Yoruba John


/1 Li atetekose li Oro wa, Oro si wa
pelu Olorun, Olorun si li Oro na.

2 On na li o wa li atetekose pelu
Olorun.

3 Nipase re li a ti da ohun gbogbo;
lehin re a ko si da ohun kan ninu ohun
ti a da.

4 Ninu re ni iye wa; iye na si ni
imole araiye.

5 Imole na si nmole ninu okunkun;
okunkun na ko si bori re.

6 & Okonrin kan wa ti a ran lati
odo Olorun wa, oruko eniti nje
Johannu.

7 On na li a si ran fun eri, ki o le se
eleri fun imole na, ki gbogbo enia ki o
Ie gbagbo nipase re.

8 On ki ise Imole na, sugbon a ran
a wa lati se eleri fun Imole na.

9 Imole otito mbe ti ntan mole fun
olukuluku enia ti o wa si aiye.

10 On si wa li aiye, nipase re li a si
ti da aiye, aiye ko si mo o.

11 O to awon tire wa, awon ara
tire ko si gba a.

12 Sugbon iye awon ti o gba a,
awon li o fi agbara fun lati di omo
Olorun, ani awon na ti o gba oruko re
gbo:

13 Awon eniti a bi, ki ise nipa ti
eje, tabi nipa ti ife ara, beni ki ise nipa
ife ti enia, bikose nipa ife ti Olorun.

14 Oro na si di ara, on si mba wa
gbe, (awa si nwo ogo re, ogo bi ti omo
bibi kansoso lati odo Baba wa,) o kun
fun ore-ofe ati otito.

15 & Johannu si jeri re o si kigbe,
wipe, Eyi ni eniti mo soro re pe, Eniti
mbo lehin mi, o poju mi lo: nitori o
wa siwaju mi.

16 Nitori ninu ekun re ni gbogbo
wa si ti gba, ati ore-ofe kun ore-ofe.

17 Nitoripe nipase Mose li a ti fi
ofin funni, sugbon ore-ofe ati otito
tipase Jesu Kristi wa.

18 Ko si eniti o ri Olorun ri; Omo
bibi kansoso, ti mbe li okan aiya Baba,
on na li o fi i han.

19 & Eyi si li eri Johannu, nigbati
awon Ju ran awon alufa ati awon omo
Lefi lati Jerusalemu wa lati bi i lere pe,
Tani iwo se?

20 O si jewo, ko si se; o si jewo pe,
Emi ki ise Kristi na.

21 Nwon si bi i pe, Tani iwo ha ise?
Elijah ni o bi? O si wipe Beko. Iwo
ni woli na bi? O si dahun wipe,
Beko.

22 Nitorina nwon wi fun u pe, Tani
iwo ise? ki awa ki o le fi esi fun awon
ti o ran wa. Kili o wi ni ti ara re?

23 O wipe, Emi li ohun eni ti nkigbe
ni iju, E se ki ona Oluwa to, gege bi
woli Isaiah ti wi.

24 Awon ti a ran si je ninu awon
Farisi.

25 Nwon si bi i lere, nwon si wi fun
u pe, Nje ese ti iwo fi mbaptisi, bi iwo
ki iba se Kristi na, tabi Elijah, tabi
woli na?

26 Johannu da won lohun, wipe,
Enii nfi omi baptisi: enikan duro larin
nyin, eniti enyin ko mo;

27 On na li eniti mbo lehin mi, ti o
popu mi lo, eniti emi ko ye lati tu okun
bata re.

28 Nkan wonyi li a se ni Betani loke
odo Jordani, nibiti Johannu gbe
mbaptisi.

29 & Ni ijo keji Johannu ri Jesu
mbo wa sodo re; o wipe. Wo o, Odo-
agutan Olorun, eniti o ko ese aiye lo!

30 Eyi li eniti mo ti wipe, Okonrin
kan mbo wa lehin mi, eniti o poju mi
lo: nitoriti o ti wa siwaju mi.

31 Emi ko si mo O: sugbon ki a le fi
i han fun Israeli, nitorina li emi se wa
ti mo nfi omi baptisi.

32 Johannu si jeri, o wipe, mo ri
Emi sokale lati orun wa bi adaba, o si
ba le e.

33 Emi ko si mo o: sugbon eniti o
ran mi wa, lati fi omi baptisi, on na li o
wi fun mi pe, Lori eniti iwo ba ri, ti
Emi sokale si, ti o si ba le e, on na li
eniti nfi Emi Mimo baptisi.

34 Emi si ti ri, emi si ti njeri pe, Eyi
11 Omo Olorun.

35 & Ni ijo keji ewe Johannu duro,
ati meji ninu awon omo-ehin re:

36 O si wo Jesu bi o ti nrin, o si
wipe. Wo Odo-agutan Olorun!

37 Awon omo-ehin meji na si gbo
nigbati o wi, nwon si to Jesu lehin.

38 Nigbana ni Jesu yipada, o ri
nwon nto on lehin, o si wi fun won pe,
Kili enyin nwa? Nwon wi fun u pe,
Rabbi, (itumo eyi ti ije Olukoni,) nibo
ni iwo ngbe?

39 O wi fun won pe, E wa wo o.
Nwon si wa, nwon si ri ibi ti o ngbe,
nwon si ba a joko ni ijo na: nitoriti o
je iwon wakati kewa ojo.

40 Okan ninu awon meji ti o gbo
Oro Johannu, ti o si to Jesu lehin, ni
Anderu, arakonrin Simoni Peteru.

41 On teteko ri Simoni arakonrin
on tikarare, o si wi fun u pe, Awa ti ri
Messia, itumo eyi ti ije Kristi.

42 O si mu u wa sodo lesa. Jess
si wo o, o wipe, Iwo ni Simoni omo
Jona: Kefa li a o si ma pe o, itumo eyi
ti ije Peteru.

43 & Ni ojo keji Jesu me jade lo si
Galili, o si ri Filippi, o si wi fun u pe,
Ma to mi lehin.

44 Ara Betsaida ni Filippi ise, ilu
Anderu ati Peteru.

45 Filippi ri Natanaeli, o si wi fun u
pe, Awa ti ri eniti Mose ninu ofin ati
awon woli ti kowe re, Jesu ti Nasareti,
Omo Josefu.

46 Natanaeli si wi fun u pe, Ohun
rere kan ha le ti Nasareti jade? Filippi
wi fun u pe, Wa wo o.

47 Jesu ri Natanaeli mbo wa sodo
re, o si wi nipa re pe. Wo o, omo
Israeli nitoto, ninu eniti etan ko si!

48 Natanaeli wi fun u pe, Nibo ni
iwo ti mo mi? Jesu dahun, o si wi fun
u pe, Ki Filippi to pe o, nigbati iwo
wa labe igi opoto, mo ti ri o.

49 Natanaeli dahun, o si wi fun u
pe, Rabbi, iwo li Omo Olorun; iwo li
Oba Israeli.

50 Jesu dahun, o si wi fun u pe,
Nitori mo wi fun o pe, mo ri o labe igi
opoto ni iwo se gbagbo? iwo o ri ohun
ti o poju wonyi lo.

51 O si wi fun u pe, Loto, loto nt
mo wi fun nyin, Enyin o ri orun si
sile, awon angeli Olorun yio si ma
goke, nwon o si ma sokale sori Omo-
enia.

/2 Ni ijo keta a si nse igbeyawo kan ni
Kana ti Galili; iya Jesu si mbe
nibe:

2 A si pe Jesu ati awon Omo-ehin
re pelu, si ibi igbeyawo.

3 Nigbati waini si tan, iya Jesu wi
fun u pe, Nwon ko ni waini.

4 Jesu wi fun u pe, Kini se temi tire,
obirin yi? wakati mi ko iti de.

5 Iya re wi fun awon iranse pe,
Ohunkohun ti o ba wi fun nyin, e se e.

6 Ikoko okuta omi mefa li a si gbe
kale nibe, gege bi ise iwenu awon Ju,
okokan nwon gba to iwon ladugbo
meji tabi meta.

7 Jesu wi fun won pe, E pon omi
kun ikoko wonni. Nwon si kun won
titi de eti.

8 O si wi fun won pe, E bu u jade
nisisiyi, ki e si gbe e to olori ase lo.
Nwon si gbe e lo.

9 Bi olori ase si ti to omi ti a so di
waini wo, ti ko si mo ibi ti o ti wa
(sugbon awon iranse ti o bu omi na
wa mo), olori ase pe oko iyawo,

10 O si wi fun u pe, Olukuluku enia
a ma ko gbe waini rere kale; nigbati
awon enia ba si mu yo tan, nigbana ni
imu eyi ti ko dara tobe wa: sugbon
iwo ti pa waini daradara yi mo titi o
fi di isisiyi.

11 Akose ise ami yi ni Jesu se ni
Kana ti Galili, o si fi ogo re han; awon
omo-enin re si gba a gbo.

12 & Lehin eyi, o sokale lo si Kaper-
namu, on ati iya re ati awon arakonrin
re, ati awon omo-ehin re: nwon ko si
gbe ibe li ojo pupo.

13 & Ajo irekoja awon Ju si sunmo
etile, Jesu si goke lo si Jerusalemu,

14 O si ri awon ti nta malu, ati
agutan, ati adaba ni tempili, ati awon
onipasiparo owo joko:

15 O si fi okun tere se pasan, o si le
gbogbo won jade kuro ninu tempili, ati
agutan ati malu; o si da owo awon
onipasiparo owo nu, o si bi tabili won
subu.

16 O si wi fun awon ti nta adaba
pe, E gbe nkan wonyi kuro nihin; e
mase so ile Baba mi di ile oja tita.

17 Awon omo-ehin re si ranti pe, a
ti ko o pe, Itara ile re je mi run.

18 & Nigbana li awon Ju dahun,
nwon si wi fun u pe Ami wo ni iwo fi
han wa, ti iwo fi nse nkan wonyi?

19 Jesu dahun o si wi fun won pe,
E wo tempili yi pale, ni ijo meta Emi
o si gbe e ro.

20 Nigbana li awon Ju wipe, Odun
merindiladota li a fi ko tempili yi, iwo
o ha si gbe ro ni ijo meta?

21 Sugbon on nso ti tempili ara re.

22 Nitorina nigbati o jinde kuro
ninu oku, awon omo-ehin re ranti pe,
o ti so eyi fun won; nwon si gba iwe-
muno gbo, ati oro ti Jesu ti so.

23 & Nigbati o si wa ni Jerusalemu,
oi ajo irekoja, lakoko ajo na, opo enia
gba oruko re gbo nigbati nwon ri ise
ami re ti o se.

24 Sugbon Jesu ko gbe ara le won,
nitoriti o mo gbogbo enia.

25 On ko si wa ki enikeni ki o jeri
enia fun on: nitoriti on mo ohun ti
mbe ninu enia.


/3 Okonrin kan si wa ninu awon
Farisi, ti a npe ni Nikodemu, ijoye
kan ninu awon Ju:

2 On na li o to Jesu wa li oru, o si
wi fun u pe. Rabbi, awa mo pe olu-
koni lati odo Olorun wa ni iwo ise:
nitoripe ko si eniti o le se ise ami
wonyi ti iwo nse, bikosepe Olorun wa
pelu re.

3 Jesu dahun o si wi fun u pe, Loto,
loto ni mo wi fun o, Bikosepe a tun
enia bi, on ko le ri ijoba Olorun.

4 Nikodemu wi fun u pe, A o ti se
le tun enia bi, nigbati o di agbalagba
tan? o ha le wo inu iya re lo nigba keji,
ki a si bi i?

5 Jesu dahun wipe, Loto, loto ni
mo wi fun o, Bikosepe a fi omi ati Emi
bi enia, on ko le wo ijoba Olorun.

6 Eyiti a bi nipa ti ara, ara ni; eyiti
a si bi nipa ti Emi, emi ni.

7 Ki enu ki o mase ya o, nitori mo
wi fun o pe, A ko le se alaitun nyin bi.

8 Afefe nfe si ibi ti o gbe wu u, iwo
si ngbo iro re, sugbon iwo ko mo ibi
ti wa, ati ibi ti o gbe nio: gege beni
olukuluku eniti a bi nipa ti Emi.

9 Nikodemu dahun, o si wi fun u pe,
Nkan wonyi yio ti se le ri be?

10 Jesu dahun, o si wi fun u pe, Se
olukoni ni Israeli ni iwo ise, o ko si mo
nkan wonyi?

11 Loto, loto ni mo wi fun o, Awa
nso eyiti awa mo, a si njeri eyiti awa ti
ri; enyin ko si gba eri wa.

12 Bi mo ba so ohun ti aiye yi fun
nyin, ti enyin ko si gbagbo, enyin o ti
se gbagbo bi mo ba so ohun ti orun
fun nyin?

13 Ko si si eniti o goke re orun,
bikose eniti o ti orun sokale wA, ani
Omo-enia ti mbe li orun.

14 & Bi Mose si ti gbe ejo soke li
aginju, gege belt a ko le se alaigbe
Omo-enia soke pelu:

15 Ki enikeni ti o ba gba a gbo, ki
o ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye
ainipekun.

16 & Niton Olorun fe araiye tobe
ge, ti o fi Omo bibi re kansoso funni,
ki enikeni ti o ba gba a gbo ma ba
segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun.

17 Nitori Olorun ko ran Omo re
si aiye lati da araiye lejo; sugbon ki a
Ie ti ipase re gba araiye la.

18 & Eniti o ba gba a gbo, a ko ni
da a lejo; sugbon a ti da eniti ko gba a
gbo lejo na, nitoriti ko gba oruko
Omo bibi kansoso ti Olorun gbo.

19 Eyi ni idajo na pe, imole wa si
aiye, awon enia si fe okunkun ju imole
lo, nitoriti ise won buru.

20 Nitori olukuluku eniti o ba buwa
buburu ni ikorira imole, ki isi wa si
imole, ki a mase ba ise re wi.

21 Sugbon eniti o ba nse otito ni
iwa si imole, ki ise re ki o le fi ara han
pe, a se won nipa ti Olorun.

22 & Lenin nkan wonyi Jesu pelu
awon omo-ehin re wa si ile Judea; o si
duro pelu won nibe o si baptisi.

23 Johannu pelu si mbaptisi ni
Ainoni, li agbegbe Salimu, nitoriti omi
pipo wa nibe: nwon si nwa, a si baptisi
won.

24 Nitoriti a ko ti iso Johannu sinu
tubu.

25 & Nigbana ni iyan kan wa larin
awon omo-ehin Johannu, pelu Ju kan
niti iwenu.

26 Nwon si to Johannu wa, nwon si
wi fun u pe, Rabbi, eniti o yi wa pelu
re loke odo Jordani, ti iwo ti jeri re, wo
o, on mbaptisi, gbogbo enia si nto o
wa.

27 Johannu dahun o si wipe, Enia
ko le ri nkankan gba, bikosepe a ba ti
fifun u lati orun wa.

28 Enyin tikaranyin jeri mi, pe mo
wipe, Emi ki ise Kristi na, sugbon pe
a ran mi siwaju re.

29 Eniti o ba ni iyawo ni oko iyawo;
Sugbon ore oko iyawo ti o duro ti o si
ngbohun re, o nyo gidigidi nitori ohun
oko iyawo; nitorina ayo mi yi di
kikun.

30 On ko le saima posi i, sugbon
emi ko le saima rehin.

31 Eniti o ti oke wa ju gbogbo enia
lo : eniti o ti aiye wa ti aiye ni, a si ma
so ohun ti aiye: eniti o ti orun wa ju
gbogbo enia lo.

32 Ohun ti o ti ri ti o si ti gbo eyina
si li on njeri re; ko si si eniti o gba
eri re.

33 Eniti o gba eri re fi edidi di i pe,
otito li Olorun.

34 Nitori eniti Olorun ti ran nso
Oro Olorun: nitoriti Olorun ko fi Emi
fun u nipa osuwon.

35 Baba fe Omo, o si ti fi ohun gbo-
gbo le e lowo.

36 Eniti o ba gba Omo gbo, o ni iye
ainipekun: eniti ko ba si gba Oro?
gbo, ki yio ri iye; sugbon ibinu
Olorun mbe lori re.

/4 Nitorina nigbati Oluwa ti mo bi
awon Farisi ti gbo pe, Jesu nse o si
mbaptisi awon omo-ehin pupo ju
Johannu lo,

2 (Sugbon Jesu tikarare ko baptisi
bikose awon omo-ehin re,)

3 O fi Judea sile, o si tun lo si Galili.

4 On ko si le saima koja larin
Samaria.

5 Nigbana li o de ilu Samaria kan,
ti a npe ni Sikari, ti o sunmo eti ile biri
ni, ti Jakobu ti fifun Josefu, omo re.

6 Kanga Jakobu si iwa nbe. Nito-
rina bi o ti re Jesu tan nitori irin re,
beli o joko leti kanga: o si je iwon
wakati kefa ojo.

7 Obirin kan, ara Samaria, si wa
lati fa omi: Jesu wi fun u pe, Fun mi
mu.

8 (Nitori awon omo-ehin re ti lo s1
ilu lo ira onje.)

