Ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse, ni Joṣua wipe, 13 Ranti ọ̀rọ ti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin pe, OLUWA Ọlọrun nyin nfun nyin ni isimi, on o si fun nyin ni ilẹ yi. 14 Awọn obinrin nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati ohunọ̀sin nyin, yio joko ni ilẹ ti Mose fi fun nyin ni ìha ihin Jordani; ṣugbọn ẹnyin o gòke lọ niwaju awọn arakunrin nyin ni ihamọra, gbogbo awọn alagbara akọni, ẹnyin o si ràn wọn lọwọ, 15 Titi OLUWA yio fi fun awọn arakunrin nyin ni isimi, gẹgẹ bi o ti fi fun nyin, ati ti awọn pẹlu yio fi gbà ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun wọn: nigbana li ẹnyin o pada si ilẹ iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla-õrùn, ẹnyin o si ní i. 16 Nwọn si da Joṣua lohùn, wipe, Gbogbo ohun ti iwọ palaṣẹ fun wa li awa o ṣe, ibikibi ti iwọ ba rán wa lọ, li awa o lọ. 17 Gẹgẹ bi awa ti gbọ́ ti Mose li ohun gbogbo, bẹ̃li awa o gbọ́ tirẹ: kìki ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o wà pẹlu rẹ, gẹgẹ bi o ti wà pẹlu Mose. 18 Ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ti o ba tapá si ofin rẹ, ti ki yio si gbọ́ ọ̀rọ rẹ li ohun gbogbo ti iwọ palaṣẹ fun u, pipa li a o pa a: kìki ki iwọ ṣe giri ki o si mu àiya le.

Joṣua 2

Joṣua Rán Àwọn Amí Lọ sí Jẹriko

1 JOṢUA ọmọ Nuni si rán ọkunrin meji jade lati Ṣittimu yọ lọ ṣe amí, wipe, Ẹ lọ iwò ilẹ na, ati Jeriko. Nwọn si lọ, nwọn si dé ile panṣaga kan, ti a npè ni Rahabu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀. 2 A si sọ fun ọba Jeriko pe, Kiyesi i, awọn ọkunrin kan ninu awọn ọmọ Israeli dé ihinyi li alẹ yi lati rìn ilẹ yi wò. 3 Ọba Jeriko si ranṣẹ si Rahabu, wipe, Mú awọn ọkunrin nì ti o tọ̀ ọ wá, ti o wọ̀ inu ile rẹ jade wá: nitori nwọn wá lati rìn gbogbo ilẹ yi wò. 4 Obinrin na si mú awọn ọkunrin meji na, o si fi wọn pamọ́; o si wi bayi pe, Awọn ọkunrin kan wá sọdọ mi, ṣugbọn emi kò mọ̀ ibi ti nwọn ti wá. 5 O si ṣe li akokò ati tì ilẹkun ẹnubode, nigbati ilẹ ṣú, awọn ọkunrin na si jade lọ: ibi ti awọn ọkunrin na gbé lọ, emi kò mọ̀: ẹ lepa wọn kánkán; nitori ẹnyin o bá wọn. 6 Ṣugbọn o ti mú wọn gòke àja ile, o si fi poroporo ọ̀gbọ ti o ti tòjọ soke àja bò wọn mọlẹ. 7 Awọn ọkunrin na lepa wọn li ọ̀na ti o lọ dé iwọ̀do Jordani: bi awọn ti nlepa wọn si ti jade lọ, nwọn tì ilẹkun ẹnubode. 8 Ki nwọn ki o tó dubulẹ, o gòke tọ̀ wọn lọ loke àja; 9 O si wi fun awọn ọkunrin na pe, Emi mọ̀ pe OLUWA ti fun nyin ni ilẹ yi, ati pe ẹ̀ru nyin bà ni, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin. 10 Nitoripe awa ti gbọ́ bi OLUWA ti mu omi Okun Pupa gbẹ niwaju nyin, nigbati ẹnyin jade ni Egipti; ati ohun ti ẹnyin ṣe si awọn ọba meji ti awọn Amori, ti mbẹ ni ìha keji Jordani, Sihoni ati Ogu, ti ẹnyin parun tútu. 11 Lọgán bi awa ti gbọ́ nkan wọnyi, àiya wa já, bẹ̃ni kò si sí agbara kan ninu ọkunrin kan mọ́ nitori nyin; nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li Ọlọrun loke ọrun, ati nisalẹ aiye. 12 Njẹ nitorina, emi bẹ̀ nyin, ẹ fi OLUWA bura fun mi, bi mo ti ṣe nyin li ore, ẹnyin o ṣe ore pẹlu fun ile baba mi, ẹnyin o si fun mi li àmi otitọ: 13 Ati pe ẹnyin o pa baba mi mọ́ lãye, ati iya mi, ati awọn arakunrin mi, ati awọn arabinrin mi, ati ohun gbogbo ti nwọn ní, ki ẹnyin si gbà ẹmi wa lọwọ ikú. 14 Awọn ọkunrin na da a lohùn pe, Ẹmi wa ni yio dipò ti nyin, bi ẹnyin kò ba fi ọ̀ran wa yi hàn; yio si ṣe, nigbati OLUWA ba fun wa ni ilẹ na, awa o ṣe ore ati otitọ fun ọ. 15 Nigbana li o fi okùn sọ̀ wọn kalẹ li oju-ferese: nitoriti ile rẹ̀ wà lara odi ilu, on a si ma gbé ori odi na. 16 O si wi fun wọn pe, Ẹ bọ sori òke, ki awọn alepa ki o má ba le nyin bá; ki ẹnyin si fara nyin pamọ́ nibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa yio fi pada: lẹhin na ẹ ma ba ọ̀na ti nyin lọ. 17 Awọn ọkunrin na wi fun u pe, Ara wa o dá niti ibura rẹ yi, ti iwọ mu wa bú. 18 Kiyesi i, nigbati awa ba dé inu ilẹ na, iwọ o so okùn owú ododó yi si oju-ferese ti iwọ fi sọ̀ wa kalẹ: iwọ o si mú baba rẹ, ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ, ati gbogbo ara ile baba rẹ, wá ile sọdọ rẹ. 19 Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba jade lati inu ilẹkun ile rẹ lọ si ode, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori ara rẹ̀, awa o si wà li aijẹbi: ati ẹnikẹni ti o ba wà pẹlu rẹ ni ile, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori wa, bi ẹnikẹni ba fọwọkàn a. 20 Bi o ba si sọ ọ̀ran wa yi, nigbana ni ara wa o dá niti ibura rẹ ti iwọ mu wa bú yi. 21 O si wipe, Gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin, bẹ̃ni ki o ri. O si rán wọn lọ, nwọn si lọ: o si so okùn ododó na si oju-ferese. 22 Nwọn si lọ, nwọn si dé ori òke, nwọn si gbé ibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa fi pada: awọn alepa wá wọn ni gbogbo ọ̀na, ṣugbọn nwọn kò ri wọn. 23 Bẹ̃li awọn ọkunrin meji na pada, nwọn si sọkalẹ lori òke, nwọn si kọja, nwọn si tọ̀ Joṣua ọmọ Nuni wá; nwọn si sọ ohun gbogbo ti o bá wọn fun u. 24 Nwọn si wi fun Joṣua pe, Nitõtọ li OLUWA ti fi gbogbo ilẹ na lé wa lọwọ; nitoripe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori wa.

Joṣua 3

Àwọn Ọmọ Israẹli La Odò Jọdani Kọjá

1 JOṢUA si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si ṣí kuro ni Ṣittimu, nwọn si dé Jordani, on ati gbogbo awọn ọmọ Israeli; nwọn si sùn sibẹ̀ ki nwọn ki o to gòke odò. 2 O si ṣe lẹhin ijọ́ mẹta, ni awọn olori là ãrin ibudó já; 3 Nwọn si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Nigbati ẹnyin ba ri apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti ẹ ba si ri awọn alufa awọn ọmọ Lefi rù u, nigbana li ẹnyin o ṣí kuro ni ipò nyin, ẹnyin o si ma tọ̀ ọ lẹhin. 4 Ṣugbọn alafo yio wà li agbedemeji ti ẹnyin tirẹ̀, to bi ìwọn ẹgba igbọnwọ: ẹ má ṣe sunmọ ọ, ki ẹnyin ki o le mọ̀ ọ̀na ti ẹnyin o gbà; nitoriti ẹnyin kò gbà ọ̀na yi rí. 5 Joṣua si wi fun awọn enia pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́: nitori li ọla OLUWA yio ṣe ohuniyanu lãrin nyin. 6 Joṣua si wi fun awọn alufa pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki ẹ si kọja siwaju awọn enia. Nwọn si gbé apoti majẹmu na, nwọn si ṣaju awọn enia. 7 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi gbé ọ ga li oju gbogbo Israeli, ki nwọn ki o le mọ̀ pe, gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o wà pẹlu rẹ. 8 Iwọ o si paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na pe, Nigbati ẹnyin ba dé eti odò Jordani, ki ẹnyin ki o duro jẹ ni Jordani. 9 Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ ihin, ki ẹ si gbọ́ ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun nyin. 10 Joṣua si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe Ọlọrun alãye mbẹ lãrin nyin, ati pe dajudaju on o lé awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Hifi, ati awọn Perissi, ati awọn Girgaṣi ati awọn Amori, ati awọn Jebusi, kuro niwaju nyin. 11 Kiyesi i, apoti majẹmu OLUWA gbogbo aiye ngòke lọ ṣaju nyin lọ si Jordani. 12 Njẹ nitorina, ẹ mu ọkunrin mejila ninu awọn ẹ̀ya Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya. 13 Yio si ṣe, lojukanna bi atẹlẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti OLUWA, Oluwa gbogbo aiye, ba ti tẹ̀ omi Jordani, omi Jordani yio ke kuro, ani omi ti nti òke ṣànwá; yio si duro bi òkiti kan. 14 O si ṣe, nigbati awọn enia ṣí kuro ninu agọ́ wọn, lati gòke Jordani, ti awọn alufa si rù apoti majẹmu wà niwaju awọn enia; 15 Bi awọn ti o rù apoti si ti dé Jordani, ti awọn alufa ti o rù apoti na si tẹ̀ ẹsẹ̀ wọn bọ̀ eti omi na, (nitoripe odò Jordani a ma kún bò gbogbo bèbe rẹ̀ ni gbogbo akokò ikore,) 16 Ni omi ti nti oke ṣàn wá duro, o si ga jìna rére bi òkiti li ọnà ni ilu Adamu, ti o wà lẹba Saretani: eyiti o si ṣàn sodò si ìha okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, a ke wọn kuro patapata: awọn enia si gòke tàra si Jeriko. 17 Awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA, si duro ṣinṣin lori ilẹ gbigbẹ lãrin Jordani, ati gbogbo awọn enia Israeli kọja lori ilẹ gbigbẹ, titi gbogbo awọn enia na fi gòke Jordani tán.

Joṣua 4

Wọ́n To Òkúta Ìrántí Jọ

1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia rekọja Jordani tán, ni OLUWA wi fun Joṣua pe, 2 Mú ọkunrin mejila ninu awọn enia, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya, 3 Ki ẹnyin si paṣẹ fun wọn pe. Ẹ gbé okuta mejila lati ihin lọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa gbé duro ṣinṣin nì, ki ẹnyin ki o si rù wọn kọja pẹlu nyin, ẹ si fi wọn si ibùsun, ni ibi ti ẹnyin o sùn li alẹ yi. 4 Nigbana ni Joṣua pè awọn ọkunrin mejila, ti o ti pèse silẹ ninu awọn ọmọ Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya: 5 Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ kọja lọ niwaju apoti OLUWA Ọlọrun nyin si ãrin Jordani, ki olukuluku ninu nyin ki o gbé okuta kọkan lé ejika rẹ̀, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli: 6 Ki eyi ki o le jẹ́ àmi lãrin nyin, nigbati awọn ọmọ nyin ba bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la, wipe, Èredi okuta wọnyi? 7 Nigbana li ẹnyin o da wọn lohùn pe, Nitori a ke omi Jordani niwaju apoti majẹmu OLUWA; nigbati o rekọja Jordani, a ke omi Jordani kuro: okuta wọnyi yio si jasi iranti fun awọn ọmọ Israeli lailai. 8 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi Joṣua ti paṣẹ, nwọn si gbé okuta mejila lati inu ãrin Jordani lọ, bi OLUWA ti wi fun Joṣua, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; nwọn si rù wọn kọja pẹlu wọn lọ si ibùsun, nwọn si gbé wọn kalẹ nibẹ̀. 9 Joṣua si tò okuta mejila jọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na gbé duro: nwọn si mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni. 10 Nitoriti awọn alufa ti o rù apoti na duro lãrin Jordani, titi ohun gbogbo fi pari ti OLUWA palaṣẹ fun Joṣua lati sọ fun awọn enia, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Mose palaṣẹ fun Joṣua: awọn enia na si yára nwọn si rekọja. 11 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia na rekọja tán, ni apoti OLUWA rekọja, ati awọn alufa, li oju awọn enia. 12 Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, si rekọja ni ihamọra niwaju awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi Mose ti sọ fun wọn: 13 Ìwọn ọkẹ meji enia ti o mura ogun, rekọja niwaju OLUWA fun ogun, si pẹtẹlẹ̀ Jeriko. 14 Li ọjọ́ na OLUWA gbé Joṣua ga li oju gbogbo Israeli: nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, gẹgẹ bi nwọn ti bẹ̀ru Mose li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo. 15 OLUWA si wi fun Joṣua pe, 16 Paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti ẹri nì pe, ki nwọn ki o ti inu Jordani jade. 17 Nitorina Joṣua paṣẹ fun awọn alufa wipe, Ẹ ti inu Jordani jade. 18 O si ṣe, nigbati awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA ti ãrin Jordani jade, ti awọn alufa si gbé atẹlẹsẹ̀ wọn soke si ilẹ gbigbẹ, ni omi Jordani pada si ipò rẹ̀, o si ṣàn bò gbogbo bèbe rẹ̀, gẹgẹ bi ti iṣaju. 19 Awọn enia si ti inu Jordani gòke ni ijọ́ kẹwa oṣù kini, nwọn si dó ni Gilgali, ni ìha ìla-õrùn Jeriko. 20 Ati okuta mejila wọnni ti nwọn gbé ti inu Jordani lọ, ni Joṣua tòjọ ni Gilgali. 21 O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati awọn ọmọ nyin yio bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la wipe, Ẽredi okuta wọnyi? 22 Nigbana li ẹnyin o jẹ ki awọn ọmọ nyin ki o mọ̀ pe, Israeli là Jordani yi kọja ni ilẹ gbigbẹ. 23 Nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju nyin, titi ẹnyin fi là a kọja, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si Okun Pupa, ti o mu gbẹ kuro niwaju wa, titi awa fi là a kọja: 24 Ki gbogbo enia aiye ki o le mọ ọwọ́ OLUWA, pe o lagbara; ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin lailai.

Joṣua 5

1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba Amori, ti o wà ni ìha keji Jordani ni ìwọ-õrùn, ati gbogbo awọn ọba Kenaani ti mbẹ leti okun, gbọ́ pe OLUWA ti mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa fi là a kọja, ni àiya wọn já, bẹ̃li ẹmi kò sí ninu wọn mọ́, nitori awọn ọmọ Israeli. 2 Nigbana li OLUWA wi fun Joṣua pe, Fi okuta ṣe abẹ ki iwọ ki o si tun kọ awọn ọmọ Israeli nilà lẹ̃keji. 3 Joṣua si ṣe abẹ okuta, o si kọ awọn ọmọ Israeli nilà, ni Gibeati-haaralotu. 4 Idí rẹ̀ li eyi ti Joṣua fi kọ wọn nilà: gbogbo awọn enia ti o ti Egipti jade wá, ti o ṣe ọkunrin, ani gbogbo awọn ọmọ-ogun, nwọn kú li aginjù, li ọ̀na, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni Egipti. 5 Nitori gbogbo awọn enia ti o jade ti ibẹ̀ wà, a kọ wọn nilà: ṣugbọn gbogbo awọn enia ti a bi li aginjù li ọ̀na, bi nwọn ti jade kuro ni Egipti, awọn ni a kò kọnilà. 6 Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn li ogoji ọdún li aginjù, titi gbogbo iran na, ani awọn ologun, ti o jade ti Egipti wá fi run, nitoriti nwọn kò gbà ohùn OLUWA gbọ́: awọn ti OLUWA bura fun pe, on ki yio jẹ ki wọn ri ilẹ na, ti OLUWA bura fun awọn baba wọn lati fi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 7 Ati awọn ọmọ wọn, ti o gbé dide ni ipò wọn, awọn ni Joṣua kọnilà: nitoriti nwọn wà li alaikọlà, nitoriti a kò kọ wọn nilà li ọ̀na. 8 O si ṣe, nigbati nwọn kọ gbogbo awọn enia na nilà tán, nwọn joko ni ipò wọn ni ibudó, titi ara wọn fi dá. 9 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni ni mo yi ẹ̀gan Egipti kuro lori nyin. Nitorina li a ṣe npè orukọ ibẹ̀ ni Gilgali titi o fi di oni yi. 10 Awọn ọmọ Israeli si dó ni Gilgali; nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla oṣù li ọjọ́ alẹ, ni pẹtẹlẹ̀ Jeriko. 11 Nwọn si jẹ ọkà gbigbẹ ilẹ na ni ijọ́ keji lẹhin irekọja, àkara alaiwu, ọkà didin li ọjọ̀ na gan. 12 Manna si dá ni ijọ́ keji lẹhin igbati nwọn ti jẹ okà gbigbẹ ilẹ na; awọn ọmọ Israeli kò si ri manna mọ́; ṣugbọn nwọn jẹ eso ilẹ Kenaani li ọdún na.

Joṣua ati Ẹni Tí Ó Mú Idà Lọ́wọ́

13 O si ṣe, nigbati Joṣua wà leti Jeriko, o gbé oju rẹ̀ soke o si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan duro niwaju rẹ̀ pẹlu idà fifayọ li ọwọ́ rẹ̀: Joṣua si tọ̀ ọ lọ, o si wi fun u pe, Ti wa ni iwọ nṣe, tabi ti ọtá wa? 14 O si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn bi olori ogun OLUWA ni mo wá si nisisiyi. Joṣua si wolẹ niwaju rẹ̀, o si foribalẹ, o si wi fun pe, Kili oluwa mi ni isọ fun iranṣẹ rẹ̀? 15 Olori-ogun OLUWA si wi fun Joṣua pe, Bọ́ salubata rẹ kuro li ẹsẹ̀ rẹ; nitoripe ibi ti iwọ gbé duro nì ibi mimọ́ ni. Joṣua si ṣe bẹ̃.

Joṣua 6

Wíwó Odi Jẹriko

1 (NJẸ a há Jeriko mọ́ gága nitori awọn ọmọ Israeli: ẹnikẹni kò jade, ẹnikẹni kò si wọle.) 2 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Wò o, mo ti fi Jeriko lé ọ lọwọ, ati ọba rẹ̀, ati awọn alagbara akọni. 3 Ẹnyin o si ká ilu na mọ́, gbogbo ẹnyin ologun, ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃kan. Bayi ni iwọ o ṣe ni ijọ́ mẹfa. 4 Alufa meje yio gbé ipè jubeli meje niwaju apoti na: ni ijọ́ keje ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃meje, awọn alufa yio si fọn ipè wọnni. 5 Yio si ṣe, nigbati nwọn ba fọn ipè jubeli kikan, nigbati ẹnyin ba si gbọ́ iró ipè na, gbogbo awọn enia yio si hó kũ; odi ilu na yio si wó lulẹ, bẹrẹ, awọn enia yio si gòke lọ tàra, olukuluku niwaju rẹ̀. 6 Joṣua ọmọ Nuni si pè awọn alufa, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki alufa meje ki o gbé ipè jubeli meje nì niwaju apoti OLUWA. 7 O si wi fun awọn enia pe, Ẹ kọja, ki ẹ si yi ilu na ká, ki awọn ti o hamọra ki o si kọja niwaju apoti OLUWA. 8 O si ṣe, nigbati Joṣua wi fun awọn enia tán, awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje, kọja niwaju OLUWA nwọn si fọn ipè wọnni: apoti majẹmu OLUWA si tẹle wọn. 9 Awọn ti o hamọra si lọ niwaju awọn alufa, ti nfọn ipè, ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti lẹhin, awọn alufa nlọ nwọn si nfọn ipè. 10 Joṣua si paṣẹ fun awọn enia wipe, Ẹ kò gbọdọ hó bẹ̃li ẹ kò gbọdọ pariwo, bẹ̃li ọ̀rọ kan kò gbọdọ jade li ẹnu nyin, titi ọjọ́ ti emi o wi fun nyin pe, ẹ hó; nigbana li ẹnyin o hó. 11 Bẹ̃li o mu ki apoti OLUWA ki o yi ilu na ká, o yi i ká lẹ̃kan: nwọn si lọ si ibudó, nwọn si wọ̀ ni ibudó. 12 Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, awọn alufa si gbé apoti OLUWA. 13 Awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje niwaju apoti OLUWA nlọ titi, nwọn si nfọn ipè wọnni: awọn ti o hamọra-ogun nlọ niwaju wọn; ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti OLUWA lẹhin, awọn alufa si nfọn ipè bi nwọn ti nlọ. 14 Li ọjọ́ keji nwọn yi ilu na ká lẹ̃kan, nwọn si pada si ibudó: bẹ̃ni nwọn ṣe ni ijọ́ mẹfa. 15 O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn dide ni kùtukutu li afẹmọjumọ́, nwọn si yi ilu na ká gẹgẹ bi ti iṣaju lẹ̃meje: li ọjọ́ na nikanṣoṣo ni nwọn yi ilu na ká lẹ̃meje. 16 O si ṣe ni ìgba keje, nigbati awọn alufa fọn ipè, ni Joṣua wi fun awọn enia pe, Ẹ hó; nitoriti OLUWA ti fun nyin ni ilu na. 17 Ilu na yio si jẹ́ ìyasọtọ si OLUWA, on ati gbogbo ohun ti mbẹ ninu rẹ̀: kìki Rahabu panṣaga ni yio là, on ati gbogbo awọn ti mbẹ ni ile pẹlu rẹ̀, nitoriti o pa awọn onṣẹ ti a rán mọ́. 18 Ati ẹnyin, bi o ti wù ki o ri, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu ohun ìyasọtọ, ki ẹ má ba yà a sọ̀tọ tán ki ẹ si mú ninu ohun ìyasọtọ na; ẹnyin a si sọ ibudó Israeli di ifibu, ẹnyin a si mu iyọnu bá a. 19 Ṣugbọn gbogbo fadakà, ati wurà, ati ohunèlo idẹ ati ti irin, mimọ́ ni fun OLUWA: nwọn o wá sinu iṣura OLUWA. 20 Bẹ̃li awọn enia na hó, nigbati awọn alufa fọn ipè: o si ṣe, nigbati awọn enia gbọ́ iró ipè, ti awọn enia si hó kũ, odi na wólulẹ bẹrẹ, bẹ̃li awọn enia wọ̀ inu ilu na lọ, olukuluku tàra niwaju rẹ̀, nwọn si kó ilu na. 21 Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ohun ti o wà ni ilu na run, ati ọkunrin ati obinrin, ati ewe ati àgba, ati akọ-mãlu, ati agutan, ati kẹtẹkẹtẹ. 22 Ṣugbọn Joṣua sọ fun awọn ọkunrin meji ti o ti ṣe amí ilẹ na pe, Ẹ lọ si ile panṣaga nì, ki ẹ si mú obinrin na jade nibẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní, gẹgẹ bi ẹnyin ti bura fun u. 23 Awọn ọmọkunrin ti o ṣamí si wọle, nwọn si mú Rahabu jade, ati baba rẹ̀, ati iya rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní, nwọn si mú gbogbo awọn ibatan rẹ̀ jade; nwọn si fi wọn si ẹhin ibudó Israeli. 24 Nwọn si fi iná kun ilu na ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀; kìki fadakà, ati wurà, ati ohunèlo idẹ ati irin, ni nwọn fi sinu iṣura ile OLUWA. 25 Joṣua si gbà Rahabu panṣaga là, ati ara ile baba rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; o si joko lãrin Israeli titi di oni-oloni; nitoriti o pa awọn onṣẹ mọ́ ti Joṣua rán lọ ṣamí Jeriko. 26 Joṣua si gégun li akokò na wipe, Egún ni fun ọkunrin na niwaju OLUWA ti yio dide, ti yio si kọ ilu Jeriko yi: pẹlu ikú akọ́bi rẹ̀ ni yio fi pilẹ rẹ̀, ati pẹlu ikú abikẹhin rẹ̀ ni yio fi gbé ilẹkun ibode rẹ̀ ró. 27 Bẹ̃ni OLUWA wà pẹlu Joṣua; okikí rẹ̀ si kàn ká gbogbo ilẹ na.