9 Nigbana li obirin ara Samaria na
wi fun u pe, Eti ri ti iwo ti ise Ju, fi
mbere ohun mimu lowo mi, emi eniti
ise obirin ara Samaria? nitoriti awon
Ju ki iba awon ara Samaria lo-po.

10 Jesu dahun, o si wi fun u pe;
Ibasepe iwo mo ebun Olorun, ati en111
o wi fun o pe, Fun mi mu, iwo iba si ti
bere iowo re, on iba ti fi omi iye fun o.

11 Obirin na wi fun u pe, Ogbeni,
iwo ko ni nkan ti iwo o fi fa omi, beni
kanga na jin: nibo ni iwo gbe ti ri omi
iye na?

12 Iwo poju Jakobu baba wa lo bi,
eniti o fun wa ni kanga na, ti on tika-
rare mu ninu re, ati awon omo re, ati
awon eran re?

13 Jesu dahun, o si wi fun u pe,
Enikeni ti o ba mu ninu omi yi,
orungbe yio si tun gbe e:

14 Sugbon enikeni ti o ba mu ninu
omi ti emi o fifun u, orungbe ki yio
gbe e mo lai; sugbon omi ti emi o fifun
u yio di kanga omi ninu re, ti yio ma
sun si iye ainipekun.

15 Obirin na si wi fun u pe, Ogbeni,
fun mi li omi yi, ki orungbe ki o mase
gbe mi, ki emi ki o ma si wa fa omi
nihin.

16 Jesu wi fun u pe, Lo ipe oko re,
ki o si wa si ihinyi.

17 Obirin na dahun, o si wi fun u pe,
Emi ko li oko. Jesu wi fun u pe, Iwo
wi rere pe, emi ko li oko:

18 Nitoriti iwo ti li oko marun ri;
eniti iwo si ni nisisiyi ki ise oko re;
iwo so otito li eyini.

19 Obirin na wi fun u pe, Ogbeni,
mo woye pe, woli ni iwo ise.

20 Awon baba wa sin lori Oke yi;
enyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o
ye ti a ba ma sin.

21 Jesu wi fun u pe, Gba mi gbo,
obirin yi, wakati na mbo, nigbati ki
yio se lori oke yi, tabi Jerusalemu, li
enyin o ma sin Baba.

22 Enyin nsin ohun ti enyin ko mo:
awa nsin ohun ti awa mo: nitori igbala
ti odo awon Ju wa.

23 Sugbon wakati mbo, o si de tan
nisisiyi, nigbati awon olusin toto yio
ma sin Baba li emi ati li otito: nitori
iru won ni Baba nwa ki o ma sin on.

24 Emi li Olorun: awon eniti nsin
i ko le se alaisin i li emi ati li otito.

25 Obirin na wi fun u pe, mo mo pe
Messia mbo wa, ti a npe ni Kristi:
nigbati on ba de, yio so ohun gbogbo
fun wa.

26 Jesu wi fun u pe, Emi eniti mba
o soro yi li on.

27 & Lori eyi li awon omo-ehin re
de, enu si ya won, pe o mba obirin
soro: sugbon ko si enikan ti o wipe,
Kini iwo nwa? tabi, Ese ti iwo fi mba
a soro?

28 Nigbana li obirin na fi ladugbo
re sile, o si mu ona re pon lo si ilu, o si
wi fun awon enia pe,

29 E wa wo okonrin kan, eniti o so
ohun gbogbo ti mo ti se ri fun mi: eyi
ha le je Kristi na?

30 Nigbana ni nwon ti ilu jade,
nwon si to o wa.

31 & Larin eyi awon omo-ehin re
nro o, wipe, Rabbi, jeun.

32 Sngbon o wi fun won pe, emi li
onje lati je, ti enyin ko mo.

33 Nitorina li awon omo-ehin re
mbi ara won lere wipe, Enikan mu
onje fun u wa lati je bi?

34 Jesu wi fun won pe, Onje mi ni
lati se ife eniti o ran mi, ati lati pari ise
re.

35 Enyin ko ha nwipe, O ku osu
merin, ikore yio si de? wo o, mo wi
fun nyin, E gbs oju nyin soke, ki e si
wo oko; nitoriti nwon ti funfun fun
ikore na.

36 Eniti nkore ngba owo oya, o si
nko eso jo si iye ainipekun: ki eniti o
nfonrugbin ati eniti nkore le jo ma yo
po.

37 Nitori ninu eyi ni oro na fi je
otito: Enikan li o fonrugbin, elomiran
li o si nkore jo.

38 Mo ran nyin lo ikore ohun ti e
ko sise le lori: awon elomiran ti sise,
enyin si wo inu ise won lo.

39 opo awon ara Samaria lati ilu
na wa si gba a gbo, nitori oro obirin
na, o jeri pe, O so gbogbo ohun ti mo
ti se fun mi.

40 Nitorina, nigbati awon ara Sa-
maria wa sodo re, nwon be e Pe, ki o
ba won joko: o si gbe ibe ni ijo meji.

41 Awon opolopo si i si gbagbo
nitori oro re;

42 Nwon si wi fun obirin na pe, Ki
ise nitori oro re mo li awa se gbagbo:
nitoriti awa tikarawa ti gbo oro re,
awa si mo pe, nitoto eyi ni Kristi na,
Olugbala araiye.

43 & Lehin ijo meji o si ti ibe kuro,
o lo si Galili.

44 Nitori Jesu tikarare ti jeri wipe,
Woli ki ini ola ni ile on tikarare.

45 Nitorina nigbati o de Galili,
awon ara Galili gba a, nitoriti nwon ti
ri ohun gbogbo ti o se ni Jerusalemu
nigba ajo; nitori awon tikarawon lo si
ajo pelu.

46 Beni Jesu tun wa si Kana ti
Galili, nibiti o gbe so omi di waini.
Okonrin olola kan si wa, eniti ara omo
re ko da ni Kapernaumu.

47 Nigbati o gbo pe, Jesu ti Judea
wa si Galili, o to o wa, o si mbe e, ki
o le sokale wa ki o mu omo on larada:
nitoriti o wa li oju iku.

48 Nigbana ni Jesu wi fun u pe,
Bikosepe enyin ba ri ami ati ise iyanu,
enyin ki yio gbagbo lai.

49 Okonrin olola na wi fun u pe,
Oluwa, sokale wa, ki omo mi ki o to
ku.

50 Jesu wi fun u pe, Ma ba ona re
lo; omo re ye. Okonrin na si gba
oro ti Jesu so fun u gbo, o si lo.

51 Bi o si ti nsokale lo, awon omo-
odo re pade re, nwon si wi fun u pe,
omo re ye.

52 Nigbana li o bere wakati ti o
bere si isan lowo won. Nwon si wi
fun u pe, Li ana, ni wakati keje, ni iba
na fi i sile.

53 Beni baba na mo pe, ni wakati
kanna ni, ninu eyi ti Jesu wi fun u pe,
Omo re ye: on tikarare si gbagbo, ati
gbogbo ile re.

54 Eyi ni ise ami keji, ti Jesu se
nigbati o ti Judea jade wa si Galili.

/5 Tehin nkan wonyi ajo awon Ju
kan ko; Jesu si goke lo si Jerusa-
lemu.

2 Adagun omi kan si wa ni Jerusa-
lemu, leti bode agutan, ti a npe ni
Betesda li ede Heberu, ti o ni iloro
marun.

3 Ninu wonyi li opo awon abirun
enia gbe dubule si, awon afoju, aro
ati awon gbigbe, nwon si nduro de riru
omi.

4 Nitori angeli a ma digba sokale lo
sinu adagun na, a si ma ru omi: lehin
igbati a ba ti ru omi na tan enikeni ti
o ba ko wo inu re, a di alaradida ninu
arunkarun ti o ni.

5 Okonrin kan si wa nibe, eniti o
wa ni ailera re li odun mejidilogoji.

6 Bi Jesu ti ri i ni idubule, ti o si mo
pe, o pe ti o ti wa be, o wi fun u pe,
Iwo fe ki a mu o larada bi?

7 Abirun na da a lohun wipe,
Ogbeni, emi ko li eni, ti iba gbe mi
sinu adagun, nigbati a ba nru omi na:
bi emi ba ti mbo wa, elomiran a sokale
sinu re siwaju mi.

8 Jesu wi fun u pe, Dide, gbe akete
re, ki o si ma rin.

9 Logan a si mu okonrin na larada,
o si gbe akete re, o si nrin. ojo na si
je ojo isimi.

10 & Nitorina awon Ju wi fun oko-
nrin na ti a mu larada pe, ojo isimi li
oni: ko to fun o lati gbe akete re.

11 O si da won lohun wipe, Eniti o
mu mi larada, on li o wi fun mi pe,
Gbe akete re, ki o si ma rin.

12 Nigbana ni nwon bi i lore wipe,
Okonrin wo li eniti o wi fun o pe, Gbe
akete re, ki o si ma rin?

13 Eniti a mu larada na ko si mp
eniti ise: nitori Jesu ti kuro nibe,
nitori awon enia pipo wa nibe.

14 Lehinna Jesu ri i ni tempili o si
wi fun u pe. Wo o, a mu o larada:
mase dese mo, ki ohun ti o buru ju yi
lo ki o ma ba ba o.

15 Okonrin na lo, o si so fun awon
Ju pe, Jesu li eniti o mu on larada.

16 Nitori eyi li awon Ju si nse
inunibini si Jesu, nwon si nwa ona ati
pa a, nitoriti a nse nkan wonyi li ojo
isimi.

17 & Sugbon Jesu da won lohun
wipe, Baba mi nsise titi di isisiyi, emi
si nsise.

18 Nitori eyi li awon Ju tube nwa
Ona ati pa a, ki ise nitoripe o ba W
isimi je nikan ni, sugbon o wi pelu pe,
Baba on li Olorun ise, o nmu ara re
ba Olorun dogba.

19 Nigbana ni Jesu dahun, o si wi
fun won pe, Loto, loto ni mo wi fun
nyin, Omo ko le se ohunkohun fun
ara re, bikose ohun ti o ba ri pe Baba
nse: nitori ohunkohun ti o ba nse,
wonyi li Omo si nse be gege.

20 Nitori Baba reran Omo, o si fi
ohun gbogbo ti on tikarare nse ban a;
on o si fi ise ti o tobi ju wonyi lo nan
a, ki enu ki o le ya nyin.

21 Nitoripe gege bi Baba ti nji oku
dide, ti o si nso won di aye; beli Omo
si nso awon ti o fe di aye.

22 Nitoripe Baba ki ise idajo eni-
keni, sugbon o ti fi gbogbo idajo le
Omo lowo:

23 Ki gbogbo enia ki o le ma fi Ola
fun Omo gege bi nwon ti nfi ola fun
Baba. Eniti ko ba fi ola fun Omo,
ko fi ola fun Baba ti o ran a.

24 Loto, loto ni mo wi fun nyin,
Enikeni ti o ba gbo oro mi, ti o ba si
gba eniti o ran mi gbo, o ni iye ti ko
nipekun, on ki yio si wa si idajo;
sugbon o ti re iku koja bo si iye.

25 Loto, loto ni mo wi fun nyin,
Wakati na mbo, o si de tan nisisiyi,
nigbati awon oku yio gbo ohun Omo
Olorun: awon ti o ba gbo yio si ye.

26 Nitoripe gege bi Baba ti ni iye
ninu ara re; gege beli o si fifun Omo
lati ni iye ninu ara re;

27 O si fun u li ase lati ma se idajo
pelu, nitoriti on ise Omo-enia.

28 Ki eyi ki o mase ya nyin li enu;
nitoripe wakati mbo, ninu eyiti gbogbo
awon ti o wa ni isa oku yio gbo ohun
re.

29 Nwon o si jade wa; awon ti o se
rere, si ajinde iye; awon ti o si se
buburu, si ajinde idajo.

30 Emi ko le se ohun kan fun ara
mi: bi mo ti ngbo, mo ndajo: ododo
si ni idajo mi; nitori emi ko wa ife ti
emi tikarami, bikose ife ti eniti o ran
mi.

31 Bi emi ba njeri ara mi, eri mi ki
ise otito.

32 & Elomiran li eniti njeri mi; emi
si mo pe, otito li eri mi ti o je.

33 Enyin ti ranse lo sodo Johannu,
on si ti jeri si otito.

34 Sugbon emi ko gba eri lodo enia:
sugbon nkan wonyi li emi nso, ki
enyin ki o le la.

35 On ni fitila ti o njo, ti o si nran-
mole: enyin si fe fun sa kan lati ma yo
ninu imole re.

36 & Sugbon emi ni eri ti o poju ti
Johannu lo: nitori is? ti Baba ti fifun
mi lati se pari, ise na papa ti emi nse
ni njeri mi pe, Baba li o ran mi.

37 Ati Baba ti o ran mi ti jeri mi.
Enyin ko gbo ohun re nigba kan ri,
beli e ko ri awo re.

38 E ko si ni oro re lati ma gbe inu
nyin: nitori eniti o ran, on li enyin ko
gbagbo.

39 & Enyin nwa inu iwe-mimo
nitori enyin ro pe ninu won U enyin ni
iye ti ko nipekun; wonyi si li awon ti
njeri mi.

40 Enyin ko si fe lati wa sodo mi,
ki enyin ki o le ni iye.

41 Emi ko gba ogo lodo enia.

42 Sugbon emi mo nyin pe, enyin
tikaranyin ko ni ife Olorun ninu nyin.

43 Emi wa li oruko Baba mi, enyin
ko si gba mi: bi elomiran ba wa li
oruko ara re, on li enyin o gba.

44 Enyin o ti se le gbagbo, enyin ti
ngba ogo lodo ara nyin, ti ko wa ogo
ti o ti odo Olorun nikan wa?

45 E mase ro pe, emi o fi nyin sun
lodo Baba: eniti nfi nyin sun wa, ani
Mose, eniti enyin gbekele.

46 Nitoripe enyin iba gba Mose
gbo, enyin iba gba mi gbo: nitori o ko-
iwe nipa ti emi.

47 Sugbon bi enyin ko ba gba iwe
re gbo, enyin o ti se gba oro mi gbo?

/6 Lehin nkan wonyi, Jesu koja si
apakeji okun Galili, ti ise okun
Tiberia.

2 opo ijo enia si to o lehin, nitoriti
nwon ri ise ami re, ti o nse lara awon
alaisan.

3 Jesu si gun ori oke lo, nibe li o si
gbe joko pelu awon omo-ehin re.

4 Ajo irekoja, odun awon Ju, si
sunmo etile.

5 & Nje bi Jesu ti gbe oju re soke, ti
o si ri opo enia wa sodo re, o wi fun
Filippi pe, Nibo li a o ti ra akara, ki
awon wonyi le je?

6 O si so eyi lati dan a wo; nitoriti
on tikarare mo ohun ti on o se.

7 Filippi da a lohun pe, Akara igba
owo ide ko to fun won, ti olukuluku
won iba fi mu die-die.

8 Okan ninu awon omo-ehm re,
Anderu, arakonrin Simoni Peteru wi
fun u pe,

9 Omodekonrin kan mbe nihinyi, ti
o ni isu akara barle marun, ati eJa-
kekeke meji: sugbon kini wonyi j?
larin opo enia wonyi bi eyi?

10 Jesu si wipe, E mu ki awon enia
na joko. Koriko pipo si wa nibe.
Beli awon okonrin na joko, iwon
egbedogbon enia ni iye.

11 Jesu si mu isu akara wonni;
nigbati o si ti dupe, o pin won fun
awon omo-ehin re, awon omo-ehin re;
si pin won fun awon ti o joko; be;
gege si li eja ni iwon bi nwon ti nfe.

12 Nigbati nwon si yo, o wi fun
awon omo-ehin re pe, E ko ajeku ti o
ku jo, ki ohunkohun mase segun.

13 Beni nwon ko won jo nwon si fi
ajeku isu akara barle marun na kun
agbon mejila eyi ti o siku, fun awon
ti o jeun.

14 Nitorina nigbati awon okonrin
na ri ise ami ti Jesu se, nwon wipe,
Loto eyi ni woli na ti mbo wa aiye.

15 & Nigbati Jesu si woye pe, nwon
nfe wa ifi agbara mu on lo ifi joba, o
tun pada lo sori oke on nikan.

16 Nigbati ale si le, awon omo-ehin
re lo sinu okun.

17 Nwon si bo sinu oko, nwon si
rekoja okun lo si Kapemaumu.
Okunkun si ti kun, Jesu ko si ti ide
Odo won.

18 Okun si nru nitori efufu lile ti
nfe.

19 Nigbati nwon wa oko to bi iwon
furlongi medogbon tabi ogbon, nwon
ri Jesu nrin lori okun, o si sunmo oko;
eru si ba won.

20 Sugbon o wi fun won pe, Emi ni;
e ma beru.

21 Nitorina nwon fi ayo gba a sinu
oko: lojukanna oko na si de ile ibiti
nwon gbe nio.

22 & Ni ijo keji, nigbati awon enia
ti o duro li apakeji okun ri pe, ko si
oko miran nibe, bikose okanna ti
awon omo-ehin re wo, ati pe Jesu ko
ba awon omo-ehin re wo inu oko na,
sugbon awon omo-ehin re nikan li o
lo;

23 (Sugbon awon oko miran ti
Tiberia wa, leti ibi ti nwon gbe je
akara, lehin igbati Oluwa ti dupe:)

24 Nitorina nigbati awon enia ri pe,
Jesu ko si nibe, tabi awon omo-ehin
re, awon pelu wo oko lo si Kapernau-
mu, nwon nwa Jesu.

25 Nigbati nwon si ri i li apakeji
okun nwon wi fun u pe. Rabbi,
nigbawo ni iwo wa sihinyi?

26 Jesu da won lohun o si wipe,
Loto, loto ni mo wi fun nyin, Enyin
nwa mi, ki ise nitoriti enyin ri ise ami,
Sugbon nitori enyin je isu akara wonni,
enyin si yo.

27 E mase sise fun onje ti isegbe,
Sugbon fun onje ti iwa titi di iye aini-
pekun, eyiti Omo-enia yio fifun nyin:
nitoripe on ni, ani Olorun Baba ti fi
edididi.

28 Nigbana ni nwon wi fun u pe,
Kili awa o ha se, ki a le se ise Olorun?

29 Jesu dahun o si wi fun won pe,
Eyi ni ise Olorun pe, ki enyin ki o gba
eniti o ran gbo.

30 Nigbana ni nwon wi fun u pe,
Ise ami kini iwo nse, ki awa le ri, ki a
si gba o gbo? ise kini iwo se?

31 Awon baba wa je manna li
aginju; gege bi a ti ko o pe, O fi onje
fun won je lati Orun wa.

32 Nigbana ni Jesu wi fun won pe,
Loto, loto ni mo wi fun nyin, ki ise
Mose li o fi onje ni fun nyin lati orun
wa; sugbon Baba mi li o fi onje otito
ni fun nyin lati orun wa.

33 Nitoripe onje Olorun li eniti o
ti orun sokale wa, ti o si fi iye fun
araiye.

34 Nigbana ni nwon wi fun u pe,
Oluwa, ma fun wa li onje yi titi lai.

35 Jesu wi fun won pe, Emi li onje
iye: enikeni ti o ba to mi wa, ebi ki
yio pa a; eniti o ba si gba mi gboi
orungbe ki yio gbe e mo lai.

36 Sugbon mo wi fun nyin pej
Enyin ti ri mi, e ko si gbagbo.

37 Ohun gbogbo ti Baba fifun mi,
yio to mi wa; eniti o ba si to mi wa,
emi ki yio ta a nu, bi o ti wu ki o ri.

38 Nitori emi sokale lati orun wa,
ki ise lati ma se ife ti emi tikarami,
bikose ife ti eniti o ran mi.

39 Eyi si ni ife Baba ti o ran mi, pe
ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o
mase so okan nu ninu won, sugbon
ki emi ki o le ji i dide nikehin ojo.

40 Eyi si ni ife eniti o ran mi, pe
enikeni ti o ba wo Omo, ti o ba si gba
a gbo, ki o le ni iye ainipekun: Emi o
si ji i dide nikehin ojo.

41 Nigbana ni awon Ju nkun si ij
nitoriti o wipe, Emi ni onje ti o ti orun
sokale wa.

42 Nwon si wipe, Jesu ha ko eyi,
Omo Josefu, baba ati iya eniti awa mo?
etise wipe, Emi ti orun sokale wa?

43 Nitorina Jesu dahun, o si wi fun
won pe, E mase kun larin ara nyin.

44 Ko si enikeni ti o le wa sodo mi,
bikosepe Baba ti o ran mi fa a: Emi o
si ji i dide nikehin ojo.

45 A sa ti ko o ninu awon woli pe,
A o si ko gbogbo won lati odo Olorun
wa. Nitorina enikeni ti o ba ti gbo,
ti a si ti odo Baba ko, on li o nto mi wa.

46 Kosepe enikan ti ri Baba bikose
eniti o ti odo Olorun wa, on li o ti ri
Baba.

47 Loto, loto ni mo wi fun nyin,
Eniti o ba gba mi gbo, o ni iye aini-
pekun.

48 Emi li onje iye.

49 Awon baba nyin je manna li
aginju, nwon si ku.

50 Eyi ni onje ti o ti orun sokale wa,
ki enia le ma je ninu re ki o ma si ku.

51 Emi ni onje iye ni ti o ti orun
sokale wa: bi enikeni ba je ninu onje
yi, yio ye titi lailai: onje na ti emi o si
fifunni li ara mi, fun iye araiye.

52 Nitorina li awon Ju se mba ara
won jiyan, wipe, Okonrin yi yio ti se
le fi ara re fun wa lati je?

53 Nigbana ni Jesu wi fun won pe,
Loto, loto ni mo wi fun nyin, Biko-
sepe enyin ba je ara Omo-enia, ki enyin
si mu eje re, enyin ko ni iye ninu nyin.

54 Enikeni ti o ba je ara mi, ti o ba
si mu eje mi, o ni iye ti ko nipekun;
Emi o si ji i dide nikehin ojo.

55 Nitori ara mi li ohun jije nitoto,
ati eie mi li ohun mimu nitoto.

56 Eniti o ba je ara mi, ti o ba si
mu eje mi, o ngbe inu mi, emi si ngbe
inu re.

57 Gege bi Baba alaye ti ran mi, ti
emi si ye nipa Baba: gege beli eniti o
je mi, on pelu yio ye nipa mi.

58 Eyi si li onje na ti o sokale lati
orun wa: ki ise bi awon baba nyin ti
je manna, ti nwon si ku: eniti o ba je
onje yi yio ye lailai.

59 Nkan wonyi li o so ninu sina-
gogu, bi o ti nkoni ni Kapernaumu.

60 Nitorina nigbati opo awon omo-
ehin re gbo eyi, nwon wipe, oro, ti o le
li eyi; tani le gbo o?

61 Nigbati Jesu si mo ninu ara re
pe, awon omo-ehin re nkun si oro na,
o wi fun won pe, Eyi je ikose fun nyin
bi?

62 Nje, bi enyin ba si ri ti Omo-enia
ngoke lo sibi ti o gbe ti wa ri nko?

63 Emi ni isoni di aye; ara ko ni
ere kan; oro wonni ti mo so fun nyin,
emi ni, iye si ni.

64 Sugbon awon kan wa ninu nyin
ti ko gbagbo. Nitori Jesu mo lati
ibere wa eniti nwon ise ti ko gbagbo,
ati eniti yio fi on han.

65 O si wipe, Nitorina ni mo se wi
fun nyin pe, ko si eniti o le to mi wa,
bikosepe a fifun u lati odo Baba mi
wa.

66 & Nitori eyi opo awon omo-ehin
re pada sehin, nwon ko si ba a rin mo.

67 Nitorina Jesu wi fun awon
mejila pe, Enyin pelu nfe lo bi?

68 Nigbana ni Simoni Peteru da a
lohun wipe, Oluwa, Odo tali awa o lo?
iwo li o ni Oro iye ainipekun.

69 Awa si ti gbagbo, a si mo pe,
iwo ni Kristi na, Omo Olorun alaye.

70 Jesu da won lohun pe, Enyin
mejila ko ni,mo yan, okan ninu nyin
ko ha si ya Esu?

71 O nso ti Judasi Iskariotu omo
Simoni: nitoripe on li eniti yio fi i han,
okan ninu awon mejila.

/7 Lehin nkan wonyi Jesu nrin ni
Galili: nitoriti ko fe rin ni Judea,
nitori awon Ju nwa ona ati pa a.

2 Ajo awon Ju ti ise ajo ipago,
sunmo etile tan.

3 Nitorina awon arakonrin re wi
fun u pe, Lo kuro nihinyi, ki o si lo si
Judea, ki awon omo-ehin re pelu ki o.
le ri ise re ti iwo nse.

4 Nitoripe ko si enikeni ti ise ohun-
kohun nikoko, ti on tikarare si nfe ki
a mo on ni gbangba. Bi iwo ba nse
nkan wonyi, fi ara re han fun araiye.

5 Nitoripe awon arakonria re ko
tile gba a gbo.

6 Nigbana ni Jesu wi fun won pe,
Akoko temi ko ti ide: sugbon akoko
ti nyin ni imura tan nigbagbogbo.

7 Aiye ko le korira nyin; sugbon
emi li o korira, nitoriti mo jeri gbe e pe,
ise re buru.

8 Enyin e goke lo si ajo yi: emi ki
yio ti igoke lo si ajo yi; nitoriti akoko
temi ko ti ide.

9 Nigbati o ti so nkan wonyi fun
won tan, o duro ni Galili sibe.

10 & Sugbon nigbati awon arakon-
rin re goke lo tan, nigbana li on si
goke lo si ajo na pelu, ki ise ni gba-
ngba, sugbon bi enipe nikoko.

11 Nigbana li awon Ju si nwa a kiri
nigba ajo, wipe, Nibo li o wa?

12 Kikun pipo si wa larin awon ijo
enia nitori re: nitori awon kan wipe,
Enia rere ni ise: awon miran wipe,
Beko; sugbon o ntan enia je ni.

13 Sugbon ko si enikan ti o soro re
ni gbangba nitori iberu awon Ju.

14 & Nigbati ajo de arin Jesu goke
lo si tempili o si nkoni.

15 Enu si ya awon Ju, nwon wipe,
Okonrin yi ti se mo iwe, nigbati ko
ko eko?

16 Nitorina Jesu da won lohun, o
si wipe, Eko mi ki ise temi, bikose ti
eniti o ran mi.

17 Bi enikeni ba fe lati se ife re, yio
mo niti eko na, bi iba se ti Olorun,
tabi bi emi ba nso ti ara mi.

18 Eniti nso ti ara re nwa ogo ara
re: sugbon eniti nwa ogo eniti o rBn a,
on li oloto, ko si si aisododo ninu re.

19 Mose ko ha fi ofin nyin, ko si
enikeni ninu nyin ti o pa ofin na mo?
Ese ti enyin fi nwa ona lati pa mi?

20 Ijo enia dahun nwon si wipe,
Iwo li emi esu: tani nwa ona lati pa o?

21 Jesu dahun o si wi fun won pe,
kiki ise ami kan ni mo se, enu si ya
gbogbo nyin.

22 Nitori eyi ni Mose fi ikola fun
nyin (ki ise nitoriti ise ti Mose, su-
gbon ti awon baba); nitorina e si nko
enia ni ila li ojo isimi.

23 Bi enia ba ngba ikola li ojo isimi,
ki a ma ba ru ofin Mose, e ha ti se
nabinu si mi, nitori mo mu enia kan
larada sasa li ojo isimi?

24 E mase idajo nipa ode ara, su-
gbon e ma se idajo ododo.

25 Nigbana li awon kan ninu awon
ara Jerusalemu wipe, Eniti nwon nwa
Ona ati pa ko yi?

26 Si wo o, o nsoro ni gbangba,
nwon ko si wi nkankan si i. Awon
olori ha mo nitoto pe, eyi ni Kristi na?

27 Sugbon awa mo ibi ti okonrin yi
gbe ti wa: sugbon nigbati Kristi ba de,
ko si eniti yio mo ibiti o gbe ti wa.

28 Nigbana ni Jesu kigbe ni tempili
bi o ti nkoni, wipe, Enyin mo mi, e si
mo ibiti mo ti wa: emi ko si wa fun
ara mi, sugbon oloto li eniti o ran mi,
eniti enyin ko mo.

29 Sugbon emi mo O: nitoripe lodo
re ni mo ti wa, on li o si ran mi.

30 Nitorina nwon nwa ona ati mu
u: sugbon ko si enikan ti o gbe owo le
e, nitoriti wakati re ko ti ide.

31 Opo ninu ijo enia si gba a gbo,
nwon si wipe, Nigbati Kristi na ba de,
yio ha se ise ami ju wonyi lo, ti oko-
nrin yi ti se?

32 & Awon Farisi gbo pe, ijo enia
nso nkan wonyi labele nipa re; awon
Farisi ati awon olori alufa si ran awon
onse lo lati mu u.

33 Nitorina Jesu wi fun won pe,
Niwon igba die si i li emi wa pelu nyin;
emi o si lo sodo eniti o ran mi.

34 Enyin yio wa mi, enyin ki yio si
ri mi: ati ibiti emi ba wa, enyin ki yio
Ie wa.

35 Nitorina li awon Ju mba ara
won so pe, Nibo ni okonrin yi yio gbe
lo, ti awa ki yio fi ri i? yio ha lo sarin
awon Hellene ti nwon fonka kiri, ki o
si ma ko awon Hellene bi?

36 Oro kili eyi ti o so yi, Enyin o
wa mi, e ki yio si ri mi: ati ibiti emi ba
wa, enyin ki yio le wa?

37 Lojo ikehin, ti ise ojo nia ajo,
Jesu duro, o si kigbe, wipe, Bi oru-
ngb? ba ngbe enikeni, ki o to mi wa,
ki o si mu.

38 Enikeni ti o ba gba mi gbo,
gege bi iwe-mimo ti wi, lati inu re ni
odo omi iye yio ti ma san jade wa.

39 (Sugbon o so eyi niti Emi, ti
awon ti o gba a gbo mbowa gba:
nitori a ko ti ifi Emi Mimo funni;
nitoriti a ko ti ise Jesu logo.)

40 & Nitorina nigbati opo ninu ijo
enia gbo oro wonyi, nwon wipe, Loto
eyi ni woli na.

41 Awon miran wipe, Eyi ni Kristi
na. Sugbon awon kan wipe Kinla,
Kristi yio ha ti Galili wa bi?

42 Iwe-mimo ko ha wipe, Kristi yio
ti inu iru omo Dafidi wa, ati Betle-
hemu, ilu ti Dafidi ti wa?

43 Beni iyapa wa larin ijo enia
nitori re.

44 Awon miran ninu won si fe lati
mu u; sugbon ko si enikan ti o gbe
owo le e.

45 & Nitorina awon onse pada to
awon olori alufa ati awon Farisi wa;
nwon si wi fun won pe, Ese ti enyin ko
fi mu u wa?

46 Awon onse dahun wipe, Ko si
eniti o ti isoro bi okonrin yi ri.

47 Nitorina awon Farisi da won
lohun wipe, A ha tan enyin jepelu bi?

48 O ha si enikan ninu awon ijoye,
tabi awon Farisi ti o gba a gbo?

49 Sugbon ijo enia yi, ti ko mo ofin,
di eni ifibu.

50 Nikodemu si wi fun won pe,
(eniti o to Jesu wa loru, o je okan ninu
won),

51 Ofin wa nse idajo ema ki o to
gbo ti enu re, ati ki o to mo ohun ti o
se bi?

52 Nwon dahun nwon si wi fun u
pe, Iwo pelu nse ara Galili ndan?
Wa kiri, ki o si wo: nitori ko si woli
kan ti o ti Galili dide.

53 Nwon si lo olukukuku si ile re.

/8 Jesu si lo si ori oke Olifi.

2 O si tun pada wa si tempili ni
kutukutu owuro, gbogbo enia si wa
sodo re; o si joko, o nko won.

3 Awon akowe ati awon Farisi si
mu obirin kan wa sodo re, ti a mu ninu
pansaga; nigbati nwon si mu u duro
larin,

4 Nwon wi fun u pe, Olukoni, a mu
obirin yi ninu pansaga, ninu sise e
papa.

5 Nje ninu ofin, Mose pase fun wa
lati so iru awon be li okuta pa: su-
gbon iwo ha ti wi?

6 Eyini nwon wi, nwon ndan a wo,
ki nwon ba le ri ohun lati fi i sun.
Sugbon Jesu bere sile, o si nfi ika re
kowe ni ile.

7 Sugbon nigbati nwon mbi i lere
sibesibe, o gbe ara re soke, o si wi fun
won pe, Eniti o ba se ailese ninu nyin,
Je ki o ko so okuta lu u.

8 O si tun bere sile, o nkowe ni ile.

9 Nigbati nwon gbo eyi, nwon si
jade lo lokokan, bere lati odo awon
agba titi de awon ti o kehin; a si fi
Jesu nikan sile, ati obirin na larin,
nibiti o ti wa.

10 Jesu si gbe ara re soke, o si wi
fun u pe, Obirin yi, awon da? ko si
enikan ti o da o lebi?

11 O wipe, Ko si enikan, Oluwa.
Jesu si wi fun u pe, Beli emi na ko da
o lebi: ma lo, lati igbayi lo ma dese
mo.

12 & Jesu si tun so fun won pe, Emi
ni imole aiye; eniti o ba to mi lehin ki
yio rin ninu okunkun, sugbon yio m
imole iye.