Joṣua 7

Ẹ̀ṣẹ̀ Akani

1 ṢUGBỌN awọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ kan niti ohun ìyasọtọ: nitoriti Akani, ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀ya Juda, mú ninu ohun ìyasọtọ: ibinu OLUWA si rú si awọn ọmọ Israeli. 2 Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai. 3 Nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, nwọn si wi fun u pe, Má ṣe jẹ ki gbogbo enia ki o gòke lọ; ṣugbọn jẹ ki ìwọn ẹgba tabi ẹgbẹdogun enia ki o gòke lọ ki nwọn si kọlù Ai; má ṣe jẹ ki gbogbo enia lọ ṣiṣẹ́ nibẹ̀; nitori diẹ ni nwọn. 4 Bẹ̃ni ìwọn ẹgbẹdogun enia gòke lọ sibẹ̀: nwọn si sá niwaju awọn enia Ai. 5 Awọn enia Ai pa enia mẹrindilogoji ninu wọn: nwọn si lepa wọn lati ẹnubode titi dé Ṣebarimu, nwọn si pa wọn bi nwọn ti nsọkalẹ: àiya awọn enia na já, o si di omi. 6 Joṣua si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si dojubolẹ niwaju apoti OLUWA titi di aṣalẹ, on ati awọn àgba Israeli; nwọn si bù ekuru si ori wọn. 7 Joṣua si wipe, Yẽ, Oluwa ỌLỌRUN, nitori kini iwọ fi mú awọn enia yi kọja Jordani, lati fi wa lé ọwọ́ awọn Amori, lati pa wa run? awa iba mọ̀ ki a joko ni ìha keji ọhún Jordani! 8 A, Oluwa, kili emi o wi, nigbati Israeli pa ẹhin wọn dà niwaju awọn ọtá wọn! 9 Nitoriti awọn ara Kenaani ati gbogbo awọn ara ilẹ na yio gbọ́, nwọn o si yi wa ká, nwọn o si ke orukọ wa kuro li aiye: kini iwọ o ha ṣe fun orukọ nla rẹ? 10 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Dide; ẽṣe ti iwọ fi doju rẹ bolẹ bayi? 11 Israeli ti dẹ̀ṣẹ, nwọn si ti bà majẹmu mi jẹ́ ti mo palaṣẹ fun wọn: ani nwọn ti mú ninu ohun ìyasọtọ nì; nwọn si jale, nwọn si ṣe agabagebe pẹlu, ani nwọn si fi i sinu ẹrù wọn. 12 Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin. 13 Dide, yà awọn enia na simimọ́, ki o si wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ fun ọla: nitori bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wipe; Ohun ìyasọtọ kan mbẹ ninu rẹ, iwọ Israeli: iwọ ki yio le duro niwaju awọn ọtá rẹ, titi ẹnyin o fi mú ohun ìyasọtọ na kuro ninu nyin. 14 Nitorina li owurọ̀ a o mú nyin wá gẹgẹ bi ẹ̀ya nyin: yio si ṣe, ẹ̀ya ti OLUWA ba mú yio wá gẹgẹ ni idile idile: ati idile ti OLUWA ba mú yio wá li agbagbole; ati agbole ti OLUWA ba mú yio wá li ọkunrin kọkan. 15 Yio si ṣe, ẹniti a ba mú pẹlu ohun ìyasọtọ na, a o fi iná sun u, on ati ohun gbogbo ti o ní: nitoriti o rú ofin OLUWA, ati nitoriti o si hù ìwakiwa ni Israeli. 16 Bẹ̃ni Joṣua dide ni kùtukutu owurọ̀, o si mú Israeli wá gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; a si mú ẹ̀ya Juda: 17 O si mú idile Juda wá; a si mu idile Sera: o si mú idile Sera wá li ọkunrin kọkan; a si mú Sabdi: 18 O si mú ara ile rẹ̀ li ọkunrin kọkan; a si mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ninu, ẹ̀ya Judah. 19 Joṣua si wi fun Akani pe, Ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, fi ogo fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, ki o si jẹwọ fun u; ki o si sọ fun mi nisisiyi, ohun ti iwọ se; má ṣe pa a mọ́ fun mi. 20 Akani si da Joṣua lohùn, o si wipe, Nitõtọ ni mo ṣẹ̀ si OLUWA, Ọlọrun Israeli, bayi bayi ni mo ṣe: 21 Nigbati mo ri ẹ̀wu Babeli kan daradara ninu ikogun, ati igba ṣekeli fadakà, ati dindi wurà kan oloṣuwọn ãdọta ṣekeli, mo ṣojukokoro wọn, mo si mú wọn; sawò o, a fi wọn pamọ́ ni ilẹ lãrin agọ́ mi, ati fadakà na labẹ rẹ̀. 22 Joṣua si rán onṣẹ, nwọn si sare wọ̀ inu agọ́ na; si kiyesi i, a fi i pamọ́ ninu agọ́ rẹ̀, ati fadakà labẹ rẹ̀. 23 Nwọn si mú wọn jade lãrin agọ́ na, nwọn si mú wọn wá sọdọ Joṣua, ati sọdọ gbogbo awọn ọmọ Israeli, nwọn si fi wọn lelẹ niwaju OLUWA. 24 Joṣua, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si mú Akani ọmọ Sera, ati fadakà na, ati ẹ̀wu na, ati dindi wurà na, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ati akọ-mãlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati agutan rẹ̀, ati agọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; nwọn si mú wọn lọ si ibi afonifoji Akoru. 25 Joṣua si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yọ wa lẹnu? OLUWA yio yọ iwọ na lẹnu li oni yi. Gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta pa; nwọn si dánasun wọn, nwọn sọ wọn li okuta. 26 Nwọn si kó òkiti okuta nla kan lé e lori titi di oni-oloni; OLUWA si yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ibẹ̀ li Afonifoji Akoru, titi di oni-oloni.

Joṣua 8

Gbígbà ati Pípa Ìlú Ai Run

1 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o má ṣe fò ọ: mú gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ ki iwọ ki o si dide, ki o si gòke lọ si Ai: kiyesi i, emi ti fi ọba Ai, ati awọn enia rẹ̀, ati ilunla rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀ lé ọ lọwọ: 2 Iwọ o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀: kìki ikogun rẹ̀, ati ohun-ọ̀sin rẹ̀, li ẹnyin o mú ni ikogun fun ara nyin: rán enia lọ iba lẹhin ilu na. 3 Joṣua si dide, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun, lati gòke lọ si Ai: Joṣua si yàn ẹgba mẹdogun, alagbara akọni, o si rán wọn lo li oru. 4 O si paṣẹ fun wọn pe, Wò o, ẹnyin o ba tì ilu na, ani lẹhin ilu na: ẹ má ṣe jìna pupọ̀ si ilu na, ṣugbọn ki gbogbo nyin ki o murasilẹ. 5 Ati emi, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu mi, yio sunmọ ilu na: yio si ṣe, nigbati nwọn ba jade si wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju, awa o si sá niwaju wọn; 6 Nitoriti nwọn o jade si wa, titi awa o fi fà wọn jade kuro ni ilu; nitoriti nwọn o wipe, Nwọn sá niwaju wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju; nitorina li awa o sá niwaju wọn: 7 Nigbana li ẹnyin o dide ni buba, ẹnyin o si gbà ilu na: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin yio fi i lé nyin lọwọ. 8 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gbà ilu na tán, ki ẹnyin ki o si tinabọ ilu na; gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA ni ki ẹnyin ki o ṣe: wò o, mo ti fi aṣẹ fun nyin na. 9 Nitorina ni Joṣua ṣe rán wọn lọ: nwọn lọ iba, nwọn si joko li agbedemeji Beti-eli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn Ai: ṣugbọn Joṣua dó li oru na lãrin awọn enia. 10 Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si kà awọn enia, o si gòke lọ si Ai, on, ati awọn àgba Israeli niwaju awọn enia. 11 Ati gbogbo awọn enia, ani awọn ọmọ-ogun ti mbẹ pẹlu rẹ̀, nwọn gòke lọ, nwọn si sunmọtosi, nwọn si wá siwaju ilu na, nwọn si dó ni ìha ariwa Ai; afonifoji si mbẹ li agbedemeji wọn ati Ai. 12 O si mú to bi ẹgbẹdọgbọ̀n enia, o si fi wọn si ibuba li agbedemeji Betieli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn ilu na. 13 Nwọn si yàn awọn enia si ipò, ani gbogbo ogun ti mbẹ ni ìha ariwa ilu na, ati awọn enia ti o ba ni ìha ìwọ-õrùn ilu na; Joṣua si lọ li oru na sãrin afonifoji na. 14 O si ṣe, nigbati ọba Ai ri i, nwọn yára nwọn si dide ni kùtukutu, awọn ọkunrin ilu na si jade si Israeli lati jagun, ati on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, niwaju pẹtẹlẹ̀, ibi ti a ti yàn tẹlẹ; ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn ti o ba dè e mbẹ lẹhin ilu. 15 Joṣua ati gbogbo awọn Israeli si ṣe bi ẹniti a lé niwaju wọn, nwọn si sá gbà ọ̀na aginjú. 16 A si pe gbogbo enia ti mbẹ ni Ai jọ lati lepa wọn: nwọn si lepa Joṣua, a si fà wọn jade kuro ni ilu. 17 Kò si kù ọkunrin kan ni Ai tabi Beti-eli, ti kò jade tọ̀ Israeli: nwọn si fi ilú nla silẹ ni ṣíṣí nwọn si lepa Israeli. 18 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Nà ọ̀kọ ti mbẹ li ọwọ́ rẹ nì si Ai; nitoriti emi o fi i lé ọ lọwọ. Joṣua si nà ọ̀kọ na ti o ni li ọwọ́ rẹ̀ si ilu na. 19 Awọn ti o ba si dide kánkan kuro ni ipò wọn, bi o si ti nàwọ́ rẹ̀, nwọn sare, nwọn si wọ̀ ilu na lọ, nwọn si gbà a; nwọn si yára tinabọ ilu na. 20 Nigbati awọn ọkunrin Ai boju wo ẹhin wọn, kiyesi i, nwọn ri ẹ̃fi ilu na ngòke lọ si ọrun, nwọn kò si lí agbara lati gbà ihin tabi ọhún sálọ: awọn enia ti o sá lọ si aginjù si yipada si awọn ti nlepa. 21 Nigbati Joṣua ati gbogbo Israeli ri bi awọn ti o ba ti gbà ilu, ti ẹ̃fi ilu na si gòke, nwọn si yipada, nwọn si pa awọn ọkunrin Ai. 22 Awọn ti ara keji si yọ si wọn lati ilu na wá; bẹ̃ni nwọn wà li agbedemeji Israeli, awọn miran li apa ihin, awọn miran li apa ọhún: nwọn si pa wọn, bẹ̃ni nwọn kò si jẹ ki ọkan ki o kù tabi ki o sálọ ninu wọn. 23 Nwọn si mú ọba Ai lãye, nwọn si mú u wá sọdọ Joṣua. 24 O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u. 25 O si ṣe, gbogbo awọn ti o ṣubu ni ijọ́ na, ati ọkunrin ati obinrin, jẹ́ ẹgba mẹfa, ani gbogbo ọkunrin Ai. 26 Nitoriti Joṣua kò fà ọwọ́ rẹ̀ ti o fi nà ọ̀kọ sẹhin, titi o fi run gbogbo awọn ara ilu Ai tútu. 27 Kìki ohun-ọ̀sin ati ikogun ilu na ni Israeli kó fun ara wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA ti o palaṣẹ fun Joṣua. 28 Joṣua si kun Ai, o sọ ọ di òkiti lailai, ani ahoro titi di oni-oloni. 29 Ọba Ai li o si so rọ̀ lori igi titi di aṣalẹ: bi õrùn si ti wọ̀, Joṣua paṣẹ ki a sọ okú rẹ̀ kuro lori igi kalẹ, ki a si wọ́ ọ jù si atiwọ̀ ibode ilu na, ki a si kó òkiti nla okuta lé e lori, ti mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.

Joṣua Ka Òfin ní Òkè Ebali

30 Nigbana ni Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, li òke Ebali, 31 Gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwé ofin Mose, pẹpẹ odidi okuta, lara eyiti ẹnikan kò fi irin kan: nwọn si ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA, nwọn si ru ẹbọ alafia. 32 O si kọ apẹrẹ ofin Mose sara okuta na, ti o kọ niwaju awọn ọmọ Israeli. 33 Ati gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori, ati awọn onidajọ wọn, duro li apa ihin ati li apa ọhún apoti ẹrí niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti o rù apoti majẹmu OLUWA, ati alejò ati ibilẹ; àbọ wọn kọjusi òke Gerisimu; ati àbọ wọn kọjusi òke Ebali, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ rí, pe ki nwọn ki o sure fun awọn enia Israeli. 34 Lẹhin eyi o si kà gbogbo ọ̀rọ ofin, ibukún ati egún, gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ ninu iwé ofin. 35 Kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo eyiti Mose palaṣẹ, ti Joṣua kò kà niwaju gbogbo ijọ Israeli, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹrẹ, ati awọn alejò ti nrìn lãrin wọn.

Joṣua 9

Àwọn Ará Gibeoni Tan Joṣua Jẹ

1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba ti mbẹ li apa ihin Jordani, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni gbogbo àgbegbe okun nla ti o kọjusi Lebanoni, awọn Hitti, ati awọn Amori, awọn Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi, gbọ́ ọ; 2 Nwọn si kó ara wọn jọ, lati fi ìmọ kan bá Joṣua ati Israeli jà. 3 Ṣugbọn nigbati awọn ara Gibeoni gbọ́ ohun ti Joṣua ṣe si Jeriko ati si Ai, 4 Nwọn ṣe ẹ̀tan, nwọn si lọ nwọn si ṣe bi ẹnipe onṣẹ ni nwọn, nwọn si mú ogbologbo àpo kà ori kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ìgo-awọ ọti-waini ti lailai, ti o ya, ti a si dì; 5 Ati bàta gbigbo ati lilẹ̀ li ẹsẹ̀ wọn, ati ẹ̀wu gbigbo li ara wọn; ati gbogbo àkara èse wọn o gbẹ o si hùkasi. 6 Nwọn si tọ̀ Joṣua lọ ni ibudó ni Gilgali, nwọn si wi fun u, ati fun awọn ọkunrin Israeli pe, Ilu òkere li awa ti wá; njẹ nitorina ẹ bá wa dá majẹmu. 7 Awọn ọkunrin Israeli si wi fun awọn Hifi pe, Bọya ẹnyin ngbé ãrin wa; awa o ti ṣe bá nyin dá majẹmu? 8 Nwọn si wi fun Joṣua pe, Iranṣẹ rẹ li awa iṣe. Joṣua si wi fun wọn pe, Tali ẹnyin? nibo li ẹnyin si ti wá? 9 Nwọn si wi fun u pe, Ni ilu òkere rére li awọn iranṣẹ rẹ ti wá, nitori orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoriti awa ti gbọ́ okikí rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ṣe ni Egipti, 10 Ati ohun gbogbo ti o ṣe si awọn ọba awọn Amori meji, ti mbẹ ni òke Jordani, si Sihoni ọba Heṣboni, ati si Ogu ọba Baṣani, ti mbẹ ni Aṣtarotu. 11 Awọn àgba wa ati gbogbo awọn ara ilu wa sọ fun wa pe, Ẹ mú onjẹ li ọwọ́ nyin fun àjo na, ki ẹ si lọ ipade wọn, ki ẹ si wi fun wọn pe, Iranṣẹ nyin li awa iṣe: njẹ nitorina, ẹ bá wa dá majẹmu. 12 Àkara wa yi ni gbigbona li a mú u fun èse wa, lati ile wa wá, li ọjọ́ ti a jade lati tọ̀ nyin wá; ṣugbọn nisisiyi, kiyesi i, o gbẹ, o si bu: 13 Ìgo-awọ waini wọnyi, ti awa kún, titun ni nwọn; kiyesi i, nwọn fàya: ati ẹ̀wu wa wọnyi ati bàta wa di gbigbo nitori ọ̀na ti o jìn jù. 14 Awọn ọkunrin si gbà ninu onjẹ wọn, nwọn kò si bère li ẹnu OLUWA. 15 Joṣua si bá wọn ṣọrẹ, o si bá wọn dá majẹmu lati da wọn si: awọn olori ijọ enia fi OLUWA Ọlọrun Israeli bura fun wọn. 16 O si ṣe li opin ijọ́ mẹta, lẹhin ìgbati nwọn bá wọn dá majẹmu, ni nwọn gbọ́ pe aladugbo wọn ni nwọn, ati pe làrin wọn ni nwọn gbé wà. 17 Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si dé ilu wọn ni ijọ́ kẹta. Njẹ ilu wọn ni Gibeoni, ati Kefira, ati Beerotu, ati Kiriati-jearimu. 18 Awọn ọmọ Israeli kò pa wọn, nitoriti awọn olori ijọ awọn enia ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn. Gbogbo ijọ awọn enia si kùn si awọn olori. 19 Ṣugbọn gbogbo awọn olori wi fun gbogbo ijọ pe, Awa ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn: njẹ nitorina awa kò le fọwọkàn wọn. 20 Eyi li awa o ṣe si wọn, ani awa o da wọn si, ki ibinu ki o má ba wà lori wa, nitori ibura ti a bura fun wọn. 21 Awọn olori si wi fun wọn pe, Ẹ da wọn si: nwọn si di aṣẹ́gi ati apọnmi fun gbogbo ijọ; gẹgẹ bi awọn olori ti sọ fun wọn. 22 Joṣua si pè wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi tàn wa wipe, Awa jìna rére si nyin; nigbati o jẹ́ pe lãrin wa li ẹnyin ngbé? 23 Njẹ nitorina ẹnyin di ẹni egún, ẹrú li ẹnyin o si ma jẹ́ titi, ati aṣẹ́gi ati apọnmi fun ile Ọlọrun mi. 24 Nwọn si da Joṣua lohùn wipe, Nitoriti a sọ fun awọn iranṣẹ rẹ dajudaju, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, lati fun nyin ni gbogbo ilẹ na, ati lati pa gbogbo awọn ara ilẹ na run kuro niwaju nyin; nitorina awa bẹ̀ru nyin gidigidi nitori ẹmi wa, a si ṣe nkan yi. 25 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, li ọwọ́ rẹ li awa wà: bi o ti dara si ati bi o ti tọ́ si li oju rẹ lati ṣe wa, ni ki iwọ ki o ṣe. 26 Bẹ̃li o si ṣe wọn, o si gbà wọn li ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si pa wọn. 27 Joṣua si ṣe wọn li aṣẹ́gi ati apọnmi fun ijọ, ati fun pẹpẹ OLUWA li ọjọ́ na, ani titi di oni-oloni, ni ibi ti o ba yàn.

Joṣua 10

Wọ́n Ṣẹgun Àwọn Ará Amori

1 O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn; 2 Nwọn bẹ̀ru pipọ̀, nitoriti Gibeoni ṣe ilu nla, bi ọkan ninu awọn ilu ọba, ati nitoriti o tobi jù Ai lọ, ati gbogbo ọkunrin inu rẹ̀ jẹ́ alagbara. 3 Nitorina Adoni-sedeki ọba Jerusalemu ranṣẹ si Hohamu ọba Hebroni, ati si Piramu ọba Jarmutu, ati si Jafia ọba Lakiṣi, ati si Debiri ọba Egloni, wipe, 4 Ẹ gòke tọ̀ mi wá, ki ẹ si ràn mi lọwọ, ki awa ki o le kọlù Gibeoni: nitoriti o bá Joṣua ati awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ. 5 Awọn ọba Amori mararun, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni, kó ara wọn jọ, nwọn si gòke, awọn ati gbogbo ogun wọn, nwọn si dótì Gibeoni, nwọn si fi ìja fun u. 6 Awọn ọkunrin Gibeoni si ranṣẹ si Joṣua ni ibudó ni Gilgali, wipe, Má ṣe fà ọwọ́ rẹ sẹhin kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ; gòke tọ̀ wa wá kánkán, ki o si gbà wa, ki o si ràn wa lọwọ: nitoriti gbogbo awọn ọba Amori ti ngbé ori òke kójọ pọ̀ si wa. 7 Bẹ̃ni Joṣua gòke lati Gilgali lọ, on ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn alagbara akọni. 8 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru wọn: nitoriti mo ti fi wọn lé ọ lọwọ; ki yio sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ. 9 Joṣua si yọ si wọn lojijì; o si gòke lati Gilgali lọ ni gbogbo oru na. 10 OLUWA si fọ́ wọn niwaju Israeli, o si pa wọn ni ipakupa ni Gibeoni, o si lepa wọn li ọ̀na òke Beti-horoni, o si pa wọn dé Aseka, ati dé Makkeda. 11 O si ṣe, bi nwọn ti nsá niwaju Israeli, ti nwọn dé gẹrẹgẹrẹ Beti-horoni, OLUWA rọ̀ yinyin nla si wọn lati ọrun wá titi dé Aseka, nwọn si kú: awọn ti o ti ipa yinyin kú, o pọ̀ju awọn ti awọn ọmọ Israeli fi idà pa lọ. 12 Nigbana ni Joṣua wi fun OLUWA li ọjọ́ ti OLUWA fi awọn Amori fun awọn ọmọ Israeli, o si wi li oju Israeli pe, Iwọ, Õrùn, duro jẹ lori Gibeoni; ati Iwọ, Oṣupa, li afonifoji Aijaloni. 13 Õrùn si duro jẹ, oṣupa si duro, titi awọn enia fi gbẹsan lara awọn ọtá wọn. A kò ha kọ eyi nã sinu iwé Jaṣeri? Bẹ̃li õrùn duro li agbedemeji ọrun, kò si yára lati wọ̀ nìwọn ọjọ́ kan tọ̀tọ. 14 Kò sí ọjọ́ ti o dabi rẹ̀ ṣaju rẹ̀ tabi lẹhin rẹ̀, ti OLUWA gbọ́ ohùn enia: nitoriti OLUWA jà fun Israeli. 15 Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.

Joṣua Fi Ogun Kó Àwọn Ọba Amori Maraarun

16 Ṣugbọn awọn ọba marun nì sá, nwọn si fara wọn pamọ́ ni ihò kan ni Makkeda. 17 A si sọ fun Joṣua pe, A ri awọn ọba marun ni ifarapamọ́ ni ihò ni Makkeda. 18 Joṣua si wipe, Ẹ yí okuta nla di ẹnu ihò na, ki ẹ si yàn enia sibẹ̀ lati ṣọ́ wọn: 19 Ṣugbọn ẹnyin, ẹ má ṣe duro, ẹ lepa awọn ọtá nyin, ki ẹ si kọlù wọn lẹhin; ẹ máṣe jẹ ki nwọn ki o wọ̀ ilu wọn lọ: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi wọn lé nyin lọwọ. 20 O si ṣe, nigbati Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa wọn ni ipakupa tán, titi a fi run wọn, ti awọn ti o kù ninu wọn wọ̀ inu ilu olodi lọ, 21 Gbogbo enia si pada si ibudó sọdọ Joṣua ni Makkeda li alafia: kò sí ẹni kan ti o yọ ahọn rẹ̀ si awọn ọmọ Israeli. 22 Nigbana ni Joṣua wipe, Ẹ ṣi ẹnu ihò na, ki ẹ si mú awọn ọba mararun na jade kuro ninu ihò tọ̀ mi wá. 23 Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mú awọn ọba mararun nì jade lati inu ihò na tọ̀ ọ wá, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni. 24 O si ṣe, nigbati nwọn mú awọn ọba na tọ̀ Joṣua wá, ni Joṣua pè gbogbo awọn ọkunrin Israeli, o si wi fun awọn olori awọn ọmọ-ogun ti o bá a lọ pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ si fi ẹsẹ̀ nyin lé ọrùn awọn ọba wọnyi. Nwọn si sunmọ wọn, nwọn si gbé ẹsẹ̀ wọn lé wọn li ọrùn. 25 Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ má ṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya; ẹ ṣe giri, ki ẹ si mu àiya le: nitoripe bayi li OLUWA yio ṣe si awọn ọtá nyin gbogbo ti ẹnyin mbájà. 26 Lẹhin na ni Joṣua si kọlù wọn, o si pa wọn, o si so wọn rọ̀ lori igi marun: nwọn si sorọ̀ lori igi titi di aṣalẹ. 27 O si ṣe li akokò ìwọ-õrùn, Joṣua paṣẹ, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ kuro lori igi, nwọn si gbé wọn sọ sinu ihò na ninu eyiti nwọn ti sapamọ́ si, nwọn si fi okuta nla di ẹnu ihò na, ti o wà titi di oni-oloni.

Joṣua Tún Gba Àwọn Ìlú Amori Mìíràn Sí i

28 Li ọjọ́ na ni Joṣua kó Makkeda, o si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀; o pa wọn run patapata, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, kò kù ẹnikan silẹ: o si ṣe si ọba Makkeda gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko. 29 Joṣua si kọja lati Makkeda lọ si Libna, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si fi ijà fun Libna: 30 OLUWA si fi i lé Israeli lọwọ pẹlu, ati ọba rẹ̀: o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù ẹnikan ninu rẹ̀; o si ṣe si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko. 31 Joṣua si kọja lati Libna lọ si Lakiṣi, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si dótì i, o si fi ìja fun u. 32 OLUWA si fi Lakiṣi lé Israeli lọwọ, o si kó o ni ijọ́ keji, o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Libna. 33 Nigbana ni Horamu ọba Geseri gòke lati ràn Lakiṣi lọwọ; Joṣua si kọlù u ati awọn enia rẹ̀, tobẹ̃ ti kò fi kù ẹnikan silẹ fun u. 34 Lati Lakiṣi Joṣua kọja lọ si Egloni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si dótì i, nwọn si fi ijà fun u; 35 Nwọn si kó o li ọjọ́ na, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ li o parun patapata li ọjọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Lakiṣi. 36 Joṣua si gòke lati Egloni lọ si Hebroni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si fi ijà fun u: 37 Nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù enikan silẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Egloni; o si pa a run patapata, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀. 38 Joṣua si pada lọ si Debiri, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; o si fi ijà fun u: 39 O si kó o, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀; nwọn si fi oju idà kọlù wọn; nwọn si pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ run patapata; kò si kù ẹnikan silẹ: gẹgẹ bi o ti ṣe si Hebroni, bẹ̃li o ṣe si Debiri, ati ọba rẹ̀; ati gẹgẹ bi o ti ṣe si Libna, ati ọba rẹ̀. 40 Bẹ̃ni Joṣua kọlù gbogbo ilẹ, ilẹ òke, ati ti Gusù, ati ti pẹtẹlẹ̀, ati ti ẹsẹ̀-òke, ati awọn ọba wọn gbogbo; kò kù ẹnikan silẹ: ṣugbọn o pa ohun gbogbo ti nmí run patapata, gẹgẹ bi OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti pa a laṣẹ. 41 Joṣua si kọlù wọn lati Kadeṣi-barnea lọ titi dé Gasa, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ani titi dé Gibeoni. 42 Ati gbogbo awọn ọba wọnyi ati ilẹ wọn, ni Joṣua kó ni ìgba kanna, nitoriti OLUWA, Ọlọrun Israeli, jà fun Israeli. 43 Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.

Joṣua 11

Joṣua Ṣẹgun Jabini ati Àwọn tí Wọ́n Darapọ̀ Mọ́ ọn

1 O si ṣe, nigbati Jabini ọba Hasoru gbọ́ nkan wọnyi, o ranṣẹ si Jobabu ọba Madoni, ati si ọba Ṣimroni, ati si ọba Akṣafu, 2 Ati si awọn ọba ti mbẹ ni ìha ariwa, lori òke, ati ti pẹtẹlẹ̀ ni ìha gusù ti Kinnerotu, ati ni ilẹ titẹju, ati ni ilẹ òke Doru ni ìha ìwọ-õrùn, 3 Ati si awọn ara Kenaani ni ìha ìla-õrùn ati ni ìha ìwọ-õrùn, ati awọn Amori, ati si awọn Hitti, ati si awọn Perissi, ati si awọn Jebusi lori òke, ati si awọn Hifi nisalẹ Hermoni ni ilẹ Mispa. 4 Nwọn si jade, awọn ati gbogbo ogun wọn pẹlu wọn, ọ̀pọlọpọ enia, bi yanrin ti mbẹ li eti okun fun ọ̀pọ, ati ẹṣin ati kẹkẹ́ pipọ̀pipọ. 5 Gbogbo awọn ọba wọnyi si pejọ pọ̀, nwọn wá nwọn si dó ṣọkan ni ibi omi Meromu, lati fi ijà fun Israeli. 6 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru nitori wọn: nitori li ọla li akokò yi emi o fi gbogbo wọn tọrẹ niwaju Israeli ni pipa: iwọ o já patì ẹṣin wọn, iwọ o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn. 7 Bẹ̃ni Joṣua, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, yọ si wọn lojijì ni ibi omi Meromu, nwọn si kọlù wọn. 8 OLUWA si fi wọn lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn, nwọn si lé wọn titi dé Sidoni nla ati titi dé Misrefoti-maimu, ati dé afonifoji Mispa ni ìha ìla-õrùn; nwọn si pa wọn tobẹ̃ ti kò kù ẹnikan silẹ fun wọn. 9 Joṣua si ṣe si wọn gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o já patì ẹṣin wọn, o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn. 10 Joṣua si pada li akokò na, o si kó Hasoru, o si fi idà pa ọba rẹ̀: nitori li atijọ́ rí Hasoru li olori gbogbo ilẹ-ọba wọnni. 11 Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, nwọn run wọn patapata: a kò kù ẹnikan ti nmí silẹ: o si fi iná kun Hasoru. 12 Ati gbogbo ilu awọn ọba wọnni, ati gbogbo ọba wọn, ni Joṣua kó, o si fi oju idà kọlù wọn, o si pa wọn run patapata, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti palaṣẹ. 13 Ṣugbọn awọn ilu ti o duro lori òke wọn, Israeli kò sun ọkan ninu wọn, bikoṣe Hasoru nikan; eyi ni Joṣua fi iná sun. 14 Ati gbogbo ikogun ilu wonyi, ati ohunọ̀sin, ni awọn ọmọ Israeli kó fun ara wọn; ṣugbọn gbogbo awọn ọkunrin ni nwọn fi oju kọlù, titi nwọn fi pa wọn run, nwọn kò kù ẹnikan silẹ ti nmí. 15 Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, bẹ̃ni Mose paṣẹ fun Joṣua: bẹ̃ni Joṣua si ṣe; on kò kù ohun kan silẹ ninu gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ fun Mose.

Àwọn Ilẹ̀ Tí Joṣua Gbà

16 Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, ilẹ òke, ati gbogbo ilẹ Gusù, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ati ilẹ titẹju, ati pẹtẹlẹ̀, ati ilẹ òke Israeli, ati ilẹ titẹju rẹ̀; 17 Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn. 18 Joṣua si bá gbogbo awọn ọba wọnni jagun li ọjọ́ pipọ̀. 19 Kò sí ilu kan ti o bá awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ, bikoṣe awọn Hifi awọn ara ilu Gibeoni: gbogbo wọn ni nwọn fi ogun gbà. 20 Nitori lati ọdọ OLUWA li a ti mu ọkàn wọn le, ki nwọn ki o le jade ogun tọ̀ Israeli wá, ki o le pa wọn run patapata, ki nwọn ki o má si ṣe ri ojurere, ṣugbọn ki o le pa wọn run, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 21 Li akokò na ni Joṣua wá, ti o si ke awọn ọmọ Anaki kuro ni ilẹ òke, kuro ni Hebroni, kuro ni Debiri, kuro ni Anabu, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Juda, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Israeli: Joṣua run wọn patapata pẹlu ilu wọn. 22 Kò kù ẹnikan ninu awọn ọmọ Anaki ni ilẹ awọn ọmọ Israeli: bikoṣe ni Gasa, ni Gati, ati ni Aṣdodu, ni nwọn kù si. 23 Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti OLUWA ti wi fun Mose; Joṣua si fi i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi ipín wọn nipa ẹ̀ya wọn. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.

Joṣua 12

Àwọn Ọba Tí Mose Ṣẹgun

1 NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun: 2 Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni; 3 Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga: 4 Ati àgbegbe Ogu ọba Baṣani, ọkan ninu awọn ti o kù ninu awọn Refaimu, èniti ngbé Aṣtarotu ati Edrei, 5 O si jọba li òke Hermoni, ati ni Saleka, ati ni gbogbo Baṣani, titi o fi dé àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati àbọ Gileadi, àla Sihoni ọba Heṣboni. 6 Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.

Àwọn Ọba Tí Joṣua Ṣẹgun

7 Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn. 8 Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: 9 Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan. 10 Ọba Jerusalemu, ọkan; ọba Hebroni, ọkan; 11 Ọba Jarmutu, ọkan; ọba Lakiṣi, ọkan; 12 Ọba Egloni, ọkan; ọba Geseri, ọkan; 13 Ọba Debiri, ọkan; ọba Gederi, ọkan; 14 Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan; 15 Ọba Libna, ọkan; ọba Adullamu, ọkan; 16 Ọba Makkeda, ọkan; ọba Betieli, ọkan; 17 Ọba Tappua, ọkan; ọba Heferi, ọkan; 18 Ọba Afeki, ọkan; ọba Laṣaroni, ọkan; 19 Ọba Madoni, ọkan; ọba Hasoru, ọkan; 20 Ọba Ṣimroni-meroni, ọkan; ọba Akṣafu, ọkan; 21 Ọba Taanaki, ọkan; ọba Megiddo, ọkan; 22 Ọba Kedeṣi, ọkan; ọba Jokneamu ti Karmeli, ọkan; 23 Ọba Doru, li òke Doru, ọkan; ọba awọn orilẹ-ède Gilgali, ọkan; 24 Ọba Tirsa, ọkan; gbogbo awọn ọba na jẹ́ mọkanlelọgbọ̀n.

Joṣua 13

Ilẹ̀ Tí Ó kù láti Gbà

1 JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà. 2 Eyi ni ilẹ ti o kù; gbogbo ilẹ awọn Filistini, ati gbogbo Geṣuri; 3 Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù: 4 Gbogbo ilẹ awọn ara Kenaani, ati Meara ti awọn ara Sidoni, dé Afeki, titi dé àgbegbe awọn Amori: 5 Ati ilẹ awọn Gebali, ati gbogbo Lebanoni ni ìha ìla-õrùn, lati Baali-gadi nisalẹ òke Hermoni titi o fi dé atiwọ̀ Hamati: 6 Gbogbo awọn ara ilẹ òke lati Lebanoni titi dé Misrefoti-maimu, ani gbogbo awọn ara Sidoni; awọn li emi o lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli: kìki ki iwọ ki o fi keké pín i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun ọ. 7 Njẹ nitorina pín ilẹ yi ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.

Pípín Agbègbè Tí Ó Wà ní Ìlà Oòrùn Odò Jọrdani

8 Pẹlu rẹ̀ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ti gbà ilẹ-iní wọn, ti Mose fi fun wọn ni ìha keji Jordani ni ìha ìla õrùn, bi Mose iranṣẹ OLUWA ti fi fun wọn; 9 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji na, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ Medeba titi dé Diboni; 10 Ati gbogbo ilu Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, titi dé àgbegbe awọn ọmọ Ammoni: 11 Ati Gileadi, ati àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati gbogbo òke Hermoni, ati gbogbo Baṣani dé Saleka; 12 Gbogbo ilẹ ọba Ogu ni Baṣani, ti o jọba ni Aṣtarotu ati ni Edrei, ẹniti o kù ninu awọn Refaimu iyokù: nitori awọn wọnyi ni Mose kọlù, ti o si lé jade. 13 Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli kò lé awọn Geṣuri, tabi awọn Maakati jade: ṣugbọn awọn Geṣuri ati awọn Maakati ngbé ãrin awọn ọmọ Israeli titi di oni. 14 Kìki ẹ̀ya Lefi ni on kò fi ilẹ-iní fun; ẹbọ OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti a fi iná ṣe ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Reubẹni

15 Mose si fi fun ẹ̀ya awọn ọmọ Reubeni, gẹgẹ bi idile wọn. 16 Àla wọn bẹ̀rẹ lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji nì, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ti mbẹ ni ìha Medeba; 17 Heṣboni, ati gbogbo ilu rẹ̀ ti mbẹ ni pẹtẹlẹ̀; Diboni, ati Bamoti-baali, ati Beti-baali-meoni; 18 Ati Jahasa, ati Kedemoti, ati Mefaati; 19 Ati Kiriataimu, ati Sibma, ati Sareti-ṣahari ni òke afonifoji na; 20 Ati Beti-peori, ati orisun Pisga, ati Beti-jeṣimotu; 21 Ati gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, ti Mose kọlù pẹlu awọn ọmọ alade Midiani, Efi, ati Rekemu, ati Suri, ati Huri, ati Reba, awọn ọmọ alade Sihoni, ti ngbé ilẹ na. 22 Ati Balaamu ọmọ Beori, alafọṣẹ, ni awọn ọmọ Israeli fi idà pa pẹlu awọn ti nwọn pa. 23 Ati àla awọn ọmọ Reubeni ni Jordani, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni ilẹ iní awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi idile wọn, awọn ilu ati ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Gadi

24 Mose si fi ilẹ fun ẹ̀ya Gadi, ani fun awọn ọmọ Gadi, gẹgẹ bi idile wọn. 25 Àla wọn bẹ̀rẹ ni Jaseri, ati gbogbo ilu Gileadi, ati àbọ ilẹ awọn ọmọ Ammoni, titi dé Aroeri ti mbẹ niwaju Rabba; 26 Ati lati Heṣboni titi dé Ramatu-mispe, ati Betonimu; ati lati Mahanaimu titi dé àgbegbe Debiri; 27 Ati ni afonifoji, Beti-haramu, ati Beti-nimra, ati Sukkotu, ati Safoni, iyokù ilẹ-ọba Sihoni ọba Heṣboni, Jordani ati àgbegbe rẹ̀, titi dé ìha opín okun Kinnereti ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn. 28 Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọn ati ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Manase ní ìlà Oòrùn

29 Mose si fi ilẹ-iní fun àbọ ẹ̀ya Manasse: o si jẹ́ ti àbọ ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse gẹgẹ bi idile wọn. 30 Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Mahanaimu lọ, gbogbo Baṣani, gbogbo ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani, ati gbogbo ilu Jairi, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu: 31 Ati àbọ Gileadi, ati Aṣtarotu, ati Edrei, ilu ilẹ-ọba Ogu ni Baṣani, jẹ́ ti awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ani ti àbọ awọn ọmọ Makiri, gẹgẹ bi idile wọn. 32 Wọnyi li awọn ilẹ-iní na ti Mose pín ni iní ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, li apa keji Jordani, lẹba Jeriko ni ìha ìla-õrùn. 33 Ṣugbọn ẹ̀ya Lefi ni Mose kò fi ilẹ-iní fun: OLUWA, Ọlọrun Israeli, ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.

Joṣua 14

Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Wà Ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn Odò Jọrdani

1 WỌNYI si ni ilẹ-iní ti awọn ọmọ Israeli gbà ni iní ni ilẹ Kenaani, ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli pín fun wọn, 2 Keké ni nwọn fi ní ilẹ-iní wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá, fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya ni. 3 Nitori Mose ti fi ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya meji ati àbọ ẹ̀ya li apa keji Jordani: ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni on kò fi ilẹ-iní fun lãrin wọn. 4 Nitoripe ẹ̀ya meji ni ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu: nitorina nwọn kò si fi ipín fun awọn ọmọ Lefi ni ilẹ na, bikoṣe ilu lati ma gbé, pẹlu àgbegbe ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn ati ohun-iní wọn. 5 Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni awọn ọmọ Israeli ṣe, nwọn si pín ilẹ na.

Wọ́n fún Kalebu ní Hebroni

6 Nigbana ni awọn ọmọ Juda wá sọdọ Joṣua ni Gilgali: Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ ohun ti OLUWA wi fun Mose enia Ọlọrun nipa temi tirẹ ni Kadeṣi-barnea. 7 Ẹni ogoji ọdún ni mi nigbati Mose iranṣẹ OLUWA rán mi lati Kadeṣi-barnea lọ ṣamí ilẹ na; mo si mú ìhin fun u wá gẹgẹ bi o ti wà li ọkàn mi. 8 Ṣugbọn awọn arakunrin mi ti o gòke lọ já awọn enia li àiya: ṣugbọn emi tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata. 9 Mose si bura li ọjọ́ na wipe, Nitõtọ ilẹ ti ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ nì, ilẹ-iní rẹ ni yio jẹ́, ati ti awọn ọmọ rẹ lailai, nitoriti iwọ tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata. 10 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, OLUWA da mi si gẹgẹ bi o ti wi, lati ọdún marunlelogoji yi wá, lati ìgba ti OLUWA ti sọ ọ̀rọ yi fun Mose, nigbati Israeli nrìn kiri li aginjù: si kiyesi i nisisiyi, emi di ẹni arundilãdọrun ọdún li oni. 11 Sibẹ̀ emi lí agbara li oni gẹgẹ bi mo ti ní li ọjọ́ ti Mose rán mi lọ: gẹgẹ bi agbara mi ti ri nigbana, ani bẹ̃li agbara mi ri nisisiyi, fun ogun, ati lati jade ati lati wọle. 12 Njẹ nitorina fi òke yi fun mi, eyiti OLUWA wi li ọjọ́ na; nitoriti iwọ gbọ́ li ọjọ́ na bi awọn ọmọ Anaki ti wà nibẹ̀, ati ilu ti o tobi, ti o si ṣe olodi: bọya OLUWA yio wà pẹlu mi, emi o si lé wọn jade, gẹgẹ bi OLUWA ti wi. 13 Joṣua si sure fun u; o si fi Hebroni fun Kalebu ọmọ Jefunne ni ilẹ-iní. 14 Nitorina Hebroni di ilẹ-iní Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi titi di oni-oloni; nitoriti o tọ̀ OLUWA Ọlọrun Israeli lẹhin patapata. 15 Orukọ Hebroni lailai rí a ma jẹ́ Kiriati-arba; Arba jẹ́ enia nla kan ninu awọn ọmọ Anaki. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.

Joṣua 15

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Juda

1 ILẸ ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn si dé àgbegbe Edomu, ni aginjù Sini, ni ìha gusù, ni apa ipẹkun gusù. 2 Ati àla gusù wọn ni lati eti Okun Iyọ̀ lọ, lati ibi kọ̀rọ omi nì lọ ti o dojukọ ìha gusù: 3 O si lọ si apa gusù òke Akrabbimu, o si lọ si Sini, o si gòke lọ ni ìha gusù Kadeṣi-barnea, o si lọ ni ìha Hesroni, o si gòke lọ si Adari, o si yiká lọ dé Karka: 4 Lati ibẹ̀ o lọ dé Asmoni, o si nà lọ si odò Egipti; opín ilẹ na si yọ si okun: eyi ni yio jẹ́ àla ni gusù nyin. 5 Ati àla ìha ìla-õrùn ni Okun Iyọ̀, ani titi dé ipẹkun Jordani. Ati àla apa ariwa ni lati kọ̀rọ okun nì wá dé ipẹkun Jordani: 6 Àla na si gòke lọ si Beti-hogla, o si kọja lọ ni ìha ariwa Beti-araba; àla na si gòke lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni: 7 Àla na si gòke lọ si Debiri lati afonifoji Akoru, ati bẹ̃ lọ si ìha ariwa, ti o dojukọ Gilgali, ti mbẹ niwaju òke Adummimu, ti mbẹ ni ìha gusù odò na: àla si kọja si apa omi Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Eni-rogeli: 8 Àla na si gòke lọ si ìha afonifoji ọmọ Hinnomu si ìha gusù ti Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): àla na si gòke lọ si ori òke nla ti mbẹ niwaju afonifoji Hinnomu ni ìha ìwọ-õrùn, ti mbẹ ni ipẹkun afonifoji Refaimu ni ìha ariwa: 9 A si fà àla na lati ori òke lọ si isun omi Neftoa, o si nà lọ si ilu òke Efroni; a si fà àla na lọ si Baala, (ti iṣe Kirjati-jearimu:) 10 Àla na yi lati Baala lọ si ìha ìwọ-õrùn si òke Seiri, o si kọja lọ si ẹba òke Jearimu (ti ṣe Kesaloni), ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Beti-ṣemeṣi, o si kọja lọ si Timna: 11 Àla na si kọja lọ si ẹba Ekroni si ìha ariwa: a si fà àla na lọ dé Ṣikroni, o si kọja lọ si òke Baala, o si yọ si Jabneeli; àla na si yọ si okun. 12 Àla ìwọ-õrùn si dé okun nla, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni àla awọn ọmọ Juda yiká kiri gẹgẹ bi idile wọn.