13 Nitorina awon Farisi wi fun u
pe, Iwo njeri ara re; eri re ki ise otito.

14 Jesu dahun o si wi fun won pe,
Bi mo tile njeri fun ara mi, otito li eri
mi: nitoriti mo mo ibiti mo ti wa, mo
si mo ibiti mo nio; sugbon enyin ko
Ie mo ibiti mo ti wa, ati ibiti mo nio.

15 Enyin nse idajo nipa ti ara; emi
ko se idajo enikeni.

16 Sugbon bi emi ba si se idajo,
otito ni idajo mi: nitori emi nikan ko,
Sugbon emi ati Baba ti o ran mi.

17 E si ko o pelu ninu ofin nyin pe,
otito li eri enia meji.

18 Emi li eniti njeri ara mi, ati Baba
ti o ran mi si njeri fun mi.

19 Nitorina nwon wi fun u pe, Nibo
ni Baba re wa? Jesu dahun pe,
Enyin ko mo mi, beli e ko mo Baba
mi: ibasepe enyin mo mi, enyin iba si
ti mo Baba mi pelu.

20 Oro wonyi ni Jesu so nibi isura,
bi o ti nkoni ni tempili: enikeni ko si
mu u; nitori wakati re ko ti ide.

21 Nitorina o tun wi fun won pe,
Emi nio, enyin yio si wa mi, e o si ku
ninu ese nyin: ibiti emi gbe nio, enyin
ki o le wa.

22 Nitorina awon Ju wipe. On o ha
pa ara re bi? nitoriti o wipe, Ibiti emi
gbe lo, enyin ki o le wa.

23 O si wi fun won pe, Enyin ti
isale wa; emi ti oke wa: enyin je ti
aiye yi; emi ki ise ti aiye yi.

24 Nitorina ni mo se wi fun nyin
pe, e o ku ninu ese nyin: nitori bikose
e ba gbagbo pe, emi ni, e o ku ninu
ese nyin.

25 Nitorina nwon wi fun u pe. Tani
iwo ise? Jesu si wi fun won pe, Ani
eyini ti mo ti wi fun nyin li atetekose.

26 Mo ni ohun pupo lati so, ati
lati se idajo nipa nyin: sugbon oloto
li eniti o ran mi, ohun ti emi si ti gbo
lati odo re wa, nwonyi li emi nso fun
araiye.

27 Ko ye won pe, ti Baba li o nso
fun won.

28 Nitorina Jesu wi fun won pe,
Nigbati e ba gbe Omo-enia soke,
nigbana li e o mo pe, emi ni, ati pe emi
ko da ohurikohun se fun ara mi;
sugbon bi Baba ti ko mi, emi nso
nkan wonyi.

29 Eniti o ran mi si mbe pelu mi:
ko jowo emi nikan si; nitoriti emi nse
ohun ti o wu u nigbagbogbo.

30 Bi o ti nso nkan wonyi, opo enia
gba a gbo.

31 Nitorina Jesu wi fun awon Ju ti
o gba a gbo pe, Bi enyin ba duro ninu
Oro mi, nigbana li enyin je omo-ehin
mi nitoto.

32 E o si mo otito, otito yio si so
nyin di omnira.

33 & Nwon da a lohun wipe, Iru-
omo Abrahamu li awa ise, awa ko si
se eru fun enikeni ri lai: iwo ha se
wipe, E o di omnira?

34 Jesu da won lohun pe, Loto,
loto ni mo wi fun nyin, Enikeni ti o ba
ndese, on li eru ese.

35 Eru ki si igbe ile titilai: Omo ni
igbe ile titilai.

36 Nitorina bi Omo ba so nyin di
omnira, e o di omnira nitoto.

37 Mo mo pe iru-omo Abrahamu
U enyin ise; sugbon e nwa ona ati pa
mi, nitori oro mi ko ri aye ninu nyin.

38 Ohun ti emi ti ri lodo Baba ni
mo nso: enyin pelu si nse eyi ti enyin
ti gbo lati odo baba nyin.

39 Nwon dahun nwon si wi fun u
pe, Abrahamu ni baba wa. Jesu wi
fun won pe, Ibasepe omo Abrahamu
li enyin ise, enyin iba se ise Abrahamu.

40 Sugbon nisisiyi enyin nwa ona
ati pa mi, eniti o so otito fun nyin, eyi
ti mo ti gbo lodo Olorun: Abrahamu
ko se eyi.

41 Enyin nse ise baba nyin. Ni-
gbana ni nwon wi fun u pe, A ko bi wa
nipa pansaga: a ni Baba kan, eyini li
Olorun.

42 Jesu wi fun won pe, Ibasepe
Olorun ni Baba nyin, enyin iba feran
mi: nitoriti emi ti odo Olorun jade, mo
si wa: beli emi ko si wa fun ara mi,
sugbon on li o ran mi.

43 Etise ti ede mi ko fi ye nyin?
nitori e ko le gbo oro mi ni.

44 Ti esu baba nyin li enyin ise,
ifekufe baba nyin li e si nfe se. Apania
li on ise lati atetekose, ko si duro ni
otito; nitoriti ko si otito ninu re.
Nigbati o ba nseke, ninu ohun tire li o
nso, nitori eke ni, ati baba eke.

45 Sugbon nitori emi so otito fun
nyin, e ko si gba mi gbo.

46 Tani ninu nyin ti o ti ida mi li
ebi ese? Bi mo ba nso otito ese ti
enyin ko fi gba mi gbo?

47 Eniti ise ti Olorun, a ma gbo
oro Olorun: nitori eyi li enyin ko se
gbo, nitori enyin ki ise ti Olorun.

48 Awon Ju dahun nwon si wi fun
u pe, Awa ko wi nitoto pe, ara Samaria
ni iwo ise, ati pe iwo li emi esu?

49 Jesu dahun wipe, Emi ko li enii
esu; sugbon emi mbola fun Baba mi,
enyin ko si bola fun mi.

50 Emi ko wa ogo ara mi: enikan
mbe ti o nwa a ti o si nse idajo.

51 Loto, loto ni mo wi fun nyin,
Bi enikan ba pa oro mi mo, ki yio ri
iku lailai.

52 Awon Ju wi fun u pe, Nigbayi
ni awa mo pe iwo li emi esu. Abra-
hamu ku, ati awon woli; iwo si wipe,
Bi enikan ba pa oro mi mo, ki yio to
iku wo lailai.

53 Iwo ha poju Abrahamu baba wa
lo, eniti o ku? awon woli si ku: tani
iwo nfi ara re pe?

54 Jesu dahun wipe, Bi mo ba nyin
ara mi li ogo, ogo mi ko je nkan: Baba
mi ni eniti nyin mi li ogo, eniti enyin
wipe, Olorun nyin ni ise:

55 E ko si mo O; sugbon emi mo o:
bi mo ba si wipe, emi ko mo o, emi o
di eke gege bi enyin: sugbon emi mo
o, mo si pa oro re mo.

56 Abrahamu baba nyin yo lati ri
ojo mi: o si ri i, o si yo.

57 Nitorina awon Ju wi fun u pe,
Odun re ko ti ito adota, iwo si ti ri
Abrahamu?

58 Jesu si wi fun won pe, Loto,
loto ni mo wi fun nyin, Ki Abrahamu
to wa, emi niyi.

59 Nitorina nwon gbe okuta lati so
lu u: sugbon Jesu fi ara re pamo, o si
jade kuro ni tempili.

/9 Bi o si ti nkoja lo, o ri okonrin kan
ti o foju lati igba ibi re wa.

2 Awon omo-ehin re si bi i lere,
wipe. Olukoni, tani dese, okonrin yi
tabi awon obi re, ti a fi bi i li afoju?

3 Jesu dahun pe, Ki ise nitoriti
okonrin yi dese, tabi awon obi re:
sugbon ki a le fi ise Olorun han lara re.

4 Emi ko le se alaise ise eniti o ran
mi, nigbati ise osan: oru mbo wa
nigbati enikan ki o le se ise.

5 Niwon igba ti mo wa li aiye, emi
ni imole aiye.

6 Nigbati o ti wi be tan, o tuto sile,
o si fi ito na se amo, o si fi amo na pa
oju afoju na,

7 O si wi fun u pe, Lo, we ninu
adagun Siloamu, (itumo eyi ti ije Ran-
lo.) Nitorina o gba ona re lo, o we, o
si de, o nriran.

8 Nje awon aladugbo ati awon ti o
ri i nigba atijo pe alagbe ni ise, wipe,
Eniti o ti njoko sagbe ko yi?

9 Awon kan wipe. On ni: awon
elomiran wipe, Beko, o jo O ni: su-
gbon on wipe, Emi ni.

10 Nitorina ni nwon wi fun u pe,
Nje oju re ti se la?

110 dahun o si wi fun won pe,
Okonrin kan ti a npe ni Jesu li o se
amo, o si fi kun mi loju, o si wi fun mi
pe, Lo si adagun Siloamu, ki o si we:
emi si lo, mo we, mo si riran.

12 Nwon si wi fun u pe. On na ha
da? O wipe, emi ko mo.

13 & Nwon mu eniti oju re ti fo ri
wa sodo awon Farisi.

14 Nje ojo isimi lojo na nigbati
Jesu se amo na, ti o si la a loju.

15 Nitorina awon Farisi pelu tun
bi i lere, bi o ti se riran. O si wi fun
won pe, O fi amo le oju mi, mo si we
mo si riran.

16 Nitorina awon kan ninu awon
Farisi wipe, Okonrin yi ko ti odo
Olorun wa, nitoriti ko pa ojo isimi mo.
Awon elomiran wipe, Okonrin ti ise
elese yio ha ti se le se iru ise ami
wonyi? Iyapa si wa larin won.

17 Nitorina nwon si tun wi fun
afoju na pe, Kini iwo wi nitori re,
nitoriti o la o loju? O si wipe, Woli
ni ise.

18 Nitorina awon Ju ko gbagbo
nitori re pe, oju re ti fo ri, ati pe o si
tun riran, titi nwon fi pe awon obi
eniti a ti la loju.

19 Nwon si bi won lere, wipe, Eyi
li omo nyin, eniti enyin wipe, a bi i li
afoju? ehase riran nisisiyi?

20 Awon obi re da won lohun wipe,
Awa mo pe omo wa li eyi, ati pe a bi
i li afoju:

21 Sugbon bi o ti se nriran nisisiyi
awa ko mo; tabi eniti o la a loju, awa
ko mo; eniti o gbonju ni ise; e bi i
lere: yio wi fun ara re.

22 Nkan wonyi li awon obi re so,
nitoriti nwon beru awon Ju: nitori
awon Ju ti fi ohun sokan pe, bi enikan
ba jewo pe, Kristi ni ise, nwon o yo o
kuro ninu sinagogu.

23 Nitori eyi li awon obi re fi wipe,
Eniti o gbonju ni ise; e bi i lere.

24 Nitorina nwon pe okonrin afoju
na lekeji, nwon si wi fun u pe, Fi ogo
fun Olorun: awa mo pe elese-li oko-
nrin yi ise.

25 Nitorina o dahun o si wipe, Bi
elese ni, emi ko mo: ohun kan ni mo
mo, pe mo ti foju ri, mo riran nisisiyi.

26 Nitorina nwon wi fun u pe, Kili
o se si o? o ti se la o loju?

27 O da won lohun wipe, Emi ti so
fun nyin na, enyin ko si gbo: nitori
kili, enyin se nfe tun gbo? enyin pelu
nfe se omo-enin re bi?

28 Nwon si fi i se eleya, nwon si
wipe, Iwo li omo-ehin re; sugbon omo-
ehin Mose li awa.

29 Awa mo pe Olorun ba Mose
soro: sugbon bi o se ti eleyi, awa ko
mo ibiti o gbe ti wa.

30 Okonrin na dahun o si wi fun
won pe, Ohun iyanu sa li eyi, pe, enyin
ko mo ibiti o gbe ti wa, sugbon on sa
ti la mi loju.

31 Awa mo pe, Olorun ki igbo ti
elese: sugbon bi enikan ba se olufo-
kansin si Olorun, ti o ba si nse ife re,
on ni igbo tire.

32 Lati igba ti aiye ti se, a ko ti
igbo pe, enikan la oju eniti a bi li
afoju ri.

33 Ibasepe okonrin yi ko ti odo
Olorun wa, ki ba ti le se ohunkohun.

34 Nwon si dahun wi fun u pe, Ninu
ese li a bi iwo patapata, iwo si nko wa
bi? Nwon si ti i sode.

35 Jesu gbo pe, nwon ti ti i sode;
nigbati o si ri i, o wipe, Iwo gba Omo
Olorun gbo bi?

36 On si dahUn wipe, Tani, Oluwa,
ki emi ki o le gba a gbo?

37 Jesu wi fun u pe, iwo ti ri i, on
na si ni eniti mba o soro yi.

38 O si wipe, Oluwa, mo gbagbo, o
si wole fun u.

39 & Jesu si wipe, Nitori idajo ni
mo se wa si aiye yi, ki awon ti ko riran,
le riran; ati ki awon ti o riran le di
afoju.

40 Ninu awon Farisi ti o wa lodo
re gbo nkan wonyi, nwon si wi fun u
pe, Awa pelu foju bi?

41 Jesu wi fun won pe, Ibasepe
enyin foju, enyin ki ba ti li ese: sugbon
nisisiyi enyin wipe, Awa riran; nitorina
ese nyin wa sibe.

/10 Loto, loto ni mo wi fun nyin,
Eniti ko ba gba enuona wo inu
agbo agutan, sugbon ti o ba gba ibo-
miran gun oke, on na li ole ati olosa.

2 Sugbon eniti o ba ba ti enu-ona
wole, on ni ise oluso awon agutan.

3 On ni oludena silekun fun; awon
agutan si gbo ohun re: o si pe awon
agutan tire li oruko, o si se amona
won jade.

4 Nigbati o si mu awon agutan tire
jade, o siwaju won, awon agutan si
nto o lehin: nitoriti nwon mo ohun re.

5 Nwon ko je to alejo lehin, su-
gbon nwon a ma sa lodo re; nitoriti
nwon ko mo ohun alejo.

6 Owe yi ni Jesu pa fun won:
$ugbon oye ohun ti nkan wonni je ti
o nso fun won ko ye won.

7 Nitorina Jesu tun wi fun won pe,
Loto, loto ni mo wi fun nyin, Emi ni
ilekun awon agutan.

8 Ole ati olosa ni gbogbo awon ti
o ti wa siwaju mi: sugbon awon agu-
tan ko gbo ti won.

9 Emi ni ilekun: bi enikan ba ba
odo mi wole, on li a o gba la, yio wole,
yio si jade, yio si ri koriko.

10 Ole ki iwa bikose lati jale, ati
lati pa, ati lati parun: emi wa ki nwon
Ie ni iye, ani ki nwon le ni i lopolopo.

11 Emi ni oluso-agutan rere: oluso-
agutan rere fi emi re lele nitori awon
agutan.

12 Sugbon alagbase, ti ki ise oluso-
agutan, eniti awon agutan ki ise tire,
o ri ikoko mbo, o si fi awon agutan
sue, o si sa lo: ikoko si mu awon agu-
tan, o si ton won ka kiri.

13 Alagbase sa lo nitoriti ise ala-
gbase, ko si nani awon agutan.

14 Emi ni oluso-agutan rere, mo si
mo awon temi, awon temi si mo mi.

15 Gege bi Baba ti mo mi, ti emi si
mo Baba; mo si fi emi mi lele nitori
awon agutan.

16 Emi si ni awon agutan miran, ti
ki ise ti agbo yi: awon li emi ko le se
alaimu wa pelu, nwon o si gbo ohun
mi; nwon o si je agbo kan, oluso-
agutan kan.

17 Nitorina ni Baba mi se feran mi,
nitoriti mo fi emi mi lele, ki emi ki o
le tun gba a.

18 Enikan ko gba a lowo mi, su-
gbon mo fi i lele fun ara mi. Mo li
agbara lati fi i lele, mo si li agbara lati
tun gba a. Ase yi ni mo ti gba lati
odo Baba mi wa.

19 & Nitorina iyapa tun wa larin
awon Ju nitori oro wonyi.

20 Opo ninu won si wipe, O li emi
esu, ori re si baje; ese ti enyin fi ngboro
re?

21 Awon miran wipe, Wonyi ki ise
Oro eniti o li emi esu. Emi esu le la
oju awon afoju bi?

22 & O si je ajo odun iyasimimo ni
Jerusalemu, igba otutu ni.

23 Jesu si nrin ni tempili, ni iloro
Solomoni.

24 Nitorina awon Ju wa duro yi i
ka, nwon si wi fun u pe, Iwo o ti mu
wa se iyemeji pe to? Bi iwo ni ise
Kristi na, wi fun wa gbangba.

25 Jesu da won lohun wipe, Emi ti
wi fun nyin, enyin ko si gbagbo; ise ti
emi nse li oruko Baba mi, awon ni
njeri mi.

26 Sugbon enyin ko gbagbo, nitori
enyin ko si ninu awon agutan mi, gege
bi mo ti wi fun nyin.

27 Awon agutan mi ngbo ohun mi;
emi si mo won, nwon a si ma to mi
lehin:

28 Emi si fun won ni iye ainipekun,
nwon ki o si segbe lailai, ko si si eniti
o le ja won kuro li owo mi.

29 Baba mi, eniti o fi won fun nil,
po ju gbogbo won lo; ko si si eniti o
Ie ja won kuro li owo Baba mi.

30 Okan li emi ati Baba mi jasi.

31 Awon Ju si tun he okuta, lati so
lu u.

32 Jesu da won lohun pe, Opolopo
ise rere ni mo fi han nyin lati odo Baba
mi wa; nitori ewo ninu ise wonni li
enyin se so mi li okuta?

33 Awon Ju si da a lohun, wipe,
Awa ko so O li okuta nitori ise rere,
sugbon nitori oro-odi: ati nitori iwo
ti ise enia nfi ara re se Olorun.

34 Jesu da won lohun pe, A ko ha
ti ko o ninu ofin nyin pe, Mo ti wipe,
olorun li enyin ise?

35 Bi o ba pe won li olorun, awon
eniti a fi oro Olorun fun, a ko si le ba
iwe-mimo je,

36 Enyin ha nwi niti eniti Baba ya
si mimo, ti o si ran si aiye, pe Iwo
nsoro-odi?

37 Bi emi ko ba se ise Baba mi, e
mase gba mi gbo.

38 Sugbon bi emi ba se won, bi
enyin ko tile gba mi gbo, e gba ise na
gbo: ki enyin ki o le mo, ki o si le ye
nyin pe, Baba wa ninu mi, emi si wa
ninu re.

39 Nwon si tun nwa ona lati mu u:
o si bo lowo won.

40 O si tun koja lo si apakeji
Jordani si ibiti Johannu ti ko mbaptisi;
nibe li o si joko.

41 Awon enia pipo si wa sodo re,
nwon si wipe, Johannu ko se ise ami
kan: sugbon otito li ohun gbogbo ti
Johannu so nipa ti okonrin yi.

42 Awon enia pipo nibe si gba a
gbo.

/11 Ara okonrin kan si se alaida,
Lasaru, ara Betani, ti ise ilu Maria
ati Marta arabirin re.

2 (Maria na li eniti o fi ororo ikunra
kun Oluwa, ti o si fi irun ori re nu ese
re nu, arakonrin re ni Lasaru ise, ara
eniti ko da.)

3 Nitorina awon arabirin re ranse
si i, wipe, Oluwa, wo o, ara eniti iwo
feran ko da.

4 Nigbati Jesu si gbo, o wipe, Aisan
yi ki ise si iku, sugbon fun ogo Olorun,
ki a le yin Omo Olorun logo nipase re.

5 Jesu si feran Marta, ati arabirin
re, ati Lasaru.

6 Nitorina nigbati o ti gbo pe, ara
re ko da, o gbe ijo meji si i nibikanna
ti o gbe wa.

7 Nje lehin eyi li o wi fun awon
omo-ehin re pe, E Je ki a tun pada lp
si Judea.

8 Awon omo-ehin re si wi fun u pe,
Rabbi, ni lolo yi li awon Ju nwa ona
ati so o li okuta; iwo si ntun pada lo
sibe?

9 Jesu dahun pe, Wakati mejila ki
mbe ninu osan kan? Bi enikan ba
rin li osan, ki yio kose, nitoriti o ri
imole aiye yi.

10 Sugbon bi enikan ba rin li oru,
yio kose, nitoriti ko si imole ninu re.

11 Nkan wonyi li o so: lehin eyini
o si wi fun won pe, Lasaru ore wa sun;
sugbon emi nio ki emi ki o le ji i dide
ninu orun re.

12 Nitorina awon omo-ehin re wi
fun u pe, Oluwa, bi o ba se pe o sun,
yio san.

13 Sugbon Jesu nso ti iku re:
Sugbon nwon ro pe, o nso ti orun sisun.

14 Nigbana ni Jesu wi fun won
gbangba pe, Lasaru ku.

15 Emi si yo nitori nyin, ti emi ko
si nibe, Ki e le gbagbo; sugbon e je ki
a lo sodo re.

16 Nitorina Tomasi, eniti a npe ni
Didimu, wi fun awon omo-ehin egbe
re pe, E je ki awa na lo, ki a le ba a ku
pelu.

17 Nitorina nigbati Jesu de, o ri pe
a ti te e sinu iboji ni ijo merin na.

18 Nje Betani sunmo Jerusalemu to
furlongi medogun:

19 Opo ninu awon Ju si wa sodo
Marta ati Maria, lati tu won ninu
nitori ti arakonrin won.

20 Nitorina nigbati Marta gbo pe
Jesu mbo wa, o jade lo ipade re:
sugbon Maria joko ninu ile.

21 Nigbana ni Marta wi fun Jesu
pe, Oluwa, ibasepe iwo ti wa nihin,
arakonrin mi ki ba ku.

22 Sugbon nisisiyi na, mo mo pe,
ohunkohun ti iwo ba bere lowo Olo-
run, Olorun yio fifun o.

23 Jesu wi fun u pe, Arakonrin re
yio jinde.

24 Marta wi fun u pe, mo mo pe
yio jinde li ajinde nigbehin ojo.

25 Jesu wi fun u pe, Emi ni ajinde,
ati iye: eniti o ba gba mi gbo, bi o tile
ku, yio ye:

26 Enikeni ti o mbe laye, ti o si gba
mi gbo, ki yio ku lailai. Iwo gba eyi
gbo?

27 O wi fun u pe, Beni, Oluwa: emi
gbagbo pe, iwo ni Kristi na Omo
Olorun, eniti mbo wa aiye.

28 Nigbati o si ti wi eyi tan, o lo, o
si pe Maria arabirin re sehin wipe,
Olukoni de, o si npe o.

29 Nigbati o gbo, o dide logan, o si
wa sodo re.

30 Jesu ko sa ti iwo ilu, sugbon o
wa nibikanna ti Marta pade re.

31 Nitorina awon Ju ti o wa lodo
re ninu ile, ti nwon ntu u ninu, nigbati
nwon ri ti Maria dide kankan, ti o si
jade, nwon tele e, nwon sebi o nio si
iboji lo isokun nibe.

32 Nigbati Maria si de ibiti Jesu
gbe wa, ti o si ri i, o wole leba ese re,
o wi fun u pe, Oluwa, ibasepe iwo ti
wa nihin, arakonrin mi ki ba ku.

33 Nje nigbati Jesu ri i, ti o nsokun,
ati awon Ju ti o ba a wa nsokun pelu
re, o kerora li okan re, inu re si baje,

34 O si wipe, Nibo li enyin gbe te
e si? Nwon si wi fun u pe, Oluwa, wa
wo o.

35 Jesu sokun.

36 Nitorina awon Ju wipe, sa wo o
bi o ti feran re to!

37 Awon kan ninu won si wipe,
Okunrin yi, eniti o la oju afoju, ko le
se ki okonrin yi ma ku bi?

38 Nigbana ni Jesu tun kerora ninu
ara re, o wa si iboji. O si je iho, a si
gbe okuta le enu re.

39 Jesu wipe, E gbe okuta na kuro.
Marta, arabirin eniti o ku na wi fun
u pe, Oluwa, o ti nrun nisisiyi: nito-
ripe o di ijo merin ti o ti ku.

40 Jesu wi fun u pe, Emi ko ti wi
fun o pe, bi iwo ba gbagbo, iwo o ri
ogo Olorun?

41 Nigbana ni nwon gbe okuta na
kuro nibiti a gbe te oku na si. Jesu si
gbe oju re soke, o si wipe, Baba, mo
dupe lowo re, nitoriti iwo gbo ti emi.

42 Emi si ti mo pe, iwo a ma gbo
ti emi nigbagbogbo: sugbon nitori ijo
enia ti o duro yi ni mo se wi i, ki nwon
ki o le gbagbo pe iwo li o ran mi.

43 Nigbati o si ti wi be tan, o kigbe
li ohim rara pe, Lasaru, jade wa.

44 Eniti o ku na si jade wa, ti a fi
aso oku di towo tese a si fi gele di i
loju. Jesu wi fun won pe, E tu u, e
si je ki o ma lo.

45 Nitorina li opo awon Ju ti o wa
sodo Maria, ti nwon ri ohun ti Jesu
se, nwon gba a gbo.

46 Sugbon awon elomiran ninu won
to awon Farisi lo, nwon si so fun won
ohun ti Jesu se.

47 & Nigbana li awon olori alufa
ati awon Farisi pe igbimo jo, nwon si
wipe, Kili awa nse? nitori okonrin yi
nse opolopo ise ami.

48 Bi awa ba jowo re be, gbogbo
enia ni yio gba a gbo: awon ara Romu
yio si wa gba ile ati orile-ede wa pelu.

49 Sugbon Kaiafa, okan ninu won,
eniti ise olori alufa li odun na, o wi fun
won pe, Enyin ko mo ohunkohun rara.

50 Beni e ko si ronu pe, o sanfani
fun wa, ki enia kan ku fun awon enia,
ki gbogbo orile-ede ki o ma ba segbe.

51 Ki ise fun ara re li o so eyi;
sugbon bi o ti je olori alufa li odun na,
o sotele pe, Jesu yio ku fun orile-ede
na:

52 Ki si ise kiki fun orile-ede na
nikan, sugbon pelu ki o le ko awon
omo Olorun ti a ti funka kiri jo li
okansoso.

53 Nitorina lati ojo na lo ni nwon
ti jo gbimo po lati pa a.

54 Nitorina Jesu ko rin ni gbangba
larin awon Ju mo; sugbon o ti ibe lo
si igberiko kan ti o sunmo aginju, si
ilunla kan ti a npe ni Efraimu, nibe li
o si wa pelu awon omo-ehin re.

55 & Ajo irekoja awon Ju si sunmo
etile: opolopo lati igberiko wa si goke
lo si Jerusalemu siwaju irekoja, lati ya
ara won si mimo.

56 Nigbana ni nwon nwa Jesu;
nwon si mba ara won so, bi nwonti
duro ni tempili, wipe, Enyin ti ro o si?
pe ki yio wa si ajo?

57 Nje awon olori alufa ati awon
Farisi ti pase pe bi enikan ba mo ibi
ti o gbe wa, ki o fi i han, ki nwon ki o
le mu u.

/12 Nitorina nigbati ajo irekoja ku
ijo mefa, Jesu wa si Betani, nibiti
Lasaru wa, eniti o ti ku, ti Jesu ji dide
kuro ninu oku.

2 Nwon si se ase-ale fun u nibe:
Marta si nse iranse: sugbon Lasaru
je okan ninu awon ti o joko nibi tabili
pelu re.

3 Nigbana ni Maria mu ororo
ikunra nardi, osuwon litra kan, aila-
bula, olowo iyebiye, o si nfi kun Jesu
li ese, o si nfi irun ori re nu ese re nu:
ile si kun fun orun ikunra na.

4 Nigbana li okan ninu awon omo-
ehin re, Judasi Iskariotu, omo Simoni,
eniti yio fi i han, wipe,

5 Ese ti a ko ta ororo ikunra yi ni
odurun owo ide ki a si fifun awon
talaka?

6 Sugbon o wi eyi, ki ise nitoriti o
nani awon talaka; sugbon nitoriti ise
ole, on li o si ni apo, a si ma gbe ohun
ti a fi sinu re.

7 Nigbana ni Jesu wipe, E jowo re,
o se e sile de ojo sisinku mi.

8 Nigbagbogbo li enyin sa ni talaka
pelu nyin; sugbon emi li e ko ni
nigbagbogbo.

9 Nitorina ijo enia ninu awon Ju li
o mo pe o wa nibe: nwon si wa, ki ise
nitori Jesu nikan, sugbon ki nwon le
ri Lasaru pelu, eniti o ti ji dide kuro
ninu oku.

10 & Sugbon awon olori alufa gbi-
mo ki nwon le pa Lasaru pelu;

11 Nitoripe nipase re li opo ninu
awon Ju jade lo, nwon si gba Jesu gbo.

12 & Ni ijo keji nigbati opo enia ti
o wa si ajo gbo pe, Jesu mbo wa si
Jerusalemu,

13 Nwon mu imo-ope, nwon si jade
lo ipade re, nwon si nkigbe pe,
Hosanna: Olubukun li eniti mbowa li
oruko Oluwa, Oba Israeli.

14 Nigbati Jesu si ri omo ketekete
kan, o gun u; gege bi a ti kowe pe,

15 Ma beru, omobirin Sioni: wo o,
Oba re mbo wa, o joko lori omo
ketekete.

16 Nkan wonyi ko tete ye awon
Omo-ehin re: sugbon nigbati a se Jesu
logo, nigbana ni nwon ranti pe, a kowe
nkan wonyi niti re, ati pe, on ni nwon
se nkan wonyi si.

17 Nitorina ijo enia ti o wa lodo
re, nigbati o pe Lasaru jade ninu iboji
re, ti o si ji i dide kuro ninu oku, nwon
jeri.

18 Nitori eyi ni ijo enia si se lo
ipade re, nitoriti nwon gbo pe o ti se
ise ami yi.

19 Nitorina awon Farisi wi fun ara
won pe, E kiyesi bi e ko ti le bori li;
ohunkohun? e wo bi gbogbo aiye ti
nwo to o.

20 & Awon Hellene kan si wa ninu
awon ti o goke wa lati sin nigba ajo:

21 Awon wonyi li o to Filippi wa,
eniti ise ara Betsaida ti Galili, nwon si
mbere lowo re, wipe, Alagba, awa nfe
ri Jesu.

22 Filippi wa, o si so fun Anderu;
Anderu ati Filippi wa, nwon si so fun
Jesu.

23 & Jesu si da won lohun wipe,
Wakati na de, ti a o se Omo-enia logo.

24 Loto, loto ni mo wi fun nyin,
Bikosepe woro alikama ba bo si ile,
ti o ba si ku, o wa on nikan: sugbon
bi o ba ku, a si so opolopo eso.

25 Eniti o ba fe emi re yio so o nu;
eniti o ba si korira emi re li aiye yi ni
yio si pa a mo titi fi di iye ainipekun.

26 Bi enikeni ba nsin mi, ki o ma to
mi lehin: ati nibiti emi ba wa, nibe
ni iranse mi yio wa pelu: bi enikeni ba
nsin mi, on ni Baba yio bu ola fun.

27 Nisisiyi li a npon okan mi loju;
kili emi o si wi? Baba, gba mi kuro
ninu wakati yi: sugbon nitori eyi ni
mo se wa si wakati yi.

28 Baba, se oruko re logo. Nito-
rina ohun kan ti orun wa, wipe, Emi
ti se e logo na, emi o si tun se e logo.

29 Nitorina ijo enia ti o duro nibe,
ti nwon si gbo o, wipe, Ara nsan:
awon elomiran wipe, Angeli kan li o
mba a soro.

30 Jesu si dahun wipe, Ki ise nitori
mi li ohun yi se wa, bikose nitori nyin.

31 Nisisiyi ni idajo aiye yi de:
nisisiyi li a o le alade aiye yi jade.

32 Ati emi, bi a ba gbe mi soke kuro,
li aiye, emi o fa gbogbo enia sodo ara
mi.

33 Sugbon o wi eyi, o nsapere iru
iku ti on o ku.

34 Nitorina awon ijo enia da a;
lohun wipe, Awa gbo ninu ofin pe,.
Kristi wa titi lailai: iwo ha se wipe, A
ko le saima gbe Omo-enia soke? tani
ise Omo-enia yi?

35 Nigbana ni Jesu wi fun won pe,
Nigba die si i ni imole wa larin nyin.
E ma rin nigbati enyin ni imole, ki
okunkun mase ba le nyin; eniti o ba
si nrin li okunkun ko mo ibiti on gbe
nio.

36 Nigbati enyin ni imole, e gba
imole gbo, ki e le je omo imole.
Nkan wonyi ni Jesu so, o si jade lo, o
fi ara pamo fun won.

37 & Sugbon bi o ti se opolopo ise
ami to bayi li oju won, nwon ko gba a
gbo;

38 Ki oro woli Isaiah le se, eyiti o
so pe, Oluwa, tali o gba iwasu wa gbo?
ati tali a si fi apa Oluwa han fun?

39 Nitori eyi ni nwon ko fi le gba-
gbo, nitori Isaiah si tun so pe,

40 O ti fo won loju, o si ti se aiya
won le; ki nwon ma ba fi oju won ri,
ki nwon ma ba fi okan won mo, ki
nwon ma ba yipada, ki emi ma ba mu
won larada.

41 Nkan wonyi ni Isaiah wi, nitori
o ti ri ogo re, o si soro re.

42 & Sibe opo ninu awon olori gba
a gbo pelu; sugbon nitori awon Farisi
nwon ko jewo re, ki a ma ba yo won
kuro ninu sinagogu:

43 Nitori nwon fe iyin enia ju iyin
ti Olorun lo.

44 & Jesu si kigbe o si wipe, Eniti o
ba gba mi gbo, emi ko h o gbagbo,
sugbon eniti o ran mi.