Kalebu Ṣẹgun Heburoni ati Debiri

13 Ati fun Kalebu ọmọ Jefunne li o fi ipín fun lãrin awọn ọmọ Juda, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA fun Joṣua, ani Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni); Arba si ni baba Anaki. 14 Kalebu si lé awọn ọmọ Anaki mẹta kuro nibẹ̀, Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki. 15 O si gòke lati ibẹ̀ tọ̀ awọn ara Debiri lọ: orukọ Debiri lailai rí ni Kiriati-seferi. 16 Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o sì kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya. 17 Otnieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya. 18 O si ṣe, bi Aksa ti dé ọdọ rẹ̀, o mu u bère ọ̀rọ kan lọwọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́? 19 On si dahùn pe, Ta mi li ọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fun mi ni isun omi pẹlu. O si fi isun òke ati isun isalẹ fun u.

Àwọn Ìlú Ńláńlá Tí Wọ́n Wà ní Juda

20 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn. 21 Ilu ipẹkun ẹ̀ya awọn ọmọ Juda li àgbegbe Edomu ni Gusù ni Kabseeli, ati Ederi, ati Jaguri; 22 Ati Kina, ati Dimona, ati Adada; 23 Ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Itnani; 24 Sifu, ati Telemu, ati Bealotu; 25 Ati Haṣori-hadatta, ati Keriotu-hesroni (ti iṣe Hasori); 26 Amamu, ati Ṣema, ati Molada; 27 Ati Hasari-gada, ati Heṣmoni, ati Beti-peleti; 28 Ati Hasari-ṣuali, ati Beeri-ṣeba, ati Bisi-otia; 29 Baala, ati Iimu, ati Esemu; 30 Ati Eltoladi, ati Kesili, ati Horma; 31 Ati Siklagi, ati Madmanna, ati Sansanna; 32 Ati Lebaotu, ati Ṣilhimu, ati Aini, ati Rimmoni: gbogbo ilu na jasi mọkandilọgbọ̀n, pẹlu ileto wọn. 33 Ni pẹtẹlẹ̀, Eṣtaoli, ati Sora, ati Aṣna; 34 Ati Sanoa, ati Eni-gannimu Tappua, ati Enamu; 35 Jarmutu, ati Adullamu, Soko, ati Aseka; 36 Ati Ṣaaraimu, ati Aditaimu, ati Gedera, ati Gederotaimu; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. 37 Senani, ati Hadaṣa, ati Migdali-gadi; 38 Ati Dilani, ati Mispe, ati Jokteeli; 39 Lakiṣi, ati Boskati, ati Egloni; 40 Ati Kabboni, ati Lamamu, ati Kitliṣi; 41 Ati Gederotu, Beti-dagoni, ati Naama, ati Makkeda; ilu mẹrindilogun pẹlu ileto wọn. 42 Libna, ati Eteri, ati Aṣani; 43 Ati Ifta, ati Aṣna, ati Nesibu; 44 Ati Keila, ati Aksibu, ati Mareṣa; ilu mẹsan pẹlu ileto wọn. 45 Ekroni, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ati awọn ileto rẹ̀: 46 Lati Ekroni lọ ani titi dé okun, gbogbo eyiti mbẹ leti Aṣdodu, pẹlu ileto wọn. 47 Aṣdodu, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; Gasa, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; dé odò Egipti, ati okun nla, ati àgbegbe rẹ̀. 48 Ati ni ilẹ òke, Ṣamiri, ati Jattiri, ati Soko; 49 Ati Dana, ati Kiriati-sana (ti ṣe Debiri); 50 Ati Anabu, ati Eṣtemo, ati Animu; 51 Ati Goṣeni, ati Holoni, ati Gilo; ilu mọkanla pẹlu ileto wọn. 52 Arabu, ati Duma, ati Eṣani; 53 Ati Janimu, ati Beti-tappua, ati Afeka; 54 Ati Humta, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni), ati Siori; ilu meṣan pẹlu ileto wọn. 55 Maoni, Karmeli, ati Sifu, ati Juta; 56 Ati Jesreeli, ati Jokdeamu, ati Sanoa; 57 Kaini, Gibea, ati Timna; ilu mẹwa pẹlu ileto wọn. 58 Halhulu, Beti-suru, ati Gedori; 59 Ati Maarati, ati Beti-anotu, ati Eltekoni; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn. 60 Kiriati-baali (ti iṣe Kiriati-jearimu), ati Rabba; ilu meji pẹlu ileto wọn. 61 Li aginjù, Beti-araba, Middini, ati Sekaka; 62 Ati Nibṣani, ati Ilu Iyọ̀, ati Eni-gedi; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn. 63 Bi o si ṣe ti awọn Jebusi nì, awọn ara Jerusalemu, awọn ọmọ Juda kò le lé wọn jade: ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Juda gbé ni Jerusalemu, titi di oni-oloni.

Joṣua 16

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1 IPÍN awọn ọmọ Josefu yọ lati Jordani lọ ni Jeriko, ni omi Jeriko ni ìha ìla-õrùn, ani aginjù, ti o gòke lati Jeriko lọ dé ilẹ òke Beti-eli; 2 O si ti Beti-eli yọ si Lusi, o si kọja lọ si àgbegbe Arki dé Atarotu; 3 O si sọkalẹ ni ìha ìwọ-õrùn si àgbegbe Jafleti, dé àgbegbe Beti-horoni isalẹ, ani dé Geseri: o si yọ si okun. 4 Bẹ̃li awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu, gbà ilẹ-iní wọn.

Efraimu

5 Àla awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn li eyi: ani àla ilẹ-iní wọn ni ìha ìla-õrùn ni Atarotu-adari, dé Beti-horoni òke; 6 Àla na si lọ si ìha ìwọ-õrùn si ìha ariwa Mikmeta; àla na si yi lọ si ìha ìla-õrùn dé Taanati-ṣilo, o si kọja lẹba rẹ̀ lọ ni ìha ìla-õrùn Janoha; 7 O si sọkalẹ lati Janoha lọ dé Atarotu, ati dé Naara, o si dé Jeriko, o si yọ si Jordani. 8 Àla na jade lọ lati Tappua si ìha ìwọ-õrùn titi dé odò Kana; o si yọ si okun. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn; 9 Pẹlu ilu ti a yàsọtọ fun awọn ọmọ Efraimu lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Manasse, gbogbo ilu na pẹlu ileto wọn. 10 Nwọn kò si lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade: ṣugbọn awọn ara Kenaani joko lãrin Efraimu titi di oni yi, nwọn si di ẹrú lati ma sìnru.

Joṣua 17

Ilẹ̀ Ẹ̀yà Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1 EYI si ni ipín ẹ̀ya Manasse; nitori on li akọ́bi Josefu. Bi o ṣe ti Makiri akọ́bi Manasse, baba Gileadi, nitori on ṣe ologun, nitorina li o ṣe ní Gileadi ati Baṣani. 2 Awọn ọmọ Manasse iyokù si ní ilẹ-iní gẹgẹ bi idile wọn; awọn ọmọ Abieseri, ati awọn ọmọ Heleki, ati awọn ọmọ Asrieli, ati awọn ọmọ Ṣekemu, ati awọn ọmọ Heferi, ati awọn ọmọ Ṣemida: awọn wọnyi ni awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn. 3 Ṣugbọn Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, kò ní ọmọkunrin, bikoṣe ọmọbinrin: awọn wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀, Mala, ati Noa, Hogla, Milka, ati Tirsa. 4 Nwọn si wá siwaju Eleasari alufa, ati siwaju Joṣua ọmọ Nuni, ati siwaju awọn olori, wipe, OLUWA fi aṣẹ fun Mose lati fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin wa: nitorina o fi ilẹ-iní fun wọn lãrin awọn arakunrin baba wọn, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA. 5 Ipín mẹwa si bọ́ sọdọ Manasse, làika ilẹ Gileadi ati Baṣani, ti mbẹ ni ìha keji Jordani; 6 Nitoriti awọn ọmọbinrin Manasse ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin: awọn ọmọ Manasse ọkunrin iyokù si ní ilẹ Gileadi. 7 Àla Manasse si lọ lati Aṣeri dé Mikmeta, ti mbẹ niwaju Ṣekemu; àla na si lọ titi ni ìha ọtún, sọdọ awọn ara Eni-tappua. 8 Manasse li o ní ilẹ Tappua: ṣugbọn Tappua li àla Manasse jẹ́ ti awọn ọmọ Efraimu. 9 Àla rẹ̀ si sọkalẹ lọ si odò Kana, ni ìha gusù odò na: ilu Efraimu wọnyi wà lãrin awọn ilu Manasse: àla Manasse pẹlu si wà ni ìha ariwa odò na, o si yọ si okun: 10 Ni ìha gusù ti Efraimu ni, ati ni ìha ariwa ti Manasse ni, okun si ni àla rẹ̀; nwọn si dé Aṣeri ni ìha ariwa, ati Issakari ni ìha ìla-õrùn. 11 Manasse si ní ni Issakari ati ni Aṣeri, Beti-ṣeani ati awọn ilu rẹ̀, ati Ibleamu ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Dori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Enidori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Taanaki ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Megiddo ati awọn ilu rẹ̀, ani òke mẹta na. 12 Ṣugbọn awọn ọmọ Manasse kò le gbà ilu wọnyi; awọn ara Kenaani si ngbé ilẹ na. 13 O si ṣe, nigbati awọn ọmọ Israeli ndi alagbara, nwọn mu awọn ara Kenaani sìn, ṣugbọn nwọn kò lé wọn jade patapata.

Ẹ̀yà Efraimu ati ti Manase ti Ìwọ̀ Oòrùn Bèèrè fún Ilẹ̀ Sí i

14 Awọn ọmọ Josefu si wi fun Joṣua pe, Ẽṣe ti iwọ fi fun mi ni ilẹ kan, ati ipín kan ni ilẹ-iní, bẹ̃ni enia nla ni mi, niwọnbi OLUWA ti bukún mi titi di isisiyi? 15 Joṣua si da wọn lohùn pe, Bi iwọ ba jẹ́ enia nla, gòke lọ si igbó, ki o si ṣanlẹ fun ara rẹ nibẹ̀ ni ilẹ awọn Perissi ati ti Refaimu; bi òke Efraimu ba há jù fun ọ. 16 Awọn ọmọ Josefu si wipe, Òke na kò to fun wa: gbogbo awọn ara Kenaani ti ngbé ilẹ afonifoji si ní kẹkẹ́ irin, ati awọn ti mbẹ ni Beti-ṣeani, ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ti mbẹ ni afonifoji Jesreeli. 17 Joṣua si wi fun ile Josefu, ani fun Efraimu ati fun Manasse pe, Enia nla ni iwọ, iwọ si lí agbara pipọ̀: iwọ ki yio ní ipín kanṣoṣo: 18 Ṣugbọn ilẹ òke yio jẹ́ tirẹ; nitoriti iṣe igbó, iwọ o si ṣán a, ati ìna rẹ̀ yio jẹ́ tirẹ: nitoriti iwọ o lé awọn ara Kenaani jade, bi o ti jẹ́ pe nwọn ní kẹkẹ́ irin nì, ti o si jẹ́ pe nwọn lí agbara.

Joṣua 18

Pípín Ilẹ̀ Yòókù

1 GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si pejọ ni Ṣilo, nwọn si gbé agọ́ ajọ ró nibẹ̀: a si ṣẹgun ilẹ na niwaju wọn. 2 Ẹ̀ya meje si kù ninu awọn ọmọ Israeli, ti kò ti igbà ilẹ-iní wọn. 3 Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin o ti lọra pẹ to lati lọ igbà ilẹ na, ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, ti fi fun nyin? 4 Ẹ yàn ọkunrin mẹta fun ẹ̀ya kọkan: emi o si rán wọn, nwọn o si dide, nwọn o si là ilẹ na já, nwọn o si ṣe apejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi ilẹ-iní wọn; ki nwọn ki o si pada tọ̀ mi wá. 5 Nwọn o si pín i si ọ̀na meje: Juda yio ma gbé ilẹ rẹ̀ ni gusù, ile Josefu yio si ma gbé ilẹ wọn ni ariwa. 6 Ẹnyin o si ṣe apejuwe ilẹ na li ọ̀na meje, ẹnyin o si mú apejuwe tọ̀ mi wá nihin, ki emi ki o le ṣẹ́ keké rẹ̀ fun nyin nihin niwaju OLUWA Ọlọrun wa. 7 Nitoriti awọn ọmọ Lefi kò ní ipín lãrin nyin; nitori iṣẹ-alufa OLUWA ni iní wọn: ati Gadi, ati Reubeni, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ti gbà ilẹ-iní wọn na ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun wọn. 8 Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo. 9 Awọn ọkunrin na si lọ, nwọn si là ilẹ na já, nwọn si ṣe apejuwe rẹ̀ sinu iwé ni ilu ilu li ọ̀na meje, nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, si ibudó ni Ṣilo. 10 Joṣua si ṣẹ́ keké fun wọn ni Ṣilo niwaju OLUWA: nibẹ̀ ni Joṣua si pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ipín wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Bẹnjamini

11 Ilẹ ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini yọ jade, gẹgẹ bi idile wọn: àla ipín wọn si yọ si agbedemeji awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Josefu. 12 Àla wọn ni ìha ariwa si ti Jordani lọ; àla na si gòke lọ si ìha Jeriko ni ìha ariwa, o si là ilẹ òke lọ ni iwọ-õrùn; o si yọ si aginjù Beti-afeni. 13 Àla na si ti ibẹ̀ lọ si Lusi, si ìha Lusi (ti ṣe Beti-eli), ni ìha gusù; àla na si sọkale lọ si Atarotu-adari, lẹba òke ti mbẹ ni gusù Beti-horoni isalẹ. 14 A si fà àla na lọ, o si yi si ìha ìwọ-õrùn lọ si gusù, lati òke ti mbẹ niwaju Beti-horoni ni ìha gusù; o si yọ si Kiriati-baali (ti ṣe Kiriati-jearimu), ilu awọn ọmọ Juda kan: eyi ni apa ìwọ-õrùn. 15 Ati apa gusù ni lati ipẹkun Kiriati-jearimu, àla na si yọ ìwọ-õrùn, o si yọ si isun omi Neftoa: 16 Àla na si sọkalẹ lọ si ipẹkun òke ti mbẹ niwaju afonifoji ọmọ Hinnomu, ti o si mbẹ ni afonifoji Refaimu ni ìha ariwa; o si sọkalẹ lọ si afonifoji Hinnomu, si apa Jebusi ni ìha gusù, o si sọkalẹ lọ si Eni-rogeli; 17 A si fà a lati ariwa lọ, o si yọ si Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Gelilotu, ti o kọjusi òke Adummimu; o si sọkalẹ lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni; 18 O si kọja lọ si apa ibi ti o kọjusi Araba ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Araba: 19 Àla na si kọja lọ dé apa Beti-hogla ni ìha ariwa: àla na si yọ ni ìha ariwa si kọ̀rọ Okun Iyọ̀, ni ipẹkun gusù ti Jordani: eyi ni àla gusù. 20 Jordani si ni àla rẹ̀ ni ìha ìla-õrùn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini, li àgbegbe rẹ̀ kakiri, gẹgẹ bi idile wọn. 21 Njẹ ilu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn, ni Jeriko, ati Beti-hogla, ati Emekikesisi; 22 Ati Beti-araba, ati Semaraimu, ati Beti-eli; 23 Ati Affimu, ati Para, ati Ofra; 24 Ati Kefari-ammoni, ati Ofni, ati Geba; ilu mejila pẹlu ileto wọn: 25 Gibeoni, ati Rama, ati Beerotu; 26 Ati Mispe, ati Kefira, ati Mosa; 27 Ati Rekemu, ati Irpeeli, ati Tarala; 28 Ati Sela, Elefu, ati Jebusi (ti iṣe Jerusalemu), Gibeati, ati Kitiria; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn.

Joṣua 19

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Simeoni

1 IPÍN keji yọ fun Simeoni, ani fun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn; ilẹ-iní wọn si wà lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Juda. 2 Nwọn si ní Beeri-ṣeba, tabi Ṣeba, ati Molada, ni ilẹ-iní wọn; 3 Ati Hasari-ṣuali, ati Bala, ati Esemu; 4 Ati Eltoladi, ati Bẹtulu, ati Horma; 5 Ati Siklagi, ati Beti-markabotu, ati Hasari-susa; 6 Ati Beti-lebaotu, ati Ṣaruheni; ilu mẹtala pẹlu ileto wọn: 7 Aini, Rimmoni, ati Eteri, ati Aṣani; ilu mẹrin pẹlu ileto wọn: 8 Ati gbogbo ileto ti o yi ilu wọnyi ká dé Baalati-beeri, Rama ti Gusù. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn. 9 Ninu ipín awọn ọmọ Juda ni awọn ọmọ Simeoni ni ilẹ-iní: nitori ipín awọn ọmọ Juda pọ̀ju fun wọn: nitorina ni awọn ọmọ Simeoni fi ní ilẹ-iní lãrin ilẹ-iní wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Sebuluni

10 Ilẹ kẹta yọ fun awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: àla ilẹ-iní wọn si dé Saridi: 11 Àla wọn gòke lọ si ìha ìwọ-õrùn, ani titi o fi dé Marala, o si dé Dabaṣeti; o si dé odò ti mbẹ niwaju Jokneamu; 12 O si ṣẹri lati Saridi lọ ni ìha ìla-õrùn si ìla-õrùn dé àla Kisloti-tabori; o si yọ si Daberati; o si jade lọ si Jafia; 13 Ati lati ibẹ̀ o kọja ni ìha ìla-õrùn si Gati-heferi, dé Ẹti-kasini; o si yọ si Rimmoni titi o fi dé Nea; 14 Àla na si yi i ká ni ìha ariwa dé Hannatoni: o si yọ si afonifoji Ifta-eli; 15 Ati Katati, ati Nahalali, ati Ṣimroni, ati Idala, ati Beti-lehemu: ilu mejila pẹlu ileto wọn. 16 Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Isakari

17 Ipín kẹrin yọ fun Issakari, ani fun awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn. 18 Àla wọn si dé Jesreeli, ati Kesuloti, ati Ṣunemu; 19 Ati Hafaraimu, ati Ṣihoni, ati Anaharati; 20 Ati Rabbiti, Kiṣioni, ati Ebesi; 21 Ati Remeti, ati Eni-gannimu, ati Enhadda, ati Beti-passesi; 22 Àla na si dé Tabori, ati Ṣahasuma, ati Beti-ṣemeṣi; àla wọn yọ si Jordani: ilu mẹrindilogun pẹlu ileto wọn. 23 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi ati ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Aṣeri

24 Ipín karun yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn. 25 Àla wọn si ni Helkati, ati Hali, ati Beteni, ati Akṣafu; 26 Ati Allammeleki, ati Amadi, ati Miṣali; o si dé Karmeli ni ìha ìwọ-õrùn, ati Ṣihorilibnati; 27 O si ṣẹri lọ si ìha ìla-õrùn dé Beti-dagoni, o si dé Sebuluni, ati afonifoji Ifta-eli ni ìha ariwa dé Betemeki, ati Neieli; o si yọ si Kabulu li apa òsi, 28 Ati Ebroni, ati Rehobu, ati Hammoni, ati Kana, ani titi dé Sidoni nla; 29 Àla na si ṣẹri lọ si Rama, ati si Tire ilu olodi; àla na si ṣẹri lọ si Hosa; o si yọ si okun ni ìha Aksibu: 30 Ati Umma, ati Afeki, ati Rehobu: ilu mejilelogun pẹlu ileto wọn. 31 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Naftali

32 Ipín kẹfa yọ fun awọn ọmọ Naftali, ani fun awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn. 33 Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Helefu, lati igi-oaku Saanannimu, ati Adami-nekebu, ati Jabneeli dé Lakkumu; o si yọ si Jordani. 34 Àla na si ṣẹri lọ sí ìha ìwọ-õrùn si Asnoti-taboru, o si ti ibẹ̀ lọ si Hukkoki; o si dé Sebuluni ni gusù, o si dé Aṣeri ni ìwọ-õrùn, ati Juda ni Jordani ni ìha ìla-õrùn. 35 Awọn ilu olodi si ni Siddimu, Seri, ati Hammati, Rakkati, ati Kinnereti; 36 Ati Adama, ati Rama, ati Hasoru; 37 Ati Kedeṣi, ati Edrei, ati Eni-hasoru; 38 Ati Ironi, ati Migdali-eli, Horemu, ati Beti-anati, ati Beti-ṣemeṣi; ilu mọkandilogun pẹlu ileto wọn. 39 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Dani

40 Ilẹ keje yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn. 41 Àla ilẹ-iní wọn si ni Sora, ati Eṣtaolu, ati Iri-ṣemeṣi; 42 Ati Ṣaalabbini, ati Aijaloni, ati Itla; 43 Ati Eloni, ati Timna, ati Ekroni; 44 Ati Elteke, ati Gibbetoni, ati Baalati; 45 Ati Jehudi, ati Bene-beraki, ati Gati-rimmọni; 46 Ati Me-jarkoni, ati Rakkoni, pẹlu àla ti mbẹ kọjusi Jọppa. 47 Awọn ọmọ Dani si gbọ̀n àla wọn lọ: awọn ọmọ Dani si gòke lọ ibá Leṣemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀, nwọn si pè Leṣemu ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn. 48 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Kù

49 Nwọn si pari pipín ilẹ na fun ilẹ-iní gẹgẹ bi àla rẹ̀; awọn ọmọ Israeli si fi ilẹ-iní kan fun Joṣua ọmọ Nuni lãrin wọn: 50 Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA, nwọn fun u ni ilu ti o bère, ani Timnati-sera li òke Efraimu: o si kọ ilu na, o si ngbé inu rẹ̀. 51 Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.

Joṣua 20

Àwọn Ìlú Ààbò

1 OLUWA si sọ fun Joṣua pe, 2 Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ yàn ilu àbo fun ara nyin, ti mo ti sọ fun nyin lati ọwọ́ Mose wa: 3 Ki apania ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan li aimọ̀ ki o le salọ sibẹ̀: nwọn o si jẹ́ àbo fun nyin lọwọ olugbẹsan ẹ̀jẹ. 4 On o si salọ si ọkan ninu ilu wọnni, yio si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na, yio si rò ẹjọ́ rẹ̀ li etí awọn àgba ilu na, nwọn o si gbà a sọdọ sinu ilu na, nwọn o si fun u ni ibi kan, ki o le ma bá wọn gbé. 5 Bi olugbẹsan ẹ̀jẹ ba lepa rẹ̀, njẹ ki nwọn ki o má ṣe fi apania na lé e lọwọ; nitoriti o pa aladugbo rẹ̀ li aimọ̀, ti kò si korira rẹ̀ tẹlẹrí. 6 On o si ma gbé inu ilu na, titi yio fi duro niwaju ijọ fun idajọ, titi ikú olori alufa o wà li ọjọ́ wọnni: nigbana ni apania na yio pada, on o si wá si ilu rẹ̀, ati si ile rẹ̀, si ilu na lati ibiti o gbé ti salọ. 7 Nwọn si yàn Kedeṣi ni Galili ni ilẹ òke Naftali, ati Ṣekemu ni ilẹ òke Efraimu, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni) ni ilẹ òke Juda. 8 Ati ni ìha keji Jordani lẹba Jeriko ni ìla-õrùn, nwọn yàn Beseri li aginjù ni pẹtẹlẹ̀ ninu ẹ̀ya Reubeni, ati Ramotu ni Gileadi ninu ẹ̀ya Gadi, ati Golani ni Baṣani ninu ẹ̀ya Manasse. 9 Wọnyi ni awọn ilu ti a yàn fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo lãrin wọn, ki ẹnikẹni ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan, ki o le salọ sibẹ̀, ki o má ba si ti ọwọ́ olugbẹsan ẹ̀jẹ ku, titi on o fi duro niwaju ijọ.

Joṣua 21

Ìlú Àwọn Ọmọ Lefi

1 NIGBANA ni awọn olori awọn baba awọn ọmọ Lefi sunmọ Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; 2 Nwọn si wi fun wọn ni Ṣilo ni ilẹ Kenaani pe, OLUWA palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá lati fun wa ni ilu lati ma gbé, ati àgbegbe wọn fun ohun-ọ̀sin wa. 3 Awọn ọmọ Israeli si fi ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn fun awọn ọmọ Lefi ninu ilẹ-iní wọn, nipa aṣẹ OLUWA. 4 Ipín si yọ fun idile awọn ọmọ Kohati: ati awọn ọmọ Aaroni alufa, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu ẹ̀ya Juda, ati lati inu ẹ̀ya Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya Benjamini. 5 Awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Kohati, fi keké gbà ilu mẹwa lati inu idile ẹ̀ya Efraimu, ati lati inu ẹ̀ya Dani, ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse. 6 Awọn ọmọ Gerṣoni si fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu idile ẹ̀ya Issakari, ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati inu àbọ ẹ̀ya Manasse ni Baṣani. 7 Awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn, ní ilu mejila, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni. 8 Awọn ọmọ Israeli fi keké fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá. 9 Nwọn si fi ilu ti a darukọ wọnyi fun wọn, lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni wá: 10 Nwọn si jẹ́ ti awọn ọmọ Aaroni, ni idile awọn ọmọ Kohati, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, nitoriti nwọn ní ipín ikini. 11 Nwọn si fi Kiriati-arba, ti iṣe Hebroni fun wọn, (Arba ni baba Anaki ni ilẹ òke Juda,) pẹlu àgbegbe rẹ̀ yi i kakiri. 12 Ṣugbọn pápa ilu na, ati ileto rẹ̀, ni nwọn fi fun Kalebu ọmọ Jefunne ni ilẹ-iní rẹ̀. 13 Nwọn si fi Hebroni ilu àbo fun apania pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Libna pẹlu àgbegbe rẹ̀, fun awọn ọmọ Aaroni alufa; 14 Ati Jatiri pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Eṣtemoa pẹlu àgbegbe rẹ̀; 15 Ati Holoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Debiri pẹlu àgbegbe rẹ̀; 16 Ati Aini pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jutta pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-ṣemeṣi pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹsan ninu awọn ẹ̀ya meji wọnni. 17 Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini, Gibeoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Geba pẹlu àgbegbe rẹ̀; 18 Anatotu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Almoni pelu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 19 Gbogbo ilu awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, jẹ́ ilu mẹtala pẹlu àgbegbe wọn. 20 Ati idile awọn ọmọ Kohati, awọn ọmọ Lefi, ani awọn ọmọ Kohati ti o kù, nwọn ní ilu ti iṣe ipín ti wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu. 21 Nwọn si fi Ṣekemu fun wọn pẹlu àgbegbe rẹ̀, ni ilẹ òke Efraimu, ilu àbo fun apania, ati Geseri pẹlu àgbegbe rẹ̀; 22 Ati Kibsaimu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-horoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 23 Ati ninu ẹ̀ya Dani, Elteke pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gibbetoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; 24 Aijaloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 25 Ati ninu àbọ ẹ̀ya Manasse, Taanaki pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji. 26 Gbogbo ilu na jasi mẹwa pẹlu àgbegbe wọn fun idile awọn ọmọ Kohati ti o kù. 27 Ati awọn ọmọ Gerṣoni, idile awọn ọmọ Lefi, ni nwọn fi Golani ni Baṣani fun pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; lati inu ẹ̀ya Manasse, ati Be-eṣtera pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji. 28 Ati ninu ẹ̀ya Issakari, Kiṣioni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Dabarati pẹlu àgbegbe rẹ̀; 29 Jarmutu pẹlu àgbegbe rẹ̀, Engannimu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 30 Ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, Miṣali pẹlu àgbegbe rẹ̀, Abdoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; 31 Helkati pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Rehobu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 32 Ati lati inu ẹ̀ya Naftali, Kedeṣi ni Galili pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; ati Hammotu-dori pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Kartani pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹta. 33 Gbogbo ilu awọn ọmọ Gerṣoni gẹgẹ bi idile wọn, jẹ́ ilu mẹtala pẹlu ileto wọn. 34 Ati fun idile awọn ọmọ Merari, awọn ọmọ Lefi ti o kù, ni Jokneamu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Karta pẹlu àgbegbe rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni, 35 Dimna pẹlu àgbegbe rẹ̀, Nahalali pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 36 Ati ninu ẹ̀ya Reubeni, Beseri pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jahasi pẹlu àgbegbe rẹ̀, 37 Kedemotu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Mefaati pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 38 Ati ninu ẹ̀ya Gadi, Ramotu ni Gileadi pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; ati Mahanaimu pẹlu àgbegbe rẹ̀. 39 Heṣboni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Jaseri pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin ni gbogbo rẹ̀. 40 Gbogbo wọnyi ni ilu awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi idile wọn, ani awọn ti o kù ni idile awọn ọmọ Lefi; ipín wọn si jẹ́ ilu mejila. 41 Gbogbo ilu awọn ọmọ Lefi ti mbẹ lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli jẹ́ ilu mejidilãdọta pẹlu àgbegbe wọn. 42 Olukuluku ilu wọnyi li o ní àgbegbe wọn yi wọn ká: bayi ni gbogbo ilu wọnyi ri.

Israẹli Gba Ilẹ̀ náà

43 OLUWA si fun Israeli ni gbogbo ilẹ na, ti o bura lati fi fun awọn baba wọn; nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀. 44 OLUWA si fun wọn ni isimi yiká kiri, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o bura fun awọn baba wọn: kò si sí ọkunrin kan ninu gbogbo awọn ọtá wọn ti o duro niwaju wọn; OLUWA fi gbogbo awọn ọtá wọn lé wọn lọwọ. 45 Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israeli; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ.

Joṣua 22

Joṣua Dá Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn Pada Sílé

1 NIGBANA ni Joṣua pè awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, 2 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ṣe gbogbo eyiti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin, ẹnyin si gbọ́ ohùn mi ni gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun nyin: 3 Ẹnyin kò fi awọn arakunrin nyin silẹ lati ọjọ́ pipọ̀ wọnyi wá titi o fi di oni, ṣugbọn ẹnyin ṣe afiyesi ìlo ofin OLUWA Ọlọrun nyin. 4 Njẹ nisisiyi OLUWA Ọlọrun nyin ti fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: njẹ nisisiyi ẹ pada, ki ẹ si lọ sinu agọ́ nyin, ati si ilẹ-iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA ti fun nyin ni ìha keji Jordani. 5 Kìki ki ẹ kiyesara gidigidi lati pa aṣẹ ati ofin mọ́, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin, lati fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati lati faramọ́ ọ, ati lati sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo. 6 Bẹ̃ni Joṣua sure fun wọn, o si rán wọn lọ: nwọn si lọ sinu agọ́ wọn. 7 Njẹ fun àbọ ẹ̀ya Manasse ni Mose ti fi ilẹ-iní wọn fun ni Baṣani: ṣugbọn fun àbọ ẹ̀ya ti o kù ni Joṣua fi ilẹ-iní fun pẹlu awọn arakunrin wọn ni ìha ihin Jordani ni ìwọ-õrùn. Nigbati Joṣua si rán wọn pada lọ sinu agọ́ wọn, o sure fun wọn pẹlu, 8 O si wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ pẹlu ọrọ̀ pipọ̀ si agọ́ nyin, ati pẹlu ohunọ̀sin pipọ̀, pẹlu fadakà, ati pẹlu wurà, ati pẹlu idẹ ati pẹlu irin, ati pẹlu aṣọ pipọ̀pipọ: ẹ bá awọn arakunrin nyin pín ikogun awọn ọtá nyin. 9 Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse si pada, nwọn si lọ kuro lọdọ awọn ọmọ Israeli lati Ṣilo, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, lati lọ si ilẹ Gileadi, si ilẹ iní wọn, eyiti nwọn ti gbà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA lati ọwọ́ Mose wá.

Pẹpẹ Tí Ó Wà Lẹ́bàá Odò Jọrdani

10 Nigbati nwọn si dé eti Jordani, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan lẹba Jordani, pẹpẹ ti o tobi lati wò. 11 Awọn ọmọ Israeli si gbọ́ pe, Kiyesi i, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan dojukọ ilẹ Kenaani, lẹba Jordani ni ìha keji awọn ọmọ Israeli. 12 Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli kó ara wọn jọ ni Ṣilo, lati gòke lọ ibá wọn jagun. 13 Awọn ọmọ Israeli si rán Finehasi ọmọ Eleasari alufa si awọn ọmọ Reubeni, ati si awọn ọmọ Gadi, ati si àbọ ẹ̀ya Manasse ni ilẹ Gileadi; 14 Ati awọn olori mẹwa pẹlu rẹ̀, olori ile baba kọkan fun gbogbo ẹ̀ya Israeli; olukuluku si ni olori ile baba wọn ninu ẹgbẹgbẹrun Israeli. 15 Nwọn si dé ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ati ọdọ àbọ ẹ̀ya Manasse, ni ilẹ Gileadi, nwọn si bá wọn sọ̀rọ pe, 16 Bayi ni gbogbo ijọ OLUWA wi, Ẹ̀ṣẹ kili eyiti ẹnyin da si Ọlọrun Israeli, lati pada li oni kuro lẹhin OLUWA, li eyiti ẹnyin mọ pẹpẹ kan fun ara nyin, ki ẹnyin ki o le ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni? 17 Ẹ̀ṣẹ ti Peori kò to fun wa kọ́, ti a kò ti iwẹ̀mọ́ ninu rẹ̀ titi di oni, bi o tilẹ ṣe pe ajakalẹ-àrun wà ninu ijọ OLUWA, 18 Ti ẹnyin fi pada kuro lẹhin OLUWA li oni? Yio si ṣe, bi ẹnyin ti ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni, li ọla, on o binu si gbogbo ijọ Israeli. 19 Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa. 20 Ṣe bẹ̃ni Akani ọmọ Sera da ẹ̀ṣẹ niti ohun ìyasọtọ, ti ibinu si dé sori gbogbo ijọ Israeli? ọkunrin na kò nikan ṣegbé ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 21 Nigbana ni awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse dahùn, nwọn si wi fun awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli pe, 22 OLUWA, Ọlọrun awọn ọlọrun, OLUWA Ọlọrun awọn ọlọrun, On mọ̀, Israeli pẹlu yio si mọ̀; bi o ba ṣepe ni ìṣọtẹ ni, tabi bi ni irekọja si OLUWA, (má ṣe gbà wa li oni,) 23 Ni awa fi mọ pẹpẹ fun ara wa, lati yipada kuro lẹhin OLUWA; tabi bi o ba ṣe pe lati ru ẹbọ sisun, tabi ẹbọ ohunjijẹ, tabi ẹbọ alafia lori rẹ̀, ki OLUWA tikala rẹ̀ ki o bère rẹ̀. 24 Bi o ba ṣepe awa kò kuku ṣe e nitori aniyàn, ati nitori nkan yi pe, Lẹhinọla awọn ọmọ nyin le wi fun awọn ọmọ wa pe, Kili o kàn nyin niti OLUWA, Ọlọrun Israeli? 25 Nitoriti Ọlọrun ti fi Jordani pàla li agbedemeji awa ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi; ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA: bẹ̃li awọn ọmọ nyin yio mu ki awọn ọmọ wa ki o dẹkun ati ma bẹ̀ru OLUWA. 26 Nitorina li a ṣe wipe, Ẹ jẹ ki a mura nisisiyi lati mọ pẹpẹ kan, ki iṣe fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan: 27 Ṣugbọn ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin, ati awọn iran wa lẹhin wa, ki awa ki o le ma fi ẹbọ sisun wa, ati ẹbọ wa, pẹlu ẹbọ alafia wa jọsìn fun OLUWA niwaju rẹ̀; ki awọn ọmọ nyin ki o má ba wi fun awọn ọmọ wa lẹhinọla pe, Ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA. 28 Nitorina ni awa ṣe wipe, Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi bẹ̃ fun wa, tabi fun awọn iran wa lẹhinọla, awa o si wipe, Ẹ wò apẹrẹ pẹpẹ OLUWA, ti awọn baba wa mọ, ki iṣe fun ẹbọ sisun, bẹ̃ni ki iṣe fun ẹbọ; ṣugbọn o jasi ẹrí li agbedemeji awa ati ẹnyin. 29 Ki Ọlọrun má jẹ ki awa ki o ṣọ̀tẹ si OLUWA, ki awa si pada li oni kuro lẹhin OLUWA, lati mọ pẹpẹ fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ ohunjije, tabi fun ẹbọ kan, lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa ti mbẹ niwaju agọ́ rẹ̀. 30 Nigbati Finehasi alufa, ati awọn olori ijọ, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli ti o wà pẹlu rẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ ti awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati awọn ọmọ Manasse sọ, o dùnmọ́ wọn. 31 Finehasi ọmọ Eleasari alufa si wi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Manasse pe, Li oni li awa mọ̀ pe OLUWA wà lãrin wa, nitoriti ẹnyin kò dẹ̀ṣẹ yi si OLUWA: nisisiyi ẹnyin yọ awọn ọmọ Israeli kuro lọwọ OLUWA. 32 Finehasi ọmọ Eleasari alufa, ati awọn olori, si pada lati ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati lati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ni ilẹ Gileadi, si ilẹ Kenaani, sọdọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si mú ìhin pada tọ̀ wọn wá. 33 Ohun na si dùnmọ́ awọn ọmọ Israeli; awọn ọmọ Israeli si fi ibukún fun Ọlọrun, nwọn kò si sọ ti ati gòke tọ̀ wọn lọ ijà, lati run ilẹ na ninu eyiti awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ngbé. 34 Awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi si sọ pẹpẹ na ni Edi: nwọn wipe, Nitori ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin pe OLUWA on li Ọlọrun.

Joṣua 23

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Tí Joṣua Sọ

1 O si ṣe li ọjọ́ pipọ̀ lẹhin ti OLUWA ti fi isimi fun Israeli lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn yiká, ti Joṣua di arugbó, ti o si pọ̀ li ọjọ́; 2 Joṣua si pè gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn, o si wi fun wọn pe, Emi di arugbó tán, emi si pọ̀ li ọjọ́: 3 Ẹnyin si ti ri ohun gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si gbogbo orilẹ-ède wọnyi nitori nyin; nitori OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti o ti jà fun nyin. 4 Wò o, emi ti pín awọn orilẹ-ède wọnyi ti o kù fun nyin, ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya nyin, lati Jordani lọ, pẹlu gbogbo awọn orilẹ-ède ti mo ti ke kuro, ani titi dé okun nla ni ìha ìwọ-õrùn. 5 OLUWA Ọlọrun nyin, on ni yio tì wọn jade kuro niwaju nyin, yio si lé wọn kuro li oju nyin; ẹnyin o si ní ilẹ wọn, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin. 6 Nitorina ẹ mura gidigidi lati tọju ati lati ṣe ohun gbogbo ti a kọ sinu iwé ofin Mose, ki ẹnyin ki o má ṣe yipada kuro ninu rẹ̀ si ọwọ́ ọtún tabi si ọwọ́ òsi; 7 Ki ẹnyin ki o má ṣe wá sãrin awọn orilẹ-ède wọnyi, awọn wọnyi ti o kù pẹlu nyin; ki ẹnyin má ṣe da orukọ oriṣa wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe fi wọn bura, ẹ má ṣe sìn wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe tẹriba fun wọn: 8 Ṣugbọn ki ẹnyin faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe titi di oni. 9 Nitoriti OLUWA ti lé awọn orilẹ-ède nla ati alagbara kuro niwaju nyin; ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, kò sí ọkunrin kan ti o ti iduro niwaju nyin titi di oni. 10 ọkunrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun nyin. 11 Nitorina ẹ kiyesara nyin gidigidi, ki ẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin. 12 Ṣugbọn bi ẹ ba daṣà ati pada, ti ẹ si faramọ́ iyokù awọn orile-ède wọnyi, ani awọn wọnyi ti o kù lãrin nyin, ti ẹ si bá wọn gbeyawo, ti ẹ si nwọle tọ̀ wọn, ti awọn si nwọle tọ̀ nyin: 13 Ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe OLUWA Ọlọrun nyin ki yio lé awọn orilẹ-ède wọnyi jade mọ́ kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o jẹ́ okùn-didẹ ati ẹgẹ́ fun nyin, ati paṣán ni ìha nyin, ati ẹgún li oju nyin, titi ẹ o fi ṣegbé kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin. 14 Ẹnyin kiyesi i, li oni emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: ényin si mọ̀ li àiya nyin gbogbo, ati li ọkàn nyin gbogbo pe, kò sí ohun kan ti o tase ninu ohun rere gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ niti nyin; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ fun nyin, kò si sí ohun ti o tase ninu rẹ̀. 15 Yio si ṣe, gẹgẹ bi ohun rere gbogbo ti ṣẹ fun nyin, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin; bẹ̃ni OLUWA yio mú ibi gbogbo bá nyin, titi yio fi pa nyin run kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin. 16 Nigbati ẹnyin ba re majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin kọja, ti o palaṣẹ fun nyin, ti ẹ ba si lọ, ti ẹ ba nsìn oriṣa ti ẹnyin ba tẹ̀ ori nyin bà fun wọn; nigbana ni ibinu OLUWA yio rú si nyin, ẹnyin o si ṣegbé kánkan kuro ni ilẹ daradara ti o ti fi fun nyin.

Joṣua 24

Joṣua Bá Àwọn Eniyan náà Sọ̀rọ̀ ní Ṣekemu

1 JOṢUA si pè gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli jọ si Ṣekemu, o si pè awọn àgba Israeli, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn; nwọn si fara wọn hàn niwaju Ọlọrun. 2 Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Bayi ni OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Awọn baba nyin ti gbé ìha keji Odò nì li atijọ rí, ani Tera, baba Abrahamu, ati baba Nahori: nwọn si sìn oriṣa. 3 Emi si mú Abrahamu baba nyin lati ìha keji Odò na wá, mo si ṣe amọ̀na rẹ̀ là gbogbo ilẹ Kenaani já, mo si sọ irú-ọmọ rẹ̀ di pipọ̀, mo si fun u ni Isaaki. 4 Emi si fun Isaaki ni Jakobu ati Esau: mo si fun Esau li òke Seiri lati ní i; Jakobu pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ si sọkalẹ lọ si Egipti. 5 Mo si rán Mose ati Aaroni, mo si yọ Egipti lẹnu, gẹgẹ bi eyiti mo ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin na mo si mú nyin jade. 6 Emi si mú awọn baba nyin jade kuro ni Egipti: ẹnyin si dé okun; awọn ara Egipti si lepa awọn baba nyin ti awọn ti kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin dé Okun Pupa. 7 Nigbati nwọn kigbepè OLUWA, o fi òkunkun si agbedemeji ẹnyin ati awọn ara Egipti, o si mú okun ya lù wọn, o si bò wọn mọlẹ; oju nyin si ti ri ohun ti mo ṣe ni Egipti: ẹnyin si gbé inu aginjù li ọjọ́ pipọ̀. 8 Emi si mú nyin wá si ilẹ awọn Amori, ti ngbé ìha keji Jordani; nwọn si bá nyin jà: emi si fi wọn lé nyin lọwọ ẹnyin si ní ilẹ wọn; emi si run wọn kuro niwaju nyin. 9 Nigbana ni Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu dide, o si ba Israeli jagun; o si ranṣẹ pè Balaamu ọmọ Beori lati fi nyin bú: 10 Ṣugbọn emi kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; nitorina o nsure fun nyin ṣá: mo si gbà nyin kuro li ọwọ́ rẹ̀. 11 Ẹnyin si gòke Jordani, ẹ si dé Jeriko: awọn ọkunrin Jeriko si fi ìja fun nyin, awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; emi si fi wọn lé nyin lọwọ. 12 Emi si rán agbọ́n siwaju nyin, ti o lé wọn kuro niwaju nyin, ani awọn ọba Amori meji; ki iṣe pẹlu idà rẹ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu ọrun rẹ. 13 Emi si fun nyin ni ilẹ ti iwọ kò ṣe lãla si, ati ilu ti ẹnyin kò tẹ̀dó, ẹnyin si ngbé inu wọn; ninu ọgbà-àjara ati ọgbà-igi-olifi ti ẹnyin kò gbìn li ẹnyin njẹ. 14 Njẹ nitorina ẹ bẹ̀ru OLUWA, ki ẹ si ma sìn i li ododo ati li otitọ: ki ẹ si mu oriṣa wọnni kuro ti awọn baba nyin sìn ni ìha keji Odò nì, ati ni Egipti; ki ẹ si ma sìn OLUWA. 15 Bi o ba si ṣe buburu li oju nyin lati sìn OLUWA, ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sìn li oni; bi oriṣa wọnni ni ti awọn baba nyin ti o wà ni ìha keji Odò ti nsìn, tabi awọn oriṣa awọn Amori, ni ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sìn. 16 Awọn enia na dahùn, nwọn si wipe, Ki a má ri ti awa o fi kọ̀ OLUWA silẹ, lati sìn oriṣa; 17 Nitori OLUWA Ọlọrun wa, on li ẹniti o mú wa, ati awọn baba wa gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro li oko-ẹrú, ti o si ṣe iṣẹ-iyanu nla wọnni li oju wa, ti o si pa wa mọ́ ni gbogbo ọ̀na ti awa rìn, ati lãrin gbogbo enia ti awa là kọja: 18 OLUWA si lé gbogbo awọn enia na jade kuro niwaju wa, ani awọn Amori ti ngbé ilẹ na: nitorina li awa pẹlu o ṣe ma sìn OLUWA; nitori on li Ọlọrun wa. 19 Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Enyin kò le sìn OLUWA; nitoripe Ọlọrun mimọ́ li on; Ọlọrun owú li on; ki yio dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin. 20 Bi ẹnyin ba kọ̀ OLUWA silẹ, ti ẹ ba si sìn ọlọrun ajeji, nigbana ni on o pada yio si ṣe nyin ni ibi, yio si run nyin, lẹhin ti o ti ṣe nyin li ore tán. 21 Awọn enia na si wi fun Joṣua pe, Rárá o; ṣugbọn OLUWA li awa o sìn. 22 Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Ẹnyin li ẹlẹri si ara nyin pe, ẹnyin yàn OLUWA fun ara nyin, lati ma sìn i. Nwọn si wipe, Awa ṣe ẹlẹri. 23 Njẹ nitorina ẹ mu ọlọrun ajeji ti mbẹ lãrin nyin kuro, ki ẹnyin si yi ọkàn nyin si OLUWA Ọlọrun Israeli. 24 Awọn enia na si wi fun Joṣua pe, OLUWA Ọlọrun wa li awa o ma sìn, ohùn rẹ̀ li awa o si ma gbọ́. 25 Bẹ̃ni Joṣua bá awọn enia na dá majẹmu li ọjọ́ na, o si fi ofin ati ìlana fun wọn ni Ṣekemu. 26 Joṣua si kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwé ofin Ọlọrun, o si mú okuta nla kan, o si gbé e kà ibẹ̀ labẹ igi-oaku kan, ti o wà ni ibi-mimọ́ OLUWA. 27 Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Ẹ kiyesi i, okuta yi ni ẹlẹri fun wa; nitori o ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o bá wa sọ: nitorina yio ṣe ẹlẹri si nyin, ki ẹnyin má ba sẹ́ Ọlọrun nyin. 28 Bẹ̃ni Joṣua jọwọ awọn enia na lọwọ lọ, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀.