45 Eniti o ba si ri mi, o ri eniti o
ran mi.

46 Emi ni imole ti o wa si aiye, ki
enikeni ti o ba gba mi gbo ki o mase
wa li okunkun.

47 Bi enikeni ba si gbo oro mi, ti
ko si pa won mo, emi ki yio se idajo
re: nitoriti emi ko wa lati se idajo aiye,
bikose lati gba aiye la.

48 Eniti o ba ko mi, ti ko si gba
oro mi, o ni enikan ti nse idajo re:
oro ti mo ti so, on na ni yio se idajo re
ni igbehin ojo.

49 Nitori emi ko da oro so fun ara
mi, sugbon Baba ti o ran mi, on li o
ti fun mi li ase, ohun ti emi o so, ati
eyiti emi o wi.

50 Emi si mo pe iye ainipekun li
ofin re: nitorina, ohun wonni ti mo ba
wi, gege bi Baba ti so fun mi, beni mo
wi.

/13 Nje ki ajo irekoja ki o to de, nigbati
Jesu mo pe wakati re de tan, ti on
o ti aiye yi kuro lo sodo Baba, fife ti o
fe awon tire ti o wa li aiye, o fe won
titi de opin.

2 Bi nwon si ti nje onje ale, ti Esu
ti fi i si okan Judasi Iskariotu omo
Simoni lati fi i han;

3 Ti Jesu si ti mo pe Baba ti fi ohun
gbogbo le on lowo, ati pe lodo Olorun
li on ti wa, on si nio sodo Olorun;

4 O dide ni idi onje ale, o si fi agbada
re lele li apakan; nigbati o si mu gele,
o di ara re li amure.

5 Lehinna o bu omi sinu awokoto
kan, o si bere si ima we ese awon
omo-ehin re, o si nfi gele ti o fi di
amure nu won.

6 Nigbana li o de odo Simoni
Peteru. On si wi fun u pe, Oluwa,
iwo nwe mi li ese?

7 Jesu dahun o si wi fun u pe, Ohun
ti emi nse iwo ko mo nisisiyi; sugbon
yio ye o nikehin.

8 Peteru wi fun u pe, Iwo ki yio we
mi li ese lai. Jesu da a lohun pe, Bi
emi ko ba we o, iwo ko ni ipin lodo
mi.

9 Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa,
ki ise ese mi nikan, sugbon ati owo ati
ori mi pelu.

10 Jesu wi fun u pe, Eniti a ti we
ko tun fe ju ki a san ese re, sugbon o
mo nibi gbogbo: enyin si mo, sugbon
ki ise gbogbo nyin.

11 Nitoriti o mo eniti yio fi on han;
nitorina li o se wipe, Ki ise gbogbo
nyin li o mo.

12 Nitorina lehin ti o we ese won
tan, ti o si ti mu agbada re, ti o tun
joko, o wi fun won pe, Enyin mo ohun
ti mo se si nyin?

13 Enyin npe mi li Olukoni ati
Oluwa: enyin wi rere; beni mo je.

14 Nje bi emi ti ise Oluwa ati Olu-
koni nyin ba we ese nyin, o to ki
enyin pelu si ma we ese ara nyin.

15 Nitori mo ti fi apere fun nyin,
ki enyin ki o le ma se gege bi mo ti se
si nyin.

16 Loto, loto ni mo wi fun nyin,
Omo-odo ko tobi ju oluwa re lo; beni
eniti a ran ko tobi ju eniti o ran a lo.

17 Bi enyin ba mo nkan wonyi,
alabukun-fun ni nyin, bi enyin ba nse
won.

18 & Ki ise ti gbogbo nyin ni mo
nso: emi mo awon ti mo yan: sugbon
ki iwe-mimo ki o le se, Eniti mba mi
jeun po si gbe gigise re si mi.

19 Lati isisiyi lo mo so fun nyin ki
o to de, pe nigbati o ba de, ki enyin ki
o le gbagbo pe emi ni.

20 Loto, loto ni mo wi fun nyin,
Eniti o ba gba enikeni ti mo ran, o
gba mi; eniti o ba si gba mi o gba eniti
o ran mi.

21 Nigbati Jesu ti wi nkan wonyi
tan, okan re daru ninu re, o si jeri, o
si wipe, Loto loto ni mo wi fun nyin
pe, okan ninu nyin yio fi mi han.

22 Awon omo-ehin re nwo ara won
loju, nwon nsiye-meji ti eniti o wi.

23 Nje enikan rogun si aiya Jesu,
okan ninu awon omo-ehin re, eniti
Jesu feran.

24 Nitorina ni Simoni Peteru sapere
si i, o si wi fun u pe, Wi fun wa ti eniti
o nso.

25 Eniti o nrogun li aiya Jesu wi fun
u pe, Oluwa, tani ise?

26 Nitorina Jesu dahun pe. On na
ni, eniti mo ba fi okele fun nigbati mo
ba fi run. Nigbati o si fi i run tan, o
fifun Judasi Iskariotu omo Simoni.

27 Lehin okele na ni Satani wo inu
re lo. Nitorina Jesu wi fun u pe,
Ohun ti iwo nse ni, yara se e kankan.

28 Ko si si enikan nibi tabili ti o
mo idi ohun ti o se so eyi fun u.

29 Nitori awon miran ninu won ro
pe, nitori Judasi li o ni apo, ni Jesu fi
Wi fun u pe, Ra nkan wonni ti a ko le
se alaini fun ajo na; tabi ki o le fi nkan
fun awon talaka.

30 Nigbati o si ti gba Okele na tan,
o jade lojukanna: oru si ni.

31 & Nitorina nigbati o jade lo tan,
Jesu wipe, Nisisiyi li a yin Omo-enia
logo, a si yin Olorun logo ninu re.

32 Bi a ba yin Olorun logo ninu re,
Olorun yio si yin i logo ninu on tika-
rare, yio si yin i logo nisisiyi.

33 Enyin omode, nigba die si i li
emi wa pelu nyin. Enyin o wa mi:
ati gege bi mo ti wi fun awon Ju pe,
Nibiti emi gbe nlo, enyin ki o le wa;
beni mo si wi fun nyin nisisiyi.

34 Ofin titun kan ni mo fifun nyin,
Ki enyin ki o fe omonikeji nyin; gege
bi emi ti feran nyin, ki enyin ki o si le
feran omonikeji nyin.

35 Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi
mo pe, omo-ehin mi li enyin ise, nigbati
enyin ba ni ife si omonikeji nyin.

36 & Simoni Peteru wi fun u pe,
Oluwa, nibo ni iwo nio? Jesu da a
lohun pe, Nibiti emi nio, iwo ki o le
to mi nisisiyi; sugbon iwo yio to mi
nikehin.

37 Peteru wi fun u pe, Oluwa, ese
ti emi ko fi le to O nisisiyi? emi o fi emi
mi lele nitori re.

38 Jesu da a lohun wipe, Iwo o ha
fi emi re lele nitori mi? Loto, loto ni
mo wi fun o, Akuko ki yio ko, ki iwo
ki o to se mi nigba meta.

/14 E mase je ki okan nyin daru: e gba
Olorun gbo, e gba mi gbo pelu.

2 Ninu ile Baba ni opolopo ibugbe
li o wa: ibamase be, emi iba ti so fun
nyin. Nitori emi nio ipese aye sile fun
nyin.

3 Bi mo ba si lo ipese aye sile fun
nyin, emi o tun pada wa, emi o si mu
nyin lo sodo emi tikarami; pe nibiti
emi gbe wa, ki enyin le wa nibe pelu.

4 Enyin si mo ibi ti emi gbe nio, e si
mo ona na.

5 Tomasi wi fun u pe, Oluwa, a ko
mo ibiti o gbe nio; a o ha ti se mo ona
na?

6 Jesu wi fun u pe, Emi li ona, ati
otito, ati iye: ko si enikeni ti o le wa
sodo Baba, bikose nipase mi.

7 Ibasepe enyin ti mo mi, enyin iba
ti mo Baba mi pelu: lati isisiyi lo
enyin mo o, e si ti ri i.

8 Filippi wi fun u pe, Oluwa, fi Baba
na han wa, o si to fun wa.

9 Jesu wi fun u pe, Bi akoko ti mo
ba nyin gbe ti pe to yi, iwo ko si ti
imo mi sibe Filippi? eniti o ba ti ri mi,
o ti ri Baba; iwo ha ti se wipe, Fi Baba
han wa?

10 Iwo ko ha gbagbo pe, Emi wa
ninu Baba, ati pe Baba wa ninu mi?
oro ti emi nso fun nyin, emi ko da a
so; sugbon Baba ti ngbe inu mi, on ni
nse ise re.

11 E gba mi gbo pe, emi wa ninu
Baba, Baba si wa ninu mi: bikose be,
e gba mi gbo niton awon ise na papa.

12 Loto, loto ni mo wi fun nyin,
Eniti o ba gba mi gbo, ise ti emi nse
li on na yio se pelu; ise ti o tobi ju
wonyi lo ni yio si se; nitoriti emi mo
sodo Baba.

13 Ohunkohun ti enyin ba si bere
li oruko mi, on na li emi o se, ki a le
yin Baba logo ninu Omo.

14 Bi enyin ba bere ohunkohun li
oruko mi, emi o se e.

15 & Bi enyin ba feran mi, e o pa
ofin mi mo.

16 Emi o si here lowo Baba, on o
si fun nyin li Olutunu miran, ki o le
ma ba nyin gbe titi lailai,

17 Ani Emi otito ni; eniti araiye ko
le gba, nitoriti ko ri i, beni ko si mo o:
sugbon enyin mo o; nitoriti o mba
nyin gbe, yio si wa ninu nyin.

18 Emi ki o fi nyin sile li alaini baba:
emi o to nyin wa.

19 Nigba die si i, aiye ki o si ri mi
mo; sugbon enyin o ri mi: nitoriti emi
wa laye, enyin o wa laye pelu.

20 Li ojo na li enyin o mo pe, emi
wa ninu Baba mi, ati enyin ninu mi,
ati emi ninu nyin.

21 Eniti o ba li ofin mi, ti o ba si
npa won mo, on li eniti o feran mi:
eniti o ba si feran mi, a o feran re lati
odo Baba mi wa, emi o si feran re, emi
o si fi ara mi han fun u.

22 Judasi wi fun u pe, (ki ise Iskari-
otu) Oluwa, ehatise ti iwo o fi ara re
han fun awa, ti ki yio si se fun araiye?

23 Jesu dahun o si wi fun u pe, Bi
enikan ba feran mi, yio pa oro mi mo:
Baba mi yio si feran re, awa o si to o
wa, a o si se ibugbe wa pelu re.

24 Eniti ko feran mi ni ko pa oro
mi mo: oro ti enyin ngbo ki si ise ti
emi, sugbon ti Baba ti o ran mi.

25 Nkan wonyi li emi ti so fun nyin,
nigbati mo mba nyin gbe.

26 Sugbon Olutunu na, Emi Mimo,
eniti Baba yio ran li oruko mi, on ni
yio ko nyin li ohun gbogbo, yio si ran
nyin leti ohun gbogbo ti mo ti so fun
nyin.

27 Alafia ni mo fi sile fun nyin,
alafia mi ni mo fifun nyin: ki ise gege
bi aiye iti fi funni li emi fifun nyin.
E mase je ki okan nyin daru, e ma si
je ki o wariri.

28 Enyin sa ti gbo bi mo ti wi fun
nyin pe, Emi nio, emi o si to nyin wa.
Ibasepe enyin feran mi, enyin iba yp
nitori emi nio sodo Baba: nitori Baba
mi tobi ju mi lo.

29 Emi si ti so fun nyin nisisiyi ki
o to se, pe nigbati o ba se, ki e le
gbagbo.

30 Emi ki o ba nyin soro pipo:
nitori alade aiye yi wa, ko si ni nka-
nkan lodo mi.

31 Sugbon nitori ki aiye le my pe
emi feran Baba; gege bi Baba si ti fi
ase fun mi, beni emi nse. E dide, e
je ki a lo kuro nihinyi.

/15 Emi ni ajara toto, Baba mi si ni
olusogba.

2 Gbogbo eka ninu mi ti ko ba so
eso, on a mu u kuro: gbogbo eka ti o
ba si so eso, on a we e nio, ki o le so
eso si i.

3 Enyin mo nisisiyi nitori oro ti mo
ti so fun nyin.

4 E ma gbe inu mi, emi o si ma gbe
inu nyin. Gege bi eka ko ti le so eso
fun ara re, bikosepe o ba ngbe inu
ajara, beli enyin, bikosepe e ba ngbe
inu mi.

5 Emi ni ajara, enyin li eka. Eniti
o ngbe inu mi, ati emi ninu re, on ni
yio so eso opolopo: nitori ni yiyara
nyin kuro lodo mi, e ko le se ohun kan.

6 Bi enikan ko ba gbe inu mi, a gbe
e sonu gege bi eka, a si gbe; nwon a
si ko won jo, nwon a si so won sinu
ina, nwon a si jona.

7 Bi enyin ba ngbe inu mi, ti oro
mi ba si ngbe inu nyin, e o bere ohun-
kohun ti e ba fe, a o si se e fun nyin.

8 Ninu eyi li a yin Baba mi logo pe,
ki enyin ki o ma so eso pupo; enyin o
si je omo-enin mi.

9 Gege bi Baba ti fe mi, beli emi si
fe nyin: e duro ninu ife mi.

10 Bi enyin ba pa ofin mi mo, e o
duro ninu ife mi; gege bi emi ti pa ofin
Baba mi mo, ti mo si duro ninu ife re.

11 Nkan wonyi ni mo ti so fun nyin;
ki ayo mi ki o le wa ninu nyin, ati ki
ayo nyin ki o le kun.

12 Eyi li ofin mi, pe ki enyin la o
feran ara nyin, gege bi mo ti feran
nyin.

13 Ko si enikan ti o ni ife ti o tobi
ju eyi lo, pe enikan fi emi re lele nitori
awon ore re.

14 Ore mi li enyin ise, bi e ba se
ohun ti emi palase fun nyin.

15 Emi ko pe nyin li omo-odo mo;
nitori omo-odo ko mo ohun ti oluwa
re nse: sugbon emi pe nyin li ore;
nitori ohun gbogbo ti mo ti gbo lati
odo Baba mi wa, mo ti fi han fun nyin.

16 Ki ise enyin li o yan mi, sugbon
emi li o yan nyin, mo si fi nyin sipo, ki
enyin ki o le lo, ki e si so eso, ati ki
eso nyin le duro; ki ohunkohun ti e
ba bere lowo Baba li oruko mi, ki o le
fi i fun nyin.

17 Nkan wonyi ni mo palase fun
nyin pe, ki enyin ki o feran ara nyin.

18 Bi aiye ba korira nyin, e mo pe,
o ti korira mi saju nyin.

19 Ibasepe enyin ise ti aiye, aiye iba
fe awon tire; sugbon nitoriti enyin ki
ise ti aiye, sugbon emi ti yan nyin kuro
ninu aiye, nitori eyi li aiye se korira
nyin.

20 E ranti oro ti mo ti so fun nyin
pe, Omo-odo ko tobi ju oluwa re lo.
Bi nwon ba ti se inunibini si mi, nwon
o se inunibini si nyin pelu: bi nwon
ba ti pa oro mi mo, nwon o si pa ti
nyin mo pelu.

21 Sugbon gbogbo nkan wonyi ni
nwon o se si nyin, nitori oruko mi,
nitoriti nwon ko mo eniti o ran mi.

22 Ibasepe emi ko ti wa ki ng si ti
ba won soro, nwon ki ba ti li ese:
sugbon nisisiyi nwon di alairiwi fun
ese won.

23 Eniti o ba korira mi, o korira
Baba mi pelu.

24 Ibasepe emi ko ti se ise wonni
larin won, ti elomiran ko se ri, nwon
ki ba ti li ese: sugbon nisisiyi nwon ti
ri, nwon si korira ati emi ati Baba mi.

25 Sugbon eyi se ki oro ti a ko ninu
ofin won ki o le se pe, Nwon korira
mi li ainidi.

26 Sugbon nigbati Olutunu na ba
de, eniti emi o ran si nyin lati odo
Baba wa, ani Emi otito ni, ti nti odo
Baba wa, on na ni yio jeri mi:

27 Enyin pelu yio si jeri mi, nitoriti
enyin ti wa pelu mi lati ipilese wa.

/16 Nkan wonyi ni mo ti so fun nyin,
ki a ma ba mu nyin kose.

2 Nwon o yo nyin kuro ninu sina-
gogu: ani, akoko mbo, ti enikeni ti o
ba pa nyin, yio ro pe on nse isin fun
Olorun.

3 Nkan wonyi ni nwon o si se,
nitoriti nwon ko mo Baba, nwon ko
si mo mi.

4 Sugbon nkan wonyi ni mo ti so
fun nyin, pe nigbati wakati won ba de,
ki e le ranti won pe mo ti wi fun nyin.
Sugbon emi ko so nkan wonyi fun
nyin lati ipilese wa, nitoriti mo wa
pelu nyin.