Joṣua ati Eleasari Kú

29 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún. 30 Nwọn si sin i ni àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnatisera, ti mbẹ ni ilẹ òke Efraimu, ni ìha ariwa òke Gaaṣi. 31 Israeli si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, ti o si mọ̀ gbogbo iṣẹ OLUWA, ti o ṣe fun Israeli. 32 Egungun Josefu, ti awọn ọmọ Israeli gbé gòke lati Egipti wá, ni nwọn si sin ni Ṣekemu, ni ipín ilẹ ti Jakobu rà lọwọ awọn ọmọ Hamori baba Ṣekemu li ọgọrun owo: o si di ilẹ-iní awọn ọmọ Josefu. 33 Eleasari ọmọ Aaroni si kú; nwọn si sin i li òke Finehasi ọmọ rẹ̀, ti a fi fun u li òke Efraimu.

Onidajọ 1

Àwọn Ẹ̀yà Juda ati ti Simeoni Ṣẹgun Adonibeseki

1 O si ṣe lẹhin ikú Joṣua, ni awọn ọmọ Israeli bère lọdọ OLUWA wipe, Tani yio tète gòke tọ̀ awọn ara Kenaani lọ fun wa, lati bá wọn jà? 2 OLUWA si wipe, Juda ni yio gòke lọ: kiyesi i, emi fi ilẹ̀ na lé e lọwọ. 3 Juda si wi fun Simeoni arakunrin rẹ̀ pe, Bá mi gòke lọ si ilẹ mi, ki awa ki o le bá awọn ara Kenaani jà; emi na pẹlu yio si bá ọ lọ si ilẹ rẹ. Simeoni si bá a lọ. 4 Juda si gòke lọ; OLUWA si fi awọn ara Kenaani ati awọn Perissi lé wọn lọwọ: nwọn si pa ẹgbarun ọkunrin ninu wọn ni Beseki. 5 Nwọn si ri Adoni-beseki ni Beseki: nwọn si bá a jà, nwọn si pa awọn ara Kenaani ati awọn Perissi. 6 Ṣugbọn Adoni-beseki sá; nwọn si lepa rẹ̀, nwọn si mú u, nwọn si ke àtampako ọwọ́ rẹ̀, ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀. 7 Adoni-beseki si wipe, Adọrin ọba li emi ke li àtampako ọwọ́ wọn ati ti ẹsẹ̀ wọn, ti nwọn nṣà onjẹ wọn labẹ tabili mi: gẹgẹ bi emi ti ṣe, bẹ̃li Ọlọrun si san a fun mi. Nwọn si mú u wá si Jerusalemu, o si kú sibẹ̀.

Àwọn Ẹ̀yà Juda Ṣẹgun Jerusalẹmu ati Hebroni

8 Awọn ọmọ Juda si bá Jerusalemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si tinabọ ilu na. 9 Lẹhin na awọn ọmọ Juda si sọkalẹ lọ lati bá awọn ara Kenaani jà, ti ngbé ilẹ òke, ati ni Gusù, ati ni afonifoji nì. 10 Juda si tọ̀ awọn ara Kenaani ti ngbé Hebroni lọ: (orukọ Hebroni ni ìgba iṣaju si ni Kiriati-arba:) nwọn si pa Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai.

Otnieli Ṣẹgun Ìlú Debiri

11 Lati ibẹ̀ o si gbé ogun tọ̀ awọn ara Debiri lọ. (Orukọ Debiri ni ìgba atijọ si ni Kiriati-seferi.) 12 Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o si kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya. 13 Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya. 14 O si ṣe, nigbati Aksa dé ọdọ rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati bère oko kan lọdọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ kuro lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́? 15 On si wi fun u pe, Ta mi lọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fi isun omi fun mi pẹlu. Kalebu si fi ìsun òke ati isun isalẹ fun u.

Ìṣẹgun Àwọn Ẹ̀yà Juda ati Bẹnjamini

16 Awọn ọmọ Keni, ana Mose, si bá awọn ọmọ Juda gòke lati ilu ọpẹ lọ si aginjù Juda, ni gusù Aradi; nwọn si lọ, nwọn si mbá awọn enia na gbé. 17 Juda si bá Simeoni arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si pa awọn ara Kenaani ti ngbé Sefati, nwọn si pa a run patapata. A si pè orukọ ilu na ni Horma. 18 Juda si kó Gasa pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Aṣkeloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Ekroni pẹlu àgbegbe rẹ̀. 19 OLUWA si wà pẹlu Juda; o si gbà ilẹ òke; nitori on kò le lé awọn enia ti o wà ni pẹtẹlẹ̀ jade, nitoriti nwọn ní kẹkẹ́ irin. 20 Nwọn si fi Hebroni fun Kalebu, gẹgẹ bi Mose ti wi: on si lé awọn ọmọ Anaki mẹtẹta jade kuro nibẹ̀. 21 Awọn ọmọ Benjamini kò si lé awọn Jebusi ti ngbé Jerusalemu jade; ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Benjamini gbé ni Jerusalemu titi di oni.

Àwọn Ẹ̀yà Efraimu ati Ẹ̀yà Manase Ṣẹgun Bẹtẹli

22 Ati awọn ara ile Josefu, awọn pẹlu si gòke lọ bá Beti-eli jà: OLUWA si wà pẹlu wọn. 23 Awọn ara ile Josefu rán amí lọ si Beti-eli. (Orukọ ilu na ni ìgba atijọ rí si ni Lusi.) 24 Awọn amí na si ri ọkunrin kan ti o ti inu ilu na jade wá, nwọn si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, fi ọ̀na atiwọ̀ ilu yi hàn wa, awa o si ṣãnu fun ọ. 25 O si fi ọ̀na atiwọ̀ ilu na hàn wọn, nwọn si fi oju idà kọlù ilu na; ṣugbọn nwọn jọwọ ọkunrin na ati gbogbo awọn ara ile rẹ̀ lọwọ lọ. 26 Ọkunrin na si lọ si ilẹ awọn Hitti, o si tẹ̀ ilu kan dó, o si pè orukọ rẹ̀ ni Lusi: eyi si li orukọ rẹ̀ titi di oni.

Àwọn Tí Àwọn Ọmọ Israẹli Kò Lé Jáde

27 Manasse kò si lé awọn ara Beti-seani ati ilu rẹ̀ wọnni jade, tabi awọn ara Taanaki ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Dori ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Ibleamu ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Megiddo ati ilu rẹ̀ wọnni: ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ilẹ na. 28 O si ṣe, nigbati Israeli di alagbara tán, nwọn si mu awọn ara Kenaani sìn, nwọn kò si lé wọn jade patapata. 29 Efraimu kò si lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn ni Geseri. 30 Sebuluni kò lé awọn ara Kitroni jade, tabi awọn ara Nahalolu; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn, nwọn si nsìn. 31 Aṣeri kò lé awọn ara Akko jade, tabi awọn ara Sidoni, tabi awọn ara Alabu, tabi awọn ara Aksibu, tabi awọn ara Helba, tabi awọn ara Afiki, tabi awọn ara Rehobu: 32 Ṣugbọn awọn ọmọ Aṣeri ngbé ãrin awọn ara Kenaani, ti ngbé ilẹ na: nitoriti nwọn kò lé wọn jade. 33 Naftali kò lé awọn ara Beti-ṣemeṣi jade, tabi awọn ara Beti-anati; ṣugbọn on ngbé ãrin awọn ara Kenaani, ti ngbé ilẹ na: ṣugbọn awọn ara Beti-ṣemeṣi ati Beti-anati di ẹniti nsìn wọn. 34 Awọn Amori si fi agbara tì awọn ọmọ Dani sori òke: nitoripe nwọn kò jẹ ki nwọn ki o sọkalẹ wá si afonifoji. 35 Awọn Amori si ngbé òke Heresi, ni Aijaloni, ati ni Ṣaalbimu: ọwọ́ awọn ara ile Josefu bori, nwọn si di ẹniti nsìn. 36 Àla awọn Amori si ni lati ìgoke lọ si Akrabbimu, lati ibi apata lọ si òke.

Onidajọ 2

Angẹli OLUWA ní Bokimu

1 ANGELI OLUWA si ti Gilgali gòke wá si Bokimu. O si wipe, Emi mu nyin gòke lati Egipti wá, emi si mú nyin wá si ilẹ ti emi ti bura fun awọn baba nyin; emi si wipe, Emi ki yio dà majẹmu mi pẹlu nyin lailai: 2 Ẹnyin kò si gbọdọ bá awọn ara ilẹ yi dá majẹmu; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn lulẹ: ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ ohùn mi: Ẽha ti ṣe ti ẹnyin fi ṣe yi? 3 Nitorina emi pẹlu wipe, Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o jẹ́ ẹgún ni ìha nyin, ati awọn oriṣa wọn yio di ikẹkun fun nyin. 4 O si ṣe, nigbati angeli OLUWA sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, awọn enia na si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun. 5 Nwọn si pè orukọ ibẹ̀ na ni Bokimu: nwọn si ru ẹbọ nibẹ̀ si OLUWA.

Ikú Joṣua

6 Nigbati Joṣua si ti jọwọ awọn enia lọwọ lọ, olukuluku awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ilẹ-iní rẹ̀ lati gba ilẹ̀ na. 7 Awọn enia na si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, awọn ẹniti o ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA, ti o ṣe fun Israeli. 8 Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA si kú, nigbati o di ẹni ãdọfa ọdún. 9 Nwọn si sinkú rẹ̀ li àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnati-heresi, ni ilẹ òke Efraimu, li ariwa oke Gaaṣi. 10 Ati pẹlu a si kó gbogbo iran na jọ sọdọ awọn baba wọn: iran miran si hù lẹhin wọn, ti kò mọ̀ OLUWA, tabi iṣẹ ti o ṣe fun Israeli.

Israẹli Kọ̀ láti Sin OLUWA

11 Awọn ọmọ Israeli si ṣe buburu niwaju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu: 12 Nwọn si kọ̀ OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o mú wọn jade lati ilẹ Egipti wá, nwọn si ntọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia ti o yi wọn ká kiri, nwọn si nfi ori wọn balẹ fun wọn, nwọn si bi OLUWA ninu. 13 Nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn si nsìn Baali ati Aṣtarotu. 14 Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si fi wọn lé awọn akonilohun lọwọ, ti o kó wọn lẹrù, o si tà wọn si ọwọ́ awọn ọtá wọn yiká kiri, tobẹ̃ ti nwọn kò le duro mọ́ niwaju awọn ọtá wọn. 15 Nibikibi ti nwọn ba jade lọ, ọwọ́ OLUWA wà lara wọn fun buburu, gẹgẹ bi OLUWA ti wi, ati gẹgẹ bi OLUWA ti bura fun wọn: oju si pọ́n wọn pupọ̀pupọ̀. 16 OLUWA si gbé awọn onidajọ dide, ti o gbà wọn li ọwọ́ awọn ẹniti nkó wọn lẹrù. 17 Sibẹ̀sibẹ nwọn kò fetisi ti awọn onidajọ wọn, nitoriti nwọn ṣe panṣaga tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, nwọn si fi ori wọn balẹ fun wọn: nwọn yipada kánkan kuro li ọ̀na ti awọn baba wọn ti rìn, ni gbigbà ofin OLUWA gbọ́; awọn kò ṣe bẹ̃. 18 Nigbati OLUWA ba si gbé awọn onidajọ dide fun wọn, OLUWA a si wà pẹlu onidajọ na, on a si gbà wọn kuro li ọwọ́ awọn ọtá wọn ni gbogbo ọjọ́ onidajọ na: nitoriti OLUWA kãnu, nitori ikerora wọn nitori awọn ti npọ́n wọn loju, ti nwọn si nni wọn lara. 19 O si ṣe, nigbati onidajọ na ba kú, nwọn a si pada, nwọn a si bà ara wọn jẹ́ jù awọn baba wọn lọ, ni titọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma fi ori balẹ fun wọn; nwọn kò dẹkun iṣe wọn, ati ìwa-agidi wọn. 20 Ibinu OLUWA si rú si Israeli; o si wipe, Nitoriti orilẹ-ède yi ti re majẹmu mi kọja eyiti mo ti palaṣẹ fun awọn baba wọn, ti nwọn kò si gbọ́ ohùn mi; 21 Emi pẹlu ki yio lé ọkan jade mọ́ kuro niwaju wọn ninu awọn orilẹ-ède, ti Joṣua fisilẹ nigbati o kú: 22 Ki emi ki o le ma fi wọn dan Israeli wò, bi nwọn o ma ṣe akiyesi ọ̀na OLUWA lati ma rìn ninu rẹ̀, bi awọn baba wọn ti ṣe akiyesi rẹ̀, tabi bi nwọn ki yio ṣe e. 23 OLUWA si fi orilẹ-ède wọnni silẹ, li ailé wọn jade kánkan; bẹ̃ni kò si fi wọn lé Joṣua lọwọ.

Onidajọ 3

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ó Ṣẹ́kù lórí Ilẹ̀ Kenaani

1 NJẸ wọnyi li awọn orilẹ-ède ti OLUWA fisilẹ, lati ma fi wọn dan Israeli wò, ani iye awọn ti kò mọ̀ gbogbo ogun Kenaani; 2 Nitori idí yi pe, ki iran awọn ọmọ Israeli ki o le mọ̀, lati ma kọ́ wọn li ogun, ani irú awọn ti kò ti mọ̀ ọ niṣaju rí; 3 Awọn ijoye Filistini marun, ati gbogbo awọn Kenaani, ati awọn ara Sidoni, ati awọn Hifi ti ngbé òke Lebanoni, lati òke Baali-hermoni lọ dé atiwọ̀ Hamati. 4 Wọnyi li a o si ma fi dan Israeli wò, lati mọ̀ bi nwọn o fetisi ofin OLUWA, ti o fi fun awọn baba wọn lati ọwọ́ Mose wá. 5 Awọn ọmọ Israeli si joko lãrin awọn ara Kenaani; ati awọn Hitti, ati awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi: 6 Nwọn si fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, nwọn si fi awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmọkunrin wọn, nwọn si nsìn awọn oriṣa wọn.

Otnieli

7 Awọn ọmọ Israeli si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nwọn si gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, nwọn si nsìn Baalimu ati Aṣerotu. 8 Nitori na ibinu OLUWA ru si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia: awọn ọmọ Israeli si sìn Kuṣani-riṣataimu li ọdún mẹjọ. 9 Nigbati awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun awọn ọmọ Israeli, ẹniti o gbà wọn, ani Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu. 10 Ẹmi OLUWA si wà lara rẹ̀, on si ṣe idajọ Israeli, o si jade ogun, OLUWA si fi Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọwọ: ọwọ́ rẹ̀ si bori Kuṣani-riṣataimu. 11 Ilẹ na si simi li ogoji ọdún. Otnieli ọmọ Kenasi si kú.

Ehudu

12 Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru loju OLUWA: OLUWA si fi agbara fun Egloni ọba Moabu si Israeli, nitoripe nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju OLUWA. 13 O si kó awọn ọmọ Ammoni ati ti Amaleki mọra rẹ̀; o si lọ o kọlù Israeli, nwọn si gbà ilu ọpẹ. 14 Awọn ọmọ Israeli si sìn Egloni ọba Moabu li ọdún mejidilogun. 15 Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun wọn, Ehudu ọmọ Gera, ẹ̀ya Benjamini, ọlọwọ́-òsi: awọn ọmọ Israeli si fi ẹ̀bun rán a si Egloni ọba Moabu. 16 Ehudu si rọ idà kan olojumeji, igbọnwọ kan ni gigùn; on si sán a si abẹ aṣọ rẹ̀ ni itan ọtún. 17 O si mú ọrẹ na wá fun Egloni ọba Moabu; Egloni si jẹ́ ọkunrin ti o sanra pupọ̀. 18 Nigbati o si fi ọrẹ na fun u tán, o rán awọn enia ti o rù ọrẹ na pada lọ. 19 Ṣugbọn on tikara rẹ̀ pada lati ibi ere finfin ti o wà leti Gilgali, o si wipe, Ọba, mo lí ọ̀rọ ìkọkọ kan ibá ọ sọ. On si wipe, Ẹ dakẹ. Gbogbo awọn ẹniti o duro tì i si jade kuro lọdọ rẹ̀. 20 Ehudu si tọ̀ ọ wá; on si nikan joko ninu yará itura rẹ̀. Ehudu si wipe, Mo lí ọ̀rọ kan lati ọdọ Ọlọrun wá fun ọ. On si dide kuro ni ibujoko rẹ̀. 21 Ehudu si nà ọwọ́ òsi rẹ̀, o si yọ idà na kuro ni itan ọtún rẹ̀, o si fi gún u ni ikùn: 22 Ati idà ati ekù si wọle; ọrá si bò idà na nitoriti kò fà idà na yọ kuro ninu ikun rẹ̀; o si yọ lẹhin. 23 Nigbana ni Ehudu si ba ti iloro lọ, o si se ilẹkun gbọngan na mọ́ ọ, o si tì wọn. 24 Nigbati o si jade lọ tán, awọn iranṣẹ rẹ̀ dé; nigbati nwọn wò, si kiyesi i, awọn ilẹkun gbọngan tì; nwọn wipe, Li aisí aniani o bò ẹsẹ̀ rẹ̀ ninu yará itura rẹ̀. 25 Nwọn si duro titi o fi di itiju fun wọn: kiyesi i on kò si ṣí ilẹkun gbọngan na silẹ; nitorina nwọn mú ọmọlẹkun, nwọn si ṣí i: si kiyesi i, oluwa wọn ti ṣubu lulẹ kú. 26 Ehudu si sálọ nigbati nwọn nduro, o si kọja ibi ere finfin, o si sálọ si Seira. 27 O si ṣe, nigbati o dé, o fọn ipè ni ilẹ òke Efraimu, awọn ọmọ Israeli si bá a sọkalẹ lọ lati òke na wá, on si wà niwaju wọn. 28 On si wi fun wọn pe, Ẹ ma tọ̀ mi lẹhin: nitoriti OLUWA ti fi awọn ọtá nyin awọn ara Moabu lé nyin lọwọ. Nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ, nwọn si gbà ìwọdo Jordani, ti o wà ni ìha Moabu, nwọn kò si jẹ ki ẹnikan ki o kọja mọ̀. 29 Nwọn si pa ìwọn ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ara Moabu ni ìgba na, gbogbo awọn ti o sigbọnlẹ, ati gbogbo awọn akọni ọkunrin; kò sí ọkunrin kanṣoṣo ti o sálà. 30 Bẹ̃li a tẹ̀ ori Moabu ba ni ijọ́ na li abẹ ọwọ́ Israeli. Ilẹ na si simi li ọgọrin ọdún.

Ṣamgari

31 Lẹhin rẹ̀ ni Ṣamgari ọmọ Anati, ẹniti o fi ọpá ti a fi ndà akọmalu pa ẹgbẹta ọkunrin ninu awọn ara Filistini, on pẹlu si gbà Israeli.

Onidajọ 4

Debora ati Baraki

1 AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nigbati Ehudu kú tán. 2 OLUWA si tà wọn si ọwọ́ Jabini ọba Kenaani, ẹniti o jọba ni Hasori; olori ogun ẹniti iṣe Sisera, ẹniti ngbé Haroṣeti ti awọn orilẹ-ède. 3 Awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA: nitoriti o ní ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin; ogun ọdún li o si fi pọ́n awọn ọmọ Israeli loju gidigidi. 4 Ati Debora, wolĩ-obinrin, aya Lappidotu, o ṣe idajọ Israeli li akokò na. 5 On si ngbé abẹ igi-ọpẹ Debora li agbedemeji Rama ati Beti-eli ni ilẹ òke Efraimu: awọn ọmọ Israeli a si ma wá sọdọ rẹ̀ fun idajọ. 6 On si ranṣẹ pè Baraki ọmọ Abinoamu lati Kedeṣi-naftali jade wá, o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun Israeli kò ha ti paṣẹ pe, Lọ sunmọ òke Tabori, ki o si mú ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ọmọ Naftali, ati ninu awọn ọmọ Sebuluni pẹlu rẹ. 7 Emi o si fà Sisera, olori ogun Jabini, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati ogun rẹ̀, sọdọ rẹ si odò Kiṣoni; emi o si fi i lé ọ lọwọ. 8 Baraki si wi fun u pe, Bi iwọ o ba bá mi lọ, njẹ emi o lọ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba bá mi lọ, emi ki yio lọ. 9 On si wipe, Ni lilọ emi o bá ọ lọ: ṣugbọn ọlá ọ̀na ti iwọ nlọ nì ki yio jẹ́ tirẹ; nitoriti OLUWA yio tà Sisera si ọwọ́ obinrin. Debora si dide, o si bá Baraki lọ si Kedeṣi. 10 Baraki si pè Sebuluni ati Naftali si Kedeṣi; on si lọ pẹlu ẹgba marun ọkunrin lẹhin rẹ̀: Debora si gòke lọ pẹlu rẹ̀. 11 Njẹ Heberi ọmọ Keni, ti yà ara rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọmọ Keni, ani awọn ọmọ Hobabu, ana Mose, o si pa agọ́ rẹ̀ titi dé igi-oaku Saanannimu, ti o wà li àgbegbe Kedeṣi. 12 Nwọn si sọ fun Sisera pe, Baraki ọmọ Abinoamu ti lọ si òke Tabori. 13 Sisera si kó gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ jọ, ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, lati Haroṣeti awọn orilẹ-ède wá si odò Kiṣoni. 14 Debora si wi fun Baraki pe, Dide; nitoripe oni li ọjọ́ ti OLUWA fi Sisera lé ọ lọwọ: OLUWA kò ha ti ṣaju rẹ lọ bi? Bẹ̃ni Baraki sọkalẹ lati òke Tabori lọ, ẹgba marun ọkunrin si tẹle e lẹhin. 15 OLUWA si fi oju idà ṣẹgun Sisera, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun rẹ̀, niwaju Baraki; Sisera si sọkalẹ kuro li ori kẹkẹ́ rẹ̀, o si fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ. 16 Ṣugbọn Baraki lepa awọn kẹkẹ́, ati ogun na, titi dé Haroṣeti awọn orilẹ-ède: gbogbo ogun Sisera si ti oju idà ṣubu; ọkunrin kanṣoṣo kò si kù. 17 Ṣugbọn Sisera ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ si agọ́ Jaeli aya Heberi ọmọ Keni: nitoriti alafia wà lãrin Jabini ọba Hasori ati ile Heberi ọmọ Keni. 18 Jaeli si jade lọ ipade Sisera, o si wi fun u pe, Yà wá, oluwa mi, yà sọdọ mi; má bẹ̀ru. On si yà sọdọ rẹ̀ sinu agọ́, o si fi kubusu bò o. 19 On si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fun mi li omi diẹ mu; nitoriti ongbẹ ngbẹ mi. O si ṣí igo warà kan, o si fi fun u mu, o si bò o lara. 20 On si wi fun u pe, Duro li ẹnu-ọ̀na agọ́, yio si ṣe, bi ẹnikan ba wá, ti o si bi ọ lère pe, ọkunrin kan wà nihin bi? ki iwọ wipe, Kò sí. 21 Nigbana ni Jaeli aya Heberi mú iṣo-agọ́ kan, o si mú õlù li ọwọ́ rẹ̀, o si yọ́ tọ̀ ọ, o si kàn iṣo na mọ́ ẹbati rẹ̀, o si wọ̀ ilẹ ṣinṣin; nitoriti o sùn fọnfọn; bẹ̃ni o daku, o si kú. 22 Si kiyesi i, bi Baraki ti nlepa Sisera, Jaeli wá pade, rẹ̀, o si wi fun u pe, Wá, emi o si fi ọkunrin ti iwọ nwá hàn ọ. O si wá sọdọ rẹ̀; si kiyesi i, Sisera dubulẹ li okú, iṣo-agọ́ na si wà li ẹbati rẹ̀. 23 Bẹ̃li Ọlọrun si tẹ̀ ori Jabini ọba Kenaani ba li ọjọ́ na niwaju awọn ọmọ Israeli. 24 Ọwọ́ awọn ọmọ Israeli si le siwaju ati siwaju si Jabini ọba Kenaani, titi nwọn fi run Jabini ọba Kenaani.

Onidajọ 5

Orin Debora ati Baraki

1 NIGBANA ni Debora on Baraki ọmọ Abinoamu kọrin li ọjọ́ na, wipe, 2 Nitori bi awọn olori ti ṣaju ni Israeli, nitori bi awọn enia ti fi tinutinu wá, ẹ fi ibukún fun OLUWA. 3 Ẹ gbọ́, ẹnyin ọba; ẹ feti nyin silẹ, ẹnyin ọmọ alade; emi, ani emi, o kọrin si OLUWA; emi o kọrin iyìn si OLUWA, Ọlọrun Israeli. 4 OLUWA, nigbati iwọ jade kuro ni Seiri, nigbati iwọ nyan jade lati pápa Edomu wá, ilẹ mìtiti, awọn ọrun si kánsilẹ, ani awọsanma pẹlu kán omi silẹ. 5 Awọn òke nla yọ́ niwaju OLUWA, ani Sinai yọ́ niwaju OLUWA; Ọlọrun Israeli. 6 Li ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati, li ọjọ́ Jaeli, awọn ọ̀na opópo da, awọn èro si nrìn li ọ̀na ìkọ̀kọ̀. 7 Awọn olori tán ni Israeli, nwọn tán, titi emi Debora fi dide, ti emi dide bi iya ni Israeli. 8 Nwọn ti yàn ọlọrun titun; nigbana li ogun wà ni ibode: a ha ri asà tabi ọ̀kọ kan lãrin ẹgba ogún ni Israeli bi? 9 Àiya mi fà si awọn alaṣẹ Israeli, awọn ti nwọn fi tinutinu wá ninu awọn enia: ẹ fi ibukún fun OLUWA. 10 Ẹ sọ ọ, ẹnyin ti ngùn kẹtẹkẹtẹ funfun, ẹnyin ti njoko lori ẹni daradara, ati ẹnyin ti nrìn li ọ̀na. 11 Li ọ̀na jijìn si ariwo awọn tafàtafa nibiti a gbé nfà omi, nibẹ̀ ni nwọn o gbé sọ iṣẹ ododo OLUWA, ani iṣẹ ododo ijọba rẹ̀ ni Israeli. Nigbana ni awọn enia OLUWA sọkalẹ lọ si ibode. 12 Jí, jí, Debora; Jí, jí, kọ orin: dide, Baraki, ki o si ma kó awọn igbekun rẹ ni igbekun, iwọ ọmọ Abinoamu. 13 Nigbana ni iyokù ninu awọn ọlọ̀tọ ati awọn enia sọkalẹ; OLUWA sọkalẹ sori awọn alagbara fun mi. 14 Lati Efraimu ni nwọn ti wá awọn ti gbongbo wọn wà ni Amaleki; lẹhin rẹ, Benjamini, lãrin awọn enia rẹ; lati Makiri ni awọn alaṣẹ ti sọkalẹ wá, ati lati Sebuluni li awọn ẹniti nmú ọ̀pá-oyè lọwọ. 15 Awọn ọmọ-alade Issakari wà pẹlu Debora; bi Issakari ti ri, bẹ̃ni Baraki; nwọn sure li ẹsẹ̀ lọ si afonifoji na. Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà. 16 Ẽṣe ti iwọ fi joko lãrin agbo-agutan lati ma gbọ́ fere oluṣọ-agutan? Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà. 17 Gileadi joko loke odò Jordani: ẽṣe ti Dani fi joko ninu ọkọ̀? Aṣeri joko leti okun, o si ngbé ebute rẹ̀. 18 Sebuluni li awọn enia, ti o fi ẹmi wọn wewu ikú, ati Naftali, ni ibi giga pápa. 19 Awọn ọba wá nwọn jà; nigbana li awọn ọba Kenaani jà ni Taanaki leti odò Megiddo: nwọn kò si gbà ère owo. 20 Nwọn jà lati ọrun wá, awọn irawọ ni ipa wọn bá Sisera jà. 21 Odò Kiṣoni gbá wọn lọ, odò igbani, odò Kiṣoni. Hã ọkàn mi, ma yan lọ ninu agbara. 22 Nigbana ni patako ẹsẹ̀ ẹṣin kì ilẹ, nitori ire-sisá, iré-sisá awọn alagbara wọn. 23 Ẹ fi Merosi bú, bẹ̃li angeli OLUWA wi, ẹ fi awọn ara inu rẹ̀ bú ibú kikorò; nitoriti nwọn kò wá si iranlọwọ OLUWA, si iranlọwọ OLUWA si awọn alagbara. 24 Ibukún ni fun Jaeli aya Heberi ọmọ Keni jù awọn obinrin lọ, ibukún ni fun u jù awọn obinrin lọ ninu agọ́. 25 O bère omi, o fun u ni warà; o mu ori-amọ tọ̀ ọ wá ninu awo iyebiye. 26 O nà ọwọ́ rẹ̀ mú iṣo, ati ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú òlu awọn ọlọnà; òlu na li o si fi lù Sisera, o gba mọ́ ọ li ori, o si gún o si kàn ẹbati rẹ̀ mọlẹ ṣinṣin. 27 Li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu, o dubulẹ: li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu: ni ibi ti o gbè wolẹ, nibẹ̀ na li o ṣubu kú. 28 Iya Sisera nwò oju-ferese, o si kigbe, o kigbe li oju-ferese ọlọnà pe; Ẽṣe ti kẹkẹ́ rẹ̀ fi pẹ bẹ̃ lati dé? Ẽṣe ti ẹsẹ̀ kẹkẹ̀ rẹ̀ fi duro lẹhin? 29 Awọn obinrin rẹ̀ amoye da a lohùn, ani, on si ti da ara rẹ̀ lohùn pe, 30 Nwọn kò ha ti ri, nwọn kò ha ti pín ikogun bi? fun olukuluku ọkunrin wundia kan tabi meji; fun Sisera ikogun-aṣọ alarabara, ikógun-aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ, aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ ni ìha mejeji, li ọrùn awọn ti a kó li ogun. 31 Bẹ̃ni ki o jẹ ki gbogbo awọn ọtá rẹ ki o ṣegbé OLUWA: ṣugbọn jẹ ki awọn ẹniti o fẹ́ ẹ ki o dabi õrùn nigbati o ba yọ ninu agbara rẹ̀. Ilẹ na si simi li ogoji ọdún.

Onidajọ 6

Gideoni

1 AWỌN ọmọ Israeli si ṣe buburu loju OLUWA: OLUWA si fi wọn lé Midiani lọwọ li ọdún meje. 2 Ọwọ́ Midiani si le si Israeli: ati nitori Midiani awọn ọmọ Israeli wà ihò wọnni fun ara wọn, ti o wà ninu òke, ati ninu ọgbun, ati ni ibi-agbara wọnni. 3 O si ṣe, bi Israeli ba gbìn irugbìn, awọn Midiani a si gòke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn; nwọn a si gòke tọ̀ wọn wá; 4 Nwọn a si dótì wọn, nwọn a si run eso ilẹ na, titi iwọ o fi dé Gasa, nwọn ki isi fi onjẹ silẹ ni Israeli, tabi agutan, tabi akọ-malu, tabi kẹtẹkẹtẹ. 5 Nitoriti nwọn gòke wá ti awọn ti ohunọ̀sin wọn ati agọ́ wọn, nwọn si wá bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; awọn ati awọn ibakasiẹ wọn jẹ́ ainiye: nwọn si wọ̀ inu ilẹ na lati jẹ ẹ run. 6 Oju si pọ́n Israeli gidigidi nitori awọn Midiani; awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA. 7 O si ṣe, nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA nitori awọn Midiani, 8 OLUWA si rán wolĩ kan si awọn ọmọ Israeli: ẹniti o wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Emi mú nyin gòke ti Egipti wá, mo si mú nyin jade kuro li oko-ẹrú; 9 Emi si gbà nyin li ọwọ́ awọn ara Egipti, ati li ọwọ́ gbogbo awọn ti npọ́n nyin loju, mo si lé wọn kuro niwaju nyin, mo si fi ilẹ wọn fun nyin; 10 Mo si wi fun nyin pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin; ẹ máṣe bẹ̀ru oriṣa awọn Amori, ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn ẹnyin kò gbà ohùn mi gbọ́. 11 Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani. 12 Angeli OLUWA na si farahàn a, o si wi fun u pe, OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara. 13 Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ. 14 OLUWA si wò o, o si wipe, Lọ ninu agbara rẹ yi, ki iwọ ki ó si gbà Israeli là kuro lọwọ Midiani: Emi kọ ha rán ọ bi? 15 O si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ọ̀na wo li emi o fi gbà Israeli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jẹ́ ẹni ikẹhin ni ile baba mi. 16 OLUWA si wi fun u pe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ, iwọ o si kọlù awọn Midiani bi ọkunrin kan. 17 On si wi fun u pe, Bi o ba ṣepe mo ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, njẹ fi àmi kan hàn mi pe iwọ bá mi sọ̀rọ. 18 Máṣe lọ kuro nihin, emi bẹ̀ ọ, titi emi o fi tọ̀ ọ wá, ti emi o si fi mú ọrẹ mi fun ọ wá, ati ti emi o si fi gbé e kalẹ niwaju rẹ. On si wipe, Emi o duro titi iwọ o si fi pada wá. 19 Gideoni si wọ̀ inu ilé lọ, o si pèse ọmọ ewurẹ kan, ati àkara alaiwu ti iyẹfun òṣuwọn efa kan: ẹran na li o fi sinu agbọ̀n, omi rẹ̀ li o si fi sinu ìkoko, o si gbé e jade tọ̀ ọ wá labẹ igi-oaku na, o si gbé e siwaju rẹ̀. 20 Angeli Ọlọrun na si wi fun u pe, Mú ẹran na, ati àkara alaiwu na, ki o si fi wọn lé ori okuta yi, ki o si dà omi ẹran na silẹ. On si ṣe bẹ̃. 21 Nigbana ni angeli OLUWA nà ọpá ti o wà li ọwọ rẹ̀, o si fi ori rẹ̀ kàn ẹran na ati àkara alaiwu na; iná si là lati inu okuta na jade, o si jó ẹran na, ati àkara alaiwu; angeli OLUWA na si lọ kuro niwaju rẹ̀. 22 Gideoni si ri pe angeli OLUWA ni; Gideoni si wipe, Mo gbé, OLUWA Ọlọrun! nitoriti emi ri angeli OLUWA li ojukoju. 23 OLUWA si wi fun u pe, Alafia fun ọ; má ṣe bẹ̀ru: iwọ́ ki yio kú. 24 Nigbana ni Gideoni mọ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jehofa-ṣalomu: o wà ni Ofra ti awọn Abiesri sibẹ̀ titi di oni. 25 O si ṣe li oru ọjọ́ kanna, li OLUWA wi fun u pe, Mú akọ-malu baba rẹ, ani akọ-malu keji ọlọdún meje, ki o si wó pẹpẹ Baali ti baba rẹ ní lulẹ ki o si bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ: 26 Ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ lori ibi agbara yi, bi o ti yẹ, ki o si mú akọ-malu keji, ki o si fi igi-oriṣa ti iwọ bẹ́ lulẹ ru ẹbọ sisun. 27 Nigbana ni Gideoni mú ọkunrin mẹwa ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, o si ṣe bi OLUWA ti sọ fun u: o si ṣe, nitoripe o bẹ̀ru ile baba rẹ̀ ati awọn ọkunrin ilu na, tobẹ̃ ti kò fi le ṣe e li ọsán, ti o si fi ṣe e li oru. 28 Nigbati awọn ọkunrin ilu na si dide ni kùtukutu, si wò o, a ti wó pẹpẹ Baali lulẹ, a si bẹ́ igi-oriṣa lulẹ ti o wà lẹba rẹ̀, a si ti pa akọ-malu keji rubọ lori pẹpẹ ti a mọ. 29 Nwọn si sọ fun ara wọn pe, Tali o ṣe nkan yi? Nigbati nwọn tọ̀sẹ̀, ti nwọn si bère, nwọn si wipe, Gideoni ọmọ Joaṣi li o ṣe nkan yi. 30 Nigbana li awọn ọkunrin ilu na wi fun Joaṣi pe, Mú ọmọ rẹ jade wá ki o le kú: nitoripe o wó pẹpẹ Baali lulẹ, ati nitoriti o bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ. 31 Joaṣi si wi fun gbogbo awọn ti o duro tì i pe, Ẹnyin o gbèja Baali bi? tabi ẹnyin o gbà a là bi? ẹniti o ba ngbèja rẹ̀, ẹ jẹ ki a lù oluwarẹ̀ pa ni kùtukutu owurọ yi: bi on ba ṣe ọlọrun, ẹ jẹ ki o gbèja ara rẹ̀, nitoriti ẹnikan wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ. 32 Nitorina li ọjọ́ na, o pè orukọ rẹ̀ ni Jerubbaali, wipe, Jẹ ki Baali ki o bá a jà, nitoriti o wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ. 33 Nigbana ni gbogbo awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn kó ara wọn jọ pọ̀; nwọn rekọja, nwọn si dó li afonifoji Jesreeli. 34 Ṣugbọn ẹmi OLUWA bà lé Gideoni, on si fun ipè; Abieseri si kójọ sẹhin rẹ̀. 35 On si rán onṣẹ si gbogbo Manasse; awọn si kójọ sẹhin rẹ̀ pẹlu: o si rán onṣẹ si Aṣeri, ati si Sebuluni, ati si Naftali; nwọn si gòke wá lati pade wọn. 36 Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Bi iwọ o ba ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, bi iwọ ti wi, 37 Kiyesi i, emi o fi irun agutan le ilẹ-pakà; bi o ba ṣepe ìri sẹ̀ sara kìki irun nikan, ti gbogbo ilẹ si gbẹ, nigbana li emi o mọ̀ pe iwọ o ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, gẹgẹ bi iwọ ti wi. 38 Bẹ̃li o si ri: nitoriti on dide ni kùtukutu ijọ́ keji, o si fọ́n irun agutan na, o si fọ́n ìri na kuro lara rẹ̀, ọpọ́n kan si kún fun omi. 39 Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Má ṣe jẹ ki ibinu rẹ ki o rú si mi, emi o sọ̀rọ lẹ̃kanṣoṣo yi: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o fi irun na ṣe idanwò lẹ̃kan yi; jẹ ki irun agutan nikan ki o gbẹ, ṣugbọn ki ìri ki o wà lori gbogbo ilẹ. 40 Ọlọrun si ṣe bẹ̃ li oru na: nitoriti irun agutan na gbẹ, ìri si wà lori gbogbo ilẹ na.

Onidajọ 7

1 NIGBANA ni Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, dide ni kùtukutu, nwọn si dó lẹba orisun Harodu: ibudó Midiani si wà ni ìha ariwa wọn, nibi òke More, li afonifoji. 2 OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia ti o wà lọdọ rẹ pọ̀ju fun mi lati fi awọn Midiani lé wọn lọwọ, ki Israeli ki o má ba gbé ara wọn ga si mi, pe, Ọwọ́ mi li o gbà mi là. 3 Njẹ nitorina, lọ kede li etí awọn enia na, wipe, Ẹnikẹni ti o ba nfòya ti ẹ̀ru ba si mbà, ki o pada lati òke Gileadi ki o si lọ. Ẹgbã mọkanla si pada ninu awọn enia na; awọn ti o kù si jẹ́ ẹgba marun. 4 OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia na pọ̀ju sibẹ̀; mú wọn sọkalẹ wá si odò, nibẹ̀ li emi o gbé dan wọn wò fun ọ: yio si ṣe, ẹniti mo ba wi fun ọ pe, Eyi ni yio bá ọ lọ, on na ni yio bá ọ lọ; ẹnikẹni ti mo ba si wi fun ọ pe, Eyi ki yio bá ọ lọ, on na ni ki yio si bá ọ lọ. 5 Bẹ̃li o mú awọn enia na wá si odò: OLUWA si wi fun Gideoni pe, Olukuluku ẹniti o ba fi ahọn rẹ̀ lá omi, bi ajá ti ma lá omi, on na ni ki iwọ ki o fi si apakan fun ara rẹ̀; bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ lati mu omi. 6 Iye awọn ẹniti o lá omi, ti nwọn fi ọwọ́ wọn si ẹnu wọn, jẹ́ ọdunrun ọkunrin: ṣugbọn gbogbo awọn enia iyokù kunlẹ li ẽkun wọn lati mu omi. 7 OLUWA si wi fun Gideoni pe, Nipaṣe ọdunrun ọkunrin wọnyi ti o lá omi li emi o gbà nyin, emi o si fi awọn Midiani lé ọ lọwọ: jẹ ki gbogbo awọn iyokù lọ olukuluku si ipò rẹ̀. 8 Awọn enia na si mu onjẹ ati ipè li ọwọ́ wọn: on si rán gbogbo Israeli lọ, olukuluku sinu agọ́ rẹ̀, o si da ọdunrun ọkunrin nì duro: ibudó Midiani si wà nisalẹ rẹ̀ li afonifoji. 9 O si ṣe li oru na, ni OLUWA wi fun u pe, Dide, sọkalẹ lọ si ibudó; nitoriti mo ti fi i lé ọ lọwọ. 10 Ṣugbọn bi iwọ ba mbẹ̀ru lati sọkalẹ lọ, ki iwọ ati Pura iranṣẹ rẹ sọkalẹ lọ si ibudo: 11 Iwọ o si gbọ́ ohun ti nwọn nwi; lẹhin eyi ni ọwọ́ rẹ yio lí agbara lati sọkalẹ lọ si ibudó. Nigbana ni ti on ti Pura iranṣẹ rẹ̀ sọkalẹ lọ si ìha opin awọn ti o hamora, ti o wà ni ibudó. 12 Awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati gbogbo awọn ọmọ ìha ìla-õrùn tò lọ titi li afonifoji gẹgẹ bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; ibakasiẹ wọn kò si ní iye, bi iyanrin ti mbẹ leti okun li ọ̀pọlọpọ. 13 Nigbati Gideoni si dé, kiyesi i, ọkunrin kan nrọ́ alá fun ẹnikeji rẹ̀, o si wipe, Kiyesi i, emi lá alá kan, si wò o, àkara ọkà-barle kan ṣubu si ibudó Midiani, o si bọ́ sinu agọ́ kan, o si kọlù u tobẹ̃ ti o fi ṣubu, o si doju rẹ̀ de, agọ́ na si ṣubu. 14 Ekeji rẹ̀ si da a lohùn, wipe, Eyiyi ki iṣe ohun miran bikoṣe idà Gideoni ọmọ Joaṣi, ọkunrin kan ni Israeli: nitoripe Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ibudo lé e lọwọ. 15 O si ṣe, nigbati Gideoni gbọ́ rirọ́ alá na, ati itumọ̀ rẹ̀, o tẹriba; o si pada si ibudó Israeli, o si wipe, Ẹ dide; nitoriti OLUWA ti fi ogun Midiani lé nyin lọwọ. 16 On si pín ọdunrun ọkunrin na si ẹgbẹ mẹta, o si fi ipè lé olukuluku wọn lọwọ, pẹlu ìṣa ofo, òtufu si wà ninu awọn ìṣa na. 17 On si wi fun wọn pe, Ẹ wò mi, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ: si kiyesi i, nigbati mo ba dé opin ibudó na, yio si ṣe bi emi ba ti ṣe, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ṣe. 18 Nigbati mo ba fun ìpe, emi ati gbogbo awọn ti mbẹ lọdọ mi, nigbana ni ki ẹnyin pẹlu ki o fun ìpe yiká gbogbo ibudó na, ki ẹnyin ki o si wi pe, Fun OLUWA, ati fun Gideoni. 19 Bẹ̃ni Gideoni, ati ọgọrun ọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀, wá si opin ibudó, ni ibẹ̀rẹ iṣọ́ ãrin, nigbati nwọn ṣẹṣẹ yàn iṣọ́ sode: nwọn fun ipè, nwọn si fọ́ ìṣa ti o wà li ọwọ́ wọn. 20 Ẹgbẹ mẹtẹta na si fun ipè wọn, nwọn si fọ́ ìṣa wọn, nwọn si mú awọn òtufu li ọwọ́ òsi wọn, ati ipè li ọwọ́ ọtún lati fun: nwọn si kigbe li ohùn rara pe, Idà OLUWA, ati ti Gideoni. 21 Olukuluku ọkunrin si duro ni ipò rẹ̀ yi ibudó na ká: gbogbo ogun na si sure, nwọn si kigbe, nwọn si sá. 22 Awọn ọkunrin na fun ọdunrun ipè, OLUWA si yí idà olukuluku si ẹnikeji rẹ̀, ati si gbogbo ogun na: ogun na si sá titi dé Beti-ṣita ni ìha Serera, dé àgbegbe Abeli-mehola, leti Tabati. 23 Awọn ọkunrin Israeli si kó ara wọn jọ lati Naftali, ati lati Aṣeri ati lati gbogbo Manasse wá, nwọn si lepa awọn Midiani. 24 Gideoni si rán onṣẹ lọ si gbogbo òke Efraimu, wipe, Ẹ sọkalẹ wá pade awọn Midiani, ki ẹ si tète gbà omi wọnni dé Beti-bara ani Jordani. Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin Efraimu kó ara wọn jọ, nwọn si gbà omi wọnni, titi dé Beti-bara ani Jordani. 25 Nwọn si mú meji ninu awọn ọmọ-alade Midiani, Orebu ati Seebu; Orebu ni nwọn si pa lori apata Orebu, ati Seebu ni nwọn si pa ni ibi-ifọnti Seebu, nwọn si lepa awọn ara Midiani, nwọn si mú ori Orebu ati Seebu wá fi fun Gideoni li apa keji odò Jordani.