5 Sugbon nisisiyi emi nio sodo eniti
o ran mi; ko si si enikan ninu nyin ti
o bi mi lere pe, Nibo ni iwo nlo?

6 Sugbon nitori mo so nkan wonyi
fun nyin, ibinuje kun okan nyin.

7 Sugbon otito li emi nso fun nyin;
Anfani ni yio je fun nyin bi emi ba
lo: nitori bi emi ko ba lo, Olutunu ki
yio to nyin wa: sugbon bi mo ba lo,
emi o ran a si nyin.

8 Nigbati on ba si de, yio fi oye ye
araiye niti ese, ati niti ododo, ati niti
idajo:

9 Niti ese, nitoriti nwon ko gba mi
gbo;

10 Niti ododo, nitoriti emi nlo
sodo Baba, enyin ko si ri mi mo;

11 Niti idajo, nitoriti a ti se idajo
alade aiye yi.

12 Mo ni ohun pipo lati so fun nyin
pelu, sugbon e ko le gba won nisisiyi.

13 Sugbon nigbati on, ani Emi
otito ni ba de, yio to nyin si ona otito
gbogbo; nitori ki yio so ti ara re;
Sugbon ohunkohun ti o ba gbo, on ni
yio ma so: yio si so ohun ti mbo fun
nyin.

14 On o ma yin mi logo: nitoriti yio
gba ninu ti emi, yio si ma so o fun nyin.

15 Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni:
nitori eyi ni mo se wipe, on o gba ninu
temi, yio si so o fun nyin.

16 Nigba die, enyin ki o si ri mi:
ati nigba die ewe, e o si ri mi, nitoriti
emi nio sodo Baba.

17 Nitorina omiran ninu awon omo-
ehin re mba ara won so pe, Kili eyi ti
o nwi fun wa yi, Nigba die, enyin ki o
si ri mi: ati nigba die ewe, enyin o si ri
mi: ati, Nitoriti emi nio sodo Baba?

18 Nitorina nwon wipe, Kili eyi ti
o wi yi, Nigba die? awa ko mo ohun
ti o wi.

19 Jesu sa ti mo pe, nwon nfe lati
bi on lere, o si wi fun won pe, Enyin
mbi ara nyin lere niti eyi ti mo wipe,
Nigba die, enyin ki o si ri mi: ati nigba
die ewe, enyin o si ri mi?

20 Loto, loto ni mo wi fun nyin pe,
Enyin o ma sokun e o si ma pohunrere
ekun, sugbon awon araiye yio ma yo:
mu nyin yio si baje, sugbon ibinuje
nyin li yio si di ayo.

21 Nigbati obirin ba nrobi, a ni
ibinuje, nitoriti wakati re de: sugbon
nigbati o ba ti bi omo na tan, on ki si
iranti irora na mo, fun ayo nitori a bi
enia si aiye.

22 Nitorina enyin ni ibinuje nisisiyi:
sugbon emi o tun ri nyin, okan nyin
yio si yo; ko si si eniti yio gba ayo nyin
lowo nyin.

23 Ati ni ijo na enyin ki o bi mi lere
ohunkohun. Loto, loto ni mo wi fun
nyin, Ohunkohun ti enyin ba bere
lowo Baba li oruko mi, on o fifun nyin.

24 Titi di isisiyi e ko ti ibere ohun-
kohun li oruko mi: e bere, e o si ri
gba, ki ayo nyin ki o le kun.

25 Nkan wonyi ni mo ti fi owe so
fun nyin: sugbon akoko de, nigbati
emi ki yio fi owe ba nyin soro mo,
sugbon emi o so ti Baba fun nyin
gbangba.

26 Li ojo na enyin o bere li oruko
mi: emi ko si wi fun nyin pe, emi o
bere lowo Baba fun nyin:

27 Nitoriti Baba tikarare feran nyin,
nitoriti enyin ti feran mi, e si ti gba-
gbo pe, lodo Olorun li emi ti jade wa.

28 Mo ti odo Baba jade wa, mo si
wa si aiye: ewe, mo fi aiye sile, mo si
nio sodo Baba.

29 Awon omo-ehin re wi fun u pe,
Wo o, nigbayi ni iwo nsoro gbangba,
iwo ko si so ohunkohun li owe.

30 Nigbayi li awa mo pe, iwo mo
ohun gbogbo, iwo ko ni ki a bi o lere:
nipa eyi li awa gbagbo pe, lodo
Olorun ni iwo ti jade wa.

31 Jesu da won lohun pe, Enyin
gbagbo wayi?

32 Kiyesi i, wakati mbo, ani o de
tan nisisiyi, ti a o fon nyin ka kin,
olukuluku si ile re; e o si fi emi nikan
sile: sugbon ki yio si se emi nikan,
nitoriti Baba mbe pelu mi.

33 Nkan wonyi ni mo ti so fun
nyin tele, ki enyin ki o le ni alafia ninu
mi. Ninu aiye, enyin o ni iponju;
sugbon e tujuka; mo ti segun aiye.

/17 Nkan wonyi ni Jesu so, o si gbe oju
re soke orun, o si wipe, Baba,
wakati na de: yin Omo re logo, ki
Omo re ki o le yin o logo pelu:

2 Gege bi iwo ti fun u li ase lori
enia gbogbo, ki o le fi iye ainipekun
fun gbogbo awon ti o fifun u.

3 Iye ainipekun na si li eyi, ki nwon
ki o le mo o, iwo nikan Olorun otito,
ati Jesu Kristi, eniti iwo ran.

4 Emi ti yin o logo li aiye: emi ti
pari ise ti iwo fifun mi lati se.

5 Nje nisisiyi, Baba, se mi logo pelu
ara re, ogo ti mo ti ni pelu re ki aiye
ki o to wa.

6 Emi ti fi oruko re han fun awon
enia ti iwo ti fifun mi lati inu aiye wa:
tire ni nwon ti je ri, iwo si ti fi won fun
mi; nwon si ti pa oro re mo.

7 Nisisiyi nwon mo pe, ohunkohun
gbogbo ti iwo ti fifun mi, lati odo re
wa ni.

8 Nitori oro ti iwo fifun mi, emi ti
fifun won, nwon si ti gba a, nwon si ti
mo nitoto pe, lodo re ni mo ti jade wa,
nwon si gbagbo pe iwo li o ran mi.

9 Emi ngbadura fun won: emi ko
gbadura fun araiye, sugbon fun awon
ti iwo ti fifun mi; nitoripe tire ni nwon
ise.

10 Tire sa ni gbogbo ohun ti ise
temi, ati temi si ni gbogbo ohun ti ise
tire; a si ti se mi logo ninu won.

11 Emi ko si si li aiye mo, awon
wonyi si mbe li aiye, emi si mbo wa
sodo re. Baba mimo, pa awon ti o ti
fifun mi mo, li oruko re, ki nwon ki o
le je okan, ani gege bi awa.

12 Nigbati mo wa pelu won li aiye,
mo pa won mo li oruko re: awon ti
iwo fifun mi, ni mo ti pamo, enikan
ninu won ko si segbe bikose omo egbe;
ki iwe-mimo ki o le se.

13 Sugbon nisisiyi emi si mbo wa
sodo re, nkan wonyi ni mo si nso li
aiye, ki nwon ki o le ni ayo mi ni kikun
ninu awon tikarawon.

14 Emi ti fi oro re fun won; aiye si
ti korira won, nitoriti nwon ki ise ti
aiye, gege bi emi ki iti ise ti aiye.

15 Emi ko gbadura pe, ki iwo ki o
mu won kuro li aiye, sugbon ki iwo ki
o pa won mo kuro ninu ibi.

16 Nwon ki ise ti aiye, gege bi emi
ki ti ise ti aiye.

17 So won di mimo ninu otito:
otito li oro re.

18 Gege bi iwo ti ran mi wa si aiye,
be li emi si ran won si aiye pelu.

19 Emi si ya ara mi si mimo nitori
won, ki a le so awon tikarawon pelu di
mimo ninu otito.

20 Ki si ise kiki awon wonyi ni mo
ngbadura fun, sugbon fun awon pelu
ti yio gba mi gbo nipa oro won;

21 Ki gbogbo nwon ki o le je elean;
gege bi iwo, Baba, ti je ninu mi, ati emi
ninu re, ki awon pelu ki o le je okan
ninu wa: ki aiye ki o le gbagbo pe, iwo
li o ran mi.

22 Ogo ti iwo ti fifun mi li emi si ti
fifun won; ki nwon ki o le je okan,
gege bi awa ti je okan;

23 Emi ninu won, ati iwo ninu mi,
ki a le se won pe li okan; ki aiye ki o
le mo pe, iwo li o ran mi, ati pe iwo
si feran won gege bi iwo ti feran mi.

24 Baba, emi fe ki awon ti iwo fifun
mi, ki o wa lodo mi, nibiti emi gbe wa;
ki nwon le ma wo ogo mi, ti iwo ti fi
fifun mi: nitori iwo sa feran mi siwaju
ipilese aiye.

25 Baba olododo, aiye ko mo o:
sugbon emi mo o, awon wonyi si mo
pe iwo li o ran mi.

26 Mo ti so oruko re di mimo fun
won, emi o si so o di mimo: ki ife ti
iwo feran mi, le ma wa ninu won, ati
emi ninu won.

/18 Nigbati Jesu si ti so nkan wonyi
tan, o jade pelu awon omo-ehin re
lo soke odo Kedroni, nibiti agbala kan
wa, ninu eyi ti o wo, on ati awon
omo-ehin re.

2 Judasi, eniti o fi i han, si mo ibe
pelu: nitori nigba-pupo ni Jesu ima lo
sibe pelu awon omo-ehin re.

3 Nigbana ni Judasi, lehin ti o ti
gba egbe omo-ogun, ati awon onse lati
odo awon olori alufa ati awon Farisi,
wa sibe ti awon ti fitila ati oguso, ati
ohun ija.

4 Nitorina bi Jesu ti mo ohun gbo-
gbo ti mbo wa ba on, o jade io, o si wi
fun won pe. Tali e nwa?

5 Nwon si da a lohun wipe, Jesu ti
Nasareti. Jesu si wi fun won pe, Emi
niyi. Ati Jusadi pelu, eniti o fi i han,
duro pelu won.

6 Nitorina bi o ti wi fun won pe,
Emi niyi, nwon bi sehin, nwon si subu
lule.

7 Nitorina o tun bi won lere, wipe,
Tali e nwa? Nwon si wipe, Jesu ti
Nasareti.

8 Jesu dahun pe, Mo ti wi fun nyin
pe, emi niyi: nje bi emi li e ba nwa, e
je ki awon wonyi ma lo:

9 Ki oro ni ki o le se, eyi ti o wipe,
Awon ti iwo fifun mi, emi ko so okan
nu ninu won.

10 Nigbana ni Simoni Peteru eniti
o ni ida, o fa a yo, o si sa omo-odo olori
alufa, o si ke eti otun re sonu. Oruko
iranse na ama je Malku.

11 Nitorina Jesu wi fun Peteru pe,
Te ida re bo inu ako re: ago ti Baba ti
fifun mi, emi o se alaimu u bi?

12 Nigbana li egbe omo-ogun, ati
olori eso, ati awon onse awon Ju mu
Jesu, nwon si de e.

13 Nwon ko fa a lo sodo Anna;
nitori on ni ise ana Kaiafa, eniti ise
olori alufa li odun na.

14 Kaiafa sa ni ise, eniti o ti ba awon
Ju gbimo pe, o sanfani ki enia kan ku
fun awon enia.

15 & Simoni Peteru si nto Jesu
lehin, ati omo-ehin miran kan: omo-
ehin na je eni mimo fun olori alufa, o
si ba Jesu wo afin olori alufa lo.

16 Sugbon Peteru duro li enu-Ona
lode. Nigbana li omo-ehin miran ni,
ti ise eni mimo fun olori alufa, o jade
lo, o si ba olusona na so o, o si mu
Peteru wole.

17 Nigbana li omobirin na ti nso
enu-ona wi fun Peteru pe, Iwo pelu ha
se okan ninu awon omo-ehin okonrin
yi bi? O wipe, Emi ko.

18 Awon omo-odo ati awon onse
si duro nibe, awon eniti o ti dana eyin;
nitori otutu mu, nwon si nyana: Peteru
si duro pelu won, o nyana.

19 & Nigbana li olori alufa bi Jesu
lere niti awon omo-ehin re, ati niti
eko re.

20 Jesu da a lohun wipe, Emi ti
soro ni gbangba fun araiye; nigba-
gbogbo li emi nkoni ninu sinagogu, ati
ni tempili nibiti gbogbo awon Ju
npejo si: emi ko si so ohun kan ni
ikoko.

21 Ese ti iwo fi mbi mi lere? bere
lowo awon ti o ti gbo oro mi, ohun ti
mo wi fun won: wo o, awon wonyi
mo ohun ti emi wi.

22 Bi o si ti wi eyi tan, okan ninu
awon onse ti o duro ti i fi owe re lu
Jesu, wipe, Olori alufa ni iwo nda
lohun be?

23 Jesu da a lohun wipe, Bi mo ba
soro buburu, jeri si buburu na:
sugbon bi rere ba ni, ese ti iwo fi nlu
mi?

24 Nitori Anna ran a lo ni dide
sodo Kaiafa olori alufa.

25 Sugbon Simoni Peteru duro, o si
nyana. Nigbana ni nwon wi fun u
pe, Iwo pelu ha se okan ninu awon
omo-ehin re? O si se, o si wipe, Emi
ko.

26 Okan ninu awon omo-odo olori
alufa, ti ise ibatan eniti Peteru ke eti
re sonu, wipe, Emi ko ha ri o pelu re
li agbala?

27 Nitorina Peteru tun se: loju-
kanna akuko si ko.

28 & Nitorina nwon fa Jesu lati
odo Kaiafa lo si ibi gbangan idajo:
o si je kutukutu owuro; awon tikara-
won ko wo inu gbangan idajo, ki nwon
ki o ma se di alaimo, sugbon ki nwon
ki o le je ase irekoja.

29 Nitorina Pilatu jade to won lo,
o si wipe, Esun kili enyin mu wa si
okonrin yi?

30 Nwon si dahun wi fun u pe,
Ibamasepe okonrin yi nhuwa ibi, a ki
ba ti fa a le o lowo.

31 Nitorina Pilatu wi fun won pe,
E mu u tikaranyin, ki e si se idajo re
gege bi ofin nyin. Nitorina li awon
Ju wi fun u pe, Ko to fun wa lati pa
enikeni:

32 Ki oro Jesu ki o le ba se, eyiti o
so, ti o nsapere iru iku ti on o ku.

33 Nitorina Pilatu tun wo inu gba-
ngan idajo lo, o si pe Jesu, o si wi fun
u pe, Oba awon Ju ni iwo ise?

34 Jesu dahun pe, Iwo so eyi fun
ara re ni, tabi awon elomiran so o fun
o nitori mi?

35 Pilatu dahun wipe, Emi ise Ju
bi? Awon orile-ede re, ati awon olori
alufa li o fa o le emi lowo: kini iwo
se?

36 Jesu dahun wipe, Ijoba mi ki ise
ti aiye yi; ibasepe ijoba mi ise ti aiye
yi, awon onse mi iba ja, ki a ma ba fi
mi le awon Ju lowo: sugbon nisisiyi
ijoba mi ki ise lati ihin lo.

37 Nitorina Pilatu wi fun u pe, Nje
iwo ha se oba bi? Jesu dahun wipe,
Iwo wipe, oba li emi ise. Nitori eyi
li a se bi mi, ati nitori idi eyi ni mo si se
wa si aiye, ki emi ki o le jeri si otito.
Olukuluku eniti ise ti otito ngbo ohun
mi.

38 Pilatu wi fun u pe, Kili otito?
Nigbati o si ti wi eyi tan, o tun jade to
awon Ju lo, o si wi fun won pe, Emi
ko ri ese kan lowo re.

39 Sugbon enyin ni asa kan pe, ki
emi ki o da okan sile fun nyin nigba
ajo irekoja: nitorina e ha fe ki emi ki o
da Oba awon Ju sile fun nyin bi?

40 Nitorina gbogbo won tun kigbe
wipe, Ki ise okonrin yi, bikose Barab-
ba. Olosa si ni Barabba.

/19 Nitorina ni Pilatu mu Jesu, o si
na a.

2 Awon omo-ogun si wun ade
egun, nwon si fi de e li ori, nwon si fl
aso igunwa elese aluko wo o.

3 Nwon si wipe, Kabiyesi, Oba
awon Ju! nwon si fi owe won gba a
loju.

4 Pilatu si tun jade, o si wi fun won
pe. Wo o, mo mu u jade to nyin wa, ki
enyin ki o le mo pe, emi ko ri ese kan
lowo re.