Onidajọ 8

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Àwọn Ará Midiani ní Àṣẹ́tán

1 AWỌN ọkunrin Efraimu si wi fun u pe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa bayi, ti iwọ kò fi pè wa, nigbati iwọ nlọ bá awọn ara Midiani jà? Nwọn si bá a sọ̀ gidigidi. 2 On si wi fun wọn pe, Kini mo ha ṣe nisisiyi ti a le fiwe ti nyin? Ẽṣẹ́ àjara Efraimu kò ha san jù ikore-àjara Abieseri lọ? 3 Ọlọrun sá ti fi awọn ọmọ-alade Midiani lé nyin lọwọ, Orebu ati Seebu: kini mo si le ṣe bi nyin? Nigbana ni inu wọn tutù si i, nigbati o ti wi eyinì. 4 Gideoni si dé odò Jordani, o si rekọja, on ati ọdunrun ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀, o di ãrẹ, ṣugbọn nwọn nlepa sibẹ̀. 5 On si wi fun awọn ọkunrin Sukkotu pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ìṣu-àkara melokan fun awọn enia wọnyi ti ntọ̀ mi lẹhin: nitoriti o di ãrẹ fun wọn, emi si nlepa Seba ati Salmunna, awọn ọba Midiani. 6 Awọn ọmọ-alade Sukkotu si wi pe, ọwọ́ rẹ ha ti ítẹ Seba on Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ogun rẹ li onjẹ? 7 Gideoni si wipe, Nitorina nigbati OLUWA ba fi Seba ati Salmunna lé mi lọwọ, nigbana li emi o fi ẹgún ijù, ati oṣuṣu yà ẹran ara nyin. 8 On si gòke lati ibẹ̀ lọ si Penueli, o si sọ fun wọn bẹ̃ gẹgẹ: awọn ọkunrin Penueli si da a lohùn gẹgẹ bi awọn ara Sukkotu si ti da a lohùn. 9 On si wi fun awọn ọkunrin Penueli pẹlu pe, Nigbati mo ba pada dé li alafia, emi o wó ile-ẹṣọ́ yi lulẹ̀. 10 Njẹ Seba ati Salmunna wà ni Karkori, ogun wọn si wà pẹlu wọn, o to ìwọn ẹdẹgbajọ ọkunrin, iye awọn ti o kù ninu gbogbo ogun awọn ọmọ ìha ìla-õrùn: nitoripe ẹgba ọgọta ọkunrin ti o lo idà ti ṣubu. 11 Gideoni si gbà ọ̀na awọn ti ngbé inú agọ́ ni ìha ìla-õrùn Noba ati Jogbeha gòke lọ, o si kọlù ogun na; nitoriti ogun na ti sọranù. 12 Seba ati Salmunna si sá; on si lepa wọn; o si mù awọn ọba Midiani mejeji na, Seba ati Salmunna, o si damu gbogbo ogun na. 13 Gideoni ọmọ Joaṣi si pada lẹhin ogun na, ni ibi ati gòke Heresi. 14 O si mú ọmọkunrin kan ninu awọn ọkunrin Sukkotu, o si bère lọwọ rẹ̀: on si ṣe apẹrẹ awọn ọmọ-alade Sukkotu fun u, ati awọn àgba ti o wà nibẹ̀, mẹtadilọgọrin ọkunrin. 15 On si tọ̀ awọn ọkunrin Sukkotu na wá, o si wi fun wọn pe, Wò Seba ati Salmunna, nitori awọn ẹniti ẹnyin fi gàn mi pe, Ọwọ́ rẹ ha ti tẹ Seba ati Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ọkunrin rẹ ti ãrẹ mu li onjẹ? 16 On si mú awọn àgbagba ilu na, ati ẹgún ijù ati oṣuṣu, o si fi kọ́ awọn ọkunrin Sukkotu li ọgbọ́n. 17 On si wó ile-ẹṣọ́ Penueli, o si pa awọn ọkunrin ilu na. 18 Nigbana li o sọ fun Seba ati Salmunna, wipe, Irú ọkunrin wo li awọn ẹniti ẹnyin pa ni Taboru? Nwọn si dahùn, Bi iwọ ti ri, bẹ̃ni nwọn ri; olukuluku nwọn dabi awọn ọmọ ọba. 19 On si wipe, Arakunrin mi ni nwọn, ọmọ iya mi ni nwọn iṣe: bi OLUWA ti wà, ibaṣepe ẹnyin da wọn si, emi kì ba ti pa nyin. 20 On si wi fun Jeteri arẹmọ rẹ̀ pe, Dide, ki o si pa wọn. Ṣugbọn ọmọkunrin na kò fà idà rẹ̀ yọ: nitori ẹ̀ru bà a, nitoripe ọmọde ni iṣe. 21 Nigbana ni Seba ati Salmunna wipe, Iwọ dide, ki o si kọlù wa: nitoripe bi ọkunrin ti ri, bẹ̃li agbara rẹ̀ ri. Gideoni si dide, o si pa Seba ati Salmunna, o si bọ́ ohun ọṣọ́ wọnni kuro li ọrùn ibakasiẹ wọn. 22 Nigbana li awọn ọkunrin Israeli wi fun Gideoni pe, Iwọ ma ṣe olori wa, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ pẹlu: nitoripe o gbà wa lọwọ awọn ara Midiani. 23 Gideoni si wi fun wọn pe, Emi ki yio ṣe olori nyin, bẹ̃ni ọmọ mi ki yio ṣe olori nyin: OLUWA ni yio ma ṣe alaṣẹ nyin. 24 Gideoni si wi fun wọn pe, Emi o bère nkan lọwọ nyin, pe ki olukuluku nyin ki o le fi oruka-etí ti mbẹ ninu ikogun rẹ̀ fun mi. (Nitoriti nwọn ní oruka-etí ti wurà, nitoripe ọmọ Iṣmaeli ni nwọn iṣe.) 25 Nwọn si dahùn wipe, Tinutinu li awa o fi mú wọn wá. Nwọn si tẹ́ aṣọ kan, olukuluku nwọn si sọ oruka-etí ikogun rẹ̀ si i. 26 Ìwọn oruka-etí wurà na ti o bère lọwọ wọn jẹ́ ẹdẹgbẹsan ṣekeli wurà: làika ohun ọṣọ́ wọnni, ati ohun sisorọ̀, ati aṣọ elesè-àluko ti o wà lara awọn ọba Midiani, ati li àika ẹ̀wọn ti o wà li ọrùn ibakasiẹ wọn. 27 Gideoni si fi i ṣe ẹ̀wu-efodu kan, o si fi i si ilu rẹ̀, ni Ofra: gbogbo Israeli si ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin nibẹ̀: o si wa di idẹkun fun Gideoni, ati fun ile rẹ̀. 28 Bẹ̃li a si tẹ̀ ori Midiani ba niwaju awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si gbé ori wọn soke mọ́. Ilẹ na si simi ni ogoji ọdún li ọjọ́ Gideoni.

Ikú Gideoni

29 Jerubbaali ọmọ Joaṣi si lọ o si ngbe ile rẹ̀. 30 Gideoni si ní ãdọrin ọmọkunrin ti o bi fun ara rẹ̀: nitoripe o lí obinrin pupọ̀. 31 Ale rẹ̀ ti o wà ni Ṣekemu, on pẹlu bi ọmọkunrin kan fun u, orukọ ẹniti a npè ni Abimeleki. 32 Gideoni ọmọ Joaṣi si kú li ọjọ́ ogbó, a si sin i si ibojì Joaṣi baba rẹ̀, ni Ofra ti awọn Abieseri. 33 O si ṣe, lojukanna ti Gideoni kú, li awọn ọmọ Israeli pada, nwọn si ṣe panṣaga tọ̀ Baalimu lọ, nwọn si fi Baaliberiti ṣe oriṣa wọn. 34 Awọn ọmọ Israeli kò si ranti OLUWA Ọlọrun wọn, ẹniti o gbà wọn lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn ni ìha gbogbo: 35 Bẹ̃ni nwọn kò si ṣe ore fun ile Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, gẹgẹ bi gbogbo ire ti o ti ṣe fun Israeli.

Onidajọ 9

Abimeleki

1 ABIMELEKI ọmọ Jerubbaali si lọ si Ṣekemu sọdọ awọn arakunrin iya rẹ̀, o si bá wọn sọ̀rọ, ati gbogbo idile ile baba iya rẹ̀, wipe, 2 Emi bẹ̀ nyin, ẹ sọ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu pe, Ẽwo li o rọ̀run fun nyin, ki gbogbo awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, ki o ṣe olori nyin, tabi ki ẹnikan ki o ṣe olori nyin? ki ẹnyin ki o ranti pẹlu pe, emi li egungun nyin, ati ẹran ara nyin. 3 Awọn arakunrin iya rẹ̀ si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi nitori rẹ̀ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu: àiya wọn si tẹ̀ si ti Abimeleki; nitori nwọn wipe, Arakunrin wa ni iṣe. 4 Nwọn si fun u li ãdọrin owo fadakà lati inu ile Baali-beriti wá, Abimeleki si fi i bẹ̀ awọn enia lasan ati alainilari li ọ̀wẹ, nwọn si ntẹ̀le e. 5 On si lọ si ile baba rẹ̀ ni Ofra, o si pa awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, lori okuta kan: ṣugbọn o kù Jotamu abikẹhin ọmọ Jerubbaali; nitoriti o sapamọ́. 6 Gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu si kó ara wọn jọ, ati gbogbo awọn ara ile Millo, nwọn lọ nwọn si fi Abimeleki jẹ́ ọba, ni ibi igi-oaku ile-ẹṣọ́ ti mbẹ ni Ṣekemu. 7 Nigbati nwọn si sọ fun Jotamu, on si lọ o si duro lori òke Gerisimu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o kigbe, o si wi fun wọn pe, Ẹ fetisi ti emi, ẹnyin ọkunrin Ṣekemu, ki Ọlọrun ki o le fetisi ti nyin. 8 Awọn igi lọ li akokò kan ki nwọn ki o le fi ọba jẹ́ lori wọn; nwọn si wi fun igi olifi pe, Wá jọba lori wa. 9 Ṣugbọn igi olifi wi fun wọn pe, Emi ha le fi ọrá mi silẹ, nipa eyiti nwọn nfi mi bù ọlá fun Ọlọrun ati enia, ki emi ki o si wá ṣe olori igi? 10 Awọn igi si wi fun igi ọpọtọ́ pe, Iwọ wá jọba lori wa. 11 Ṣugbọn igi ọpọtọ́ wi fun wọn pe, Emi le fi adùn mi silẹ, ati eso mi daradara, ki emi ki o si wá ṣe olori awọn igi? 12 Awọn igi si wi fun àjara pe, Iwọ wá jọba lori wa. 13 Àjara si wi fun wọn pe, Ki emi ki o fi ọti-waini mi silẹ, eyiti nmu inu Ọlọrun ati enia dùn, ki emi ki o si wá ṣe olori awọn igi? 14 Nigbana ni gbogbo igi si wi fun igi-ẹgún pe, Iwọ wá jọba lori wa. 15 Igi-ẹgún si wi fun awọn igi pe, Bi o ba ṣepe nitõtọ li ẹnyin fi emi jẹ́ ọba lori nyin, njẹ ẹ wá sá si abẹ ojiji mi: bi kò ba si ṣe bẹ̃, jẹ ki iná ki o ti inu igi-ẹgún jade wá, ki o si jó awọn igi-kedari ti Lebanoni run. 16 Njẹ nitorina, bi ẹnyin ba ṣe otitọ, ati eyiti o pé, ni ti ẹnyin fi Abimeleki jẹ ọba, ati bi ẹnyin ba si ṣe rere si Jerubbaali ati si ile rẹ̀, ti ẹnyin si ṣe si i gẹgẹ bi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀; 17 (Nitoriti baba mi jà fun nyin, o si fi ẹmi rẹ̀ wewu, o si gbà nyin kuro li ọwọ Midiani: 18 Ẹnyin si dide si ile baba mi li oni, ẹnyin si pa awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ãdọrin enia, lori okuta kan, ẹnyin si fi Abimeleki, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ̀ jẹ́ ọba lori awọn Ṣekemu, nitoriti arakunrin nyin ni iṣe;) 19 Njẹ bi ẹnyin ba ṣe otitọ, ati eyiti o pé si Jerubbaali ati si ile rẹ̀ li oni yi, njẹ ki ẹnyin ki o ma yọ̀ si Abimeleki, ki on pẹlu si ma yọ̀ si nyin: 20 Ṣugbọn bi kò ba si ri bẹ̃, jẹ ki iná ki o ti ọdọ Abimeleki jade wá, ki o si jó awọn ọkunrin Ṣekemu run, ati ile Millò: jẹ ki iná ki o si ti ọdọ awọn ọkunrin Ṣekemu ati ile Millo jade wá, ki o si jó Abimeleki run. 21 Jotamu si ṣí, o sálọ, o si lọ si Beeri, o si joko sibẹ̀, nitori ìbẹru Abimeleki arakunrin rẹ̀. 22 Abimeleki sí ṣe olori awọn ọmọ Israeli li ọdún mẹta. 23 Ọlọrun si rán ẹmi buburu sãrin Abimeleki ati awọn ọkunrin Ṣekemu; awọn ọkunrin Ṣekemu si fi arekereke bá Abimeleki lò: 24 Ki ìwa-ìka ti a ti hù si awọn ãdọrin ọmọ Jerubbaali ki o le wá, ati ẹ̀jẹ wọn sori Abimeleki arakunrin wọn, ẹniti o pa wọn; ati sori awọn ọkunrin Ṣekemu, awọn ẹniti o ràn a lọwọ lati pa awọn arakunrin rẹ̀. 25 Awọn ọkunrin Ṣekemu si yàn awọn enia ti o ba dè e lori òke, gbogbo awọn ti nkọja lọdọ wọn ni nwọn si njà a li ole: nwọn si sọ fun Abimeleki. 26 Gaali ọmọ Ebedi si wá ti on ti awọn arakunrin rẹ̀, nwọn si kọja lọ si Ṣekemu: awọn ọkunrin Ṣekemu si gbẹkẹ wọn le e. 27 Nwọn si jade lọ si oko, nwọn si ká eso-àjara wọn, nwọn si fọ́n eso na, nwọn si nṣe ariya, nwọn si lọ si ile oriṣa wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu, nwọn si fi Abimeleki ré. 28 Gaali ọmọ Ebedi si wipe, Tani Abimeleki? ta si ni Ṣekemu, ti awa o fi ma sìn i? Ṣe ọmọ Jerubbaali ni iṣe? ati Sebulu ijoye rẹ̀? ẹ mã sìn awọn ọkunrin Hamoru baba Ṣekemu: ṣugbọn nitori kili awa o ha ṣe ma sìn on? 29 Awọn enia wọnyi iba wà ni ikawọ mi! nigbana ni emi iba ṣí Abimeleki ni ipò. On si wi fun Abimeleki pe, Gbá ogun kún ogun rẹ, ki o si jade. 30 Nigbati Sebulu alaṣẹ ilu na si gbọ́ ọ̀rọ Gaali ọmọ Ebedi, o binu gidigidi. 31 On si rán awọn onṣẹ ìkọkọ si Abimeleki, wipe, Kiyesi i, Gaali ọmọ Ebedi ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si Ṣekemu; si kiyesi i, nwọn rú ilú na sokè si ọ. 32 Njẹ nitorina, dide li oru, iwọ ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ, ki ẹnyin ki o si ba sinu oko: 33 Yio si ṣe, li owurọ̀, lojukanna bi õrùn ba si ti là, ki iwọ ki o dide ni kùtukutu owurọ̀, ki iwọ ki o si kọlù ilu na: si kiyesi i, nigbati on ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ ba jade tọ̀ ọ, nigbana ni ki iwọ ki o ṣe si wọn bi iwọ ba ti ri pe o yẹ. 34 Abimeleki si dide, ati gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ li oru, nwọn si ba ni ipa mẹrin leti Ṣekemu. 35 Gaali ọmọ Ebedi si jade, o si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: Abimeleki si dide, ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, kuro ni ibùba. 36 Nigbati Gaali si ri awọn enia na, o wi fun Sebulu pe, Wò o, awọn enia nti ori òke sọkalẹ wa. Sebulu si wi fun u pe, Ojiji òke wọnni ni iwọ ri bi ẹnipe enia. 37 Gaali si tun wipe, Wò o, awọn enia nti òke sọkalẹ li agbedemeji ilẹ wá, ẹgbẹ kan si nti ọ̀na igi-oaku Meonenimu wá. 38 Nigbana ni Sebulu wi fun u pe, Nibo li ẹnu rẹ wà nisisiyi, ti iwọ fi wipe, Tani Abimeleki, ti awa o fi ma sìn i? awọn enia ti iwọ ti gàn kọ́ ni iwọnyi? jọwọ jade lọ, nisisiyi, ki o si bà wọn jà. 39 Gaali si jade niwaju awọn ọkunrin Ṣekemu, o si bá Abimeleki jà. 40 Abimeleki si lé e, on si sá niwaju rẹ̀, ọ̀pọlọpọ ninu nwọn ti o gbọgbẹ si ṣubu, titi dé ẹnu-ọ̀na ibode. 41 Abimeleki si joko ni Aruma: Sebulu si tì Gaali ati awọn arakunrin rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe joko ni Ṣekemu. 42 O si ṣe ni ijọ keji, ti awọn enia si jade lọ sinu oko; nwọn si sọ fun Abimeleki. 43 On si mu awọn enia, o si pín wọn si ipa mẹta, o si ba ninu oko: o si wò, si kiyesi i, awọn enia nti ilu jade wá; on si dide si wọn, o si kọlù wọn. 44 Abimeleki, ati ẹgbẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀ sure siwaju, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: ẹgbẹ meji si sure si gbogbo awọn enia na ti o wà ninu oko, nwọn si kọlù wọn. 45 Abimeleki si bá ilu na jà ni gbogbo ọjọ́ na; on si kó ilu na, o si pa awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, o si wó ilu na palẹ, o si fọn iyọ̀ si i. 46 Nigbati gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu gbọ́, nwọn si wọ̀ inu ile-ẹṣọ́ oriṣa Eliberiti lọ. 47 A si sọ fun Abimeleki pe, gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu kó ara wọn jọ pọ̀. 48 Abimeleki si gùn ori òke Salmoni lọ, on ati gbogbo enia ti o wà pẹlu rẹ̀; Abimeleki si mu ãke kan li ọwọ́ rẹ̀, o si ke ẹka kan kuro lara igi, o si mú u, o si gbé e lé èjika rẹ̀, o si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Ohun ti ẹnyin ri ti emi ṣe, ẹ yára, ki ẹ si ṣe bi emi ti ṣe. 49 Gbogbo awọn enia na pẹlu, olukuluku si ke ẹka tirẹ̀, nwọn si ntọ̀ Abimeleki lẹhin, nwọn si fi wọn sinu ile-ẹṣọ́ na, nwọn si tinabọ ile na mọ́ wọn lori, tobẹ̃ ti gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu fi kú pẹlu, ìwọn ẹgbẹrun enia, ọkunrin ati obinrin. 50 Nigbana ni Abimeleki lọ si Tebesi, o si dótì Tebesi, o si kó o. 51 Ṣugbọn ile-ẹṣọ́ ti o lagbara wà ninu ilu na, nibẹ̀ ni gbogbo awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati gbogbo awọn ẹniti o wà ni ilu na gbé sá si, nwọn si fara wọn mọ́ ibẹ̀; nwọn si gòke ile-ẹṣọ́ na lọ. 52 Abimeleki si wá si ibi ile-ẹṣọ́ na, o si bá a jà, o si sunmọ ẹnu-ọ̀na ile-ẹṣọ na lati fi iná si i. 53 Obinrin kan si sọ ọlọ lù Abimeleki li ori, o si fọ́ ọ li agbári. 54 Nigbana li o pè ọmọkunrin ti nrù ihamọra rẹ̀ kánkan, o si wi fun u pe, Fà idà rẹ yọ, ki o si pa mi, ki awọn enia ki o má ba wi nipa ti emi pe, Obinrin li o pa a. Ọmọkunrin rẹ̀ si gún u, bẹ̃li o si kú. 55 Nigbati awọn ọkunrin Israeli si ri pe, Abimeleki kú, nwọn si lọ olukuluku si ipò rẹ̀. 56 Bayi li Ọlọrun san ìwa buburu Abimeleki, ti o ti hù si baba rẹ̀, niti pe, o pa ãdọrin awọn arakunrin rẹ̀: 57 Ati gbogbo ìwa buburu awọn ọkunrin Ṣekemu li Ọlọrun si múpada sori wọn: egún Jotamu ọmọ Jerubbaali si ṣẹ sori wọn.

Onidajọ 10

Tola

1 LẸHIN Abimeleki li ẹnikan si dide lati gbà Israeli là, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, ọkunrin Issakari kan; o si ngbé Ṣamiri li òke Efraimu. 2 On si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹtalelogun o si kú, a si sin i ni Ṣamiri.

Jairi

3 Lẹhin rẹ̀ ni Jairi dide, ara Gileadi; o si ṣe idajọ Israeli li ọdún mejilelogun. 4 On si ní ọgbọ̀n ọmọkunrin ti ngùn ọgbọ̀n ọmọ kẹtẹkẹtẹ, nwọn si ní ọgbọ̀n ilu ti a npè ni Haffoti-jairi titi o fi di oni, eyiti o wà ni ilẹ Gileadi. 5 Jairi si kú, a si sin i ni Kamoni.

Jẹfuta

6 Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu, ati Aṣtarotu, ati awọn oriṣa Siria, ati awọn oriṣa Sidoni, ati awọn oriṣa Moabu, ati awọn oriṣa awọn ọmọ Ammoni, ati awọn oriṣa awọn Filistini; nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn kò si sìn i. 7 Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ awọn Filistini, ati si ọwọ́ awọn ọmọ Ammoni. 8 Li ọdún na nwọn ni awọn ọmọ Israeli lara, nwọn si pọ́n wọn loju: ọdún mejidilogun ni nwọn fi ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ti o wà ni ìha keji Jordani ni ilẹ awọn Amori, ti o wà ni Gileadi, lara. 9 Awọn ọmọ Ammoni si gòke odò Jordani lati bá Juda jà pẹlu, ati Benjamini, ati ile Efraimu; a si ni Israeli lara gidigidi. 10 Awọn ọmọ Israeli si kepè OLUWA wipe, Awa ti ṣẹ̀ si ọ, nitoriti awa ti kọ̀ Ọlọrun wa silẹ, a si nsín Baalimu. 11 OLUWA si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi kò ti gbà nyin kuro lọwọ awọn ara Egipti, ati lọwọ awọn ọmọ Amori, ati lọwọ awọn ọmọ Ammoni, ati lọwọ awọn Filistini? 12 Awọn ara Sidoni pẹlu, ati awọn Amaleki, ati awọn Maoni si ti npọ́n nyin loju; ẹnyin kepè mi, emi si gbà nyin lọwọ wọn. 13 Ṣugbọn ẹnyin kọ̀ mi silẹ, ẹ si nsìn ọlọrun miran: nitorina emi ki yio tun gbà nyin mọ́. 14 Ẹ lọ kigbepè awọn oriṣa ti ẹnyin ti yàn; jẹ ki nwọn ki o gbà nyin li akokò wah