5 Nitorina Jesu jade wa, ti on ti ade
egun ati aso elese aluko. Pilatu si wi
fun won pe, E wo okonrin na!

6 Nitorina nigbati awon olori alufa,
ati awon onse ri i, nwon kigbe wipe,
Kan a mo agbelebu, kan a mo agbe-
lebu. Pilatu wi fun won pe, E mu u
fun ara nyin, ki e si kan a mo agbelebu:
nitoriti emi ko ri ese lowo re.

7 Awon Ju da a lohun wipe, Awa
li ofin kan, ati gege bi ofin wa o ye lati
ku, nitoriti o fi ara re se Omo Olorun.

8 & Nitorina nigbati Pilatu gbo oro
yi eru tube ba a.

9 O si tun wo inu gbangan idajo lo,
o si wi fun Jesu pe, Nibo ni iwo ti wa?
Sugbon Jesu ko da a lohun.

10 Nitorina Pilatu wi fun u pe, Emi
ni iwo ko fohun si? iwo ko mo pe,
emi li agbara lati da o sile, emi si li
agbara lati kan o mo agbelebu?

11 Jesu da a lohun pe, Iwo ki ba ti
li agbara kan lori mi, bikosepe a fi i
fun o lati oke wa: nitorina eniti o fi mi
le o lowo li o ni ese poju.

12 Nitori eyi Pilatu nwa ona lati da
a sile: sugbon awon Ju kigbe, wipe, Bi
iwo ba da okonrin yi sile, iwo ki ise
ore Kesari: enikeni ti o ba se ara re li
oba, o soro odi si Kesari.

13 & Nitorina nigbati Pilatu gbo
oro wonyi, o mu Jesu jade wa, o si joko
lori ite idajo ti a npe ni Okuta-tite,
sugbon li ede Heberu, Gabbata.

14 O je Ipalemo ajo irekoja, o je
iwon wakati ekefa: o si wi fun awon
Ju pe, E wo Oba nyin!

15 Nitorina nwon kigbe wipe, Mu
u kuro, mu u kuro, kan a mo agbelebu.
Pilatu wi fun won pe, Emi o ha kan
Oba nyin mo agbelebu bi? Awon
olori alufa dahun wipe,

16 Awa ko li oba bikose Kesari.
Nigbana li o fa a le won lowo lati kan
a mo agbelebu.

17 Nitorina nwon mu Jesu, o si jade
lo, o ru agbelebu fun ara re si ibi ti a
npe ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a
npe ni Golgota:

18 Nibiti nwon gbe kan a mo
agbelebu, ati awon meji miran pelu
re, niha ikini ati niha keji, Jesu si wa
larin.

19 & Pilatu si ko iwe akole kan
pelu, o si fi i le ori agbelebu na. Ohun
ti a si ko ni, JESU TI NASARETI
OBA AWON JU.

20 Nitorina opo awon Ju li o ka iwe
akole yi: nitori ibi ti a gbe kan Jesu
mo agbelebu sunmo eti ilu: a si ko o
li ede Heberu, ati ti Latini, ati ti
Helene.

21 Nitorina awon olori alufa awon
Ju wi fun Pilatu pe, Mase ko o pe,
Oba awon Ju; sugbon pe on wipe,
Emi li Oba awon Ju.

22 Pilatu dahun pe, Ohun ti mo ti
ko tan, mo ti ko na.

23 & Nigbana li awon omo-ogun,
nigbati nwon kan Jesu mo agbelebu
tan, nwon mu aso re, nwon si pin
won si ipa merin, apakan fun omo-
ogun kokan, ati toro re: sugbon toro
na ko li ojuran, nwon wun u lati oke
titi jale.

24 Nitorina nwon wi fun ara won
pe, E ma je ki a fa a ya, sugbon ki a
se gege nitori re, ti eniti yio je: ki iwe-
mimo ki o le se, ti o wipe, Nwon pin
aso mi larin ara won, nwon si se gege
fun aso ileke mi. Nkan wonyi li
awon omo-ogun se.

25 Iya Jesu ati arabirin iya re Maria
aya Klopa, ati Maria Magdalene, si
duro nibi agbelebu.

26 Nitorina nigbati Jesu ri iya re,
ati omo-ehin na duro, eniti Jesu feran,
o wi fun iya re pe, Obirin, wo omo re!

27 Lehin na li o si wi fun omo-ehin
na pe, Wo iya re! Lati wakati na lo
li omo-ehin na si ti mu u lo si ile ara
re.

28 & Lehin eyi, bi Jesu ti mo pe, a
ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe-mimo
le ba se, o wipe, Orungbe ngbe mi.

29 A gbe ohun elo kan kale nibe ti
o kun fun oti kikan: nwon si fi spunge
ti o kun fun oti kikan, son igi hissopu,
nwon si fi si i li enu.

30 Nitorina nigbati Jesu si ti gba
oti kikan na, o wipe, O pari: o si te ori
re ba, o jowo emi re lowo.

31 Nitori o je ojo Ipalemo, ki oku
won ma ba wa lori agbelebu li ojo
isimi, (nitori ojo nla ni ojo isimi na)
nitorina awon Ju be Pilatu pe ki a se
egungun itan won, ki a si gbe won
kuro.

32 Nitorina awon omo-ogun wa,
nwon si se egungun itan ti ekini, ati
ti ekeji, ti a kan mo agbelebu pelu re.

33 Sugbon nigbati nwon de odo
Jesu, ti nwon si ri pe, o ti ku na, nwon
ko si se egungun itan re:

34 Sugbon okan ninu awon omo-
ogun na fi oko gUn u li egbe, lojukanna
eje ati omi si tu jade.

35 Eniti o ri i si jeri, otito si li eri
re: o si mo pe oto li on wi, ki enyin ki
o le gbagbo.

36 Nkan wonyi se, ki iwe-mimo ki
o le se, ti o wipe, A ki yio fo egungun
re.

37 Iwe-mimo miran ewe si wipe,
Nwon o ma wo eniti a gun li oko.

38 & Lehin nkan wonyi ni Josefu
ara Arimatea, eniti ise omo-ehin Jesu,
sugbon ni ikoko nitori iberu awon Ju,
o be Pilatu ki on ki o le gbe oku Jesu
kuro: Pilatu si fun u li ase. Nitorina
li o wa, o si gbe oku Jesu lo.

39 Nikodemu pelu si wa, eniti o to
Jesu wa loru lakose, o si mu adapo
ojia ati aloe wa, o to iwon ogorun litra.

40 Beni nwon gbe oku Jesu, nwon
si fi aso Ogbo di i pelu turari, gege bi
ise awon Ju ti ri ni isinku won.

41 Agbala kan si wa nibiti a gbe
kan a mo agbelebu; iboji titun kan si
wa ninu agbala na, ninu eyiti a ko ti
ite enikeni si ri.

42 Nje nibe ni nwon si te Jesu si,
nitori Ipalemo awon Ju; nitori iboji
na wa nitosi.

/20 Li ojo ikini ose ni kutukutu nigbati
ile ko ti imo, ni Maria Magdalene
wa si iboji, o si ri pe, a ti gbe okuta
kuro li enu iboji.

2 Nitorina o sare, o si to Simoni
Peteru wa, ati omo-ehin miran na eniti
Jesu feran, o si wi fun won pe, Nwon
ti gbe Oluwa kuro ninu iboji, awa ko
si mo ibi ti nwon gbe te e si.

3 Nigbana ni Peteru jade, ati omo-
ehin miran na, nwon si wa si iboji.

4 Awon mejeji si jumo sare: eyi
omo-ehin miran ni si sare ya Peteru,
o si teteko de igoji.

5 O si bere, o si wo inu re, o ri aso
Ogbo na lele; sugbon on ko wo inu re.

6 Nigbana ni Simoni Peteru ti mbo
lehin re de, o si wo inu iboji, o si ri aso
ogbo na lele,

7 Ati pe gele, ti o wa nibi ori re,
ko si wa pelu aso ogbo na, sugbon a
ka a jo ni ibikan fun ara re.

8 Nigbana li omo-ehin miran na,
eniti o ko de iboji, wo inu re pelu, o si
ri, o si gbagbo.

9 Nitoripe nwon ko sa ti imo iwe-
mimo pe, on ko le saima jinde kuro
ninu oku.

10 Beli awon omo-ehin na si tun
pada lo si ile won.

11 & Sugbon Maria duro leti iboji
lode, o nsokun: bi o ti nsokun, beli o
bere, o si wo inu iboji.

12 O si kiyesi awon angeli meji
alaso funfun, nwon joko, okan niha
ori, ati okan niha ese, nibiti oku Jesu
gbe ti sun si.

13 Nwon si wi fun u pe, Obirin yi,
ese ti iwo fi nsokun? O si wi fun won
pe, Nitoriti nwon ti gbe Oluwa mi, emi
ko si mo ibiti nwon gbe te e si.

14 Nigbati o si ti wi eyi tan, o
yipada, o si ri Jesu duro, ko si mo pe
Jesu ni.

15 Jesu wi fun u pe, Obirin yi, ese
ti iwo fi nsokun? tani iwo nwa? On
sebi olusogba ni ise, o wi fun u pe,
Alagba, bi iwo ba ti gbe e kuro nihin,
so ibiti o gbe te e si fun mi, emi o si
gbe e kuro.

16 Jesu wi fun u pe, Maria. O si
yipada, o wi fun u pe, Rabboni; eyi ti
o je Olukoni.

17 Jesu wi fun u pe, Mase fi owe
kan mi; nitoriti emi ko ti igoke lo
sodo Baba mi: sugbon lo sodo awon
arakonrin mi, si wi fun won pe, Emi
ngoke lo sodo Baba mi, ati Baba nyin;
ati sodo Olorun mi, ati Olorun nyin.

18 Maria Magdalene wa, o si so fun
awon omo-ehin pe, on ti ri Oluwa, ati
pe, o si ti so nkan wonyi fun on.

19 Lojo kanna, lojo ikini ose ni-
gbati ale le, ti a si ti ti ilekun ibiti awon
omo-ehin gbe pejo, nitori iberu awon
Ju, beni Jesu de, o duro larin, o si wi
fun won pe, Alafia fun nyin.

20 Nigbati o si ti wi be tan, o fi owo
ati iha re han won. Nitorina li awon
omo-ehin yo, nigbati nwon ri Oluwa.

21 Nitorina Jesu si tun wi fun won
pe, Alafia fun nyin: gege bi Baba ti
ran mi, beli emi si ran nyin.

22 Nigbati o si ti wi eyi tan, o mi si
won, o si wi fun won pe, E gba Emi
Mimo:

23 Ese enikeni ti enyin ba fi ji, a fi
ji won; ese enikeni ti enyin ba da duro,
a da won duro.

24 & Sugbon Tomasi, okan ninu
awon mejila, ti a npe ni Didimu, ko
wa pelu won nigbati Jesu de.

25 Nitorina awon omo-ehin iyoku
wi fun u pe, Awa ti ri Oluwa. Su-
gbon o wi fun won pe, Bikosepe mo
ba ri apa iso li owe re ki emi ki o si fi
ika mi si apa iso na, ki emi ki o si fi
owo mi si iha re, emi ki yio gbagbo.

26 & Lehin ijo mejo awon omo-ehin
si tun wa ninu ile, ati Tomasi pelu won:
nigbati a si ti ti ilekun, Jesu de, o si
duro larin, o si wipe, Alafia fun nyin.

27 Nigbana li o wi fun Tomasi pe,
Mu ika re wa nihin, ki o si wo owo mi;
si mu owe re wa nihin, ki o si fi si iha
mi: ki iwo ki o mase alaigbagbo mo,
sugbon je onigbagbo.

28 Tomasi dahun o si wi fun u pe,
Oluwa mi ati Olorun mi!

29 Jesu wi fun u pe, nitoriti iwo ri
mi ni iwo se gbagbo: alabukun-fun li
awon ti ko ri, ti nwon si gbagbo.

30 & Opolopo ise ami miran ni Jesu
se niwaju awon omo-ehin re, ti a ko
ko sinu iwe yi:

31 Sugbon wonyi li a ko, ki enyin
ki o le gbagbo pe, Jesu ni ise Kristi na,
Omo Olorun; ati ni gbigbagbo, ki
enyin ki o le ni iye li oruko re.

/21 Lehin nkan wonyi, Jesu tun fi ara
re han fun awon omo-ehin re leti
okun Tiberia; bayi li o si farahan.

2 Simoni Peteru, ati Tomasi ti a
npe ni Didimu, ati Natanaeli ara Kana
ti Galili, ati awon omo Sebede, ati
awon omo-ehin re meji miran jumo
wa po.

3 Simoni Peteru wi fun won pe,
Emi nlo ipeja. Nwon wi fun u pe,
Awa pelu mba o lo. Nwon jade,
nwon si wo inu oko; li oru na nwon
ko si mu ohunkohun.

4 Sugbon nigbati ile bere si imo,
Jesu duro leti okun: sugbon awon
omo-ehin ko mo pe Jesu ni.

5 Nitorina Jesu wi fun won pe,
Enyin omode, e li onje die bi? Nwon
da a lohun wipe, Ndao.

6 O si wi fun won pe, E so awon si
apa otun oko, enyin o si ri. Nitorina
nwon so o, nwon ko si le fa a jade
nitori opo eja.

7 Nitorina li omo-ehin na ti Jesu
feran wi fun Peteru pe, Oluwa ni.
Nigbati Simoni Peteru gbo pe Oluwa
ni, beli o di amure ewu re mora,
(nitori o wa ni ihoho), o si gbe ara re
so sinu okun.

8 Sugbon awon omo-ehin iyoku mu
oko kekere kan wa (nitoriti nwon ko
jina sile, sugbon bi iwon igba igbo-
nwo); nwon nwo awon na ti o kun
fun eja.

9 Nigbati nwon gunle, nwon ri ina
eyin nibe, ati eja lori re, ati akara.

10 Jesu wi fun won pe, E mu ninu
eja ti e pa nisisiyi wa.

11 Nitorina Simoni Peteru goke, o
si fa awon na wale, o kun fun eja nla,
o je metaleladojo: bi nwon si ti po to
ni, awon na ko ya.

12 Jesu wi fun won pe, E wa jeun
owuro. Ko si si enikan ninu awon
Omo-ehin ti o je bi i pe, Tani iwo ise?
nitoriti nwon mo pe Oluwa ni.

13 Jesu wa, o si mu akara, o si fifun
won, gege be si li eja.

14 Eyi ni igba keta nisisiyi ti Jesu
farahan awon omo-ehin re, lehin
igbati o jinde kuro ninu oku.

15 & Nje lehin igbati nwon jeun
owuro tan, Jesu wi fun Simoni Peteru
pe, Simoni, omo Jona, iwo fe mi ju
awon wonyi lo bi? O si wi fun u pe,
Beni Oluwa; iwo mo pe, mo feran re.
O wi fun u pe, Ma bo awon odo-
agutan mi.

16 O tun wi fun u nigba keji pe,
Simoni, omo Jona, iwo fe mi bi? O
wi fun u pe, Beni Oluwa; iwo mo pe,
mo feran re. O wi fun u pe, Ma bo
awon agutan mi.

17 O wi fun u nigba keta pe, Simoni,
omo Jona, iwo feran mi bi? Inu
Peteru baje, nitoriti o wi fun u nigba
eketa pe, Iwo feran mi bi? O si wi
fun u pe, Oluwa, iwo mo ohun gbogbo;
iwo mo pe, mo feran re. Jesu wi fun
u pe, Ma bo awon agutan mi.

18 Loto, loto ni mo wi fun o, ni-
gbati iwo wa li ode-mode, iwo a ma di
ara re li amure, iwo a si ma rin lo si
ibiti iwo ba fe: sugbon nigbati iwo ba
di arugbo, iwo o na owe re jade, elo-
miran yio si di o li amure, yio si mu o
lo si ibiti iwo ko fe.

19 O wi eyi, o fi nsapere iru iku ti
yio fi yin Olorun logo. Lehin igbati
o si ti wi eyi tan, o wi fun u pe, Ma to
mi lehin.

20 Peteru si yipada, o ri omo-ehin
ni, eniti Jesu feran, mbo lehin; eniti o
si rogun si aiya re nigba onje ale ti o
si wi fun u pe, Oluwa, tali eniti o fi o
han?

21 Nigbati Peteru ri i, o wi fun Jesu
pe, Oluwa, Eleyi ha nko?

22 Jesu wi fun u pe, Bi emi ba fe ki
o duro titi emi o fi de, kili eyini si o?
iwo ma to mi lehin.

23 Nitorina oro yi si tan ka larin
awon arakonrin pe, omo-ehin ni ki
yio ku: sugbon Jesu ko wi fun u pe,
On ki yio ku; sugbon, Bi emi ba fe ki
o duro titi emi o fi de, kili eyini si o?

24 Eyi li omo-ehin na, ti o jeri
nkan wonyi, ti o si kowe nkan wonyi:
awa si mo pe, otito li eri re.

25 Opolopo ohun miran pelu ni
Jesu se, eyiti bi a ba kowe won li
okokan, mo ro pe aiye papa ko le gba
iwe na ti a ba ko. Amin.